title
stringlengths 16
155
| text
stringlengths 248
10.5k
| url
stringlengths 48
132
| date
stringdate 2025-01-01 00:00:00
2025-12-04 00:00:00
| source_type
stringclasses 2
values |
|---|---|---|---|---|
Wo ohun mẹ́ta tí oríṣi gèlè wíwé ń sọ àti ohun tí ọ̀nà márùn-ún tí a ń gbà dé fìlà ń wí
|
Ni ilẹ Yoruba, onírúurú ọna mẹta ni àwọn obìnrin ń gba we gèlè. Wọn máa ń we gele si iwaju, ẹyin tàbí ẹgbẹ. Ikọọkan ọna mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọn ń gba we gèlè yìí sí lo ni ìtumọ̀ tiwọn. Bákan náà ni fìlà dìde, ọ̀nà márùn-ún ni àwọn ọkùnrin ń gba de fila wọn. Wọn le de fila sì ọwọ́ iwájú, ẹyin, ẹgbẹ́ ọ̀tun tàbí òsì tàbí kí wọn na fìlà náà gogoro sì òkè Ikọọkan ọna maraarun tí wọn ń gba de fila yìí sí lo ni ìtumọ̀ tiwọn. BBC News Yorùbá wà ṣe àkójọpọ̀ àwọn ọ̀nà tí obìnrin ń gba wé gèlè àti ọ̀nà márùn-ún tí ọkùnrin ń gbà gẹ fìlà pẹ̀lú ohun tí àwọn ìlànà náà túmọ̀ sí. Ìgbàgbọ́ Yoruba ni pé bí àwọn obinrin to wa nile ọkọ lọ máa ń kọ ojú gele wọn sì ọwọ́ iwájú. Ìdí ni pé tiwọn ni ayé ń gbọ́. Bákan náà, wọn gbagbọ pé àwọn obìnrin tó ti di arúgbó lọ máa ń we gele si ọwọ́ ẹyin. Èyí túmọ̀ sí pé ọjọ́ wọn tí di alẹ. Àmọ́ ọmọge to ń wá ọkọ lọ máa ń kọ ojú gele rẹ sì ọwọ́ ẹgbẹ́. Bí ọkùnrin bá gẹ fìlà sì ọwọ́ iwájú, ó túmọ̀ sí pé ayé dun jẹ ju ìyá lọ, sì ń bẹ lọ́wọ́ iwájú. Bí wọn ba gẹ fìlà sì ọwọ́ àlàáfíà, ó túmọ̀ sí pé ọkùnrin bẹẹ tí ní ìyàwó nílẹ̀. Bí ọkùnrin bá gẹ fìlà sì apá ọ̀tún, ó túmọ̀ sí pé apọn ni, kò ti ní ìyàwó nílẹ̀, ó sì ń wá ìyàwó. Bí ọkùnrin bá sì gẹ fìlà sì ọwọ́ ẹyin, ó túmọ̀ sí pé kò sí ohun tuntun lábẹ́ ọrùn mọ. Àmọ́ tí ọkùnrin kan kan ṣe fìlà rẹ gogoro, ó túmọ̀ sí pé ó ń sọ fún àwọn èèyàn pé ẹni ńlá ni òun. Ibo wá ní ẹyin ń kọ ojú fìlà àbí gele yín sí?
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cr5e9e70zmno
|
2025-11-13
|
bbc
|
Kí ló fà á táwọn agbébọn ṣe rọgba yí ìpínlẹ̀ Kwara ká àti ipa tó ní lórí aráàlú?
|
Ni bii ọdun mẹwaa sẹyin, ọkan lara awọn ipinlẹ ti eto aabo rẹ duro ire ni ipinlẹ Kwara jẹ ṣugbọn eyi ti yipada lati bii ọdun diẹ bayii Awọn olugbe Kwara paapaa lawọn agbegbe kan ni ijọba ibilẹ Lafiagi, Patigi, Edu àti Baruten ni ẹkun ariwa ati ifelodun, Irepodun, Isin ati ijọba ibilẹ Ekiti ko le sun asunpiye mọ bayii Eyi ko ṣẹyin bi ijinigbe ati ipaniyan ṣe n gbilẹ lojoojumọ lawọn agbegbe yii. Ni ọsẹ to kọja lawọn agbebọn yawọ ile ijọsin CAC ni ilu Eruku, ṣekupa eeyan mẹta, ji eeyan mejidinlọgbọn gbe lọ ki wọn to gba itusilẹ ni ahamọ awọn ajinigbe naa lẹyn ọjọ marun-un Oríṣun àwòrán,Truth Nigeria Ṣaaju asiko yii ni awọn eeyan ilu Oke Ode ni ijọba ibilẹ Ifelodun sa fi ile wọn silẹ lẹyin ikọlu awọn agbebọn to ṣekupa eeyan mọkanla. Inu oṣu Kẹjọ ni ilu Babanla atawọn ilu to wa ni agbegbe rẹ di ahoro latari ikọlu awọn agbebọn Ni ẹkun ariwa, ninu oṣu kẹrin ọdun yii ni awọn agbebọn yawọ ibudokọ kan ni Ilesha Baruba, ijọba ibilẹ Baruten ti wọn si ṣina ibọn bolẹ nibi ti eeyan mẹjọ ti padanu ẹmi wọn Ni ilu Karunji ati Kermanji, bakan naa ni ọmọ ṣe ṣori Ọpọ awọn olugbe ilu Lafiaji, ijọba ibilẹ Edu nibi ti iwa ijinigbe ti di tọrọ fọkanle, lo ti n fi ilu silẹ lati wa aabo lọ sawọn ibomiran Ibeere to gbẹnu ọpọ eeyan ni pe ki ni o ṣokunfa ijinigbe ati ipenija eto aabo to n sọ awọn olugbe ipinlẹ Kwara sinu inu fu aya fu yii? Nigba to n ba BBC News Yoruba, ọkan lara awọn eekan ilu ni ijọba ibilẹ ti ko fẹ darukọ oun woye pe lati bii ọdun 2016 si 2017 ni awọn agbebọn yii ti n fi awọn inu igbo to wa ni ipinlẹ Kwara ṣe ibugbe tawọn eeyan si gbiyanju ta awọn ijọba lolobo. "Lati igba tawọn agbebọn yii ti wa ninu igbo lati bii ọdun 2016 si 2017, wọn ko maa ṣe ikọlu rara titi di nnkan bii oṣu mẹrin si marun-un sẹyin lọ. Ero rẹ yii yatọ diẹ si ti Ọjọgbọn Abdulganiy Jawondo, onimọ nipa itan ni ile ẹkọ giga fasiti, University of Ilorin to gbagbọ pe awọn agbebọn yii ko fi ipinlẹ Kwara ṣe ibujokoo. Jawondo, to tun figba kan ri jẹ adari ẹka imọ nipa ipẹtusaawọ, Centre for Peace and Strategic Studies ní University of Ilorin sọ pe afẹfẹ awọn ohun to n ṣẹlẹ ni awọn ipinlẹ to paala pẹlu Kwara lasan ni a n ri bayii. Amọ awọn mejeeji lo gba pe ohun alumọni inu ilẹ wa lara ohun to bi ikọlu awọn agbebọn paapaa ni ẹkun ariwa Kwara. "O ṣeeṣe ko jẹ pe awọn ohun alomọni inu ilẹ lo ṣokunfa ikọlu awọn agbebọn yii nitori bi awọn to n wakusa ṣe n wọ ọpọ awọn ilu ti ohun alumọni wa lati gba aṣẹ fun iwakusa n pọ si. "Láti bíi ọdún meji sẹyin bayii ni awọn awakusa labẹle atawọn ti ilẹ okeere n pọ si ni Kwara lati maa wa kusa." Wọn rọ ijọba Kwara lati ri pe wọn mojuto eto iwakusa lojuna ati dena awọn to n lo awọn agbebọn lati maa fi da aabo iṣẹ ibi ti wọn n ṣe. Ohun mii ti wọn ni o ṣokunfa bi awọn ajinigbe ṣe pọ lawọn ijọba ibilẹ yii ni pe o kun fun igbo eyi tawọn agbebọn le ha si fun igba pipẹ lai ni fu eeyan lara. Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Kwara, Rafiu Ajakaye nigba to n ba BBC sọrọ ṣalaye pe ọpọ awuyewuye lo ti n waye lori eto aabo to mẹhẹ ni Kwara. O ni gbogbo igbesẹ to yẹ lati da aabo bo awọn eeyan ni ijọba n gbe ati gbogbo awọn ọlọpaa àtawọn ọmọ ogun ni wọn ti da sinu igbo lati ri pe aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia awọn eeyan.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c3v1r6wyq0do
|
2025-11-28
|
bbc
|
Agbébọn jí obìnrin tó fẹ́ ṣe ìgbéyàwó láàárọ̀ òní, ọ̀rẹ́ rẹ̀, àtàwọn mẹ́jọ míì gbé lọ
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Agbebọn ti ji obinrin to n mura igbeyawo ati ọrẹ rẹ timọtimọ gbe labule Chacho, ni ijọba ibilẹ Wurno, ni ipinlẹ Sokoto. Ileeṣẹ iroyin Channels jabọ pe nnkan bii aago kan abọ oru ni awọn agbesunmọmi naa yabo abule ọhun ti wọn si gbe iyawo, ọrẹ iyawo atawọn mẹjọ mii gbe lọ nibẹ. Awọn eeyan to n gbe lagbegbe naa sọ pe ọjọ keji ọjọ Aiku naa gan ti iṣẹlẹ ọhun waye ni wọn ji obinrin naa gbe. Gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lo jẹ obinrin, ayafi ọkunrin kan to farapa lasiko ikọlu naa to si ti n gba itọju lọwọ bayii. Ọkan lara olugbe ilu naa ti ko fẹ ki awọn akọroyin darukọ oun sọ pe iṣẹlẹ ọhun jẹ eyii to buru jai to si da omi tutu si ọkan awọn. O ni aarọ oni ọjọ Aje lo yẹ ki obinrin naa ṣe igbeyawo ki wọn to gbe oun ati ọrẹ rẹ lọ. Ẹni naa fi kun pe awọn ke si awọn agbofinro lasiko ti ikọlu naa n lọ lọwọ amọ wakati kan lẹyin ti awọn agbesunmọmi naa na papa bora ni ọlọpaa to de. Gẹgẹ bo ṣe sọ, bi wọn ṣe pẹ de naa jẹ ki ikọlu ọhun tubọ dun awọn eeyan naa. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ O ni " A n ke si ijọba ki wọn ji giri si ojuṣe wọn lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu." Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpee ipinlẹ naa, DSP Ahmad Rufa'i, to fidi iroyin naa mulẹ fun ileeṣẹ iroyin Channels ni awọn ti gbe igbesẹ lọri ikọlu ọhun. Iṣẹlẹ yii tun ti kun oniruru iṣẹlẹ ijinigbe ati iṣẹrubalu to n waye lemọlemọ ni Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yii. Ṣaaju lọjọ Aiku ni awọn agbebọn kọlu ile ijọsin alaṣọ funfun kan nipinlẹ Kogi, nibi ti wọn ti gbe pasitọ atawọn ọmọ ijọ kan lọ nibẹ. Asiko ti isin n lọ lọwọ ni awọn agbesunmọmi naa kọlu ile ijọsin Cherubim and Seraphim Church to wa ni Ejiba, ni ijọba ibilẹ Yabgba, nipinlẹ ọhun.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cgkemlmk12ro
|
2025-12-01
|
bbc
|
Wo àwọn orílẹ̀èdè tó ṣeéṣe kí Super Eagles bá pàdé nínú 'Play Off' láti yege lọ sí ìdíje fún ife ẹ̀yẹ àgbáyé
|
Oríṣun àwòrán,NurPhoto via Getty Images Ajọ ere bọọlu ni ilẹ Adulawọ CAF, ti jẹ kede ibi ti ifẹsẹwọnsẹ idije awọn ipo keji orilẹede ti wọn ko ni anfani lati lọ si idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye ni ọdun to n bọ. Ninu atẹjade ti CAF fi lede, orilẹede Morocco, to n gba alejo idije ife ẹyẹ adulawọ ti ọdun 2025 naa ni yoo gba alejo idije Play Off yii laarin awọn orilẹede ilẹ Afrika. Awọn orilẹede mẹrin ti wọn wa ni ipo keji ṣugbọn ni ọpọ ami ni wọn yoo ni anfani lati kopa ninu idije Play Off yii. Ikọ Super Eagles orilẹede Naijiria yoo pẹlu awọn orilẹede yii bi wọn ṣe bori awọn akẹgbẹ wọn lati orilẹede Benin pẹlu ami ayo mẹrin si odo. Victor Oshimen mi awọn ni igba mẹta ọtọọtọ, ti Frank Onyeka naa sig be ikọ Super Eagles wọ ipile Play Off fun idije ife eye agbaye. Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ ikọ Super Eagles pẹlu Benin ni ilu Uyo laana, wọn yoo gbera lọ sinu idije Play Off nibi ti wọn ti ma wọ ija pẹlu orilẹede mẹrin mii lati ilẹ Adulawọ. Awọn orilẹede mẹrin ti yoo kopa ninu Play Off yii ni Orilẹede Naijiria, Gabon, Cameroon ati Democratic Republic of Congo. Inu oṣu kọkanla ni awọn ifẹsẹwọnsẹ yii ma waye ni orilẹede Morocco, ti Ikọ Super Eagles yoo si lọkitipọ pẹlu orilẹede Gabon, ẹni to to ba bori ni yoo ba orilẹede to ba bori laarin Cameroon ati DR Congo. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Orilẹede to ba bori idije Play Off yii ni yoo lọ soju ilẹ Afrika ninu idije Play Off miiran ti ajọ FIFA, ti yoo si ma pade awọn orilẹede miiran kaakiri agbaye lati tikẹẹti lọ si idije ife ẹyẹ agbaye ti ọdun to n bọ. Lẹyin ọpọ ifẹsẹwọnsẹ kaakiri fun awọn orilẹede lati kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye, BBC News Yoruba ṣe akojọpọ awọn orilẹede to ti gba tikẹẹti lati le kopa. Awọn orilẹede to n gba alejo: Canada, Mexico, United States Ilẹ Asia: Australia, Iran, Japan, Jordan, Qatar, Saudi Arabia, South Korea, Uzbekistan Ilẹ Africa: Algeria, Cape Verde, Egypt, Ghana, Ivory Coast, Morocco, Senegal, South Africa, Tunisia Ilẹ Yoruupu: England
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cpv1217xj3go
|
2025-10-15
|
bbc
|
Ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ọlọ́run ń gbà bá èèyàn sọ̀rọ̀, kò yẹ kí ẹ̀sìn máa fa ìjà - Bíṣọ́ọ̀bù Ladigbolu
|
Bíṣọ́ọ̀bù àgbà, Ayo Ladigbolu ti sọ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kò yẹ kó máa dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn. Bíṣọ́ọ̀bù Ladigbolu tó jẹ́ àgbà ẹlẹ́sìn Kristẹni tó fẹ̀yìntì gẹ́gẹ́ bí Bíṣọ́ọ̀bù nínú ìjọ Methodist Church nínú ìfọ̀rọ̀wérò tó ṣe pẹ̀lú BBC News Yorùbá sọ pé òun kò rò pé ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn máa dá ìjà sílẹ̀ rárá. Ó ní ọkàn ẹni ló máa ń ṣe ìdarí ẹ̀sìn tí èèyàn yóò ṣe láyé nítorí ọkàn ẹni ni ìgbàgbọ́ ẹni wà. Ó sọ pé inú ẹ̀sìn Islam ni wọ́n bí òun sí ṣùgbọ́n òun gbàgbọ́ pé ìrìnàjò ayé òun ló gbé òun wọ inú ẹ̀sìn ìgbàgbọ́. "Ní gbogbo ẹbí wa, ẹ̀sìn mùsùlùmí ni a gbà, nípa bẹ́ẹ̀ tí ẹ bá ríbi tí wọ́n ti ń jìjà ẹ̀sìn, ẹ ò lè rí irú àwa níbẹ̀." Ladigbolu ní òun gbàgbọ́ pé nǹkan tí ọkàn ẹni bá gbàgbọ́ pé òun ló tọ̀nà jù ló máa sọ bí ẹ̀sìn tí èèyàn náà máa ṣe. Ó wòye pé kò yẹ kí ẹlẹ́sìn kan máa sọ fún ẹlòmíràn pé ẹ̀sìn rẹ̀ kò da nítorí kò mọ ọkàn àti inú ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀ àti bí ó ṣe súnmọ́ Ọlọ́run tó. "Nígbà tí mo gba ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ láàárín gbùngbùn ẹ̀sìn Mùsùlùmí, tí kìí bá ṣe pé Ọlọ́run fún àwọn ara Oyo ní sùúrù, wọn ò bá pamí. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ "Mo gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kó sí àwọn tí wọ́n bími nínú nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé kò yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn fa ìjà." Bíṣọ́ọ̀bù náà ṣàlàyé pé kìí ṣe pé èèyàn kan ló wàásù fún òun láti gba ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ tí òun sì gbàgbọ́ pé bí Ọlọ́run ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ yàtọ̀ sí ara wọn.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cwypz8we9dvo
|
2025-12-04
|
bbc
|
A ní ìwé ilẹ̀ ìjọba, síbẹ̀, ìjọba Oyo fẹ́ lé wa lórí ilẹ̀ wá- Ọ̀kan lára àwọn tọ́rọ̀ kàn
|
Awọn olugbe agbegbe Alabata, olorisaoko, Amosun ati awọn olugbe agbegbe ogoji labẹ ijọba ibilẹ Akinyele lọ ti rọ Gomina Seyi Makinde ti Ipinlẹ Ọyọ lati mase fi katakata ijọba wo ile wọn lai ṣe wi pe ijọba mu adehun rẹ ṣe. Awọn eeyan ọhun ni wọn gbe ọpọlọpọ takada dani, eyi ti wọn fi ṣe iwọde alaafia yika agbegbe Olorisaoko, ki wọn to pari rẹ si oju ọna opopona ilu Ibadan si Iseyin. Ninu ọrọ rẹ, Olusoaguntan Samuel Omotunde Olaleye ṣalaye pe nisẹ ni ijọba Ipinlẹ Oyo n gba awọn sotun ati sosi nitori wi pe wọn ko fẹ mu ileri wọn ṣe. Samuel Olaleye ṣalaye siwaju; "Ki ṣe wi pe ori ilẹ ijọba la kọle sii, ijọba fun wa ni iwe ilẹ ka to kọ ile wa, Erunmu ni ile iṣe reluwe wa tẹlẹ ki wọn to gbẹ wa si agbegbe wa, nitori ile iṣe reluwe, ni wọn ṣe gbe ile iṣe "Dry port" wa si agbegbe wa. "A ko ba ijọba ja, ṣugbọn ki ijọba ma wo ile wa, ilẹ ti ko si wi pe wọn kọ kọ nkankan si ni ki ijọba lọ lọ, oun ta daye baa ni wi pe ijọba ma ń sọ igbẹ di igboro, ìjọba ki sọ igboro di ìgbẹ́. "Olorisaoko, Alabata ati Ọpabunmi, Igboro ni wọn, wọn ki se inu igbo, ki wọn ma tu wa nilu, ki wọn si jẹ ko wa ni akosilẹ, ati ṣe ipade pẹlu aṣoju ijọba, o ti su wa" Olanipekun Wasiu ṣalaye wi pe abule mẹtalelogoji lo wa ninu awọn ilu ti ijọba gbese le ilẹ wọn, Wasiu ṣalaye "Ijọba kọ ti sọrọ kuna pẹlu wa papa julọ lori ọrọ ilẹ, ti ijọba baa fẹ lọ ilẹ, ati sọrọ lori ibiti wọn yoo ko awọn ti wọn wo ile won sì, ati sọrọ sisan owo gba mabinu. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Nigbati ileeṣe reluwe bẹrẹ, won beere fun saari ile hectares ọgbọn (30)nigba to ya gomina ipinle Oyo Seyi Makinde ni ijọba Ipinlẹ Ọyọ nilo ilẹ ofi 1717,235 hectares Ile, ti wọn gba ni ọdun 2021, nigba ti o tun ya lari wi pe ijọba tun tii fee loju di ẹgbẹrun mẹta le die ilẹ ni ijọba tun gba. Ijoba pin ile na si ọna mẹta ti ida kan yoo lọ fun awọn ti wọn fẹ wo ile wọn, sugbọn ohun ti a ri ni wi pe, ẹdun ọkan wa ti a ṣalaye fun ile ṣe ijoba lori ilẹ, ọtọ ni ọrọ ti wọn jise fun wa pada lati ọdọ gomina Ipinlẹ Ọyọ, "A ko ni igbagbo ninu ileeṣe ijọba to ri si ilẹ, gbogbo ilẹ wa ni wọn ti taa tan ". Nigbati o n ba akọroyin ileeṣe BBC Yoruba sọrọ, Iyaafin Mofoluke Adebiyi, ẹni ti o risi ileeṣe ijọba to risi ọrọ ilẹ, tẹnu bọrọ, "awọn ilẹ ti ijọba gba ni agbegbe ilu titun, ìjọba ko ti ṣe nkankan pẹlu enikeni lori ilẹ naa, a n igbiyanju lati mọ awọn ilẹ yẹn a si gbero lati san ọwọ gba mabinu fawọn ti wọn padanu awọn ilẹ ati ile. "Ijoba ti bẹrẹ si ni baa awọn eeyan sọrọ, ati ṣe ipade pẹlu awọn tọrọ kan, ijọba si ma fun wọn ni owo gba mabinu, ki awọn eniyan wa ki wọn ní suuru, "Awon ti ijọba baa gba ilẹ wọn ni a fẹ ní kí wọn ni suuru nitori gbogbo eniyan ni yoo jẹ anfaani rẹ ti idagbasoke baa ba awọn agbegbe yii". Mofoluke ṣeleri lati pe ipade alaafia pẹlu awọn tí ọrọ ọhun kan ki igun mejeji le gbọ ara wọn yee.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/ce865p09dg3o
|
2025-11-29
|
bbc
|
Ijó, ayọ̀ báwọn èèyàn 38 tí wọ́n jí gbé ní Eruku ṣe padà sílé
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images/BBC Olujọsin mejidinlogoji ti wọn ji gbe ni ile ijọsin CAC ni ilu Eruku, ijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ Kwara lọjọ Kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 ti pada sile ile wọn. Atẹjade kan ti agbẹnusọ ijọba ibilẹ Ekiti fi lede lọjọ Keji, oṣu Kejila sọ pe awọn eeyan naa ti pada si ile wọn bayii. O ni gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq ko awọn eeyan naa le alaga ijọba ibilẹ Ekiti, Awelewa Olawale Gabriel lọwọ. Nigba to n gba awọn eeyan naa, Awelewa dupẹ lọwọ Aarẹ Bola Tinubu, Gomina AbdulRasaq atawọn ẹṣọ aabo latari bi wọn ṣe tete gba itusilẹ awọn eeyan naa kuro ni akata awọn ajinigbe. O ni ajọṣepọ awọn ẹṣọ aabo ati ijọba lo jẹ ki wọn tete gba itusilẹ awọn eeyan naa ati pe nnkan bii aago mẹfa abọ irọlẹ ọjọ Iṣẹgun ni awọn eeyan naa pada sile tawọn araalu si fi ijo ati ọyaya gba wọn pada. Alaga ijọba ibilẹ naa fi kun pe ijọba yoo tunbọ maa tẹsiwaju lati maa da aabo bo gbogbo awọn eeyan ati dukia ni gbogbo ẹkun mẹwaa to wa nibẹ. Ẹ o ranti pe Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu, ti kede pe awọn eeyan mejidinlogoji (38) ti awọn ajinigbe ji gbe ni ṣọọṣi CAC Oke-Iṣẹgun, nipinlẹ Kwara, ti gba ominira bayii. Irọlẹ ọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni Aarẹ Tinubu kede bẹẹ loju opo X rẹ. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Lati igba naa ni awọn eeyan ọhun si ti wa pẹlu ijọba Kwara nibi ti wọn ti n gba itọju lori ikọlu naa. Oríṣun àwòrán,Aare Bola Tinubu Nigba to n ṣalaye itusilẹ naa, Aarẹ Tinubu sọ pe : "Ẹ o ranti pe mo fagile irinajo mi lọ sibi ipade G20 to yẹ ko waye lorilẹede South Africa, lati le mojuto aabo nile. "Ọpẹ fun awọn ẹṣọ alaabo wa lati bii ọjọ meloo sẹyin, gbogbo awọn olujọsin 38 ti wọn ji gbe ni Eruku, ipinlẹ Kwara ni wọn ti ri idande bayii." Bakan naa ni Aarẹ fi kun un pe mọkanlelaaadọta (51) ninu awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe nile ẹkọ awọn Katoliiki nipinlẹ Niger ni wọn ti pada sile . "Mo n tọpinpin bi eto aabo ṣe n lọ kaakiri orilẹede Naijiria , mo si n gba iroyin nipa bo ṣe n lọ" Gẹgẹ bo ṣe wi, Tinubu ni oun ko ni i sinmi lori eto aabo, o ni gbogbo ọmọ Naijiria lo ni ẹtọ si aabo to peye. Labẹ iṣakoso oun si ree, oun yoo ri i pe oun da aabo bo awọn ọmọ Naijiria bo ṣe yẹ Oríṣun àwòrán,Screenshot Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Lẹyin ọjọ marun-un ti awọn agbebọn kọlu ṣọọṣi CAC ilu Eruku, nipinlẹ Kwara, isin ọjọ isinmi waye ni ṣọọṣi naa lonii, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025. Ninu ọrọ iwaasu alufa ijọ naa, o rọ awọn ọmọ ijọ lati ma ṣe bẹru iku, ki wọn si ma ṣe sẹ́ Jesu Oluwa ninu ohun gbogbo. Gẹgẹ bo ṣe wi ninu fidio ijọsin naa ti wọn fi sori ayelujara, pasitọ to waasu naa ni: "Gẹgẹ bii onigbagbọ, ẹ ko gbọdọ bẹru wọn. Jesu ti ṣeleri iye ayeraye fun wa. Ẹ ma jẹ ka bẹru iku, ibikibi ti iku ba ti de, ma sẹ́ Jesu. " To o ba ti sẹ́ Jesu, ileri yii wa fun ọ, wi pe Ọmọ Alade Alaafia n mu ọ lọ si ijọba alaafia. "Aye yii lopin o, ṣugbọn ijọba ti Jesu n bọ waa ṣe ko lopin, ijọba ayeraye ni, oun lo fi sọ pe ki a ma ṣe jẹ ki ọkan wa daru." Bẹẹ ni Alufa naa wi. Ẹ o ranti pe ikọlu awọn agbebọn si sọọṣi CAC Oke Isegun, niluu Eruku, ijọba ibilẹ Ekiti nipinlẹ Kwara, waye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla Odun 2025. Eeyan mẹta ni iroyin sọ pe o ku ninu ikọlu naa, ọpọ eeyan lo si w ani igbekun awọn ajinigbe naa titi di asiko ti a n kọ iroyin yii, ti ajinigbe n beere owo gọbọi lati tu wọn silẹ. Oríṣun àwòrán,@CAN Kwara Ẹgbẹ ọmọ lẹyin Kristi (CAN), ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti fagile ayẹyẹ isin orin ọdun Keresimesi tọdun yii to yẹ ko waye ni ọjọ Aje, ọjọ kin-in-ni oṣu Kejila, ọdun 2025 . Wiwọgile ayẹyẹ orin ọdun Keresimesi naa waye latari ikọlu awọn agbebọn to ṣẹlẹ ninu ijọ CAC Eruku, nijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ Kwara, nibi ti wọn ti ṣekupa awọn olujọsin ti wọn si tun ji awọn mi-in gbe lọ. Ẹgbẹ CAN ipinlẹ Kwara ni inu ọfọ lawọn ọmọlẹyìn Kristi wa bayii latari iṣẹlẹ naa, eyi ti ki i ṣe akọkọ iru ẹ. Ẹgbẹ naa ni awọn kẹdun pẹlu gbogbo awọn mọlẹbi tọrọ naa kan, ijọ Ọlọrun ati apapọ awọn eeyan ilu Eruku. Gẹgẹ bi ẹgbẹ ọmọ lẹyin Kristi, wọn ni awọn ko le tẹsiwaju ninu ayẹyẹ naa niru akoko yii ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa wa ninu ọfọ. Ẹgbẹ CAN ni ifagile ayẹyẹ isin orin ọdun Keresimesi tọdun yii jẹ ibanikẹdun ati ibọwọ fun awọn to padanu ẹmi wọn, pẹlu awọn to f'arapa nibi ikọlu naa. CAN Kwara dupẹ lọwọ Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazak, fun atilẹyin rẹ ati ilakaka rẹ. Oríṣun àwòrán,@CAN Kwara Atẹjade kan lati ọwọ Alaga ẹgbẹ (CAN) ipinlẹ Kwara, Bishop Adewole, sọ pe awọn ba Gomina ipinlẹ naa kẹdun, awọn si rọ ọ lati fi kun igbiyanju rẹ lori bi wọn yoo ṣe sawari awọn ti wọn ji gbe, ki idajọ ododo waye, ki àláfíà si pada si ilu naa. Ẹgbẹ naa ke si gbogbo ọmọlẹyìn Kristi nipinlẹ Kwara lati darapọ mọ adura ọlọjọ mẹta kan ti wọn lo da lorii títu awọn mọlẹbi awọn eeyan tọrọ yii kan ninu. Ikeji ni dida awọn ti wọn ji gbe pada layọ ati imularada awọn to farapa. Tẹ o ba gbagbe, ọjọ iṣẹgun, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni awọn agbebọn yawọ inu ijọ CAC niluu Eruku, lasiko ti wọn n ṣe isin lọwọ, ti wọn si ṣekupa eeyan mẹta, ji eeyan mejidinlọgbọn gbe. Awọn ajinigbe to ji awọn olujọsin mẹtadinlogoji ni ile ijọsin CAC gbe ni ilu Eruku, ipinlẹ Kwara ti mu adinku ba iye ti wọn n beere fun gẹgẹ bi owo itusilẹ. Awọn ajinigbe naa ti n beere fun ogun miliọnu naira gẹgẹ bi owo itusilẹ fun ẹnikọọkan lodi si ọgọrun-un miliọnu naira ti wọn ti ṣaaju beere. Ọba ilu Eruku, Ọba Busari Olarewaju lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC News Yoruba ni owurọ ọjọ Ẹti, ọjọ Kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025. Ọba Olanrewaju ni awọn ko i tii mọ ohun to maa jẹ ṣiṣe lori lati wa owo naa fun eeyan mẹtalelogoji. Ṣaaju ni awọn janduku agbebọn to ya bo ile ijọsin CAC ni ilu Eruku nijọba ibilẹ Ekiti ni ipinlẹ Kwara ti beere fun ọdunrun un miliọnu naira (N300m) lati tu awọn eeyan mẹtadinlogoji ti wọn ji gbe silẹ Ohun ti a gbọ ni pe awọn ajinigbe ọhun ti pin awọn eeyan ti wọn ji gbe si isọri mẹta. Kabiyesi ilu Eruku, Ọba Busari Olarewaju, salaye pe awọn ajinigbe naa ti kan si ẹbi awọn ti wọn ji gbe lati wa sanwo itusilẹ fun wọn. Ọba Ọlarewaju ṣalaye siwaju si pe wọn ni ki isọri kọọkan san ọgọrun kan mílíọ̀nù naira ti apapọ owo naa si jẹ ọdunrun un milionu naira. Ọkan lara awọn ọdọ ilu naa, Ọgbẹni Ṣogo fidi rẹ mulẹ pe ẹrọ ibanisọrọ awọn ti wọn ji gbe ni awọn ajinigbe fi ba mọlebi wọn sọrọ. O salaye pe awọn ajinigbe naa ni kawọn ti wọn ji gbe pe mọlẹbi wọn lati fi beere fun owo itusilẹ. Sogo fikun ọrọ rẹ pe ọkan lara awọn oloye ilu, Olusẹgun Olukọtun, to ni mọlẹbi mẹrin ninu awọn ti wọn ji gbe sọ pe awọn ajinigbe ti pe oun. Bakan naa, ilu Eruku ti ṣagbejade orukọ awọn mẹtadinlogoji ti wọn ji gbe. Ninu ọrọ tiẹ, alaga ijọba ibilẹ Ekiti nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Gabriel Awẹlẹwa naa jẹrii pe awọn ajinigbe ti pe awọn mọlebi awọn ti wọn ji gbe. O ni awọn o si mọ idi ti wọn fi pin wọn si isọri mẹta, nitori awọn ti wọn ji gbe lo sọ lori ẹrọ ibanisọrọ pe, wọn ti pin awọn si isọri mẹta. Lasiko to n sọrọ, ọkan lara ọdọ ilu naa, Lekan ni awọn o mọ ọna ti awọn fẹ gbe ọrọ yii gba. Lekan ni owo ti wọn n beere fun ti pọju, o ni awọn obinrin ti sa kuro ni ilu tan wi pe awọn ọkunrin nikan lo ku. Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Kwara ti gbe gbogbo awọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama to wa ni ijọba ibilẹ marun-un ti pa lẹkun gusu ipinlẹ naa tori bi ọrọ eto abo se ri bayii nibẹ. Awọn ijọba ibilẹ tọrọ naa kan ni, ìjọba ibilẹ Ekiti, Isin, Oke ẹrọ, Ifẹlodun ati Irẹpọdun ti gbogbo wọn wa ni lẹkun Gusu ipinlẹ Kwara. Titi pa awọn ile ẹkọ naa ko sẹyin bọrọ eto abo ṣe n buru si i lẹkun naa. Alaga ẹgbẹ awọn olukọ ipinlẹ Kwara (NUT), Kọmureedi Yusuf Agboọla, sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe ijọba ti awọn ile ẹkọ naa pa latari ipenija ọrọ eto abo. O salaye pe ki awọn olukọ kiyesi atẹjade yii, ati pe bi nnkan ba se ri awọn yóò pada fi to wọn leti. Ninu ọrọ rẹ, alakoso awọn olukọ nijọba ibilẹ Isin, Oloye Lere Balogun, naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. Kọmisọna feto ẹkọ ni ipinlẹ Kwara, Dr Lawal Ọlọrungbẹbẹ naa sọ pe ijoba ipinlẹ gbe igbesẹ yii lati daabobo awọn akẹkọọ ni. O fi kun un pe ijọba fẹ ki aabo to peye wa fun awọn akẹẹkọ to fi mọ awọn akẹẹkọ to n gbe lọgba ile ẹkọ. Gbogbo ile ẹkọ ijọba ati aladani lọrọ naa kan bayii lawọn ijọba ibilẹ marun-un ọhun. Ni irọlẹ ana ni ibẹrubojo gbalẹ pe, awọn ajinigbe fẹ kọlu ile ẹkọ Anglican Girls College Iludun Oro, ṣugbọn ti ijọba tete ko awọn ẹṣọ alabo sọwọ si ile ẹkọ naa. Titi awọn ile ẹkọ pa yii waye lẹyin wakati merinlelogun tawọn agbebọn kọlu ile ìjọsìn CAC niluu Eruku nijọba ibilẹ Ekiti nibi ti wọn pawọn olujọsin, ti wọn si ji awọn ọmọ ijọ marundinlogoji gbe lọ. Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazak naa sabẹwo si ilu Eruku l'Ọjọru lati bawọn kẹdun, to si bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ikọlu naa.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c4g4ld3y44zo
|
2025-11-21
|
bbc
|
Kí nìdí tí ìjọba Adeleke ṣe fi Davido ṣe aláàmójútó àṣùwọ̀n ẹ̀dáwó àti nǹkan tí yóò ṣe fún àjọ náà?
|
Oríṣun àwòrán,Instagram/Davido Ijọba ipinlẹ Osun ti ṣalaye idi ti wọn fi yan David Adeleke, ẹni ti ọpọ mọ si Davido gẹgẹ bii alaamojuto asuwọn ẹdawo ere idaraya nipinlẹ Osun. Ikede yii jade ni Ọjọ kejidinlogun oṣu kẹwaa ọdun 2025 nigba ti igbakeji gomina ipinlẹ Osun, Ọmọọba Kola Adewusi, n gba alejo ẹgbẹ awọn akọroyin ere idaraya nipinlẹ Osun. Nigba to n ba BBC News Yoruba, agbẹnusọ Gomina ipinlẹ Osun, Olawale Rasheed ni yatọ si pe Davido jẹ ọmọ ẹgbọn gomina ipinlẹ Osun, o tun jẹ eeyan to ajọsepọ nla pẹlu awọn ileeṣẹ nlanla lagbaye ti wọn le pese owo fun idagbasoke ere idaraya nipinlẹ Osun. Rasheed ni ohun akọkọ ti ijọba ro ti wọn fẹ fi da asuwọn owo naa silẹ ni lati ṣe atunṣe si paapa iṣere ipinlẹ Osun ti yoo fi ba ẹgbẹ pe lawujọ. "Lati gba ere idaraya larugẹ ki n ṣe ti ijọba nikan le ṣe, nitori owo nla nla lo ma n wa nidi rẹ, lati sise paapa iṣere ati awọn itọju awọn elere idaraya, ti a si nilo awọn aladani lati wa fọwọsowọpọ pẹlu wa. "Eyi ki n ṣe ẹru ti ijọba nikan le da gba,ṣugbọn bayii awọn aladani le dasi iṣẹ ijọba, to si ran wa lọwọ pupọ." Rasheed ni ijọba yoo pese ilana ati ofin ti yoo dirọ owo ẹdawo naa lori bi owo yoo ṣe wọlw ati bi yoo ṣe jade pẹlu akọsilẹ. "Ki n se ẹdawo ti ko ni ofin ni eyi, owo yoo wa, ti yoo si da bobo owo ti awọn ba da ni wọn fi ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Agbẹunusọ Gomina, Olawale Rasheed ni idi pato ti awọn fi kan si Davido ni pe yoo pese ọpọ iranlọwọ lati ri pe ẹdawo wa si imuṣẹ. Rasheed ni yiyan Davido gẹgẹ bii alaga ni o da bi pe wọn ke si i pe ko ṣe aanu awọn araalu gẹgẹ bii o ti ṣe n ṣe tẹlẹ. "Ko se eyi nitori owo, olowo ni Davido, to tun jẹ ọmọ baba olowo, ọdọdun ni o fun awọn ọmọ orukan ni owo. "Ilumọka ni Davido ti yoo si lo ipo rẹ fi pese anfani fun ere idaraya nipinlẹ Osun ati fun awọn ọdọ naa." Oríṣun àwòrán,Instagram/Osun State Govt Ijọba ipinlẹ Osun ti kede gbajugbaja olorin takasufe, David Adeleke, ẹni ti ọpọ mọ si Davido gẹgẹ bii alaga àṣùwọ̀n ẹ̀dáwó ìdàgbàsókè eré ìdárayá, igbesẹ ti wọn ni yoo pese owo fun idagbasoke ẹka ere idaraya ni ipinlẹ naa. Ijọba tun jẹ ko di mimọ pe igbesẹ n lọ lati pari atunṣe to n lọ lọwọ ni paapa iṣere to wa ni ilu Osogbo, pẹlu erongba lati jẹ ko jẹ lilo fun idije Olympics. Igbakeji Gomina ipinlẹ Osun, Kola Adewusi, lo sọ eyi di mimọ nigba ti ẹgbẹ awọn akọroyin ere idaraya, ẹka ti ipinlẹ Osun, (SWAN) ṣe abẹwo si ọfisi rẹ, igbakeji gomina, ẹni to tun jẹ Kọmisana fun ere idaraya nipinlẹ naa, tẹnumọ pe iṣejọba Gomina Ademola Adeleke n ṣe akitiyan lati mu atunṣe nla ba papa iṣere ilu Osogbo lati le ba ẹgbẹ pe lagbaye. Adewusi fi kun pe ijọba ipinlẹ naa ti n ipele aṣekagba lati da ajọ ere idaraya ti yoo wa fun idagbasoke ere idaraya nipinlẹ Osun. O ni ni awọn se fẹ sẹda ajọ ni yoo pese iranlọwọ fun ere idaraya nipinlẹ Osun ati bii yoo ṣe gboro si. "Inu mi dun lati sọ fun iyin pe a ti wa ni ipele aṣekagba lati da ajọ ere idaraya ipinlẹ Osun silẹ. "Idasilẹ àṣùwọ̀n ẹ̀dáwó ìdàgbàsókè eré ìdárayá yii yoo jẹ ki a ri iranlọwọ gba kaakiri, ti ere idaraya yoo si ma gboro si nipinlẹ Osun. "Davido ko yi ohun pada lati gba pe ko di alaga ajọ naa, ti yoo si ri pe iranlọwọ wa kaakiri agbaye." Ọmọbibi ilu Ede nipinlẹ Osun ni David Adeleke, ta tun mọ si Davido. Ọjọ Kọkanlelogun osu Kọkanla ọdun 1992 si lo dele aye lati ipasẹ baba rẹ, Adedeji Adeleke amọ iya rẹ ti jade laye. Isẹ orin kikọ ni lo yan laayo, gbajumọ akọrin takansufe si ni Davido lorilẹede Naijiria ati lawujọ agbaye lapapọ. Ọdun 2010 si lo bẹrẹ isẹ orin kikọ, eyiun ọdun mejila sẹyin. Lara awọn orin rẹ to gbajugbaja julọ ni 'Ẹ ma da mi duro, emi lọmọ baba olowo ati orin Assurance to fi sọri Chioma. Davido ti gba ọpọ ami ẹyẹ nidi isẹ orin kikọ labẹle ati loke okun.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cvgv1wlk29go
|
2025-10-23
|
bbc
|
Kí ni ìtúmọ̀ ìlànà 'non-kinetic' tí ìjọba ní òun fi dúnàádúrà gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kebbi àti olùjọ́sìn Eruku lọ́wọ́ àwọn ajínigbé?
|
Oríṣun àwòrán,Yushau Shuaib Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 ni ìjọba àpapọ̀ kéde pé àwọn ti gba ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama Government Girls Comprehensive Senior Secondary School (GGCSS) Maga, ìpínlẹ̀ Kebbi, lẹ́yìn táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lo ọjọ́ mẹ́sàn-án ní àhámọ́ ajínigbé. Ààrẹ Bola Tinubu, nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ rẹ̀, Bayo Onanuga fi léde sọ pé ìlànà ìdúnàádúrà láì lo ipá ni wọ́n fi gba ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà. Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, gómìnà ìpínlẹ̀ Kebbi, Nasir Idris sọ pé ìjọba kò san owó kankan láti gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀. Ó fi kun pe láyọ̀ àti àlááfíà ,ni àwọn ọmọ náà wà àti pé wọ́n máa darapọ̀ mọ́ àwọn òbí wọn lọ́jọ́rú. Ìbéèrè tó gba ẹnu ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé kí ló ń jẹ́ ìdúnàádúrà "non-kinetic" tí ìjọba ní àwọn lò láti gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀. Èyí ló mú BBC News Yoruba kàn sí ọ̀gágunfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ológun Nàìjíríà, Lukman Gidado láti ṣàlàyé ohun tí ìgbésẹ̀ yìí túmọ̀ sí nínú iṣẹ́ ológun. Gidado, tó tún jẹ́ ọ̀mọ̀wé nínú ìmọ̀ ìpẹ̀tùsááwọ̀ ṣàlàyé pé, nínú iṣẹ́ ológun, ọ̀nà méjì ni wọ́n máa ń gbà láti ja ogun lójúnà àti ri pé ohun tí wọ́n ń fẹ́ wá sí ìmúṣẹ. "Tí a bá ń sọ̀rọ̀ ogun, ọ̀nà méjì ni a máa ń gba ja ogun, àkọ́kọ́ ni kinetic, tí èkejì sì jẹ́ non-kinetic." End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ó ṣàlàyé pé kinetic túmọ̀ sí lílo àwọn ohun ìjà ogun bíi ìbọn, àdó olóró àtàwọn ìjà olóró míì láti fi kojú àwọn tí wọ́n bá ń bá ja ogun náà. Nígbà tí non-kinetic sì jẹ́ lílo ìdúnàádúrà, ìlànà bíbá àwọn tí wọ́n ń bá ja ogun sọ̀rọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n ri pé ohun tí àwọn ń ṣe kò dára. Ó sọ pé èyí máa ń fún àwọn ológun ní àǹfàní láti bá àwọn èèyàn náà jíròrò láti jẹ́ kí wọ́n mọ ipa tí ìgbésẹ̀ wọn le ní lórí ètò ààbò. Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Gidado wòye pé lílo ìgbésẹ̀ non-kinetic ló tọ̀nà jù láti fi gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kalẹ̀ nítorí òun ni ọ̀nà tó dára jùlọ láti ri pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kò farapa lọ́wọ́ àwọn ajínigbé tó fi wọ́n fi àhámọ́. "Àwọn ológun ti mọ ibi tí àwọn agbébọn tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gbé wà. Tí wọ́n bá ju àdó olóró síbẹ̀, ó ṣeéṣe káwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà farapa tàbí kí wọ́n ba lọ. "Ṣé a máa sọ pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ba lọ ni? Ìgbésẹ̀ tí ìjọba gbé ló dáa jù nítorí àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n fẹ́ gbà kalẹ̀." "Tí ìjọba bá ní kí àwọn lọ yìnbọn níbẹ̀ ó túmọ̀ sí pé wọ́n fẹ́ pa àwọn ọmọ yẹn ni nítorí àwọn agbébọn náà le lò wọ́n láti fi dá ààbò bo ara wọn." Ọ̀gágunfẹ̀yìntì náà sọ pé pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra lọ́wọ́ yìí, ohun tó tọ́ ni kí ìjọba wádìí ohun tó ń mú àwọn agbébọn náà mọ ohun tó ń ṣokùnfà tí wọ́n fi ń jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé. Ó fi kun pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjọsọ̀ ló ti máa wáyé láàárín ìjọba àtàwọn ológun kó tó di pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gba ìtúsílẹ̀ tí ìjọba kò sì ní lè jáde sọ fún àwọn èèyàn látàrí ọ̀rọ̀ ààbò tó jẹ́. Lórí ọ̀rọ̀ pé ìgbésẹ̀ ìdúnàádúrà yìí yóò máa jẹ́ kóríyá fáwọn agbébọn tó ń jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé káàkiri ilé ẹ̀kọ́, Gidado ní kìí ṣe gbogbo ìgbà ni ìlànà yìí máa ń jẹ́ ṣíṣe àmúlò, tó sì jẹ́ pé nígbà tí ìnílò rẹ̀ bá wáyé ni wọ́n máa ń lò ó. Ó ní tí ìjọba kò bá tètè gbé ìgbésẹ̀ láti gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀ lásìkò, ó ṣeéṣe káwọn agbébọn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní lo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún lọ́nà tí kò dára. Ó ní wọ́n le máa lò wọ́n láti dá ààbò bo ara wọn tàbí kí wọ́n máa fipá báwọn lòpọ̀, èyí tó le ṣàkóbá fún ọjọ́ ọ̀la àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó tẹ̀síwájú pé lílo ìgbésẹ̀ ìdúnàádúrà ní irú àsìkò yìí kò túmọ̀ sí pé ìjọba tàbí àwọn ológun kò kájú òṣùwọ̀n láti ṣe ohun tó yẹ, ó ní ó máa ń jẹ́ láti wá ààbò àti àlááfíà àwọn èèyàn tó wà ní àkàtà àwọn ajínigbé bíi irúfẹ́ èyí tó wáyé ní Kebbi níbi tí ìjọba ti nílò láti dá ààbò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní àhámọ́ wọn. Ó sọ pé kìí ṣe Nàìjíríà nìkan ni ìjọba ti máa ń lo ìlànà yìí tí wọ́n bá ń fẹ́ nǹkan, tí wọn kò sì fẹ́ kí ìtàjẹ̀sílẹ̀ wáyé rárá. Ó ní àwọn orílẹ̀ èdè ńlá bíi Amẹ́ríkà, China àti Russia náà máa ń lo ìgbésẹ̀ yìí pàápàá tí wọ́n bá ri pé lílo ìwà ipá yóò túnbọ̀ ṣàkóbá fún ohun tí àwọn bá ń fẹ́ ni. Ọ̀gágun Gidado ní kìí ṣe gbogbo ìgbà ni ìlànà yìí máa ń mú àṣeyọrí tí èèyàn bá ń fẹ́ jáde. Ó wòye pé ìjọba kò lè lo ìlànà yìí tí wọ́n bá kẹ́fín pé àwọn agbésùmọ̀mí tàbí àwọn agbébọn bá fẹ́ ṣe ìkọlù sí ibìkan láti dáwọn dúró. "Tó bá jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń bọ̀ wá láti jí àwọn ọmọ yìí gbé ni àwọn agbébọn náà kojú wọn, ohun tó yẹ láti ṣe ni láti kojú wọn pẹ̀lú gbígbé ìjà kò wọ́n lójú láti ri pé wọn kò súnmọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà rárá." Ó ní ìjọba nílò láti ri pé gbogbo àwọn ohun ìjà táwọn ológun àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó kù nílò láti máa kojú àwọn ọ̀daràn ni ìjọba nílò láti pèsè fún wọn. Ó ní èyí yóò jẹ́ kí wọ́n le máa ṣe iṣẹ́ wọn bó ṣe tọ́ àti lọ́nà tó yẹ àti pé yóò lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa àwọn ìgbésẹ̀ àwọn agbéṣùmọ̀mí náà kí wọ́n tó ṣọṣẹ́ rárá. Bẹ́ẹ̀ náà ló fi kun pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ìlú ìyẹn NSCDC tó yẹ kí wọ́n máa ṣọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan ni wọn kìí sí ní ilé ẹ̀kọ́ kankan nítorí àìní ohun ìjà tó péye lọ́wọ́ àti àìní òṣìṣẹ́ tó. Ọ̀gágun náà ní dídá àwọn iléeṣẹ́ ààbò sílẹ̀ ní Nàìjíríà kò dàbí fífún àwọn iléeṣẹ́ náà ní ohun èlò tó péye láti fi ṣe iṣẹ́ wọn. Ó wá rọ ìjọba láti ṣe àwọn nǹkan tó yẹ lójúnà àti lè jẹ́ káwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ṣe iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún wọn àti láti ri pé ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní Nàìjíríà dúró ire padà.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cn4dxz9n04eo
|
2025-11-26
|
bbc
|
Èèyàn tó lé ní 70,000 ni Israel ti pa ní Gaza – Hamas
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Ileeṣẹ eto ilera Gaza ti Hamsa n ṣakoso rẹ ti sọ pe o le ni ẹgbẹrun lọna aadọrin eeyan ti wọn ti padanu ẹmi wọn lati igba ti Israel ti n kọlu agbegbe naa lọdun 2023. Amọ iye eeyan eeyan to ku yii lo tunbọ n pọ si lẹyin adehun jogun-o-mi ti wọn tọbọ bọ lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 yii. Lẹyin adehun naa ni Israel tun n ju ado oloro si Gaza lẹyin to fẹsun kan Hamas pe wọn yẹ adehun ọhun. Lara awọn to padanu ẹmi wọn lẹyin ado oloro Israel tuntun yii ni awọn ọmọdekunrin meji ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa, Fadi ati Juma Abu Assi, ti awọn obi wọn ni ado oloro naa gbẹmi wọn nibi ti wọn ti n ṣa igi idana. Ileeṣẹ eto abo Israle, Israel Defense Forces (IDF) sọ fun BBC pe awọn afurasi meji kan ti wọn kọja ala ti ko yẹ ki wọn kọja lawọn fi ado oloro naa ṣọwọ si. Ala naa jẹ ibi ti Israel fẹnuko si pe awọn ko ni rekọja lasiko adehun naa pẹlu ijọba Amẹrika lọsẹ meje sẹyin. Ẹgbọn awọn ọmọ to ku naa juwe wọn gẹgẹ bii ọmọ ọdun mẹwaa ati ọmọ ọdun mọkanla. Oríṣun àwòrán,Getty Images Awọn alabagbe wọn sọ pe igi idana ni wọn n wa lagbagbe Khan Younis ki wọn to padanu ẹmi wọn. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Wọn ti sin oku awọn ọmọ ọhun nile iwosan Nasser, to wa ni Gaza, lọjọ Abamẹta. Gbogbo igba ni ileeṣẹ eto ilera Gaza maa n kede awọn to ku ninu ogun naa ti ajọ UN si maa n sọ pe ko si irọ ninu iye eeyan ti wọn kede. Amọ ṣa, lọpọ igba ni ijọba Israel maa n sọ pe Hamas maa n fi kun iye awọn eeyan naa lati le jẹ ki awọn eeyan wa ni iha tiwọn. Ẹwẹ, ijọba Israel ko gba awọn akọroyin bii ti BBC laaye lati wọ Gaza funra wọn, fun idi eyii, o ṣoro lati fidi iye eeyan to ku mulẹ. Ileeṣẹ eto ilera Gaza ni 70,100 eeyan ni Israel ti ṣekupa ti 350 ninu iku naa si waye laarin ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa ti wọn tọwọ bọwe adehun jogun-o-mi. Ogun aarin awọn mejeji bẹrẹ lẹyin ti Hamas gbẹmi awọn ọmọ Israle lọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023. Ọmọ Israel 1,200 ni Hamas pa lọjọ naa, ti wọn si ko eeyan 251 lẹru.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cq60ymg82yyo
|
2025-11-30
|
bbc
|
Àwọn agbébọn tún ṣèkọlù sí Eruku ní Kwara, jí àgbẹ̀ kan gbé lọ lẹ́yìn ìkọlù ilé ìjọ́sìn CAC
|
Oríṣun àwòrán,Nigerian Army Awọn agbebọn tun ti ya bo ilu Eruku ni ijọba ibilẹ Ekiti ni Ipinlẹ Kwara nibi ti wọn ti arakunrin agbẹ kan ti orukọ rẹ n jẹ Annas Aasanru gbe lọ. Loni ọjọ Aje ni agbẹnusọ ọlọpaa fun Ipinlẹ Kwara SP Adetoun Ejire-Adeyemi, fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC News Yoruba. Ni ana ọjọ Aiku ni iṣẹlẹ yii waye ni ilu naa, o si jẹ ẹlẹẹkeji iru ẹ ninu osu Kọkanla ọdun yii. Ni nnkan bii ọsẹ kan sẹyin lawọn olujọsin 38 ti wọn ji gbe ni ilu ọhun gba ominira lakata ajinigbe. Ijọba ipinlẹ Kwara ṣe itọju awọn eeyan naa lẹyin ti wọn lo ọjọ marun-un ni igbekun awọn ajinigbe. Gẹgẹ bi eeyan kan lati ilu naa to ni ki a fi orukọ bo oun lasiri ṣe sọ, awọn agbebọn naa to jẹ mẹrin niye ya bo oko kan to wa lọna to jasi ilu Koro nibi ti wọn ti gbe agbẹ naa lọ. O ni "awọn afurasi ajinigbe naa fi ada ati ibọn ṣe ikọlu si Aasanru ninu igbo to sa wọ.'' O sọ pe, ni ọjọ Aiku ni wọn fi to awọn ọlọpaa ilu Eruku, leti pe awọn agbebọn mẹrin tun ya bo Eruku, wọn si gbe ọkunrin kan, ẹni ogoji ọdun gbe lọ. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ara ilu naa fikun ọrọ rẹ pe lẹyọ-osọka ni ajọ eleto abo ti ko awọn ọmọ ogun to fi mọ fijilante lọ si bẹ. Ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ wi pe gbogbo ipa ni ọlọpaa n sa lati doola ẹni ti wọn ji gbe naa.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cy47v3wkvzjo
|
2025-12-01
|
bbc
|
Iye ìgbà tí Sowore ti dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tó gbéná wojú ìjọba Naijiria
|
Oríṣun àwòrán,Omoyele Sowore Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti sọ pe oun yoo wọgile beeli to fun Omoyele Sowore to ba tun pada sọ ọrọ ti wọn gbagbọ pe o le da omi alaafia Naijiria ru. Adajọ Mohammed Umar lo sọ ọrọ naa lẹyin ti DSS pe e lẹjọ llori ọrọ to ṣo nipa Aarẹ Bola Tinubu lori ayelujara. Umar sọ pe niwọn igba ti Sowore jẹ oludie sipo Aarẹ nigba kan ri, ti ile ẹjọ naa si ti fun ni beeli to tun gba iwe irinna rẹ lọwọ rẹ, ile ẹjọ ọhun lẹtọọ lati fun ni beeli. Sowore lọ ile ẹjọ lasiko yii lẹyin ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS fẹsun kan an pe o tabuku Aarẹ Bola Tinubu lasiko to pe Aarẹ ni "ọdaran" loju opo X ti Facebok rẹ. Ẹsun marun un ọtọtọ ni DSS fi kan Sowore to dije du ipo Aarẹ Naijiria lọdun 2019 ati ọdun 2023 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC. DSS tun pe ileeṣẹ Meta to ni Facebook toun ti ileeṣẹ X lẹjọ lori bi wọn ṣe kọ lati yọ ọrọ naa ti wọn ni o ba orukọ Aarẹ jẹ lori ayelujara kuro loju opo wọn. Ọpọ igba ni Omoyele Soworo maa n ko si gbaga ijọba latari bo ṣe jẹ ajafẹtọọmọniyan to si maa n gbena woju ijọba Naiiria. Fun idi eyii, o le ṣoro diẹ lati ṣe akojọpọ iye ni pato ti ọkunrin naa ti sọ oko ọrọ si ijọba to si dero atimọle nitori rẹ nitori ọkẹ aimoye igba lo ti ṣe bẹẹ. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Oríṣun àwòrán,Omoyele Sowore Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Ọdun 1992 ni UNILAG Lọdun 1992 ni Sowore kọkọ ko awọn ọmọ ile ẹkọ UNILAG ti iye wọn to ẹgbẹrun marun sọdi ti wọn si ṣe ifẹhonuhan lodi si ijọba ologun asiko naa. Nibi iwọde ọhun ni ọlọpaa ti yinbọn pa eyan mẹjọ. Wọn fi ṣikun ofin gbe Sowore lọdun naa lọhun fun ipa to ko ninu iwọde naa, wọn si fi iya jẹ ninu atimọle. Inu oṣu Kẹjọ, ọdun 2019 Lọdun 2019, ajọ DSS fi sikun ofin gbe Sowore lẹyin to ṣagbatẹro iwọde #RevolutionNow, ninu eyii to ti fẹsun ajẹbanu ati fifi iya jẹ araalu kan ijọba Aarẹ ana, Muhammadu Buhari. Oṣu Kinni ọdun 2021 Ninu oṣu Kinni ọdun 2021, oloṣelunaa tun ko si gbaga ijọba Naijiria lori iwọde kan to ṣagbatẹru rẹ. Ti ẹ ko ba gbabe, iwọde naa lo n waye lẹyin iwọde EndSARS inu oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 to mi gbogbo Naijiria titi. Ọrọ oju op X ati Facebook Sowore lọdun 2025 Lọdun 2025 ti a wa yii, Sowore kọ awọn ọrọ kan loju opo Facebook ati X rẹ ninu eyii to ti pe Aarẹ Bola Tinubu ni "ọdaran." Lẹyin ọrọ naa ni ijọba Naijiria sọ fun ko yọ ọrọ naa latari pe o tabuku Aarẹ, ati pe o le da rugudu silẹ laarin ilu amọ Sowore kọ jalẹ. DSS tun kan si Sowore ko yọ ọrọ naa amọ o ko jọ. Ko pẹ lẹyin rẹ ti ijọba Naijiria kan ileeṣẹ X pe ki wọn yọ ọrọ ọhun ṣugbọn X ni oun ko ni yọ ọrọ naa nitori ko tapa si ofin awọn. Ka ma fa ọrọ gun, ọrọ yii lo gbe Sowore lẹ ile ẹjọ lọtẹ yii. Yatọ si awọn ti a mẹnuba loke yii, gbogbo igba ni Sowore maa n gbena woju ẹkun ijọba ti kii si foya ti wọn ba fẹ fi ofin gbe. O ni afojusun oun ni lati gba agbara lọwọ awọn to n da Naijiria ru fun awọn araalu funra wọn fun anfani gbogbo mutumuwa.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cm21k98lr1lo
|
2025-12-03
|
bbc
|
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
|
Ijó, ayọ̀ báwọn mọlẹbi èèyàn mejidinlogoji tí wọ́n jí gbé ní Eruku Irọlẹ ana ni ijọba da awọn eeyan naa padà sílé lẹyin ti wọn gba ominira Alaga ijọba ibilẹ Ekiti, Awelewa Olawale lo kede eyi ninu atẹjade kan O ni gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq lo ko awọn eeyan naa le oun lọwọ. Ekunrere wa loju opo BBC News Yoruba //////////////////////////////////////////////////////////////////////////// Igun apa kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ti kede Adebayo Adedamola gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ oṣelu naa fun eto idibo Osun Eyi waye lẹyin wakati mejila ti Gomina Adeleke kede pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ naa Eto idibo abẹlẹ naa waye niluu Osogbo, to jẹ olu ilu ipinlẹ Osun Ekunrere wa loju opo BBC Yoruba ////////////////////////////////////////////////////////////////// Nipinlẹ Osun, Ọkùnrin tó jí ara rẹ̀ gbé láti gba owó lọ́wọ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ l'Ondo dèrò àtìmọ́lé Lobatan, ẹni n fa n wa ofo ni ọrọ rẹ niyẹn Mathew Ekele ni ọwọ tẹ niluu Ogbese to wa loju ọna marosẹ ilu Akure siluu Owo.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c87e81lzqqvo
|
2025-07-31
|
bbc
|
Mo ṣetán láti jápa tí orílẹ́èdè ilẹ̀ òkèèrè kan bá fún mi ní 'asylum' - Hauwa Lawal
|
Gbajugbaja sọrọsọrọ ori ayelujara, Hauwa Lawal, ti sọ pe oun ṣetan lati japa lọ soke okun ti orilẹede ilẹ okeere kan ba le fun oun ni ''asylum.'' Nigba to n sọrọ ninu ifọrọwanilẹnu kan to ṣe pẹlu BBC Yoruba, Hauwa ni loootọ loun fi n ṣere ninu fidio kan toun gbe jade wi pe kawọn eeyan boun buwọlu fọọmu ṣiṣe atipo nilẹ okeere foun. Amọ, Hauwa sọ fun BBC Yoruba wi pe oun ti ṣetan bayii lati fi Naijiria silẹ toun ba ri anfaani tori orilẹede Naijiria ko rọrun rara fawọn ọdọ bii toun. ''Fidio asylum ti mo ṣe, mo kan fi n ṣere ni, amọ, Naijiria yii ko rọrun fun awa ọdọ. Iṣẹ gidi wa lasiko tawọn obi mi wa ni ọdọ gẹgẹ bii temi, wọn si maa n rowo diẹdiẹ nigba naa. Ṣugbọn nisinyin, ti o ko ba ni miliọnu kan si meji, eeyan o le gba ile ni igboro. Naijiria ti le ju, ti wọn ba fun mi ni asylum, mo maa lọ o,'' Hawa lo sọ bẹẹ. Hauwa ni awọn eeyan ro pe ọmọ Hausa ni mi, amọ, ọmọ Yoruba pọnbele ni mi. Abeokuta ni ilu baba mi, eeyan ti kii fẹ lati jade si ni mi pẹlu. Ṣugbọn nitori fidio ti mo maa n ṣe, awọn eeyan maa n ro pe mo maa n jade ni gbogbo igba.'' Hauwa ni nitori awọn eeyan n fẹran fidio toun n gbe sita lo fun oun ni igboya lati maa ṣe e lọ. Hauwa ni ''fun bi ọdọ marun mi o ṣe fi oju han rara, bo tilẹ jẹ pe emi ni mo n gbe awọn fidio naa sita. Ọdun 2023 ni mo kọkọ fi oju ara mi han lori ayelujara, eyi lo jẹ ki ọpọ eeyan maa ro pe mo ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ yii ni.'' Hauwa ni lati igba toun ti wa ni kekere loun ti maa n kọ itan. Sọrọsọrọ ori ayelujara naa ni kii ṣe gbogbo igba lowo fi maa n wọle pẹlu iru iṣẹ toun n ṣe. O ni ifẹ toun ni si iṣẹ naa lo jẹ koun tẹra mọ ọn. Hauwa ni oun ti maa n fi aṣọ bori koun to bẹrẹ si ni ṣe fidio ori ayelujara. Ọdọbinrin naa sọ pe sikaafu toun n we ti di ara ''brand'' oun bayii. Hauwa wa rọ awọn ọdọbinrin lati ni iṣẹ ti wọn n ṣe, ki wọn si ni owo ti wọn ki wọn le da duro.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cpd2g37vv02o
|
2025-11-17
|
bbc
|
Ìdúró, ìjókòó tàbí kí ọkùnrin bẹ̀rẹ̀ tọ̀, èwo ló dára jù fún ìlera?
