en
stringlengths 7
537
| yo
stringlengths 6
583
|
|---|---|
English
|
Yoruba
|
Pending the time she would finally pack and go, everybody should be content with eating just anything.
|
Títí di ìgbà tí ó máa fi kó ẹrù rẹ̀ lọ pátápátá, kí oníkálùkù ní ìtẹ́lọ̀rùn pẹ̀lú ohunkóhun tó bá rí jẹ.
|
She knew how best she was going to take care of herself and Tinu.
|
Ó mọ bí ó ṣe má a tọ́jú ara rẹ̀ àti Tinú.
|
Alamu Should learn to look after himself.
|
Kí Àlàmú kọ́ bí ó ṣe máa tọ́jú ara rẹ̀.
|
His old Mama should not come back again and be given the chance to snap and make any further wicked insinuations.
|
Kí ìyá rẹ̀ má tún padà wá láti máa jágbe kí ó sì pòwe ìkà kankan.
|
Now it was going to be everybody for himself, God for us all.
|
Báyìí, ó ti di kí olórí dorí ẹ̀ mú, kí oníkálùkù wà fún ra ara rẹ̀, Ọlọ́run wà fún gbogbo wa.
|
Labake assumed a "na him sabi" posture and found herself suddenly in high spirits, she sang in high pitch, her voice rang like a bell.
|
Làbákẹ́ ń ṣe ìṣe "òun ló mọ̀" ọkàn rẹ̀ déédé gbé sókè láti kọ orin rẹ̀ pẹ̀lú ohùn òkè, ohùn rẹ̀ dún bí i agogo.
|
Her countenance was gay.
|
Ìrísí rẹ̀ fi inú dídùn rẹ̀ hàn.
|
She told herself she had no problem.
|
Ó sọ fún ara rẹ̀ pé òun kò ní ìṣòro kankan.
|
Nothing to worry about.
|
Kò ní nǹkankan láti dààmú fún.
|
No woman on earth in the whole wide world was ever as happy as she was.
|
Kò sí obìnrin náà lórí ilẹ̀ ní gbogbo ayé tí inú rẹ̀ dún tó bí inú rẹ̀ ṣe dùn.
|
Why should she not be happy?
|
Kí ló ṣe tí inú rẹ̀ kò ní dún?
|
Her days were numbered in Alamu's house.
|
Ọjọ́ rẹ̀ ti níye nínú ilé Àlàmú.
|
The days of sorrow and tribulations were numbered.
|
Ọjọ́ ìbànújẹ́ àti wàhálà rẹ̀ ti níye.
|
The divorce suit was well on the way, she'd almost finished packing her things.
|
Ẹjọ́ ìkọ̀sílẹ̀ ti wà lọ́nà, òun náà ti fẹ́rẹ̀ ẹ́ palẹ̀mọ́ àwọn nǹkan rẹ̀ tán.
|
Tinu gave her no problem, the little girl was full of life and spirit, she herself had been blessed with good health.
|
Tinú ò sì fún un ní wàhálà kankan, ọmọbìnrin kékeré náà kúnfún ìyè, ẹ̀mí àlàáfìà tó péye ni Ọlọ́run fi jíǹkí òun fún ara rẹ̀.
|
In spite of the difficult period at home she'd maintained her pretty look, her elegant posture.
|
Ládúrú ìnira tó wà nílẹ̀ ó sì rẹ̀wà síbẹ̀, ìdúró rẹ̀ dún síbẹ̀.
|
Nobody seeing her would ever think she was a woman with problems.
|
Kò sí ẹni tó má ri tá sọ pé obìnrin tó ní ìṣòro ni.
|
With her present girlish shape and figure, she could go back to England and re-enter the glamorous world of fashion.
|
Pẹ̀lú ìrísí omidan tí ó ní lọ́wọ́ lọ́wọ́ yìí, ó lè padà sí England kí ó sì tún padà sí àyè oge síse ẹ̀.
|
She would need only three or four months tuning up and reconditioning her body, then catch up finally.
|
Á kàn nílò láti tún ara rẹ̀ ṣe fún bí oṣù mẹ́ta sí mẹ́rin, á padà sípò.
|
So no regrets, she sang hilariously, she clapped her hands, she danced.
|
Fún ìdí èyí, kò sí àbámọ̀, ó rẹ́rìn-ín tàríyá-tàríyá, ó palẹ̀mọ̀, ó jó.
|
Her soprano voice was throated, and trembling, she wiggle her hips the imaginary rhythm of the brass and the wind instruments, she took measured steps forward backward and jumped up excitedly telling herself again and again that she was a happy woman, happy... h-a-p-p-y! happy... very happy.
