audio audioduration (s) 1.84 20 | transcription stringlengths 21 95 |
|---|---|
Ó ti pé ọgọ́rùn-ún ọjọ́ tí ìjọba ti f'òfin de wá. | |
Gómìnà obìnrin ẹyọ kan péré la ti ní ní ìpínlẹ̀ Ayédé | |
Inú àbótí ńlá ni Àjàní kó gbogbo àwọn aṣọ rẹ̀ sí. | |
Kò sí ìwé ẹ̀rí fun olùdíje tí àwọn ẹgbẹ́ onígbàálẹ̀ fà kalẹ̀. | |
Àmọ̀tẹ́kùn ti gba àṣẹ ìdáábòbò lọ́wọ́ ìjọba. | |
Ọ̀gá ni Bọ́lá jẹ́ fún Bọ̀dé lágbo òṣèlú. | |
Àsìkò àjàkálẹ̀ ààrùn yìí jẹ́ kí n di télọ̀ tó mọṣẹ́ gidi. | |
Ó ṣeé ṣe kí ọdún wáyé lábẹ́ àwọn òfin tuntun nípa arùn àjàkáyé | |
Ọmọ àlè ti fi ilé jóná báyìí nílùú Ìbàdàn. | |
Àrẹ̀mú faraya lórí báwọn jàǹdùkú ṣe ń borí ọmọogun wa. | |
Ọ̀daràn mẹ́jọ ni wón mú ní ìlú Èrúwà lánàá. | |
Lọ sí ilé Délé Gíwá láti wo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń gbé ibẹ̀. | |
Àjọ elétò ìlera ti ní íjọba ti ra àwọn ohun ìgbógun ti ààrùn. | |
Omi gbé arákùnrin ẹni ọdún mẹ́tàlá kan lọ ní Ìbàdàn | |
Àdúrà ò ní padà gbà mọ́ nígbà tí àbòsí bá ti pọ̀ jù. | |
Wo ohun tí òṣìṣẹ́ yìí ṣe tí ọ̀gá rẹ̀ fi fún ní ẹ̀bùn owó. | |
Agbẹjọ́rò ẹbí olóògbé Láwuyì ti yá owó ńlá kan ní báǹkì | |
Arákùnrin tí àwọn ọlọ́pàá mú ní òun kìí ṣe olè. | |
Àwọn Dókítà kan ti da iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí àti gba owó lọ́wọ́ ìjọba | |
Tírélà agbépo ṣekúpa ọmọ ọdún méjì àti àwọn mẹ́ta míì | |
Àwọn Fúlàní ya bo ilé ìtura àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa | |
Wọ́n fi Ṣàǹgó búra fún ààrẹ Nàìjíríà tuntun. | |
Wọ́n ti rán Adéṣọlá lọ ésí ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélọ́gbọ̀n | |
Ìyálé mi ti di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ nínú ìlú, kò sí ẹni tó le múu | |
Ọkọ àti ìyàwó ti gbọ̀nà oko lọ láti àárọ̀. | |
Ilé ẹjọ́ gíga wọ́gilé ìyọnípò Àdìsá gẹ́gẹ́ bíi alága ẹgbẹ́ rẹ̀. | |
Ẹnìkan pe àwọn wí pé ilé kan ń jó ní agbègbè náà. | |
Ọwá Obòkun ni orúkọ ọba ìlú Iléshà, Ajerò ni ti Ìjerò | |
Túndé kó sí gbaga ọlọ́pàá nítórí ikú ọmọ ọdún mẹ́wàá kan. | |
Ó tẹ̀síwájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tó farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà. | |
Lékan ní òun kò lérò pé òun le mókè nínú iṣẹ́ orin. | |