|
Ko fẹrẹ wọpọ ninu awọn ọkunrin ti wọn maa n bẹrẹ, jokoo tabi loṣoo ti wọn ba fẹẹ tọ, ọpọ ọkunrin maa n duro tọ ni. Ida perete awọn to maa n loṣoo tọ yii naa lo si saba maa n jẹ pe Musulumi ni wọn, ti wọn n tẹle ilana ti ẹsin Islam fi kọ wọn. Ṣugbọn ninu ki ọkunrin duro, jokoo tabi bẹrẹ tọ, ewo lo daa ju fun ilera ni ibere to n jẹyọ ninu iroyin yii. Bo si tilẹ jẹ pe ko si ibi kankan ti awọn eleto ilera ti fidi ẹ mulẹ, pe bibẹrẹ tabi jijoko sori awo ile igbọnsẹ tọ ni anfaani to n ṣe fun ara, sibẹ, ọpọ eeyan lo gba pe ilana yii lo mọ julọ ti eeyan ba fẹẹ tọ. Idi eyi ni pe itọ ko ni i ṣan si ara ọkunrin to n tọ, ko si ni i ta sibi ti ko yẹ ko ta de. Ko ni i ko ẹgbin ba awọn nnkan bii burọọṣi ifọyin tawọn mi-in maa n tọju si ile iwẹ . "Ko si ilana titọ kan to dara ju ikeji lọ, eyi ti kaluku ba fẹ lo n tẹle." Dokita Mary Garthwaite, Aarẹ ẹka to n ri si ẹya ara ti eeyan fi n tọ ni UK lo sọ bẹẹ. Oríṣun àwòrán,Getty Images Iṣẹ iwadii kan ti wọn ṣe ni Leiden University, ni Netherlands, lọdun 2014, ṣe agbeyẹwo ọna ti ọkunrin ba gba tọ ṣe n ni ipa lara wọn, ati bi itọ ọhun yoo ṣe tete jade si. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Wọn fẹnuko si pe bi ọkunrin ti isẹtọ ti ṣe ri ba jokoo lori awo ile igbọnsẹ to si tọ, o dara bẹẹ fun un ju ki o duro tọ lọ. Eyi yoo jẹ ko tete ri itọ tọ, itọ naa yoo si tan ninu agbẹdu rẹ lasiko to n tọ, ko ni i sé tabi farapamọ sọhun-un. Ṣugbọn fun awọn ọkunrin ti nnkan kan ko ṣe, wọn ni ko si iyatọ kan ninu iduro tabi ijokoo tọ fun wọn. Wọn fi kun un pe idurotọ le mu ki atọ jade nigba ti ọkunrin ba n tọ, eyi ti ọpọ ọkunrin ki i fẹ ko ri bẹẹ. Bakan naa ni wọn ni idurọtọ yoo tun mu ki awọn itọ kan ta si ilẹẹlẹ ibi ti ọkunrin ti duro tọ. Ni 2023, YouGov ṣe iwadii kan lori ọna ti awọn ọkunrin n fẹran lati maa gba tọ lorilẹede mẹtala. Iyatọ to gbooro ni wọn ri latọdọ awọn orilẹede ti wọn jọ wa ni kọntinẹnti kan naa. Ida ogoji (40 percent) awọn ọkunrin Germany sọ pe awọn maa n jokoo bawọn ba fẹẹ tọ ni, ida mẹwaa pere lo ni awọn maa n duro tọ ni tawọn ni. Ni UK, ida mẹsan-an (9%) lo n jokoo to, nigba ti ida mẹtalelọgbọn (33%) maa n duro tọ ni. Eyi fi han pe bibẹrẹ tabi jokoo tọ wọpọ ni Germany, orukọ ti wọn maa n pe ọkunrin to ba n loṣoo tọ ni Sitzpinkler, eyi to tumọ so akọ ẹlẹdẹ. Ni Brazil, wọn maa n sọ ọrọ kan pe obinrin ati ọpọlọ lo ni ibẹrẹ. Dokita Robert Dunbar, lati Yunifasit Oxford, jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa abuda eeyan. O ni ki i ṣe abuda ni bawọn ọkunrin ṣe n duro tọ. "Ko si ẹri kankan lati ara Iṣẹda eeyan to ṣalaye idi ti ọkunrin fi n duro tọ." Dokita Dunbar lo sọ eyi. "Ni ti ododo, ọ rọ awọn ọkunrin kan lọrun lati duro tọ, nigba ti awọn mi-in si maa n fẹ lati jokoo tabi bẹrẹ tọ." Dokita Garthwaite lo ṣe afikun bẹẹ. Nigba ti ko ti si imọran ilera lori ọna to yẹ ki ọkunrin gba tọ, awọn funra wọn ni wọn yoo maa yan eyi to ba wu wọn, to si rọ wọn lọrun. Ṣugbọn bi o ba mu diduro tọ, yoo dara ki o ri i daju pe itọ ko ta sibi ti ko yẹ, o ko si jẹ ko gba ibi ti ko yẹ ko gba. Jẹ ko lọ gbọọrọ sibi ti o n tọ si.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cgkzkpr51y6o
|
2025-11-27
|
bbc
|
"Koko lara ọta mi le" - Bàbá Ẹda Onile ola sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ tó ní ó kú
|
Agba ọjẹ onitiata ilẹ Yoruba, Lere Paimọ ti sọrọ lori iroyin ẹlejẹ to jade ni afẹmọju, ọjọ kọkandinlọgbọn, kọkanla ọdun 2025, eyi to kede baba ọhun ti pa ipo da. BBC Yoruba kan si ilẹ Baba Lere Paimo niluu Ibadan, ti wọn si fidi ẹ mule wi pe iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin naa ati pe alaafia ni baba wa. Nigba ti baba n ba ikanni BBC News Yoruba sọrọ lori iroyin ọhun, Baba Ẹda Onile-Ọla salaye wi pe ojiji ni iroyin ọhun ba oun ati idile rẹ lati oru ana ọjọ Ẹti. Baba, to tun jẹ Aarẹ Arobajo ti ilu Ogbomọsọ, rọ awọn ti n ro irokiro lati jawọ, o rọ wọn lati dẹkun a n gbe iroyin ofege kiri. Bakan naa lo tun gba adura fun awọn ọmọ ẹgbẹ ati ololufẹ wọn fun ifẹ wọn. "Iroyin ohun ba awa gan lojiji lati oru ana, gbogbo ẹni to ba n gbe iroyin ki iroyin, to n ro irokuro, ki wọn mọ wipe gbogbo ohun ti awọn ba n se, ika kan ni wọn na si ọmọlakeji, mẹsan-an to ku ọdọ wọn ni o maa wa" "Mo rọ wọn ki wọn mọ gbe iroyin igbekugbe mọ, ohun ti o ba daa yin loju ẹ mọ sọ-ọ mọ, koko lara ọta mi le, ẹẹ ni se aarẹ o, ẹ ronupiwada, ẹmi gbogbo wa o gun titi dọjọ alẹ". Ọkan lara awọn ọmọ-iṣẹ agba osere ninu iṣẹ tiata ọhun, Nikẹ Afrikana, salaye wi pe afẹmọju l'awọn gbọ iroyin aheso ọhun. O fidi ẹ mulẹ wipe ara baba le koko, ti wọn si wa ni alaafia. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Osere-binrin ọhun, ti a tun mọ si Iya Bukọla Ọmọ daddy, tunbọ rọ awọn oniroyin lati maa fi idi otitọ mulẹ ki wọn to ma gbe iroyin jade. "A se ajọyọ, a se ọjọ-ibi, ẹ o bawa gbe, a se ohun ribiribi ti ẹnikẹni o bawa gbe-e, kilode ti wọn wa n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri. Kokoko lara baba le, alaafia ni wọn wa, wọn ti rin inu ọgba kiri laarọ yii, ẹdakun ẹ mọ gbe iru iroyin bẹẹ mọ". Nigba ti wọn n sọrọ, Gomina ana fun ẹgbẹ awọn osere ANTP ni ipinlẹ Ọyọ, Boye Abidoye tunbọ fidi rẹ mule wi pe baba wa laye ati laaye. Abidoye se afikun wipe eniyan gidi, ti awọn ọmọ ẹgbẹ onitiata n kọ ẹkọ ribiribi ati ọgbọn lara rẹ ni Lere Paimo. Abidoye rọ awọn ti n gbe iroyin ofege pe ki wọn ronupiwada nitori wipe ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ osere o le sun latari iroyin ẹlẹjẹ ọhun. Sunday Olu-ọmọ Ẹda salaye wipe deede aago mẹwaa ni alẹ ana ọjọ Aje lawọn gbọ iroyin ọhun. Sunday tunbọ fidi rẹ mulẹ wipe kebekebe ni agba osere ọhun wa nigba ti ohun dele wọn ni aarọ oni ọjọ abamẹta. Oríṣun àwòrán,Instagram Ni owurọ ọjọ Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni iroyin kan jade pe gbajugbaja oṣere tiata, Oloye Olalere Osun Paimo ti jade laye ṣugbọn lẹyin ọpọ iwadii a ri pe iroyin ofege ni. Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ẹgbẹ, Association of Nigeria Theatre Arts Practitioners (ANTP), Ọmọọba Adejonwo Oluwafemi Femson buwọlu fun awọn akọroyin fidi rẹ mulẹ pe irọ to jina si otitọ ni iroyin ọhun. Femson ni o ṣeni laanu pe awọn eeyan kan n gbe irufẹ iroyin ofege bayii sita, to si fi di rẹ mulẹ pe oun ti ba mọlẹbi oloye naa sọrọ. "A ti ba iyawo Baba Eda Onile Ola sọrọ, o si jẹ ko di mimọ pe alaafia ni Baba wa ninu ilera to peye. "A n rọ awọn araalu lati ye gbe iroyin ofege sita lati fi si ọpọ eeyan lọkan. "Oloye Olalere Osun Paimo (MFR), ọkan ẹgbẹ Association of Nigeria Theatre Arts Practitioners (ANTP), wa laaaye ." Oloye Lere Paimo, jẹ oṣere tiata, oludari sinima ati agbesinima jade lati orilẹede Naijiria. Wọn bi ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 1939 niluu Ile Ikoyi Odan, Osupa niluu Ogbomoso nipinlẹ Oyo. Baba rẹ jẹ agbẹ oni tabako, ti iya rẹ si jẹ onisowo ọja. Lere Paimo bẹrẹ ẹkọ alakọbẹrẹ ni Ogbomoso, ko to di pe o morile orilẹede Ghana.. Lẹyin eto ẹkọ rẹ, o pada si orilẹede Naijiria, to si n gbe ni ilu Osogbo nipinlẹ Osun nibi to ti ṣisẹ gẹgẹ bii olukọ ni ile ẹkọ Baptist Missionary School. Lere Paimo bẹrẹ iṣẹ tiata ni ọdun 1958 nigba to darapọ mọ egbẹ oṣere Oyin Adejobi, ti Pa Oyinade Adejobi da silẹ. Nigba to ya, o darapọ mọ ẹgbẹ oṣere Duro Ladipo. O di ilumọka lẹyin to kopa ninu sinima kan Ogbori Elemosho, nibẹ lo ti jẹ Soun Ogunola. Ni ọdun 2005, ijọba orilẹede Naijiria fi ami ẹyẹ Member of the Federal Republic (MFR) fi da Lere Paimo lọla fun iṣẹ ribiribi to ti ṣe ninu ere sinima. Bakan naa lo tun yege ninu ere kan ti a n pe ni Who Wants to Be a Millionaire, to si gba ẹbun milọnu kan naira.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cd74dp0yl8go
|
2025-11-29
|
bbc
|
Obasanjo ki ijó mọ́lẹ̀ láàrin ọ̀pọ̀ èrò, bí ọdún Owu 2025 ṣe ṣọkutu wọ̀wọ̀
|
Ọdun Owu ti ọdun 2025 ti waye, o si ti kọja lọ. Amọ ọpọ ohun ara meeriri to waye nibẹ ni yoo maa wa ni iranti ọpọ eeyan fun igba pipẹ. Se ti ijo, ilu, asọ to n pe asọ ransẹ wa woran ati gele ara to wa lori awọn obinrin ni ka sọ ni abi awọn eekanlu to peju sibi ọdun Owu naa. Koda, Oloye Olusegun Obasanjo, tii se Balogun ilu Owu ati Olowu naa wa lara awọn eekanlu to sọrọ nibi ọdun Owu naa. Bakan naa, aarẹ ana ni orilẹede Naijiria wa naa tun fi ẹsẹ ra ijo lasiko ọdun Owu naa, eyi to wu ọpọ eeyan lori. Ọpọ eeyan lo n beere pe bawo gan ni ọdun Owu to n milẹ titi yii se bẹrẹ, igba wo si lo bẹrẹ. Ninu ọrọ rẹ, alaga akọkọ fun ẹgbẹ gbogbo ọmọ bibi ilu Owu nilẹ Naijiria salaye pe ọdun 1984 ni ọdun Owu bẹrẹ. "Oloye Akin Olugbade to ti di Oloogbe lo bẹrẹ ọdun Owu ni ọdun 1984. Amọ ọdun 1992 ni Oloye Olusegun Obasanjo tẹwọ gbaa, to si n se ọdun naa daadaa. Nigba ti oun naa n sọ pataki ọdun Owu, Oloye Sharafa Tunji Ishola ni ọdun Owu naa lo maa n fun awọn ọmọ bibi ilu Owu lati wa sile nibikibi ti wọn wa. "Ọdun yii lo n mu kawọn ọmọ bibi Owu wale lati wa se ajọyọ, ti wọn yoo si tun wo awọn ohun meremere ti wọn le se silu Owu." Ninu ọrọ rẹ nibi ayẹyẹ ọdun Owu, Oloye Olusegun Obasanjo ni ẹya pupọ ni wọn fi da ilu Abeokuta silẹ. "Diversity la fi da ilu Abeokuta silẹ, eyi si lo jẹ ki Abeokuta ni ilọsiwaju ju gbogbo ilu miran lọ. Bi a ko ba si jẹ ki diversity naa bajẹ, ilu Abeokuta naa yoo maa dara si ni." Lẹyin eyi ni Balogun Owu naa wa bọ sijo, to si n gbe ẹsẹ siwaju ati sẹyin.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/ce3zw00239vo
|
2025-11-24
|
bbc
|
Kí ló fà á tí Owa ìlú Igbajo fi pé méjì èyí tó fa rògbòdìyàn lẹ́yìn ìpapòdà Ọba Famodun?
|
Oríṣun àwòrán,Collage Ni ọjọ Kẹrinlelogun osu Kọkanla ọdun 2022 ni Ọba Famodun gba ọpa asẹ gẹgẹ bi Ọwa ti ilu Igbajọ. Eyi waye ni o ku ọjọ diẹ ti gomina ana nipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola yoo kuro lori aga gẹgẹ bi gomina, to si gbe ọpa asẹ le Oba Famodun lọwọ gẹgẹ bi Ọba ti iluu Igbajọ. Sugbọn kete ti wọn bura wọle fun Gomina Ademola Adeleke, ni o yọ Ọba Adegboyega Famodun gẹgẹ bi Ọwa ti iluu Igbajọ to si yan Ọba miran ti orukọ rẹ n jẹ Ọba Ademola Makinde rọpo rẹ. Ẹbi ati awọn eekan iluu Igbajọ ko fara mọ igbesẹ ti Gomina Ademola Adeleke gbe, eyi lo mu ki wọn gba ile ẹjọ giga ti ẹka rẹ wa ni iluu ile-Ifẹ lọ, ti ile ẹjọ naa si ni ki wọn da Ọba Famodun pada si ori apere awọn baba nla rẹ ni Ọgbọn ọjọ osu Kinni ọdun 2025. Ṣaaju ki Oba Famodun to jade laye ni ile ẹjọ ti paṣẹ pe ki wọn da Ọba Famodun pada ni ipo ọba, gẹgẹ bi Ọwa ti iluu Igbajọ. Ọba Famodun, lasiko aye rẹ, tẹle asẹ ti ile ẹjọ gbe kalẹ pe ko pada si ipo Ọba gẹgẹ bi Ọwa ti iluu Igbajọ. Sugbọn ti gomina Adeleke fariga pe ko si ohun to jọ bẹ rara. Gẹgẹ bi a se gbọ pe Ọba Famodun ko fi aafin silẹ fun Ọba Ademola Makinde ti Gomina Adeleke yan gẹgẹ bi Ọwa ti iluu Igbajọ. Sugbọn ara ko rọ okun ara ko rọ adiẹ Ọba Famodun lati igba naa titi di asiko ti ọlọjọ de ni ọjọ Kejidinlọgbọn osu Kọọkanla ọdun 2025 ti a wa yii. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ninu ọrọ rẹ, Ọmọọba Adekunle Famodun, to jẹ akọwe ẹbi Famodun, se apejuwe Ọba Adegboyega Famodun gẹgẹ bi ẹni to ni ifẹ to si tun jẹ adari rere larin iluu ati larin ẹbi lapapọ. O tẹsiwaju pe itan ko ni gbagbe gomina to fi Ọba Adegboyega Famodun jẹ ọba ati gomina to ni ko kuro lori apere lialia. Oríṣun àwòrán,Molẹbi Oba Famodun Ọwa ti iluu Igbajọ Ọba Adegboyega Famodun, ẹni to ti fi igba kan jẹ alaga ẹgbẹ oselu APC, ẹka ti ipinlẹ Osun ti waja. Ọmọ Ọba Adekunle Famodun, ẹni to jẹ akọwe fun ẹbi Ọba Adegboyega Famodun lo fi atẹjade sita lati kede iku Ọba Famodun, ẹni ti o jade laye ni ọjọ Ẹti, ọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kọkanla yii. Eni ọdun mẹtadinlaadọrun ni Ọba Famodun ko to jade laye. Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti kede konile-o-gbele niluu Igbajo. Kolapo Alimi, to jẹ kọmiṣọna fun eto iroyin nipinlẹ naa lo fi atẹjade ọhun sita lowurọ ọjọ kinni, oṣu Kejila, ọsun 2025 ti a wa yii. Kolapo sọ pe idi ti ofin konile-o-gbele yii fi waye ni iluu Igbajo to wa ni ijọba ibilẹ Boluwaduro nipinlẹ Osun, ko sẹyin bi awọn ọdọ ilu naa se n fa wahala lati alẹ ọjọ Aiku titi di owurọ ọjọ Aje. Oríṣun àwòrán,Ademola Adeleke Eleyi lo mu ki gomina Adeleke gbe ikede naa sita lati owurọ ọjọ kinni, oṣu Kejila yii, ti gomina Adeleke si da awọn agbofinro si iluu Igbajo ati agbegbe to yii ka. Kolapo tun tẹsiwaju pe bi ẹnikẹni ba ru ofin naa ki awọn agbofinro fi iru imu ẹni bẹẹ ko ata ofin ni kiakia. Gomina Adeleke ni oun ko ni fi aaye gba ẹnikẹni to ba fẹ da omi alaafia ipinlẹ Osun ati ilu Igbajo ru. Gomina ni ki gbogbo olugbe ilu Igbajo ati agbegbe rẹ tẹle ofin isede oni wakati mẹrinlelogun ojojumọ to bẹrẹ yii. Adeleke sọ pe bo ti lẹ jẹ pe iku ọmọba Adegboyega Famodun ba awọn lojiji to si jẹ adanu nla fun ipinlẹ Osun, ko yẹ ko tun si wahala ti ẹnikẹni yoo tun maa da silẹ rara. O ni ijọba oun ko ni kawọ gbera lati fi aaye gba iwa ibajẹ ni ipinlẹ Osun rara. Gomnia Adeleke sọ mfiwaju si pe gẹgẹ bi oun ṣe jẹ olori ẹsọ alaabo ni ipinlẹ Osun oun kede isede konile-o-gbele titi alaafia yoo fi jọba ni ilu Igbajo ati agbegbe rẹ. Ninu atẹjade kan ti Olawale Rasheed to jẹ agbẹnusọ fun gomina Adeleke fi lede, Gomina Ademola Adeleko ba awọn ẹbi ati ẹgbẹ oselu APC kẹdun isipo pada Oba Adegboyega Famodun. Gomina Adeleke si gba ni adura pe ki Ọlọrun ko fun ẹbi ati ẹgbẹ oselu APC ni okun ati le gbe isẹlẹ naa. Rasheed, ni gomina Adeleke ti mọ ologbe Famodun tipẹ gẹgẹ bi oloselu to fara mọ ẹbi Adeleke igba ti o wa ni orileẹde Amẹrika. bẹẹ ni gomina Adeleke se apejuwe ologbe Famodun gẹgẹ bi ẹni to ti ni ipa nla ninu oselu to si ti mu itẹsiwaju ba ipinlẹ Osun. Nigba ti gomina Adeleke de si orilẹde Naijira lonii lo fi ọrọ ibanikẹdun ransẹ si iluu Igbajọ ati gbogbo awọn ti iku ologbe Famodun kan wi pe, ki Ọlọrun ko fun gbogbo wọn ni ọkan ti wọn yoo fi le gba iku ologbe gẹgẹ bi amuwa Ọlọrun.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cj4qne485nqo
|
2025-11-30
|
bbc
|
WHO kéde ìlànà tuntun láti kojú ìṣòro àìrí ọmọ bí
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Àjọ tó ń rí sí ìlera lágbàáyé, World Health Organization, WHO, fún ìgbà àkọ́kọ́, ti gbé àwọn ìlànà kalẹ̀ láti kojú àìrí ọmọ bí tó máa ń da ọ̀pọ̀ obìnrin láàmú. Àtẹ̀jáde kan tí àjọ náà fi sójú òpó ayélujára wọn sọ pé obìnrin kan láàárín obìnrin mẹ́fà tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín obìnrin tó lè bímọ ló ń kojú àìrí ọmọ bí. WHO ní ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tí àwọn lọ́kọláya tó bá ń kojú ìṣòro yìí nílò láti ṣe ni lílọ sí ilé ìwòsàn fún àyẹ̀wò tó péye. Àtẹ̀jáde náà sọ pé kìí ṣe obìnrin nìkan ló máa ń kojú ìṣòro yìí bíkòṣe pé àwọn ọkùnrin náà máa ń la ìṣòro kí àtọ̀ wọn má lè fún obìnrin lóyún kọjá. Wọ́n ní síbẹ̀, àwọn obìnrin ló máa ń kojú ìpèníjà àtàwọn ìnìra tó máa ń ti ẹ̀yìn àìrí ọmọ bí wá. WHO sọ pé ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta àwọn obìnrin tó ń kojú ìṣòro àìrí ọmọ bí ló máa ń kojú ìfìyàjẹni nínú ìgbéyàwó nítorí àìrí ọmọ bí. Àjọ ètò ìlera àgbáyé náà ní ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ni kò ní àǹfàní sí ilé ìwòsàn fún ètò àyẹ̀wò tó péye láwọn orílẹ̀ èdè kan Bákan náà ni wọ́n wòye pé àwọn ìnáwó tí àwọn tó bá ń wá ọmọ máa ń ná lórí àyẹ̀wò àti ìtọ́jú máa ń pọ̀ púpọ̀ tó sì jẹ́ pé àpò ara wọn ni wọ́n ti máa ń mu lọ́pọ̀ ìgbà. "Tí àwọn tọkọtaya bá gbìyànjú láti lo ìlànà IVF, owó rẹ̀ wọn púpọ̀, tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò ní owó náà." Èyí ló mu wọn gbé àwọn ìlànà kalẹ̀ fáwọn tó bá ń wá ọmọ láti jìnà sí àti pé àwọn ìlànà náà kìí ṣe fún obìnrin bíkòṣe àti ọkùnrin náà. Àwọn ìlànà náà nìyí: Gẹ́gẹ́ bí àjọ náà ṣe sọ, ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ló le ṣokùnfà àìrí ọmọ bí fún àwọn obìnrin, tí wọ́n sì ní ìwádìí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àyíká náà wà lára ohun tó le ṣòkùnfà àìrí ọmọ bí fáwọn ọkùnrin. Bákan náà ni wọ́n ní àwọn oúnjẹ kan wà tó le ṣe ìrànwọ́ nípa kí ọlẹ̀ ọmọ tètè sọ nínú obìnrin, tí wọ́n sì gba àwọn obìnrin tó bá ń wá ọmọ nímọ̀ràn láti máa jẹ àwọn oúnjẹ náà lóòrèkóòrè.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cq8dy5p99l9o
|
2025-12-01
|
bbc
|
Tinubu ní kí wọ́n dáàbò bo olùdíje sípò Ààrẹ Guinea-Bissau ní ọọ́físì ìjọba Naijiria lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba ológun
|
Oríṣun àwòrán,Samba BALDE / AFP via Getty Images) Aarẹ Bola Tinubu ti paṣẹ ki wọn daabo bo Fernando Dias Da Costa, to jẹ oludije fun ipo Aarẹ Guinea Bissau ninu eto idibo orilẹede naa to waye loṣu to kọja. Ninu lẹta kan ti minisita to n ri si ọrọ ilẹ okeere, Yusuf Tuggar, buwọlu, eyii to fi ṣọwọ si Aarẹ ẹgbẹ Ecowas, Omar Touray, Tuggar ni Aarẹ Naijiria ti paṣe pe ki wọn gbalejo ọkunrin naa ni ọọfisi ijọba Naijiria to wa lorilẹede naa, ki wọn si tun daabo bo nibẹ. Lẹta naa sọ pe igbesẹ Tinubu ko ṣẹyin akitiyan rẹ lati daabo bo ọgbẹni Da Costa ki awọn kan ma baa gbẹmi rẹ. Igbesẹ yi lo n waye lẹyin ti awọn ologun ditẹgbajọba lorilẹede naa lasiko ti awọn araalu n reti esi ibo Aarẹ ti wọn di loṣu to kọja. Tinubu ni igbesẹ naa waye lati fi han pe digbi loun wa lẹyin ijọba awarawa ni Afrika ati ni gbogbo agbaye. Fernando Dias lo n lewaju ninu awọn to gbe apoti ibo tako Aarẹ Umaro Sissoco ninu eto idibo naa, o si gbajumọ laarin ilu. Ṣaaju ni ajọ eleto idibo orilẹede naa ti kọkọ kilọ faraalu pe ki wọn ma kede esi ibo kankan ayafi ti awọn funra awọn ba kede rẹ. Asiko ti araalu n reti esi ibo Aarẹ naa lawọn ọkunrin kan ti wọn di ihamọra ogun fi panpẹ ofin mu Aarẹ Guinea-Bissau, Umaro Sissoco Embaló, eyii to farajọ iditẹgbajọba. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Ọjọ kẹta lẹyin idibo naa ti wọn ti kọkọ yọ ẹni to n lewaju ninu awọn alatako Aarẹ ni iṣẹlẹ ọhun waye. Awọn ologun kede lori ẹrọ amohunmaworan pe awọn ni yoo maa ṣakoso orilẹede naa titi di igba ti awọn yoo kede. 'Magomago' ṣẹlẹ nibẹ Ẹwẹ, Aarẹ Naijiria Naijiria tẹlẹ, Goodluck Jonathan wa lara awọn to kọkọ ha si orilẹede naa lẹyin ti ologun gbajọa nibẹ. Amọ lẹyin iṣẹlẹ naa ni baalu ileesẹ Aarẹ Ivory Coast gbe Jonathan pada wa si Naijiria lai farapa Nigba to de, Jonathan sọ pe wọn gbọdọ kede orukọ ẹni to jawe olubori ninu idibo ọhun. O ni asiko ti Aarẹ Guinea-Bissau, Embalo n ba awọn akọroyin sọrọ lọwọ ni iditẹgbajọba naa waye, amọ kii ṣe bẹẹ ni iditẹgbajọba ṣe maa n waye, to si mu ifura lọwọ O sọ pe "Ohun to waye ni Guinea-Bissau kii ṣe iditẹgbajọba, nitori Aarẹ funra rẹ lo kede iditẹgbajọba naa faraye… bẹẹ kọ ni iditẹgbajọba ṣe maa n waye. "Asiko ti iṣẹle naa n lọ lọwọ ni Embalo funra rẹ n ba awọn ileeṣẹ iroyin agbaye sọrọ lori aago pe wọn ti fi ṣikun ofin mu oun."
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cx2e0l7wl2ko
|
2025-12-02
|
bbc
|
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Edo ní kí ìyàwó Tuface, Natasha Osawaru, wáá ṣàlàyé ara rẹ̀, ìdí rèé
|
Oríṣun àwòrán,Others Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Edo ti paṣẹ pe ki iyawo gbajugbaja olorin taka-sufee nni, Tuface Idibia, iyẹn Ọnarebu Natasha Osawaru Irobosa, yọju si igbimọ to n ri si iwa ọmọluabi ati anfaani nile naa. Natasha ti ifẹ oun ati Tuface gbode lojiji, ni aṣofin to n ṣoju ẹkun Egor, nipinlẹ Edo. Ibẹrẹ ọsẹ yii si ni iwa ti awọn aṣofin ẹgbẹ rẹ ka si idojuti, jẹ jade ti wọn fi ni ko waa ṣalaye . Abẹnugan ile igbimọ aṣofin Edo, Blessing Agbebaku lo kede lọjọ Iṣẹgun, ọjọ keji oṣu Kẹjila ọdun 2025 lasiko ipade, pe: "Ọnarebu Natasha Irobosa ni lati yọju si igbimọ to n ri si iwa ọmọluabi ati anfaani, lati jẹ ka mọ idi to ṣe fi ile igbimọ wọlẹ." Bakan naa ni Agbebaku kede pe Natasha tun ni lati ṣalaye idi ti ile naa ko ṣe ni I fi iya jẹ ẹ. Laaarin ọsẹ kan ni wọn ni ki Iyawo Tuface yọju, ki igbimọ ti yoo ri si ọrọ rẹ si mu abọ wa laaarin ọsẹ meji. Oríṣun àwòrán,Hon. Natasha Osawaru/ Facebook Bi Tuface ṣe jẹ gbajumọ olorin ti ọpọ eeyan fẹran to, awọn ohun to n ṣe awọn ololufe rẹ ni kayeefi lo n ṣẹlẹ si i to si n tori rẹ di ọmọ ti aye n sọ lori ayelujara latigba to ti fẹ Natasha Osawaru. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ọpọ igba ni wọn maa n yanna-an ọrọ rẹ pẹlu iyawo to ṣẹṣẹ fẹ naa, ti iroyin si maa n gbe e pe oju ọkunrin ti wọn tun n pe ni Tu-Baba yii n ri nnkan ninu igbeyawo tuntun yii. Ni ti eyi to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ ti ile igbimọ aṣofin Edo fi ranṣẹ pe iyawo rẹ yii, o waye lasiko ti Tuface fi ara han lori eto ori Instagram kan ti atọkun eto, Daddy Freeze, n dari. Lori eto naa ni awọn eeyan mi-in naa ti darapọ, pẹlu awon eeyan ti Tuface paapaa ti ba ṣiṣẹ pọ ri. Ko pẹ ti Tu-Baba darapọ mọ eto naa ni Natasha naa fi ara han, ariyanjiyan bẹ silẹ laaarin tọkọ-tiyawo naa bi eto ọhun ṣe n lọ lọwọ, kia si ni Tuface kuro lori eto ọhun. Atọkun eto naa ti i ṣe Daddy Freeze lo gbe fọnran ohun to ṣẹlẹ yii jade lọjọ Aje ọsẹ yii loju opo Facebook rẹ. Ṣaaju ni fidio kan naa ti jade sori ayelujara, nibi ti wọn ti ni ọlọpaa mu Tuface ni UK, lẹyin ti ọrọ ṣe bii ọrọ laaarin oun ati Ọnarebu Natasha. Oríṣun àwòrán,Hon. Natasha Osawaru/Facebook Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Ọrukọ rẹ ni kikun ni Natasha Irobosa Osawaru, awọn eeyan maa n pe e ni Ọnarebu Natasha. Oloṣelu ni, ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Edo lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP ni. Akọsilẹ iyawo Tuface yii lati ọdọ ajọ eleto idibo, INEC, sọ pe ijọba ibilẹ Egor, nipinlẹ Edo ni wọn ti bi Natasha lọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla odun 1994. Lọwọlọwọ yii, oun ni Igbakeji olori ọmọ ẹgbẹ to pọ ju lọ nile igbimọ aṣofin Edo. Amofin ni Natasha, o gboye ninu ẹkọ imọ ofin ni Yunufasiti Igbinedion, ipinlẹ Edo, o si kẹkọọ agba (Masters) ni Full Sail University, orilẹede America. Ẹkọ nipa fiimu ṣiṣe lo kọ nibẹ. Ko too darapọ mọ oṣelu, awọn ọdọ ati awọn obinrin lo maa n gbẹnusọ fun, lati ri i pe idagbasoke n ba wọn. Oṣu Kokanla ọdun yii ni oun ati Tuface bi akọbi ọmọ wọn, ọmọ ọkunrin. Ẹ o ranti pe Annie Macaulay ni iyawo ti ọpọ eeyan mọ pẹlu Tuface fun ọdun pipẹ, ti wọn jọ maa n fi ifẹ han kiri. Ṣugbọn lojiji ni Tu-Baba ati Annie tuka, ti eyi si dun ọpọ awọn ololufẹ wọn pupọ. Bi Annie ṣe lọ ni Natasha gba ipo iyawo tuntun lọọdẹ Tuface, bo tilẹ jẹ pe awuyewuye jẹyọ lọtun-un losi lori ajọṣepọ naa nigba yẹn.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c0je78eegvyo
|
2025-12-03
|
bbc
|
Orúkọ àwọn aṣojú Naijiria sílẹ̀ òkèèrè ti Tinubu fi ránṣẹ́ sí àwọn aṣòfin di ariwo
|
Oríṣun àwòrán,Reno Omokri /Facebook Lẹyin iku akan, ariwo ẹnu lo kan ni ọrọ da bayii lati igba ti Aarẹ Bola Tinubu ti kede orukọ awọn eeyan marundinlogoji to fi ranṣẹ sile igbimọ aṣofin lati buwọ lu gẹgẹ bii aṣoju Naijria si awọn ilẹ okeere. Ẹ o ranti pe opin ọsẹ to kọja yii ni iroyin orukọ awon eeyan ti aarẹ fẹ lo naa jade sita. Lara awọn eeyan ti Tinubu fi orukọ wọn ranṣẹ lẹyin ọdun meji to ti n ba iṣakoso yii bọ ni Femi-Fani Kayode, Reno Omokri, Ọjọgbọn Mahmud Yakubu, Florence Ajimobi ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ṣugbọn pupọ ninu awọn eeyan ti aarẹ fẹ lo naa ni awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ati awọn ọmọ Naijiria paapaa n koro oju si. Wọn ni awon eeyan ti ko ni akọsilẹ ire lẹka ti wọn di mu, ti wọn ko ṣe ododo, ti wọn si le jẹ kilẹ okeere maa fi oju abuku wo Naijiria ni Tinubu ko jọ lati ṣoju wa. Ọpọ lo n sọ pe Aarẹ Tinubu fi orukọ awọn eeyan naa ranṣẹ lati san oore ti wọn ṣe fun un lọna kan tabi ikeji pada ni. Bẹẹ ni awọn mi-in si n sọ pe ki aarẹ tete pa orukọ naa pada, ko ma ba Naijiria loju jẹ ju bẹẹ lọ kaakiri agbaye. Eyi ni diẹ lara ẹgbẹ oṣelu ati awọn araalu ti wọn ti fi aidunnu wọn han si awọn aṣoju ti Tinubu fẹ lo nilẹ okeere. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Ẹgbẹ alatako gboogi fun APC ni Naijiria, PDP ti ṣapejuwe iyansipo naa bii jibiti, ohun ti eeyan gbọdọ bu ẹnu atẹ lu ati eyi ti ko ni ẹtọ ninu rara. Wọn ni awọn eeyan ti orukọ ati ìṣe wọn ko ṣee ranti si rere ni aarẹ yan, o si fi han pe ko si ètò mọ nipa yiyan ẹni to yẹ si ọfiisi ijọba. Akọwe apapọ fun PPDP, Ini Ememobong, sọ pe awọn ti Tinubu yan yii fi han pe Aarẹ funra rẹ ko ka jijẹ ọmọluabi ati kiko akoyawọ kun . O ni o fi han pe aarẹ ko ka oju yowu ti wọn ba fi n wo Naijiria si nilẹ okeere kun pẹlu. "Oju ohun ti aarẹ n ri lọwọlọwọ yii lo fi fẹ ran iru awọn eeyan yii lati ṣoju Naijiria, oju ti awọn ilẹ okeere yoo fi wo Naijiria ko kan an, nitori ẹ lo ṣe n ran iru awọn eeyan yii lọ lati ṣoju Naijiria." Ememobong lo sọ bẹẹ. Bakan naa lo ni bi Tinubu ṣe yan alaga INEC tẹlẹ, Mahmud Yakubu, ko daa. Ememobong sọ pe Yakubu to jẹ magomago pọ lasiko to n ṣe alaga INEC. O ni bi Aarẹ ṣe fa a kalẹ yii tumọ si idupẹ oore magomago to ṣe fun un lasiko ibo ọdun 2023 ni. PDP ni ki Aarẹ Tinubu tete gba iwe orukọ to fi ranṣẹ sile igbimọ aṣofin naa pada, nitori awọn eeyan ti orukọ wọn kun fun iwakiwa lo fi ranṣẹ pe ki wọn ṣoju Naijiria nilẹ okeere. Ẹgbẹ Alaburada ni ki Tinubu yan awọn mi-in ti orukọ wọn muni ranti iwa ọmọluabi lati ṣoju Naijiria. Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) koro oju si igbesẹ aarẹ yii. Agbẹnusọ ADC, Bolaji Abdullahi, ṣapejuwe rẹ bii pe APC ko ni nnkan kan lati ṣe. "To ba jẹ pe ohun ti wọn ri mu wa ree lẹyin ọdun meji aabọ ti wọn ti fi ṣọfo, o fi han pe wọn ko ni nnkan kan lati ṣe. "Bii igba ti wọn fi san ara wọn lẹsan ni, ki i ṣe pe wọn ni ohun ti wọn fẹ ṣe fun Naijiria lasiko yii lori awọn ohun to n ṣẹlẹ." "O ni awọn ti wọn fẹ ṣoju ilẹ Africa ninu wọn le maa koju ayẹwo finni-finni lati awọn orileede naa, ṣugbọn awọn to ba fẹ ṣoju Naijria ni United States, Moscow, abi UK, le ma tete ri itẹwọgba wọn gba titi di ọdun to n bọ. NNPP: Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party, (NNPP) Ladipo Johnson, ni tiẹ koro oju si orukọ alaga INEC tẹlẹ, Mahmud Yakubu to wa lara awọn aṣoju naa. O ni bi aarẹ tilẹ ni aniyan rere to fi yan Yakubu, araalu ko fi oju ire wo eyi, afi bi a ba fẹ maa tan ara wa. "Ẹ ma gbagbe pe alaga to ṣẹsẹ fipo silẹ naa lo ṣeto idibo apapọ ni INEC, ibo naa lo si gbe Aarẹ Tinubu wọle, gbogbo wa naa la si mọ pe awuyewuye pọ ninu ibo yẹn." Agbẹnusọ NNPP yii sọ pe ko tọna rara bi Tinubu ṣe yan Yakubu to ṣẹṣẹ fipo alaga INEC silẹ. Lara awọn ẹgbẹ to tun ti koro oju si awọn eeyan ti Aarẹ Tinubu yan lati ṣoju Naijiria nilẹ okeere ni ẹgbẹ to maa n kọwe lori ẹtọ ọmọniyan ni Naijiria, Human Rights Writers Association of Nigeria (HURIWA). HURIWA pe iyansipo naa ni ohun to buru jai to si tun mu idojutini dani. Oludari HURIWA, Emmanuel Onwubiko, sọ pe Tinubu n san oore fun awọn oloṣelu ti nnkan ko ṣe ẹnu ire fun wọn mọ ni, awọn arire-bani-jẹ ati awọn eeyan ti wọn ko ni iwa ọmọluabi. Awọn eeyan bii Femi Fani-Kayode ati Reno Omokri, ni HURIWA kọminu lori wọn ju, wọn ni iṣẹ ka maa bu awọn alatako wọn ti wọn yan laayo ni Aarẹ san ẹsan rẹ fun wọn bayii. Loju opo X, ẹnikan to pe ara rẹ ni @InibeheEffiong, kọ ọ sibẹ pe: "Iwe orukọ awọn aṣoju ti Aarẹ Tinubu fi ranṣẹ yii tun fidi ẹ mulẹ si i, pe ilu ti wọn ti maa n da awọn ọdaran lọla ni a n gbe. "Awọn ti wọn lọwọ si bi Naijiria ṣe bajẹ ni wọn tun pọju ti wọn yan lati ṣoju orilẹede wa nilẹ okeere. "Pupọ ninu awọn orukọ to wa lori iwe naa lo jẹ ti awọn oloṣelu ti wọn ti kuna lati ṣiṣẹ nipo ti wọn ti di mu ri, awọn arijẹni-madaru ati awọn ti jijẹ ọmọluabi wọn ko fẹsẹ rinlẹ." @ruffydfire kọ ọ pe: "Awọn ọmọ Naijiria duro fun ọpọ ọdun lati ni aṣoju, lẹyin naa lo si wa han si wọn pe oṣelu ni gbogbo ẹ ba de, iṣẹ awọn ọkunrin ati obinrin wọn ni. @engr_shaibu_: " Abuku ni eyi fun gbogbo ọmọ Naijiria kọọkan to n gbiyanju lati jẹ eeyan. Tinubu ti yan Reno Omokri bii aṣoju. Reno Omokri kan naa to fi ọpọlọpọ ọdun pe Tinubu ni ọba awọn to n gbe egboogi oloro, to ni ẹwọn lo yẹ ki Tinubu wa, pe ki i ṣe Aso Rock. Ẹni kan yii naa lo gbe iwe yunifasiti Chicago jade, to ni Tinubu ko yẹ lati jẹ olori. Reno yẹn. Lonii, afẹsunkanni ti di aṣoju. Agabagebe ti ni ọmọ iranṣẹ tuntun. "Eyi ni ohun to fi han wa pata, pe jijẹ ọmọluabi ko nitumọ ninu iṣakoso yii, iwọ ṣaa ti jẹ oloootọ leyin idibo" @Samzonal: "Tinubu san oore fun awọn isọngbe rẹ, Reno Omokri ati Femi Fani-Kayode, pẹlu eeyan Wike; Okezie Ikpeazu ati Ifeanyi Ugwuanyi, o sọ wọn di aṣoju. "Ko jọ ọpọ loju, Bola Tinubu n tẹsiwaju ninu sisan oore fawọn to n ṣe tiẹ ni Naijiria ni." @macburnertunes: "Tinubu n yan awọn oloṣelu to ti darugbo, ti wọn ti fẹyinti, lati ṣoju Naijiria nilẹ okeere. "Ko si ohun kan to maa yipada, bi a ba n tẹsiwaju lati maa lo awọn arugbo ni ẹka oṣelu wa." @Nwafresh: "Reno ati FFK bii aṣoju. Koda Ikpeazu to jẹ ipinlẹ Abia run ati Yakubu… Ẹ ko le ri awọn eeyan to ni otitọ inu layika Tinubu. Awọn eeyan bii tiẹ naa lo fi yi ara rẹ po…" Ko ni i buru buru ki ma ku ẹnikan mọ ni, ẹni ti yoo kù la o mọ niYoruba wi. Bi awọn kan ṣe bu ẹnu atẹ lu awọn ti Aarẹ Tinubu fẹ lo yii naa ni a ri awọn ti wọn gbe ori yin fun un. Diẹ lara awọn wọnyi ni: Senetọ Teslim Folarin Ọkunrin to dupo ipo gomina ipinlẹ Oyo ni 2023 yii ko ri ohun to buru ninu orukọ awọn eeyan ti Aarẹ Tinubu fi ranṣẹ. Teslim Folarin gboriyin fun Tinubu fun bo ṣe yan Florence Ajimobi, iyawo gomina Oyo tele, Oloogbe Abiola Ajimobi, gẹgẹ bii aṣoju Naijiria nilẹ okeere. O ni ipo to yẹ Florence Ajimobi ni Aarẹ Tinubu fun un. Bakan naa ni ẹgbẹ kan, ''The Security Committee of Yoruba Leaders, naa gboriyin fun Aarẹ Tinubu fun orukọ Ayo Oke, adari NIA tẹlẹ to wa lara awọn aṣoju naa. Wọn ni o kaju ẹ gidi. Ninu awijare ẹgbẹ APC lori ẹsun yii, Alukoro apapọ fun ẹgbẹ naa, Bala Ibrahim, sọ pe eletekete ni awon ẹgbẹ oṣelu to n tako orukọ awọn eeyan ti Aarẹ fa kalẹ . "Ṣe o wa tumọ si pe bi eeyan ba ti ṣe alaga INEC ri, ki i ṣe ọmọ Naijiria mọ niyẹn, tabi ko le dipo mu mọ?" Bẹẹ ni Bala beere. O ni bi ẹnikẹni ba n tako Yakubu lasiko yii nitori pe o ṣe alaga INEC ri, itako ti ko lesẹ nilẹ ni. Alukoro APC naa sọ pe iṣẹ INEC kọ ni Yakubu n lọ ṣe bayii, iṣẹ aṣoju Naijiria ni. O fi kun un pe Yakubu nikan kọ lo kuro ni INEC to si tun gba iṣẹ oṣelu, o ni bẹẹ lo ri fun aṣiwaju rẹ ti I ṣe Ọjọgbọn Atahiru Jega naa. O ni Jega naa gba iṣe ilu lẹyin to kuro ni INEC Bala sọ pe koda ko jẹ pe ẹsan oore ni eyi jẹ fun Yakubu, ẹsan oore to le kan oun abi ọmọ Naijiria eyikeyi to ba ṣe iṣẹ rẹ daadaa ni. Oríṣun àwòrán,Bayo Onanuga/X Aarẹ Bola Tinubu ti yan mínísítà ọkọ ofurufu tẹlẹ, Femi Fani-Kayode, alaga ajọ INEC tẹlẹ, Mahmood Yakubu, oludamọran aarẹ Naijiria tẹlẹ, Reno Omokri, Florence Ajimobi to jẹ aya Gomina ipinlẹ Oyo nigba kan ri at'awọn mejidinlọgbọn mii sipo aṣoju ijọba Naijiria nilẹ okeere. Oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, lo fọrọ yii lede loju opo X rẹ lanaa ọjọ Àbámẹ́ta tíì ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kọkànlá yii. Awọn mii to wa ninu awọn ti Tinubu kede orukọ wọn ni gomina ipinlẹ Abia tẹlẹ, Okezie Ikpeazu, igbakeji gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Femi Pedro, Sẹnẹtọ Jimoh Ibrahim lati Ondo, aya Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Erelu Angela Adebayo ati Sẹnẹtọ Grace Bent lati ipinlẹ Adamawa. Aarẹ Tinubu ti forukọ awọn eeyan mejilelọgbọn náà ṣọwọ sile aṣofin agba l'Abuja fún ibuwọlu iyansipo wọn. Lẹta meji ọtọọtọ ni Tinubu kọ sí aarẹ ile igbimọ aṣofin agba, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio, wí pe ki ile buwọ́lù mẹẹdogun ninu won gẹgẹ bii akọṣẹmọṣẹ aṣojú ìjọba Naijiria nilẹ okeere ati metadinlogun mii gẹgẹ bii aṣoju Nàìjíríà lasan an. Atupalẹ orukọ awọn eeyan naa fi han pe obinrin mẹwàá lo wa ninu awọn ti Tinubu ṣẹṣẹ yan sipo ọhun. Awọn mii to wa lara awon ti Tinubu yan sipo naa ni Ogbonaya Kalu lati ipinlẹ Abia, Tasiu Musa Maigari lati Katsina ati kọmíṣọ́nà tẹlẹ lati ipinlẹ Plateau, Yakubu N. Gambo. Awọn mii tun ni Sẹnẹtọ Nora Ladi Daduut lati Plateau, Nkechi Ufochukwu lati Anambra, kọmiṣọna nipinlẹ Eko tẹlẹ, Lola Akande ati asojú ìjọba Naijiria si Holy See tẹlẹ, Paul Oga Adikwu lati ipinlẹ Benue. Lara awọn mii ti aarẹ tun yan sipo aṣoju ijọba Naijiria nilẹ okeere tun ni Enebechi Monica Okwuchukwu lati Abia, Yakubu Nyaku Danladi lati Taraba, Miamuna Ibrahim Besto lati ipinlẹ Adamawa, Musa Abubakar lati Kebbi, Syndoph Endoni lati Bayelsa, Chima Geoffrey Lioma David lati ipinlẹ Ebonyi ati Mopelola Adeola-Ibrahim lati Ogun. Onanuga ṣàlàyé nínú atẹjade to fi síta náà pé àwọn orílẹ̀ede to ni ibasepọ to dan mọran pẹlu Naijiria bíi India, South Korea, Canada, Mexico, UAE, Qatar, South Africa, àti Kenya lawọn eeyan naa yoo ti lọ ṣojú ìjọba Naijiria. O ni lẹyìn tí ile aṣòfin ba ti buwọ́lù iyansipo wọn tán ni wọn yoo mọ orilẹede ti wọn n lọ. Iyansipo yìí wáyé lẹyìn tí Tinubu ti kọkọ forukọ eeyan mẹta ranṣẹ sile aṣofin agba fun ibuwọlu. Awọn eeyan naa ni Ayodele Oke lati ipinlẹ Oyo, Amin Mohammed Dalhatu láti Jigawa ati Ajagunfẹyinti Lateef Kayode Are lati Ogun. Ileeṣẹ aarẹ ni o ṣee ṣe kawon eeyan yii lọ ṣojú ìjọba Naijiria lorilẹede UK, Amerika ati France. This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Xcookie policyandprivacy policybefore accepting. To view this content choose 'accept and continue'. End of X post Content is not available
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cx25xvrev04o
|
2025-11-30
|
bbc
|
Àkójọpọ̀ ìkọlù tó ti ṣẹlẹ̀ ní Naijiria lẹ́yìn tí Tinubu kéde ìlú ò fararọ lẹ́ka ètò ààbò
|
Oríṣun àwòrán,AUDU MARTE/AFP via Getty Images/Google Oriṣiiriṣii ikọlu awọn agbebọn lo ṣẹlẹ ni ọsẹ ti Aarẹ Bola Tinubu ṣe ikede pajawiri lẹka eto aabo lorirẹede Naijiria. Orilẹede Naijiria n koju oniruuru ipenija lọwọ yii latari oriṣiiriṣii ikọlu tawọn janduku agbebọn n ṣe kaakiri papaa julọ lẹkun ariwa orilẹede yii. Bi wọn ti n ṣe ikọlu si ile ẹkọ ni wọn tun n ṣekọlu si ile ijọsin kaakiri apa ariwa Naijiria. Ṣaaju ikede ilu o fararọ Tinubu lawọn ẹgbẹ agbesunmọmi ISWAP ṣekupa awọn ọmogun Naijiria kan to fi mọ ọgagun kan to n jẹ Musa Uba. Lẹyin naa lawọn agbebọn kan ya wọ ike ijọsin CAC kan niluu Eruku nipinlẹ Kwara nibi ti wọn ti ji awọn olujọsin mejidinlogoji gbe lọ ti wọn si tun pa awọn eeyan nibẹ. Awọn janduku agbebọn naa tun ṣọṣẹ nile ẹkọ kan nipinlẹ Kebbi ati Niger. O kudiẹ bayii bayii ko pe ọsẹ kan ti Tinubu kede ilu o fararọ lẹka eto abo, to si paṣẹ fun ileeṣẹ ologun ati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lati ṣẹgun awọn agbesunmọmi to n da ilu ru kaakiri. Amọ, kaka ki ewe agbọn dẹ niṣe lo n le koko sii ọrọ ikọlu agbebọn to n ṣẹlẹ ni Naijiria. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Wọnyii lawọn ikọlu to ti waye lẹyin ikede ilu o fararọ Tinubu lẹka eto aabo. Lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kọkanla awọn janduku agbebọn tun ti ya wọ ile ijọsin kan nipinlẹ Kogi nibi ti wọn ti ji pasitọ ati iyawo rẹ pẹlu awọn eeyan mii gbe lọ. Ile ijọsin ọhun ni a gbọ pe o wa lawujọ Ejiba ni ijọba ibilẹ guusu Yagba. Oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Kogi kan lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fun BBC. A gbọ wi pe ṣadeedee lawọn janduku agbebọn ọhun ya wọ ṣoọṣi C & S naa ti wọn si bẹrẹ sii yinbọn lera lera. Iroyin naa sọ pe bayii lawọn olujọsin bẹrẹ si ni sa asala fun ẹmi wọn. Ẹwẹ, agbẹnusọ ijọba ipinlẹ Kogi, Kingsley Fanwo, ti sọ pe ijọba n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ eleto aabo atawọn fijilante lati doola awọn tawọn agbebọn naa ji gbe lọ nile ijọsin C&S ni awujọ Ejiba. ''Loootọ ni mo gbọ nipa iṣẹlẹ ijinigbe to ṣẹlẹ, awọn ẹṣọ eleto aabo atawọn fijilante ti bẹrẹ iṣẹ lati mawọn janduku agbebọn naa. Awọn to ṣiṣẹ laabi yii naa mọ pe ipinlẹ Kogi yoo ri pe gbogbo awọn eeyan ti wọn ji gbe lo kuro lakata wọn,'' Fanwo lo sọ bẹẹ fun BBC. Awọn janduku agbebọn ṣekọlu si agbegbe Gidan-bijimi nijọba ibilẹ bwari niluu Abuja nibi ti wọn ti ji eeyan meje lọ, gẹgẹ bii nkan tawọn olugbe agbegbe naa sọ fun ileeṣẹ tẹlifisan Arise. Ọkan lara awọn eeyan naa sọ pe Suleiman Shuaibu to jẹ ibatan ọkan lara awọn ọdọbinrin ti wọn ji ọhun sọ pe ọjọ ori awọn ọmọbinrin ti wọn ji gbe bẹrẹ lati ọdun mẹtadinogun si ọdun mẹtalelogun nigba ti ọmọkunrin to wa laarin wọn jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun. Awọn o-ṣoju-mi-koro sọ pe ni nnkan boo ago mẹwaa alẹ l'Ọjọru ọsẹ to lọ ni iṣẹlẹ ọhun waye, nigba tawọn janduku ọhun bẹrẹ sii yinbọn soke tawọn eeyan si bẹrẹ sii sa asala fun ẹmi wọn. Koda, a gbọ pe awọn fijilante to wa lagbegbe baa fẹsẹ fẹẹ nigba ti wọn ri iru nnkan ija oloro to wa lọwọ awọn janduku naa. Awọn janduku agbebọn tun ṣọṣẹ lawujọ Palaita nijọba ibilẹ Shiroro nipinlẹ Niger nibi ti wọn ti ji eeyan mẹrinlelogun lọ. Koda, awọn obinrin alaboyun wa ninu awọn eeyan naa. Ni nnkan bii aago meji ọsan ni iṣẹlẹ ọhun waye nibi tawọn eeyan ti n ṣiṣẹ ninu oko irẹsi. Awọn to moribọ nibi iṣẹlẹ naa sọ pe awọn agbebọn naa pada ji awọn eeyan gbe, bi tilẹ jẹ pe agbegbe naa ko jina awujọ Erena nibi to jẹ ibudo awọn ọmogun. Ijọba ipinlẹ Niger fidi iṣẹ ọhun mulẹ, amọ, wọn eeyan mẹwaa ni wọn gbe lọ. Ẹwẹ, awọn ẹṣọ eleto aabo ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹu lati igba ti Tinubu ti kede ilu o fararọ lẹka eto aabo. Ileeṣẹ ologun ni o le lawọn agbebọn ọdunrun un tawọn tuka ni ibudo wọn lawujọ Chibok ni nnka bii aago mẹta oru. Bakan naa ni ileeṣẹ ologun tun ti ṣe aṣeyọri kan tabi omiran lawọn ipinlẹ maa papaa julọ lẹkun ariwa Naijiria.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c93wgnj9l27o
|
2025-12-02
|
bbc
|
Ṣé ọmọ bíbí lè dín iye ọjọ́ tó yẹ kí obìnrin lò lókè eèpẹ̀ kù?