|
Ohùn òkè rẹ̀ tínrín, ó sì ń gbọ̀n rìrì, ó jùdí sí ìlú àti orin inú afẹ́fẹ́ tí ó ń rò lọ́kàn, ó ka ìwọ̀n ẹsẹ̀ díẹ̀ síwájú-sẹ́yìn ó ń fò sókè tìdùnnú-tìdùnnú, ó tún sọ fún ara rẹ̀ léraléra pé obìnrin tí ó láyọ̀ ni òun, ó láyọ̀... l-á-y-ọ̀! láyọ̀... láyọ̀ gidi gan.
|
Labake straightened her back and threw out her chest, arms swung freely, her feet marked time left, right, left right, she was sweating!
|
Làbákẹ́ na ẹ̀yìn, ó sì ti àyà sí wájú, ó jupá láìsídìíwọ́, ó ń gbé ẹsẹ̀ sósì sọ́tùn-ún, sọ́tùn-ún sósì, ó ń làágùn!
|
But wait... what really was happening?
|
Ṣùgbọ́n dúró ná ó ... kí gan-an ló ń sẹlẹ̀?
|
Labake stopped briefly to ask herself.
|
Làbákẹ́ dúró díẹ̀ láti bi ara rẹ̀ ní èyí.
|
She held her breath minute, pondering.
|
Ó sé èémí fún ìṣẹ́jú kan, ó ń wòye.
|
Why all this show of excitement and intoxication?
|
Kíni ìdí fún gbogbo àfihàn ìdùnnú àti ìyírí yìí?
|
Was she going mad? Was she going crazy too?
|
Ṣe òun ti ń ya wèrè? Ṣe òun náà ti ń ya wèrè ni?
|
"No, No," she answered herself... No.
|
"Rárá, Rárá o," ó dá ará rẹ̀ lóhùn ... Rárá.
|
It was Alamu going mad, it was Alamu who had infact, gone mad.
|
Àlàmú ló ń sínwín, kódà, Àlàmú ló tí ya wèrè.
|
Not her ... Not her!
|
Kìí ṣe òun ...kì í ṣe òun!
|
Before God and man!
|
Níwájú Ọlọ́run àti ènìyàn!
|
Labake stretched forward her two arms and danced, more enthusiastically, to that imaginary rhythm of music.
|
Làbákẹ́ ná ọwọ́ rẹ̀ méjéèjì síwájú, ó sì jó pẹ̀lú ìtara sí ìlú àfinúrò orin náà.
|
No more problem for her.
|
Kò sí ìṣòro fún un mọ́.
|
She was happy, quite happy. She breezed into the sitting room with her clumsy dancing footsteps, her strange, intricate movement of the hips, slowly towards the standing mirror where she became even more excited
|
Inú rẹ̀ dùn, ó dùn dáadáa. Ó bẹ́ wọ inú yàrá ìgbafẹ́ pẹ̀lú ìgbésẹ̀ ijó rẹ̀ tó lọ́pọ̀, ìsọwọ́jùdí rẹ̀ sàjèjì, ó ń rìn súnmọ́ jígí adádúró díẹ̀díẹ̀ níbi tí inú rẹ̀ ti tún bọ̀ dùn sí i.
|
She threw up her two hands into empty air and twisted her body round and round and round several times - until she became dizzy.
|
Ó ju ọwọ́ rẹ̀ méjéèjì sínú afẹ́fẹ́ ó sì yípoyípo láìmọye ìgbà títí tí òyì fi kọ́ ọ.
|
Then she slumped into the nearby chair, breathing heavily, perspiring profusely.
|
Ó sì ṣubú sínú àga tí ó wà nítòsí, ó ń mí lókèlókè.
|
Then the whole building started a momentary journey into space with her as its solitary astronaut...
|
Lẹ́yìn èyí ni gbogbo ilé bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò àjò pàtàkì sínú òfurufú pẹ̀lú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adáwakọ̀ òfurufú ...
|
Why? Why all these? She asked herself again. What's happening? Wasn't she really running out of her mind too?
|
Kíni ìdí? Kíni ìdífún gbogbo èyí? Ó tún ara rẹ̀ bi. Kí ló ń sẹlẹ̀? Se orí tirẹ̀ náà o ti máa yí báyìí?
|
Zenabu heaved a heavy sigh from behind the pantry door where she stood watching her madam.
|
Sènábù mí kanlẹ̀ láti ẹ̀yìn ìlèkùn ilé ìkóunjẹpamọ́ sí níbi tí ó ti ń dúró wòran màdáámù rẹ̀.
