Proverbs
stringlengths
8
373
Labels
int64
0
1
Búni-búni, a-bèébú-wọ̀ntì-wọ̀ntì.
1
Dábírì sọ wí pé ìṣẹ̀lẹ̀ tó burú ni èyí tó ń lọ lọ́wọ́ ní ìlú Súnmọ́mi.
0
‘‘Ọbẹ̀ lọmú àgbà’’ ló pa onígbaǹso Ògòdò.
1
Abiyamọ ojanjàn-án; o-ș'ọrọ-ọmọ-pàdé-Olóòlù.
1
Èní Tete jìn sọfìn, ọla Tete jìn sọfìn, Tete nìkàn níí bẹ lọfìn?
1
Ọ̀nà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni Ọládipúpọ̀ mórí lé nígbà tí ó gba ọkọ̀ náà tán.
0
Aláàfin kópa nínú ìdàgbàsókè ilẹ̀ Adúláwọ̀ àti ti ilè Yorùbá.
0
Bí àwọn adigunjalè ṣe pòórá nínú túbú kò yé ẹnikẹ́ni.
0
Iṣẹ́ alásè oúnjẹ ni mò ń ṣe tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó sọ pé iṣẹ́ wà ní Ìtaọlá.
0
Àwo orin náà jẹ́ pé àwọn orin tí ó ti kọ tẹ́lẹ̀ pọ̀ nínú rẹ̀.
0
Àwọn akọ̀ròyìn òfegè ló fi fídíò ìṣẹ̀lẹ̀ ti Ṣáínà síbẹ̀.
0
Ọ̀pọ̀ èèyàn gbàgbọ́ pé owó ti dé bí wọ́n bá ti rí wa..
0
Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin òde òní ń fi ohun tí wọ́n ni gba ohun tí wọ́n ń fẹ́
0
Ààyè tí a pèsè sílẹ̀ yìí wà fún àwọn ènìyàn jàǹkànjàǹkàn nìkan.
0
Eyẹ tó bá jẹ èso-ikù kì í gbọdún mẹta (láyé).
1
Àgún-ùn-jẹ-iyán ni tẹrú.
1
Àṣàyá kì í jẹ́ kí ọmọ ọ̀yà ó gbọ́n.
1
Àwọn jagunjagun kápá ajínigbé tó kọjú ìbọn sí wọn.
0
Ẹní na Ọyẹkú á ríjà Ogbè.
1
Inú ọgbà ńlá kan ni wọ́n sin òkú Ọ̀gbẹ́ni Ràúfù sí.
0
Kò rọrùn kí ó tó rí i ṣe.
0
Ẹni tó jókòó ló ń nase.
1
Àwọn olóṣèlú ń ṣe ìlérí láti fòpin sí ìwà ìpáǹle ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
0
B'éèyán 'ò tiẹ leè rú lógun bí èéfín, ó yẹ kí ó leè jò bùlà bíi igi egbà l'áàrò, l'áàrin igborò.
1
B'órí igún ti rí lóko-etílẹ bẹè ló rí lóko egàn.
1
Àjọ náà ṣiṣẹ́ látàrí ìfitónilétí kan láti ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú.
0
Ẹgbẹ́ ti kéde orúkọ olùdíje fún ipò ààrẹ àti amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.
0
Fọlọ́runṣọ́ sọ pé kì í ṣe ìfẹ́ inú òun ni láti bá ajá náà sùn.
0
Àwọn ẹ̀yà aláwọ̀ funfun apá Gúúsù ilẹ̀ Afíríkà kò ju ìdá méje àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Afíríkà.
0
Bí ọmọdé bá ṣu imí búburú, èsìsì la fi ń nù ú nídìí.
1
” Éèyàn kì í gbọn, kí tiẹ,má bá a.
1
A kì í so ẹran mẹ́ran kó kàn án pa.
1
Bọ́látitó yòǹbó àwọn gómìnà Yorùbá lórí ìpìnnu ìpàdé.