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Ti awọn ọmọde ba n ṣe ijọgbọn tabi ti wọn ba kọ lati jẹun, awọn obinrin kan a sọ pe awọn ọmọ naa n din iye ọjọ awọn gẹgẹ bii obi ku. Iwadii tuntun kan ti fi han pe eyii ko jina si ootọ, paapaa fun awọn obinrin ti iya n jẹ. Koda, nnkan bii oṣu mẹfa gbako lo le dinku ninu aye awọn obinrin mii fun ọmọ kọọkan ti wọn ba bi, paapaa fun awọn obinrin to n gbe ninu inira. Lasiko ti iyan ja ni Finland laarin ọdun 1866 si ọdun 1868, awọn oluwadii ṣewadii obinrin 4,684. Ọmọwe Euan Young lati fasiti Groningen lorilẹede Netherlands atawọn ikọ rẹ, Ọjọgbọn Hannah Dugdale, Ọjọgbọn Virpi Lummaa aati Ọmọwe Erik Postma sọ pe iyan naa lo buru julọ ninu itan ile Yuroopu. Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn obinrin ti wọn bimọ kasiko iyan naa ni oṣu mẹfa ge kuro lara iye ọjọ to yẹ ki wọn lo loke eepẹ lori ọmọ kọọkan ti wọn n bi. Iwadii naa fi han pe eyii le ri bẹẹ latari pe awọn obi naa n lo agbara to pọ lati tun awọn sẹeli inu ara wọn ṣe, eyii to fi wọn sinu ewu kiko awọn arun lọjọ iwaju. Ṣugbọn wọn ko ri aridaju iye ọjọ ti awọn obinrin n lo ati bi wọn ṣe n bi ọmọ si ṣaaju iyan naa. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ikọ oluwadii naa fidi rẹ mulẹ pe agbegbe ti awọn obinrin naa n gbe lasiko ti wọn n bimọ ni nnkan lati pẹlu esi iwadii ọhun. Nitori naa, ki ni idi to fi ri bẹẹ? Alaye akọkọ ni pe ipa ti ọmọ bibi n ni lara obinrin le buru si latari inira ti irufẹ obinrin naa n koju lagbegbe to n gbe. Kii ṣe tuntun pe awọn iya wa wa ninu awọn ewu aisan bii aisan ọkan latari bi wọn ṣe n sanra si atawọn wahala mii ti wọn n ṣe. Ọmọwe Young sọ pe wahala ti awọn obinrin maa n ṣe lasiko ti wọn ba n fun ọmọ lọyan atawọn wahala mii maa n din iye agbara obinrin to bimọ ku. Ipo iloyun ati fifun ọmọ loyun maa n gba ọpọ agbara lara obinrin, to n tumọ si pe awọn obinrin yoo padanu ọpọ agbara wọn lasiko ti iyan ba n mu. Young sọ siwaju si pe ti obinrin ba n bimọ leralera lai ni isinmi to yẹ, o le ṣakoba fun ilera irufẹ obinrin bẹẹ. Oríṣun àwòrán,Getty Images Amọ ṣa, ṣe ohun to pa awọn obinrin lara ni igba ọdun sẹyin le maa pa awọn obinrin lara laye ode oni? Young ni 'ti a ba fi oju ṣunukun wo ọrọ yii, a maa ṣakiyesi pe eto ilera to wa lode oni ko si laye atijọ. "Laye igba naa, awọn obinrin n bi ọmọ bii mẹrin si marun un lọ, eyii ti ko ri bẹẹ laye ode oni." Lati ọdun 1800 lawọn obinrin ti n din iye ọmọ ti wọn n bi ku kaakiri agbaye. Lọdun 2023, pupọ obinrin ni ko bi ju ọmọ meji pere lọ, eyii to jẹ ayipada to n waye lataro ọlaju ati bi awọn eeyan ṣe n kawe si. Amọ awọn orilẹede kan wa bii Niger, Chad, Somalia ati South Sudan ti awọn obinrin ṣi n bimọ bẹẹrẹ. Lọdun to kọja si ni wọn kede iyan ni Sudan ati Gaza eyii ti yoo tunbọ mu ki aye le koko fun awọn obinrin to wa nibẹ.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cjwy34d5j4jo
|
2025-12-02
|
bbc
|
Igun PDP kan kéde Adebayo Adedamola gẹ́gẹ́ bíi olùdíje gómìnà l'Osun
|
Oríṣun àwòrán,Others Igun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ Osun ti kede Adebayo Olugbenga Adedamola, ẹni ti ọpọ mọ si FRYO gẹgẹ bii ẹni to bori eto idibo abẹle lati jẹ oludije ẹgbẹ naa lasiko eto idibo Gomina nipinlẹ naa. Eto idibo abẹle yii lo waye lọjọ Isẹgun, ọjọ keji, oṣu Kejila ọdun 2025, ti awọn asoju to le ni igba si wa lati ijọba ibilẹ ọgbọn nipinlẹ Osun. Idibo yii waye lẹyin wakati mejila ti Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke kede pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nitori rogbodiyan to n lọ lọwọ ninu ẹgbẹ naa, ti wọn si yọ orukọ rẹ kuro ninu awọn oludije eto idibo abẹle. Adebayo ni apapọ ibo 919 ninu ibo 957 to jẹ ti awọn aṣoju ẹgbẹ naa. Alaga idibo abẹle naa Humphrey Abba, lasiko to n kede esi idibo naa ṣalaye ni, "eeyan ogun nikan ni a ko ibo wọn. A sọ fun yin ṣaaju pe oludije kan juwọ silẹ. Oludije to ko gbogbo ibo ni Adebayo Adedamola pẹlu apapọ ibo 919." Pẹlu bii Adeleke ṣe kede pe oun ti kuro, akọwe ẹgbẹ , Theophilus Shan, ni mimi kankan ko ni mi eto idibo abẹle naa, pe yoo waye, to si waye. Idibo naa waye niluu Osogbo, ti ajọ INEC si ṣe amojuto idito naa pẹlu awọn agbofinro. Ohun iyalẹnu lo jẹ pe orukọ Adeleke si han ninu iwe idibo abẹle naa. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Oríṣun àwòrán,Others Oríṣun àwòrán,Governor Ademola Adeleke/X Igbimọ to ṣagbatẹru eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP fun ipo gomina nipinlẹ Osun ti ṣalaye idi ti orukọ Gomina Ademola Adeleke si fi wa lori iwe idibo, bo tilẹ jẹ jẹ pe o ti kọwe fi ẹgbẹ naa silẹ. Akọwe igbimọ to n ṣakoso eto idibo naa, Ọgbẹni Sunday Solarin, sọ pe orukọ Gomina Adeleke ati alatako rẹ, Adebayo Adedamola, ni yoo si wa ninu iwe idibo nitori ko saye lati ṣe atunṣe lori iwe idibo naa mọ. Ọgbẹni Solarin ṣalaye pe lalẹ ana ọjọ Aje ọjọ kinni oṣu Kejila ọdun yii ni gomina kede wi pe oun ti fẹgbẹ oṣelu PDP silẹ. O ni ẹgbẹ si ti tẹ iwe idibo silẹ ko to di akoko yii, eyi to tumọ si pe ko saye lati ṣe ayipada kankan mọ. ''Ni bayii, gbogbo ẹni to ba fẹ dibo gbọdọ mọ pe Adebayo Adedamola nikan ni oludije oludije fun ipo gomina ninu idibo abẹnu ẹgbẹ PDP nipinlẹ Osun tori gomina Adeleke to jẹ alatako rẹ tẹlẹ ti kọwe fi ẹgbẹ silẹ,'' Solarin ṣalaye. A gbọ wi pe awọn aṣoju kaakiri ẹkun ninu ẹgbẹ ti dibo ninu eto abẹnu ọhun to waye niluu Osogbo lonii nipinlẹ Osun. Iroyin to tẹ wa lọwọ lati gbọngan Adolak Hall ti eto idibo naa ti waye fidi rẹ mulẹ pe awọn aṣoju ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, wa nibẹ lati wo bi eto naa yoo ṣe lọ Ẹwẹ, Gomina Adeleke ko tii kede ẹgbẹ oṣelu ti yoo darapọ mọ bayii, lẹyin to fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ. Oríṣun àwòrán,X/GovAdemola Adeleke O ku wakati mẹrindinlogun si eto idibo abele ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Osun, Gomina Ademola Adeleke kọwe kuro ninu ẹgbẹ oṣelu naa. Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Osun, Sunday Bisi kede lọjọ Aje pe ẹgbẹ oṣelu naa ko ni ṣe eto idibo abẹlẹ to yẹ ko waye lọjọ Isẹgun nitori bi iyapa ẹgbẹ ṣe n ba ẹgbẹ naa ja lọwọ yii ati bi Gomina Adeleke ko ṣe fi ifẹ han si gbigba tikẹẹti ẹgbẹ oṣelu PDP lati soju ẹgbẹ ninu eto idibo Gomina to n bọ nipinlẹ Osun. Ẹwẹ, ninu lẹta kan ti akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP buwọlu, tẹnu mọ pe eto idibo abẹle lati yan ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ ninu eto idibo Gomina yoo waye gẹgẹ bii wọn ṣe ti daba rẹ ni ile gbọngan Atlantic multipurpose Hall niluu Osogbo. Ninu lẹta miiran, ti wọn buwọlu lọjọ kẹrin oṣu kọkanla ọdun 2025, Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ni oun ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, to si ṣalaye idi rẹ. Lẹta ọhun to kọ ransẹ si alaga ẹgbẹ oṣelu naa ni wọọdu Sagba niluu Ede, Adeleke ni igbesẹ ohun da lori gbogbo rogbodiyan to koju ẹgbẹ naa lasiko yii. n. "Nitori rogbodiyan olori to n da ẹgbẹ oṣelu PDP laamu, mo n fi asiko yii kọwe kuro gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lẹsẹkẹsẹ. "Mo dupẹ lọwọ ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party fun anfani ti wọn fun mi gẹgẹ bii Sẹnetọ to n soju Osun West ati gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Osun." This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Xcookie policyandprivacy policybefore accepting. To view this content choose 'accept and continue'. End of X post Content is not available Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Ninu oṣu keju, Gomina Ademọla Adeleke sọ pe oun ati awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ọṣun ti gba lati ṣe atilẹyin fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu fun saa keji ni ipo aarẹ Naijiria. Gomina Adeleke sọ eyi ninu atẹjade kan to fi sita loju opo ayelujara X rẹ ninu eyi to ti sọ pe oun atawọn atukọ ẹgbẹ oṣelu naa ni ipinlẹ ṣe ipinnu yii lẹyin ifikuluku ọpọlọpọ ọsẹ pẹlu awọn obalaye, awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn iyalọja ati babalọja kaakiri ipinlẹ naa. Bakan naa lo fi kun un awọn eeyan wọnyii pẹlu ti buwọlu oun gẹgẹbi oludije ẹgbẹ oṣelu naa fun eto idibo ọdun 2026, eyi to ti pada kuro ninu ẹgbẹ naa bayii. Atẹjade ọhun ti wọn fi sita lẹyin ijiroro ati ifikuluku naa to waye ni ile ijọba ipinlẹ Ọṣun niluu Oṣogbo sọ pe lara awọn nnkan ti wọn ro mọ Aarẹ Tinubu lara ti wọn fẹ fi tii lẹyin bayii ni pe ọmọ onilẹ loun naa ni ipinlẹ Ọṣun. Atẹjade naa fi kun un pe lootọ lọrọ didarapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC jade eleyi ti awọn kan ni ẹgbẹ oṣelu APC ko fara mọ, ṣugbọn kii ṣe gomina Adeleke funrarẹ "lo gbe erongba ati dara pọ mọ APC dide" "Ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ko fara mọ didarapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, wọn kọ titori ifẹ ati ijolootọ si iṣakoso gomina , fẹ tẹle igbesẹ naa ni" Lẹyin ipade wọn ọhun, awọn adarigbẹ oṣelu naa gba lati ṣe atilẹyin fun aarẹ Tinubu fun saa keji nitori "ipinlẹ Ọṣun ni ipinlẹ abinibi rẹ…" Bakan naa ni wọn pinnu pe gomina Adeleke yoo dije fun ipo gomina lọdun 2026 labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2026.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c8r3gygyl78o
|
2025-12-02
|
bbc
|
Mi ò lè pe ohun tó wáyé ní Guinea- Bissau ní ìdìtẹ̀gbàjọba, ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé - Goodluck Jonathan
|
Oríṣun àwòrán,PATRICK MEINHARDT / AFP Aarẹ orilẹede Naijiria nigba kan ri, Goodluck Jonathan ti sọrọ sita lori iṣẹlẹ iditẹgbajọba to waye lorilẹede Guinea-Bissau, to si ni ohun iyalẹnu lo jẹ pe Aarẹ orilẹede naa, Umaro Embalo lo kede iditẹgbajọba ọhun sita. Gẹgẹ bii o ṣe sọ, Jonathan ni iditẹgbajọba ti wọn gbimọpọ lo waye lorilẹede Guinea Bissau. "Ohun to waye ni Guinea-Bissau, mi o ni pe ni iditẹgbajọba. Ko ki n ṣe iditẹgbajọba, mo le pe ni erepa nitori Aarẹ Embalo lo kọkọ kede pe awọn ologun ti gba ijọba ṣaaju ki awọn ologun to jade sita sọrọ pe awọn ti gba akoṣo orilẹede naa. "Embalo lo kede iditẹgbajọba, eyi to jẹ ohun iyalẹnu, ki n ṣe iyẹn nikan, nigba ti iditẹgbajọba yii n waye, Embalo n lo foonu rẹ fi ba awọn akọroyin agbaye sọrọ pe awọn ologun ti mu oun si ahamọ," Gomina ipinlẹ Bayelsa nigba kan ri ni ohun to ṣẹlẹ ni Guinea-Bissau jẹ ohun to dun oun pupọ gẹgẹ bii ẹni to gbagbọ ninu ijọba awarawa. "Mo jẹ ọmọ aadọrun ọdun lati orilẹede Naijiria, mo mọ bi wọn ṣe ma n ṣe awọn olori ijọba lasiko iditẹgbajọba. Aipẹ yii mo sọju ECOWAS ni Mali, ti iditẹgbajọba si waye lasiko naa. "Ologun ko ni gba ijọba, ko wa jẹ pe aarẹ to wa lori ipo yoo ni anfani lati ma ba awọn akọroyin sọrọ pe ọwọ ti tẹ oun, Ta lo n tan ara wọn? "Ko da, ọrọ yii dun mi ju ọjọ ti mo pe Buhari pe mo ki ku orilẹ lọ nigba ti mo padanu eto idibo aarẹ lọ End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Jonathan tẹnumọ pe eto idibo orilẹede Guinea Bissau waye lai si rogbodiyan kankan, to si pe fun pe ki wọn kede esi eto idibi naa. "Eto idibo waye lai si rogbodiyan, ti gbogbo wa si n reti ki wọn kede si idibo naa sita fun araalu. "Nigba ti wọn fẹ ṣetan ni, ti a n duro pe ki wọn kede esi idibo, ni Embalo kede pe iditẹgbajọba ti waye, ti ọwọ si ti tẹ oun. "Ṣugbọn, ko si ọwọ kankan to tẹ. Ọrọ temi fun ajọ ECOWAS ati AU ni pe wọn gbọdọ kede esi idibo naa," Oríṣun àwòrán,AFP via Getty Images Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Ijọba tuntun ti bẹrẹ ni Guinea-Bissau pẹlu bi wọn ṣe bura fun olori ogun kan, Horta N'Tam, gẹgẹ bii olori orilẹede naa bayii. Ẹ o ranti pe ana ode yii ni awọn kan to dihamọra ogun gbe aarẹ to wa nipo naa tẹlẹ, Umaro Sissoco Embaló, lọ. Gbigbe ti awọn to dihamọra ogun naa gbe Umaro lọ, waye lẹyin ọjọ kẹta ti wọn dibo aarẹ lorilẹede naa, ti Umaro si ti reti pe ki wọn kede oun bii ẹni to jawe olubori. Oni Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 2025 yii ni ajọ eleto idibo Guinea-Bissau fẹ kede esi idibo naa tẹlẹ, ṣugbọn ọjọ naa gan-an ni awọn ologun kede Ọgagun Horta N'Tam bii olori orilẹede tuntun. Iditẹgbajọba ti ko tete foju han lo waye lorilẹede naa lanaa ode yii, araalu sọ fun BBC pe awọn n gburoo ibọn, ṣugbọn awọn ko mọ ohun to n ṣẹlẹ. Ni ti Jẹnẹra Horta N'Tam ti wọn bura fun bii olori orilẹede Guinea-Bissau, eyi to waye ni olu ileeṣẹ ologun ilẹ naa lonii Ọjọbọ, ọdun kan ni wọn ni yoo fi wa nipo naa. Ṣaaju ni awọn ologun naa ti dena awọn eleto idibo lati ma ṣe kede esi ibo to yẹ ki wọn kede lonii, ti wọn si kede ijọba ṣọja bii eyi ti yoo maa ṣakoso lọ. Awọn ologun naa kede pe awọn ti gbakoso Guinea-Bissau, bẹẹ ni BBC gbọ pe wọn ti fi Umaro Embaló si ahamọ. Lori ẹrọ amohunmaworan orilẹede Guinea-Bissau ni awọn ologun naa ti kede pe awọn ti da ikọ ologun onirapada silẹ, awọn yoo si maa dari rẹ lọ titi digba ti ikede miran yoo waye. Loju iwoye awọn ẹgbẹ kan lorilẹede Guinea-Bissau, wọn ni aarẹ ti wọn le lọ naa, Umaro Sissoco Embaló, lo ṣeto iditẹgbajọba to yọ ọ nipo. Awọn ẹgbẹ naa sọ pe Umaro gbe igbesẹ ọhun lati ma ṣe jẹ ki esi ibo jade ni, nitori to ba lọ fidirẹmi. "Ero rẹ lori ọna to gba yii ni lati ma ṣe jẹ ki ajọ eleto idibo gbe esi ibo jade lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kọkanla to yẹ ki esi idibo jade, nitori to ba kuna lati yege." Bẹẹ ni ẹgbẹ Coalition Popular Front naa wi ninu atẹjade wọn l'Ọjọru. Ẹwẹ, Embalo ti wọn gbe lọ ko ti i wi nnkan kan lori ẹsun yii. O ti figba kan sọ pe aimọye igbiyanju lati gbajọba loun ti koju nigba toun wa lori aleefa. Laarin aadọta ọdun si asiko yii, iditẹgbajọba to ti waye ni Guinea-Bissau ti to mẹsan-an. Oríṣun àwòrán,Getty Images Aarẹ orilẹede Guinea-Bissau, Umaro Sissoco Embalo ni awọn agbebọn kan ti mu bayii, lẹyin ọjọ kẹta ti idibo waye lorilẹede naa. Oni Ọjọru, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kọkanla ni awọn eeyan kan to dihamọra, mu Aarẹ Umaro. Eyi n waye lẹyin to dena alatako rẹ lati kopa ninu idibo to waye naa. Nnkan bii aago kan ọsan ni awọn araalu bẹrẹ si i gburoo ibọn to n ro lakọlakọ bi wọn ṣe wi, ṣugbọn wọn ko tete mọ awọn to n yinbọn naa. Ohun ti ọpọ eeyan n sọ ni pe mimu ti wọn mu aarẹ naa le ni i ṣe pẹlu iditẹgbajọba. Oríṣun àwòrán,Getty Images Ninu idibo to waye lọjọ kẹtalelogun oṣu Kọkanla yii ni Aarẹ Umaro Sissoco Embalo to wa lori aleefa ko ti jẹ ki alatako rẹ gan-an, Domingos Simoes Pereira, dije. Fernando Dias ni wọn pada jọ du ipo aarẹ naa, ti igun mejeeji si ni awọn jawe olubori ni abala akọkọ idibo ọhun. Ṣugbọn Fernando Dias sọ pe oun ko gba pe Umaro bori. Olootu ijọba Guinea Bissau tẹlẹ, Domingos Simoes Pereira, ṣatilẹyin fun Fernando Dias, bo tilẹ jẹ pe wọn ko jẹ koun naa dije ninu ẹgbe PAIGC. Ẹgbẹ PAIGC yii lo ṣatọna bi Guinea-Bissau ṣe gba ominira. Ọjọbọ ọla yii ni ajọ eleto idibo ti ṣeleri lati kede ẹni to jawe olubori gan-an tẹlẹ. Wọn kilọ fawọn oludibo, awọn oludije, ẹgbẹ oṣelu ati awọn akọroyin lati ma ṣe kede esi idibo kankan ṣaaju asiko naa. Ninu eeyan 2.2 million to n gbe ni Guinea-Bissau, gbogbo wọn ni wọn fẹrẹ lẹtọ lati dibo. Awọn ti wọn si jade dibo yii kọja ida marundinlaadọrin (65%). Ṣugbọn lẹyin ọjọ kẹta ti ibo naa waye ni awọn kan yi ọrọ pada, wọn wọle gbe aarẹ to wa lori aleefa to si n reti ki won kede oun bii ẹni to tun jawe olubori lẹẹkan si i. Ọkan lara awọn orilẹede Iwọ-Oorun Africa ni Guinea-Bissau, alajọsẹ awọn Potogi ni wọn lati ibẹrẹ aye wọn. 2019 ni wọn kọkọ yan Umaro Sissiko Embalo sipo aarẹ. Lati ọdun 1974 ti orilẹede naa ti gba ominira, o ti to igba mẹwaa ti wọn ti koju igbiyanju lati ditẹ gba ijọba. Orilẹede Guinea Bissau ti fi ọpọ igba koju iṣoro airẹsẹ duro nipa oṣelu. Ẹẹkan pere ni wọn ni aarẹ adiboyan nilana ijọba awa arawa to pari saa rẹ ri.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c4gelx5rp0go
|
2025-11-26
|
bbc
|
Àwọn jàǹdùkú kọlu Obesere lágbo eré ní Okitipupa, ariwo sọ
|
Oríṣun àwòrán,Obesere/Instagram Gbajúmọ̀ olórin Fuji nnì, Abass Akande Obesere ti képe ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo láti bá òun ṣàwárí àwọn jàǹdùkú tó ṣe ìkọlù sí òun, tí wọ́n sì ba ohun èlò orin òun jẹ́. Ohun tá a gbọ́ ni pé ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 ni Obesere lọ ṣeré níbi ètò ayẹyẹ òkú kan ní ìlú Okitipupa, ìjọba ìbílẹ̀ Okitipupa, ìpínlẹ̀ Ondo táwọn jàǹdùkú kan sì ṣed ìkọlù si. Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Obesere fi síta Ayonla Althentic fi sórí ìkànnì Facebook lọ́jọ́ Àìkú sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ba Obesere lọ́kàn jẹ́, tó sì ń rọ àwọn aláṣẹ ní ìpínlẹ̀ Ondo láti gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ tí irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò fi ní máa wáyé mọ́. Ó ṣàlàyé nínú àtẹ̀jáde náà pé, lẹ́yìn tí àwọn ṣeré tán, tí àwọn ń kúrò níbi òde àríyá náà ni àwọn jàǹdùkú náà tí wọ́n pọ̀ bìbà yabo àwọn. "Àwọn kan wá sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀dọ̀ mi nítorí ọwọ́ mi ni owó wà. Gbogbo ìgbìyànjú wa láti ri pé a kúrò níbẹ̀ láyọ̀ ló já sí pàbó, tí wọ́n sì ń sọ pé kí n gbé báàgì owó ọwọ́ mi wá. "Wọ́n lù mí, èjìká mi yẹ̀, tí wọ́n sì fi ọ̀bẹ gún mi nígbà tí mò ń gbìyànjú láti sá wọ inú ọkọ̀ lọ. Gbogbo ara ló ń dùn mí báyìí." Althentic fi kun pé apá àwọn jàǹdùkú náà padà ká òun tí wọ́n sì gbé báàgì owó lọ. Ó ní bí wọ́n ṣe ń ṣèkọlù sí òun ni àwọn míì ń ṣèkọlù sí Obesere kódà lẹ́yìn tó gbìyànjú láti fi owó tú àwọn jàǹdùkú náà ká. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ó sọ pé àwọn ṣá à gbìyànjú láti gbé ara àwọn dé ìdí ọkọ̀ láti dá ààbò bo ara àwọn àti láti ri pé àwọn lọ tọ́jú ara àwọn. Ó wá rọ àwọn aláṣẹ láti ṣàwárí àwọn tó ṣe ìkọlù náà, kí wọ́n sì fojú winá òfin lójúnà àti dènà irúfẹ́ ìkọlù bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Alága ìjọba ìbílẹ̀ Okitipupa ní ìpínlẹ̀ Ondo, Andrew Ogunsakin ti wá sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù tó wáyé sí Obesere ní ìlú Okitipupa. Ogunsakin nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sójú òpó Facebook rẹ̀ sọ pé ọwọ́ ti tẹ àwọn afurasí mẹ́ta tí ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ìkọlù tó wáyé sí Obesere, tí wọ́n sì ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá. Ó sọ pé àwọn rí àwọn nǹkan gbà padà lọ́wọ́ àwọn afurasí náà àti pé gbogbo àwọn afurasí tó kù ni àwọn ṣì ń dọdẹ wọn, tí àwọn yóò sì ri dájú pé ọwọ́ tẹ̀ wọ́n láìpẹ́. Ó ṣàlàyé pé ní kété tí òun gbọ́ ìròyìn ìkọlù náà ni òun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti ri dájú pé àlááfíà jọba ní agbègbè náà àti láti ri dájú pé àwọn ṣe ohun tó yẹ. Bákan náà ló ní pé òun ti kàn sí àwọn aláṣẹ Obesere láti pe ìpàdé pẹ̀lú òun àti ikọ̀ rẹ̀. Ogunsakin tún gbóríyìn fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò fún bí wọ́n ṣè tètè dìde sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti ọ̀nà tí wọ́n gbà yanjú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún. Ó tẹmpẹlẹmọ pé ìṣèjọba tó wà lóde kò ní fi ààyè gba ìwà jàgídíjàgan, tí àwọn sì ní ìfarajìn láti mú ìgbéga bá àṣà àti ìṣe ilẹ̀ Ikale. Oríṣun àwòrán,Obesere/Instagram Ní ogúnjọ́ oṣù Kìíní ọdún 1965 ni wọ́n bí gbajúgbajà olórin Fújì Abass Akande Obesere. Obesere àti Ọmọrapala ni orúkọ tí àwọn èèyàn mọ̀ ọ́ sí jùlọ. Ọmọ bíbí ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo ni Obesere tó sì gbajúmọ̀ fún àwọn àṣà tó máa ń dá nínú àwọn orin rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwò orin ni Obesere ti gbé jáde tó fi mọ́ Omorapala Overthrow, Egunun Be Careful, Obaadan, Old Skool Lape, Mr Magic, Introduction àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Obesere ti kọrin káàkiri ìpínlẹ̀ ní Nàìjíríà àti lókè òkun. Bákan náà ló ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹ̀yẹ nílé àti lẹ́yìn odi.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cvgrd2xjxvxo
|
2025-11-24
|
bbc
|
Kí ló fà á tí ọ̀nà Circular Road n'Ibadan tó yẹ kó mú inú aráàlú dùn ṣe ń gba omijé lójú wọn?
|
Irinajo Circular Road bẹrẹ lati igba iṣejọba Gomina Rasheed Adewolu Ladoja, titi to fi kan Gomina Seyi Makinde. Lọdun yii, Gomina Makinde gbe aba isuna ₦891,985,074,480.27 kalẹ niwaju awọn asofin ipinlẹ naa fun ijiroro ati fifi ontẹ lu fun ọdun luu fun ti ọdun 2026. Bẹẹni ọna Circular Road yii jẹ ọkan lara ohun ti ijọba ipinnu lati ṣe fun ọdun to n bọ. Ṣugbọn igbesẹ yii n pa ọpọ araalu Ibadan lẹkun. Ọpọ awọn olugbe ijọba ibilẹ mẹfa ni ilu Ibadan, olu ilu Ipinlẹ Oyo fi ehonu han lọjọ Aje ọjọ kẹwaa oṣu kọkonla ọdun 2025 lori bi ijọba Ipinlẹ Oyo se n wo dukia won lulẹ. Awon olugbe ijọba ibilẹ, Egbeda, Ido, Akinyele, Ona Ara, Lagelu ati Oluyole ni wọn ko ara wọn jọọ lori bíi ijọba Ipinlẹ oyo ti fe yoo meter 500 si apa ọtun ati osi opopona obiripo (Circular Road) ti ijọba Ipinlẹ oyo nṣe lọwọ. Awọn olugbe awọn agbegbe ọhun lọ ni bi ijọba ipinlẹ Oyo ba tesiwaju pẹlu igbesẹ yìí, o le ni eeyan ẹgbẹrun lọna ọọdunrun 300,00, ti yoo di alainilelori ni ijọba ibilẹ mẹfefa ti opopona naa yoo gba kọja. BBC ṣe akojọpọ alaye lori irinajo Circular Road ati ibi ti ọrọ de lasiko yii.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cd0kle10kkeo
|
2025-12-03
|
bbc
|
Àwọn ajínigbé fún ìlú ní ọ̀sẹ̀ kan láti san 300m owó ìtúsílẹ̀ àwọn tí wọ́n jí gbé, tàbí kí wọ́n padà wá láti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ aráàlú
|
Oríṣun àwòrán,others Awọn ajinigbe kan ti wọn ya wọ ilu Isapa ni ijọba ibilẹ Ekiti ni Ipinlẹ Kwara ti kan si ilu naa, ti wọn si n bere fun owo Ń300 million gẹgẹ bi owo itusilẹ fun awọn ti wọn wa lakata wọn. Ko tan si bẹ o, ṣe ni wọn tun fun ilu naa ni gbendeke ọsẹ kan lati san owo yii tabi ki wọn pa gbogbo awọn ti wọn ji gbe. Lẹyin eyi ni wọn tun leri leka lati ya bo ilu naa lẹẹkan si lati pa ọpọlọpọ araalu, ti wọn kọ lati san owo naa laarin igba ti wọn fun wọn. Olori-Ọdẹ ilu Isapa, arakunrin Adeyeye lo sọ eyi di mímọ loni ọjọ Ọjọru nigba ti BBC News Yoruba kan sii lori iṣẹlẹ ijinigbe ọhun. Arakunrin Adeyeye sọ pe "wọn ti kọkọ pe, ti wọn bere fun N500m, sugbọn iduna-dura n lọwọ lori rẹ. "Sugbọn ni ọjọ Aiku, wọn pe pada, wi pe ki a san N300 million. "Ilu bẹbẹ lati san N5 million amọ wọn yari kanlẹ, wọn ni irufẹ owo bẹ kii se tawọn. "Wọn ni awọn fun ilu ni ọsẹ kan lati san owo naa tabi ki awọn pa awọn ti wọn ji gbe. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ "Wọn ni awọn yoo tun ya wọ ilu lati pa ọpọlọpọ eniyan ti a o ba san owo naa ni aarin igba ti wọn fun wa. "A o mọ boya irọ ni tabi ootọ, awọn ajinigbe naa sọ pe awọn lo lọ sọsẹ ni ilu Ejiba ni Ipinlẹ Kogi. Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aiku ni awọn ajinigbe ya wọ sọọsi C&S kan ni Ejiba ni Ipinlẹ Kogi, ti wọn si gbe pasitọ ati iyawo rẹ, ati awọn mii lọ. Gbogbo akitiyan lati kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa lo jasi pabo Saaju ni ọjọ kẹẹdọgbọn osu to kọjá ni BBC News Yoruba gbe pe awọn ajinigbe naa ya wọ ilu Isapa lẹba Eruku, ti wọn si ji awọn eeyan gbe lọ. Iroyin naa gbe pe ọdẹ ibilẹ kan lo kọkọ koju wọn, wọn si yinbọn lu u, amọ ko wọle si i lara.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cx2ej9p8yw3o
|
2025-12-03
|
bbc
|
Wo bí obìnrin tí kò ní ilé ọmọ ṣe di ọlọ́mọ láyé nípasẹ̀ ọ̀rẹ́
|
Oríṣun àwòrán,Georgia Barrington Obinrin kan, Georgia Barrington, ṣẹṣẹ di iya ọmọ ikoko obinrin kan ni, ṣugbọn oun funra rẹ kọ lo bi ọmọ naa bi obinrin ṣe n loyun bimọ. Kaka bẹẹ, ọrẹ rẹ timọtimọ Daisy Hope, lo ba a gbe oyun ọmọ naa, o fi mu ileri to ṣe fun Georgia nigba ti wọn wa lọmọge ṣẹ. Bi igbin fa ikarahun a tẹle e ni ọrọ awọn obinrin meji yii. Orukọ ti wọn maa n pe ara wọn ni tẹgbọn-taburo to ni ẹmi kan naa. Ibaṣepọ wọn yii naa lo pada di ohun ti ẹnikan fi aanu ṣe oore fun ikeji rẹ. Nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹẹẹdogun, awọn dokita sọ ohun ti ọmọbinrin ki i fẹ gbọ fun Georgia- Ohun ti wọn sọ fun un naa ni pe ko ni ile ọmọ lati ọrun wa, wọn ni ko ni i bimọ laye rẹ, nitori ko ni ile ọmọ. Arun ti wọn lo n ṣe Georgia ni Mayer-Rokitansky-Küster-Hauser (MRKH) syndrome, o si maa n ṣe ẹyọkan ninu ẹgbẹrun marun-un obinrin, fun Georgia ni tiẹ, niṣe lo jọ pe ko si ireti kankan fun un laye mọ nigba to gbọ ohun to n ṣe e naa. " O ba mi lọkan jẹ, bii pe aye mi ti tuka yanga ni. Emi ti mo ti maa n ro o pe emi naa yoo di ọlomọ nigba ti mo ba dagba, o si di ohun ti ko le ṣee ṣe niṣoju mi, gbogbo ala mi parẹ mọ mi ninu." Bẹẹ ni Georgia ṣalaye nigba to ranti iṣoro aye rẹ to ti pada waa di ayọ bayii. Awọn ẹbi rẹ ran an lọwọ lati ṣalaye ohun ti wọn lo n ṣe e fun un, wọn si mu ọkan rẹ le gẹgẹ bii ọrẹ rẹ, Daisy Hope naa ṣe ṣe fun . End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Daisy maa n ronu nipa bi ọrẹ rẹ to fẹran ọmọ ko ṣe ni i bimọ laye, o si maa n ro o pe ko yẹ ko ri bẹẹ. "Mi o fẹ ko o maa banujẹ, mo si maa n fun un ni ọrọ itunu pe ohun to n ṣe e ki i ṣe opin aye rẹ. Mo sọ fun un pe mo maa ba a gbe ọmọ rẹ sinu mi lọjọ kan." Daisy lo ṣalaye bẹẹ lori eto kan, Ready to Talk, eyi ti Emma Barnett jẹ atọkun rẹ. "Emi gan-an ko ro pe ohun ti mo n ṣeleri ẹ nigba naa ye mi, ṣugbọn mo mọ pe ohun ti mo maa pada ṣe fun Georgia ni." Oríṣun àwòrán,Georgia Barrington Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Nigba ti ọdun mẹwaa yoo fi kọja, Daisy bẹrẹ igbesẹ bi ileri rẹ yoo ṣe wa si imuṣẹ, nigba to si di 2023, awọn mejeeji bẹrẹ eto ilana ọmọ bibi ti i ṣe IVF. Iṣẹ olugbẹbi ni Georgia lọ fun nile ẹkọ, o n ri i bawọn abiamọ ṣe n bimọ, ṣugbọn oun funra rẹ ko le ba ọlọmọ pe. "Ẹnikan ti beere lọwọ mi ri, pe ṣe mo si ro pe iṣẹ to yẹ mi ni mo yan laayo yii, ṣugbọn ni ti ododo, iṣẹ yii ran mi lọwọ lati mu ọgbẹ ọkan mi san, mo mọ pe emi naa ṣaa ni ọmọ lọna kan abi omiran ti mo ba wa lawujọ awọn to n bimọ." Bẹẹ ni Georgia ṣalaye. Lẹyin ọdun diẹ si i, Daisy bimọ akọkọ ni tiẹ, Georgia lo si gba ẹbi fun un - bi Daisy ṣe di ọlọmọ ni tiẹ tun jẹ ki ọkan rẹ fẹ lati mu ileri to ṣe fun ọrẹ rẹ ṣẹ. "Ifẹ ti mo ni si ọmọ mi ko ṣee fi ẹnu ṣalaye, mo si lero pe gbogbo eeyan lo yẹ ko le ni iru ifẹ bẹẹ si ọmọ ti wọn ba bi, mo fẹ ki gbogbo eeyan ni iriri iru ifẹ yẹn." Daisi lo ṣalaye bẹẹ. Loootọ, o ni oun ti ro pe bi oun ṣe loyun ọmọ oun nirọrun ni ti IVF toun fẹ ba Georgia ṣe naa yoo ri, ṣugbọn ẹni to ba debẹ lo le sọ. Eto IVF naa bẹrẹ, Daisy loyun nilana to fẹ lo fun ọrẹ rẹ lati di ọlọmọ, o si jọ pe gbogbo ẹ n lọ letoleto bi wọn ṣe ro. Ṣugbọn nigba ti wọn ṣe ayẹwo oyun naa lọsẹ meji, niṣe lo han pe ko si nnkan kan nibẹ. Ko soyun, ko sọmọ. Georgia loun ranti igba ti nọọsi to ṣe ayẹwo naa sọ pe oun ko ri nnkan kan nibi ti wọn n ro pe oyun wa. "Irẹwẹsi mu mi, gbogbo ireti mi si dofo." "Mi o ri iru ibanujẹ to to bẹẹ yẹn ri laye mi, mo si bẹrẹ si i ronu pe emi ni mo fa a." Daisi lo ṣalaye bayii, nigba ti ai si oyun ninu rẹ naa han si i kedere . Georgia ni tiẹ ko tete mọ ohun ti yoo tiẹ sọ si ohun to ṣẹlẹ naa, niṣe ni ireti rẹ dofo. Nigba ti wọn yoo tun fidi ai si oyun ninu Daisy naa mulẹ si i fun wọn, osẹ kan lẹyin ayewo akọkọ ni wọn fidi ẹ mulẹ pe ọlẹ ti wọn gbe sinu Daisi ko di ọmọ. Ṣugbọn wọn ko dakẹ iyanju, wọn gbiyanju lẹẹkan si i. Ẹlẹẹkeji yii ni Daisy ti sọ pe : "Nigba ti mo loyun ikeji, mo ro o lokan mi pe eyi ko tun ni i da bii ti akọkọ, aye ko le buru si wa bii ti akọkọ mọ." Oríṣun àwòrán,Georgia Barrington Ọsẹ kẹfa lẹyin eyi, awọn mejeeji tun lọ ṣe ayẹwo, wọn n reti esi ayọ pẹlu ikayasoke. Bẹẹ ni kinni kekere kan han loju ibi ti wọn ti n wo ọlẹ inu Daisy, o jọ pe oyun ọtẹ yii ti duro. Ṣugbọn ki ilẹ ọjọ naa too ṣu, Daisy bẹrẹ si i ri ẹjẹ, ẹjẹ naa si pọ gan-an. "Niṣe ni mo ro pe ohun to ṣẹlẹ lakọkọ tun ti n ṣẹlẹ lẹẹkeji ni, ẹru si ba mi gidi." Daisi lo sọ bẹẹ. Wakati mẹfa lo fi ri ẹjẹ naa, o si ti ro pe oyun ọhun ti walẹ ni, ṣugbọn nigba ti awọn dokita ṣe ayẹwo, ọmọ ṣi wa nibẹ to n mi. Bẹẹ lo si ṣe ti oyun naa bẹrẹ si i dagba to fi pe asiko ti yoo waye . Igba ti wọn n fọkan si pe Daisy yoo tilẹ bimọ ko ti i to to fi bi i, o ya diẹ si asiko naa, ṣugbọn o bi i layọ ati alaafia, ọmọ ọbinrin. Inu Georgia dun kọja alaye, ko tilẹ ranti wo iru ọmọ ti ọrẹ rẹ ba a bi, boya ọkunrin ni tabi obinrin. "Bi mo ṣe ri ori ọmọ naa bayii to n jade bọ, mo bẹrẹ si i sunkun ni, gbogbo wa la n sunkun." Geogia lo sọ bẹẹ. O ni o ṣi n da bii ala loju oun ni, pe oun naa ti di ọlọmọ niyẹn. O ni oun ranti igba toun wa lọmọ ọdun mẹẹẹdogun ti wọn ni oun ko le bimọ laye. Bii koun da asiko ti ọmọ de yii pọ mọ ọdun naa lọhun-un, ti wọn sọ foun nibi ayẹwo GP surgery pe oun ko le lọmọ laye lo ri. Bi Georgia ṣe n sọ pe ori oun sọ ire to si n dupẹ lọwọ ọrẹ rẹ, bẹẹ ni Daisy naa n sọ pe oun ti mọ pe oun yoo ran ọrẹ oun pataki yii lọwọ lati di ọlọmọ laye, labẹ bo ti wu ko ri. " Ọrẹ tiwa kuro ni eyi ti ẹnikẹni le ri iru rẹ , nitori a ti la ohun to jẹ awa nikan la ṣe e funra wa kọja." Daisy lo ṣalaye bayii, bo ṣe n sọ pe ọrẹ tawọn ko ṣee fi owo wọ.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c5y9erj77eko
|
2025-11-29
|
bbc
|
Níṣe ló dàbí kí n la gbohùngbohùn mọ́ Obasanjo lórí nígbà tó sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí mi - Fayose
|
Oríṣun àwòrán,GettyImages/ Ayodele Fayose/Facebook Ó jọ bí ẹni pé ohun tí Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo sọ níbi ètò ayẹyẹ ọjọ́ ìbí gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Ayodele Fayose kò ì tíì tán nínú rẹ̀. Èyí kò ṣẹ̀yìn bí Fayose ṣe tún sọ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe láìpẹ́ yìí pé níṣe ló dàbí kí òun gba gbohùngbohùn lọ́wọ́ Obasanjo níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí òun, kí òun sì là á mọ́ Obasanjo lórí bó ṣe ń sọ̀rọ̀ náà. Fayose ní òun ti gbìyànjú láti parí aáwọ̀ pẹ̀lú Obasanjo ṣáájú ọjọ́ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí karùndínláàádọ́rin tí òun ṣe náà. Ó ní òun lo èèyàn kan gẹ́gẹ́ bí alárinnà láàárín àwọn méjéèjì ṣáájú ayẹyẹ náà. "Gbogbo àwọn ìfaǹfà tí a bá ti ní sẹ́yìn, kí a fi sẹ́yìn. Tí mo bá ṣẹ̀ ẹ́ tàbí tí o bá ṣẹ̀ mí, ẹ jẹ́ ka fi sẹ́yìn," Fayose sọ. Ó ṣàlàyé pé òun kò pe Obasanjo síbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí òun láti fi tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí òun kò ṣẹ Obasanjo. Ó fi kun pé Obasanjo ló ṣẹ òun nítorí òun ló yọ òun nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà àti pé tí ẹnikẹ́ni yóò bá tọrọ àforíjì, Obasanjo ló yẹ kó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ òun. Fayose ní Obasanjo gba òun ní àlejò dáadáa nígbà tí òun ṣe àbẹ̀wò sí ilé rẹ̀, tó sì ṣèlérí pé òun máa wá síbi ayẹyẹ náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ní ayẹyẹ míì ní orílẹ̀ èdè Rwanda. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ó fi kun pé òun ṣe ètò owó $20,000 fún ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí náà láti wá síbi ayẹyẹ náà. "Báwo ni èèyàn ṣe máa gba owó ẹni tí yóò sì tún máa wá sọ ìṣokúsọ nípa ẹni náà?" Fayose bèèrè. Ó tẹ̀síwájú pé ìkùnsínú bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Obasanjo sọ pé òun ni òun fẹ́ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn níbi ayẹyẹ náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbákejì ààrẹ ni àwọn ti ṣètò tẹ́lẹ̀ láti parí ayẹyẹ ọ̀hún. Ó júwe àwọn ọ̀rọ̀ tí Obasanjo sọ níbi ayẹyẹ náà bíi pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ìkọlù sí òun ni. "Báwo ni èèyàn ṣe máa sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sí ẹni tó ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún márùndínláàádọ́rin? "Inú bí mi gan ní àsìkò yẹn, ó dàbí ẹni pé kí n gba gbohùngbohùn lọ́wọ́ rẹ̀, kí n là á mọ lórí ṣùgbọ́n mo gbà á mọ́ra nítorí igbákejì ààrẹ wà lórí ìjókòó." Fayose fi kun pé òun fẹ́ kí ìbáṣepọ̀ tòótọ́ wáyé láàárín òun àti Obasanjo ṣùgbọ́n ìwà Obasanjo túmọ̀ sí pé kò fẹ́ kí àlááfíà wáyé. "Tí mo bá mọ̀ pé bí ó ṣe máa parí nìyẹn, kí ni mo nílò Obasanjo fún? Ṣé mo fẹ́ gbégbá ìbò ni?" Oríṣun àwòrán,people's Gazzet O jọ bii pe ija tuntun ti bẹrẹ laarin Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Olusẹgun Obasanjo, ati gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri, Ayodele Fayose. Ija naa ko ṣẹyin awọn oko ọrọ kan to jabọ lati ẹnu Obasanjo si Fayose nibi ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to waye niluu Eko lopin ọsẹ. Ko pẹ ti ọrọ Obasanjo bẹrẹ si n fa ori ayelujra ya ti Fayose naa da esi pada fun Obasanjo eyii to fi han pe oun kii ṣe ọmọ lọ ile lọ gba esi wa. Gbas-gbos Aarẹ tẹlẹ ati gomina tẹlẹ naa bẹrẹ lopin ọsẹ nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun marunlelọgọta Fayose. Nibi ayẹyẹ naa to waye niluu Eko ni wọn ti fun Obasanjo lanfani lati sọrọ to si jade lati ṣe bẹẹ. Lara awọn ọrọ ti Obasanjo sọ si Fayose loju awọn mọlẹbi, ọrẹ, iyawo atawọn alejo to wa nibi ayẹyẹ naa ni ko dun mọ Fayose ninu. Gẹgẹ bii ohun ti Obsan sọ nibẹ, Fayose funra rẹ lo fi iwe pe Aarẹ tẹlẹ sibi ayẹyẹ ọhun, koda, oun naa lo tun fi owo baalu rẹ lati ilu Kigali, lorilẹede Rwanda ranṣẹ. Oríṣun àwòrán,Fayose/Obasanjo Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Nigba to n sọrọ nibi eto naa ni Obasanjo ti kọkọ ni Fayose ti rin oun fi ni aimoye igba lai yipada. O ni bo tilẹ jẹ pe o maa n tọrọ aforijin lọwọ nigba mii ko dẹkun ati maa sọrọ abuku si oun. Obasanjo tẹsiwaju pe Fayose ko to ẹni to n pe oun sibi ayẹyẹ naa amọ o ran minisita nigba kan ri, Osita Chidoka, lati ṣe alarena laarin wọn ti oun si sọ fun pe oun ko ni fi owo ifẹyinti oun gbe baalu lati Kigali wa si Naijiria fun ayẹyẹ naa ki Fayose to fi owo ranṣẹ. Obasanjo ni "Awọn kan pe mi pe 'agbọ pe ẹ fẹ lọ sibi ayẹyẹ ọjọ ibi Fayose, ṣe ẹ ti gbagbe pe o maa n tabuku yin nigba kan ri ni?' Ṣugbọn mo ni ki wọn ma ṣeyọnu pe ọkan lara awọn ọmọ mi naa ni. "Ṣugbọn mi o fẹ ki a gbagbe ẹkọ ohun to ti waye laarin emi ati iwọ latẹyinwa, o gbọdọ kọ ẹkọ nla lati ara awọn iṣẹlẹ naa. Baba Iyabo tun mẹnuba bo ṣe gba Fayose nimọran lodi si didokoowo adiyẹ sinsin lasiko rẹ bii gomina amọ Fayose kọ jalẹ ti okoowo naa si lulẹ lẹyinorẹyin. Obasano juwe okoowo ọhun bii iwa jibiti. Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn to wa nibẹ lo n rẹrin ti Fayhose ati iyawo rẹ si duro niwaju Obasanjo tọwọtọwọ, pupọ ninu ọrọ ti Obasanjo sọ ku dun mọ Fayose ninu. Lẹyin ayẹyẹ naa ti ọrọ Obasanjo bẹrẹ si n fa ori ayelujra ya ni Fayose da esi pada fun Obasanjo pẹlu ọrọ abuku mii. Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abeokuta, agbẹnusọ Obasanjo, Kehinde Akinyemi ni Fayose ti fesi pada lori ọrọ ti Obsanjo sọ nibi ayẹyẹ re, eebu lo si fi ranṣẹ. Gẹgẹ bii ọrọ Akinyemi, o ni Fayose dupẹ lọwọ Obasanjo fun bo ṣe yẹ oun si lati lati yọju sibi ayẹyẹ naa amọ o sọ awọn "ọrọ ti ko mu ọgbọn dani" nibẹ. O ni Fayoṣe sọ pe oun yan lati ma fesi ni gbagede ayẹyẹ ọhun "ki gbogbo aye le mọ iyatọ laarin ọkunrin ti ori rẹ pe ati ọkunrin to n sinwin." O ni Fayose tun ti rọ Obasanjo ko da owo ti oun fi ranṣẹ si pada, o tun fidi rẹ mulẹ pe Obasanjo ti da owo ọhun pada lai fọwọ kan an.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cew4v0987qqo
|
2025-11-18
|
bbc
|
Abẹ ìsẹjọba rẹ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ni ìgbésùnmọ̀mí ti bẹ̀rẹ̀- Iléeṣẹ́ Ààrẹ fèsì padà fún Obasanjo
|
Oríṣun àwòrán,Others Ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria ti fesi pada fun aarẹ orilẹede Naijiria nigba kan ri, Olusegun Obasanjo pe ko ni ẹtọ lati bu ẹnu atẹlu iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu lori bi eto aabo ṣe mẹhe lorilẹede Naijiria. Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ kan niluu Jos, to jẹ olu ilu ipinlẹ Plateau, Obasanjo bu ẹnu atẹlu ipo ti eto aabo wa lorilẹede Naijiria. O ni awọn ọmọ Naijiria ni ẹtọ lati kesi oke okun pe ki wọn gba wọn nitori ijọba ti ja wọn kulẹ ni gbogbo ọna. Ẹwẹ, ileeṣẹ aarẹ ni gbogbo ohun to jọ mọ igbesunami lorilẹede Naijiria gberasọ labẹ iṣejọba Obasanjo, ti wọn si fẹsun pe oun naa dakun rogbodiyan eto aabo to wa lorilẹede Naijiria. Bakan naa ni ileeṣẹ aarẹ tun wọgile ọrọ Obasanjo to ni pe ki Aarẹ Bola Tinubu kesi ijọba oke okun fun iranlọwọ ti ko ba le gbe ogun ti iṣoro eto aabo. "Sisọ pe ki aarẹ bẹrẹ fun iranlọwọ lati oke okun lati koju iṣoro eto aabo ki n ṣe apẹẹrẹ adari rere to nifẹ ilu lọkan. Awọn ọrọ yii lo jẹ yọ ninu atẹjade kan ti oludamọran pataki si aarẹ lori ọrọ iroyin, Sunday Dare gbe sori ayelujara X. Atẹjade naa tun sọ ọrọ pe ki Obasanjo to daba pe ki Aarẹ Tinubu ju wọle fun orilẹede oke okun, o yẹ ki Obasanjo ronu bi oun fun ara rẹ se kuna lati gbe ogun ti iwa igbesunami lasiko to wa ni ijọba. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion "Ọrọ ti aarẹ nigba kan ri sọ nipa iṣejọba aarẹ Tinubu pe ko ni agbara lati da bobo awọn ọmọ Naijiria ni ko yẹ ko tẹnu Obasanjo jade, pe awọn araalu n koju ikọlu awọn agbebọn. "Naijiria lonii ni koju ọpọ ikọlu lati ọdọ awọn agbesunami ISIS, al-Qaeda ati awọn agbebọn ti ẹnu ibode. "Awọn agbebọn yii ni awọn ti wọn siṣẹ fun. Wọn n pin owo, ohun ija, ati awọn mii, to si jẹ erogba wọn ni lati pin orilẹede Naijiria. "Ẹ jẹ ka pe wọn ni orukọ wọn, Agbesunami ni wọn," ileeṣẹ aarẹ ṣalaye. "O yẹ ka jẹ ko di mimọ pe awọn agbebọn yii gbera sọ lasiko ijọba alagbada Obasanjo. Bi wọn se n korawọnjọ, ti wọn n da ibudo silẹ, ijọba lasiko naa kọ lati gbe igbesẹ to yẹ. "Nnkan to bẹrẹ pẹlu nnkan kekere, ni o ti di nnkan nla bayii lagbaye. "Fun olori to jẹ pe asiko rẹ ni iwa igbesunami gberasọ, ni o ti ohun ti a n sọ kaakiri agbaye bayii. Ileeṣẹ aarẹ tun jẹ ko di mimọ pe bi orilẹede Naijiria ṣe ṣetan lati ba orilẹede oke okun ṣiṣẹ pọ, ko ṣetan lati juwọ lẹ ominira rẹ fun orilẹede kankan. "Naijiria yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu agbaye, bẹẹni ṣugbọn ko ni juwọlẹ fun ẹnikẹni . "Naijiria nilo iranlọwọ ati igbọraẹniye orilẹede Amẹrika, ti ajọsepọ si n lọ lọwọ," ileeṣẹ aarẹ fikun. Oríṣun àwòrán,Other Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Oloye Olusegun Obasanjo, ti kìlọ pe kí ìjọba àpapọ dẹkùn idunaadura pẹlu awọn agbésùnmọ̀mí. Obasanjo to fidi ọrọ yii múlẹ ninu fídíò kan to ti lu ori ayelujara pa bayii, gba ìjọba Aarẹ Bola Tinubu ni imọran lati gba iranwọ awọn orilẹede ilẹ okeere lati wa ojutuu si eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria. Nigba to n sọrọ nibi isin orin Keresimesi to waye niluu Jos nipinlẹ Plateau lanaa ọjọ Ẹtì ọjọ kejidinlogun osu kẹwàá yii, Obasanjo ni ki ìjọba ye tọrọ aforijin lọwọ àwọn janduku agbésùnmọ̀mí mọ. Aarẹ Naijiria tẹlẹ sọrọ yii lẹyìn oniruuru iṣẹlẹ ipaniyan ati ijinigbe to ti waye nipinlẹ Kwara, Kebbi ati Niger lẹnu lọọlọ yìí. Akẹẹkọ 315 ati olukọ 13 láwọn agbésùnmọ̀mí ji gbe nile ẹkọ St Mary's Catholic school ni Papiri lọjọ kọkanlelogun oṣu Kọkànlá yii nipinlẹ Niger. Ṣaaju ni awọn janduku agbébọn ti jí akẹ́kọ̀ọ́binrin mẹrindinlọgbọn nile ẹkọ girama to wa ni Maga, ni ìjọba ìbílẹ̀ Danko-Wasagu ni ipinlẹ Kebbi. Ko din ni ogun eeyan tawon janduku agbébọn tún jí gbe nipinlẹ Kano ati Kwara laarin ọjọ Aje ati ọjọ Isẹgun ọsẹ yii. Ìṣẹlẹ yìí wáyé lẹyìn t'awọn janduku ti kọkọ ji olùjọsìn mejidinlogoji ni ṣọọṣi CAC kan niluu Eruku nipinlẹ Kwara gbé nibi ti won tun ti ṣekú p'awọn eeyan kan. Obasanjo fi aidunnu rẹ lori bi eto aabo ṣe n buru sii ni Nàìjíríà, ààrẹ Naijiria tẹlẹ ni awọn ọmọ Naijiria lẹtọọ lati bèèrè iranwọ ilẹ okeere lẹyìn tí ìjọba ti kuna lati daabo bo araalu. "Iru ẹṣin yowu ti o le maa ṣe, ibikibi to wu ki o ti wa, ọmọ Naijiria lawọn eeyan ti wọn n pa. O si dabi ẹni pe ìjọba wa ko lagbara lati daabo bo wa mọ. Ara awọn orilẹ-ede agbaye ni Naijiria wa, a lẹtọọ lati pe fun iranwọ ti ijọba wa ko ba le pese aabo fún wa," Obasanjo lo sọ bẹẹ. Aarẹ ana fikun ọrọ rẹ pe awọn ohun elo ijagun Igbalode ti jẹ ko rọrùn lati ṣẹgun awọn janduku agbébọn bayii. Obasanjo ni "ki n to kuro nijoba, ijọba lagbara lati gbe ẹnikẹni to ba huwa odaran nibi kibi. Ipenija ti a ni lasiko naa ni pe ori ilẹ ati oju ofurufu ni a le gba mu iru ọdaràn bẹẹ. Ṣugbọn awọn ẹṣọ eleto aabo le lo ẹrọ "drone" lati mu ọdaràn ki ọdaràn to ba sẹ sofin lọwọ yii."