|
She had heard madam's strange songs and now she's seen her dance a strange, off-beat dance.
|
Ó ti gbọ́ àwọn orin àjèjì màdáámù, ó sì tún ti rí ijó abàmì rẹ̀ tí ò bálù mu.
|
As she tried to get back inside the pantry to avoid her attention, she knocked her head against the wall and tripped over the plates she'd just brought inside the pantry.
|
Bí ó ṣe wá ń gbìyànjú àti padà sínú ilé oúnjẹ láti má jẹ́ ki wọ́n rí i, ó sẹrí mọ́ ògiri, ó sì ṣísẹ̀ sórí àwọn abọ́ tí ó sẹ̀sẹ̀ kó wọ ilé oúnjẹ náà.
|
There was something about madam now that was always pushing Zenabu away from her.
|
Nǹkankan máa ń wà nípa màdáámù báyìí tí ó ń lé Sènábù lára rẹ̀ ni gbogbo ìgbà.
|
Each time she saw her something always told her to run away, or hide.
|
Nígbàkúgbà tí ó ba rí i, nǹkankan máa ń sọ fún un pé kí ó sá lọ, tàbí kí ó sá pamọ́.
|
Madam had been so aggressive in recent times.
|
Màdáámù ti ń kanra ganan lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.
|
It did not appear that she liked her anymore - the way she now looked and talked to her.
|
Kò fẹ́ jọ pé ó fẹ́ràn rẹ̀ mọ́ ìsọwọ́ wò ó àti bí ó se ń ba sọ̀rọ̀.
|
Each time madam showed up in the sitting room, therefore, Zenabu would find her way into the toilet to answer nature's call!
|
Nígbàkúgbà tí Màdáámù bá farahàn ní yàrá ìgbafẹ́, kíá ni Sènábù máa ń wábi gbà wọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ láti lọ sẹ̀yọ́!
|
But, it did not seem as if that trick would work anymore.
|
Sùgbọ́n kò fẹ́ jọ pé ọgbọ́n yẹn máa ṣiṣẹ́ mọ́.
|
Because only yesterday, madam cried out: Zenabu! Zenabu! Where is this mischievous little creature?
|
Nítorí àná alánàá ni màdáámù ṣì kígbe pé: Sènábù! Sènábù! Ibo ni èké kékeré yì wà?
|
Here madam! Here madam! Zenabu had answered.
|
Níbí Màdáámù! Níbí Màdáámù! Sènábù dáhùn.
|
"Inside the toilet as usual? What the hell is wrong with this little wretch?
|
Nílé ìgbọ̀nsẹ̀, bí ó ṣe ń ṣe? Kí ni ó ń bá olòṣì kékeré yìí jà ná?
|
Always in the toilet 'Nothing madam! Here I am madam!" Zenabu had stood before her, looking at her pleadingly.
|
Gbogbo ìgbà ní ilé ìgbọ̀nsẹ̀ "kò sí nǹkankan Màdààmú, èmi rè é màdààmú" Sènábù dúró níwájú rẹ̀, ó ń wò pẹ̀lú ojú ẹ̀bẹ̀.
|
Madam's smart fingers caught Zenabis little ears, and as she uttered some obscenities shook her violently, pushing her hither and thither.
|
Ọwọ́ màdààmú ti yára gbá etí Sènábù kékeré mú ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìríra sí i, ó gbò ó jìgìjìgì síbí sóhùn-ún.
|
You will soon go away!' she shouted, "your job here is almost done, you don't seem to know.
|
Ó pariwo, "Wà á tó lọ, isẹ́ ẹ ti fẹ́rẹ̀ ẹ́ tán, ó dàbí i pé o ò mọ̀.
|
Soon you'll be returned to your people.
|
Láìpé, wọn á dá ẹ padà fún àwọn ènìyàn rẹ̀.
|
Give me just two or three days.
|
Fúnmi lọ́jọ́ méjì sí mẹ́ta.
|
Labake let go her hands and Zenabu's body hit the floor with a thump!
|
Làbákẹ́ tú ọwọ́ rẹ̀, Sènábù sì subú, gbà!.
|
There was nobody near to tell all these to.
|
Kò sẹ́nikẹ́ni nítòsí láti sọ gbogbo èyí fún.
|
Zenabu, very much, longed for somebody to relate her experience to - a trusted person, one who would understand and pity her.
|
Ó wu Sènábù púpọ̀ láti rẹ́ni sọ ìrírí rẹ̀ fún - ẹni tó ṣe é fọkàn tán, ẹni tí yóò yé, tí yóò sì káàánú ẹ̀.