0
Àkísà aṣọ la fi ń ṣe òṣùká.
1
Bọro bá ta kókó, tọrọ dí yàyà eegun òtòlò làá f ií tò ó.
1
Alukoro ẹgbẹ́ àwọn ọmọ Ìbò rọ àwọn olówó wọn fún ìrànlọ́wọ́.
0
Àjẹkù là ń mayo.
1
Ajá níí kun ni; ìkùn èèyàn ò sunàn.
1
Ìjọba Ọ̀yọ́ yóò fẹnu kò láìpẹ́ lórí Aláàfin tuntun.
0
Èèyàn tì 'ò nítìjú, apá Ọlọrun ò ká a.
1
Ení jókòó ló ń nase.
1
Ní nǹkan bí ọgọ́ta kìlómítà ni àwọn ikọ̀ tí wọ́n fara wọn kalẹ̀ fún iṣẹ́ ìlú mìíràn wà.
0
Ení le fun nì lewù làyé 'ò pọ, bí ẹní le fa'ni lẹwù ya.
1
Ìpalẹ̀mọ́ ti ń lọ lórí ètò ìdíje láàárín àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga tí yóò wáyé.
0
Adìẹ òpìpì kì í rápá gun orílé.
1
A kì í bú ọba onígẹ̀gẹ̀ lójú àwọn èèyàn-án rẹ̀.
1
Aṣòroójà bí ìjà ọjà; onítìjú ò níí sá; ẹni tí ń nà án ò níí dáwọ́ dúró.
1
Ìròyìn kan gbòde pé àwọn agbófinró ti gba Olúwagbénga sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Ẹrúukú.
0
Asúrétete ní ń wojú ọjọ́.
1
Gbamgba d'ekùn; kedere be e wo.
1
Ẹran gíníngín la fì ń. dán okánjúà wò
1
Eni búni leyìn ifà ló kó. B'éèyàn búni lójú eni àdí ó ó dà sí l.
1
Ẹni ọrọ 'ò bá kì í mose.
1
Àfẹ́ká là ń fẹ́ iná.
1
Ẹ̀bìtì tí yóò pa erè, ojú-u rẹ̀ á pọ́n.
1
Ìgbìmọ̀ ti wà tí yóò tọpinpin ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
0
Àwọn ìwà ìbàjẹ́ pọ̀ lóríṣìíríṣìí láwùjọ wa.
0
Àtíkù ní ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ààrẹ Tinubu ní nǹkan ṣe pẹ̀lú kíkọ́ ọ̀nà Ìbàdàn sí Èkó yìí.
0
Ìyà ń jẹ àwọn olùkọ́ ní àwọn Fáfitì wa káàkiri.
0
Arákùnrin tí àwọn ọlọ́pàá mú ní òun kìí ṣe olè.
0
Àwọn ọba alayé kan ń pe ara wọn ní Pásítọ̀ tàbí Àlùfáà nítorí owó.
0
À ń lọ kábọ̀ ni wọ́n dá gbére àfi ìgbà tí bàbá ò padà dé mọ́.
0
Babalọlá lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀ ní àtìmólẹ́.
0
Bíṣọ́ọ̀bù jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ìwádìí ọlọ́pàá.
0
Gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni yóò kópa níbi ìdíje náà.
0
Enmnọ lukutupẹbę; sòbià Àjàyí tó múu lẹsẹ tó ń ro ó lógòóróó.eyìn.
1
.Bí a bá tí ń fàpárí-isu han àlejò; òwe ilé tó ó lọ ni.
1
Àwọn ará àdúgbò dáná sun ará kùnrin kan torí pé ó jalè.
0
Aláṣejù, pẹ̀rẹ̀ ní ń tẹ́; àṣéjù, baba àṣetẹ́ .
1
B'ọrọ 'ò bà p'ọlọrọ, kò leè pa alàfoòfojúrí.