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cm201m3m69no
|
2025-11-29
|
bbc
|
Omiyalé gbé èèyàn 159 lọ ní Sri Lanka, 20,000 di àwátì
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images O kere tan, eeyan 159 ni agbara omi ti gbe lọ lorilẹede Sri Lanka ni bayii ti orilẹede naa n koju ọkan lara iṣẹlẹ omiyale to buru julọ ninu itan rẹ. Yatọ si awọn to ku, eeyan to le igba ni wọn ṣi n wa. Iroyin ni ileegbe to le ni ẹgbẹrun lọna ogun lo ti ba omi lọ eyii to sọ 108,000 eeyan di alairilegbe. Ajọ Disaster Management Centre sọ pe ida kan ninu mẹta orileede naa ni ko ni ina ijọba lọwọ yii latari iṣẹlẹ naa. Agbegbe ti awọn eeyan ti padanu ẹmi wọn julọ ni Kandy ati Badulla ti awọn adoola ẹmi ko tete de. Saman Kumara to jẹ olugbe abule Badulla lagbegbe Maspanna sọ pe "eeyan meji ni a padanu ni abule wa… A ko le fi abule naa silẹ bẹẹ lawọn mii ko le wọle nitori ilẹ to ya di oju ọna." O sọ fun ileeṣẹ iroyin News Center lori ẹrọ ilewọ pe "Ko si ounjẹ fun wa, bẹẹ ni ko si omi to mọ geere." Oríṣun àwòrán,Getty Images Ọlọpaa ni ara awọn to ku ni eeyan mọkanla ni abule naa nibi ti wọn ti n tọju awọn arugbo lẹyin ti omi gbe ibi ti wọn n gbe lọ. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ni Anuradhapura, wọn doola eeyan 69 ti wọn ha sinu bọọsi ti omi gbe lọ. Ọkan lara ero inu bọọsi naa sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe awọn ologun lo ran awọn lọwọ lati gun ori igi ki wọn to moribọ. Ijọba orilẹede naa ti rawọ ẹbẹ sawọn ijọba ilẹ mii fun iranlọwọ, bẹẹ ni wọn tun rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ orilẹede naa to wa nilẹ okeere lati fi owo ranṣẹ fun iranlọwọ awọn ti ọrọ naa kan. Iji lile Cyclone Ditwah to kọlu Sri Lanka lọjọ Ẹti lo ṣokunfa iṣẹlẹ naa amọ a gbọ pe iji lile naa ti kuro nilẹ naa ti alagbalugbu om iyi ka. Lootọ ni Sri Lanka maa n koju iji nla amọ orilẹede naa ko tii ri irufẹ iji bayii ri. Iṣẹlẹ omiyale to buru julọ nilẹ naa waye ninu oṣu Kẹfa ọdun 2003 to si mu ẹmi eeyan 254 lọ ti ẹgbẹgbẹrun tun di alainilelori.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cy5gnewryg7o
|
2025-11-30
|
bbc
|
Iná ṣẹ́yọ nílé alájà púpọ̀ ní Hong Kong, èèyàn 65 jáde láyé, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ èèyàn míì di àwátì
|
Eeyan marundinlaadọrin ti jade laye, nigba ti wọn ṣi n wa eeyan omilẹgbẹ eeyan mii lẹyin ina kan to ṣẹyọ nileegbe alaja pupọ kan ni Hong Kong, lorilẹede China. Iroyin ni o ti fẹ ẹ le ni odidi wakati mẹrinlelogun ti ina ọhun bẹrẹ. Bo tilẹ jẹ pe awọn oṣiṣẹ panapana n ṣiṣẹ takuntakun lati rẹyin rẹ, ina ọhun ṣi n jo kikankikan. Oríṣun àwòrán,AFP via Getty Images Ina naa ṣẹyọ ni Wang Fuk Court, to jẹ ile nla ọlọpọ ero to ni aja mọkanlelọgbọn ni Tai Po, niluu Hong Kong. Nnkan bii aago mẹta ọsan ku isẹju mẹsan an lo bẹrẹ lọjọru. Ojule 1,984 lo wa nile naa ti nnkan bii 4,600 eeyan n gbe gẹgẹ bii eto ikaniyan ọdun 2021. Ọdun 1983 ni wọn kọ ile ọhun amọ wọn n ṣe awọn atunṣe kan lara rẹ eyii ti wọn fi igi ọparun bo. Awọn aworan lati ibẹ ṣafinhan bi ina ṣe n jo awọn ọparun naa kikankika. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ileegbe ti awọn arugbo pọ si ni iṣẹlẹ naa ti waye niluu Tai Po. Awọn ile naa ti orukọ rẹ n jẹ Wang Fuk Court ni eeyan 4,600 n gbe. Ninu eeyan 4,600 yii, 1,840 ninu wọn, to jẹ ida ogoji lo jẹ agbalagba ti ọjọ ori wọn ti le ni ọdun marundinlaadọrin. Pupọ ninu wọn lo si ti n gbe nibẹ lati ibẹrẹ ọdun 1980 ti wọn ti kọ awọn ile ọhun. Pupọ ninu wọn lo si ti n gbe nibẹ lati ibẹrẹ ọdun 1980 ti wọn ti kọ awọn ile ọhun. Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe igba akọkọ ree ti ina yoo ṣẹyọ nile alaja pupọ ni Hong Kong, awọn alaṣẹ ni ina yii lo buru julọ lati ọgọta ọdun sẹyin. Ijọba agbegbe naa ti sọ pe ile ẹkọ mẹtala to wa lagbegbe ti ina ọhun ti n jo ni wọn yoo gbe tipa titi ti wọn yoo fi rẹyin ina ọhun. Ẹnikan to gbẹnusọ fun ijọba ni awọn yoo kọ awọn ile alaburada ti awọn eeyan le wa fun akoko diẹ titi wọn yoo fi rẹyin ina naa. Oríṣun àwòrán,Reuters Lọwọ yii, ọwọ ọlọpaa ti tẹ eeyan mẹta ti wọn funra si pe wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa, wọn si ti fi ẹsun gbigbẹmi eeyan lairotẹlẹ kan wọn. Awọn mẹta naa ti ọjọ ori wọn jẹ lati ọdun mejilelaadọta si mejidinlaadọrin ni wọn jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ to n kọ ile, meji ninu wọn jẹ adari nileeṣẹ naa nigba ti ẹnikẹta wọn jẹ amojuẹrọ. Ọlọpaa ni awọn ri eroja 'mesh' ati 'Styrofoam' lara ile naa eyii to le jẹ ki ina tere jo daadaa. Awọn oṣiṣẹ panapana ti juwe iṣẹlẹ naa bii 'level five alarm' to jẹ iṣẹlẹ ina to buru julọ. Wọn ni yoo gba wọn ni odidi ọjọ kan ki wọn to le pa ina ọhun tan. Wayi o, titi di asiko ti a n ko iroyin yii, ko tii si ẹni to le sọ ohun pato to ṣokunfa ina naa. Jack Lau, BBC Global China Unit ati Gemini Cheng,to fi mọ BBC Chinese niluu Hong Kong fi kun iroyin yii.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c62d7d4ye6no
|
2025-11-27
|
bbc
|
Tórí ìgbélárugẹ àṣà àti ìṣe Yorùbá ló jẹ́ kí n fi iṣẹ́ agbẹjọ́rò sílẹ̀ fún eré orí ìtàgé - Bolanle Austen-Peters
|
Gbajugbaja oludari ati olootu ere n ni, Bolanle Austen-Peters, sọ pe igbelarugẹ aṣa ati iṣe Yoruba lo jẹ koun fi iṣẹ agbẹjọro silẹ fun ere ori itage. Bolanle sọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC Yoruba wi pe lati kekere loun ti fẹran lati maa kọ itan. O ni awọn nnkan yii lo jẹ koun nifẹẹ si ere ori itage. Bolanle ni ''ọmọbibi ipinlẹ Ekiti ni baba mi, amọ, ilu Eko ati Ibadan ni mo dagba si. Ẹkọ amofin ni mo kọ nile ẹkọ giga fasiti. Nigba ti mo ri i pe ko si ibi tawọn eeyan ti le kọ nipa aṣa, ounjẹ, ijo ati orin wa ni mo da ''Terra Kulture'' silẹ.'' Gbajugbaja olootu ere naa ni oun rii pe awọn eeyan fẹ ko nipa aṣa ati iṣe Yoruba lati igba ti oun ti bẹrẹ ere ori itage. ''Ọpọ lo fẹ lati wa wo ere wa, igba yẹn ni mo wa ri pe iṣẹ ti a n ṣe yii ṣe pataki gan an.'' Bolanle ti ṣe oriṣiiriṣii ere, amọ, o ni ''Moremi'' jẹ ere to ṣe pataki soun tori o sọ nipa agbara obinrin. ''Mo lo aṣọ wa, mo lo aṣa wa lati sọ itan Moremi, awọn eeyan si gbadun itan naa. Emi naa gbadun ere ọhun tori mi o mawọn itan yii tẹlẹ, iyẹn lo fi n dun mi pe a ko maa gbe aṣa wa larugẹ daadaa,'' Bolanle lo sọ bẹẹ. Oludari ere naa sọ pe inu oun dun pe nnkan ti oun n ṣe yoo wulo fawọn ọmọ oun atawọn ''ọmọ wa to n bọ lọjọ iwaju. Idi ni pe ta ni wa ti gbogbo wa ba gbagbe aṣa, iṣe, ẹkọ ati ede wa? Inu mi dun pe mo jẹ awokọṣe fun awọn to n bọ lẹyin,'' Bolanle lo sọ bẹẹ.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cvgr4mzjm2mo
|
2025-11-21
|
bbc
|
"Ẹ wo bí ẹ̀rí èké tí mo jẹ́ nílé ẹjọ́ ṣe sọ ọ̀dọ́ mẹ́ta tí kò lẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn dèrò ẹ̀wọ̀n ódún 36"
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Ron Bishop mọ ninu ara rẹ pe irọ loun n pa. Ọmọ ọdun mẹrinla pere ni i ṣe nigba ti o n jẹrii niwaju adajọ nibi igbẹjọ ẹsun ipaniyan. Ẹjọ naa da lori awọn ọdọ mẹta ti wọn fẹsun kan wi pe wọn ṣekupa ọrẹ rẹ timọ timọ, DeWitt Duckett, loṣu Kọkanla ọdun 1983. Alfred Chestnut, Andrew Stewart ati Ransom Watkins ni Bishop n jẹrii tako nile ẹjọ. Ẹjọ naa si ti n lọ daadaa pẹlu ẹlẹrii mẹta kan ti wọn ti jẹrii nile ẹjọ, eyi lo jẹ ki Bishop ronu pe ki ni yoo ṣẹlẹ toun ba sọ nnkan to tako ọrọ awọn to ti jẹrii. ''Awọn ẹlẹrii mẹta to ti sọrọ fidi rẹ mulẹ pe awọn ọdọ mẹta naa jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan wọn. Ero mi nigba naa ni pe ile ẹjọ le ma gbami gbọ ti mo ba sọ nnkan to yatọ si ohun tawọn to ti jẹrii tẹlẹ ti sọ,'' Bishop lo sọ bẹẹ. Irọ ti Bishop pa yii lo ran awọn ọdọ alawọdudu mẹta lọ ẹwọn ni Baltimore. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ O le ni ọgbọn ọdun ti ẹri ọkan Bishop fi n da a laamu wi pe irọ to pa lo ran awọn alaiṣẹ lọ sẹwọn. Oríṣun àwòrán,Ron Bishop Nigba ti Bishop n dagba ni kekere, o maa n ro pe aabo to peye wa nile ẹkọ fawọn akẹkọọ. Amọ, wọn ti pa arakunrin rẹ lai ri ẹni to ṣiṣẹ laabi yii. Ọrẹ meji ti Duckett jẹ ọkan ninu wọn ni Bishop maa n ba ni ajọṣepọ daadaa lasiko to ba wa nile ẹkọ. '''Duckett ko laapọn, a si ni ọrẹ mii to ṣikẹta wa toun naa n gbe ladugbo,''Bishop lo sọ bẹẹ. Harlem Park jẹ ile ẹkọ to tobi gan an ti o si le pẹlu, awọn ọrẹ mẹtẹẹta yii maa n wa ọna abuja lati ma le bọ si aarin ero. Wọn gba ọkan lara awọn ọna abuja naa loṣu Kọkanla ọdun 1983. Oríṣun àwòrán,Ron Bishop ''A n rin lọ ninu ọgba ile ẹkọ ni nigba ẹnikan ṣadeedee sọ pe ki Duckett bọ aṣọ ọrun rẹ wa.'' Aṣọ ẹgbẹ agbabọọlu alapẹrẹ Georgetown University ti gbogbo eeyan fẹran ni Duckett wọ lọjọ naa. ''Nigba ti mo yi wo ẹgbẹ mi, mo rii pe ẹnikan ti na ibọn si mi, bi mo ṣe sun sẹyin ni ẹni naa na ibọn sọrun Duckett. Emi ati ọrẹ mi bérẹ sii salọ, bi a ti n salọ ni a gbọ iro ibọn.'' Bishop ni bayii lawọn ṣe sa de ile ounjẹ awọn akẹkọọ, o ni nibẹ ni DeWitt ti n di mọ ọrun rẹ ti o si ṣubu silẹ. Oríṣun àwòrán,Getty Images Pẹlu iyalẹnu gbogbo nnkan to ṣẹlẹ, gbogbo wọn pada lọ sile wọn. Amọ, ko pẹ ko jina ni awọn ọlọpaa bẹrẹ sii wa gbogbo wọn kaakiri. Ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, Donald Kincaid, to wọle wa bawọn lagọ ọlọpaa lo sọ fun wọn pe Duckett ti ku. Bishop loun o mọ boun ṣe le ṣapejuwe nnkan to n ṣẹlẹ ninu ara oun nigba naa. Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Lẹyin ọjọ meloo kan ni ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọ sile Bishop. O ni wọn fi ori'siiriṣii fọto awọn afurasi han oun, ṣugbọn oun sọ fun wọn pe oun ko ri ẹnikéni nibẹ to jẹ pe oun lo pa Duckett. Bishop sọ pe nigba to ya ni ọlọpaa Kincaid mu oun wọ inu yara kan ti o si bẹrẹ si fọrọ wa oun lẹnu wo lori iku Duckett. O ni Ọgbẹni Kincaid sọ pe irọ loun n pa wi pe oun ko fẹ jẹwọ nnkan to ṣẹlẹ ni. Bishop ni ẹlẹrii tuntun mii ti darukọ afurasi mẹta wi pe awọn lo pa Duckett, ati pe ẹlẹrii meji mii naa sọ bẹẹ. Amọ, Bishop mọ ninu ara rẹ pe ẹnikan ṣoṣo lo ṣekupa Duckett. Bishop ni bayii ni ọlọpaa naa binu to si fẹẹ maa fi ibọn dẹru ba oun. O ni nigba naa loun sọ pe oun ṣetan lati sọ nnkan ti wọn ba fẹ koun sọ. Lẹyin o rẹyin, Bishop buwọlu iwe wi pe Chestnut, Stewart ati Watkins lówọ ninu iku ọrẹ rẹ. Lẹyin naa ni wọn mawọn mẹtẹẹta ti wọn si ran wọn lẹwọn. Bishop ni oun mọọmọ ma sọ fun ẹbi oun ni papaa julọ tori oun ko mọ bi mama oun ṣe maa gba ọrọ naa, ati pe koun ma baa bawọn ọlọpaa ninu. Oríṣun àwòrán,Getty Images Bishop ni niṣe loun n gbọn nigba ti wọn ni koun wa jẹrii nile ẹjọ tori nnkan ti ko ṣẹlẹ ni wọn sọ pe koun maa sọ. O ni irọ ni wọn sọ pe ko oun pa, ati pe oun loun jẹrii kẹyin dipo ki oun kọkọ jẹrii. ''Mo lero wi pe ile ẹjọ ro pe mo n parọ ni tori ọmọ ọdun mẹrinla ni mi nigba naa, bo tilẹ jẹ otitọ ni mo n sọ. Ọlọpaa Kincaid ti dunkoko mọ mi ṣaaju pe emi naa lọwọ ninu iku Duckett pẹlu awọn afurasi to n jẹjọ,'' Bishop ṣalaye. Lẹyin o rẹyin, Bishop sọ pe awọn afurasi mẹta yẹn naa lo wa nidi iku Duckett. Ileejọ si dajọ iku ati ẹwọn gbere fun wọn. Oríṣun àwòrán,Ron Bishop Ọgbẹni Bishop sọ pe ni gbogbo igba ni ẹri ọkan oun maa n da oun laamu wi pe ẹri eke loun jẹ nile ẹjọ. ''O dami loju pe awon eeyan yii kọ lo pa Duckett, mo si mọ pe ẹlomiran lo ṣiṣẹ naa. Mo tun maa n ro pe abi wọn le fẹ pa emi naa ni?'' Bishop pada lọ sile ẹkọ giga fasiti nibi to ti kọ nipa ero ẹro ati ihuwasi ẹda. Amọ, nnkan kan to maa n wa lọkan rẹ ni pe oun yoo sọ nnkan to ṣẹlẹ lọjọ kan. Ọdun 2019 ni akoko naa de lẹyin ọgbọn ọdun ti iṣẹlẹ naa ti waye. Awọn ọlọpaa pe Bishop fun ifọrọwanilẹnuwo, wọn si fidi rẹ mulẹ ileeṣẹ ọlọpaa lo fipa mawọn ọmọde lati jẹrii eke. Wọn si tun fidi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ṣewadii afurasi mii ti wọn ri lẹgbẹ ile ẹkọ naa mọ lẹyin ti wọn ti mu afurasi mẹta ti wọn ran lọ sẹwọn. Ẹlerii kan jẹrii nigba naa pe ọkunrin kan, Michael Willis lawọn eeyan kan ri lẹgbẹ ile ẹkọ naa lasiko iṣẹlẹ ọhun ti o si wọ aṣọ Georgetown sọrun. Ọdun 2002 ni wọn yinbọn pa Willis, iku si ni ko jẹ ki wọn mọ ẹni to pa Duckett gan an. In October 2023, the city of Baltimore reached a Loṣu Kẹwaa ọdun 2023 ni ilu Baltimore pinnu lati fawọn ọkunrin mẹtẹẹta naa ni 48-million gẹgẹ bii owo gba mabinu lori ẹwọn ti wọn ṣe lai ṣẹ. Ọkan Bishop naa ti mọ bayii, koda, o ni oun ṣetan lati tọrọ aforijin lọwọ wọn ti oun ba le ri wọn.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c208wnv3wxdo
|
2025-12-03
|
bbc
|
Àwọn ajínigbé jí Ọba gbé ní Kwara, bèèrè N150m owó ìtúsílẹ̀
|
Oríṣun àwòrán,Buhari Ọlatunde Awọn ajinigbe kan tun kọlu agbegbe Bayangan nijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara, ti wọn si ji Ori Ade ilu naa gbe lọ. Nnkan bi ago mẹsan an abọ owurọ ọjọ Satide ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti Oba, Ojibara ti ilu Bayangan, Alhaji Kamilu Salami wa ninu oko rẹ. Ninu ọrọ rẹ, Ọgbẹni Buhari Ọlatunde to jẹ ọmọ agbegbe naa sọ pe, awọn Ọba alaye to ku ni ìjọba ibilẹ Ifẹlodun ti n se ipade lati jiroro lori igbesẹ ti wọn yoo gbe lori iṣẹlẹ naa. Ọgbẹni Ọlatunde tẹsiwaju pe awọn ajinigbe naa ti kan si mọlẹbi kabiyesi, ti wọn si n beere fun aadọjọ miliọnu naira, owo itusilẹ ki wọn to yọnda Ọba alaye naa. Lasiko to n akọroyin BBC Yoruba sọrọ, kansilọ to n soju ilu Bayangan nijọba ibilẹ Ifẹlodun, Hon. Quadri Ọlaitan sọ pe, kabiyesi wa ninu oko pẹlu awọn ọmọ isẹ rẹ lasiko ti awọn ajinigbe yabo wọn . Hon. Quadri ni, awọn ajinigbe naa ti pe, ti wọn si bere fun aadọjọ miliọnu naira. "Pẹlu alaye pe, wọn tun ti pe ni irọlẹ ana ti wọn din owo itusilẹ naa ku si ọgọrun kan million naira." Hon. Quadri ni gbogbo ilu naa n sa sokesodo ni bayii lati wa ọna ti wọn fẹ gbe ọrọ owo naa gba. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ O fikun pe, awọn ọdẹ ilu naa ti wọ inu igbo lọ lati ọjọ Ṣatide ti iṣẹlẹ naa ti waye, sugbon wọn o ko ti ri kabiyesi, Ọba Ojibara ilu Bayangan, Alhaji Kamilu Salami. Akọroyin wa kan si Alukoro Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyemi Toun ṣugbọn titi di asiko yii, ko gbe ipe wa lati sọrọ lori iṣẹlẹ naa. Hon Quadri Ọlaitan tun ba BBC Yoruba sọrọ ni owurọ onii, to si tun fidi rẹ mulẹ pe wọn ko ti ri Ori Ade ọhun. Lori awuyewuye boya wọn ti yọnda kabiesi, Hon Qudri Ọlaitan ni irọ to jina si otitọ ni.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cvg81glkkzjo
|
2025-12-01
|
bbc
|
Ìyà tí mọ́ àwa olólùfẹ́ Arsenal lára ni mo ṣe kọ Ewúrẹ́ sára aṣọ mi – Agba Inaki
|
Eekan lara awọn sọrọsọrọ lori ayelujara ni Lekan Ọlalẹyẹ ti inagijẹ rẹ n jẹ Lekan Kingkong tabi Agba Inaki. Ọpọ lo mọ Lekan Agba Inaki gẹgẹ bi i ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal eyi to si maa fi n ṣe ọpọlọpọ fọnran ayelujara pẹlu yala nigba ti nnkan n dun fun ẹgbẹ agbabọọlu naa tabi igba ti nnkan lọ jaijai fun wọn. Ninu ifọrọwerọ yii pẹlu BBC News Yoruba lori ifẹ rẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, paapaa julọ lawọn saa ti nnkan dorikodo fun ẹgbẹ agbabọọlu naa ti wọn si n ti inu ijakulẹ kan bọ si omiran, Lekan Kingkong ṣalaye pe 'Ìya ti mọ awa Arsenal lara, ẹ o ri nnkan ti mo maa n kọ si ẹyin aṣọ ere idaraya mi, Ewurẹ ni. Itumọ rẹ ni pe Ewurẹ jẹ ẹran ile...' O ni oun nigbagbọ pe o loju ẹgbẹ agbabọọlu to le gbena woju ikọ Arsenal lọwọ yii ati pe idaniloju wa pe wọn yoo gba ife ẹyẹ kan gboogi ni saa yii. Oríṣun àwòrán,Screenshot/lekan_kingkong Gẹgẹbi ẹni to gbe lorilẹede South Africa fun ọpọlọpọ ọdun, BBC News Yoruba bi i leere boya oun pẹlu foju wina idẹyẹsi awọn ọmọ Naijiria to waye lawọn asiko kan lorilẹede South Africa, Agba Inaki ṣalaye pe oun ko le sọ pe eyi ko waye si awọn kan nibẹ ṣugbọn oun ko fi igba kankan doju kọ irufẹ idẹyẹsi bẹẹ. Bakan naa lo fi kun un pe iroyin okeere ton lekan ju ọkan lọ lọpọ igba ni iroyin ti awọn eeyan maa n gbe nipa idẹyẹsi awọn ajeji lorilẹede South Africa. Agba Inaki ni oun 'le sọ pe ko le to bi ayelujara ṣe maa n gbe e bi i wi pe gbogbo wa ni wọn ti pa sibẹ'.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cdx4ez4lzjko
|
2025-12-04
|
bbc
|
Ìgbà wo ní ìfẹnukonu kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀?
|
Oríṣun àwòrán,Getty Ìfẹnukonu jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn, àwọn ẹranko tó fi mọ́ àwọn ọ̀bọ. Ní báyìí àwọn olùwádìí ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìwádìí nípa bí ìfẹnukonu ṣe bẹ̀rẹ̀. Ìwádìí wọn fi hàn pé láti bíi ọdún mílíọ̀nù mọ́kànlélógún sẹ́yìn ni àṣà fífi ẹnu kora ẹni ti wà tó sì jẹ́ ohun tó gbajúmọ̀ láàárín ìran èèyàn àtàwọn ìran ọ̀bọ. Ìwádìí náà tún sọ pé àwọn èèyàn tí wọ́n farajọ ẹranko farajọ èèyàn náà ṣeéṣe kí wọ́n fẹnuko ara wọn rí. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe ìwádìí lórí ìfẹnukora ẹni lẹ́nu nítorí àwọn àdììtú kan tó wà lórí rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní ohun kankan ṣe pẹ̀lú ọmọ bíbí ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn tí wọ́n sì máa ń bá láàárín àwọn ẹranko náà. Oríṣun àwòrán,Getty Pẹ̀lú ẹ̀rí ohun tí wọ́n ṣàwárí nípa àwọn ẹranko míì tí àwọn náà máa ń fẹnukonu, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì wòye nípa bí ìfẹnukonu ṣe bẹ̀rẹ̀. Nínú ìwádìí wọn tí wọ́n tẹ̀ síta nínú jọ́nà Evolution and Human Behaviour, wọ́n júwe ìfẹnukonu bíi ohun tí kò mú ìpalára dání, tó jẹ́ fífi itọ́ kan ara pẹ̀lú ètè àtàwọn ẹ̀yà ẹnu míì láì sí oúnjẹ níbẹ̀. Àwọn èèyàn, ẹrank ọṣà àti bonobos ni wọ́n máa ń fi ẹnu kora gẹ́gẹ́ àlàyé Dókítà Matilda Brindle ti ilé ẹ̀kọ́ University of Oxford tó ṣáájú ìwádìí náà ṣe sọ. "A lérò pé nǹkan bí ọdún mílíọ̀nù mọ́kànlélógún sẹ́yìn ni ìfẹnukonu ti wáyé láàárín àwọn ìnàkí." End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Oríṣun àwòrán,Getty Images Nínú ìwádìí yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì rí ìwà ìfẹnukonu tó farajọ ti ìkoòkò, ajá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n fi ìwádìí wọn sọrí ìnàkí láti ṣe ìwádìí wọn lórí bí èèyàn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ni fẹnukonu. Ìwádìí náà tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn Neanderthal - tí ìrísí wọn farajọ ti èèyàn tí ìran wọn parẹ́ ní bíi ẹgbẹ̀rún ogójì sẹ́yìn – náà fẹnukonu. Iṣẹ́ ìwádìí kan tó ti wáyé rí lórí àwọn Neanderthal ṣàfihàn pé àwọn èèyàn tó wà láyé lónìí àtàwọn Neanderthals jọ ní kòkòrò àìfojúrí kan tó máa ń wà nínú itọ́ èèyàn. Dókítà Brindle ní èyí túmọ̀ sí pé ó ṣeéṣe kí wọ́n máa fi ẹnu kora fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí ẹ̀yà méjéèjì pín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí yìí sọ orírun bí ìfẹnukonu ṣe bẹ̀rẹ̀, kò sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Oríṣun àwòrán,Getty Onírúurú nǹkan ni àwọn èèyàn ti gbé jáde lórí èyí báwọn kan ṣe ní ó wáyé láti mọ ìlera ẹni tí èèyàn yóò jọ àṣepọ̀ pẹ̀lú ṣe le tó tàbí mọ bí wọ́n ṣe bara wọ mú si. Dókítà Brindle ní òun gbèrò pé èyí máa lè ṣe okùnfà ìwádìí láti mọ ìdí tí ìfẹnukonu fi ń wáyé. Ó ní ó ṣe pàtàkì láti mọ pé ìfẹnukonu jẹ́ ohun kan tí à ń ṣe tó farajọ ohun tí àwọn ohun abẹ̀mí tí kìí ṣe èèyàn náà ń ṣe. "Kí a máa ṣe ìwádìí ìwà yìí, kí a kàn má máa ko dànù nítorí ó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ láàárín àwọn èèyàn. Oríṣun àwòrán,Chester Zoo
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cj0149e4qe4o
|
2025-11-23
|
bbc
|
Ogbomoso Parapo: Bí ìgbẹ́jọ́ láàárín Soun àtàwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ ṣe lọ rèé
|
Oríṣun àwòrán,Facebook Ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó fi ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo ṣe ibùjókòó ti sún ìgbẹ́jọ́ èyí tó ń pè fún fífi òfin de Soun ìlú Ogbomoso, Oba Ghandi Olaoye láti má yan àwọn aláṣẹ fìdíẹ́ lé ọmọ ẹgbẹ́ Omo Ogbomoso Parapo Agbaye lórí. Ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní, ọdún 2026 ni ilé ẹjọ́ náà sún ìgbẹ́jọ́ náà sí. Adájọ́ N.E. Maha nígbà tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà lọ́jọ́ Kìíní, oṣù Kejìlá, ọdún 2025 sọ pé Oba Ghandi kò gbọdọ̀ tú àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ tó ti wà tẹ́lẹ̀ ká. Ilé ẹjọ́ tún ṣe ìdádúró àwọn aláṣẹ fìdíẹ́ tí Ọba Ghandi yàn láti yé pe ara wọn ní aláṣẹ ẹgbẹ́ náà títí tí ìgbẹ́jọ́ fi máa wáyé ní oṣù Kìíní ọdún 2026. Ṣáájú ni adélé alága Egbe Omo Ogbomoso Parapo Agbaye, Alhaji Yusuf Adetayi àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ méjì míì, Tolani Balogun àti Bukola Badmus ti wọ́ Ọba Ghandi, Ọ̀jọ̀gbọ́n Josiah Ajiboye àti ìgbìmọ̀ atófaratì ẹgbẹ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ fẹ́sùn pé wọ́n fẹ́ yan àwọn aláṣẹ mìíràn fún ẹgbẹ́ náà. Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Soun ìlú Ogbomoso kéde, nínú oṣù Kẹsàn-án pé òun ti tú ìgbìmọ̀ àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ náà ká. Bákan náà ló kéde yíyan Ọ̀jọ̀gbọ́n Josiah Ajiboye gẹ́gẹ́ alága fìdíẹ́ kó tó di pé wọ́n máa ṣe ètò ìdìbò láti yan àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ tuntun. Ilé ẹjọ́ ní Ọba Ghandi kò gbọdọ̀ tún àwọn aláṣẹ náà ká àti pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Josiah Ajiboye kò gbọdọ̀ máa pe ara rẹ̀ ní alága, kí gbogbo nǹkan wà bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ títí ìgbẹ́jọ́ fi máa wá sópin. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Àmọ́ agbẹjọ́rò àwọn olùjẹ́jọ́ níbi ìgbẹ́jọ́ ọjọ́ Ajé náà sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn ti pé ẹjọ́ láti fi tako àṣẹ àti pé àwọn tún ti pe ẹjọ́ míì pé ilé ẹjọ́ náà kò láṣẹ láti gbọ́ ẹjọ́ náà. Èyí ló mú kí wọ́n sún ìgbẹ́jọ́ di ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní, ọdún 2026 kí àwọn olùjẹ́jọ́ le fún àwọn tó pe ẹjọ́ ní ìwé ìpẹjọ́ lórí ẹ̀sùn tuntun náà. Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Nínú oṣù Kẹsàn-án ni awuyewuye mii tun ṣẹyọ niluu Ogbomoso lẹyin tawọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ alaṣẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye ti Soun ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye Orumogege Kẹta, tuka ke gbajare wi pe kabiesi naa ko lagbara lati tu igbimọ naa ka. Ninu fọnran kan ti alukoro ẹgbẹ naa, Kọmureedi T.M. Balogun, alaga abẹle ẹgbẹ naa, Alhaji Iliasu Jamiu ati akọwe abẹle, Arabinrin Janet Akintoyinbo fi ranṣẹ sawọn ileeṣẹ iroyin ni wọn ti ṣalaye pe igbesẹ Ọba Olaoye tako iwe ofin ati ilana ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye. Awọn oloye ẹgbẹ naa ko ṣai fidi rẹ mulẹ wi pe awọn ko tabuku tabi ṣe arifin si kabiyesi, ṣugbọn awọn n tẹle nnkan to wa ninu ofin ẹgbẹ naa ni. Awọn oloye ẹgbẹ naa sọ fawọn ọmọbibi ilu Ogbomoso nile loko ati lẹyin odi wi pe awọn si wa nipo awọn gẹgẹ bii igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye. Wọn ni igbesẹ Ọba Olaoye lati tu igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ ọhun ka ju agbara kabiyesi naa lọ. Awọn oloye naa sọ ninu fọnran ti wọn fi sita naa wi pe ''Ọba ko ni agbara lati tu ẹgbẹ wa ka. Ko si ninu iwe ofin ẹgbẹ wa bẹẹ, nitori naa, gbogbo awa oloye ẹgbẹ si wa ni ipo wa. A ko fi eyi tabuku kabiyesi, bi ko ṣe wi pe a duro lori nnkan ti iwe ofin wa sọ lọ ni.'' Kabiyesi Ọba Ghandi Olaoye to jẹ baba isalẹ ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye kede pe oun ti tu igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa ka. Kabiyesi si gbe igbimọ fidihẹ kan dide eyi ti Ọjọgbọn Olusegun Ajiboye to jẹ akọwe agba ẹgbẹ to n ri si iforukọsilẹ awọn olukọọ, TRCN, tẹlẹ jẹ adari rẹ. Igbimọ yii ni ori ade naa sọ pe yoo maa ṣakoso ẹgbẹ naa lọwọ yii. Ọba Olaoye ni oun tu igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa ka fun atunto ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye ki ẹgbẹ naa le wa ni ibamu pẹlu eto idagbasoke ọlọdun mẹẹdọgbọn oun fun ilu Ogbomoso. Amọ, ọpọ lo ti n sọ pe igbesẹ kabiyesi ko ṣẹyin ibaṣepọ ori ade naa ti ko dan mọran pẹlu awọn oloye ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye, eyi to jẹ ki ọpọ ninu wọn jinna si aafin. Iroyin kan tiẹ fidi rẹ mulẹ wi pe aarẹ ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye tẹlẹ to doloogbe loṣu Kẹfa ọdun yii, Adajọ fẹyinti Afolabi Adeniran, kuna lati wa ojutuu si faakaja to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa. Iroyin naa sọ pe eyi gan an lo jẹ ki kabiyesi gbe igbesẹ to gbe tori o dabi ẹni pe awọn kan ti fẹ ja ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye gba. Lẹyin naa ni adele alaga ẹgbẹ atawọn mii gbe Ọba Ghandi atawọn meji mii lọ sile ẹjọ.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c23e0rej599o
|
2025-12-02
|
bbc
|
Olórí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò kú sí àhámọ́ lẹ́yìn oṣù kan
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Ọkan lara awọn olori ẹgbẹ oṣelu African Movement for New Independence and Democracy (MANIDEM), lorilẹede Cameroon, Anicet Ekane, ti dagbere faye ninu ahamọ ti ijọba orilẹede naa sọ ọ si lẹyin oṣu kan to ti wa nibẹ. Agbẹjọro rẹ ati ẹgbẹ oṣelu MANIDEM lo kede iku Anicet laarọ ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila odun 2025. Anicet Ekane to ku si ahamọ yii jẹ ọkan lara awọn to ṣe atileyin fun Issa Tchiroma Bakary, alatako Aarẹ Paul Biya, ninu ibo to wa ye loṣu Kẹwaa ọdun yii. Awọn alaṣẹ lo ṣadeede gbe Anicet atawọn ọmọ ẹgbẹ alatako kan ni Douala, ti wọn gbe wọn lọ si ahamọ ni olu iu Cameroon ti i ṣe Yaoundé. Ẹnikan to ba BBC sọrọ lori iku ojiji yii sọ pe Anicet ku si ile iwosan awọn ologun ti wọn gbe e lọ. "A ko ri alaye kankan gbọ, wọn kan pe iyawo rẹ pe ko wa ni, nigba to si debẹ, wọn gbe oku ọkọ rẹ fun un." O fi kun un pe awọn ẹbi ni wọn pada gbe oku naa lọ si ile igbokuusi. Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ologun, Ọgagun Cyrille Serge Atonfack, fi sita lo ti ni aisan lo pa Anicet, ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin (74). End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion "O ti pẹ diẹ ti wọn ti n tọju Oloogbe ti aisan oriṣiiriṣii n ṣe naa ni ileewosan awọn ologun, awọn dokita si n ṣetọju rẹ lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹwaa ti wọn ti fi ofin mu un." Bẹẹ ni agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun naa wi. Nipa ẹṣẹ ti Oloogbe Anicet Ekane ṣẹ ti ijọba fi ti i mọle, awọn agbẹjọro rẹ ṣalaye pe ijọba fi ẹsun aifẹran ilu rẹ kan an, pẹlu kikọ awọn ẹlomiran si ijọba, titako ijọba ati dida oju ija kọ ijọba. "Wọn ko gbe e lọ siwaju adajọ kankan tabi fi ẹsun kan an ni kootu." Ọkan lara awọn lọọya Oloogbe, Hippolyte Meli, lo sọ bẹẹ loju opo ayelujara. O ṣapejuwe atimọle Anicet, olori ẹgbẹ MANIDEM bii eyi to lodi sofin. Iku Oloogbe Anicet Ekane ti da jinni-jinni bolẹ ni Cameroon, bẹẹ ni ọpọ alatilẹyin rẹ ni wọn ti kora jọ si olu ile ẹgbẹ naa to wa ni Douala lati kẹdun rẹ. Bakan naa ni ẹgbẹ rẹ ti kede pe awọn agbofinro ti yi ile olori ẹgbẹ to ku si ahamọ naa po. Nigba aye rẹ, Anicet Ekane kọkọ ṣe atilẹyin fun Maurice Kamto lati di aarẹ. Ṣugbọn ajọ eleto idibo Cameroon, ELECAM, ko gba Kamto wọle, wọn ni ẹgbẹ naa fa eeyan kalẹ ju ẹyọkan lọ. Nigba naa ni Ekane ati awọn oloṣelu miran lọ da ẹgbẹ mi-in silẹ, eyi ti wọn pe ni Union for Change Coalition, nibẹ ni wọn si ti yan Issa Tchiroma Bakary bii oludije. Ninu atẹjade ti wọn fi sita lati daro ilu Oloogbe Anicet Ekane, Minisita fun eto iroyin ni Cameroon, René Emmanuel Sadi, ṣalaye pe o wulẹ ti rẹ Oloogbe ṣaaju ki ijọba to fi i si ahamọ. O ni oriṣiiriṣii aisan lo ti n ṣe oloṣelu naa ko de atimọle lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹwaa, to si pada ja si iku loṣu Kejila. Bo tilẹ jẹ pe Sadi ko sọ iru aisan to ni o n ṣe Anicet tẹlẹ, o ni o gba itọju to peye nileewosan awọn ologun to ku si. "Lorukọ olori orilẹede, mo fi asiko yii ki ẹbi Oloogbe ati ẹgbẹ MANIDEM" Bẹẹ ni Sadi, Minisita eto iroyin ni Cameeroon, daro iku naa lorukọ ijọba apapọ wọn. O ni ijọba paapaa n ṣe iwadii ohun to fa iku Anicet. Bakan naa ni wọn ni ki araalu ṣọra lori ikayasoke nitori iku Anicet Ekane, ko ma si ṣe di rogbodiyan kankan. Ọpọ eeyan lo ti n koro oju si iku olori ẹgbẹ MANIDEM ti iroyin rẹ jade lowurọ oni. Lara wọn ni ajọ European Union, to ni alafo nla ni iku Anicet Ekane yoo mu ba oṣelu Cameroon . Wọn rọ ijọba lati ri si aabo ati alaafia awọn oloṣelu, ki wọn si fi gbogbo awọn to wa ni ahamọ latigba ti wọn ti dibo lọjọ kejila, oṣu Kẹwaa ọdun yii silẹ. Ẹwẹ, gbajumọ lọya to maa n fi igba gbogbo bu ẹnu atẹ lu iwa ajẹbanu, Akere Muna, ti ṣapejuwe iku Ekane bii igba ti eeyan ba pa ina to nla to n jo lọwọ, bẹẹ ina naa n jo fun ijangbara ijọba awaarawa ni. Muna, toun naa kuro ninu ere idije dupo aarẹ Cameroon, sọ pe Ekane ti sọ foun ri pe ara rẹ ko le to bo ṣe yẹ. Ṣaa, ẹgbẹ MANIDEM ti ni ki awọn alatilẹyin awọn ṣe suuru, ki wọn si duro niṣọkan, maa reti ibi ti yoo yọri si.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cjrj7z3w491o
|
2025-12-02
|
bbc
|
Orí kó ìkọ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles yọ lọ́wọ́ ikú ọkọ̀ òfufufú
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Iku to ba fẹ pani, to ṣini ni fila, o yẹ ki oluwarẹ maa dupẹ ni. Bẹẹ lọrọ ri fun ikọ agbabọọlu ilẹ wa, Super Eagles, lanaa ode yii, nigba ti ọkọ ofurufu to n gbe wọn bọ pada sile lati Polokwane, South Africa, balẹ ni ti pajawiri ni Luanda, orilẹede Angola, lati dena ijamba to le mu ẹmi lọ. Gẹgẹ bi ajọ to n ri si ere bọọlu lorilẹede yii, NFF, ṣe ṣalaye, : "Baaluu ValueJet to n gbe ikọ naa lati Polokwane, South Africa, lọ si Uyo fun ifẹsẹwọnsẹ ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun fun ti idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 2026, ti wọn yoo ti koju ilẹ Olominira Benin Republic, koju iṣoro ferese to fọ lofurufu, lẹyin to gbera nibi ti wọn ti rọ epo si i ni Luanda, orilẹede Angola. "Awakọ naa tete ṣe bii akọṣẹmọṣẹ, o dari baaluu pada si papakọ ofurufu Luanda, lati dena ijamba. "Ọkọ yii kan naa lo ti kọkọ ko awọn ikọ Super Eagles kan lọ si Polokwane lalẹ Ọjọbọ, to si balẹ si South Africa ni aarọ ọjọ Ẹti." Ajọ NFF ninu alaye rẹ, tẹsiwaju pe ọkọ ofurufu yii kan naa ni wọn lo lasiko ti Super Eagles koju ikọ Bafana Bafana ilẹ South Africa, ni Bloemfontein, loṣu to kọja. "Ajọ NFF fi da ẹyin ololufẹ ati alẹnulọrọ gbogbo loju, pe ValueJet ati awọn ẹka to yẹ, titi kan Minisita irinajo ofurufu ati ti ilẹ okeere, ati Olori oṣiṣẹ lọfiisi Aarẹ, ti n ṣiṣẹ lori bi wọn yoo ṣe gba iwe aṣẹ ti yoo paaarọ baaluu yii. Baaluu tuntun naa yoo fo lati Eko lọ si Luanda, lati gbe ikọ agbabọọlu yii lọ si Uyo." End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ajọ NFF dupẹ lọwọ awọn ololufẹ ikọ naa fun suuru ti wọn ni, wọn ni awọn yoo ri i daju pe Super Eagles balẹ gudẹ pẹlu alaafia . Lasiko ti a n pari iroyin yii, afikun alaye ti NFF fi si oju opo X wọn ni pe ikọ Super Eagles ti balẹ si Uyo. This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Xcookie policyandprivacy policybefore accepting. To view this content choose 'accept and continue'. End of X post Content is not available
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cn4w4pdq1q2o
|
2025-10-12
|
bbc
|
Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ẹ̀dínwó bá owó èròjà oúnjẹ́, kí ló fà á?