|
Imagine her joy when at last, old Mama again knocking at the door of the house.
|
Ẹ wòye bí ayọ̀ rẹ̀ ṣe kún tó nígbẹ̀yìn gbẹ́yín tí màmá àgbà tún kan ìlẹ̀kùn ilé yẹn.
|
And her all alone in the house too!
|
Tí ó tún bá òun nìkan nílé!
|
Mama had barely taken her seat when Zenabu's tongue started to wag like the restless tail of a dog on seeing its owner.
|
Màmá ò tíì jóòkó tàìjókòó ti ahọ́n Sènábù bẹ̀rẹ̀ si í gbòn bí i ti ìrù ajá tí ó ń mì tí ó bá rí olówó rẹ̀.
|
Madam has gone mad! Zenabu announced to old Mama.
|
Màdáámù ti ya wèrè! Sènábù kéde fún màmá àgbà.
|
Gone thoroughly mad! It is a great looks wild like the bush cat.
|
Wọ́n ti ya wèrè gan-an! Ó ti jọ ehànnà, bí ológbò-igbó.
|
Her rough bushy hair has dropped carelessly over her neck, stretching to her shoulders making her look like a devil.
|
Irun rẹ̀ tí ó ki bí i igbó yẹn ti dà wálẹ̀ sí èjìká rẹ̀, èyí sì ń jẹ́ kí jọ èṣù.
|
Her finger nails are now very long and sharp, like the beak of the kingfisher.
|
Èékánná rẹ̀ ti wá gùn gan-an ó sì mú, à fi bí ti ẹnu ẹyẹ.
|
There was not a day madam would not deep her long nails inside her cheeks and pull her by the ears.
|
Ọjọ́ kan ò lè kọjá kí màdáaḿù má ti èékánná yẹn bọ̀ ọ́ lẹ́rẹ̀kẹ́ kí ò sì fà á létí.
|
She showed her blistered ears and swollen cheeks to Mama.
|
Ó fi etí àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ wíwú han màmá.
|
Madam would one day tear her to pieces, at the rate she was going, with those long, sharp nails of hers or with those snaggy iron teeth because she had become mad.
|
Màdáámù á sì yá á sí wẹ́wẹ́ níjọ́ kan pẹ̀lú bí ó ṣe ń lọ yìí, pẹ̀lú èékánná gígùn rẹ̀ tí ó mú yẹn tàbí eyín irin rẹ̀ yẹn nítorí ó tí ya wèrè.
|
Very mad, Zenabu confessed she was fed up, and would like to go back to her people at home.
|
Wèrè gidi, Sènábù jẹ́wọ́ pé ó ti sú òun, á sì wù òun láti padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ nílé.
|
Listening to Zenabu relate her story gave Mama great joy.
|
Màmá láyọ̀ ńlá bí ó ṣe ń tẹ́tí sí bí Sènábù ṣe ń sọ ìtàn rè.
|
She patted the little girl on the back and told her not to worry.
|
Ó fi ọwọ́ lu ọmọ náà jẹ́jẹ́ lẹ́yìn, ó sì sọ fún un pé kí ó má ṣe dààmú.
|
All would be well at last...
|
Ohun gbogbo á dára níkeyìn ...
|
It was good Labake was running mad.
|
Ó dára bí Làbákẹ́ ṣe ń yí lórí.
|
It was expected.
|
Ohun tí wọn ń retí ni.
|
Mama was not surprised.
|
Èyí kò sì jẹ́ ìyàlẹ́nu fún màmá.
|
Esuniyi had told her Labake would have a bitter taste of her own medicine before long.
|
Èṣùníyì ti sọ fún un pé Làbákẹ́ á jẹ nínú ẹ̀fọ́ ìkà tí ó ti rò kí ó tó pẹ́.
|
And now, it has started to happen, greater things were soon going to happen.
|
Ní báyìí, ó tí wá ń sẹlẹ̀, nǹkan tí ó ju èyí á tó máa sẹlẹ̀.
|
Mama was in town to collect some of Labake's hair and her fingernails.
|
Irun-orí àti èékánná Làbákẹ́ ni màmá wá gbà ní ìgboro.
|
Esuniyi needed them for further action so that Labake's final doom might be sealed.
|
Èṣùníyì fẹ́ lò ó láti fi túnbọ̀ ba ti Làbákẹ́ jẹ́.
|
It should not surprise anybody, therefore, to see Labake - probably next week or week after - run out to the streets and pitch her home in the market square under the full glare of people who had come to buy and sell.