1
Àjàkálẹ̀-àrùn a máa mú ìyara-ẹni-sọ́tọ̀ wá.
0
Àbàjà ò papọ; ẹniire níí kọ ọ.
1
Àwọn ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ sí ní tọpasẹ̀ kẹ̀kẹ̀ tí wọ́n jí kiri.
0
Mi ò lérò pé àwọn òbí ọmọ náà mọ̀ sí ohun tí ó ń ṣe ọmọ wọn.
0
Ẹni tó juni lọ, ó lè juni nù, kó juni sẹnu kálo.
1
Kété tí àwọn ọlọ́kadà rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n sá lọ.
0
Gbogbo wa la ș'ọmọdé rí, àgbà la ò tíì dà.
1
Eni feserin wọlú'ò rowo fi lalẹ bi eni fori wọ o.E má f'orun yo edá kò seni tíi ò ní kǔ.
1
Ìjọba fẹ́ yanju rògbòdìyàn láàárin àwọn Mùsùlùmí ìlú Ìkàrẹ́.
0
Àdìó tún sọ wí pé ó ti pẹ́ tí inú òun ti dùn báyìí gbẹ̀yìn.
0
A ní kọ́mọ má kùú, o ní kò jọ bàbá kò jọ ìyá.
1
Àdán ní kàkà k'ẹyẹ m'ẹ́yẹ jẹ, èrè á di taṣẹgità.
1
Adẹ́tẹ̀ sọ̀rọ̀ méjì, o fìkan purọ́; ó ní nígbà tí òún lu ọmọ òun lábàrá, òún ja léèékánná pàtì.
1
A dẹ́bọ fún igúnnugún, ó ní òun kò rú; a d bọ fún àkàlà, ó ní òun kò rú; a dẹ́bọ fún ẹyẹlé, ẹyẹlé gbẹ́bọ, ó rúbọ.
1
À ń gba òròmọ adìẹ lọ́wọ́ ikú, ó ní wọn ò jẹ́ kí òun jẹ̀ láàtàn.
1
B'ọsàn-án bá pọn ganrínganrín, elékuru a hu. (polówó)
1
Alákàn ṣe díẹ l'ókun, omi ló pọ.
1
Àlòkùàdá ò jọ obìnrin lójú.
1
Èké ní ń rojọ́; ìkà ní ń dá a.
1
Amúlùúdùn tún lè jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ lórí rédíò.
0
Òṣìyẹmí sọ wí pé kí ọkọ̀ máa gba ọ̀nà tí kì í ṣe ẹ̀tọ́ lójú pópó ń bani lọ́kàn jẹ́.
0
Àkùko adiẹ kì í pọkọrọ lọjà Èjìgbòmẹkùn.
1
Àwọn ọmọ ijọ dáwó láti kọ́ ilé ìjọsìn tuntun.
0
Ọkọ Àjíún sọ wí pé òun kò fẹ́ rí mi nítòsí ìyàwó òun mọ́ láé.
0
Àwọn tó ti kú ní orílẹ̀-èdè méjéèjì ti lé ní ọ̀ọ́dúnruń.
0
Aṣòfin Oríyọmí dábàá kíkó àwọn ẹ̀ṣọ́ elétò àbò míì lọ sí Ọ̀yọ́.
0
Àwọn tálákà náà tún figbe ta lórí ọ̀rọ̀ tí ìjọba àpapọ̀ tún fẹ́ ṣe lórí ojú ọ̀nà.
0
‘‘Gba akọṣu’’ ni ‘‘Gba ewùrà’’; gbà lẹ́nu ọ̀fọ́n-ọ̀n ni gbà lẹ́nu agánrán.
1
Bí ẹ bá r'árúgbó tó rẹrù, tó ń tẹpá, ó tí fàárọ rẹ seré ni.
1
Akẹ́yinjẹ ò mọ̀ pé ìdí ń ro adìẹ.
1