|
Yoruba ni tie bi ba ti kuro ninu isẹ, isẹ buse. Bẹẹ si ni orisa bii ọfun ko si, ojoojumọ lo n gba ẹbọ lọwọ ẹnu. Ko si ojumọ kan, ti a ko ni fi ọwọ sẹnu lati jẹun amọ bi owo awọn eroja ounjẹ naa se gbe owo lori, lo n kọ ọpọ idile lominu. Ariwo lori ọwọngogo ọja naa si lo gbode lati igba ti ijọba Tinubu ti yọwọ kuro lori sise eto iranwọ lori owo eroja epo rọbi. Sugbọn iroyin ayọ lo jẹ fun ọpọ ọmọ orilẹede yii lati ri pe ẹdinwo ti n bao wo awọn eroja ounjẹ naa. Ọpọ eeyan lo ti n sọrọ lori owo eroja ounjẹ ati awọn ọja miran to ti n wa silẹ naa. Awọn eeyan kan ni tori pe a w ani asiko ojo, ti ikore oko maa n waye ni owo ọja se n lọ silẹ ni akoko yii. Awọn miran ni oju ọjọ to dara fawọn agbẹ lati gbin ire oko lo faa, ero awọn miran si ni pe eto aabo to gbogbọn si ni . Amọ sa, awọn miran ni ijọba apapọ lo seto bi wọn se ko ọpọ eroja ounjẹ wọ orilẹede yii wa lati ilẹ okeere eyi to mu ki ẹdinwo ba eroja ounjẹ. Koda, ẹgbẹ awọn agbẹ lorilẹede Naijiria, All Farmers Association of Nigeria (AFAN), gbagbọ pe fun igba diẹ ni ẹdinwo naa yoo fi wa nitori igbesẹ to n mu adinku bao wo ounjẹ naa yoo sisẹ fun igba diẹ ni. Idi ree ti BBC News Yoruba fi se abẹwo si awọn ọja ti wọn ti n ta eroja ounjẹ kaakiri ilẹ Kaarọ Oojire. BBC de Ọja Bodeija nilu Ibadan, Ọja tuntun ni Osogbo, Ilorin ati Abeokuta. Afojusun wa ni lati mọ bi owo ọja se dinwo si, ka si tun se awari ipa ti ẹdinwo ounjẹ naa yoo ni lori awọn olokoowo ounjẹ.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cwy7lx5exvwo
|
2025-11-11
|
bbc
|
Àgbà ọ̀jẹ̀ òṣèré tíátà, Oyewole Olowomojuore, tí a mọ̀ sí Bàbá Gébú, dágbére fáyé
|
Oríṣun àwòrán,KunleAfod / Instagram Ikú tí pa àgbè, bíi ẹni tí kò le è da aro Ikú tí pa Aluko bíi ẹni tí kò lè pa Osun Ikú tí pa Lekenleke bíi ẹni tí kò lè pa ẹfun Ikú tún ti pa àgbà òṣèré miran ni agbo tíátà Yorùbá. Gbajúmọ̀ alawada àti odu ni agbo tíátà, Ọmọọba Oyewole Olowomojuore, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Baba Gebu lo jade laye. Gbajugbaja òṣèré tíátà nni, Kunle Afod lo kede ikú Baba Gebu ni ojú òpó ayélujára Instagram rẹ̀. Ìrọ̀lẹ́ òní ni àgbà ọjẹ òṣèré tíátà náà dágbére fáyé. Oríṣun àwòrán,Baba Gebu/Facebook Gẹ́gẹ́ bíi Afod tí wí, àìsàn ranpẹ lo ṣe Baba Gebu to fi tẹrí gbasọ. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Oloogbe Olowomojuore wa lara awọn Agba ọjẹ òṣèré tíátà to dúró sínú ẹgbẹ́ àwọn òṣèré ANTP nigba ti àwọn òṣèré kan lọ da ẹgbẹ́ TAMPAN silẹ. Nígbà ayé rẹ̀, baba Gebu tí kopa ninu ọ̀pọ̀ ere tíátà lórí telifisan àti sinimá. Lara awọn ere tíátà tí Baba Gebu tí kopa ni Kengbe ọrọ, Aare Agbaye (1983), Anikura (1982) Citation (2020) àti àwọn ere tíátà miran ni orisirisi. Oríṣun àwòrán,KunleAfod/Instagram
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/ce9d703jzy8o
|
2025-11-13
|
bbc
|
Àwọn jàndùkú agbébọn tún ya wọ ṣọ́ọ̀ṣì Kerubu (C&S) ní Kogi, jí pásítọ̀ àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn míì gbé lọ
|
Oríṣun àwòrán,Google Iroyin to tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Kogi ti sọ pe awọn janduku agbebọn tun ti ya wọ ile ijọsin kan nipinlẹ Kogi nibi ti wọn ti ji pasitọ ati iyawo rẹ pẹlu awọn eeyan mii gbe lọ. Ile ijọsin ọhun ni a gbọ pe o wa lawujọ Ejiba ni ijọba ibilẹ guusu Yagba. Oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Kogi kan lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fun BBC. A gbọ wi pe ṣadeedee lawọn janduku agbebọn ọhun ya wọ ṣoọṣi C & S naa ti wọn si bẹrẹ sii yinbọn lera lera. Iroyin naa sọ pe bayii lawọn olujọsin bẹrẹ si ni sa asala fun ẹmi wọn. Ẹwẹ, agbẹnusọ ijọba ipinlẹ Kogi, Kingsley Fanwo, ti sọ pe ijọba n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ eleto aabo atawọn fijilante lati doola awọn tawọn agbebọn naa ji gbe lọ nile ijọsin C&S ni awujọ Ejiba. ''Loootọ ni mo gbọ nipa iṣẹlẹ ijinigbe to ṣẹlẹ, awọn ẹṣọ eleto aabo atawọn fijilante ti bẹrẹ iṣẹ lati mawọn janduku agbebọn naa. Awọn to ṣiṣẹ laabi yii naa mọ pe ipinlẹ Kogi yoo ri pe gbogbo awọn eeyan ti wọn ji gbe lo kuro lakata wọn,'' Fanwo lo sọ bẹẹ fun BBC. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Iṣẹlẹ yii waye lẹyin oniruuru iṣẹlẹ ijinigbe bẹẹ to ti ṣẹlẹ lawọn ile ẹkọ ati ile ijọsin nipinlẹ Kebbi, Niger ati Kwara. Laipẹ yii ni lawọn janduku agbebọn ji akẹkọọ 300 ni ile ẹkọ ijọ Katoliiki kan to wa nipinlẹ Niger gbe lọ. Bakan naa lawọn janduku agbebon tun ji awọn akẹkọọbinrin ile ẹkọ onileegbe kan lọ nipinlẹ Kebbi. Lasiko kan naa ni wọn ti ji awọn olujọsin lọ ninu ijọ CAC kan niluu Eruku nipinlẹ Kwara nibi ti wọn tun ti ṣekupa awọn eeyan. Iṣẹlẹ ti Kogi yii yoo tun jẹ ki ijọba tun okun ṣokoto rẹ so lori ati pese aabo fawọn akẹkọọ atawọn olujọsin nile ijọsin ti ko si ni igboro.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c865p5nwyz7o
|
2025-11-30
|
bbc
|
Ìdí rèé tí Trump ṣe dáwọ́ fífún àwọn ọmọ orílẹ̀èdè 19, tí kò rọ́wọ́ họrí, ní físà dúró
|
Oríṣun àwòrán,Facebook/Donald J. Trump Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ti kede pe oun yoo da fifun awọn awọn orilẹede ti ko rọwọ họri ni fisa fun akoko diẹ. Amọ ko mẹnuba atupalẹ bi igbesẹ naa yoo ṣe jẹ ati awọn orilẹede ti ọrọ naa kan ni pato. Aarẹ ọhun fẹsun kan awọn eeyan ilẹ okere pe awọn lo n da omi alaafia orilẹede Amẹrika ru, o si ṣeleri pe oun yoo le ẹnikẹni to ba n ṣakoba fun eto abo orilẹede naa kuro nibẹ. Ọrọ yii lo n jẹyọ lẹyin ti wọn fẹsun kan ọmọ orilẹede Afganistan kan pe oun lo ṣekupa ọmọ ogun National Guard kan niluu Washington DC lana ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025. Trump sọ pe ikọlu naa ṣafihan ewu eto abo to n koju ilẹ Amẹrika, oun yoo si le gbogbo awọn to dunkoko mọ eto abo orilẹede naa kuro nibẹ. Lọjọru ni ijọba Amẹrika bẹgidina gbogbo awọn to n gbiyanju lati gba fisa wọ Amẹrika latari pe ijọba ilẹ naa n ṣe awọn iwadii eto abo awọn eeyan ọhun. Ninu atẹjade to fi lede loju opo X rẹ, Trump ni oun yoo da gbogbo awọn anfani ijọba ti awọn atọhunrinwa n jẹ nilẹ naa duro. Nigba ti BBC bere lọwọ ijọba Amẹrika nipa awọn orilẹede ti ọrọ naa kan, niṣe lo tọka si atẹjade kan to fi lede ninu oṣu Kẹfa ọdun yii nibi to ti mẹnuba orilẹede bii Afghanistan, Cuba, Haiti, Iran, Somalia ati Venezuela. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Awọn orilẹede mii ti ijọba Amẹrika yoo ṣayẹwo awọn to ti gba kaadi alawọ ewe rẹ ni Burma, Chad, Republic of Congo ati Libya. Trump funra rẹ tabi awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ ko darukọ tabi ṣalaye kikun nipa awọn orilẹede ti ọrọ yii yoo kan. Amọ Joseph Edlow to jẹ ọga agba ajọ to n ri si wọlewọde ilẹ Amẹrika, United States Citizenship and Immigration Services ni Trump ti paṣẹ ki awọn ṣe ọfintoto gbogbo ọmọ orilẹede ti wọn n pe ni "country of concern" ti wọn ti gba kaadi alawọ ewe lati maa gbe l'Amẹrika finifini. Fun idi eyii, awọn orilẹede wo gan ni wọn ka si orilẹede 'Countries of Concern?' Ninu oṣu kẹfa ọdun yii, Trump fofin de awọn ọmọ orilẹede mejila kan pe wọn ko gbọdọ wọ Amẹrika mọ, bẹẹ lo tun fofin de awọn orilẹede meje mii fun igba diẹ lori pe wọn jẹ orilẹede 'Countries of Concern.' Awọn orilẹede naa ni: Orilẹede mẹrinlogoji ni ajọ UN ka sabẹ awọn ti ko rọwọ họri tabi ti oṣi n ta, iyẹn "'Third World Countries?' ti mẹtalelọgbọn wọn si wa nilẹ Afrika. Awọn orilẹede naa ni Afrika ree: Awọn ti ko rọwọ họri tabi ti oṣi n ta ni Asia: Awọn ti ko rọwọ họri tabi ti oṣi n ta ni Caribbean: Awọn ti ko rọwọ họri tabi ti oṣi n ta ni Pacific:
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c74xeq3pj1lo
|
2025-11-29
|
bbc
|
Àlàyé rèé lórí báwọn olólùfẹ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Kano Pillars ṣe na 3SC ní àlùkì lẹ́yìn tí wọn gbá ọ̀mì ní Kano
|
Oríṣun àwòrán,3SC TV Gugugbẹ ja ni papa iṣere Sani Abacha to wa niluu Kano lalẹ ọjọ Aiku lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Shooting Stars (3SC) ti ilu Ibadan pada jẹ goolu mọ ẹgbẹ agbabọọlu Kano Pillars lara lasiko to ku iṣẹju diẹ ki ifẹsẹwọnṣe to n waye laarin wọn pari. Goolu ti 3SC jẹ yii lo mu ki ifẹsẹwọnsẹ ọhun pari si ami ayo kọọkan fun ikọ agbagbọọlu mejeji ni ọjọ kẹjọ idije bọọlu afẹsẹgba Naijiria, Nigerian Premier Football League (NPFL). Lẹyin ti 3Sc sọ goolu naa wọle tan ni awọn alatilẹyin Kano Pillars binu ya wọ ori papa ti wọn si bẹrẹ si n ṣe iya fun awọn alakoso ere, to fi mọ awọn agbagbọọlu 3SC. Oríṣun àwòrán,3SC TV Gbas-gbos naa le to bẹẹ ti awọn agbofinro fi yin afẹfẹ tajutaju lati tu wọn ka. Awọn aworan lati papa iṣere naa ṣafihan awọn ololufẹ Kano Pillars pẹlu igi lọwọ wọn, to fi mọ awọn ohun ija mii ti wọn si n le awọn alakoso ere kuro lori papa. Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣalaye pe pupọ ninu awọn alakoso ere ọhun ni ko ba farapa yanayana amọ ori ko wọn yọ. Akọroyin kan ti ọrọ naa ṣoju rẹ jabọ pe "rugudu nla lo ja ni papa iṣẹre naa, ni kete ti Shooting Stars sọ goolu wọ inu awọn Kano Pillars bayii, ni wahala bẹrẹ. "Wọn fo irin ti wọn fi pin papa iṣere, wọn si wọ inu papa ti awọn agbagbọọlu maa n wa, wọn si bẹrẹ si n le adari ayo naa kabakaba. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ "Niṣe lawọn ọlọpaa ni lati yin afẹfẹ tajutaju lati le wọn pada sẹyin." Wayi o, kii ṣe igba akọkọ ree ti ija yoo bẹ silẹ lasiko ifẹsẹwọnsẹ ni liigi bọọlu Naijiiria. Ninu oṣu Kẹrin ọdun yii, awọn ololufẹ 3SC yii kan naa de awọn agbabọọlu, rẹfiri atawọn akọroyin ni igbekun fun odidi wakati kan ni papa iṣẹre Lekan Salami to wa niluu Ibadan lẹyin ti 3SC gba ọmi pẹlu ikọ agbabọọlu Ikorodu City. Nigba ti wọn n salaye bi rogbodiyan naa se waye, ikọ agbabọọlu 3SC koro oju si isẹlẹ naa, eyinto sapejuwe bii iwa idaluru. Atẹjade kan ti ikọ adari 3SC fisita lori isẹlẹ naa salaye pe ohun eelo fun irẹpọ, itara ati awujọ lo yẹ ki ifẹsẹwọnsẹ ere bọọlu jẹ nitori pe ere lasan la n fi ọmọ ayo se. "Ko yẹ ki iwa ipa tabi idunkooko mọ ni maa waye lasiko ere bọọlu, a si n ke si ikọ NPFL atawọn agbofinro lati tanna wadii isẹlẹ naa. A fẹ ki wọn mu awọn eeyan to wa nidi idaluru naa, ki wọn si foju ko ata ofin, bakan naa, a fẹ ki wọn se agbekalẹ eto ifiyajẹni to gbopọn lati dena irufẹ iwa yii lọjọ iwaju. Ohun to yẹ ko se koko ni sise ipese eto aabo to gbopọn fun ẹka ere idaraya ati awọn olukopa" Ikọ 3SC wa fọwọ gbaya pe ohun to jẹ oun logun ni aisegbe ninu ere idaraya ati ibọwọ funraẹni lasiko ifigagbaga kọọkan. Wayi o, ikọ to n se akoso ifẹsẹwọnsẹ bọọlu liigi labẹle, The Nigerian Premier Football League (NPFL) ti sọrọ nipa isẹlẹ ifiyajẹni to waye nilu Kano naa. Ninu atẹjade kan ti Davidson Owumi, to jẹ adari ajọ NPFL fi lede, o bu ẹnu atẹ iṣẹlẹ naa, o si juwe rẹ gẹgẹ bii eyiii ti ko bojumu. NPFL ni awọn n reti awọn ẹri maa jẹ mi rinṣo lori ohun to ṣẹlẹ ni papa iṣere naa ati ọrọ lẹnu awọn alakoso ere. O ni "A bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe wu iwa ipa ati idunkokomọni si awọn agabọọlu, alakoso bọọlu atawọn ololufẹ bọọlu." O sọ siwaju si pe iwa yii kii ṣe irufẹ iwa to maa n waye lemọlemọ amọ awọn yoo gbe igbesẹ to tọ lori rẹ ni kete ti ọwọ awọn ba ti to gbogbo ẹri ti yẹ tan. NPFL pari atẹjade naa pe awọn ko ni sinmi ninu ojuṣe awọn lati ri pe irufẹ iwa ibajẹ bẹẹ ko waye lagbo ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria mọ. Oríṣun àwòrán,Naija metro April 27, 2012 - Gombe Lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2012, awọn ololufẹ Gombe United kọlu awọn agbabọọlu atawọn alakoso Shooting Stars lori papa, koda, wọn gun agbagbọọlu 3Sc kan lọbẹ lọdun naa lọhun. Sept 11, 2013 – Akure Lọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan an, ọdun 2013, awọn ololufẹ ẹgbẹ agbagbọọlu Sunshine Starts ti ilu Akure kọlu awọn agbabọọlu 3SC lẹyin ifẹsẹwọnsẹ kan ti esi rẹ ko tẹ Sunshine Stars lọrun. Iṣẹlẹ naa mu ki wọn fi ofin de ẹgbẹ agbagbọọlu ọhun fun akoko diẹ ki ajọ NPFL to pada yọ okun lọrun wọn. Oct 12, 2025 -Kano Igba kẹta ti awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu mii yoo kọlu 3SC ni eyii to waye ni papa iṣere Sanni Abacha to wa niluu Kano lọdun 2025 yii.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c5y4k8vngn1o
|
2025-10-13
|
bbc
|
Kókó àbájáde ìwádìí àwọn aṣòfin Amẹrika lórí ọ̀rọ̀ tí Trump sọ pé ìpanirun àwọn Kristẹ́nì ń ṣẹlẹ̀ ní Naijiria
|
Oríṣun àwòrán,Others Awọn aṣofin orilẹede Amẹrika ti fẹsun kan awọn ẹgbẹ alakatakiti ẹsin pe wọn fẹ pa ẹsin kristẹni run ni Naijiria lo jẹ ki wọn maa ṣe oriṣiiriṣii ikọlu sawọn ile ijọsin atawọn kristẹni. Awọn aṣofin naa tun fẹsun kan ijọba Naijiria wi pe o ti kuna lati pese eto aabo to peye. Ọrọ yii jade nibi ipade apapọ awọn aṣofin ti Aarẹ Donald Trump pe fun lori ọrọ ikọlu sawọn kristẹni to n ṣẹlẹ ni Naijiria. Awọn aṣofin to jẹ ọmọ igbimọ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ati ọrọ awọn ẹgbẹ agbesunmọmi bii Boko Haram, ISWAP to fi mawọn Fulani to n ṣekolu si ileto awọn kristẹni laarin gbungbun ati apa ariwa orilẹede Naijiria sọrọ nibi ipade ọhun. Brian Mast to n ri sọrọ ilẹ okeere sọ pe ko si nnkan to jọ ija ileto kan si omiran ninu nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria bayii, Mast ni awọn to n ṣe ikọlu yii mọọmọ fẹ pawọn kristẹni run lori ilẹ ati nile wọn ni. Chris Smith toun naa n dari igbimọ kan to n ri sọrọ to niṣe pẹlu Afirika sọ pe awọn janduku to n ṣe ikọlu ni Naijiria n huwa ta ni yoo mu mi pẹlu bi wọn ṣe n pawọn eeyan, ji eeyan gbe ti ẹnikankan ko si dawọn lọwọ kọ. Awọn akọṣẹmọṣẹ kan nibi apero naa sọ pe bi wọn ṣe n ji awọn eeyan gbe ati bi wọn ṣe n lo awọn ofin ẹsin kan lati ṣekupa awọn eeyan lawọn ipinlẹ ariwa Naijiria kan n ṣafihan pe Naijiria kii ṣe orilẹede ti eeyan ti le ṣe ẹsin to ba wu u mọ. Vicky Hartzler, aṣofin to jẹ alaga igbimọ Amẹrika to n ri si ominira lati ṣe ẹsin to ba wu eeyan, sọ pe ko si ominira lati ṣe ẹsin to wu eeyan mọ ni Naijiria. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Hartzler ni ijinigbe awọn akẹkọọ to le ni 300 nile ẹkọ ijọ Katoliiki kan nipinlẹ Niger jẹ ọkan lara ẹri to le fidi eyi mulẹ. Ọpọ akọṣẹmọṣẹ lori eto aabo ti sọ fun ijọba Amẹrika wi pe ko ma fi Aarẹ Bola Tinubu lọrun silẹ lori ọrọ eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria, titi ti ijọba apapọ yoo fi ṣẹgun gbogbo ẹgbẹ alakatakiti ẹsin to n ṣoṣẹ ni Naijiria. Ile aṣofin Amẹrika ti bẹrẹ iṣẹ lori abọ to fẹ fun Aarẹ Trump lori nnkan to kan fun Amẹrika lati ṣe lori oniruuru ikọlu to n waye ni Naijiria. Amẹrika ti kede wi pe ọrọ nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria n kọ awọn lominu, eyi lo si jẹ ki Aarẹ Trump dunkoko lati ko ọmogun wa Naijiria lati wa koju awọn to wa nidi ikọlu to n waye. Bo tilẹ jẹ pe awọn aṣofin Amẹrika ti pe fun atunṣe ofin Sharia lawọn ipinlẹ kan lapa ariwa Naijiria, iwe ofin Naijiria ko fun Tinubu lagbara lati dasi ọrọ naa bo ba ṣe wu u. Ipinlẹ mejila lẹkun ariwa Naijiria lo n lo ofin Sharia lati ọdun 1999, atunṣe ofin yii maa nilo ayipada iwe ofin Naijiria, aarẹ Naijiria ko si lagbara ṣe atunṣe iru ofin bayii. Aarẹ Naijiria ko laṣẹ lori awọn ile ẹjọ ipinlẹ, tori naa, ọpọ ni yoo ṣe atako si iru igbesẹ bẹẹ ti aarẹ ba le gbiyanju lati yi ofin Naijiria pada. Ijọba apapọ le gba awọn ijọba ipinlẹ ni imọran lati ṣe atunṣe ofin Sharia, amọ, ko laṣẹ lati fopin si ofin Sharia. Ṣaaju ipade awọn aṣofin Amẹrika yii lawọn aṣoju ijọba Naijiria kan ti oludamọran aarẹ lori eto aabo, Nuhu Ribadu, dari wọn ṣabẹwo si Amẹrika lati fọrọ jomitoro ọrọ pẹlu ijọba Amẹrika lori ọna lati fopin si ikọlu to n ṣẹlẹ ni Naijiria. Lasiko abẹwo naa lawọn aṣoju Naijiria sọ pe ko si ohun to jọ iṣekupani awọn kristẹni ni Naijiria gẹgẹ bii Trump ṣe sọ. Awọn aṣoju Naijiria ni awọn janduku agbebọn to n ṣọṣẹ ni Naijiria ko fi ti ẹsin kan ṣe, bi wọn ṣe n kọlu kristẹni ni wọn n kọlu musulumi naa. Lara imọran tawọn aṣofin Amẹrika fun ijọba Naijiria lori eto aabo to n buru sii ni pe ijọba Amẹrika yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu Naijiria, yoo si ṣe iranwọ nipa ṣiṣe idanilẹkọọ fawọn ọlọpaa Naijiria. Awọn aṣofin naa tun sọ pe ijọba Naijira gbọdọ tete maa gbe igbesẹ ti wọn ba ti ri ikilọ nipa ikọlu to le ṣẹlẹ. Nnkan mii ni pe ijọba Amẹrika yoo tun tẹsiwaju lati lo awọn akọṣẹmọṣẹ rẹ lati le koju awọn agbesunmọmi to n ṣoṣẹ ni Naijiria.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c8dy19r5zy7o
|
2025-12-03
|
bbc
|
Wo ipa tí bí ikọ̀ Super Eagles ṣe kọ̀ láti gbáradì fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn ọ́la, yóò ní lórí àṣèyọrí wọn
|
Oríṣun àwòrán,Sina Okeleji Awọn agbabọọlu Super Eagles ti kọ lati ṣe igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ wọn ti yoo waye pẹlu orilẹede Garbon lọla Ọjọbọ. Ifẹsẹwọnṣe naa ṣe pataki fun Super Eagles nitori o le sọ boya wọn ṣi le kopa ninu idije ife ẹye agbaye 2026 World Cup. A gbọ pe Aarẹ NFF ti balẹ si Morocco ti Super Eagles wa, o si ti ṣe ipade pẹlu awọn agbabọọlu naa, to fi mọ awọn oṣiṣẹ ikọ ọhun miran. Wayi o, kii ṣe igba akọkọ ree ti ikọ Super Eagles yoo kọ lati kopa ninu igbaradi wọn latari idi kan tabi omiran. Iwọnyii ni idi pataki ti ikọ Super Eagles fi kọ lati ṣe igbaradi fun ọkan lara awọn ifẹsẹwọnsẹ rẹ to ṣe pataki lasiko yii. Eredi ti ikọ Super Eagles ṣe kọ lati kopa ninu igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Gabon Idi pataki ti awọn agbabọọlu Super Eagle ṣe gbe igbesẹ naa ko ṣẹyin awọn ajẹmọnu kan to yẹ ki NFF ti san fun wọn amọ to kuna lati san. Iroyin ni awọn ajẹmọnun naa lo yẹ ki wọn gba fun kikopa ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ igbaradi AFCON 2025 ati 2026 World Cup. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ẹgbẹrun marundinlogun dọla lawọn agbabọọlu naa bere fun ifẹsẹwọnṣe meji to wa niwaju wọn, ti apapọ owo to yẹ ki wọn gba jẹ ẹgbẹrun lọna ọgbọn dọla amọ NFF ni ẹgbẹrun mẹwaa dọla pere loun yoo fun wọn, eyii ti ko tẹ wọn lọrun. A tilẹ gbọ pe awọn oṣiṣe NFF kan sọ pe ẹgbẹrun marun dọla pere ti to wọn, to tunbọ fẹ rogbodiyan naa loju si. Awọn agbabọọlu ọhun sọ pe awọn ko ni ṣe igbaradi kankan ayafi ti ajọ NFF ba yanju ọrọ ajẹmọnu naa. Ẹnikan to ba awọn akọroyin sọrọ amọ ti ko fẹ fi orukọ ara rẹ lede ni awọn agbabọọlu naa sọ pe ijọba Cameroon, DR Congo, ati Gabon ti fikun ajẹmọnu awọn agbabọọlu wọn ti wọn ba bori ifẹwọnsẹ, Naijiria nikan ni ko tii ṣe afikun tirẹ. Ọla Ọjọbọ lo yọ ki Super Eagles koju ẹgbẹ agbabọọlu Gabon ni papa iṣere Moulay Hassan, niluu Rabat, lorilẹede Morocco ki rogbodiyan naa to ṣuyọ. Ẹwẹ, olori awọn agbagbọọlu naa, William Troost-Ekong sọ pe afojusun awọn ni lati kopa ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ nla to wa niwaju awọn. Bo tilẹ jẹ Troost-Ekong fidi rẹ mulẹ rẹ pe aawọ wa laarin awọn agbabọọlu ọhun ati NFF. Nigba to n sọrọ loju opo X rẹ, o ni "Ti a ba ti yanju ọrọ naa ẹnu wa ni ẹ ti maa kọkọ gbọ. "Afojusun wa ko ju bi a ṣe maa kopa ninu awọn ifẹsẹwọn to ṣe pataki to wa niwau wa." 2014:Lọdun 2014, awọn agbabọọlu Super Eagles kọ lati wọ bọọsi lati lọ ṣe igbaradi wọn lasiko ife ẹyẹ agbaye, 2014 World Cup nitori ajẹmọnu ti ijọba jẹ wọn. Iṣẹlẹ naa lo waye lẹyin ifẹwọnsẹ wọn pẹlu orilẹede Argentina. 2019:Lẹyin ti wọn lulẹ ninu idije 2019 Women's World Cup awọn agbabọọlu Naijiria obinrin (Super Falcons) kọ lati fi ile itura wọn silẹ lati fẹhonuhan pe ijọba gbọdọ san ajẹmọnu wọn fun wọn. 2022:Awọn agbabọọlu obinrin (Super Falcons) kọ lati ṣe igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ ipo kẹta wọn ninu idije 2022 Women's Africa Cup of Nations (AWCON) ni Casablanca. 2025:Awọn agbabọọlu Super Egles kọ lati ṣe igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Gabon ni Rabat, Morocco, nitori awọn ajẹmọnu ti ijọba jẹ wọn lati ọdun 2019.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c2emy9lk830o
|
2025-11-12
|
bbc
|
Ọkùnrin tó jí ara rẹ̀ gbé láti gba owó lọ́wọ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ l'Ondo dèrò àtìmọ́lé
|
Oríṣun àwòrán,Ondo Police Command Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan to parọ fun awọn mọlẹbi rẹ pe wọn ji oun gbe lati gba owo lọwọ wọn. Mathew Ekele ni ọwọ tẹ niluu Ogbese to wa loju ọna marosẹ ilu Akure siluu Owo. Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, DSP Ayanlade Olayinka Olushola lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan niluu Akure. Gẹgẹ bii atẹjade ọlọpaa, agbarijọpọ akitiyan ọlọpaa, ẹgbẹ OPC atawọn ọdẹ ibilẹ lo jẹ ki aṣiri ọrọ naa tu. O ni asiko ti awọn agbofinro ọhun n ṣiṣẹ ninu igbo Kashimola/Agunla ni wọn pade ọkunrin meji kan, John Peter ati James Peter lori alupupu lati abule Igbodudu to wa lẹba Daada Ala. Ayanlade sọ pe asiko ti wọn yẹ ara awọn ọkunrin naa wo ni wọn ba owo ti iye rẹ jẹ ₦800,000 lọwọ wọn, paali siga Benson kan to fi mọ igo Aromatic Schnapps kan. Nigba ti awọn gbofinro fi ọrọ wa wọn lẹnu wo, wọn ni ajinigbe to ji aburo awọn gbe lawọn fẹ lọ gbe owo naa fun lati gba itusilẹ rẹ. Lẹyin eyii ni ọlọpaa fi ogbọn tan ẹni to fẹ wa gba owo itusilẹ naa ti wọn si ko ṣẹkẹkẹṣẹkẹ sọwọ rẹ. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ninu iwadii ọlọpaa ni akara tu sepo pe wọn ko ji Mathew gbe amọ oun funra rẹ lo da bii ọgbọn lati gba owo lọwọ awọn mọlẹbi rẹ. Lẹyinorẹyin, ọwọ ọlọpaa tẹ Matthew lẹba igbo kan niluu Ogbes nibi to n duro si lati gba owo itusilẹ ti awọn mọlẹbi rẹ fẹ san. Ninu iroyin miran, ileeṣẹ naa ti sọ pe ko si ni aaye fun ohunkohun to farajọ banga yinyin atawọn ohun amuṣere bii iru rẹ lasiko ọdun yii. Agbẹnusọ ileeṣẹ naa ni igbesẹ naa ko ṣẹyin oniruru iṣẹlẹ ijinigbe to gbode, to fi mọ eto aabo to mẹhẹ. Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa, Adebowale Lawal, tun kilọ fun awọn to n ji ara wọn gbe lọna ati gba owo lọwọ awọn mọlẹbi wọn ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ ki wọn ma ba rija ofin. O pari ọrọ rẹ pe ileeṣẹ naa ko ni la oju rẹ silẹ ki awọn ọdaran fi ipinlẹ Ondo ṣe ibuba.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cp84yxgm2ppo
|
2025-12-03
|
bbc
|
Ìkọ́ aláàbò dóòlà ọ̀dọ́bìnrin méjìlá tí ajínigbé jí gbé ní Borno
|
Oríṣun àwòrán,Nigerian Army Awọn ọmọ ologun lorilẹede Naijiria, Hadin Kai ti doola ẹmi awọn ọdọmọbinrin mejila ti ikọ Boko Haram/ISWAP ji gbe ni agbegbe Mussa, ni ijọba ibilẹ Askira/Uba nipinlẹ Borno. Eyi waye ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ologun fi lede loju opo ayelujara wọn lọgbọn ọjọ oṣu kọkanla ọdun 2025. "Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ṣe aseyọri lati doola ẹmi awọn ọdọmọbinrin mejila ti agbebọn Boko Haram/ISWAP jigbe ni agbegbe Mussa ni ijọba ibilẹ Askira/Uba nipinlẹ Borno," atẹjade naa ṣalaye. "Awọn ọdọmọbinrin yii gba ominira ni ọjọ Ṣatide, ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu kọkanla, lẹyin ti ikọ ologun HADIN KAI kọlu awọn agbebọn ni guusu ipinlẹ Borno". Ileeṣẹ ologun ni awọn ọdọmọbinrin yii ni wọn tig be wọn lọ sibi ti wọn yoo ti ni anfani si ilera to peye ati ifọrọwanilẹnuwo. Ọjọ ori awọn ọdọmọbinrin naa lo wa laarin ọmọ ọdun mẹdogun si ẹni ogun ọdun, ti wọn si ji wọn gbe ni ogunjọ oṣu kọkanla nigba ti wọn n ṣiṣẹ lori oko mọlẹbi wọn. "Lẹyin ti a ba ṣe gbogbp eyi, wọn yoo darapọ mọ awọn mọlẹbi wọn. Itusilẹ yii ti mu ọkan awọn ara agbegbe naa balẹ, eyi to ti ka soke lati igba ti awọn agbebọn ti ji awọn ọdọmọbinrin naa gbe." Gẹgẹ bii atẹjade naa ṣe ṣalaye, orukọ awọn ọdọmọbinrin naa ni Fatima Shaibu (17), Fatima Umaru (15), Hauwa Abubakar (18), Saliha Muhammed (15), Sadiya Umaru (17), Amira Babel (15), Zara Adamu (17), Nana Shaibu (15), Zainab Musa (18), Zainab Muhammed (17), Jamila Saidu (15) ati Hauwa Hamidu (17) End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Awọn olori ikọ ologun orilẹede Naijiria ti kan sara si ileeṣẹ ologun fun bi wọn ṣe mu iṣẹ lọkunkundun . This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Xcookie policyandprivacy policybefore accepting. To view this content choose 'accept and continue'. End of X post Content is not available
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cvgj5vxq83vo
|
2025-11-30
|
bbc
|
Ẹ wo bí onírúurú ẹbí ṣe ń fi okòwò tata rán àwọn ọmọ wọn nílé ẹ̀kọ́, gbọ́ bùkátà
|
Asiko kan wa t'awọn tata alawọ ewe maa n pọ gan an lapa guusu Ariwa orilẹede Cameroon, pẹlu ayọ ati idunnu lawọn eeyan ẹkun naa maa fí n foju sọna si akoko naa. Ọrọ aje gidi lo jẹ fun ọpọ eeyan níbẹ, wọn si maa n dọdẹ tata bi ẹni n dọdẹ ẹranko ninu igbo. Ilu Bambui ti ko ju kilomita mẹẹdogun lọ sí Bamenda lẹkun guusu Ariwa Cameroon ni Mama Mbani Janet n gbe. Ogbeni Joseph ọkọ Janet at'awọn ọmọ wọn l'ọkunrin l'obinrin n mura silẹ lati dọdẹ tata nírọ̀lẹ́. Mama Janet sọ pe "a maa n foju sọna si akoko yìí lọdọọdun. Oṣu ti a maa n mu saa ni oṣu ti a maa n ri tata yii mu. Eledua fi ọpọlọpọ ọmọ jinki mi. Gbogbo wọn lo si ti wa nile ẹkọ, iṣẹ ọtika ti mo n ṣe ko to wa jẹ mọ. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Amọ, mo mọ pe nnkan maa n yatọ daadaa fun wa laarin oṣu Kẹwàá ọdún si oṣu Kejìlá," Arabinrin Janet lo sọ bẹẹ. Ṣiṣe odẹ tata ti wọn maa n pe ni Mungwin ni ede Cameroon jẹ nnkan to ti di aṣa nilẹ naa, o si jẹ ọrọ aje fun ọpọ eeyan níbẹ. Wọn maa n máwọn tata yii ni irọlẹ, wọn si maa ṣe aayan rẹ. Lẹyìn naa ni won maa n ta a yala ni gbígbẹ tàbí ni tutu. Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Fún àwọn eeyan bíi Mama Janet, okowo tata yii lo maa n sọ bo ya awọn ọmọ rẹ yoo pada sile ẹkọ, tabi wọn o le san gbese ti ẹbí jẹ. Bi wọn ba se ri tata yii mu si ni yoo tun sọ bo ya ẹbi mama yoo le jẹ ounjẹ gidi lasiko ọdún Keresimesi. Lẹyìn ile mama Janet ati ọkọ rẹ Joseph ni igbaradi lati lọ soko ọdẹ tata alawọ ewe ti maa n waye. Orisiirisii ohun elo bíi paanu òrùlé ati goro ni wọn maa n lo lati mu awọn tata yii. Ọpọ ọmọbibi Cameroon ni wọn gbọju mọ awọn ọna ti wọn maa n gba lati mu tata yìí. Lati bii ọmọ ọdun mẹwàá si mẹẹdogun lawọn ọmọde ti maa n lo paanu orule ati goro lati fi mu tata. Ni igberiko bii Bambili ti mama Janet n gbe ti wọn ti ni ipenija ina mọnamọna, Joseph àti iyawo rẹ ti ra ẹrọ amunawa lati le maa fi riran lalẹ. Mama Janet sọ pé "ni gbogbo igba ni a maa n wa nibi lasiko t'awọn tata ba ti bẹrẹ sii jabọ. Emi at'awọn ọmọ mi maa n ri pe awọn tata yii ko sa mọ wa lọwọ." Àwọn tata yii maa n fo lọ sibi ina to wa ni titan sílẹ. Awọn ọmọde si maa n gbe ike lọ síbẹ lati ko wọn. Awọn to máa ń ṣọdẹ tata yii maa n ṣee titi di oru ni. Idunnu maa n ṣubu layọ fun ẹbi mama Janet lalaalẹ torí wọn mọ iye tí wọ́n maa ri nibi tata ti wọn ti mú. Lati bii ago mẹfa lawọn eeyan maa ti n de oja laarọ láti ta tata ti wọn ba mú. Owo gọbọi ni wọn maa n ta tata tutu lasiko rẹ. Ọpọ awọn alaratunta lo maa n wa lati ọna jinjin lati ra tata. "Mo maa n ta garawa tata tutu kan ni bíi 8,000 francs. Mo si maa n ta to garawa marun un lojumọ. Owo tata yii maa n ṣè'rànwọ́ fawọn ẹbi ti wọn kii ṣe oníṣẹ ìjọba. Kìí ṣe gbogbo tata ti wọn ba mu yii naa ni wọn maa n ta. Awọn ẹbi mii maa n jẹ àwọn tata ti wọn ba mu nigba mii. Nigba mii ẹwẹ, wọn maa n ṣeto tata yii ti won yoo si sa a loorun ti yoo fi gbẹ. Lẹyìn náà ni wọ́n yoo ko o pamọ lati ta to ba ya. Koda, wọn tun máa n ko tata ranṣẹ sílẹ okeere fun tita nigba mii. Olugbe ilu Bambui mii, mama Acha Mary sọ bii akoko ti wọn maa n ri tata mu ti ṣe pàtàkì tó. "Mungwin ti ran mi lọwọ láti san owo ile ẹkọ awọn ọmọ mi. Asiko yii jẹ asiko manigbagbe fun mi." Ọrọ Arabinrin Mary fi idi rẹ múlẹ síi bí okowo tata ṣe n ran ọpọ ẹbi lọwọ. Joseph ati aya rẹ, Janet naa tun jẹri si ọrọ ọhun "Okowo tata yii ni a fi n ran awọn ọmọ wa lọ ile ẹkọ." Okowo tata yii lo n ran ọpọ ẹbi ti oṣi ati iṣẹ ko ba maa ba finra lọwọ. Mama Janet ni iyanu ni okowo tata jẹ fun ẹbi oun torí ohun lawọn fi n gbọ ọpọ bukata. Bi asiko tata ọdún yii ṣe n kogba wọle diẹ diẹ, awọn ẹbi Joseph, Arabinrin Mary ati mama Janet ti bẹrẹ sii foju sọna si igba ti akoko rẹ yoo tun de lọdun to n bọ.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c3v1l1x4qw4o
|
2025-12-01
|
bbc
|
Chelsea v Arsenal: Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yìí
|
Ẹgbẹ agbabọọlu to gba ife ẹyẹ agbaye yoo ma wakọ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu to n lewaju ni ilẹ Yuroopu lọwọ yii, iyun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ati Arsenal ni deede ago marun un abọ. Arsenal ti bori ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ninu meje ti wọn ti gba ni ligi, ti Chelsea si ti bori marun ninu mẹfa. Bakan naa ni awọn mejeeji fakọyọ laarin ọsẹ nigba ti won koju Bayern Munich ati Barcelona. Ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji fidi janlẹ lọwọ Sunderland botilẹ jẹ pe Sunderland ta ọmi pẹlu Arsenal, ti wọn si bo ẹgba sidi Chelsea. Ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Sunderland ni awọn mejeeji ti padanu ami ayo laarin ifẹsẹwọnsẹ m]ẹfa ti gba gbẹyin. Chelsea ti gba ifẹsẹwọnsẹ pupọ pẹlu Arsenal (211) ju ẹgbẹ agbabọọlu miiran lọ. Ifẹsẹwọnsẹ oni yoo jẹ igba mejidinlọgọrun ti ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji ti gba bọọlu lori paapa Stamford Bridge ni gbogbo idije. Ọdun 2018 ni Chelsea na Arsenal gbẹyin ni Stamford Bridge lasiko isakoso Maurizio Sarri, ti wọn si bori pẹlu goolu mẹta si meji. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Arsenal ti padanu ifẹsẹwọnsẹ kan ninu mọkanla ti wọn ti koju Chelsea, (Wọn bori meje, ọmi mẹta). Ọdun 2021 ni eyi waye paapa iṣere Emirates Stadium, pẹlu iranlọwọ goolu lati ọwọ Romelu Lukaku ati Reece James. Ifẹsẹwọnsẹ marun un to waye ni Stamford Bridge gbẹyin Ifẹsẹwọnsẹ ti goolu ti pọju
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c78v90m8x15o
|
2025-11-30
|
bbc
|
Ọmọ Amẹrika ni mí ṣùgbọ́n nítorí olólùfẹ́ mi Aanuoluwapo ni mo ṣe lọ kọ́ èdè Yoruba - Pablo
|
Ọmọ orilẹede Amẹrika kan, Pablo ti lọ kọ ede Yoruba nitori ololufẹ rẹ kan to jẹ ọmọ Yoruba lati ipinlẹ Ondo. Ilẹ Amẹrika ni awọn mejeji ti pade ara wọn ki wọn to ṣe igbeyawo ni ọpọ ọdun sẹyin. Pablo Olusegun, bo tilẹ jẹ pe ọmọ ilẹ okeere ni, o gbọ ede Yoruba to bẹẹ to fi le fi ami sori ọrọ Yoruba. Tọkọtaya naa ti ọpọ mọ si Famili Pablanu ni wọn pade ara wọn nilẹ Amẹrika lasiko ti iyawo to jẹ ọmọ Naijiria, iyẹn Aanuoluwapo lọ silẹ Amẹrika lati kawe gboye MSc. Aanuoluwapo sọ pe "Ọrọ ifẹ wa bẹrẹ nilẹ Amẹrika. Ilẹ Amẹrika ni a ti pade. "Mo pari ile iwe giga niluu Indiana nibi ti mo ti kẹkọ gboye 'master.s' "A ṣaa pade nibi ayẹyẹ kan ṣa, bi a ṣe ri ara wa niyẹn. "Nitori titemi ni wọn ṣe lọ sile iwe lati kọ ede Yoruba. Pablo ni "Ọmọ ilu Amẹrika ni mi, ṣugbọn mo gbọ oriṣiriṣi ede.... Mi o mọ idi rẹ, ṣugbọn mo kan fẹran obinrin yii pupọ ni." Ọkunrin naa to jẹ olukọ nipa oniruru ede sọ pe oun kọ ede Yoruba, oun si mọ ede naa to bẹẹ ti oun le fi ami sori ede Yoruba. Lẹyin ọdun mẹjọ ti wọn ti gbe ara wọn niyawo ti wọn si ti bi awọn ọmọ, awọn mejeji pinnu lati kuro l'Amẹrika lati maa gbe ni Naijiria. Aanuoluwapo sọ pe lasiko ti wọn wa nilẹ Amẹrika, niṣe lo ba bii pe wọn ko ni akojọ kankan latari bi wọn ṣe n fi pupọ ninu owo ti wọn n pa wọle gbọ bukata. O ni "A wa wo o pe a ko le ni ikojọ nibi yii, bi a ṣe n ri owo naa ni o n lọ... a wa ba ẹsẹ wa sọrọ. "A ja pada ni, awọn kan n japa, awa ja pada ni." Nigba ti BBC kan sile tọkọtaya naa, a ṣakiyesi pe orukọ Yoruba ni wọn sọ awọn ọmọ wọn, gbogbo wọn si gbọ ede Yoruba. Gẹgẹ bi ẹni to fẹran ede, Pablo ni oun ti pinnu lati ilẹ lati kọ awọn ọmọ oun ni ede Italy ki iya wọn si kọ wọn ni ede Yoruba. Awọn mejeji ni eyii ko ṣẹyin eredi ti wọn ṣe fun awọn ọmọ naa ni orukọ Yoruba ti wọn si n sọ ede Yoruba si wọn ninu ile. Wo fidio oke yi fun ẹkunrẹrẹ ohun ti tọkọtaya yii ba BBC Yoruba sọ.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cx23r2l84v9o
|
2025-12-01
|
bbc
|
Ìwakùsà lọ́nà àìtọ́ ló ń ṣokùnfà ètò àbò tó mẹ́hẹ lọ́dọ̀ wa, a fẹ́ kí Ààrẹ gbẹ́sẹ̀le – Àwọn gómìnà Àríwá
|
Oríṣun àwòrán,OGA Awọn gomina ni Ariwa Naijiria ti ke si Aarẹ Bola Tinubu pe ko gbẹsẹle iwakusa lagbegbe naa fun oṣu mẹfa gbako lati le koju iṣoro eto to n ba agbegbe naa finra. Ọrọ yii lo jẹyọ nibi ipade awọn gomina mọkandinlogun agbegbe ọhun to waye niluu Kaduna. Ipade naa ti awọn ori ade agbegbe naa yọju si ni wọn ti fẹnuko pe ki wọn maa ko owo ti iye rẹ to biliọnu kan naira jọ loṣoṣu fun eto abo agbegbe naa. Gbọgan nla Sir Kashim Ibrahim House ni ipade naa ti waye labẹ asia ẹgbẹ Northern States Governors' Forum (NSGF) ati Northern Traditional Rulers' Council. Ohun ti ipade naa da lori ni eto abo agbegbe wọn to mẹhẹ ati ọna abayọ. Gomina ipinlẹ Gombe ati adari ẹgbẹ NSGF, Inuwa Yahaya, sọ pe awọn ti ṣakiyesi pe iwakusa lọna ti ko ba ofin mu lo n ro awọn agbebọn atawọn ọdaran mii lagbara lagbegbe ọhun. O wa rọ Aarẹ Bola Tinubu ko gbẹsẹle gbogbo iwe aṣẹ iwakusa lagbegbe naa fun igba diẹ. O tun kan sara si Aarẹ fun akitiyan bi wọn ṣe da awọn ọmọde ti awọn agbebọn ji gbe pada wa sọdọ awọn obi wọn. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Yahaya sọ pe awọn adari agbegbe Ariwa ti ṣetan lati rẹyin gbogbo ohun to n ṣokunfa eto abo to mẹhẹ lagbegbe awọn. Awọn gomina ati ori ade naa tun sọ pe awọn fọwọ si idasilẹ ọlọpaa agbegbe, wọn si rọ awọn aṣofin lati ṣe ohun to yẹ ni kankan fun idasilẹ ileeṣẹ agbofinro naa. Yahaya ni awọn ti fẹnuko lati fọwọsowọpọ pẹlu Aarẹ Tinubu fun alaafia agbegbe wọn. O ni biliọna kan naira ti wọn fẹ maa ko jọ loṣoṣu yoo wa fun eto abo pajawiri agbegbe maa, ijọba ipinlẹ ati ijọba ibilẹ ni yoo si lọwọ si akojọpọ owo naa. Gẹgẹ bo ṣe sọ, kii ṣe ileeṣẹ ologun nikan ni yoo yanju iṣọro eto abo to mẹhẹ, ipese iṣẹ fun awọn ọdọ atawọn ohun amayedẹrun mii yoo tun ṣeranwọ lati ri alaafia lagbegbe ọhun. Gomina ipinlẹ Kaduna, Uba Sani sọ pe bi ijọba apapọ nikan ṣe n dari ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ yii ko bojumu mọ, ko si daa fun bi nnkan ṣe ri lode oni. O wa kilọ fun awọn kọlọrọsi ẹda kan to n lo anfani eto abo to mẹhẹ fun anfani ara wọn ki wọn ki ọwọ ọmọ wọ bọ aṣọ.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c0edld8p337o
|
2025-12-02
|
bbc
|
PDP fi ìwé ẹ̀rí yíyọ kúrò nínú ẹgbẹ́ ránṣẹ́ sí Wike, Fayose àti àwọn yòókù
|
Oríṣun àwòrán,BBC/X/PDP Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti fi iwe ẹri, eyi to fọwọ osi juwe ile fun Minisita fun olu ilu Naijiria, Nyesome Wike, Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri, Ayodele Fayose ati awọn yooku ti wọn yọ kuro ninu ẹgbẹ lasiko ipade apero ẹgbẹ naa to waye niluu Ibadan nipinlẹ Oyo. Gẹgẹ bii o ṣe wa ninu atẹjade kan ti PDP fi lede loju opo ayelujara X wọn, iwe ẹri naa ni wọn fi sita lọjọ keji oṣu kọkanla ọdun 2025 niluu Abuja, nibi ti adele alaga ẹgbẹ naa, Umar Damagum ti gbe agbara fun alaga tuntun, Sẹnetọ Kabiru Turaki. Bẹẹ ba gbagbe, ẹgbẹ oṣelu PDP, lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kọkanla lasiko ipade apero, fọwọ osi juwe ile fun Wike ati awọn yooku lori ẹsun pe wọn n ditẹ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP. Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Turaki ni awọn ṣe atunyẹwo igbesẹ ti awọn gbe lasiko ipade apero lori lile awọn ọmọ ẹgbẹ kan lọ. O ni, "A mọ pe ofin orilẹede Naijiria ko faye gba ki eeyan ṣe ẹgbẹ oṣelu meji, idi ree ti a fi mu rọrun fun wọn pe ki wọn kuro ninu ẹgbẹ oṣelu wa. "Ni bayii, wọn ki n ṣe ọmọ ẹgbẹ wa mọ, ti igun olori ẹgbẹ wa, si ti fọwọ osi juwe ile fun wọn, ti a si tun pinnu pe ka fun wọn ni iwe ẹri. "Bakan naa, ti wọn ba lọ si ẹgbẹ oṣelu miiran ni Naijiria, wọn yoo ni anfani lati fi iwe ]eri wọn han pe awọn ki n ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP mọ, ti awọn ẹgbẹ oṣelu naa ko si ni ma ṣe iye meji pe boya wọn si wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP." Gẹgẹ bii o ṣe ṣalaye, awọn iwe ẹri yii ni awọn ti fi ranṣẹ si onikaluku ti ọrọ kan; Nyesom Wike, Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri, Ayodele Fayose; Sẹnetọ Samuel Anyanwu; Umaru Bature; Kamarudeen Ajibade (SAN); Abdurahman Muhammad; Sẹnetọ Mao Ohuabunwa; Austin Nwachukwu; Abraham Amah Nnanna; George Turna; ati Oloye Dan Orbih. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Turaki ni igbesẹ yii ṣe koko lati fi to awọn ọmọ Naijiria ati paapa ajọ INEC leti lori ipo ti onikaluku wa lasiko yii O ni ileeṣẹ ọlọpaa, ajọ DSS, ajọ NSCDC ati awọn ikọ agbofinro yooku ni lati mọ pe awọn eeyan ti wọn darukọ yii ko si ninu ẹgbẹ wọn mọ "A ti fun wọn ni iwe ẹri, ti a si ti fi ransẹ si wọn nibi ki ti wọn ba wa." Turaki fikun pe lọwọ yii, ẹgbẹ oṣelu PDP n ṣe gbogbo atunṣe to nilo lati pada si ipo oke tente to wa tẹlẹ, ti yoo si gba awọn ọmọ Naijiria silẹ lọwọ ijọba to n mu inira wa si ilu. Ní ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹrin ọdún 1957 ni wọ́n bí Kabiru Tanimu Turaki tó di alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin ní ilé ẹ̀kọ́ University of Jos, tó sì kẹ́kọ̀ọ́ jáde lọ́dún 198, tí wọ́n sì pè é gẹ́gẹ́ bí aṣòfin lọ́dún 1986. Ọdún 2002 ló di amòfin àgbà, tó sì di alága iléeṣẹ́ amòfin rẹ̀, KT Turaki & Co. lọ́dún kan náà. Ó ṣe mínísítà fún àkànṣe iṣẹ́ lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Goodluck Jonathan láàárín ọdún 2013 sí 2015. Bákan náà ló tún ṣe aṣojú mínísítà fọ́rọ̀ iṣẹ́, tó sì tún ṣe alága ìgbìmọ̀ tó ń pè fún àlááfíà ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà. Kó tó di alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, ó díje dupò ààrẹ lọ́dún 2018 ṣùgbọ́n tí kò rí ipò náà, tó sì ṣe alága fáwọn mínísítà tẹ́lẹ̀ rí lẹ́gbẹ́ PDP.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/ce91vjpv9k1o
|
2025-12-03
|
bbc
|
Wo àwọn àgbà agbábọ́ọ̀lù mẹ́wàá ti wọ́n ti di olósèlú
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Ohun to ba jọhun la fi n we'hun, oku ko papọ mọ iyawo, gẹgẹ bi bọọlu afẹsẹgba naa ṣe yatọ si oṣelu gedengbe. Ṣugbọn ohun to ba n wu ni naa ni i pọ ju lọla ẹni, lo fa a ti awọn ogbontarigi agbabọọlu kan ṣe pa idi ọrẹ́ da, ti wọn si di oloṣelu. Ninu iroyin yii, ẹ wa wo awọn agbabọọlu tẹlẹ ti wọn fi ọna ti wọn n tọ silẹ, ti wọn si di oloṣelu paraku . Agbabọọlu to ṣee mu yangan ni Andriy Shevchenko tẹlẹ, awọn ikọ agbabọọlu bii Chelsea, AC Milan ati Dynamo Kyiv lo ti gba bọọlu fun ri. Koda, o ti gba ami ẹyẹ to maa n wu gbogbo agbabọọlu, iyẹn Ballon d'Or. Latigba ti Shevchenko ti n gba bọọlu naa lo ti nifẹ si oṣelu ṣiṣe, niba to si di akoko kan ni awọn ọdun 1990, o ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, ni Ukraine (United). O si tun darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Ukraine Forward lẹyin to fẹyinti ni 2012, ko too di akọnimọọgba. George Weah ni ọmọ ilẹ Africa kan ṣoṣo to gba ami ẹyẹ Ballon d'Or titi di asiko yii. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ O gba bọọlu fun Chelsea, AC Milan ati AS Monaco. Idarapọ mọ oṣelu akọkọ rẹ waye ni ọdun 2005, nigba to dije fun ipo aarẹ ilẹ Liberia, ṣugbọn o padanu sọwọ Ellen Johnson Sirleaf. Nigba to di 2018, George Weah di aarẹ. Romário lasan ni ọpọ eeyan mọ ọn si, agba agbabọọlu to gba bọọlu fun SV Eindhoven, FC Barcelona, Fluminense ati Flamengo ni. Ẹẹmeji lo gba ami ẹyẹ Copa America, ni 1989 ati 1997 lo gba a. Bakan naa ni Romário si jẹ ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu to gba ife ẹyẹ agbaye FIFA ni 1994. Ni bayii, ipo sẹnetọ ni agbabọọlu tẹlẹ naa di mu lati Rio de Janeiro, ọdun 2014 lo ti n ba a bọ. Atamatase agbabọọlu tẹlẹ ni Lilian Thuram, bo ṣe le gba ọwọ aarin naa lo mọ ẹyin naa gba. Lẹyin to fẹyinti bii agbabọọlu lo di ẹni to n da si ọrọ oṣelu, ajafẹtọọ, onkọwe ati ẹlẹyinju aanu to n fi ohun to ni ran awujọ lọwọ. Ọpọ igbiyanju ni Thuram ti ṣe fun iranlọwọ ọmọniyan, bo tilẹ jẹ pe ko di ipo oṣelu kankan mu. Oríṣun àwòrán,Gettz images Awọn ikọ agbabọọlu bii Tottenham Hotspur ati Arsenal ni Sol Campbell ṣoju fun ri. Ọdun 2014 lo koro oju si owo ori kan to si ni yoo wu oun lati darapọ mọ oṣelu ninu ẹgbẹ Conservatives. O ṣe atilẹyin fun ipolongo Vote Leave ni 2016, lẹyin ti igbinyanju rẹ sipo Mayor foriṣanpọn ni 2015. Ọkan lara awọn agbabọọlu to kaju ẹ ju ni Turkey ni wọn mọ ọkunrin yii si ninu itan. Ami ayo 51 lo gba sawọn fun orilẹede rẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ 112, o si ni ami ayo to pọju fun Galatasaray (288). Ni 2011, wọn dibo yan an sile igbimọ aṣofin Turkey, bii ọmọ ẹgbẹ oṣelu Justice and Development Party to n ṣejọba. Orilẹede Mexico mọ pe eekan ni Cuauhtémoc Blanco ninu agbabọọlu wọn. O gba ami ayo mejidinlogoji sinu awọn, o si gba fila 119 fun El Tri lati 1995 titi de 2014. Agba ọjẹ ni ni Club América pẹlu. O tun gba bọọlu fun Chicago Fire ati Real Valladolid. Lẹyin ifẹyinti rẹ, Blanco dupo aarẹ Cuernavaca loṣu Kin-in-ni ọdun 2015, bii ọmọ ẹgbẹ Social Democratic Party. Ni 2018, wọn dibo yan an sipo gomina Morelos, lati ẹgbẹ Social Encounter Party. Eekan ni agbabọọlu tẹlẹ yii ni Georgia. Kakha Kaladze gba ami ẹyẹ mẹtalelọgọrin fun ikọ agbabọọlu apapọ ilu rẹ, o si fẹrẹ lo to ọdun mẹwaa ni AC Milan. 2012 lo fẹyinti bii agbabọọlu, Kaladze darapọ mọ oṣelu, o di ọmọ ẹgbẹ Georgian Dream–Democratic Georgia Party, o si di ọmọ ile igbimọ aṣofin lọdun naa. Wọn pada yan an sipo Igbakeji Olootu ijọba, ati minisita eto agbara. 2017 ni wọn yan Kaladze sipo Mayor ilu Tbilisi, o si ṣe bẹẹ di olori . Ọkan lara awọn onibọọlu ti a baa maa pe ni agba -baller ni Pele ti orilẹede Brazil. Lara awọn to fi iṣẹ bọọlu ṣe rere laye ni sentunri ogun ni. Lẹyin ti Pele fẹyinti, o di minisita eto ere idaraya ni Brazil. Lati bu ọla fun un, wọn da ofin "Pelé law" silẹ ti yoo maa gbogun ti ajẹbanu lẹka ere idaraya. Manigbagbe agbabọọlu ni Zico jẹ fun Brazil ninu itan, o mọ ere naa ṣe ni tootọ. Ami ayo 48 lo gba sawọn fun Selecao, eyi to fi ba wọn ṣe lati ọdun 1976 de 1986. Zico tun pada sidi ere bọọlu lẹyin saa akọkọ rẹ ninu oṣẹlu. Akọkọ bii adari Kashima Antlers, ati Flamengo ko too kuro nibẹ latari aawọ awọn aarin igbimọ. Zico gbiyanju lati di aarẹ FIFA ni 2015. O pada darapọ mọ igbimọ Kashima Antlers ni 2018.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/clyk11k72y7o
|
2025-10-31
|
bbc
|
Àlàyé lórí bí ọ̀kan nínú Naijiria, Cameroon, DR Congo àti Gabon láti Afirika yóò ṣe yege fún play-off ẹlẹ́kùn-jẹkùn àgbáyé ti 2026 World Cup
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Ẹgbẹ agbabọọlu kan ninu awọn mẹrin ti yoo koju ara wọn lọsẹ yii ni yoo lanfaani lati pegede fun ipele to kẹyin lati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye 2026 World Cup. Lẹyin ti wọn kuna lati pedege fun idije 2026 World Cup lati ilẹ Afririka, Cameroon, DR Congo, Gabon ati Naijiria yoo maa waako lorilẹede Mococco lati Ọjọbọ ọsẹ yii lati mọ ikọ agbabọọlu kan ti yoo lọ ṣoju Afirika ninu idije ati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye ọdun to n bọ. Ikọ agbabọọlu to ba pegede laarin awọn mẹrẹẹrin yoo tun koju ikọ agbabọọlu kan tabi meji si i lati pegede fun idije 2026 World Cup. BBC ṣalaye bi ikọ agbabọọlu ti yoo lọ ṣoju Afirika ninu ifẹsẹwọnsẹ ẹlẹkun jẹkun kaakiri agbaye nibi ti ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo pegede fun 2026 World Cup yoo ti jade sita. Awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹrẹẹrin yii, Cameroon, DR Congo, Gabon ati Naijiria, pegede fun idije play-off lẹyin ti gbogbo wọn ṣe ipo keji ni isọri onikalaku wọn. Ajọ FIFA ati CAF ko abajade ifẹsẹwọnsẹ pẹlu awọn ikọ agbabọọlu to ṣe ipo kẹfa ni isọri mẹjọ ti wọn pin awọn ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Afirika si, nitori Eritrea yọwọ kuro ninu ninu idije ati pegede fun idije ere bọọlu agbaye ọdun 2026 nigba to ku ọjọ kan ki idije naa bẹrẹ. Gabon lo ṣe daadaa julọ, lẹyin naa ni DR Congo ati Cameroon. Ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles Naijiria gan an rapala wọ ipele play-off ni lẹyin ti wọn lu Benin pẹlu ami ayo mẹrim sodo. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ipo awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹrin lori atẹ iwọn FIFA ni wọn lo lati ṣe agbekalẹ ifẹsẹwọnsẹ play-off Afirika yii. Awọn ikọ agbabọọlu meji ti wọn gbewọn daadaa yoo koju meji ti ko gbewọn to wọn lori atẹ iwọn FIFA. Ipo 41 ni Naijiria wa lori atẹ iwọn FIFA nigba ti Gabon ti wọn yoo koju lỌjọbọ wa nipo 77. Cameroon wa nipo 54 nigba ti DR Congo ti wọn yoo jọ waako wa nipo 60. Awọn meji to ba bori ninu ifẹsẹwọnsẹ mejeeji yii yoo koju ara wọn lọjọ Aiku ọsẹ to n bọ. Niluu Rabat lorilẹede Morocco ni ifẹsẹwọnsẹ mẹtẹẹta naa yoo ti waye. Oríṣun àwòrán,Getty Images Ikọ agbabọọlu to ba gba ipo kinni ninu idije play-off Afirika ni yoo lọ kopa ninu idije ati pegede fun idije 2026 World Cup ẹlẹni mẹfa eyi ti yoo waye loṣu Kẹta ọdun to n bọ. Meji ninu ikọ agbabọọlu mẹfa yii ni yoo pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye 2026 World Cup. Ẹgbẹ agbabọọlu meji ni yoo wa lati ajọ Concacaf, ọkan ni yoo wa lati ẹkun Aṣia, ọkan lati Oceania ati ọkan lati South America. Isọri meji ni wọn yoo pin awọn ikọ agbabọọlu mẹfa si i. Ọjọ karun un ọjọ Ẹti oṣu Kejila ọdun yii ni FIFA yoo pin ikọ agbabọọlu 48 si isọri mejila. Ikọ agbabọọlu 42 ni FIFA yoo le pin lọjọ karun un oṣu Kejila naa, Ẹgbẹ agbabọọlu meji lati idije play-off ẹlẹkun-jẹkun kaakiri agbaye ati ikọ agbabọọlu mẹrin ti yoo pegede lati idije play-off ilẹ Yuroopu ni FIFA ko ni tii le pin loṣu Kejila to n bọ yii. Nitori naa, ikọ agbabọọlu to ba bori ninu idije play-off Afirika le mọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti wọn yoo koju ninu idije ife ẹyẹ agbaye 2026 World Cup. Oríṣun àwòrán,Getty Images Ikọ agbabọọlu Super Eagles Naijiria lo gbewọn julọ lori atẹ iwọn FIFA laarin ẹgbẹ agbẹgbọọlu mẹrin ti yoo kopa ninu idije play-off Afirika. Amọ, ami ayo mẹrin pere ni Super Eagles rigba ninu mẹẹdogun ninu ifẹsẹwọnsẹ marun un to ti yẹ ki wọn ri ami ayo mẹẹdogun gba. Cameroon ni ẹgbẹ ẹgbẹ agbabọọlu mii to gbọrọgẹjigẹ ṣugbọn awọn naa ko fakọyọ ninu awọn idije ati pegede fun idije 2026 World Cup ti wọn gba. Ami ayo mẹri ọtọọtọ ni Cape Verde fi ṣaaju wọn gba ipo kinni ni isọri D. Nitori naa, o ṣoro lati sọ ikọ agbabọọlu ti yoo bori idije play-off Afirika ọsẹ yii ni Morocco. Oríṣun àwòrán,Getty Images Ọdun 1974 ni DR Congo ti kopa ninu idije World Cup kẹyin. Zaire ni orukọ ti orilẹede ọhun n jẹ nigba naa. DR Congo lo ṣe ipo keji ni isọri B lẹyin Senegal to ṣe ipo kinni ni isọri naa. Ẹwẹ, ẹlẹsẹ ayo DR Congo, Yoane Wissa, ko ni kopa ninu idije play-off yii tori o fi ẹsẹ ṣeṣe. Gabon ni wọn fẹ kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye fun igba akọkọ. Ami ayo kan ṣoṣo ni Ivory Coast to ṣe ipo kinni ni isọri F fi ṣiwaju wọn. Denis Bouanga ati Pierre-Emerick Aubameyang ni awọn ẹlẹsẹ ayo meji to le fakọyọ fun Gabon ninu idije play-off yii.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c4g38v5g53do
|
2025-11-12
|
bbc
|
Ẹ̀rín àríntàkìtì bí Màmá Deola ṣe kópa lórí ètò Só o Láyà
|
Yoruba dun, o si larinrin fun ẹni to ba gbọ ọ, to si tun mọ ọ. Bi BBC News Yoruba se gba gbajumọ alawada lori ayelujara kan, Folagbade Banks, ti ọpọ eeyan mọ si Mama Deola ni alejo. O tun ba wa kopa lori eto wa ti a ti n se idanwo fawọn alejo wa ni BBC News Yoruba lati mọ bi wọn se dantọ si lori eto Yoruba. Eto naa ni a n pe ni Soo Laya. Mama Deola se bẹẹ, to si sọ eto naa di ti awada patapata. Ẹ darapọ mọ wa lati rẹrin arintakiti lori eto So o Laya ti oni. Oríṣun àwòrán,Abiri Tobi Festus/ Instagram Abiri Tobi Festus ni orukọ abisọ Mama Deola to si tun n jẹ Folagbade Banks lori ayelujara. Ọkunrin ni amọ o maa n mura, sọrọ bii obinrin lasiko to ba n se bii Mama Deola, to si n dẹrin pa Osonu. Mama Deola yatọ si awọn alawada ori ayelujara yoku nitori akọ to n se bi abo ni, yoo wọ asọ obinrin, we gele, wọ bata. Mama Deola tun maa n so okun nla kan mọ inu, ti yoo si maa sọrọ bi awọn abilekọ se maa n se ninu ile. Nigba to n salaye idi to se n mura bẹẹ, mama Deola ni oun n se bii ọpọlọpọ mama se maa n huwa ninu ile ni, si awọn ọmọ ati ara adugbo. Yatọ si pe Mama Deola jẹ adẹrinposonu, o tun maa n se isẹ adari eto lagbo ariya, bakan naa lo tun jẹ gbajumọ osere. Oríṣun àwòrán,Abiri Tobi Festus/ Instagram
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cy4xm2g920yo
|
2025-11-29
|
bbc
|
Ìjọba kéde fífi òfin de lílo ojú òpó ayélujára fáwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn wà lábẹ́ ọdún mẹ́rìndínlógún, ìdí rèé
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Láti ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kejìlá, àwọn iléeṣẹ́ ojú òpó ayélujára ni orílẹ̀ èdè Australia yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn wà lábẹ́ orí ọdún mẹ́rìndínlógún kò ní ní àǹfàní láti ṣí ìkànnì láwọn ojú òpó náà mọ́. Bákan náà ni wọ́n máa gbégi wọ́gilé àwọn ojú òpó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ti ṣí tẹ́lẹ̀ ṣáájú àkókó yìí. Ìjọba Australia ní ìgbésẹ̀ fífi òfin de àwọn ojú òpó yìí, èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn obí faramọ́, jẹ́ ojúnà láti mú àdínkù bá ìpèníjà táwọn ọmọdé ń kojú lójú òpó ayélujára Wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ohun tí àwọn ọmọdé ń rí lórí ayélujára ló le ṣàkóbá fún ìlera àti ìgbáyégbádùn wọn. Ìwádìí kan tí iléeṣẹ́ ìjọba kan ní orílẹ̀ èdè náà ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ṣàfihàn rẹ̀ pé ìdá mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ùn (96%) àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀dógún ni wọ́n ti ń lo social media tí wọ́n sì ń ṣe alábàápàdé àwọn nǹkan tí kò dára tó lójú òpó náà. Lára àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe alábàápàdé lórí ayélujára ni ìwà ìfìyàjẹni, àwọn ìlànà jíjẹun tí kò dára àti ìwà pípa ara ẹni. Greg Attwells, adarí ikọ̀ ìpolongo 36 Months, àjọ tó ń pè fún fífi ọjọ́ orí tí ọmọdé le ṣí ojú òpó ayélujára sí ọdún mẹ́rìndínlógún sọ fún BBC pé ìgbésẹ̀ náà yóò jẹ́ kí àwọn ọmọdé mọ ohun tí wọ́n ń fẹ́ fúnra wọn kí wọ́n tó máa lo ojú òpó ayélujára. Ìjọba Australia ní àwọn ojú òpó tí òfin náà kan ni Facebook, Instagram, Snapchat, Threads, TikTok, X, YouTube, Reddit àti Kick. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Bákan náà ni ìjọba tún ń kojú ìpè pé kí wọ́n fòfin de àwọn ojú òpó tí wọ́n ti máa ń ṣe eré pàápàá Roblox àti Discord. Ìjọba ní àwọn yóò máa ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn iléeṣẹ́ tí òfin náà dè yẹ̀wò, tí àwọn yóò sì ohun mẹ́ta tó ṣe pàtàkì láti fi ṣe àgbéyẹ̀wò wọn. YouTube Kids, Google Classroom àti WhatsApp kò fara gbá nínú òfin yìí, tí àwọn yóò sì máa ṣiṣẹ́ lọ. Bákan náà láwọn ọmọd;e yóò máa ní àǹfàní láti máa lo YouTube lọ nítorí òun kò nílò ìlànà fífi orúkọ sílẹ̀. Àwọn òbí àtàwọn ọmọdé kò ní fara gbá tí wọ́n bá ṣẹ̀ sófin yìí. Àwọn iléeṣẹ́ tó ní àwọn ojú òpó yìí ni wọ́n gbọdọ̀ ri pé ó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Iléeṣẹ́ tó bá ṣẹ̀ sófin yìí máa san owó ìtanràn £49.5mílíọ̀nù (US$32 million, €25 million). Ìjọba gbàgbọ́ pé àwọn iléeṣẹ́ ló gbọdọ̀ gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn ọmọdé kò ní àǹfàní láti ṣí ojú òpó wọn. Onírúurú ìlànà ni wọ́n ti là kalẹ̀ láti ri pé òfin náà fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó fi mọ́ lílo àwọn ìwé ẹ̀rí nígbà tí wọ́n bá fẹ́ forúkọ sílẹ̀ lórí ayélujára. Meta, tó ni ojú òpó Facebook, Instagram àti Threads sọ pé láti ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kejìlá ni àwọn máa bẹ̀rẹ̀ sí ní ti ojú òpó tó jẹ́ àwọn ọmọdé tó wà lórí ìkànnì náà. Wọ́n ní ẹni tí àwọn bá ṣe àṣìṣe láti fi ti ojú òpó máa nílò láti ṣe fídíò láti fi hàn pé òun kìí ṣe ọmọdé. Àwọn iléeṣẹ́ míì kò ì tíì sọ bí wọ́n ṣe fẹ́ ṣe àmúṣẹ ti wọn. Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion A ò lè sọ bóyá ìgbésẹ̀ náà máa so èso rere nítorí kò ì tíì sí ìlànà kan gbòógì táwọn iléeṣẹ́ náà fẹ́ lò nítorí àwọn kan ń bẹ̀rù pé lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ láti fi mọ ọjọ́ orí èèyàn le ṣe àṣìṣe nígbà míì. Àbọ̀ ìwádìí ìjoba Australia ní lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ láti fi wo ojú ẹni tó bá fẹ́ ṣí ojú òpó ayélujára kò kájú òṣùwọ́n tó láti fi ṣàwárí àwọn ọmọdé. Bákan náà ni àwọn èèyàn kan sọ pé owó ìtanràn tí ìjọba ní àwọn iléeṣẹ́ tó bá rúfin yóò máa san kéré. Stephen Scheeler, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ tẹ́lẹ̀ rí ní Facebook sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn Australia Associated Press pé Meta ń pa owó tó $50m láàárín wákàtí méjì. Àwọn lámèyítọ́ míì wòye pé fífi òfin de àwọn iléeṣẹ́ yìí kò ní mú àdínkù bá ewu táwọn ọmọdé ń kojú lórí ayélujára nítorí òfin náà kò kan àwọn ojú òpó tó wà fún fífẹ́ ara ẹni àtàwọn tí wọ́n ti máa ń ta géèmù. Bákan náà ni wọ́n ní kò kan AI, èyí tí wọ́n ló ń kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè pa ara wọn àti tí wọ́n ń lò láti fi máa sọ̀rọ̀ ìbáraẹnilòpọ̀. Àwọn mìíràn wòye pé ó sàn láti kọ́ àwọn ọmọdé bí wọ́n ṣe lè máa lo àwọn ojú òpó yìí dípò fífi òfin dè é pátápátá. Mínísítà fọ̀rọ̀ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ní Australia, Annika Wells sọ pé ìgbésẹ̀ náà le jẹ́ èyí tí kò dára jù ṣùgbọ́n tó máa ní ipa rere. Àwọn iléeṣẹ́ tó ni social media kò faramọ́ ìgbésẹ̀ yìí nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ kéde rẹ̀ nínú oṣù Kọkànlá, ọdún 2024. Wọ́n ní ó máa ṣòro láti ṣe àmúṣẹ rẹ̀ àti pé àwọn ọmọdé le wá ọ̀nà láti lùgbàdì òfin náà. Wọ́n ní ó máa mú kí àwọn ọmọdé máa ṣe àwọn ohun tí kò tọ́ lórí ayélujára, tí kò sì ní fún wọn ní àǹfàní láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ wọn. Google, tó ni iléeṣẹ́ YouTube ní àwọn ṣì ń gbèrò láti pe ẹjọ́ lórí bí wọ́n ṣe ka àwọn pọ̀ mọ́ àwọn iléeṣẹ́ náà. Wọn kọ̀ láti fún BBC lésì sáwọn ìbéèrè. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Meta ní àwọn máa ṣe àmúṣẹ òfin náà, wọ́n ní ìgbésẹ̀ náà kò tọ̀nà tó. TikTok àti Snap náà sọ pé àwọn máa ṣe àmúṣẹ rẹ̀ bí í tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn náà kò faramọ. Àwọn ọmọdé tó bá BBC sọ̀rọ̀ sọ pé àwọn máa ṣí ojú òpó ayélujára míì pẹ̀lú píparọ́ ọjọ́ orí wọn kó tó di pé òfin náà máa fẹsẹ̀ múlẹ̀. Àmọ́ ìjọba ní àwọn nírètí pé àwọn iléeṣẹ́ tó ní àwọn ojú òpó náà máa mọ èyí tí wọ́n sì máa wọ́gile. Lórí ayélujára, àwọn ọmọdé ń fún ara wọn lámọ̀rà lórí ojú òpó míì tí wọ́n ti lè máa kàn síra àti èyí tó máa ṣe ìrànwọ́ fún wọn lórí òfin náà. Àwọn ọmọdé míì ti ń darapọ̀ mọ́ ojú òpó àwọn òbí wọn. Ṣùgbọ́n Atwell sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọdé ń wá ọ̀nà láti yẹ̀ kúrò lórí òfin yìí, ohun tó dájú ni pé òfin náà ti wà nílẹ̀. "A ní òfin láti dá ààbò bo wọn."