Pásítọ̀ na àwọn ọmọ ìjọ láti mọ̀ bí wọn ṣe gbóná fún Ọ́lọ́run tó. | |
Gómìnà Makinde bá mọ̀lẹ́bí ọkùnrin náà kẹ́dùn lọ́jọ́ náà | |
Ìjọba àpapọ̀ ń sọ̀rọ̀ tòótọ́ fún wa. | |
Ìwòsàn ló bá Kẹ́mi dáwọ́ ìtọ̀ dúró. | |
Túńdé pe gbogbo ẹgbẹ́ jọ láti sọ fún wọn pé kí wọ́n gbaradì. | |
Bí àwọn ará ìlú ṣe fara mọ́ ṣíse àbẹ́rẹ́ àjẹsára ni mo ta kò | |
Ẹ̀bà gígan ni Bísí jẹ sùn lánàá. | |
Awọn akọ́mọlédè lórílẹ̀ èdè yìí ti rọ àwọn ọmọ Yorùbá lóyè | |
Ẹgbẹ́ fún ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé ti fún àwọn obìnrin lówó níbàdàn. | |
Nínú Ọlọ́pàá àti ààrùn jẹjẹrẹ, èwo ló yẹ ka bẹ̀rù? | |
Àwọn àgbàgbà ọlọ́pàá ti ṣàánú ọmọbìnrin tí wọn gbámú | |
Àwọn aṣòfin ilẹ̀ Nàìjíríà ṣọ̀rọ̀ ìwúrí nípa Ajímọ̀bí. | |
Olórí gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó lóòótọ́, tí ò ní máa ṣọ̀tún-ṣòsì. | |
Olúọmọ oṣòdì má gbé jàgídíjàgan wá. | |
Ẹ tẹ ọkùnrin tó bá fipá bá obìnrin lòpọ̀ ní ọ̀dá, ìwà ìkà ni. | |
Ìdí tí Ìyábọ̀ Ọbásanjọ́ fi ṣe pàtàkì ní ìpínlẹ̀ Ògùn nìyí o | |
Àjẹ́ ni àwọn ìyá Àjànàkú àti Àlàbí. | |
Mo fẹ́ bá àwọn ọmọ Ajílẹ́yẹ ṣeré fún bí ọdún mẹ́ta síi | |
Ikú burúkú ló pa ìyàwó Rẹ̀mí ní ìjẹrin. | |
Ẹni tí ò bá lérò, tí ò létò, o lè jẹ́ olórí ti wa. | |
Olúmidé ti rọ àwọn ènìyàn pé kí wọn má fojú òṣèlú wo àbẹ̀wò òun. | |
Ǹkan mẹ́ta ló fàá tí jàndùkú fi ń yìnbọn pa àwọn ọlọ́pàá | |
Àwọn aṣewádìí náà gbọ́dọ̀ ri pé wọ́n ṣe ìwádìí wọn fínnífínní | |
Wọ́n ní àwọn méjìlá ní wọ́n bódòlọ. | |
Adébimpé gba omijé lójú Adédiméjì. | |
Àwọn jàndùkú jí Rẹ̀mí gbé. | |
Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ arákùrin ajínigbé kan ní ìlú Òṣogbo. | |
Bùhárí ń bèèrè fún àforíjìn gbèsè tí a jẹ lọ́dọ̀ àjọ àgbáyé | |
Ìpinu mi fọ́dún yìí ni láti yí padà si obìnrin pátápátá. | |
Àwa la gbé ìgbá orókè nínú ìdíje eré bọ́ọ̀lù ní Ìbàdàn | |
Bílíònú mẹ́fà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti yòó ná lórí Àmọ̀tẹ́kùn. | |
Gómìnà Ọbásànyà yọ ọ̀gá ikọ̀ ọlọ́pàá nípò. | |
Adéwálé fèsì padà pé àwọn àgbààgbà tó ní owó lọ́wọ́ wà níbẹ̀. | |
Ṣé lóòtọ́ ni pé ilé ẹjọ́ sọ pé kí Àrẹ̀mú lọ sí ẹ̀wọ̀n. | |
Wo ọ̀nà láti jẹ ànfàní ìforúkọsílẹ ọ̀fẹ́ tí ìjọba gbékalẹ̀. | |
Sanwó Olú ti gba àwòrán apanilẹ́rín kan nílùú Èkó. | |