|
Kò ní láti ya ẹnikẹ́ni lẹ́nu lẹ́yìn èyí láti rí Làbákẹ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì ní àwọn òpópónà kí ó sì dúró sí gbàgede ọjà níbi tí àwọn ènìyàn tí wọn wá ṣe kárà-kátà á tí rí ìran pípé wò.
|
Esuniyi had said it and Mama knew that was exactly what would happen.
|
Èṣùníyì ti sọ ọ́, màmá sì mọ́ pé bí ó ṣe máa sẹlẹ̀ gan-an nìyẹn.
|
Finally, Labake would crawl on her knees, in penitence to Esuniyi's lunatic asylum.
|
Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, Làbákẹ́ á fí orúnkún rẹ̀ ráwọ ọgbà Èsúńiyì pẹ̀lụ́ ìronúpíwàdà.
|
In the case of Alamu, Esuniyi had told Mama there was no cause for alarm anymore.
|
Ní ti Àlàmú, Èṣùníyì ti sọ fún màmá pé kò séwu lóko mọ́.
|
Alamu's condition would start improving henceforth.
|
Ipò tí Àlàmú wà á máa yàtọ̀ sí dáadáa láti ìsínyì lọ.
|
Mama was happy, all what Esuniyi told her had started to come to pass.
|
Inú màmá dùn, gbogbo nǹkan ti Èṣùníyì sọ fún ló ti ń wá sí ì músẹ.
|
Alamu returned home and met his mother with a gay countenance.
|
Àlàmú padà délé, ó sì bá ìyá rẹ̀ pẹ̀lú ìrísí tó fi inú dídùn hàn.
|
He greeted the old woman smiling prostrating.
|
Ó kí ìyá náà pẹ́lù ẹ̀rín músẹ́ lẹ́nu ní ìdọ́bálè.
|
He was returning from an important mission to town, the outcome of which greatly cheered his spirit.
|
Ó ń ti ibi isẹ́ kan pàtàkì nígboro bọ̀, èyí ti àyọrísí rẹ̀ mú un dárayá.
|
For the first time in nine months, Alamu heaved a sigh of relief.
|
Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú oṣù mẹ́sàn-án, Àlàmú mí ìmí ìtura.
|
For nine whole months, he had surrounded himself with a mystery that had continued to baffle everybody; a secret that had proved impossible for anybody to decipher - except for that one man who was so dear to him - Adio his only friend.
|
Fún odidi oṣù mẹ́sàn-án gbáko ní ó ti yí ara rẹ̀ ká pẹ̀lú àdììtú kan tí ó rú gbogbo ènìyàn lójú; àsírí kan tí kò ṣe é ṣe fún ẹnikẹ́ni láti tú - yàtọ̀ sí ọkùnrin kan tí ó súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí - Àdìó ọ̀rẹ́ rẹ̀ kanṣoṣo.
|
Now the end of that mystery was in sight.
|
Níbáyìí, òpin àdììtú yẹn ti wà nítòsí.
|
The end of his mental and physical agony was in view, the end of his madness was at hand.
|
Òpin sí dàrúdápò ọpọlọ àti ìrora rẹ̀ ti súnmo itòsí.
|
He had been told to wait for only two more weeks when all his problems would be practically solved.
|
Wọn tí sọ fún un pé kí ó dúró fún ọ̀sẹ̀ méjì sí i tí gbogbo ìṣòrorẹ̀ á fi yanjú pátápátá.
|
Alamu couldn't believe his ears.
|
Àlàmú kò gbà etí rẹ̀ gbọ́.
|
Eagerly, he counted the days one, two, five, ten, fifteen...
|
Pẹ̀lú ìwànwara ní ó fi ń ka àwọn ọjọ́, ení, èjì, ẹ̀ta, ẹ̀rin, àrún, ẹ̀wá, mẹ́ẹ̀dógún ...
|
Fifteen more days! He counted the hours! The minutes!
|
Ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún sí i! Ó ń ka wákàtí! ìsẹ́jú!
|
Adio was amused at Alamu's show of thrill and excitement.
|
Ó jẹ́ ìyàlenu fún Àdìó bí Àlàmú ṣe ń ṣe àfihàn ìrusókè ìdùnnú rẹ̀.
|
Well, two weeks more they say and judgment would be delivered?
|
Bẹ́ẹ̀, ọ̀sẹ̀ méjì sì ni wọ́n sọ, ìdájọ́ á sì wáyé?
|
That was too short a time compared with the nine months that he'd been waiting.
|
Ìyẹn kéré púpọ̀ níye sí oṣù mẹ́sàn-án tí ó ti fi ń dúró.
|
End of preview. Expand
in Data Studio
README.md exists but content is empty.
- Downloads last month
- 4