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/ceq1glxd3eeo
|
2025-12-03
|
bbc
|
Wo bí ọmọtuntun jòjòló ṣe le gbé ọlẹ̀ míì sínú látinú ìyá rẹ̀, tí ikùn rẹ̀ yóò sì ga bíi olóyún
|
Airin jina lai ri abuke ọkẹrẹ, bí èèyàn bá rìn jìnnà, yóò rí ibi tí wọn ti ń fi odó ìbúlẹ̀ jẹun. N jẹ o mọ pe o seese kí ọmọdé jòjòló gbe oyún sínú láti inú ìyá rẹ? 'Foetus in Fetu' tàbí 'foetus carrying foetus' ni àwọn oloyinbo ń pè irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí èyí tó túmọ̀ sí pé ọlẹ ń gbé inú oyún. BBC News Yoruba wa se iwadii ohun to n fa ki oyun kan maa gbe ọlẹ miran sinu, ipa rẹ lori ọmọ tuntun ati ohun ti obi le se ti irufẹ isẹlẹ yii ba waye. Irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò wọpọ, sugbon o máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọlẹ̀ méjì ba wa ninu alaboyun bíi Ibeji. Bi ọkàn nínú ọlẹ méjèèjì náà kò bá dàgbà bo ṣe yẹ gẹ́gẹ́ bíi ìkejì rẹ, to si ni àléébù, ó seese kí ọlẹ̀ kejì to ń dàgbà dáadáa gbé ọlẹ̀ tó ní àleebu mì Ọlẹ̀ tó ní aleebu náà yóò sì máa dàgbà nínú ìkejì rẹ lásìkò tí wọn wá nínú ilé ọmọ iya wọn. Àmọ́ ọlẹ̀ yìí tún seese kò máa dàgbà nínú ìkejì rẹ bíi oyún, tí àwọn aabọ ẹ̀yà ara rẹ bíi agbari tàbí ẹyin yóò sì máa dàgbà, ọmọ kékeré yóò sì dabi ẹni pé ó gbé oyún sínú. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn dókítà máa n tètè ṣàwárí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò tó di pé oyún inú ọmọdé náà yóò ga fún ayé rí, tí wọn yóò sì ṣe iṣẹ́ abẹ fún un láti yọ ọlẹ̀ abaadi to ń dàgbà nínú ọmọ tuntun náà kúrò. Tóò, tí ó bá lóyún tàbí ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, jọ̀ọ́ ṣe àkíyèsí ara rẹ tàbí ọmọ tuntun tí ó bá bí aibaamọ ọmọ tuntun náà lè tí gbé ọlẹ̀ sínú: kí ó sì gbé igbesẹ̀ tó yẹ nípa lílọ sì ilé ìwòsàn tó kúnjú iwon fún itoju lasiko.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cqjgzlrp7v2o
|
2025-11-26
|
bbc
|
Àwọn agbábọ́ọ̀lù Afrika tó ṣeé ṣe kí wọ́n fakọyọ nínú ìdíje Premier League ti sáà yìí
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Idije Premier League ti saa 2025/2026 gberasọ lonii lẹyin ti saa bọọlu 2024/2025 pari loṣu Karun un to kọja. Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool to gbafe ẹyẹ saa to lọ ni yoo ṣide saa Premier League 2025/2026 tuntun yii nigba ti wọn yoo maa koju Bournemouth lalẹ oni ọjọ Ẹti ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ ni papa iṣere Anfield. Bi saa Premier League tuntun ti bẹrẹ, awọn agbabọọlu ilẹ Afirika kan ṣẹṣẹ darapọ mawọn ikọ agbabọọlu kan ni idije liigi EPL. BBC ṣe akojọpọ awọn agbabọọlu kan lati Afirika ti wọn ṣẹṣẹ darapọ mọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu Premier League ti o ṣee ṣe ki wọn fakọyọ ni saa bọọlu tuntun yii. Ẹlẹsẹ ayo Cameroon, Bryan Mbeumo, darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United lati ikọ agbabọọlu Brentford fun£65. Goolu mẹẹdọgbọn ni Mbeumo gba sawọn ninu liigi EPL fun Brentford ni saa bọọlu to kọja. Oju wa lara Mbeumo bayii lati fakọyọ fun ẹgbẹ agbabọọlu Man United lẹyin ti wọn fi owo gọbọi ra a lati Brentford. Mbeumo nikan kọ loju wa lara rẹ, ọrọ naa tun kan Matheus Cunha ati Benjamin Sesko tawọn naa jẹ ẹlẹsẹ ayo bakan naa. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Gbogbo eeyan lo mọ pe Mbeumo maa n tẹ pian, o si maa n gba ayo Chess. Ni bayii, o gbọdọ le fi bọọlu tẹ duuru bayii lori papa fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United. Oríṣun àwòrán,Getty Images Agbabọọlu mii to ṣee ṣe ko ṣana ni idije Premier League ti saa yii ni Mohammed Kudus to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham lati West Ham fun owo to to£55m. Kudus, agbabọọlu orilẹede Ghana fakọyọ lasiko to wa ni ikọ agbabọọlu West Ham ko to fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ lọ darapọ mọ Tottenham. Anfaani ati gba bọọlu ni idije UEFA Champions League wa lara nnkan to mu ki Kudus lọ si Tottenham. Kudus ni iṣẹ ribi ribi ti akọnimọọgba Tottenham tuntun, Thomas Frank, ṣe ni Brentford to ti wa foun ni igboya pe oun yoo fakọyọ lasiko rẹ ni Tottenham. Ni bayii ti balogun ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham, Son Heung-Min ti lọ ti James Maddison naa si ṣeeṣe, Kudus niṣẹ to pọ lati ṣe. Oríṣun àwòrán,Getty Images Agbabọọlu Algeria, Rayan Ait-Nouri ti bẹrẹ si ni gbabọọlu daadaa fun Manchester City lẹyin ti wọn ra a fun£31mlati Wolves. Ifẹsẹwọnsẹ mẹta ọtọtọ ni Ait-Nouri gba fun ikọ agbabọọlu Man City ninu idije FIFA Club World Cup to waye ni Amẹrika. Goolu mẹrin ni Ait-Nouri gba sawọn fun ẹgbẹ agbabọọlu Wolves ni saa bọọlu to kọja nigba to wa nibẹ. Lẹyin to ti n mọ bii Man City ṣe n gbabọọlu bayii, akọnimọọgba Pep Guardiola yoo maa wo o bi Ait-Nouri yoo ṣe ko ipa pataki ni saa bọọlu yii. Oríṣun àwòrán,Getty Images Ẹgbẹ agbabọọlu Sunderland pada si idije Premier League fun igba akọkọ lati ọdun 2017. Agbabọọlu mọkanla si ni wọn ti ra bayii ṣaaju saa bọọlu tuntu yii. Mẹfa ninu awọn agbabọọlu mọkanla yii lo wa lati ilẹ Afirika. Agbabọọlu Senegal, Habib Diarra, Arthur Masuaku lati DR Congo ati Noah Sadiki, adilemu agbabọọlu Mozambique, Reinildo ati Chemsdine Talbi agbabọọlu Morocco ni agbabọọlu marun un ti kọkọ ra. Lẹyin naa ni raSimon Adingra, agbabọọlu Ivory Coast to gba ife ẹyẹ AFCON pẹlu Ivory Coast. Ireti wa pe Adingra yoo lo iriri rẹ ni Premier League lati ran Sunderland lọwọ. Oríṣun àwòrán,Getty Images Agbabọọlu Senegal ati Chelsea, Nicolas Jackson, wa lara awọn agbabọọlu to fakọyọ ni saa bọọlu to kọja ni Chelsea. Bo tilẹ jẹ pe, ọpọ ololufẹ Chelsea lo maa kọminu lori Jackson wi pe kii ṣaba ṣana daadaa lori papa, o si wa lara awọn agbabọọlu lo gba goolu sawọn daadaa fun Chelsea ni bọọlu to kọja. Lẹyin ti Chelsea ti ra awọn agbabọọlu ẹlẹsẹ ayo tuntun ni ọpọ eeyan ti n sọ pe Jackson ni lati gaaya fun Chelsea. Iroyin kan tiẹ gbe e pe ẹgbẹ agbabọọlu AC Milan ati Man United fẹ ra Jackson, amọ, owo ti ko din ni £100m ni a gbọ pe Chelsea gbe le e lori. Amọ, o yẹ ki Jackson le jẹrii ara rẹ ni saa yii ni ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c15lpe11qwwo
|
2025-08-16
|
bbc
|
Razak Omotoyossi, akọni ọmọ Yorùbá tó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù fún ilẹ̀ Benin àti ọkọ òṣèré tíátà, kú lẹ́ni ọdún 39
|
Oríṣun àwòrán,Bose Alao Ọmọ Naijiria to n gba bọọlu fun orilẹede Benin, Razak Omotoyossi, ti jade laye. Oun ni ọkọ gbajumọ oṣere titata Yoruba, Bose Alao, nigba kan ri. Ẹgbẹ agbabọọlu to n gba bọọlu fun tẹlẹ nilẹ Sweden, Helsingborgs IF, lo fidi iroyin iku rẹ mulẹ. Ninu atẹjada kan loju opo X rẹ, ikọ agbababọọlu naa ni ""Helsingborgs IF n ṣọfọ. "Wọn ti fi to wa leti pe agbabọọlu wa atijoọ, Razak Omotoyossi ti papoda lẹni ọdun mọkandinlogoji." Liigi bọọlu Naijiria ni Omotoyossi ti bẹrẹ gbọọlu gbọọlu gbigba ko to pa orilẹede rẹ da si ti Benin lati maa gba bọọlu fun wọn, to si di ilumọọka nibẹ. Ninu igba marunlelaadọta to gba bọọlu fun Benin, igba mọkanlelogun lo sọ bọọlu sinu awọn, eyii to mu ko di ọkan lara awọn agbabọọlu to sọ bọọlu sinu awọn julọ fun orilẹede naa. Irawọ rẹ tan kalẹ lẹyin igbiyanju rẹ ninu awọn ifẹwọnsẹ igbaradi fun idije Africa Cup of Nations ti ọdun 2008 nibi to ti sọ bọọlu mẹrin sinu awọn orilẹede Togo. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ O tun wọ inu itan gẹgẹ bii agbabọọlu akọkọ to sọ bọọlu sinu awọn ninu idije Africa Cup of Nations. Oloogbe naa ti gba bọọlu ni Afrika, ilẹ Europe ati Middle East. Lara awọn orilẹede to ti gba bọolu ri ni South Africa, Libya, Egypt, Syria, Moldova, Sweden, ati France. A ko tii le sọ ohun to ṣokunfa iku oloogbe naa lasiko ti a n ko iroyin yii jọ. Ọpọ awọn ololufẹ gbajumọ oṣere tiata, Bose Alao lo ti bẹrẹ si n ba a kẹdun ologbe naa bayii. Bo tilẹ jẹ pe oun funra rẹ ko tii sọ nnkankan nipa oloogbe naa lẹyin iku rẹ, ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo ti bẹrẹ si n fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si. Ti ẹ ko ba gbagbe, Alao lo ṣe alaga iduro nibi ayẹyẹ igbeyawo Priscilla Ojo ati ọkọ rẹ, Juma Jux to milẹ titi lọdun yii. Ṣaaju iku oloogbe ọhun ni Alao ti kọkọ kede pe igbeyawo oun ati Omotoyossi ti wa sopin lẹyin ọdun mẹwaa ti wọn ti wa papọ. Iyalẹnu ni iroyin naa jẹ fun ọpọ awọn ololufẹ rẹ nigba ti wọn gbọ pe igbeyawo ọhun ti fori ṣanpọn. Idi ni pe ikede ituka naa ko jinna si asiko to ṣajọyọ ọdun mẹwaa awọn mejeji papọ gẹgẹ bii tọkọ-taya. Ọjọ kẹjọ osu Kẹwa ọdun 1985 ni wọn bi Razak Omotoyossi, to si jẹ akọsẹmọsẹ agbaabọọlu ati atamatase lori papa. Ilu Eko ni wọn bi si, to si bẹrẹ ere bọọlu naa nilẹ Naijiria. Saaju lo ti gba bọọlu fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu nilẹ Naijiria, Egypt, Sweden, Saudi Arabia ati France. Ijọba Naijiria fofin de Razak lati mase kopa ninu ere bọọlu fun ọdun marun eyi to fẹ se akoba fun isẹ to yan laayo naa. Ẹsun ti wọn fi kan ni pe o yaju si obinrin adari ayo kan lasiko idije Premier League laarin Sunshine Stars ati Eyimba. Eyi si lo mu ko morile orilẹede Benin lati lọ maa gba bọọlu nibẹ, to si di ọmọ orilẹede Benin laarin ọdun kan. Razak soju orilẹede Benin lasiko ifẹsẹwọnsẹ laarin ilẹ Naijiria ati Benin bi o tilẹ jẹ pe ọmọ orilẹede Naijiria ni.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cger8wp4zqyo
|
2025-08-20
|
bbc
|
Àlàyé rèé lórí ohun tó mú ọmọ ọdún mẹ́fà borí nínú ìdíje Scrabble
|
Yoruba ni ọmọ ti yoo ba jẹ Àṣàmú, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu ṣamuṣamu. Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu ọdọmọde kan, Yusuff Abdulsalam, tii se ọmọ ọdun mẹfa, to bori idije Scrabble jake jado ilẹ wa. Nigba ti BBC News Yoruba kan si Yusuff ati awọn obi rẹ, a gbọ pe ọmọ ọdun mẹta pere ni ọmọ naa ti bẹrẹ si kopa ninu ere ayo scrambble. Amọ, ọmọ ti Ẹkun ba bi, Ẹkun ni yoo jọ ni ọrọ Yusuff, tori baba rẹ naa jẹ gbajumọ elere idaraya Scrabble nipinlẹ Kwara. Yusuff Abdulsalam sọ fun BBC News Yoruba pe ẹru kọkọ ba oun nipa idije naa amọ oun pada bori. Olukọ rẹ ni awọn to ju Yusuff lọ wa nibi igbaradi fun awọn oludije ti yoo soju ipinlẹ Kwara nibi idije National Youths Game fun awọn ọdọ awọn ọmọ ọdun mẹfa naa lo fakọyọ julọ. "Tori pe o fakọyọ ninu igbaradi naa lo mu ki wọn mu ko lọ soju ipinlẹ Kwara." Bakan naa ni iya Yusuff ni ọmọ ọdun mẹta pere ni ọmọ naa ti n kọ nipa ayo Scrabble, to si nifẹ si ayo naa. "Nigba ti mo gba iwe pe ọmọ mi yoo lọ kopa ninu idije National Youth Game ni Asaba, ẹnu ya mi pupọ." Bakan naa, ijọba Kwara ni kayeefi lo jẹ pe Yusuff fakọyọ ninu idije naa ni Asaba. Amọ wọn ni ati kekere ni ijọba ti maa n fa oju awọn ọdọ̀ naa si ere idaraya paapaa lasiko ti wọn ba wa lẹnu isinmi.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/czjvw373rddo
|
2025-09-29
|
bbc
|
Awuyewuye lórí bí wọ́n ṣe fi orúkọ Victor Osimhen sọ mọ́ṣálááṣí, àwọn mùsùlùmí ní àbùkù ńlá ni
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Awuyewuye ti bẹ silẹ lori bi wọn ṣe fi orukọ ẹlẹsẹ ayo ọmọ Naijiria to n gbabọọlu fun ikọ Galatasaray lorilẹede Turkey, Victor Osimhen, sọ mọṣalaaṣi kan lorilẹede naa. Laipẹ yii ni Osimhen pada si Turkey lati darapọ mawọn akẹgbẹ rẹ fun igbaradi fun saa bọọlu tuntun ninu idije liigi Turkey ati kaakiri ilẹ Yuroopu. Gẹgẹ bi iwe iroyin ere idaraya Fanatik to wa ni Turkey ṣe ṣalaye, mọṣalaaṣi Bulut to wa lẹkun Karatay ni Konya lawọn eeyan ṣadeedee ri pe o ti di ''Mọṣalaaṣi Victor Osumhen'' lori aapu itọnisọna ti wọn n pe ni Google Maps. Ọdun 2008 ni a gbọ pe wọn ṣi mọṣalaaṣi ọhun lorilẹede Turkey. Ọpọ awọn olujọsin ni wọn koro oju si bi orukọ mọṣalaaṣi ọhun ṣe yi pada si orukọ Osimhen. Wọn si n pe fun ki wọn da orukọ mọṣalaaṣi naa pada si orukọ to n jẹ tẹlẹ. ''Mọṣalaaṣi Bulut ni a mọ mọṣalaaṣi yii si lati igba ti a ti n jọsin nibẹ. Awa o faramọ ki wọn fi orukọ Victor Osimhen sọ mọṣalaaṣi wa, onigbagbọ ni Osimhen. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ A fẹ ki awọn alaṣẹ bawa dasi ọrọ yii, ki wọn si da orukọ mọṣalaaṣi naa pada si mọṣalaaṣi Bulut to n jẹ tẹlẹ,'' olujọsin kan lo sọ bẹẹ. Olujọsin mọṣalaaṣi miran sọ pe ''ohun to wa lori itakun ayelujara ni pe mọṣalaaṣi Bulut ti di mọṣalaaṣi Victor Osimhen. Ṣugbọn mọṣalaaṣi Bulut ni awa mọ mọṣalaaṣi yii si fun bii ọdun mẹwaa bayii. Osimhen kii ṣe agbabọọlu to wa lati Konyaspor, ko si ṣe nkankan fun mọṣalaaṣi yii. Agbabọọlu Osimhen kii ṣe ẹnikan ti awọn eeyan Konya ko le gbagbe laelae. Nitori naa, igbesẹ lati fi orukọ rẹ sọ mọṣalaaṣi Bulut ko ye wa.'' Zeki Yaylacı toun naa jẹ ọkan lara awọn eeyan lawujọ ti mọṣalaaṣi naa wa sọ pe nnkan to le mu inu bi eeyan ni bi wọn ṣe fi orukọ Osimhen sọ mọṣalaaṣi Bulut. Yaylacı ni nnkan itiju ni ki wọn fi orukọ ẹni ti kii ṣe musulumi sọ mọṣalaaṣi. ''A ri eleyii gẹgẹ bii ọna lati tabuku awọn musulumi, awọn eeyan awujọ ti mọṣalaaṣi yii wa ati mọṣalaaṣi yii gan an gan an. A rọ awọn alaṣẹ lati ṣe ofin ti ko ni jẹ kọ rọrun lati maa paarọ orukọ mọṣalaaṣi gẹgẹ bi eyi to ṣẹlẹ yii. Ko si ẹni to le fidi rẹ mulẹ bo ya Osimhen mọ nipa igbesẹ lati fi orukọ rẹ sọ mọṣalaaṣi ni Turkey. Osimhen fakọyọ ni saa bọọlu to kọja, goolu mẹtadinlogoji lo gba sawọn fun ẹgbẹ agbabọọlu Galatasaray. Lẹyin naa ni ẹgbẹ agbabọọlu naa ra a patapata lati ikọ agbabọọlu Napoli ti wọn ti ya a lo tẹlẹ. Osimhen ni agbabọọlu ti wọn fowo to pọ julọ ra ninu itan ere bọọlu lorilẹede Turkey lẹyin ti Galatasaray ra a ni €75m.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cx2xjr7jkj7o
|
2025-08-16
|
bbc
|
Sáà Premier League tuntun bẹ̀rẹ̀ lónìí, ẹ wo àwọn òfin tuntun tó bá dé
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Idije Premier League ti saa 2025/2026 bẹrẹ lonii lẹyin ti saa bọọlu 2024/2025 pari loṣu Karun un to kọja. Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool to gbafe ẹyẹ saa to lọ ni yoo ṣide saa Premier League 2025/2026 tuntun yii nigba ti wọn yoo maa koju Bournemouth lalẹ oni ọjọ Ẹti ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ ni papa iṣere Anfield. Ọpọ awọn ololufẹ Premier League ni Naijiria ati kaakiri agbaye lo ti n foju sọna fun saa Premier League tuntun lati gberasọ. Idije liigi tuntun yii yoo tun gbinaya lopin ọsẹ nigba ti Manchester United yoo maa gbalejo ikọ agbabọọlu Arsenal ni papa iṣere Old Trafford. Wọnyii ni akojọpọ awọn ofin tuntun to ba idije Premier League saa yii de: Omi tuntun ti ru ẹja tuntun si ti wọ ninu idije Premier League, ni saa bọọlu tuntun yii, aṣọle ko gbọdọ fi akoko ṣofo ti bọọlu ba wa lọwọ rẹ, bi bẹẹ kọọ, rẹfiri yoo paṣẹ pe ki ẹgbẹ bọọlu alatako gba kọna gẹgẹ bii ijiya fun aṣọle naa. Wọn ṣe agbekalẹ ofin yii lati dẹkun bawọn agbabọọlu ṣe maa n fi akoko ṣofo. Ofin to wa tẹlẹ ni pe aṣọle ko gbọdọ wa lori bọọlu ju iṣẹju aaya mẹfa lọ, ijiya si ni pe ẹgbẹ agbabọọlu alatako yoo gba fiiri-kiiki. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Amọ, ni saa bọọlu yii, aṣọle ko gbọdọ lo ju iṣẹju-aya mẹjọ lọ pẹlu bọọlu, bi bẹẹ kọọ, ẹgbẹ agbabọọlu alatako yoo gba kọna gẹgẹ bii ijiya fun aṣemaṣe gooli naa. Wọn ti bẹrẹ si ni ṣe amulo ofin yii kaakiri ibi ti wọn ti n gba bọọlu, koda, wọn lo o ninu idije ife ẹyẹ agbaye awọn ikọ agbabọọlu FIFA Club World Cup ti Chelsea gba lorilẹede Amẹrika. Ofin tuntun mii ni pe awọn Balogun ẹgbẹ agbabọọlu ni Premier League yoo lanfaani lati ba rẹfiri sọrọ ni saa bọọlu tuntun yii. Bakan naa, rẹfiri le fun agbabọọlu to ba lọ ba a sọrọ nigba ti ifẹsẹwọnsẹ n lọ lọwọ lai gbaṣẹ ni kaadi yẹlo gẹgẹ bi ikilọ. Ko tan sibẹ o, agbabọọlu to ba tabuku rẹfiri nigba ti ere bọọlu n lọ lọwọ naa yoo gba kaadi yẹlo fun ikilọ. Lara awọn ofin tuntun ninu idije Premier League ti saa yii ni pe awọn ẹgbẹ agbabọọlu lanfaani lati yan agbabọọlu mii gẹge bii Balogun ki ifẹsẹwọnsẹ to berẹ to ba jẹ pe goli ni Balogun ẹgbẹ agbabọọlu wọn. Ofin tuntun miran ni pe rẹfiri yoo maa faye gba agbabọọlu ti ẹsẹ rẹ ba ṣeesi kan bọọlu lẹẹmeji nigba ti o fẹ gba pẹnariti lati tun un gba lẹẹkeji. Amọ, bọọlu gbọdọ wọ inu awọn nigba to kọkọ gba pẹnariti naa. Wọn ti lo ofin yii ninu idije EURO 2025 awọn obinrin nilẹ Yuroopu nibi pẹnariti ti waye laarin Spain ati England ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije naa eyi tawọn obinrin England ti jawe olubori. Ti ẹ o ba gbagbe, agbabọọlu obinrin fun England, Beth Mead, yọ nigba to fẹ gba pẹnariti, ẹsẹ rẹ si kan bọọlu lẹẹmeji. Bo tilẹ jẹ pe bọọlu naa wọle sawọn, Mead tun pẹnariti naa gba, amọ ọwọ goli Spain, Cata Coll lo gba a si. Labẹ ofin ti tẹlẹ, rẹfiri ko ni jẹ ki Mead tun pẹnariti naa gba fun igba keji rara. Aston Villa v Newcastle United Brighton v Fulham Sunderland v West Ham United Tottenham v Hotspur v Burnley Wolves v Manchester City Chelsea v Crystal Palace Nottingham Forest v Brentford Manchester United v Arsenal
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c74djp1r341o
|
2025-08-15
|
bbc
|
Boniface àtàwọn agbábọ́ọ̀lù míì tí wọ́n kùnà láti darapọ̀ mọ́ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù míì torí àyẹ̀wò ará wọn foríṣánpọ́n
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Erongba ẹlẹsẹ ayo ọmọ Naijiria, Victor Boniface, lati darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu AC Milan lati Bayer Leverkusen foriṣanpọn lẹyin ti esi ayẹwo ara rẹ ti wọn ṣe ko kẹsẹjari. Boniface ko ni le darapọ mọ AC Milan tori ẹgbẹ agbabọọlu naa sọ pe ko pegede ninu ayẹwo ti wọn ṣe lori ara rẹ. Ṣaaju ni Leverkusen ati AC Milan ti fẹnuko lori adehun wi pe Boniface yoo wa ni AC Milan fun saa bọọlu kan fun €5m. O tun wa ninu adehun naa pe AC Milan le ra Boniface patapata fun €24m ti o ba gba bọọlu fun wọn tan fun saa kan. Ohun ti a gbọ ni pe orunkun Boniface lawọn dokita Milan ti ṣe ayẹwo to pọ. Ti ẹ o ba gbagbe, lori orunkun yii naa ni Boniface ti ṣeeṣe ni saa bọọlu 2018/2019 ati 2020/2021. Agbabọọlu mii ti ayẹwo ara rẹ forisanpọn ni Nicolas Jackson. Ẹgbẹ agbabọọlu Villarreal ati Bournemouth ti fẹnuko lori ẹlẹsẹ ayo naa wi pe yoo darapọ mọ Bournemouth loṣu Kinni ọdun 2023. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Amọ, adehun naa foriṣanpọn lẹyin ti Bournemouth sọ pe Jackson ti ṣeṣe lori iṣan to w ani itan rẹ. Ṣugbọn Jackson pada darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lẹyin oṣu mẹfa ti erongba rẹ lati lọ Bournemouth foriṣanpọn. Jackson ti gba ife ẹyẹ Europa Conference League ati FIFA Club World Cup pẹlu Chelsea bayii. O si ṣeeṣe ki o tun fi ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea silẹ laipẹ tori o dabi ẹni pe wọn fẹ ta a. Hakin Ziyech ni agbabọọlu Chelsea mii ti ko lanfaani lati darapọ ikọ agbabọọlu Al-Nassr lọdun 2023 lẹyin ti ko pegede ninu ayẹwo ara rẹ ti wọn ṣe fun un. Ohun ti ẹgbẹ agbabọọlu Al-Nassr sọ ni pe nkankan wa ninu orunkun rẹ ti ko duro daadaa. Lẹyin naa ni Ziyech pada si Chelsea ti o si darapọ mọ Galatasaray lorilẹede Turkey. Agbabọọlu iwaju Loic Remy ko ba darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool lọdun 2014. Ṣugbọn eyi foriṣanpọn lẹyin ti awọn dokita Liverpool ri pe nnkankan ko ṣe daadaa ninu ọkan Remy. Amọ, Remy pada darapọ mọ Chelsea lẹyin oṣu mẹfa si asiko naa. Koda, Remy gba ife ẹyẹ Premier League pẹlu Chelsea ni saa akọkọ to lo ni Chelsea. Ni ẹgbẹ agbabọọlu meji ọtọọtọ ni ẹlẹsẹ ayo ọmọ orilẹede Senegal ti kuna nibi ayẹwo ara rẹ ti o ṣe. Akọkọ ni ẹgbẹ agbabọọlu Germany, Stuttgart, nibi ti ayẹwo ara Demba Ba ti foriṣanpọn. Lẹyin naa ni ayẹwo ara rẹ tun foriṣanpọn lọdun 2009 ati 2011. Bo tilẹ jẹ pe ayẹwo ara Demba Ba foriṣanpọn lawọn ẹgbẹ agbabọọlu kan, o si pada gbabọọlu lawọn ẹgbẹ agbabọọlu to gbaju gbaja to fi mọ Chelsea. Ẹlẹsẹ ayo England naa wa lara awọn agbabọọlu ti ayẹwo ara wọn ko kẹsẹjari lawọn asiko kan. Toney kuna lati darapọ mọ Wolverhampton Wanderers lẹyin ti ayẹwo ara rẹ foriṣanpọn. Amọ, o pada darapọ ikọ agbabọọlu Newcastle lẹyin o rẹyin. Ẹgbẹ agbabọọlu Al-Ahli lo n ṣoju lọwọ yii lorilẹede Saudi Arabia
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cdxy704qe0zo
|
2025-08-25
|
bbc
|
Igbákejì akọ́nimọ̀ọ́gbá 3SC, Akin Olowokere jáde láyé
|
Oríṣun àwòrán,x/@TelegraphNG Akin Olowookere, to jẹ igbakeji akọnimogba ẹgbẹ agbabọọlu 3SC, ti ọpọ eeyan mọ si Shooting Stars ti ilu Ibadan ti jade laye. Akin Olowookere ni ẹgbẹ agbabọọlu 3SC ṣẹṣẹ fivlede gẹgẹ bii igbakeji akọnimọọgba ikọ ọhun lọjọ mẹta sẹyin. BBC Yoruba fidi rẹ mulẹ pe o ṣubu lakoko ti awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu 3SC n ṣe igbaradi ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ kan ti yoo waye lọla ọjọ Iṣẹgun nilou Ijebu-Ode, nibi ti wọn ti n gba ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹẹ ti Value Jet lọwọ. Awọn ti iroyin naa ṣoju wọn ni, kete ti Olowookere ṣubu, nisẹ ni wọn gbe lọ si ile iwosan to si padanu ẹmi rẹ ṣaaju ki wọn to gbe de ile iwosan naa. Ṣaaju ko to darapọ mọ 3SC, Olukọni Olowookere ṣiṣẹ gẹgẹ bii oluranlọwọ olukọni ti ikọ agbabọọlu Sunshine Stars FC, ti ilu Akure, nipinlẹ Ondo. This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Xcookie policyandprivacy policybefore accepting. To view this content choose 'accept and continue'. End of X post Content is not available O tukọ ikọ agbabọólu Sunshine Stars nigba ti Austin Eguavoen fi iṣẹ naa silẹ lọdun 2017. Olowookere lo ti gba bọọlu pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Sunshine Stars ti ilu Akure ko to fẹyinti to si ṣiṣẹ gẹgẹ bii igbakeji akọnimọọgba Edith Agoye. A ṣẹṣẹ n ko iroyin yii jọ ni, a o maa fi iryoku rẹ to yin leti laipẹ. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/crm4410dylro
|
2025-08-11
|
bbc
|
Ta ni Aitana Bonmati tó gbàmì ẹ̀yẹ Ballon d'Or lẹ́ẹ̀mẹ́ta léra wọn lẹ́yìn tórí kó o yọ lọ́wọ́ àrùn yínrùn-yínrùn?
|
Oríṣun àwòrán,Reuters Gbajugbaja agbabọọlu obinrin orilẹede Spain to n gba bọọlu fun Barcelona lo gbami ẹyẹ bọọlu Ballon d'Or ti ọdun 2025 yii. Lalẹ ana ni wọ kede Bonmati gẹgẹ bi agbabọọlu obinrin to gbade Ballon d'Or tọdun yii niluu Paris. Bonmati ni agbabọọlu obinrin akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ naa fun igba mẹta lera wọn. Akẹgbẹ rẹ, Mariona Caldentey, to n gbabọọlu fun Arsenal lo ṣe ipo keji. Nigba ti o n gba ami ẹyẹ naa lọwọ agbabọọlu Barcelona tẹlẹ, Andres Iniesta, Bonmati sọ pe bi oun ṣe gba ami ẹyẹ Ballon d'Or fun igba mẹta lera wọn dabi ala loju oun. O ni oun gbagbọ pe o ṣee ṣe ki ami ẹyẹ naa bọ si agbabọọlu miran lọwọ yatọ soun. Bonmati tun fi idunnu rẹ han lori bo ti jẹ pe Iniesta toun maa n wo bi awokọṣe nigba toun wa ni kekere lo gbe ami ẹyẹ naa le oun lọwọ. Ṣaaju idije Euro 2025 tawọn obinrin ni Bonmati wa lori idubulẹ aisan nigba to ni arun yinrun-yinrun. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Koda, oun gan an ko mọ pe oun yoo si lanfaani lati kopa ninu idije Euro mọ pẹlu aisan to da a gunlẹ. Amọ, lẹyin ti Bonmati jade nile iwosan tan ni o gba goolu to gbe Spain wọ abala aṣekagba idije naa sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba pẹlu Germany. Bo tilẹ jẹ pe England fi pẹnariti lu wọn gbami ẹyẹ idije Euro 2025, Bonmati fakọyọ fun Spain ninu idije naa. Agbabọọlu England tẹlẹ ri, Fara Williams, sọ fun BBC pe ti ẹgbẹ agbabọọlu Spain ba maa jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan, Bonmati lo maa n ṣaba jẹ pe o maa fakọyọ to si maa jẹ ki Spain bori. Ọpọ eeyan lo gba pẹlu Williams wi pe oootọ lọrọ to sọ pẹlu bi Bonmati ti gba ami ẹyẹ Ballon d'Or fun igba mẹta lera wọn bayii. Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Ọjọ kejidinlogun oṣu Kinni ọdun 1998 ni wọn bi Aitana Bonmati. Agbabọọlu aarin gbungbun ni Bonmati jẹ fun ikọ agbabọọlu obinrin Spain ati fun ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona. Lẹyin to gba gbogbo ami ẹyẹ to lamilaaka ninu ere bọọlu eyi ti wọn fi kede rẹ gẹgẹ bi agbabọọlu obinrrin to pegede julọ ni Yuroopu lọdun 2023, ọpọ eeyan lagbo ere bọọlu lo n ri Bonmati gẹgẹ bii ọkan lara agbabọọlu obinrin to pegede julọ ninu itan. Bonmati ti wa ni ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona lati ọdun 2012, nibẹ naa lo ti ṣe igba ewe rẹ. Ẹgbẹ agbabọọlu ọjẹwẹwẹ Barcelona ni Bonmati ti bẹrẹ irinajo bọọlu gbigba rẹ, ki o to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu agba Barcelona ni saa bọọlu 2016/2017. O ti gba ami ẹyẹ liigi marun un, Copas de la Reina mẹfa, Supercopas marun un, ami ẹyẹ Copas Catalunyas mẹrin ati ife ẹyẹ UEFA Champions League awọn obinrin mẹta. Lẹyin ti Bonmati gba ami ẹyẹ Ballon d'Or ati ami ẹyẹ FIFA Best lọdun 2023 ati 2024 ni o tun gba Ballon d'Or ti ọdun yii lalẹ ana ọjọ Aje ọjọ kejilelogun oṣu Kẹsan an. Oríṣun àwòrán,Getty Images Aṣọle ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons, Chiamaka Nnadozie, lo gba ipo kẹrin ni isọri awọn aṣọle obinrin to pegede julọ lagbaaye nibi ayẹyẹ Ballon d'Or tọdun 2025. Nnadozie ni aṣọle ọmọ ilẹ Afirika to pegede julọ bayii, bakan naa lo tun fakọyọ lagbo awọn goli lagbaaye pẹlu ipo kẹrin to gba. Agbabọọlu Chelsea, Hannah Hampton, lo gba ami ẹyẹ Yashin Trophy naa eyi to jẹ akọkọ iru rẹ. Ti ẹ o ba gbagbe, Hampton gba ami ẹyẹ Euro 2025 pélu England, bakan naa ni o tun gba ami ẹyẹ mẹta ọtọọtọ pẹlu Chelsea. Ọpọ eeyan lo ti n gbe oṣuba rabandẹ fun Nnadozie lori aṣeyọri nla to ṣe yii. Nnadozie to n gba bọọlu fun Brighton ni England gba ife ẹyẹ Wafcon pẹlu Super Falcons Naijiria lọdun 2025 yii. Nibi idije bọọlu agbaye awọn obinrin – 2023 Women's World Cup – ni ọpọ eeyan ti mọ Nnadozie gẹgẹ bi aṣọle to pegede lẹyin to fakọyọ ninu idije naa fun Naijiria. Oríṣun àwòrán,Getty Images Ẹlẹsẹ ayo ẹgbẹ agbabọọlu PSG ati orilẹede France, Ousmane Dembele, lo gbami ẹyẹ Ballon d'Or awọn agbabọọlu ọkunrin fun ọdun 2025. Ami ẹyẹ mẹta ọtọọtọ ni Dembele gba ni saa bọọlu 2024/2025 ti o fi la Lamine Yamal agbabọọlu Barcelona mọlẹ gba ami ẹyẹ Ballon d'Or tọdun yii. Goolu marundinlogoji ni Dembele gba sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹtalelaadọta to kopa ninu rẹ. Ni ṣe ni omije n da poro poro loju Dembele nigba ti wọn pe e wi pe oun lo gba ami ẹyẹ naa. Meji ni agbabọọlu ilẹ Afirika to wa ninu awọn agbabọọlu to ṣe ipo kinni si ikẹwaa 1. Ousmane Dembélé 2. Lamine Yamal 3. Vitinha 4. Mohamed Salah 5. Raphinha 6. Achraf Hakimi 7. Kylian Mbappé 8. Cole Palmer 9. Gianluigi Donnarumma 10. Nuno Mendes
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c98d6m67m90o
|
2025-09-23
|
bbc
|
"Lóòótọ́ ni mò ń mófo nínú tẹ́tẹ́ bọ́ọ̀lù tí mò ń ta, àmọ́, mi ò lè fi í sílẹ̀"
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Igbiyanju Musa pẹlu tẹtẹ bọọlu tita ti jẹ kí o di ẹni tí gbogbo eeyan n fi ṣe ẹlẹya ni adugbo rẹ niluu Kaduna lapa ariwa orilẹede Naijiria. Musa mọ bọọlu gba daadaa lati igba ewe rẹ, ọpọ eeyan lo si maa n wo o gẹgẹ bii ẹni tí yoo gba bọọlu jẹun. Eyi lo jẹ ko rìnrìn ajo lati ilu Kaduna lọ si ilu Eko ki o lè lanfaani lati maa gba bọọlu nibi ti gbogbo aye yoo ti maa ri i. Ti ọmọdekunrin kan ba ti gbera lati apa ariwa Naijiria lọ si guusu, awọn eeyan ariwa maa n ri igbesẹ yii gẹgẹ bi ọna lati jẹ ki ala iru ọdọ bẹẹ wa si imuṣẹ. Amọ, ọrọ ko ri bẹẹ fun Musa nitori nnkan mii to yatọ si bọọlu gbigba tawọn ẹbi rẹ atawọn eeyan mọ ọn mọ lo bẹrẹ si ni ṣe niluu Eko. Dipo ki Musa gbiyanju sii lati le lanfaani ati lọ gbabọọlu loke okun, ni ṣe ni Musa lọ kọ bi wọn ṣe n ta tẹtẹ lori bọọlu afẹsẹgba niluu Eko. Bayii ni Musa ṣe di ilumọọka lori tẹtẹ tita, bo tilẹ jẹ ofo lo mu lọgba igba to ti ta tẹtẹ. Musa ni o ṣoro foun lati dẹkun tẹtẹ tit abo tilẹ jẹ pe oun ti padanu owo gọbọi lori tẹtẹ tita. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Nigba to n ṣalaye bo ti bẹrẹ tẹtẹ tita, Musa ni ''ololufẹ bọọlu gidi ni mi. Amọ, dipo ki n maa gba bọọlu, idi tẹtẹ tita lori bọọlu ni mo ba ara mi. Mo ro wi pe bọọlu gbigba yoo mu ayipada rere ba igbe aye mi nigba ti mo kọkọ bẹrẹ si ni gba bọọlu, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ rara. Ọrẹ mi kan toun naa jẹ agbabọọlu lo mi wọ inu tẹtẹ tita. ''Koda, mo gba bọọlu de orilẹede Niger Republic, ṣugbọn nipinlẹ Eko ni ọrẹ mi ti sọ fun mi lọjọ kan pe ki n sin oun lọ si ṣọọbu kan. N14,000 ni wọn fun ọrẹ mi yii nigba ti a de ṣọọbu naa, nibẹ lo ti sọ fun mi pe oun toun jẹ nibi tẹtẹ ni owo naa. O tun wa sọ fun mi pe emi naa yoo maa jẹ owo ti mo ba le maa tẹtẹ lori bọọlu,'' Musa ṣalaye. Musa ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ọrẹ oun kilọ foun pe o maa nira lati fi tẹtẹ tita silẹ ti eeyan ba ti le bẹrẹ rẹ tan. ''N18,000 ni kọkọ jẹ nigba t imo bẹrẹ si ni ta tẹtẹ, mo si tun jẹ N6,000 nigba keji; N1,000 pere ni mo jẹ nigba ti mo ta tẹtẹ fun igba kẹta. Lẹyin igba naa ni mi o jẹ owo kankan mọ fun igba pipẹ, ọpọ eeyan lo maa n jẹwo daadaa nigba ti wọn ba kọkọ bẹrẹ tẹtẹ tita. Amọ, to ba ti dun mọ wọn tan ni wọn ko ni ri owo jẹ mọ bii ti tẹlẹ.'' Musa ni oun tẹsiwaju tẹtẹ tita nigba toun pada si ilu Kaduna lati ilu Eko. ''Mi o mọ idi ti mi o fi le fi tẹtẹ tita silẹ, bo tilẹ jẹ pe n ko ri ere nibẹ. Koda diẹ loku ki tẹtẹ tu igbeyawo mi ka, ti mo si bura lati ma de idi rẹ mọ, ṣugbọn ni gbogbo igba ni mo n pada lọ sibẹ,'' Musa ṣalaye. Musa sọ pe imọran ti baba oun foun ni pe ki oun maa gbadura pe ki Eleduwa ran oun lọwọ lati fi tẹtẹ silẹ. Ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu pọun ni iwadii sọ pe ogunlọgọ eeyan n lo lagbaaye lati fi ta tẹtẹ.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cz0yj95y54zo
|
2025-08-24
|
bbc
|
Ǹ jẹ́ ikọ̀ agbábọ́ọ́lù Super Eagles ti Nigeria ṣì le lọ ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé?
|
Oríṣun àwòrán,NG-SUPER EAGLES/GOOGLE Pẹlu bii ikọ Super Eagles ṣe ti bori ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu orilẹede Rwanda ninu idije igbaradi fun idije ife ẹyẹ agbaye, ọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu lo ti koroju si bi ifẹsẹwọnsẹ naa ṣe lọ. Ifẹsẹwọnsẹ ọhun lo waye niluu Uyo lorilẹede Naijiria, to si jẹ pe goolu kan soso to waye nibi ifẹsẹwọnsẹ wa lati ọwọ Tolu Arokodare, to jẹ agbaọwọ iwaju fun ikọ Super Eagles. Ipo kẹta ni orilẹede Naijiria wa lori tabili bayii, ti orilẹede South Africa ati Benin si wa ni ipo kinni ati ikeji. Orilẹede South Africa ati Naijiria yoo wa wako lọjọ Isẹgun, ọjọ kẹsan an, ọsu kẹsan an ọdun 2025 niluu South Africa. Ti orilẹede Naijiria ba bori ifẹsẹwọnsẹ pẹlu South Africa, igbagbọ si jẹyọ boya wọn si ni anfani lati lọ fun idije ife ẹyẹ agbaye lọdun to n bọ. Ni bayii, ami ayo mẹwaa ni Naijiria ni, ti South Africa si ni mẹrindinlogun. Ifẹsẹwọnsẹ mẹta loku bayii lati mọ boya ikọ Super Eagles yoo kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye. Oríṣun àwòrán,NG-SUPER EAGLES Ọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu ati Super Eagles ti bọ sori ayelujara lati fẹhonuhan lori ifẹsẹwọnsẹ pẹlu orilẹede Rwanda. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion @thewaleogun: "Ikọ yii ko ki n ṣe rara, o dara ti a ko ba lọ fun ife ẹyẹ agbaye." @royaleweb3_: "A ni lati karamọri kini yii. Gbigba bọọlu ni idije ife ẹyẹ agbaye tumọ si bibori. A ko le mi awọn mẹta pẹlu Rwanda." @Utd_9X: "Eyi ki n ṣe aṣeyọri ti a fẹ ṣugbọn a gba bẹẹ.." @dapzinfash: "Ọlọrun yọọ baba yin. Mo ti kọ epe silẹ fun yin, ti ma fi ransẹ si yin ni ọkọkan." @WorthyGodwin1: "Ko ba jẹ pe wọn gba wọle fun ara wọn, e ri pe bori lorilẹede SA. A dara pupọ ṣugbọn a ni lati igbiyanju si oooo." @lebar4real: "Ni ifẹsẹwọnsẹ ọjọ Isẹgun. South Africa, a n bọ wa lati wa bori ni. A ni lati kọ bi a o sẹruba awọn alatako wa. O buru pe a ni ọpọ agbaọwọ iwaju ṣugbọn a ko le mi awọn." @Joe_o_X: "Ki lo de ti ẹ fẹran goolu kan soso bayii; ṣe o buru ju ti ẹ ba mi awọn pupọ ni?" @Ohams4NewNaija: "A nilo ọpọ goolu." @Azeez_Maleek: "A nilo ọna miran nigba ti a ba koju South Africa. A ko le ma gba bọọlu bayii, ki a ma reti pe a o bori ni ita ile wa. Ifẹsẹwọnsẹ to kan bayii ṣe pataki. Ẹ jẹ ka ba tikẹẹti yii." @Famousity2222: "N jẹ ere bọọlu ni eyi? Rwanda lasanlasan! Super Eagles ti tan."