Ọwọ́ àwọn agbófinró tẹ afurasú oníjìbìtì tó lu Kẹ́mi ní jìbìtì owó. | |
Láàárín ìdílé ẹlẹ́ni márùn-ún yìí, ọmọ kan ṣoṣo ló léè sọ̀rọ̀. | |
Irọ́ ni wọn ń pa, mi ò sálọ sí sílẹ̀ òkèrè nítorí ìwọ́de. | |
Òtútù àsìkò yìí pọ̀ lápọ̀ jù. | |
Esì àyẹwò ọmọ ati ìyáwọ ọmọ Atiku ti jáde. | |
Wo ìkílọ̀ Ìjọba àpapọ̀, Ọlọ̀pàá àti Gómìnà Sanwó-olú. | |
Ààrẹ àkọ́kọ́ ní Ọ̀yọ́ jáde láyé. | |
Mo ní kí wọ́n yé ṣe àwáwí fún bàbá Ìjẹ̀shà fún oun tó ṣẹ | |
Àwọn èèyàn pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ ní Èkó. | |
Orilẹ ede Nàìjíríà ni lati ni ilọsiwaju ninu iṣẹ sinimá. | |
Ẹni tó fí ìbínú lu Ábúdù ọlọ́kadà pa ní Abẹ́òkuta ti sálọ. | |
Ayẹyẹ elégún yẹn yóò párí ní Ọjọ́ Ajé tó ń bọ̀. | |
Odùduwà sọ fún Oyètọ́lá nípa ọ̀gá ilé ìwé mẹ́ta tó dá dúró | |
Ojú ẹni máa là, á rí tó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. | |
Wọ́n ti kéde ètò ìsìnkú Ajímájàṣán àti ọjọ́ tí wọn yóò sin-ín | |
Adébáyò wá kábàámọ̀ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n ń tọwọ́ òṣèlú bọ. | |
Ọdún kẹ́ta rẹ̀é ti ọkọ àti ìyàwó ò tí ì bímọ. | |
Ìbànújẹ́ gba ìlú kan nígbà tí àṣìta ìbọn ba ọmọ ọdún méjì kan. | |
Lọ́dọ̀ àwọn agbẹjọ́rò tó ń gbé Ìshẹri ni mo ti kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ | |
Màmá tó jẹ́ onímọ̀ òye kọjá lọ ní àárọ̀ kùtùkùtù lánàá | |
Wọ́n ní kí àwọn èèyàn dẹ́kun láti máa pe àwọn obìnrin ní aṣéwó. | |
Àwọn ológun ti gbàjọba ní ìlú kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Odò Ọya | |
Gómìnà Oyètọ́lá ti pè fún alàáfíà láàrin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ | |
Amọ̀fin tó ń ṣáájú ikọ̀ agbẹjọ́rò fún ẹgbẹ́ náà ní ìlànà. | |
Iléẹjọ́ ṣe ìdájọ́ iléìfowópamọ́ lori ìwà jìbìtì. | |
Ọlá yóò gúnlẹ̀ sí Ọ̀yọ́ ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀. | |
Èmi àti Túndé ti kọ́ ẹ̀kọ́ síi nípa ààlọ́ Yorùbá | |
Kí lẹ̀ ń bú ààrẹ fún nítorí Ọlọ́run. | |
Ènìyàn mẹjọ mìíràn tún ti ní ààrùn jẹjẹrẹ ní Nàìjíríà. | |
Ọkùnrin nìkan náà ni ó lè wo orò ní ilẹ̀ Yorùbá. | |
Rẹ̀mi ti kú nípa ìkọlù tó wáyé. | |
Àwọn olórí Yorùbá ti ní kò ní sí ètò ìdìbò lọ́dún tó ń bọ̀. | |
Ìtàn málegbàgbé ni àwọn ìtàn akọni bíi Mọ́remí ní àwùjọ Yorùbá. |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.