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cwyw90gdxrro
|
2025-09-07
|
bbc
|
Wo iye ìgbà tí àwọn eléré ìdárayá gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ ààrẹ àti ẹ̀bùn tí wọn gbà
|
Oríṣun àwòrán,Bayo Onanuga/X Láti ìgbà tí ààrẹ ti kéde àwọn ẹ̀bùn yìí ni awuyewuye ti ń wáyé táwọn ọmọ Nàìjíríà sì ń sọ̀rọ̀ lórí ìgbésẹ̀ ààrẹ yìí. Bí àwọn kan ṣe ń kan sáárá sí Tinubu pẹ̀lú bó ṣe fún àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ní owó tabua náà ni àwọn míì ń bu ẹnu àtẹ́ lù ú pé owó náà ti pọ̀jù. Ohun tí àwọn kan ń sọ ni pé owó tí ààrẹ fún àwọn agbábọ́ọ̀lù ọ̀hún le tó ṣe nǹkan fún Nàìjíríà pàápàá fáwọn tálákà tí wọn kò rí ọwọ́ họrí. Ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó sọ̀rọ̀ ní Wemzo Emmanuel tó wòye pé $100,000 pọ̀ púpọ̀ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan àwọn agbábọ́ọ̀lù náà nígbà tí ìṣẹ́ àti òṣì ń bá ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà fínra. Emmanuel ní ọ̀pọ̀ àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ni wọ́n ti ní owó púpọ̀ tẹ́lẹ̀. Otolorin Hakeem ní "àwọn èèyàn sì ń jìyà ní Nàìjíríà, Ọlọ́run ń bẹ ṣá." Fún Mufuliat Musa "Erikkk kosi owo lorilede wa yi rära, yin osise ijoba elo ni owo osu yin mo fe binu san." Bákan náà ni àwọn mìíràn tún bu ẹnu àtẹ́ lu bí ààrẹ ṣe kéde ẹ̀bùn owó náà pẹ̀lú owó ilẹ̀ òkèèrè. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ohun táwọn èèyàn náà ń sọ ni pé ìgbésẹ̀ náà jẹ́ gbígbé owó ilẹ̀ òkèèrè lárugẹ ju owó náírà lọ. Àmọ́ báwọn kan ṣe ń sọ pé owó tí ààrẹ fún àwọn agbábọ́ọ̀lù ni àwọn míì ń sọ pé owó náà kò pọ̀ jù àti pé àwọn agbábọ́ọ̀lù náà yẹ láti jèèrè iṣẹ́ wọn. Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Ẹ̀wẹ̀, agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ rí kan ní Nàìjíríà Mutiu Adepoju sọ fún BBC News Yorùbá pé àwọn agbábọ́ọ̀lù Super Falcons ti ṣiṣẹ́ takuntakun, tó sì jẹ́ pé gbogbo nǹkan tí ààrẹ Tinubu fún wọn náà ni wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí. "Àwọn ọmọbìnrin yìí ti gbìyànjú, wọ́n ti gbé orílẹ̀ èdè wa lárugẹ. "Èmi lérò pé ó yẹ ká kan sáárá sí ààrẹ Nàìjíríà fún ìgbésẹ̀ yìí àti pé wọ́n ṣe irú nǹkan báyìí." Adepoju ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ì tíì sí ìjọba tó ti fún àwọn agbábọ́ọ̀lù kankan ní owó tó pọ̀ bí èyí rí, ó ní ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ìjọba yóò máa ṣe kóríyá fáwọn agbábọ́ọ̀lù. Ó tẹ̀síwájú pé àrà ọ̀tọ̀ ní ìgbésẹ̀ ààrẹ Tinubu yìí àti pé yóò jẹ́ ìwúrí fáwọn agbábọ́ọ̀lù tó wà lẹ́yìn pé tí àwọn bá ṣe dáadáa nínú ìdíje, àwọn máa rí ẹ̀bùn tó jọjú gbà nílé. Bákan náà ni agbẹnusọ Ààrẹ Tinubu, Bayo Onanuga nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí ayélujára sọ pé owó tí ààrẹ fún àwọn agbábọ́ọ̀lù náà kò pọ̀ rárá tí a bá wo iṣẹ́ táwọn agbábọ́ọ̀lù náà ṣe. Ó ní iṣẹ́ takuntakun, ìfẹ́ orílẹ̀ èdè ẹni àti ọgbọ́n àtinúdá àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ni ààrẹ bu iyì fún pẹ̀lú ohun tó ṣe fáwọn ọmọbìnrin ọ̀hún. Ó wòye pá ọ̀pọ̀ àwọn ìdíje bíi Big Brother Naija, BBN ni wọ́n máa ń fún ẹni tó bá gbégbá orókè ní owó tabua bíi ₦150m èyí tó ní kò ní ipa kankan lórí orílẹ̀ èdè. Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje ọdún 2025 ni ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu fi ẹ̀bùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó, ilé àti oyè dá àwọn agbábọ́ọ̀lù Super Falcons lọ́lá láti ṣe kóríyá fún wọn látàrí bí wọ́n ṣe gba ife ẹ̀yẹ bọ́ọ̀lù 2024 Women Africa Cup of Nations. Ní ilé ààrẹ Aso Rock tó wà ní ìlú Abuja ni ààrẹ ti gbàlejò àwọn agbábọ́ọ̀lù náà lẹ́yìn tí wọ́n padà sí Nàìjíríà láti Morocco tí ìdíje náà ti wáyé. "Ní orúkọ gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, mo fi oyè Officer of the Order of the Niger, OON, dá a yín lọ́lá," Tinubu sọ. "Ní àfikún, mo darí àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣe àkóso ilé ìgbé Renewed Hope Housing Estate láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ilé oní yàrá mẹ́ta mẹ́ta. Bákan náà ni ààrẹ tún kéde fífún àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ní owó náírà tí iye rẹ̀ jẹ́ $100,000 fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn agbábọ́ọ̀lù mẹ́rìnlélógún náà àti $50,000 fáwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn. Níbi ayẹyẹ náà ni alága àwọn gómìnà Nàìjíríà tó tún jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara kéde fífún àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ní mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn àtàwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn. Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tàbí eléré ìdárayá yóò máa rí ẹ̀bùn gbà lọ́wọ́ ìjóba nígbà tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ takuntakun lásìkò ìdíje. Ní ọdún 2023 tí ikọ̀ Super Eagles gbé ipò kejì níbi ìdíje AFCON ọdún 2023 ni ààrẹ Bola Tinubu fún wọn ní ẹ̀bùn ilé àti ilẹ̀ ní ìlú Abuja. Bákan náà ni ààrẹ tún fún ní ẹ̀bùn owó tó sì fi oyè Member of Order of Niger, MON, tó fi dáwọn lọ́la. Mutiu Adepoju sọ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ìjọba máa ń ṣe kóríyá fáwọn eléré ìdárayá tí wọ́n bá ṣe dáadáa níbi ìdíje bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ì tíì sí ẹni tó gba owó tó pọ̀ tó ti àwọn Super Falcons yí rí. Ní ọdún 2022, ààrẹ àná ní Nàìjíríà, Muhammadu Buhari fún àpapọ̀ àwọn eléré ìdárayá tó kópa níbi ìdíje 2022 Commonwealth Games (CWG) ní ẹ̀bùn ₦200m. Agbenusọ ààrẹ nígbà náà, Femi Adesina pé ààrẹ Buhari tún fi oyè dá àwọn eléré ìdárayá náà lọ́lá. Góòlù méjíl, fàdákà mẹ́sàn-án àti bàbà mẹ́rìnlá ni ikọ̀ Nàìjíríà gbà níbi ìdíje náà, tí wọ́n sì jẹ́ ilẹ̀ Africa tó wà ní ipò tó wà lókè jùlọ pẹ̀lú ipò keje tí wọ́n gbé níbi ìdíje náà.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c17n0d2d4p8o
|
2025-08-02
|
bbc
|
Saheed Osupa kan sáárá sí Burnaboy lẹ́yìn tó pè é ní 'G.O.A.T.', ìyẹn olórín tí òun gbà pé ó ta lẹ́nu jùlọ lágbáyé
|
Oríṣun àwòrán,instagram/BurnaBoy/Saheed Osupa Gbajugbaja olorin Fuji, Saheed Osupa ti kan sara si olorin takasufe to ti gba ami ẹyẹ grammy, Damini Ogulu, ti ọpọ mọ si Burna Boy fun bi o ṣe ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii olorin ó ta lẹ́nu jùlọ lágbáyé ti wọn n da pe ni Greatest of all times, iyẹn "GOAT" lede oyinbo. Itumọ "GOAT" yii lo duro fun "ẹni tó ta lẹ́nu jùlọ lágbáyé lati irande iran", ti wọn si ma n lo ọrọ yii ni ẹka ere idaraya lati ṣapejuwe eeyan ti ọpọ gba gẹgẹ bii ọga. Burna Boy, ṣapejuwe fi ọrọ yii tọka si Saheed Osupa, eekan akọrin Fuji, lasiko to fi n ṣe ifọrọwerọ kan pẹlu Roger Federer, odu agbalọọlu Tennis ti gbogbo agbaye mọ gẹgẹ bi odu ti ko lẹlẹgbẹ ninu ere idaraya naa. Burna boy kopa ninu eto ori ayelujara kan ti wọn n pe ni 'GOAT talk' pẹlu Roger Federer nibi ti awọn mejeeji yii ti n fọrọ jomitoro ọrọ nipa ohun tabi ẹni ti wọn gba ni iwoye kaluku wọn gẹgẹbi agba ọjẹ lẹka wọn. Nigba ti asiko to fun awọn mejeeji, iyẹn Burna Boy ati Roger Federer lati sọ awọn akọrin manigbagbe ti wọn mọ yii, ohun ti Burna ti mẹnu ba orukọ Saheed Osupa gẹgẹbi akọrin ti oun gba gẹgẹbi olórín tí òun gbà pé ó ta lẹ́nu jùlọ lágbáyé. "Awọn olorin Fuji ni akọrin manigbagbe ti mo gba fun; bii Saheed Osupa" Nigba to n sọrọ, Osupa ni inu dun pupọ si ohun BurnaBoy sọ nipa rẹ, eyi to tumọ si pe wọn mọ riri orin rẹ kaakiri agbaye. Osupa, ẹni ti ọpọ mọ si Oba Orin ni awọn ọrọ ti Burna Boy sọ nipa oun ṣafihan igbelarugẹ aṣa ati ipa ti orin fuji n ni kaakiri agbaye. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ "Mo mọ riri ohun ti Burna Boy, sọ nipa mi, ti emi naa si jẹ ololufẹ rẹ. Ni apapọ, a n jọ gbe orin ilẹ wa larugẹ fun agbaye ni." Osupa tun wa dupẹ lọwọ Burna Boy ati awọn ololufẹ rẹ, to rọ wọn lati tunbọ ma ṣe atilẹyin fun orin Fuji. "Si OluwaBurna ati awọn ololufẹ rẹ lagbaye, mo dupẹ lọwọ yin fun ifẹ ti ẹ ni si orin Fuji. Mo dupẹ pe ẹ ni igbagbọ ninu orin ilẹ wa." O tẹsiwaju lati sọ pe oun n gbaradi lati lọ sibi ayẹyẹ orin Burna Boy to n bọ lati fi emi imore han. This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagramcookie policyandprivacy policybefore accepting. To view this content choose 'accept and continue'. End of Instagram post Content is not available
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cly6m040r4eo
|
2025-09-27
|
bbc
|
Ballon d'Or 2025: Gbogbo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àmì ẹ̀yẹ náà àtàwọn tó ń díje
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Oni ọjọ Aje, ọjọ kejilelogun, oṣu Kesan an, ọdun 2025 ni ami ẹyẹ bọọlu agbaye, Ballon d'Or yoo waye. Asiko ayẹyẹ naa ni wọn maa n kede awọn agbabọọlu to lamilaaka julọ lagbaye ni ẹka bọọlu afẹsẹgba awọn ọkunrin ati obinrin. Inu gbagede héâtre du Châtelet to wa niluu Paris, lorilẹede France ni ayẹyẹ naa yoo ti waye lalẹ oni. Ọdun 1956 ni wọn bẹrẹ si n ṣe ami ẹyẹ Ballon d'Or lọdọdun, lati igba naa wa ni awọn agbabọọlu to dantọ ti n fakọyọ ninu rẹ. Stanley Matthews lo gba ami ẹyẹ ọhun fun igba akọkọ lẹyin ti iwe iroyin bọọlu afẹsẹgba France sọ ọ di gbajumọ ni nnkan bii ọgọrin ọdun ṣeyin. Lọdun 2018, wọn bẹrẹ ami ẹyẹ naa ni ẹka bọọlu afẹsẹgba ti awọn obinrin. Lọdun 2022 ati 2023, agbabọọlu obinrin ọmọ Naijiria Asisat Oshoala wa lara awọn ti wọn fa kalẹ fun ami ẹyẹ ọhun amo ko pegede. Ki wọn to mọ ẹni ti yoo gba ami ẹyẹ naa, wọn yoo kọkọ ko orukọ agbabọọlu ọgbọn kalẹ. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Awọn ti yoo fa orukọ ọgbọn eeyan ọhun kalẹ ni awọn ọga akọroyin iwe iroyin France Footbal, iwe iroyin L'Equipe atawọn aṣoju ajọ UEFA. Amuyẹ ti wọn yoo lo lati fi fa eeyan kalẹ ni bi wọn ṣe dantọ to laarin ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2025. Awọn agbabọọlu ti wọn si maa n fa kalẹ ni awọn to n kopa ninu liigi ilẹ Yuroopu atawọn agbabọọlu FIFA Club World Cup. Lẹyin naa, akọroyin kọọkan lati orilẹede ọgọrun to n lewaju ninu iwe FIFA yoo fa mẹwaa kalẹ ninu awọn orukọ ọgbọn to wa nilẹ tẹlẹ fun ami ẹyẹ ọhun. Fun ipele ti awọn obinrin, awọn akọroyin lati orilẹede aadọta to n lewaju ninu iwe FIFA ni yoo fa orukọ kalẹ. O ni iye maaki ti wọn maa la kalẹ fun nọmba ti orukọ agbabọọlu ba wa; fun apẹrẹ, agbabọọlu ti orukọ rẹ ba wa ni nọmba akọkọ yoo gba maaki marundinlogun, nigba ti agbabọọlu ti orukọ rẹ ba wa ni nọmba kẹwaa to gbẹyin yoo gba maaki kan ṣoṣo. Agbabọọlu ti maaki rẹ pọ julọ lẹyinorẹyin ni yoo gba ami ẹyẹ ọhun. Iwọnyi ni awọn agbabọọlu to ṣeeṣe ko gba ami ẹyẹ naa lọdun yii ati ẹgbẹ agbabọọlu ti wọn wa. Ballon d'Or ipele ọkunri Ballon d'Or ipele awọn obinrin
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cvgqvwjx268o
|
2025-09-22
|
bbc
|
Peter Rufai wọ káà ilẹ̀ sùn nílùú Eko
|
Wọn ti sin oku oku agbaọjẹ agbabọolu to tun jẹ aṣọle fun ikọ Supoer Eagles fun ọpọ ọdun, Peter Rufai niluu Eko. Ọpọ mọlẹbi, ọrẹ, ojulumọ atawọn akọroyin lo peju sibi eto isinkin ọhun. Ilẹ isinku to wa lagbegbe Ikoyi, niluu Eko ni wọn sin Dodomayana si, gẹgẹ bii ọpọ awọn ololufẹ rẹ ṣe maa n pe e nigba aye rẹ. Ẹni ọdun mọkanlelọgọta ni Rufia ko to dagbere faye lọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun 2025 yii. Oloogbe naa ti kọkọ ṣaisan fun akoko diẹ ko to pada fi aye silẹ nile iwosan kan niluu Eko. Ikọ agbabọọlu Super Eagles lo kọkọ kede iku rẹ loju opo X wọn. Nibi eto isinku naa lawọn ọmọ Rufai ti sọrọ nipa igbe aye rẹ atawọn ohun ti wọn ko le gbagbe nipa rẹ titi lai. Ọkan lara awọn ọmọ rẹ obinrin to ba BBC sọrọ sọ pe o ṣoro lati degbere fun baba oun. O ni "Baba mi jẹ eeyan daadaa, o jẹ ẹni ti ki n gba igbakugba ati ẹni to maa n lọ jẹjẹ tirẹ." "Ni bayii ti baba mi ti jade laye, mo le sọ pe mọ fẹran baba (ati iya mi ti oun naa ti di oloogbe) ni bayii ti emi naa ti di obi. A maa saaro rẹ gidi." Ẹwẹ, ọkan lara awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn jọ gba bọọlu fun Naijiria, Taribo West ti bu ẹnu atẹ lu ijọba Naijiria bi wọn ko ṣe bikita nipa oloogbe ọhun. Taribo West sọ pe o ṣeni laanu pe niṣe lawọn akẹgbẹ rẹ atawọn ẹbi n wa owo kiri lasiko to n ṣaisan. O ni oun ko ni gba ki ọmọ oun gba bọọlu fun Naijiria lai latari aibikita ijọba si awọn to ti gbe ogo rẹ larugẹ nigba aye wọn.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c4gl49q0qp7o
|
2025-08-23
|
bbc
|
Wo àwọn oníjàkadì inú ẹrọ̀fọ̀ tó wá di ògo àgbáyé
|
Ninu ẹrẹ kan ni kampala, ere ijakadi kan a maa waye ti wọn n pe ni Soft ground Wrestling, eyi ti a le tu lede Yoruba si, ijakadi ori ilẹ rirọ. Ko si ina yinrinyinrin eleyi to jẹ ara amuyẹ ere idaraya ijakadi igbalode, awọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin- ti wọn jẹ ọkunrin mejidinlọgọrin ati obinrin mọkandinlọgbọn ni iye – ti n mi ilẹ titi kaakiri agbaye. Okiki wọn si ti kan si de ọdọ awọn alaṣẹ ere idaraya ijakadi igbalode, WWE bii Cody Rhodes ẹni to ṣẹṣẹ jẹjẹ laipẹ gbagede ijakadi kan fun wọn lati ṣe atilẹyin fun wọn.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c2011yl0ly5o
|
2025-05-21
|
bbc
|
"Ogún ọdún rèé tí mo ti ń ta ẹ̀pà, gúgúrú àti dáńkúà fáwọn olólùfẹ̀ẹ́ bọ́ọ́lù Kwara United, kò sí ìlú tí ń kìí tẹ̀lé wọn lọ"
|
Yoruba ni ohun to ba n wu ni, nii pọ lọrọ ẹni, bi obinrin kan to n ta ẹpa, guguru ati dankua yoo se ri ti aje se lo mumu ni aya rẹ. Obinrin ọhun, Oluwatoyin Abdullahi si lo n kiri ẹpa ni ibudo ere idaraya to wa nilu Ilorin nibi ti ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United ti maa n sere idaraya. Ẹpa, guguru ati dankua yii si ni awọn ololufẹ ere bọọlu to n se agbelarugẹ ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United yii maa n fi panu. Koda, ẹpa obinrin naa gbadun lẹnu wọn to bẹẹ, ti ko si ilu ti wọn kii mu obinrin naa lẹyin lọ. Lasiko ti Kwara United wa gba bọọlu nilu Eko, Oluwatoyin tẹle wọn wa, nibi ti BBC Yoruba ti se alabapade rẹ. Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Iya ẹlẹpa naa ni orukọ ti gbogbo eeyan mọ oun si ni iya ẹpa 1. "Awọn ọkunrin agbabọọlu kan lo pade mi, ti wọn si ni se mo le wa maa ta ẹpa fun awọn, mo si ni bẹẹ ni. Wọn ni to ba di ọjọ Satide, ki n gbe ẹpa wa si stadium, mo si gbe lọ. Lati igba naa si ni mo ti maa n ta ẹpa fun wọn ni stadium, koda, ẹni to ba si ra ẹpa to pọ ju ni yoo ra ẹpa ati guguru ogun Naira. Mo ti di nnkan kan naa pẹlu awọn agbabọọlu ati awọn elere idaraya miran to wa ni papa isere idaraya naa, ko si si ibi ti n kii tẹle wọn lọ. Iya ẹlẹpaa naa tun tẹsiwaju pe oun maa n tẹlẹ ikọ agbabọọlu Kwara United kaakiri ilẹ Yoruba, lati se koriya fun wọn, ki n si tun ta ẹpa ati guguru. "Mo ti tẹle wọn lọ si Ibadan, Eko, Osogbo ati Akure. Mo gbọ pe wọn fẹ gba asekagba idije Federation Cup ni Eko, mo si bẹbẹ lati tẹle wọn lọ. Inu mi dun nigba ti mo de Eko, mo ta ẹpa ati guguru daadaa, koda, ko to wọn jẹ, ti wọn si tun n beere si. Mo jo, mo yọ nigba ti Kwara United yege ninu idije naa, inu mi dun pupọ." Oluwatoyin Abdullahi wa gba awọn obinrin ẹgbẹ rẹ ni imọran, ati kekere ati agba, lati mura si isẹ, ki wọn ma ba a di obinrin olobinrin tabi wo oju oloju. "Isẹ ni emi naa n se, mo mura si isẹ mi tori n ko fẹ ki awọn ọmọ mi di ọmọ ọlọmọ. Mo si ti fi isẹ yii kọ awọn ọmọ mi nile ẹkọ, mo tun fi wọn sibi ẹkọsẹ, wọn kọ isẹ. Ọjọ ti inu mi dun julọ ni ọjọ ti gomina ati Yahaya Seriki fun mi lowo pe mo jẹ obinrin to ni akinkanju, mo si n sisẹ ati ololufẹ Kwara United"
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c77ved7nemzo
|
2025-07-11
|
bbc
|
Kókó tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àṣekágbá WAFCON láàrin Super Falcons àti Morocco lónìí
|
Oríṣun àwòrán,Back page pix Pẹpẹyẹ yoo pọmọ lalẹ oni nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ba koju Morocco ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije WAFCON to n lọ lọwọ lorilẹede Morocco. Super Falcons ti wọn ti gba ife ẹyẹ naa fun igba mẹsan an ọtọọtọ fẹ lu Morocco lati gba ife naa fun igba kẹwaa. Atlas Lionesses Morocco ko tii gba ife ẹyẹ WAFCON ri ni ti wọn, ti wọn ba le bori Naijiria lalẹ oni, igba akọkọ ni yoo jẹ ti wọn yoo gba ife ẹyẹ WAFCON. Ko si ẹni to fidirẹmi ninu ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji ninu gbogbo ifẹsẹwọnsẹ marun un ti wọn ti gba ṣaaju ipele aṣekagba yii. Koda, goolu kan ṣoṣo lo ti wọ inu awọn ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ninu idije WAFCON yii. Morocco to n gbalejo idije WAFCON yii lo gba ipo keji lọdun 2022 nigba ti South Africa fagba han wọn gba ife ẹyẹ naa. Niluu Rabat ti wọn ti gba ifẹsẹwọnsẹ aṣakagba tọdun 2022 naa ni ere bọọlu ti alẹ oni yoo ti waye. O nira lati sọ ni pato ẹni ti yoo bori ninu ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji tori awọn mejeeji naa lo tiraka wọ ipele aṣekagba. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Pẹnariti ni Morocco gba ti wọn fi lu Ghana wọ ipele aṣekagba, nigba ti Naijiria ṣiṣẹ takun takun ki wọn to ri South Africa lu ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba. Amọ, agbabọọlu adilemu fun Super Falcons, Michelle Alozie, sọ pe Falcons ti ṣetan lati gba ife ẹyẹ naa fun igba kẹwaa eyi ti wọn n pe adape rẹ ni ''mission X.'' Alozie ni nnkan ẹyọkan to wa lọkan awọn ni pe kawọn gba ife ẹyẹ WAFCON fun igba kẹwaa. $1m owo to to bii biliọnu kan abọ naira ni ẹni to ba gba ife ẹyẹ naa yoo gba lọọle. Oríṣun àwòrán,CAF Agbabọọlu Super Falcons tẹlẹ ri, Desire Oparanozie, ti sọ fun BBC wi pe awọn ẹgbẹ agbabọọlu Morocco kii kaarẹ titi ti ere bọọlu yoo fi pari. ''Wọn ti fakọyọ gan an ninu idije WAFCON yii. Ni gbogbo igba ni wọn maa n gbeja ko awọn alatako wọn, eyi to jẹ nnkan to dara lati ṣe,'' Oparanozie lo sọ bẹẹ. Jorge Vilda to gba ife ẹyẹ agbaye pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu obinrin Spain ni akọnimọọgba Morocco. Awuyewuye wa lori iyansipo Vilda tori bi o ṣe kuro ni ẹgbẹ agbabọọlu Spain lẹyin iṣẹlẹ to ṣẹlẹ nigba ti aarẹ ajọ ere bọọlu lorilẹede Spain, Luis Rubiales, fẹnu ko agbabọọlu Jenni Hermoso lẹnu lẹyin ti wọn gba ife ẹyẹ agbaye tan lọdun 2023. Ẹsun ihuwa ipa fun ibalopọ ni wọn fi kan Rubiales, o si sanwo itanran. Amọ, Vilda jare ẹsun iwa ipa ti wọn fi kan oun. Ọrọ yii si wa lọkan awọn ololufẹ Atlas Lionesses kan bo tilẹ jẹ pe Vilda le gba ife ẹyẹ WAFCON akọkọ iruẹ fun Morocco. Oríṣun àwòrán,Backpage px Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ko sọ nnkan mii ju pe awọn fẹ gba ife ẹyẹ WAFCON fun igba kẹwaa lọ. Ajọ NFF to n ri si ere bọọlu ni Naijiria ti sọ ṣaaju ki idije WAFCON to bẹrẹ wi pe ''Mission X'' eyi to tumọ si gbigba ife ẹyẹ naa fun igba kẹwaa ni afojusun Super Falcons ninu idije WAFCON tọdun yii. Akọnimọọgba Naijiria, Justin Madugu, ti ṣe atunṣe lori Super Falcons debi wi pe wọn duro daadaa lẹyin ati laarin gbungbun. Bakan naa si ni awọn agbabọọlu iwaju ti Esther Okoronkwo n dari wọn naa ti mọwọ ara wọn. Lara nnkan to le jẹ anfaani fun Super Falcons ni pe agbabọọlu mẹsan an ọtọọtọ lo ti gba goolu sawọn fun Naijiria ninu idije WAFCON yii. ''Abuda wa ni lati ja fita fita ki a si bori ninu gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ti a ba n gba,'' Okoronkwo lo sọ bẹẹ fun BBC. Aṣọle Super Falcons, Chiamaka Nnadozie, ko tii ri iṣẹ ṣe dabi alara ninu idije WAFCON yii. Goolu kan ṣoṣo to tọwọ rẹ wọle naa ni pẹnariti ti South Africa gba ni ipele to kangun si aṣekagba. Oparanozie ni Super Falcons yoo gbẹsan bi Morocco ṣe lu wọn ninu idije WAFCON ọdun 2022 nibi ti rẹfiri ti le agbabọọlu Naijiria meji jade ki Atlas Lionesses to fi pẹnariti bori wọ ipele aṣekagba.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/czr6g3vr21zo
|
2025-07-26
|
bbc
|
Juliet Ukah, obìnrin ọlọ́pàá tó ń fi ẹ̀ṣẹ́ dá bírà lágbáyé
|
Ọlọpaa Naijiria ni arabinrin Juliet Ukah ṣugbọn ti o tun n ja ẹṣẹ pẹlu. Ere idaraya afẹṣẹ ati ipa ja ti awọn oyinbo n pe ni Mixed Martial Art ni o yan laayo lẹnu iṣẹ rẹ. Juliet kọkọ gbiyanju ere sisa ṣugbọn ti ko ṣ'ẹnuure fun un ki o to ya bara si ẹṣẹ ati ipa jija. "Nigba ti mo wa ni kekere, mo maa n wo awọn eekan bii Ajunwa ati Sunday Bada, ti wọn jẹ ọlọpaa ti wọn si tun jẹ elere idaraya. Eyi jẹ iwuri fun mi to si jẹ ki emi naa sọ pe bi awọn eeyan wọnyi ba le ṣe e, emi naa a le ṣe e." Ija mẹfa lo ti ti kopa ninu rẹ, mẹfẹẹfa lo si ti bori. O ni oun n lo irinajo oun lati ṣe koriya fun awọn obinrin ki wọn lee maa gbaradi daadaa fun awọn ọna lati daabo bo ara wọn lọwọ ewu ati ipalara.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c5y0ngj9jyvo
|
2025-07-21
|
bbc
|
Fifa Club World Cup: Báyìí ni ìdíje ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù káàkiri àgbáyé yóò ṣe lọ
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Ní òpin ọ̀sẹ̀ yìí ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àgbáyé tàwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù yóò bẹ̀rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù méjìlélọ́gbọ̀n tó fi mọ́ Real Madrid, Manchester City àti Chelsea ló ń gbéra lọ sí Amẹ́ríkà láti kópa níbi ìdíje ọlọ́sẹ̀ mẹ́rin náà. Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Al Ahly ti Egypt, Mamelodi Sundowns ti South Africa, Wydad Casablanca ti Morocco àti Esperance ní Tunisia wà lára àwọn tó máa kópa. Ṣáájú àsìkò yìí, ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù méje péré ló máa ń kópa níbi ìdíje ọlọ́dọọdún náà àmọ́ tí wọ́n ti fààyè gba àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù láti ẹkùn mẹ́fà ti FIFA báyìí, tí ìdíje náà yóò sì máa wáyé ní ẹ̀ẹ̀kan láàárín ọdún mẹ́rin. Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìdíje náà àtàwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó ń kópa níbẹ̀. Oríṣun àwòrán,Getty Images Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹfà ni ìdíje ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Club World Cup náà máa bẹ̀rẹ̀ tó sì máa wá sópin lọ́jọ́ Kẹtàlá, oṣù Keje. Aago kan òru ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ máa wáyé láàárín ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Inter Miami tí Lionel Messi ń gbá fún àti Al Ahly tó jẹ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Egypt ní pápá ìṣeré Hard Rock Stadium ní Miami. Ní pápá ìṣeré MetLife Stadium tó wà ní New Jersey ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí wọ́n fi máa káàdí ìdíje náà nílẹ̀ yóò ti wáyé. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Oríṣun àwòrán,Getty Images Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù méjìlélọ́gbọ̀n, tó fi mọ́ méjì láti Premier League - Manchester City àti Chelsea - ń lọ sí America fún ìdíje ọlọ́sẹ̀ mẹ́rin náà. Àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ńlá míì tó ń kópa níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà ni Real Madrid, Bayern Munich àti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Paris Saint-Germain, PSG tó gbégbá orókè níbi ìdíje Champions League tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó ń kópa ní ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan: Ìsọ̀rí A:Palmeiras, FC Porto, Al Ahly, Inter Miami Ìsọ̀rí B: Paris St-Germain, Atletico Madrid, Botafogo, Seattle Sounders Ìsọ̀rí C: Bayern Munich, Auckland City, Boca Juniors, Benfica Ìsọ̀rí D: Flamengo, Esperance Sportive de Tunis, Chelsea, Los Angeles FC Ìsọ̀rí E: River Plate, Urawa Red Diamonds, Monterrey, Inter Milan Ìsọ̀rí F: Fluminense, Borussia Dortmund, Ulsan, Mamelodi Sundowns Ìsọ̀rí G: Manchester City, Wydad, Al Ain, Juventus Ìsọ̀rí H: Real Madrid, Al Hilal, Pachuca, Salzburg Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Ipele àkọ́kọ́ Ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹfà Ìsọ̀rí A: Al Ahly àti Inter Miami ní pápá ìṣeré Hard Rock Stadium, Miami; aago kan òru Ìsọ̀rí C: Bayern Munich àti Auckland City ní pápá ìṣeré TQL Stadium, Cincinnati; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ Ìsọ̀rí B: PSG àti Atletico Madrid ní pápá ìṣeré Rose Bowl Stadium, Los Angeles; aago mẹ́jọ alẹ́ Ìsọ̀rí A: Palmeiras àti Porto ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago mọ́kànlá alẹ́ Ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Kẹfà Ìsọ̀rí B:Botafogo àti Seattle Sounders ní pápá ìṣeré Lumen Field, Seattle; aago mẹ́ta òru Ìsọ̀rí D: Chelsea àti Los Angeles FC ní pápá ìṣeré Mercedes-Benz Stadium, Atlanta; aago mẹ́jọ alẹ́ Ìsọ̀rí C: Boca Juniors àti Benfica ní pápá ìṣeré Hard Rock Stadium, Miami; aago mọ́kànlá alẹ́ Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kẹfà Ìsọ̀rí D: Flamengo àti Esperance de Tunis ní pápá ìṣeré Lincoln Financial Field, Philadelphia; aago méji òru Ìsọ̀rí F: Fluminense àti Borussia Dortmund ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ Ìsọ̀rí E: River Plate àti Urawa Red Diamonds ní pápá ìṣeré Lumen Field, Seattle; aago mẹ́jọ alẹ́ Ìsọ̀rí F:Ulsan HD àti Mamelodi Sundowns ní pápá ìṣeré Inter&Co Stadium, Orlando; aago mọ́kànlá alẹ́ Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Kẹfà Ìsọ̀rí G: Al Ain àti Juventus ní pápá ìṣeré Audi Field, Washington, D.C; aago méjì òru Ìsọ̀rí A: Palmeiras àti Al Ahly ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ Ìsọ̀rí A: Inter Miami àti Porto ní pápá ìṣeré Mercedes-Benz Stadium, Atlanta; aago mẹ́jọ alẹ́ Ìsọ̀rí B: Seattle Sounders àti Atletico Madrid ní pápá ìṣeré Lumen Field, Seattle; aago mẹ́jọ alẹ́ Ìsọ̀rí B: PSG àti Botafogo ní pápá ìṣeré Rose Bowl Stadium, Los Angeles; aago mọ́kànlá alẹ́ Ọjọ́ Ẹtì, ogúnjọ́, oṣù Kẹfà Ìsọ̀rí C: Benfica àti Auckland City ní pápá ìṣeré Inter&Co Stadium, Orlando; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ Ìsọ̀rí D: Flamengo àti Chelsea ní pápá ìṣeré Lincoln Financial Field, Philadelphia; aago méje ìrọ̀lẹ́ Ìsọ̀rí D: Los Angeles FC àti Esperance de Tunis ní pápá ìṣeré GEODIS Park, Nashville; ní aago mẹ́wàá alẹ́ Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kẹfà Ìsọ̀rí C: Bayern Munich vs Boca Juniors ní pápá ìṣeré Hard Rock Stadium, Miami; aago méjì òru Ìsọ̀rí F: Mamelodi Sundowns vs Bosurissa Dortmund ní pápá ìṣeré TQL Stadium, Cincinnati; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ Ìsọ̀rí E: Inter Milan vs Urawa Red Diamonds ní pápá ìṣeré Lumen Field, Seattle; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ Ìsọ̀rí F: Fluminense vs Ulsan HD ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago mọ́kànlá alẹ́ Ìsọ̀rí E: River Plate vs Monterrey ní pápá ìṣeré Rose Bowl Stadium, Los Angeles; aago mọ́kànlá alẹ́ Ìsọ̀rí A: Porto àti Al Ahly ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago méjì òru Ìsọ̀rí C: Auckland City àti Boca Juniors ní pápá ìṣeré GEODIS Park, Nashville; aago méje ìrọ̀lẹ́ Ìsọ̀rí C: Benfica àti Bayern Munich ní pápá ìṣeré Bank of America Stadium, Charlotte; aago mẹ́jọ alẹ́ Ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà Ìsọ̀rí D: Los Angeles FC àti Flamengo ní pápá ìṣeré Camping World Stadium, Orlando; aago méjì òru Ìsọ̀rí D: Esperance de Tunis àti Chelsea ní pápá ìṣeré Lincoln Financial Field, Philadelphia; aago méjì òru Ìsọ̀rí F: Borussia Dortmund àti Ulsan HD ní pápá ìṣeré TQL Stadium, Cincinnati; aago mẹ́jọ alẹ́ Ìsọ̀rí F: Mamelodi Sundowns àti Fluminense ní pápá ìṣeré Hard Rock Stadium, Miami; aago mẹ́jọ alẹ́ Ìsọ̀rí E: Inter Milan àti River Plate ní pápá ìṣeré Lumen Field, Seattle; aago mọ́kànlá alẹ́ Ìsọ̀rí E: Urawa Red Diamonds àti Monterrey ní pápá ìṣeré Rose Bowl Stadium, Los Angeles; aago mọ́kànlá alẹ́ Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà Ìsọ̀rí G: Juventus àti Man City ní pápá ìṣeré Camping World Stadium, Orlando; aago mẹ́jọ alẹ́ Ìsọ̀rí G: Wydad AC àti Al Ain ní pápá ìṣeré Audi Field, Washington, D.C; aago mẹ́jọ alẹ́ Ìsọ̀rí H:Al Hilal àti CF Pachuca ní pápá ìṣeré GEODIS Park, Nashville; aago kan òru Ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà Ìsọ̀rí H: FC Salzberg àti Real Madrid ní pápá ìṣeré Lincoln Financial Field, Philadelphia; kick off 1am Ìsọ̀rí H: Al Hilal vs CF Pachuca ní pápá ìṣeré GEODIS Park, Nashville; aago kan òru Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 49:Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí A àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí B ní pápá ìṣeré Lincoln Financial Field, Philadelphia; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 50: Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí C àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí D ní pápá ìṣeré Bank of America Stadium, Charlotte; aago mẹ́sàn-án alẹ́ Ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 51: Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí B àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí A ní pápá ìṣeré Mercedes-Benz Stadium, Atlanta; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 52: Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí D àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí C ní pápá ìṣeré Hard Rock Stadium, Miami; aago mẹ́sàn-án alẹ́ Ọjọ́ Ajé ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kẹfà Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 53: Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí E àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí F ní pápá ìṣeré Bank of America Stadium, Charlotte; aago mẹ́jọ alẹ́ Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kìíní, oṣù Keje Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 54: Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí G àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí H ní pápá ìṣeré Camping World Stadium, Orlando; aago méjì òru Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 55: Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí H àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí G ní pápá ìṣeré Hard Rock Stadium, Miami; aago mẹ́jọ alẹ́ Ọjọ́rú, ọjọ́ Kejì, oṣù Keje Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 56: Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí F àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí E ní pápá ìṣeré Mercedes-Benz Stadium, Atlanta; aago méji òru Ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Keje Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 57: Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 53 àti Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 54 ní pápá ìṣeré Camping World Stadium, Orlando; aago mẹ́jọ alẹ́ Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Keje Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 58: Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 49 àti Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 50 ní pápá ìṣeré Lincoln Financial Field, Philadelphia; aago méjì òru Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 59: Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 51 àti Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 52 ní pápá ìṣeré Mercedes-Benz Stadium, Atlanta; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 60: Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 55 àti Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 56 ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago mẹ́sàn-án alẹ́ Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Keje Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 61: Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 57 àti Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 58 ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago mẹ́jọ alẹ́ Ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Keje Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 62: Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 59 àti Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 60 ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago mẹ́jọ alẹ́ Ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Keje Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 63: Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 61 àti Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 62 ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago mẹ́jọ alẹ́
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cp8d0reppvvo
|
2025-06-14
|
bbc
|
Ohun tó rọ̀ mọ́ bí Peter Rufai ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ́ orúkọ ìnagijẹ 'Dodo Mayana'
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Ọjọ ti a ba ku la a dere, eeyan o ṣunwọn laaye, awọn ọmọ Naijiria atawọn ololufẹ bọọlu kaakiri agbaye si n sẹ idaro agbaọjẹ agbabọọlu Super Eagles Naijiria, Peter Rufai, to jade laye l'Ọjọbọ ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kẹta oṣu Keje ọdun yii. Ọkan gboogi ninu awọn asọle fun ẹgbẹ agbaboolu Naijiria, Super Eagles, to tun jẹ olokiki ninu ere bọọlu ni ilẹ Afirika ni Peter Rufai jẹ nigba aye rẹ. Peter Rufai ni okiki ninu ere bọọlu debi wi pe awọn ololufẹ rẹ fun un ni orukọ inagijẹ ti wọn n pe ni 'Dodo Mayana.'' Nigba kugba to ba n rin lọ loju titi papaa julọ niluu Eko to jẹ ibugbe rẹ lawọn ololufẹ rẹ maa n pe e ni ''Dodo Mayana'' ti oun naa si maa n jẹ wọn. Amọ, ta a lo sọ aṣọle Super Eagles ni inagijẹ Dodo Mayana, bawo lorukọ naa ṣe di nnkan tawọn eeyan fi n pe e? Nigba aye rẹ, Peter Rufai, funra rẹ ṣalaye bi orukọ Dodo Mayana ṣe waye gan an. Nigba ti o n sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu awọn akọroyin, Rufai ṣalaye pe ''orukọ inagijẹ Dodo Mayana waye lati ara ibaṣepọ mi pẹlu awọn goli ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria to ṣiwaju mi bii Peter Fregene, Best Ogedengbe ati Emmanuel Okala. Peter Fregene maa n pe mi ni Dodo nigba kugba ti mo ba wa ninu yara pẹlu rẹ. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Awọn agbabọọlu yii lo wa lode nigba naa ninu ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria nigba ti mo darapọ mọ wọn lọdun 1981. Bayii ni mo ṣe lanfaani lati sun mọ Peter Fregene, laaraarọ ni mo maa n ko bata awọn goli mẹtẹẹta lọ sinu ọkọ ti mo si maa n fun wọn ti wọn ba ti fẹ wọ ọ. Koda, mo maa n fẹ ko aṣọ ti wọn ba wọ fi ṣe igbaradi ati bata lati nu un lẹyin ti wọn ba ti ṣetan ṣugbọn wọn maa n sọ fun mi pe alagbafọ lo maa fọ aṣọ naa wi pe ki n maa ṣe iyọnu. Gbogbo nnkan yii ni mo maa n ṣe lasiko ti mo wa pẹlu wọn nibi ti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ti n ṣe igbaradi.'' Rufai sọ pe lati igba naa ni Fregene ti bẹrẹ sii pe oun ni Dodo tori bi oun ṣe sun mọ an toun si n wo awokọṣe rẹ ninu ile mimu. Oloogbe Rufai ni kẹrẹ kẹrẹ lawọn jọ lọ si orilẹede Portugal labẹ aṣẹ akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria nigba naa, Otto Gloria. Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Aṣọle Naijiria tẹlẹ ni lọdun 1982 lawọn lọ ṣe igbaradi lorilẹede Portugal nibi ti Peter Fregene ti kọkọ bọ soju ile. O ni lẹyin ti Fregene ṣetan ni Best Ogedengbe bọ soju ile fun igbaradi tiẹ naa. ''Lẹyin naa lo kan mi ti emi naa si lanfaani lati bọ soju ile, ṣugbọn bọọlu bi ọgbọn ni akọnimọọgba wa n gba soju ile nigba ti emi bọ soju ile. Gbogbo bọọlu ọgbọn yii si ni mo n gbiyanju lati mu bi Otto Gloria ṣe gbawọn si mi. Gbogbo nnkan ti mo ti kọ lọdọ Peter Fregene ati Best Ogedengbe ni mo n lo lati mu awọn bọọlu ti akọnimọọgba wa n gba si mi. Tori awọn ti wọn ti n kọ mi ni ile mimu naa lawọn eeyan yii. Amọ, awọn oluworan fẹran bi mo ṣe n lọ fun gbogbo bọọlu ti wọn n gba si mi loju ile. Koda, ariwo sọ nigba ti wọn fọn feere wi pe a ti pari igbaradi, awọn oluworan ni ka tẹsiwaju tori awọn n gbadun mi loju ile. Mi o tiẹ kọkọ mọ pe nitori mi lawọn oluworan fi n pariwo, ṣa deedee ni mo gbọ ti ẹnikan sọ pe ''Dodo,'' ti o si nawọ soke. Bayii ni mo ri ọpọ eeyan ti wọn n na ọwọ soke ti wọn si n pariwo. Lẹyin naa ni mo fi ọwọ sọ fun wọn pe a o tẹsiwaju ere bọọlu igbaradi ti a n ṣe lọla. Ni wọn ba sọ pe 'amaya' ti emi naa si dahun pe 'Dodo', wọn sọ pe 'Dodo amaya'' emi naa ni 'amaya dodo.'' Amaya ni ede Portuguese tumọ si ọla, nigba ti Dodo tumọ si nnkan ti eeyan yoo ri lọla. Bayii lawọn ololufẹ mi ṣe bẹrẹ si ni ki mi pe ''Dodo Amaya ti emi si maa n dahun pe ''Amayana Dodo.'' Oloogbe Rufai sọ pe awọn ololufẹ oun fẹran lati maa pe oun ni Dodo Mayana gan an ju Peter Rufai lọ. Ki Eledua ko dẹ ilẹ fun ẹni ire to lọ.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/clyz9n3l0kno
|
2025-07-05
|
bbc
|
Falcons Naijiria ń kojú South Africa, Morocco ń kojú Ghana lábala tó kángun sí àṣekágbá ìdíje WAFCON 2024
|
Oríṣun àwòrán,Confederation of African Football Lọjọ Iṣẹgun, ifẹsẹwọnsẹ alagbara meji yoo waye labala to kangun si aṣekagba ninu idije ere bọọlu awọn obinrin ilẹ Africa, WAFCON 2024 to n lọ lọwọ lorilẹede Morocco. Akọkọ ni ti orilẹede wa Naijiria to ti gba ife ẹyẹ naa nigba mẹsan-an. Naijiria yoo maa wa a ko pẹlu orilẹeede South Africa ti ife ẹyẹ naa wa lọwọ wọn lọwọlọwọ, ni Casablanca, aago marun-un irọlẹ oni ni yoo waye lọjọ Iṣẹgun. Ikeji si ni ti Morocco ti yoo maa koju Ghana, aago mẹjọ ni yoo waye. O ṣee ṣe ki iru ohun to ṣẹlẹ nipele aṣekagba idije ọdun 2022 tun waye, nibi ti ẹgbẹ agbabọọlu Banyana Banyana ti fi agba han Atlas Lionesses, ami ayo meji si ẹyọkan, nigba to ba di irọlẹ Satide. Fun Morocco ati Ghana, eyi yoo jẹ igba akọkọ ti wọn yoo jawe olubori, nigba ti apapọ ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Africa (Confederation of African Football) ti ṣe afikun owo ti ẹni to ba jawe olubori yoo gba si miliọnu kan dọla ($1m), wọn si ti ṣiṣọ loju ife ẹyẹ tuntun pẹlu. Oríṣun àwòrán,Backpage Pix Ni itẹsiwaju idije naa, orilẹede Naijiria fitan balẹ nigba ti wọn fi agba han Zambia pẹlu ami ayo marun-un si odo ni Casablanca . Ẹlẹsẹ ayo Super Falcons tẹlẹ, Desire Oparanozie, ṣapejuwe bi wọn ṣe gba bọọlu sawọn bi eyi ti ẹnikẹni ko rokan. O ni ṣugbọn oun ri i iyatọ nla ninu ijade wọn. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion "Awọn agbabọọlu Super Falcons maa n ni erongba lati gbegba oroke, ifẹṣẹwọnsẹ nla-nla ni wọn si ti maa n kopa." Oparanozie lo ṣalaye bẹẹ fun Sportsworld lẹka iroyin agbaye BBC. O ni wọn fi han pe Naijiria ni agba nilẹẹ Africa. Ohun to ku bayii ni ki wọn ri i daju pe ọna ti wọn n gba na awọn yoku ni koboko ami ayo ko bajẹ, nigba ti wọn ba pada si papa iṣere Larbi Zaouli . " Afojusun wa ni lati maa tẹsiwaju ninu erongba aṣeyọri, awọn idije nla bayii lo maa n tọka bi ilẹ Africa ṣe jẹ gan-an." Amule fun Super Falcons, Chiamaka Nnadozie, lo sọ bẹẹ fun BBC World Service. Ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu South Africa ni igbagbọ wa pe yoo tun lagbara . South Africa to fagba han Senegal pẹlu ami ayo mẹrin si odo, nigba ti wọn fi pẹnariti yanju ifẹsẹwọnsẹ to kọkọ pari si odo. Ifẹsẹwọnsẹ naa mu South Africa lomi, pẹlu bi wọn ko ṣe ni ju ọjọ kan lọ lati ṣarajọ pada, ki wọn si tun rin irin ajo lati Berkane. Ṣugbọn akọnimọọgba Banyana Banyana, Desiree Ellis, sọ pe awọn agbabọọlu oun ko ni i fi iyẹn kẹwọ. Naijiria fagba han South Africa ninu idije aṣekagba WAFCON ni 2000 ati 2018, ṣugbọn orilẹede naa lu Naijiria ni ami ayo meji si ẹyọkan lọdun mẹta sẹyin. " Awọn ni ife ẹyẹ naa wa lọwọ wọn lọwọ, iṣẹ pọ lọwọ wọn lati ma jẹ ko bọ" Oparanozie lo sọ bẹẹ. "Ifigagbaga yii ti wa nilẹ fun ọpọlọpọ ọdun, idije aṣekagba yii yoo si lagbara gan-an fun Naijiria. " South Africa nikan lo jọ ilu to le dena Naijiria lati ma jawe olubori." Bẹẹ ni Oparanozie wi. Oríṣun àwòrán,Backpage Pix Lẹyin ti wọn koju Mali pẹlu ami ayo mẹta si ẹyọkan, ikọ agbabọọlu to n gbalejo idije yii naa n foju sọna lati de aṣekagba. Bẹẹ ni wọn n reti ero rẹpẹtẹ ni papa iṣere wọn to le gba eeyan ẹgbẹrun mọkanlelogun, (21,000) ti wọn yoo maa mu ori awọn ikọ agbabọọlu Atlas Lionesses wu. " Awọn eeyan to ti wa si papa iṣere ti ran wa lọwọ gan-an lati ibẹrẹ. Bo ṣe maa n ri niyẹn, awa naa si lero pe a maa de ipele aṣekagba." Akọnimọọgba ,Jorge Vilda lo ṣalaye bẹẹ. Bakan naa ni orilẹede Ghana ti gbaradi fun ipele kẹrin to gbẹyin fun igba akọkọ lati 2016, lẹyin ti wọn fi pẹnariti bori Algeria ninu idije to kọkọ ba òdo de fun awọn mejeeji ni Satide. Akọnimọọgba won, Kim Lars Bjorkegren, ṣalaye pe apọju ero ko le da ẹru ba ikọ oun. "Ero rẹpẹtẹ le ran ọ lọwọ to ba ja si ọjọ ire fun eeyan, ṣugbọn mo mọ pe idakeji naa le ṣẹlẹ pẹlu." Kim lo sọ bẹẹ.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c0m8e383rk7o
|
2025-07-22
|
bbc
|
Irú kan ùn! Anfaani Adugbo yóò gbálejò Oriogbade ní ìbẹ̀rẹ̀ sáà Premier League tuntun
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Saa idije Premier League tuntun yoo gbinaya nigba to ba bẹrẹ loṣu Kẹjọ ọdun yii, ikọ agbabọọlu Manchester United tawọn eeyan mọ Anfaani Adugbo ni yoo gbalejo Arsenal ti inagijẹ wọn n jẹ Oriogbade. Ọjọ Kẹtadinlogun oṣu Kẹjọ ni ifẹsẹwọnsẹ yii yoo waye ni papa iṣere Old Trafford lẹyin ti Liverpool to gba ife ẹyẹ naa ba ti kọkọ ṣide saa idije EPL tuntun ọhun pẹlu Bournemouth lọjọ Ẹti ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ kan naa. Akọnimọọgba Liverpool, Arne Slot, to gba ife ẹyẹ EPL ni saa akọkọ rẹ ninu idije Premier League yoo tun gbiyanju ati tun ife ẹyẹ naa gba ni saa bọọlu tuntun yii. Ikọ agbabọọlu Man City ti Pep Guardiola n dari yoo bẹrẹ saa bọọlu tuntun tiwọn nigba ti wọn ba koju Wolverhampton Wanderers ni papa iṣere Molineux. Lọjọ Aiku ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹjọ naa ni ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea tawọn eeyan mọ si Aniyikaye yoo maa wa a ko pẹlu Crystal Palace ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ wọn ni saa bọọlu EPL 2025/2026. Ẹgbẹ agbabọọlu Everton to jẹ orogun Liverpool yoo maa ta kangbọn pẹlu ikọ Leeds to ṣẹṣẹ pada wa si idije Premier League lẹyin ti wọn ti fidirẹmi lọ si ipele ''Championship'' tẹlẹ. Sunderland tawọn naa ṣẹṣẹ pada si idije Premier League fun igba akọkọ lati ọdun 2017 ti wọn ti fidirẹmi wọ ipele ''Championship"'yoo gbalejo ikọ agbabọọlu West Ham. Akọnimọọgba Tottenham tuntun, Thomas Frank, yoo dari ẹgbẹ agbabọọlu naa fun igba akọkọ ninu idije Premier League nigba ti wọn yoo maa na tan bi owo pẹlu Burnley to ṣẹṣẹ pada si idije Premier League. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ Liverpool v Bournemouth Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹjọ Aston Villa v Newcastle Brighton v Fulham Nottingham Forest v Brentford Sunderland v West Ham Tottenham v Burnley Wolverhampton Wanderers v Manchester City Ọjọ Aiku, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹjọ Chelsea v Crystal Palace Manchester United v Arsenal Ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogun Leeds v Everton Ifẹsẹwọnsẹ okoo din ni irinwo ni ogun ẹgbẹ agbabọọlu yoo gba fun ọsẹ mẹtalelọgbọn ni saa bọọlu yii. Ọjọ kẹrinlelogun oṣu Karun un 2026 ni saa idije Premier League tuntun yii yoo pari.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c3vdklyrw79o
|
2025-06-18
|
bbc
|
Diogo Jota, òdú agbábọ́ọ̀lù Liverpool jade láyé nínú ìjàmbá ọkọ́; Ronaldo, Liverpool ń dárò
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Gbajumọ̀ agbabọọlu ọmọ orilẹede Portugal to tun n gba bọọlu jẹun ni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Dogo Jota ti jade laye. Diogo Jota jade laye ninu iṣẹlẹ ijamba mọto kan to waye ni ilu Zamora lorilẹede Spain gẹgẹbi Guardia Civil 'se fi idi rẹ mulẹ fun BBC. Iroyin naa tun fi id rẹ mulẹ pe oun ati aburo rẹ lo ku ninu ijamba ọkọ naa. Taya ọkọ Lamborghini to n wa lo fọ lori ere nigba to fẹ ya ọkọ kan silẹ loju popo. Ọkọ naa gbina, awọn mejeeji si gba ibẹ ku. Iṣẹlẹ iku Jota ninu ijamba ọkọ naa waye lẹyin ọsẹ meji to ṣe igbeyawo pẹlu ololufẹ rẹ, Rute Cardoso ni ọjọ kejilelogun oṣu kẹfa ọdun 2025. Oríṣun àwòrán,Reuters Aarẹ ajọ ere bọọlu lorilẹede Portugal, Pedro Proenca salaye ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi sita pe "iporuru ọlan ti ko ṣee fẹnusọ ni iku Diogo Jota ati aburo rẹ, Andre Silva ni owurọ yii lorilẹede Spain jẹ fun ajọ bọlu lorilẹede Portugal ati gbogbo awọn ololufẹ ere bọọlu lorilẹede naa." O din diẹ ni ifẹsẹwọnsẹ aadọta ti Jota ti gba fun Portugal ki o to jade laye. Oríṣun àwòrán,Getty Images Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool pẹlu ti ṣe idaro Diogo Jota ninu atẹjade kan ti wọn fi sita ninu eyi ti ọn ti ṣe apejuwe iku agbabọọlu naa gẹgẹ bi ọfọ nla fun awọn, awọn ololfẹ Liverpool, ẹbi ati ọrẹ rẹ. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool ni awọn yoo ṣi danu duro naa lati le bu ọwọ fun awọn ẹbi rẹ lasiko ọfọ nla to ṣẹ wọn yii. Oríṣun àwòrán,Getty Images Roanldo, eekan agbabọọlu lagbaye to tun jẹ Balogun fun ikọ agbaọọlu orilẹede Portugal ṣalaye ninu iroyin kan to fi si ori ayelujara pe: "eyi ko ye mi rara. Sebi laipẹ yii ni gbogbo wa pejọ si ikọ agbabọọlu orilẹede wa, ti o si tun jẹ wi pe o ṣẹṣẹ ṣe igbeyawo.Ronaldo wa ran'sẹ ibanikẹdun rẹ si awọn ẹbi Jota, iyawo rẹ atawọn ọmọ rẹ to fi silẹ' "Mo mọ pe o ko ni fi wọn silẹ. Sunre, Diogo ati Andre. A o ṣafẹri yin."
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/ckg345n9pvno
|
2025-07-03
|
bbc
|
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
|
Àwọn ológun wà níbí lóòótọ́, ṣùgbọ́n kò sí ààbò fún wa" Awọn eeyan ti Boko Haram le nile ni Borno lo sọ bẹẹ BBC ṣatupalẹ bi ikọ naa ṣe ti fi kun ikọlu ati idaamu awọn eeyan leralera lapa Ariwa Ila-Oorun Naijiria. Akọsilẹ UNDP sọ pe o le ni eeyan ẹgbẹrun marundinlogoji ( 35,000) ti Boko Haram ti pa laaarin 2009 si 2024. ,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,, Dakun, ṣe lootọ ni Taiwo Awoniyi wọ coma Bẹẹ ni, agbabọọlu ọmọ Naijiria naa wa lẹsẹ kan aye-ẹsẹ kan ọrun lẹyin iṣe abẹ akọkọ. Ọjọ Aiku ni Awoniyi kọlu opo ojule lasiko ifẹsẹwọnsẹ Nottingham Forest ati ẹgbẹ Leicester. BBC gbọ pe ifun Awoniyi bẹ lasiko to kọlu opo ojule naa Bawo wa ni bayii? ,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,, Ojú ọ̀nà Akure sí Ọgbagi di pàkúté ikú, ẹmí arìnrìnàjò ń bọ́ púpọ̀ torí ìjàmbá ọkọ̀, ìkọlù adigunjalè àtàwọn ajínigbé" Ọpọ eeyan lo tun n padanu ẹmi loju ọna ijọba apapọ yii latari koto giriwo. BBC Yoruba de ojú ona náà, fun ẹkunrẹrẹ
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c0lngy6dx81o
|
2025-05-14
|
bbc
|
Peter Rufai papòdà, ohun ojú wa rí rèé ní ilé rẹ̀ lẹ́yìn ikú rẹ̀.
|
Agba ọjẹ goli fun ikọ agbabọọlu Super Eagles, nigba kan ri, Peter Rufai jade laye l'Ọjọbọ, ọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun 2025. Rufai, ti ọpọ eeyan mọ si Dodomayana, jade laye ni ẹni ọdun mọkanlelọgọta. BBC ṣe abẹwo si ile rẹ to wa ni ilu Eko nibi ti awọn eeyan ati ojulumọ ti n ṣe abẹwo ẹyẹ ikẹyin fun un ni ile rẹ.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cvg8k4g1rzpo
|
2025-07-05
|
bbc
|
Lamine Yamal àti agbábọ́ọ̀lù mẹ́sàn án tó lówó lórí jùlọ lágbàáyé ní 2025
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Idi iṣẹ ẹni la a mọni lọlẹ, bi ade ogo ba si ti wa lori iyanju ẹda, onitọhun yoo tayọ laaarin ẹgbẹ rẹ. Bo ṣe ri ni awọn ẹka iṣẹ gbogbo ree, bẹẹ naa lo ri lawujọ awọn agbabọọlu kaakiri agbaye. Wọnyi lawọn to ta yọ julọ bayii ninu awọn agbabọọlu ni ọdun 2025, ati iye ti wọn n ko le wọn lori. Bi ikọ agbabọọlu kan yoo ba ra ọdọkunrin nni to n gba bọọlu fun ikọ Barcelona, Lamine Yamal, wọn yoo ni to £340m bayii. Ẹka iwadii kan ni Swiss Research Centre, lo fidi eyi mulẹ. Ajọ CIES to n woye bọọlu afẹsẹgba, ṣalaye pe irinwo miliọnu owo euro (400 million euros) ni owo to le ra Lamine Yamal ti ko ju ọmọ ọdun mẹtadinlogun lọ. Ọmọkunrin to wa lati orilẹede Spain yii ni ẹnikarun-un to kere julọ to gba bọọlu fun igba akọkọ nigba to wa lọmọ ọdun mẹẹẹdogun ati oṣu mẹsan-an. O ti gba bọọlu sawọn ni igba mẹtalelogun (23 goals), eyi ju iye bọọlu ti Lionel Messi to gba ami ẹyẹ Ballon d'Or gba sawọn lọ nigba mẹjọ, nigba tiyẹn wa ni ọjọ ori ti Lamine wa yii. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ipa kekere kọ ni Yamal ko ninu aṣeyọri Spain ninu idije Euro 2024 . Ninu idije naa ni wọn ti fun un ni inagije agbabọọlu to kere ju to si peredege julọ. O si tun gba ami ẹyẹ La Liga meji ati Copa del Rey ni Barcelona. Lamine Yamal gba ami ẹyẹ Golden Boy lọdun to kọja, eyi ti wọn n fun agbabọọlu ọmọ ilẹ Europe ti ọjọ ori rẹ ko ti i pe mọkanlelogun. Ọsẹ to kọja yii ni agbabọọlu naa kọwọ bọwe adehun ọlọdun mẹfa pẹlu ẹgbẹ Catalan. Adehun naa ti onibiliọnu kan euro tun wa, faaye gba ẹgbẹ agbabọọlu yoowu to ba fẹẹ ra a. Fun agbabọọlu to mọ bi wọn ṣe n da aabo bo ikọ rẹ ju, Pau Cubarsi, agbabọọlu kekere Barcelona ni wọn fun, iye rẹ ni 118 million euros (£99m). Bart Verbruggen ni wọn fun ni golii to le ju, ọmọ Barcelona yii ni owo rẹ jẹ 64 million euros (£54m). Florian Wirtz, agbabọọlu German to n gba ipo aarin lo wa nipo kẹwaa. O ti gbaradi lati darapọ mọ ikọ Premier League champions ni Liverpool, eyi ti afojusun wa pe yoo tobi ju ninu ere bọọlu afẹsẹgba ilẹ Gẹẹsi.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c201y8zykjgo
|
2025-06-07
|
bbc
|
Ìyàwó ilé tó di ògbóǹtarìgì nínú ìdíje àgbáyé fáwọn èèyàn tó sán eegun
|
Lati ọmọ kekere ni Roya Karimi ti lọ ile ọkọ ti o si bimọ nigba to pe ọmọ ọdun mẹẹdogun lorilẹede Afghanistan. Amọ, o ti di ilumọọka bayii ninu idije awọn aṣan-angun nilẹ Yuroopu. Igbe aye Roya n sọ nipa obinrin ti aṣa da lọwọ kọ amọ ti o ti dominira, to si jẹ awokọṣe fawọn obinrin ẹgbẹ rẹ. Ọdun mẹrinla sẹyin ni Roya sa kuro ni Afghanistan pẹlu ọmọkunrin rẹ kekere ati iya rẹ, ti wọn si morile orilẹede Norway lati lọ ṣatipo nibẹ. Bo tilẹ jẹ pe o ti di ominira ni Norway, Roya maa n ro nipa awọn obinrin ti ijọba n fi ẹtọ wọn dun wọn ni orilẹede abinibi rẹ, Aghanistan papaa julọ lati ọdun 2021 tawọn Taliban ti gbajọba pada. ''Mo maa n ranti nigba kugba ti mo ba lọ gbọngan idaraya wi pe mi o ni ominira lati ṣe awọn nnkan ti mo n ṣe bayii nigba ti mo wa ni Afghanistan. Inu mi dun wi pe mi o si labẹ iru ide bẹẹ mọ, ṣugbọn ọpọ obinrin ni wọn ko le maa n janfaani ẹtọ ọmọniyan bii lilọ ile ẹkọ, o jẹ ohun to bani lọkan jẹ,'' Roya lo sọ bẹẹ. Ijọba Taliban ti fofin de awọn ọmọbinrin ti ọjọ ori wọn ko ba tii ju ọdun mejila lọ wi pe wọn o gbọdọ lọ si ile ẹkọ mọ lorilẹede Afghanistan. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ ''Lonii, awọn ọmọbinrin ni Afghanistan ko lanfaani lati lọ ile ẹkọ mọ. Koda, wọn o le jade nile lai jẹ pe ọkunrin tẹle wọn jade, bakan naa ni awọn obinrin ko le da gbe igbesẹ kankan funra wọn,'' Roya kọminu. Roya loun si n reti ọjọ kan tawọn obinrin ni Afghanistan ko ni gbe ninu ibẹru mọ. Oniruuru ofin ni ijọba Taliban ti fi de awọn obinrin lẹyin ti wọn gbajọba lọdun 2021, nigba tawọn ọmogun Amẹrika fi orilẹede naa silẹ. Roya ni igbe aye toun n gbe ni Afghanistan ko tẹ oun lọrun ṣaaju kawọn Taliban to gbajọba gan an. O nira fun ọpọ obinrin lati gbe iru igbesẹ ti Roya gbe lẹyin to fi ọkọ rẹ silẹ ti o si sa kuro ni Afghanistan. Roya ni lati bẹrẹ igbe aye ọtun nigba to de si Norway - o ni lati mọ nipa aṣa awọn eeyan orilẹede naa ki o si tun gbọ ede wọn. Bakan naa, Roya nilo lati wa iṣẹ ti yoo maa ṣe lati tọju ẹbi rẹ. Roya kọ iṣẹ nọọsi, o si ri iṣẹ nile iwosan kan niluu Oslo ti i ṣe olu ilu orilẹede Norway. Ibẹrẹ ọtun ni kikọ nipa siṣan eegun jẹ ninu aye Roya, o ni iṣẹ naa ti foun lanfaani lati dominira ninu igbekun toun wa ninu rẹ fun ọpọlọpọ ọdun ni Afghanistan. Yatọ si iṣẹ nọọsi to n ṣe, Roya tun tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ, koda, o kẹkọọ gboye lori siṣe ere idaraya. Ni bayii, Roya ati ọkọ rẹ keji to fẹ ti di ilumọọka tọkọ taya lati Afghanistan ni Norway. Lọdun to kọja ni Roya fi iṣẹ nọọsi silẹ to si tẹra mọ iṣẹ aṣan-angun, igbesẹ yii si mu ayipada nla ba aye rẹ. Royan n gbaradi bayii fun idije agbaye awọn elere idaraya aṣan-angun agbaye eyi ti yoo bẹrẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kọkanla to n bọ. Ṣaaju ni Roya gbami ẹyẹ goolu nibi idije ti wọn pe orukọ rẹ ni Stoperiet Open. Pata alawọ ewe ni Roya wọ to fi kopa ninu idije ọhun. Lara awọn amuyẹ ti wọn maa n wo ninu idije ere idaraya aṣan-angun ni aṣọ wiwọ, bi awọn oludije ba ṣe dun un wo si ati iru irun ti wọn ṣe sori. Roya tun fakọyọ lẹyin to gbami ẹyẹ goolu ninu idije Norway Classic 2025. Idije yii jẹ ọkan lara awọn idije ere idaraya awọn aṣan-angun tawọn eeyan lati oniruuru orilẹede lapa ariwa ilẹ Yuroopu maa n kopa ninu rẹ. Bi o ṣe fakọyọ nibi idije yii lo jẹ pagede fun idije ilẹ Yuroopu, European Championships eyi to ti sọ ọ di ilumọọka bayii. Ni orilẹede Norway ni Roya ti ba ọkọ rẹ keji, Kamal Jalaluddin, pade ẹni toun naa wa lati orilẹede Afgahanistan. Iṣẹ ere idaraya aṣan-angun ni Kamal naa yan laayo, o si tun wa lara awọn ololufẹ Roya. Roya mọ riri atilẹyin ti Kamal n ṣe fun un ni gbogbo igba. ''Atilẹyin Kamal lo fun mi ni igboya lati maa ṣe nnkan nla nla ni ere idaraya aṣan-angun,'' Roya lo sọ bẹẹ. Bo tilẹ jẹ pe Roya n ṣe daadaa ni Norwaym ẹbi rẹ ni Afghanistan ko ṣatilẹyin fun un. Amọ, Roya ni ipakọ o gbọ suti ori ẹlẹgan lo daru lọrọ naa jẹ foun. Ni ọpọ igba ni wọn n dunkoko mọ ọn lati huwa ipa si i ati lati pa a. Roya ni gbogbo awọn to n dunkoko mọ oun ko tu irun kankan lara oun.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cjrn4qpn0lzo
|
2025-05-14
|
bbc
|
Orílẹ́èdè Morocco ń gbaradì láti di ibùdó alágbára lẹ́ka eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Orilẹede Morocco ti ṣeto ara rẹ bii ibujokoo ere bọọlu afẹsẹgbẹ fun awọn obinrin ilẹ Africa bayii, ko si sohun meji ti awọn alabojuto rẹ n ṣiṣẹ tọ ju bi wọn yoo ṣe di aṣiwaju lorii papa lọ. Morocco ni yoo gbalejo idije awọn obinrin, 'Women's Africa Cup of Nations (WAFCON) 2024, bẹrẹ lati lati ọjọ karun-un si ikẹrindinlọgbọn oṣu Keje. Awọn naa ni wọn patẹ aṣekagba rẹ ni 2022, ti wọn si kede pe ti 2026 naa bọ si ọdọ wọn. Eyi tun kere, bi a ba wo bo ṣe jẹ pe idije awọn ọkunrin ti akọsilẹ wọn wuyi pupọ naa tun n fi si Morocco, ti wọn si n na obitibiti miliọnu dọla lati pese awọn nnkan elo amayedẹrun . Morocco to wa ni Ariwa Africa, n ni afojusun to le gan-an lori ere bọọlu, bẹrẹ lati ọdọ wọn kari gbogbo agbaye. Igbesẹ to kan fun wọn bayii ni bi awọn obinrin agbabọọlu wọn, Atlas Lionesses, yoo ṣe rọwọ mu ju ipo keji ti wọn ṣe nilee wọn nibi idije AFCON ọdun kẹta sẹyin. " Idije WAFCON to n bọ yii yoo tun ya wa lara gaga ju ti tẹlẹ lọ, o le mu ki awọn ọdọbinrin mu bọọlu bi iṣẹ, wọn si le gbabẹ di agbabọọlu to kaju ẹ daadaa ti wọn yoo si di ọkan lara awọn ikọ agbabọọlu apapọ ilẹẹ wa" Mehdi El Qaichouri, akọnimọọgba FUS Rabat lo ṣalaye bẹẹ fun BBC Sport Africa. Oríṣun àwòrán,FUS Rabat Nibi idije WAFCON ni 2022, eyi to waye ni papa iṣere Prince Moulay Abdellah, ẹgbẹ agbabọọlu FUS Rabat gbiyanju, ero to waa wo ere naa si to ẹgbẹrun lọna aadọta, ṣugbọn South Africa na Morocco, ami ayo meji si ọkan dondo. Ipo kẹrin ni wọn ṣe ninu idije ife ẹyẹ awọn obinrin Morocco ni saa igbabọọlu to kọja. Ẹgbẹ agbbọọlu AS FAR lo gba ami ẹyẹ naa. Ẹgbẹ agbabọọlu El Qaichouri naa n reti lati bori lọjọ iwaju. Goolu FUS, Kawtar Bentaleb, ẹni to ran Morocco lọwọ ninu idije Futsal ọdun yii, ṣalaye pe agbega ti n ba ere bọọlu awọn obinrin. "Ko sẹni to n ka a si tẹlẹ. "Gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ti wọn ba n gba lọwọ yii, yala ti ọkunrin abi obinrin ni, ilọsiwaju lo maa mu ba wa. "Awọn ọdọ asiko yii ni nnkan amayedẹrun ati iranwọ ti wọn nilo lati ro ara wọn lagbara gan-an. Mo rọ wọn lati ṣe amulo gbogbo awọn eto ti wọn ti ṣe kalẹ fun wọn, nitori yoo ran wọn lọwọ gan-an." Kawtar Bentaleb lo sọ bẹẹ. Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Idije Ife ẹyẹ Africa Cup of Nations (AFCON) ti ọdun 2025 yii yoo bẹrẹ ni Morocco loṣu Kejila, owo nla ni wọn si n na le nnkan amayedẹrun nibẹ bayii, bi wọn ṣe tun n gbaradi lati kopa ninu gbigba alejo idije Ife ẹyẹ FIFA ni 2030. Morocco n gbero lati jẹ ki papakọ ofurufu rẹ gbooro si i, lati 38 million to wa nipari 2024, si eyi to le gba ero miliọnu lọna ọgọrin ( 80 million) . Wọn fẹẹ ṣe eyi laaarin ọdun mẹrin aabọ si asiko yii. Bakan naa ni wọn n ṣiṣẹ lori ọkọ oju irin ayara bi aṣa wọn. Wọn fẹ ko de Marrakech ko si tẹsiwaju de Agadir. Apapọ papa iṣere marundinlaadọta (45 stadiums) ati ibudo igbẹkọ ere idaraya ni wọn n ṣe atunṣe rẹ lọwọ bayii, ti wọn si n jẹ ko gbooro si i.. Olubori rẹ ni ti Stade Hassan II, to wa nitosi Casablanca, o gba to 115,000 eeyan. "Morocco ti yatọ si bo ṣe wa tẹlẹ, o n dagba gidi bayii ni," Bẹẹ ni alejo kan to ṣabẹwo si Rabat souk ṣalaye fun BBC. "Wọn ti n ṣiṣẹ lori ọpọ ibudo tipẹ, wọn si n ri i daju pe awọn nnkan eelo ti wọn nilo nibẹ ti wa nikalẹ. Nisinyi ti wọn ti n kọ gbogbo ẹ kia yii, pẹlu aṣẹ Ọlọrun, gbogbo ẹ yoo ti pari nigba ti wọn yoo ba fi maa ṣe idije AFCON." Bakan naa ni awọn olotẹẹli naa yoo jere ọja latari awọn eto idije yii. " O maa wu wa lati gbalejo awọn eeyan kaakiri agbaye, awọn ti ko si mọ Morocco tẹlẹ yoo lo anfaani yii lati mọbẹ" David Azuelos, ọnile itura kan ni olu ilu Morocco lo ṣalaye bẹẹ. "A lero pe ti awọn obinrin yii naa yoo nipa to ga bii tawọn ọkunrin." Bẹẹ ni ọkunrin naa wi. Oríṣun àwòrán,Populous/Getty Images Lati kọ papa iṣere Stade Hassan II yii lasan, owo to to $500m ni a gbọ pe yoo na wọn. Owo ori gọbọi: Owo ti wọn n san lori iye ti wọn n pa lọdun to ju180,000 dirhams ($19,700) lọ, ida 37% eeyan n ṣeranwọ lati fi kun owo ile kikọ naa. Gẹgẹ bi Amnesty International ṣe wi, Morocco ko fi aaye gba araalu lati sọrọ bi wọn ṣe fé, titi to fi kan pe wọn ko gbọdọ sọrọ tako ẹsin Islam, oriade to n jọba nibẹ ati awọn ileeṣẹ ijọba. Nigba ti BBC rin irinajo lọ si Rabat nibẹrẹ ọdun yii, ko sẹni to ṣetan lati sọrọ lorii bi wọn ṣe n na owo ilu. Eyi ri bẹẹ nitori wọn ni Ọba Mohammed VI, fẹran ere bọọlu afẹsẹgba, wọn si fẹ ki Ife ẹyẹ agbaye pada si Africa fun igba akọkọ lẹyin ogun ọdun. Ṣugbọn loṣu Keji, oṣiṣẹ ajọ awọn olokowo kan bu ẹnu atẹ lu awọn ero ijọba yii, fun bi wọn ṣe jẹ ki iyatọ to gbooro wa laaarin olowo ati talika lẹka ọrọ aje, to bẹẹ ti ikaniyan ti wọn ṣe laipẹ fi han pe airiṣẹ ṣe laaarin awọn eeyan pọ, ida 21.3% ni.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c1e00z30v82o
|
2025-07-03
|
bbc
|
Kókó ọ̀rọ̀ tí Tinubu bá Super Falcons sọ lẹ́yìn tí wọ́n gba ife ẹ̀yẹ WAFCON fún ìgbà kẹwàá
|
Oríṣun àwòrán,Bola Ahmed Tinubu/X Aarẹ Bola Tinubu ti gboṣuba rabandẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons Naijiria lẹyin ti wọn la Morocco mọlẹ lati gba ife ẹyẹ WAFCON fun igba kẹwaa lalẹ ana ọjọ Abamẹta niluu Rabat. Ẹkọ ko kọkọ ṣoju mimu fun Naijiria nigba ti ere bọọlu naa bẹrẹ tori goolu meji ọtọọtọ ni Morocco kọkọ gba wọle Super Falcons ti wọn o si le ta putu ni abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ ọhun. Amọ, nigba ti abala keji ere bọọlu naa bẹrẹ ni Super Falcons bẹrẹ si ni ṣana ti Esther Okoronwo si da goolu kan pada lẹyin to gba pẹnariti ti Naijiria ri sawọn Morocco. Kẹrẹ kẹrẹ ni wọn ba tun ri goolu keji gba wọle eyi to jẹ ki ami ayo di ọmi 2-2. Jennifer Echegini to wọle ni abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa lo kan Morocco ni eyin ọọkan nigba to gba goolu kẹta wọle fun Naijiria nigba ti o ku iṣẹju meji ki ere bọọlu naa pari. Nigba ti o n bawọn sọrọ lori foonu, Aarẹ Tinubu ni ''Super Falcons mọ pe awọn ni iṣẹ la ti ṣe, iṣẹ naa si ye wọn yeke yeke. Super Falcons ti wa jẹwọ ara wọn gẹgẹ bii ọmọ Naijiria tootọ ti kii kaarẹ. Super Falcons lọ soju ogun, wọn si tun ti ṣẹgun. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Wọn ti gba ife ẹyẹ WAFCON gẹgẹ bii aṣaaju ninu bọọlu awọn obinrin nilẹ Afirika. Ni bayii, ala #MissionX ti wa si imuṣẹ!'' Aarẹ Tinubu sọ pe iwuri nla ni ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons jẹ fun orilẹede Naijiria ati gbogbo ọmọ Naijiria nibi kibi to wu ki wọn le wa. Aarẹ ni ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ti mu inu awọn ọmọ Naijiria dun, tori wọn jẹwọ ara wọn gẹgẹ bii ọmọ akin. O ni aṣeyọri Super Falcons ninu idije WAFCON dara fun iṣọkan orilẹede Naijiria. Tinubu ko ṣai ki Esther Okoronkwo to ṣe itaniji fun Super Falcons ninu ifẹsẹwọnsẹ naa fun iṣẹ takun takun ti o ṣe. Bakan naa ni aarẹ tun gboriyin fun Rasheedat Ajibade to jẹ Balogun ìkọ agbabọọlu Naijiria fun ipa ribiribi ti o ko ninu idije naa. Tinubu ni oun yoo maa reti wọn lati gbe ife ẹyẹ naa wa sile, amọ, o ni ki wọn ṣe pẹlẹ ki o to digba naa. This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Xcookie policyandprivacy policybefore accepting. To view this content choose 'accept and continue'. End of X post Content is not available Oríṣun àwòrán,Getty Images Ẹwẹ, aya aarẹ orilẹede Naijiria, Sẹnẹtọ Oluremi Tinubu, naa ti gboriyin fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons fun ife ẹyẹ WAFCON ti wọn gba fun igba kẹwaa. Aya aarẹ ni eyi ṣee ṣe fawọn agbabọọlu obinrin Naijiria tori wọn o kaarẹ ninu igbiyanju wọn. ''Mo mọ riri ẹyin agbabọọlu obinrin wa fun bi ẹ ti gba ife ẹyẹ WAFCON fun igba kẹwaa. Ẹ gbiyanju bi ẹ ṣe lu Morocco ni 3-2 lẹyin ti Morocco ti kọkọ gba goolu meji sawọn Naijiria. Eyi kii ṣe ife ẹyẹ mii lasan, amọ, o ni ṣe pẹlu iṣẹ aṣekara ati ẹmi ti kii kaarẹ tawọn ọmọ Naijiria ni. A dupẹ lọwọ Eleduwa fun aṣeyọri nla yii, ẹ ti ṣe nnkan moriwu fun orilẹede wa lẹẹkan si. Ẹ si tun ti jẹ ko ye gbogbo agbaye wi pe ẹyin ni ọbabinrin ere bọọlu nilẹ Afirika,'' Oluremi lo sọ bẹẹ. Aya aarẹ wa ki Super Falcons ku oriire lorukọ gbogbo awọn obinrin ni Naijiria. Sẹnẹtọ Oluremi ni Super Falcons ti fi goolu kọ orukọ wọn; ati pe wọn ti ṣe nnkan iwuri fun ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ Naijiria.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c3wn6y49ey0o
|
2025-07-27
|
bbc
|
Gbogbo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìdíje Wafcon 2024 tó bẹ̀rẹ̀
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images/Backpage Pix Ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Africa tàwọn obìnrin tọdún 2024 'Women's Africa Cup of Nation (Wafcon) tún ti fẹ́ gbérasọ bí Morocco ṣe ń gba àlejò ìdíje náà fún ìgbà méjì léra. Ní ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Keje ni ìdíje náà yóò bẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n sun síwájú fún ọdún kan, tí orílẹ̀ èdè Morocco ti máa kojú Zambia ní pápá ìṣeré Olympic Stadium tó wà ní Rabat ní aago mẹ́sàn-án aago Nàìjíríà. Àwọn olólùfẹ́ rédíò World Service ní Africa yóò ní àǹfàní láti gbọ́ bí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà bá ṣe ń lọ lórí rédíò wọn ní ọjọ́ àkọ́kọ́, ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàárín Mali àti Tanzania tó fi mọ́ ìpele tó kẹ́yìn sí àṣekágbá àti àṣekágbá fúnra rẹ̀. Nàìjíríà tó ti gba ife ẹ̀yẹ náà fún ìgbà mẹ́sàn-án yóò kojú Tunisia ní òpin ọ̀sẹ̀ yìí ní ìsọ̀rí B nígbà tí South Africa yóò máa kojú Ghana ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Keje. Àwọn ìkọ agbábọ́ọ̀lù méjìlá tí wọ́n pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta ni wọ́n ń kópa níbi ìdíje náà pẹ̀lú orílẹ̀ èdè mẹ́rin ní ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan. Morocco tó ń gbàlejò ìdíje náà wà ní ìsọ̀rí A pẹ̀lú Zambia tó fojú wọn gbolẹ̀ níbi ìdíje Olympic Games 2024. Bákan náà ni wọ́n máa kojú Senegal àti DR Congo tí wọ́n jọ wà ní ìsọ̀rí kan náà. Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà, Super Falcons yóò máa kojú Tunisia, Algeria àti Botswana tí wọ́n wà ní ìsàlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde àjọ tó ń rí sí bọ́ọ̀lù ní àgbáyé. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ South Africa, Ghana, Mali àti Tanzania ló wà ní ìsọ̀rí C. Orílẹ̀ èdè méjì tó bá ṣe dada jùlọ ló máa bọ́ sí ipele quarter-finals. Ìsọ̀rí A: Morocco, Zambia, Senegal, DR Congo. Ìsọ̀rí B: Nigeria, Tunisia, Algeria, Botswana. Ìsọ̀rí C: South Africa, Ghana, Mali, Tanzania. Oríṣun àwòrán,Getty Images Lẹ́yìn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí wọ́n bá fi ṣíde, ó kéré tán ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ méjì ni wọ́n máa ma gbá ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan títí tí ìsọ̀rí àkọ́kọ́ fi máa tán ní ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Keje. Ní aago méjì ọ̀sán, márùn-ún ìrọ̀lẹ́ àti aago mẹ́jọ alẹ́ ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yóò máa wáyé ní abala ìsọ̀rí àkọ́kọ́. Aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ àti aago mẹ́jọ alẹ́ ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yóò wáyé ní àwọn ipele tó kàn tí yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Kejìdínlógún, oṣù Keje. Wọn kò ní lo àwọn pápá ìṣeré mẹ́ta tí wọ́n lò nígbà tí Morocco gbàlejò Wafcon ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn nítorí àtúnṣe tó ń lọ lọ́wọ́ ní àwọn pápá ìṣeré náà ní ìgbáradì fún ìdíje AFCON 2025 àti ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé 2030. Pápá ìṣeré mẹ́fà ni wọ́n máa lò ní àwọn ìlú tó ń gbàlejò ìdíje náà pẹ̀lú méjì ní Casablanca. Oríṣun àwòrán,Getty Images Nínú àwọn orílẹ̀ èdè méjìlá tó ń kópa nínú ìdíje náà, Morocco, Nàìjíríà àti South Africa ni wọ́n ti gba ife ẹ̀ye náà rí. Akọnimọ̀ọ́gbá Justin Madugwu ló kó ikọ̀ Super Falcos sòdí tí Chiamaka Nnadozie sì ti gba àmì ẹ̀yẹ bí aṣọ́lé tó dára jùlọ ní ẹ̀ẹmèjì léra. Akọ́nimọ̀ọ́gbá Banyana Banyana South Africa, Desiree Ellis sì ní ìrètí pé àwọn yóò tún gba ife ẹ̀yẹ náà lọ́tẹ̀ yìí bíi ti ọdún kẹta sẹ́yìn. Morocco ti dókoòwò gidi sídìí eré bọ́ọ̀lù àmọ́ àwọn obìnrin rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ máa ṣe dada gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin. Zambia ló gba ipò kẹta níbi ìdíje tó kọjá tí wọ́n sì ń gbèrò láti tún fakọyọ lásìkò yìí Oríṣun àwòrán,Backpage Pix Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Aago GMT ni awọn wọ̀nyí wà Ọjọ́ Karùn-ún oṣù Keje Group A:Morocco vs Zambia, Olympic Stadium, Rabat (20:00) - Ọjọ́ Kẹfà oṣù Keje Ìsọ̀rí A:Senegal vs Ivory Coast, El Bachir Stadium, Mohammedia (14:00) Ìsọ̀rí B:Nigeria vs Tunisia, Larbi Zaouli Stadium, Casablanca (16:00) Ìsọ̀rí B:Algeria vs Botswana, Pere Jego Stadium, Casablanca (19:00) Ọjọ́ Keje oṣù Keje Ìsọ̀rí C:South Africa vs Ghana, Honneur Stadium, Oujda (16:00) Ìsọ̀rí C:Mali vs Tanzania, Berkane Stadium, Berkane (19:00) Ọjọ́ Kẹsàn-án oṣù Keje Ìsọ̀rí A:Zambia vs Senegal, Mohammedia (16:00) Ìsọ̀rí A:DR Congo vs Morocco, Rabat (19:00) Ọjọ́ Kẹwàá oṣù Keje Ìsọ̀rí B: Botswana vs Nigeria, Larbi Zaouli Stadium, Casablanca (16:00) Ìsọ̀rí B:Tunisia vs Algeria, Pere Jego Stadium, Casablanca (19:00) Ọjọ́ Kọkànlá oṣù Keje Ìsọ̀rí C:Ghana vs Mali, Berkane (16:00) Ìsọ̀rí C:Tanzania vs South Africa, Oujda (19:00) Ọjọ́ Kejìlá oṣù Keje Ìsọ̀rí A:Morocco vs Senegal, Rabat (19:00) Ìsọ̀rí A:Zambia vs DR Congo, Mohammedia (19:00) Ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Keje Ìsọ̀rí B:Nigeria vs Algeria, Larbi Zaouli Stadium, Casablanca (19:00) Ìsọ̀rí B:Tunisia vs Botswana, Pere Jego Stadium, Casablanca (19:00) Ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Keje Ìsọ̀rí C:South Africa vs Mali, Oujda (19:00) Ìsọ̀rí C:Ghana vs Tanzania, Berkane (19:00) Ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Keje QF1:Ẹni tó bá gbégbá orókè ní ìsọ̀rí A àti ẹni tó bá gbégbá orókè ní ìsọ̀rí, Rabat (19:00) QF2:Ẹni tó bá gbégbá orókè ní ìsọ̀rí B àti ẹni tó bá gbégbá orókè ní ìsọ̀rí A kejì, Larbi Zaouli Stadium, Casablanca (16:00) Ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Keje QF3:Ẹni tó bá gbégbá orókè ní ìsọ̀rí C àti ẹni tó bá wà ní ipò kẹta ní ìsọ̀rí A/B, Oujda (19:00) QF4:Ẹni tó bá wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí B àtiẸni tó bá wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí C, Berkane (16:00) Oríṣun àwòrán,Backpage Pix Tuesday 22 July SF1:Ẹni tó bá gbégbá orókè ní QF1 àti Ẹni tó bá gbégbá orókè ní QF4, Rabat (19:00) SF2: Ẹni tó bá gbégbá orókè ní QF2 àti Ẹni tó bá gbégbá orókè ní QF3, Larbi Zaouli Stadium, Casablanca (16:00) Ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n oṣù Keje Ikọ̀ tó bá pàdánù SF1 àti ikọ̀ tó bá pàdánù SF2, Larbi Zaouli Stadium, Casablanca (19:00) Ọjọ́ Kínlọ́gbọ̀n oṣù Keje Ikọ̀ tó bá jáwé olúborí SF1 àti ikọ̀ tó bá jáwé olúborí SF2, Olympic Stadium, Rabat (20:00)
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cql0zzy6exvo
|
2025-07-05
|
bbc
|
Ìdí tí mo fi yarí pé Arsenal FC nìkan lẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tí mo fẹ́ darapọ̀ mọ́ rèé - Gyokeres
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Lẹyin o rẹyin, ẹlẹsẹ ayo orilẹede Sweden, Viktor Gyokeres, pada darapọ mọ ẹgbẹ agbabọolu Arsenal lẹyin ọpọlọpọ ipenija to koju lati kuro lẹgbẹ agbabọọlu Sporting. Gyokeres buwọlu iwe adehun latu darapọ mọ Arsenal fun owo to to £64m lẹyin ti wọn ṣe ayẹwo ara rẹ tan ti wọn si ri pe ṣaka lara rẹ da. Amọ, opọ eeyan lo ti n beere wi pe ki gan an ni Gyokeres ri lara Arsenal to fi taku wi pe Oriogbade nikan loun fẹẹ darapọ mọ lati Sporting.. Gyokeres ti sọrọ soke wi pe bi Arsenal ṣe lu ẹgbẹ agbabọọlu rẹ tẹlẹ Sporting pẹlu ami ayo 5-1 lo mu oun pinnu lati darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu naa. Gyokeres ni iyalẹnu lo jẹ foun pe oun ko ri goolu kankan gba sawọn Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ naa. O ni lẹyin naa loun wa roo pe ẹgbẹ agbabọọlu to gbọrẹgẹjigẹ ni Arsenal i ṣe eyi to maa n nira fawọn ẹgbẹ agbabọọlu alatako lati lu. ''Mo kan ro wi pe Arsenal lẹgbẹ agbabọọlu to dara fun mi lati darapọ mọ. Nnkan ti mo tun gbọ lẹnu Mikel Arteta to jẹ akọnimọọgba Arsenal ati Andrea Berta to jẹ adari ẹka to n ri si rira awọn agbabọọlu ni Arsenal naa wa lara idi to mo fi pinnu lati darapọ mọ Arsenal. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Ọgọọrọ awọn ololufẹ Arsenal kaakiri agbaye lo ti wa lọrun awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa papaa julọ akọnimọọgba Arteta wi pe wọn gbọdọ ra Gyokeres. Ni bayii, Gyokeres gan an ti foju sọna lati fakọyọ nipa gbigba ọpọlọpọ goolu sawọn fun Arsenal. ''Idunnu lo jẹ fun mi bi ọpọ ololufẹ Arsenal ṣe fẹ ki n darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Gunners . Inu mi maa dun lati ri awọn ololufẹ Arsenal ni papa iṣere ti mo ba ti bẹrẹ si gbabọọlu fun wọn. Emi gan an ko le duro mọ lati bẹrẹ si ni gba goolu sawọn fun Arsenal,'' Gyokeres lo sọ bẹẹ. England ni Gyokeres ti bẹrẹ irinajo bọọlu gbigba rẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Coventry lo kọkọ ṣoju ki o to darapọ Swansea. Ọdun 2023 lo darapọ Sporting ni Portugal nibi ti o ti wa si Arsenal bayii. Gyokeres sọ pe ''England nibi ni mo ti bẹrẹ irinajo bọọlu mi, o ti to ọjọ mẹta naa. O dami loju pe mo ti dara sii gẹgẹ bi ẹlẹsẹ ayo ju ti tẹlẹ lọ. Ni bayii, mo ṣetan lati jẹwọ ara mi ki n si ṣe iranwọ fun awọn akẹgbẹ mi lori papa.'' Ọpọ lo ti n wo Gyokeres wi pe yoo ran Arsenal lọwọ lati gba ife ẹyẹ Premier League ati Champions League ti wọn ko tii gba ri ninu itan ẹgbẹ agbabọọlu naa.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cd7y3p0yqnjo
|
2025-07-27
|
bbc
|
Tinubu fi oyè, owó àti ilé dá àwọn agbábọ́ọ̀lù Super Falcons lọ́lá
|
Ààrẹ Bola Tinubu ti fi ẹ̀bùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó, ilé àti oyè dá àwọn agbábọ́ọ̀lù Super Falcons lọ́lá láti ṣe kóríyá fún wọn látàrí bí wọ́n ṣe gba ife ẹ̀yẹ bọ́ọ̀lù 2024 Women Africa Cup of Nations. Ní ilé ààrẹ Aso Rock tó wà ní ìlú Abuja ni ààrẹ ti gbàlejò àwọn agbábọ́ọ̀lù náà lẹ́yìn tí wọ́n padà sí Nàìjíríà láti Morocco tí ìdíje náà ti wáyé. Níbi ètò náà ni olórí ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Falcons, Rasheedat Ajibade ṣe àgbékalẹ̀ ife ẹ̀yẹ náà fún Ààrẹ Tinubu, tí aṣọ́lé Super Falcons, Chiamaka Nnadozie náà ṣe àgbékalẹ̀ àmì ẹ̀yẹ rẹ̀ fún ààrẹ. Tinubu ṣàlàyé bí òun kò ṣe fẹ́ wo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà nítorí ẹ̀jẹ̀ rúru ṣùgbọ́n tó kan sáárá sáwọn ọmọbìnrin fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe lásìkò ìdíje ọ̀hún. "Ní orúkọ gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, mo fi oyè Officer of the Order of the Niger, OON, dá a yín lọ́lá," Tinubu sọ. "Ní àfikún, mo darí àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣe àkóso ilé ìgbé Renewed Hope Housing Estate láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ilé oní yàrá mẹ́ta mẹ́ta. Bákan náà ni ààrẹ tún kéde fífún àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ní owó náírà tí iye rẹ̀ jẹ́ $100,000 fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn agbábọ́ọ̀lù mẹ́rìnlélógún náà àti $50,000 fáwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn. Níbi ayẹyẹ náà ni alága àwọn gómìnà Nàìjíríà tó tún jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara kéde fífún àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ní mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn àtàwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Ṣáájú ni ikọ̀ ìròyìn BBC ti wà ní pápá ìṣeré Abuja níbi tó yẹ káwọn agbábọ́ọ̀lù náà balẹ̀ sí ní nǹkan bíi aago méjìlá ọ̀sán bí wọ́n ṣe ń bọ̀ láti Morocco àmọ́ tó jẹ́ pé aago méjì ọ̀sán kọjá kí wọ́n tó dé. Ìròyìn tó ti kọ́kọ́ gba ìgbooro ni pé àwọn agbábọ́ọ̀lù náà máa yíde gbogbo ìlú Abuja pẹ̀lú ife ẹ̀yẹ wọn tí wọ́n bá ti balẹ̀ sí Nàìjíríà. Akọ̀wé ìjọba Nàìjíríà, George Akume àtàwọn mínísítà míì ló gba àwọn agbábọ́ọ̀lù ní àlejò bí wọ́n ṣe ń bọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ òfurufú wọn. Ajibade na ife ẹ̀yẹ náà sókè bí wọ́n ṣe ń sọ̀kalẹ̀ táwọn eléré sì ṣeré pàdé wọn. Lẹ́yìn ìpàdé ráńpẹ́ ni àwọn agbábọ́ọ̀lù náà kó sí inú ọkọ̀ tí wọ́n sì bá ojú ọ̀nà míì kúrò ní pápákọ̀ òfurufú náà. Èyí jẹ́ ìjákulẹ̀ fáwọn olólùfẹ́ wọn tí wọ́n ti ń dúró dè wọ́n lẹ́nu ọ̀nà lójúnà àti báwọn ṣe ẹ̀yẹ lórí ìjáwé olúborí wọn. Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ló padà sọ fún àwọn èèyàn náà pé àwọn obìnrin náà ti lọ. Ìdí táwọn aláṣẹ kò ṣe jẹ́ káwọn ọmọbìnrin náà kí àwọn èèyàn kò yéni àmọ́ òjò rọ̀ láti òwúrọ̀ ní Abuja di ìgbà tí àwọn ọmọbìnrin náà fi balẹ̀. Ikọ̀ ìròyìn BBC rí ọkọ̀ tí NFF gbé kalẹ̀ láti jẹ́ káwọn agbábọ́ọ̀lù náà ṣe ìwọ́de káàkiri Abuja kí àwọn ọmọ Nàìjíríà le yẹ́ wọn sí.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c0qlz9nvjezo
|
2025-07-28
|
bbc
|
Wo ohun tó n ṣẹlẹ̀ sí ọkàn rẹ bí o bá sá eré ìje olóbìírípo láì sinmi
|
Oríṣun àwòrán,Dókimos Produções Ni 2023, ọkunrin elere ije kan, Hugo Farias, gba ami ẹyẹ agbaye fun bo ṣe pari ere olopoo to din diẹ ni irinwo, 366 marathons ,leralera. Ere sisa yii ju ki eeyan sare onikilomita mejilelogoji (42km)lọ, iyẹn maili mẹrindinlọgbọn (26miles) bi a ba ṣi i ni ti maili lojumọ kan . Bẹẹ lo ṣe sare naa fun ohun to le lọdun kan, ko si pa ọjọ kan jẹ laaarin rẹ ri tojo-tẹẹrun. Laarin asiko to n ṣe nnkan agbara yii, Hugo, ẹni ọdun marundinlaadọta (45) to si tun jẹ oniṣowo ọmọ ilẹ Brazil, kopa ninu iṣẹ iwadii iṣegun kan lati mọ ipo ti ọkan rẹ wa pẹlu iṣẹ agbara to ṣe. O fẹ lati mọ bi nnkan ṣe n lọ lara rẹ nigba to n sa kilomita mẹẹẹdogun (15,000km) (9,321 miles) laaarin ọdun kan. "Ki i ṣe pe mo jẹ elere idaraya to gbayi to bẹẹ yẹn naa tẹlẹ. Ẹẹkan pere ni mo sare lai sinmi ri laye mi. "Ṣugbọn o wu mi lati yi itan mi pada, mo fẹ fi itan balẹ lati ara ere idaraya, bo ṣe n jawọ-jasẹ ninu mi niyẹn." Hugo Farias lo ṣalaye bẹẹ. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Oríṣun àwòrán,Clayton Damasceno Gegẹ bi Farias ṣe ṣalaye fun BBC Brasil, o ni oun pinnu lati yi boun ṣe n ba aye oun bọ pada, nitori igbesi aye ojukan toun n gbe nigba naa su oun. "Igba kan wa ti mo jokoo ti mo ro o, mo ni ṣe ohun ti wọn bi mi fun ni mo n ṣe yii? Ki ni ka maa ṣe nnkan kan naa fun ọdun marundinlogoji abi ogoji ọdun? "Lati kekere ni eeyan ti n kọ ẹkọ, lati maa n wa ọna ti a maa fi yan iṣẹ kan laayo lati ṣe ka too pe ẹni ọdun mejidinlogun (18). Eeyan ti gbọdọ maa ro o bi yoo ṣe rẹsẹ tilẹ, bi yoo ṣe le da duro ti yoo si ni ẹbi tirẹ, bẹẹ ni eeyan yoo ti maa gbaradi fun ifẹyinti ko too de . "Mo bẹrẹ si i ronu pe mo le ṣe ju bẹẹ lọ, ti yoo si jẹ nnkan iwuri fun awọn eeyan mi-in lọna ọtọ." Oríṣun àwòrán,Handout Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Lara ohun to wu Farias lori bo ṣe wi ni itan ọkunrin ọlọkọ oju omi ọmọ Brazil kan ti orukọ ẹ n jẹ Amyr Klink, ọkunrin naa wa ọkọ oju omi lori alagbalugbu omi okun South Atlantic ni 1984. ''Ṣugbọn emi o ni ni i wa ọkọ oju omi, ere ni mo maa sa ni temi." Hugo lo ronu bẹẹ to si pada mu ero ọkan rẹ ṣẹ. O wa ọna lati pade elere ije ọmọ Belgium, Stefaan Engels, ẹni to ti sare olopo 365 ti fun ọdun kan. Farias naa si pinnu lati sa tiẹ ju bẹẹ lọ. O ju oṣu mẹjọ lọ to fi to gbogbo ero ọkan rẹ to fẹẹ muṣẹ yii. Bo ṣe n lọ fun idaraya lo n gba itọni lati ọdọ awọn ogbontarigi elere ijẹ. "Mo mọ pe mi o le da a se, awọn ikọ gbogbo ti mo nilo ni mo ṣeto. Awọn dokita, awọn elere idaraya , awọn to n to egungun ati dokita to n ri si irori eeyan ni mo ko jọ. " " Iṣẹ ti mo n ṣe to ti fẹsẹ mulẹ daadaa ni mo fi silẹ ti mo si kọ oju mọ ohun ti mi o mọ boya yoo tiẹ mu èrè wa fun mi rara. Ẹru maa n ba mi nigba mi-in lori ohun ti mo gunle yii, nitori ẹ lo fi ṣe pataki pe ki n ko awọn ti mo sọ yẹn mọra lati yẹ mi wo." Ọkan lara awọn akọṣẹmọṣẹ ti Hugo gbe iṣẹ naa fun ni ile iwosan itọju ọkan São Paulo Heart Institute InCor. "Mo beere pe ṣe wọn le darapọ mọ mi, ki wọn fi han mi bi ọkan mi ṣe gba iṣẹ ti mo n fun un ṣe. Boya yoo jẹ ki ọkan mi tobi si i ni tabi yoo jẹ ko kere si i, boya mo maa ni aisan ti a mọ si arrhythmias [ti ọkan ko ni i ṣiṣẹ daadaa) tabi mo maa koju awọn wahala mi-in. "Mo si tun fẹẹ da si imọ ijinlẹ sayẹnsi pẹlu." Bẹẹ ni Hugo Farias wi. Dokita onimọ nipa ọkan, Maria Janieire Alves, kopa ninu ayẹwo ọkan Farias. "Ẹnikẹni ko ti i ṣe ohun to ṣe yii ri, o si ni ipa to ṣe e tọka si lori ọkan." Dokita Maria ṣalaye lori ọna ti Hugo ko fi ni i lugbadi aisan ọkan. Oṣooṣu lo n lọ fun ayẹwo kan ti wọn pe ni 'ergospirometry (wọn fi n mọ bi ọkan ṣe n ṣiṣẹ si lasiko ere idaraya. Oṣu mẹta-mẹta naa lo si fi n ya aworan ọkan rẹ. "A ṣe eyi lati mọ bi ọkan rẹ ṣe n ṣiṣẹ si, nigba to ba n ṣere lile ati ere ti ko nira . A si n yẹ ẹ wo boya awon nnkan kan ti n yingin." Dokita Maria Alves lo ṣalaye bẹẹ. Oríṣun àwòrán,Dókimos Produções Hugo pari ere ije naa lọjọ kejidinlọgbon, oṣù Kẹjọ odun 2023. Díẹ̀ ló ku ko gba a to ẹgbẹta wakati (1,590 hours) lati pari ere ije 15,569km (9,674 miles). Idije naa ni oruko re si fi wọ iwe àkọsílẹ̀ agbaye (Guinness World Record.) Hugo to bímọ meji maa n sare laraarọ ko le baa ni asiko fún áwọn ẹbí rẹ, ko si le fi asiko to ku sinmi. Bakan naa lo fẹrẹ jẹ́ pe ọ̀nà kan naa lo maa n sare gba nigboro Americana, ilu São Paulo. Àbọ̀ iwadii ti wọn fi lede ninu iwe scientific journal Arquivos Brasileiros de Cardiologia, gba pe pẹlu bi Hugo ṣe kopa ninu ere ṣíṣá leralera, ko si apeere akoba tabi ailera kankan ni ọkàn rẹ. Ju gbogbo ẹ lọ, àbọ̀ iwadii naa fi han pe eeyan le kọ ọkàn rẹ lẹkọọ lati gbacere ìdárayá to le, to ba ti jẹ pe ko le ju. Dokita Alves lo sọ eyi. "Eyi fi han wa pe okan elere idaraya le gba ohun to ba le gan-an, niwon igba ti ko ba ti kọjá gbedeke alaafia, to si n sinmi láàárín ẹ kọ̀ọ̀kan." Dokita to n tọju arun ọkàn lẹka eré idaraya, Filippo Savioli, ti ko ba wọn ṣe ninu ìṣe ìwádìí náà ló ṣalaye bẹẹ fun BBC. Oríṣun àwòrán,Dókimos Produções O ni Hugo sare naa lọ́nà tí kò nira. Dokita Filippo Savioli sọ pe onka ọkàn re wa ni 140bpm niṣẹju kan. Onka 70-80% ni ifunpa rẹ si wa, eyi to ni o daa fun ọjọ ori rẹ. "Eyi je ko wa ni alaafia ara, ara rẹ ṣi le pese eemi to nílò." O ni bi eeyan ba n sare nilana ti Hugo tọ yii, o maa n din ewu aisan okan ku. Dokita naa sọ pe to ba jẹ pe ilana to le ju ni Farias fi sa ere rẹ ni , ipa to buru ni ko ba ni lara rẹ. O kilọ pe o lewu lati bẹ̀rẹ̀ iru ere yii lai si ẹ̀kọ́ fun un ati lai si abojuto awon dokita. "Bi èèyàn ko ba gbaradi to si bẹ̀rẹ̀ ere bi eyi, o han kedere pé yoo ṣe ara rẹ lèṣe, o si le ja siku pẹlu." Fun Hugo, o ni abajade iwadii awon dókítà ya oun lenu. "Ara mi da ṣakaṣaka leyin ère naa. Bi wọn si se ni ko si laburu kan to ṣe mi lati ara ere náà ṣe pataki gan-an.." Ṣùgbọ́n ki i ṣe pe ere sisa naa fi gbogbo ẹ rọrùn, Hugo ṣalaye pe: "Gbogbo ẹ ni mo koju: otutu, ooru, ojo, sunkẹẹrẹ-fakẹẹrẹ, mo ṣeṣe pelu. " Ẹẹmeta lo koju igbọnsẹ gbuuru, o fi ọjọ márùn-ún ṣègbọ̀nsẹ̀ lasiko kan. "Mo padanu ara sisan pelu ìwọ̀n mẹrin, 4kg. Nisẹ ni mo ṣe àtúnṣe si oúnjẹ mi ati bi mo ṣe n mumi. Ṣùgbọ́n mi o tori ẹ jáwọ́" Oríṣun àwòrán,Dókimos Produções Hugo Farias ti kọ̀wé nipa iriri rẹ yii, ko si fi ere sisa sílẹ, o ṣi n sare. Gege bo ṣe wi, idije to ku fun un bayii ni ti bo ṣe fẹẹ jẹ ẹni àkọ́kọ́ ti yoo sare yipo gbogbo America, bẹ̀rẹ̀ lati Prudhoe Bay, ní Alaska, de Ushuaia, ní Argentina. "Afojusun mi ni lati kede anfaani to wa ninu ere idaraya fun gbogbo aye, káwọn èèyàn si le mọ pe wọn le ṣe àwọn nǹkan agbayanu." "Ko seni to gbọ́dọ̀ sare ije aisinmi lojoojumọ, ṣùgbọ́n gbogbo eeyan lo yẹ ko gbagbọ ninu ẹbun ara rẹ." Hugo Farias lo pari ọrọ rẹ bẹẹ.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cly2055gknlo
|
2025-07-12
|
bbc
|
Peter Rufai, ogbóntarìgì golí fún Super Eagles, jáde l'áyé
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Agba ọjẹ goli fun ikọ agbabọọlu Super Eagles, Peter Rufai ti jade laye. Rufai, ti ọpọ eeyan mọ si Dodomayana, ni iroyin sọ pe o ku ni owurọ Ọjọbọ, ọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun 2025. Ajọ NFF kede iku Rufai, loju opo X rẹ ni alẹ Ọjọbọ. Bo tilẹ jẹ pe BBC Yoruba ko ti i le fidi ohun to pa ogbontarigi agbabọọlu naa, awọn iroyin kan sọ pe o ṣe aisan fun igba pipẹ, ki ọlọjọ to o de. Ẹni ọdun mọkanlelọgọta ni. Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 1963 ni wọn bi Rufai niluu Eko. Lasiko to fi jẹ agbabọọlu, o ṣiṣẹ ni orilẹede Belgium, Netherlands, Portugal ati Spain, fun ogun ọdun. Rufai ṣoju Naijiria ni idije World Cup meji, ati ni ọpọ Africa Cup of Nations, AFCON. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Ẹgbẹ agbabọọ̀lu Stationery Stores FC ati Femo Scorpions, ni akọsilẹ sọ pe Peter Rufai ti bẹrẹ bọọlu gbigba niluu Eko. Lẹyin naa lo lọ si Benin lọdun 1986, nibi to ti gba bọọlu fun AS Dragons FC de l'Ouémé. Yatọ si pe o gba bọọlu ni ilẹ okeere, ẹni ti ko ṣe e fi ọwọ rọ sẹyin l'agbo bọọlu ni Naijiria ni Rufai jẹ. Igba meji ọtọọtọ lo ṣoju Naijiria ni idije agbaye - ọdun 1994 ati 1998 – gẹgẹ bi aayo goli. Bakan naa lo tun ṣe iranlọwọ fun Naijiria lati gba ife 1994 African Cup of Nations ni Tunisia. Oríṣun àwòrán,Mark Leech/Getty Images Ọdun mẹfa ni Rufai fi gba bọọlu ni orilẹede Belgium pẹlu agbabọọlu K.S.C. Lokeren Oost-Vlaanderen ati K.S.K. Beveren. Lọdun 1994, Peter Rufai darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu S.C. Farense l'orilẹede Portugal. Iṣẹ takuntakun rẹ mu ko ni anfaani lati darapọ mọ idije La Liga, to si gba bọọlu fun Hércules. Rufai pada si orilẹede Spain lọdun 2003 lati fi ṣe ibugbe, to si da ile ẹkọ kan silẹ fun awọn goli. Oríṣun àwòrán,Shaun Botterill /Allsport/Getty Images
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cvgejld0vpyo
|
2025-07-03
|
bbc
|
Àwọn nǹkan tí Hulk Hogan ṣe nígbà ayé rẹ̀ tó fa awuyewuye
|
Oríṣun àwòrán,Michael Loccisano/FilmMagic/Getty Images Lai si ani ani, ọpọ eeyan ni yoo maa ṣe iranti gbajugbaja ajijakadi n ni, Hulk Hogan, to doloogbe fun itu to pa ninu ere idaraya ijakadi. Ṣugbọn ọpọ eeyan naa si tun ni yoo maa ranti rẹ fawọn nnkan to ṣe eyi to fa awuyewuye tawọn eeyan n sọ nipa rẹ. Yoruba bọ wọn ni a kii mọ ọ rin ki ori o ma mi, bayii ni ọrọ ilumọọka onijakadi to doloogbe naa ṣe ri. Wọnyii lawọn nnkan ti gbajugbaja onijakadi n ni Hogan ṣe to fa awuyewuye: Hogan jẹri nile ẹjọ lọdun 1994 ninu igbẹjọ Ọgbẹni Vince McMahon to jẹ ọkan lara awọn oludasilẹ ileeṣẹ WWE to n ṣakoso ere ijakadi. Nibi igbẹjọ naa lawọn olupẹjọ ti fẹsun kan McMahon ati ileeṣẹ WWE pe wọn fawọn onijakadi loogun oloro ''steriods'' lo lati maa ja. Nnkan Hogan sọ jẹ ọkan gboogi lara nnkan to jẹ ki ijọba jẹbi ẹjọ naa, ti McMahon si gba idalare. Amọ, ọpọ lo ri Hogan bi ọdalẹ tori o jẹri tako McMahon. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Lọdun 2015 ni wọn yọ Hulk Hogan kuro ninu ẹgbẹ ogbontarigi WWE Hall of Fame lori ẹsun pe o sọrọ kan to ni i ṣe pẹlu idẹyẹsi si ẹya mii. Ṣugbọn wọn gba a pada lẹyin ọdun mẹta ti wọn le kuro nibẹ. Lọdun 2024, Hogan sọ nipa igbakeji aarẹ Amẹrika telẹ, Kamala Harris, o si beere bo ya ki oun ju u soke koun si la a mọlẹ. Hogan sọrọ yii nibi eto kan nibi to ti n mu ọti. Ni ibẹrẹ ọdun 2025 ti Hogan yọju sita ni ọpọ ero bẹrẹ si ni ṣe huu le e lori, eyi to jẹ iyalẹnu fun ọpọ eeyan papaa julọ pẹlu aṣeyọri to ti ṣe ninu ere ijakadi. Oríṣun àwòrán,Getty Images Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Barack Obama ni Hulk Hogan ṣatilẹyin fun ninu ibo aarẹ Amẹrika ọdun 2008, oun naa lo si wọle ibo ọhun. Amọ, Hogan yi ipinnu rẹ pada lẹyin ọdun mẹta. ''Mo ṣatilẹyin fun Obama ko le wọle, ero mi ni wi pe yoo ṣe gbogbo nnkan to sọ. Obama ko mu ileri rẹ lori awọn nnkan to sọ pe oun maa ṣe ṣẹ,'' Hogan lo sọ bẹẹ fun Fox News lọdun 2011. Inu Hogan ko dun si bi Obama ṣe kọ ọrin ti akọle rẹ n jẹ '''Real American'' lasiko ounjẹ alẹ rẹ nileeṣẹ ijọba White House. Bi orin yii ṣe n lọ ni wọn ṣafihan iwe ẹri ọjọ ibi Obama eyi to fidi rẹ mulẹ pe Amẹrika ni wọn bi i si. Ṣaaju ni Donald Trump ti n sọ ahesọ kan pe Obama kii ṣe ọmọbibi orilẹede Amẹrika. Nigba to di asiko idibo aarẹ Amẹrika ọdun 2016, Trump ni Hogan ṣe atilẹyin fun. Trump naa lo tun gbaruku ti lasiko ibo aarẹ ọdun 2020, koda, o tun sọ pe oun gan an le ṣe igbakeji Trump. Hulk Hogan tun sọ pe oun gan an le dupo aarẹ orilẹede Amẹrika. Hogan tun darapọ mawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican lọdun to kọja lẹyin to mori bọ lọwọ awọn to fẹẹ pa a. Oríṣun àwòrán,Getty Images Ogbontarigi onijakadi, Hulk Hogan ti ku lẹni ọdun mọkanlelaadọrin. Ajọ to n mojuto idije ijakadi, WWE, lo fidi iroyin iku Hogan mulẹ ni irọlẹ Ọjọbọ. Ninu atẹjade ti World Wrestling Entertainment ọhun fi sita lo ti sọ pe ibanujẹ nla lo jẹ lati gbọ iku gbajugbaja elere ijakadi Hulk Hogan. Wọn ṣapejuwe Hogan gẹgẹ bi "ọkan lara awọn to gbajumọ julọ", to si ran WWE lọwọ lati di ilumọọka kaakiri agbaye ni nnkan bi ọdun 1980 soke. Wọn ni awọn ba ẹbi, ọrẹ ati awọn ololufẹ oloogbe naa kẹdun. Oríṣun àwòrán,Getty Images Hulk Hogan lo fẹ ẹ jẹ onijakadi to gbajumọ julọ ninu itan ere idaraya naa. Ọdun 1953 ni wọn bi, ti wọn si sọ orukọ rẹ ni Terry Boella. Lati ọdun 1980 titi di nnkan bi 2000, ni Hogan fi jẹ gaba lagbo awọn onijakadi kaakiri agbaye, ko to o di pe o bẹrẹ si ni kopa ninu fiimu ati awọn eto agbelewo mii lori tẹlifisan. Ọdun 1979 lo kọkọ darapọ mọ ẹgbẹ ijakadi to n jẹ World Wrestling Federation to pada di World Wrestling Entertainment. Amọ o ku kuro ni ọdun 1981. Hogan ni oludije gboogi to kọkọ kopa ninu idije WrestleMania niluu New York lọdun 1985, nibi ti oun ati Mr T ti fẹyin Paul Orndorff ati Roddy Piper, janlẹ. Lọdun 2018, ileeṣẹ naa gba a ṣiṣẹ pada, ti wọn si sọ pe o lẹtọọ si anfaani lẹẹkeji. Ṣugbọn ṣa, ọpọlọpọ awọn gbajugbaja elere ijakadi, lara eyi ti New Day ati Titus O'Neil, sọ pe yoo ṣoro lati kan gbagbe ọrọ ti Hogan sọ. Ni ọdun diẹ sẹyin, Hogan kopa nibi ipolongo ibo Trump, ati lasiko ipolongo fun idibo ilẹ America to waye lọdun to kọja. Awọn eero iworan ho le Hogan lori laipẹ yii to lọ si idije WWE kan, nigba to kopa ninu eto ileeṣẹ naa, Monday Night Raw, lati polowo ọtí to n ṣe. Oríṣun àwòrán,corbis/getty images Oríṣun àwòrán,Getty Images Ni gbogbo ọdun 1990 soke, okiki Hogan tayọ kọja ijakadi, pẹlu bo ṣe kopa ninu awọn fiimu bii Mr Nanny ati Suburban Commando. Nitori naa ni ko ṣe jẹ iyalẹnu fun ẹnikẹni nigba ti WWE fi ami ẹyẹ da a lọla gẹgẹ bi akọni manigbagbe ti wọn n pe ni Hall of Fame, lọdun 2005. Wọn tun gba a gẹgẹ ọmọ igbimọ oludari ajọ naa. Amọ ṣa, wọn yọ orukọ rẹ kuro ninu iwe awọn akọni manigbagbe lọdun 2025, nigba ti wọn fi opin si iṣẹ rẹ ninu WWE, nitori pe fidio kan to ṣafihan bo ṣe pe èdè idẹyẹsini kan lu sita.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/ce9x92xrp0eo
|
2025-07-24
|
bbc
|
Thomas Partey, agbábọ́ọ̀lù Arsenal tẹ́lẹ̀ di èèrò ilé ẹjọ́ nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Wọn ti fi ẹsun ifipabanilopọ kan agbabọọlu fun Arsenal nigba kan, Thomas Partey. Ẹsun ọhun to pin si ọna marun un ni wọn lo waye laarin ọdun 2021 si 2022, gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ. Awọn obinrin mẹta lo fi ẹsun ọhun kan Partey - obinrin akọkọ fi ẹsun meji to ni i ṣe pẹlu ifipabanilopọ kan an, obinrin keji fi ẹsun mẹta kan an lori ọrọ kan naa, nigba ti obinrin kẹta fi ẹsun ẹyọkan ṣoṣo kan. Agbabọọlu ọhun to jẹ ọmọ orilẹede Ghana sọ pe, oun ko jẹbi eyikeyi ẹsun ti wọn fi kan oun, ati pe tọwọtẹsẹ ni oun fi gba "anfaani lati fọ orukọ oun mọ". Ọjọ Aje to kọja ni ẹni ọdun mejilelọgbọn ọhun pari iṣẹ rẹ pẹlu Arsenal, lẹyin to ti gba bọọlu fun wọn lati ọdun 2020. BBC News ti kan si Arsenal, ajọ bọọlu, ati awọn alaṣẹ Premier League, lori ọrọ naa. Awọn ẹsun naa jẹyọ lẹyin ti awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣe iwadii lati oṣu Keji ọdun 2022 ti awọn ọlọpaa kọkọ gba iwe ifisun lori ifipabanilopọ. Ẹni to dari ikọ iwadii naa, Andy Furphy, sọ pe oun to jẹ awọn logun ni pipese atilẹyin fun awọn obinrin to ti yọju lati jẹrii lori awọn ẹsun ọhun. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ "Ao rọ ẹnikẹni to ba ni ohunkohun lati ṣe pẹlu ẹjọ yii, tabi to ni awọn nnkan to le ran wa lọwọ, lati yọju si wa." Ọjọ karun un oṣu Kẹjọ ni Partey yoo yọju sile ẹjọ Majisireeti to wa ni Westminster. Ninu atẹjade kan ti agbẹjọro rẹ, Jenny Wiltshire fi sita lo ti sọ pe "Thomas Partey sọ pe oun ko jẹbi ẹsun kankan. "Fun ọdun mẹta lo fi fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọlọpaa ati awọn ọtẹlẹmuyẹ lasiko iwadii wọn. "O si ti ṣetan lati wi awijare rẹ." Bakan naa ni agbẹjọro naa sọ pe onibaara oun ko ni le sọrọ lori awọn ẹsun naa nitori pe o ti di ọrọ ile ẹjọ. Ọdun 2020 ni Thomas Partey kuro ni Atletico Madrid, to si darapọ mọ Arsenal pẹlu £45.3m ninu oṣu Kẹwaa ọdun 2020, Igba marundinlogoji lo kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ fun wọn, o si gba bọọlu sinu awọn ni igba mẹrin. Partey farahan ni idije Champions League ni igba mejila. Yatọ si Arsenal. Partey tun n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Ghana, Black Stars.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cy4nj75kx54o
|
2025-07-04
|
bbc
|
Lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ kejì ní ikùn rẹ̀, Taiwo Awoniyi jí sáyé padà, ó kúrò ní ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Agba ọwọ iwaju Nottingham Forest ati ikọ Super Eagles, Taiwo Awoniyi ti ji lati ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun to wa, lẹyin isẹ abẹ to se. Awoniyi lo farapa yanayana lasiko ifẹsẹwọnsẹ to gba fun ikọ agbabọọlu rẹ nilẹ Gẹẹsi. Awoniyi ni wọn gbe digbadigba lọ ile iwosan ni ọjọ Aje, lẹyin to kọlu opo oju ile bọọlu lori paapa nigba ti ikọ agbabọọlu rẹ n koju ikọ Leicester City lọjọ Aiku to kọja. Iroyin to tẹ wa lọwọ ni ikọlu Awoniyi naa ṣe ọpọ akoba fun awọn ifun inu rẹ. O ṣe iṣẹ abẹ lọjọ Aje, ti o si lo gbogbo Ọjọ Isẹgun ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun. Lọjọru, Awoniyi ṣe iṣẹ abẹ keji, ti wọn di oju awọn egbo to ni. O taji ni irọlẹ Ọjọru, to n si gba itọju ni ile iwosan. Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe gbajumọ agbabọọlu to jẹ ọmọ ilẹ Naijiria, Taiwo Awoniyi, ẹni to tun n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Nottingham Forest, ti wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun bayii. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Awoniyi lo dero ile iwosan lati se isẹ abẹ isọri kinni lori ọgbẹ to ni nikun rẹ, ti ko si ti i laju saye lẹyin isẹ abẹ naa. Gbajumọ agbabọọlu ọhun, tii se ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn lo kọlu opo ojule lasiko ifẹsẹwọnsẹ Nottingham Forest pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Leicester nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ isẹju mejidinlaadọrun. Isẹlẹ naa to waye ni papa isere Ground City lọjọ Aiku lo waye nigba ti agbabọlu naa n gbidanwo lati gba bọọlu lọwọ Anthony Elanga. Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ Darapọ̀ mọ́ wa nibì End of podcast promotion Ikọ elere idaraya ileesẹ BBC gbọ wipe ifun Taiwo Awoniyi bẹ lasiko to kọlu opo ojule naa Alẹ ọjọ Aje ni wọn yara se isẹ abẹ fun to si w anile iwosan naa to si seese ki wọn pari awọn igbesẹ to ku nidi itọju rẹ ni ọjọru. Atẹjade kan ti ẹgbẹ agbabọọlu Nottingham Forest fisita lọjọ Isẹgun ni ara Awoniyi ti n ya lẹyin isẹ abẹ naa. Awoniyi, ẹni ti wọn fi rọpo Ibrahim Sangare nigba to ku diẹ ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari lọjọ Aiku, ni wọn kọkọ fun ni itọju pajawiri fun igba pipẹ lori papa ti wọn ti n gba bọọlu naa. Elanga lo wa ni odikeji nigba to tẹwọgba bọọlu amọ ti igbakeji alamojuto ere bọọlu naa ko gbe asia soke titi ti ikọlu Awoniyi fi waye. Ẹni to ni ikọ agbabọọlu Forest naa, Evangelos Marinakis wa bọ sori papa lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa, to si fi erongba rẹ han si alakoso ẹgbẹ agbabọọlu naa, Nuno Espirito Santo, lori ọwọ ti wọn fi mu itọju ọgbẹ Awoniyi. Atẹjade ti ẹgbẹ agbabọọlu Forest fisita naa ni ọgbẹ ti Taiwo Awoniyi ni lori papa yii lo jẹ ohun iranti nipa ọpọ ewu to rọ mọ ere idaraya naa ati idi tie to ilera agbabọọlu kọọkan ati alafia wọn se gbọdọ jẹ ohun pataki lati kọkọ mu lọkunkundun. Ọjọ Kejila osu Kẹjọ ọdun 1997 ni wọn bi Taiwo Michael Awoniyi sile aye ni ipinlẹ Kwara. Akọsẹmọsẹ agbabọọlu ni Awoniyi, ẹni to n gba bii agbaarin fun ẹgbẹ agbabọlu fun Nottingham Forest ati ikọ agbabọọlu Naijiria. Lọdun 2010 ni wọn dibo yan Awoniyi bii agbabọọlu to se iyebiye julọ nibi idije ere bọọlu ti Cocacola se onigbọwọ rẹ nilu London. Isọwọ gba bọọlu Awoniyi lo mu ki gbajumọ agbabọọlu, Seyi Olofinjana kiye si, to si ransẹ pe e lati dara pọ mọ ile ẹkọ fawọn agbabọọlu, Imperial Soccer Academy. Awoniyi lo gba bọọlu fun Naijiria nibi idije ife ẹyẹ agbaye fawọn ọjẹ wẹwẹ agbabọọlu ti ọjọ ori wọn ko to ọdun mẹtadinlogun lọdun 2013. O si yege ninu idije ere bọọlu naa pẹlu ami ayo mẹrin. Awoniyi jẹ ibeji, ti ekeji rẹ, Kehinde si jẹ obinrin. Gbajumọ agbabọọlu naa lo seto idana pẹlu ibeji miran, Taiye Jesudun ni ọjọ kẹẹdogun osu Kẹfa ọdun 2018 nilu Kabba nipinlẹ Kogi. Igbeyawo wọn lo waye nilu Ilorin ni ọjọ keji idana naa, ọmọlẹyin Kristi ni Taiwo Awoniyi I se.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/c89pxk3jxgno
|
2025-05-14
|
bbc
|
Ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa Peter Rufai, ohun táwọn èèkàn ń sọ nípa rẹ̀
|
Oríṣun àwòrán,Getty Images Peter Rufai, ọkan gboogi ninu awọn asọle fun ẹgbẹ agbaboolu Nigeria, Super Eagles, to tun jẹ olokiki fun ere bọọlu ni ilẹ adulawọ padanu ẹmi rẹ lọjọ kẹta oṣu keje ọdun 2025, ti ọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu kaakiri agbaye si n ṣe idaro rẹ. Akọni ti yoo ṣoro fun ọpọ lati gba ni Rufia jẹ pẹlu bi o ti ṣe gba Super Eagles silẹ ni ọpọ igba lasiko idije ere bọọlu. Dodomayani ni ọrukọ ti ọpọ akẹgbẹ rẹ ati awọn ololufẹ rẹ ma n pe, to si jẹ ọkan lara agbabọọlu Nigeria to gbe ẹgbẹ naa sita fun araye lati ri. Inu idile Oba ni won bi Peter Rufai si lọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹjọ ọdun 1963 ni Oshodi, nipinlẹ Eko. Baba rẹ jẹ ọkan lara Oba to jẹ ni Idimu. Ọpọ lo n ro pe yoo bọ sipo awọn Baba rẹ ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba to kọ lati tẹwọgba ipo yii nitori ifẹ rẹ fun ere bọọlu. Oríṣun àwòrán,Getty Images Rufai bẹrẹ si ni gba bọọlu rẹ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Stationery Stores ati Femo Scorpions ko to di pe o lọ Oke okun. O gba bọọlu fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu kan lorilẹede Benin (Dragons de l'Ouémé), niluu Belgium (Lokeren, Beveren), ni Netherlands (Go Ahead Eagles), Portugal (Farense, Gil Vicente), ati ni Spain (Hércules, Deportivo La Coruña), to si ni ọpọ iriri kaakiri agbaye. Ni saa ere idaraya 1994–95, Rufai ko ipa nla lati ran ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Portugal SC Farense lọwọ lati kopa fun igba akọkọ ninu idije UEFA Cup qualification. O fi ọpọ itan lelẹ lasiko naa. Rufai gba bọọlu fun orilẹede Nigeria fun igba marundinlaadọrin, to si jẹ asọle akọkọ fun ikọ Super Eagles ninu idije ife ẹyẹ agbaye ni ọdun 1994 ati 1998. End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Bakan naa lo ko ipa ribiribi ni ọdun 1994 lasiko ife ẹyẹ ile adulawo to wa ni orilẹede Tunisia. Oríṣun àwòrán,Getty Images Pe ki Gooli mi awọn lo jẹ ohun ti ko ki n fi bẹ waye. Ṣugbọn Rufia ni oreọfẹ yii lati mi awọn fun orilẹede rẹ. O gba pẹnariti fun Nigeria lasiko ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Ethiopia lọdun 1993. Ọpọ awọn awọn ololufẹ rẹ lo ma n pe ni "Dodo Mayana" nitori bi o ṣe ma n fo lọ mu bọọlu ati bi o ṣe ma dena de bọọlu lati ma wọ awọn. Ọrukọ naa ni ọpọ n pe titi to fi jade laye. Lẹyin igba ti Rufia fẹyinti lẹnu iṣẹ ere bọọlu, o pada si yara ikawe ni ọdun 2023, to si lọ si ile ẹkọ ni National Institute for Sports ni ile Eko lati iwe ẹri fun olukọni. O fẹran idagbasoke awọn ọdọ, Rufai da ile ẹkọ Staruf Football Academy silẹ niluu Eko. O jẹ eeyan to n ṣe igbalarugẹ ile ẹkọ ati ere idaraya , to si n rọ awọn obi pe ki wọn ṣe igbalarugẹ awọn ọmọ wọn ti wọn nifẹẹ ere idaraya. Oríṣun àwòrán,Getty Images Awọn akẹgbẹ oloogbe Peter Rufia ti bọ sita lati sọ nipa igbesi aye oloogbe ati awọn mọnigbagbe to wa laaarin wọn. Ọpọ wọn ni wọn fi ibanujẹ jẹ ọkan wọn nigba ti wọn ba BBC sọrọ lori igbesi aye oloogbe naa. Adegboye Onigbinde, olukọni fun ikọ Super Eagles ni oun o le gbagbe bii oloogbe ṣe ọkan ninu gba bọọlu fun orilẹede Nigeria. Onigbinde ni iwa irẹlẹ ni Oloogbe jẹ ohun to mu tayọ lasiko to n gba bọọlu. O wa aladura pe ki Ọlọrun duro ti mọlẹbi ati ọrẹ ti oloogbe naa fi silẹ. Mutiu Adepoju, agbabọọlu Nigeria tẹlẹ ri nigba kan ri iku Peter Rufia lo jẹ ajalu nla fun agbo ere bọọlu. O ni mọ iyi oloogbe naa bi o ṣe ma n ki oun pe oun ni agbara lati jẹ goolu pẹlu ori ju ẹsẹ oun lọ.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/ckgj229edpeo
|
2025-07-04
|
bbc
|
'Ìfẹ́ tí mo ní sí ọ̀bọ ló jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ eré ìdárayá lílo ọwọ́ àti ẹsẹ̀ fi sáré'
|
Ó ti pẹ́ ti mo ti fẹ́ràn ọ̀bọ tó sì máa ń wù mí láti mọ eré sá bíi wọn. Èyí ni ọ̀rọ̀ tó jáde lẹ́nu Kenichi Ito tó máa ń sáré pẹ̀lú ọwọ́ àti ẹsẹ̀, tó sì ń sáré pẹ̀lú ọwọ́ àti ẹsẹ̀ jùlọ ní àgbáyé. Ito tó máa ń sáré pẹ̀lú ọwọ́ àti ẹsẹ̀ kílómítà ọgọ́rùn-ún láàárín ìṣẹ̀jú àáyá 15.71. Ó ní ọdẹ kan rò wí pé ẹranko kan ni òun lásìkò tí òun ń gbáradì fún ìdíje tó sì na ìbọn sì òun. Ó sọ pé òun sáré fò dìde láti sọ fun pé èèyàn ni òun, òun kàn máa ń sáré bí ọ̀bọ ni. Báyìí, eré ìdárayà lílo ọwọ́ àti ẹsẹ̀ láti fi sáré, tí wọ́n ń pè ní Quadrobics ti ń tàn káàkiri orí ayélujára àti káàkiri àgbáyé pàápàá jùlọ ní orílẹ̀ èdè Russia. Kódà àwọn ọmọdé náà ti ń ṣeré ọ̀hún àmọ́ àwọn olóṣèlú kan ti ń sọ pé eré náà kò bójú mú àti pé ó lòdì sí àṣà ilẹ̀ Russia.
|
https://www.bbc.com/yoruba/articles/cnvzrdllr0eo
|
2025-12-04
|
bbc
|
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.