Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Elẹgọ èèyàn níí r'ẹeran nígbee yìnbọn sínú oko. | 1 |
Àì tọ sójúkan ni ò jẹ k'á mọ pé'tọ hó jọṣẹ. | 1 |
Bí egbò ò bá pa elégbò, kì í pa ẹni tí ń wẹ̀ . | 1 |
A kì í d'igbá d'agbọn kí a tó mọra eni. | 1 |
Àwọn ọlọ́jà ń sèdárò Ìyálọ́jà ìpínlẹ̀ Oyo tó jáde láyé. | 0 |
Afẹ́fẹ́ ń da ológìì láàmú; oníyẹ̀fun rọra. | 1 |
Enikan lòkú. | 1 |
Eja inú kànga, kì í rí ju ìmọlẹ inú kànga. | 1 |
Àkàlàmàgbò-ó ṣoore ó yọ gẹ̀gẹ̀ lọ́rùn. | 1 |
Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gba ọ̀nà ẹ̀bùrú dépò ti ń gba owó-oṣù àti àjẹmọ́nú. | 0 |
Adàgbà-má-ládiẹ-irànà, kò yẹni. | 1 |
Àwọn agbébọn tẹ́nikẹ́ni ò mọ̀ pa èèyàn mẹ́ta lálẹ́ Ọjọ́ru. | 0 |
Àbádòfin ìṣúná ọdún ré kọjá ìpele ìkejì nílé aṣòfin àgbà. | 0 |
Àwọn ènìyàn tí wọ́n há sínú ìdọ̀tí ọ̀hún ṣèṣe púpọ̀. | 0 |
Ehín tó tayọ, wàhálà ẹnu ni. | 1 |
Àpà èèyàn ò mọ̀ pé ohun tó pọ̀-ọ́ lè tán. | 1 |
Ilé iṣẹ́ apòògùn ṣe ìkìlọ̀ fún oníbàárà. | 0 |
Ilé dàwó ní ọgbà ilé-ìgbé àwọn ọlọ́pàá nílùú Ìbàdàn. | 0 |
‘‘Mo mọ̀-ọ́ tán’’ lOrò-ó fi ń gbé ọkùnrin. | 1 |
Ajàkàșù má tokùn b'ọrùn, kí ni kí atewéjẹ ó ṣe? | 1 |
Bí babaláwo 'ò bá pagún ẹrù 'ò ní badię. | 1 |
Gbogbo akitiyan rẹ̀ láti du ọ̀kadà rẹ̀ ló já sí pàbo. | 0 |
Ẹniyan ló ń bínú, Olọrun 'Ò bínú, Olọrun 'Ò șebi, ire Ló ń șe. | 1 |
Àjẹkù làgbẹ̀ ń tà. | 1 |
Mi ò mọ bí ara mi ṣe wà láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé. | 0 |
Àwọn abarapá tó ń tọrọ bárà yóò padà sí ìlú wọn. | 0 |
À ń sọ̀rọ̀ olè, aboyún ń dáhùn; odiidi èèyàn ló gbé pamọ́. | 1 |
Bọ̀dé na akẹ́kọ̀ọ́ aláìgbọràn pé kí ó ka ẹ̀kọ́ inú ìwé rẹ̀. | 0 |
Aṣèbàjẹ́ ń wá ẹni rere kúnra. | 1 |
Eléte ò pá a lójú ẹni; ẹ̀hìn ẹni là ń gbìmọ̀ràn ìkà. | 1 |
Ayéfẹ́lẹ́ ti ń ṣe ètò ńlá kan. | 0 |
Ẹsẹ olóde kì í sé lóde. (lójúde) | 1 |
Ẹ yé fojú tẹ́ḿbẹ́lú agbára àdúrà. | 0 |
Bàbá mi lòdì sí kí àwọn ènìyàn máa sọ̀rọ̀ ara wọn lẹ́yìn. | 0 |
Àwọn ènìyàn ṣèṣe látàrí ìjà tó wáyé ní ilé epo. | 0 |
Rògbòdìyàn súyọ níjọba ìbílẹ̀ Ẹgbẹ́dọ̀rẹ́ nígbà tí ètò ìdìbò fẹ́ bẹ̀rẹ̀. | 0 |
Bádémọsí ní pé àwọn tó dìde ìrànwọ́ ní àdúgbò àwọn ń fi ẹ̀mí ara wéwu. | 0 |
Àgbàbọ́ ò di tẹni. | 1 |
Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni àwọn dọ́kítà tó darí iṣẹ́ abẹ náà. | 0 |
B'ọmọ bá sẹ; iyá ọmọ là á fẹjọ sùn. | 1 |
Àwọn ọlọ́pàá sọ pé àwọn tọkọtaya yìí ló ṣe agbátẹrù ìkọlù ìpànìyàn tó wáyé. | 0 |
A kì í gbé sàráà kọjá-a mọ́ṣáláṣí. | 1 |
Wọ́n fi kòbókò lù ú ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀rí pé ó jalè. | 0 |
Bó bá kọjú sí ẹ o tá, bó bá kẹ̀yìn sí ẹ o ta á. | 0 |
A ní kí olókùnrùn ṣe tó, ó ní òun ò lè ṣe tó, tò, tó. | 1 |
Àràbà ò pẹlú igi-oko t'áfẹfẹ ń ṣe láíloláílo. | 1 |
B'ónilù n lùlù pé: “Elédùà yóó pàgbà dà, yóó múgbà mìiràn dākì í șe ìlù tó yẹ kí olówó máa fi gbogbo ara jó sí. | 1 |
‘‘Mò ń bọ̀!’’ ‘‘Máa bọ̀!’’ Àwọn méjèèjì lẹ̀rù ń bà. | 1 |
Eegun tí a bá so mọ́ ajá lọ́rùn, kì í ṣán an. | 1 |
Ejo kú sÁké. | 1 |
Ó máa ń tó ọjọ́ mẹ́rìnlá kí àrùn tó jáde lára. | 0 |
Ẹlẹrù ló ń gbé e níbi tó ti wíwò, kí a to bá a gbé e. | 1 |
Àwọn nǹkan díẹ̀ ló mú ìyàtọ̀ bá ìjọba ààrẹ Olúdé àti Adémi. | 0 |
Àwọn ọba àti àwọn òrìṣà ni wọ́n jọ ń jẹ tí wọ́n sì ń mu ní kọ̀rọ̀ | 0 |
Alára ò lè wí pé kò dun òun, ká ní ó kú àìsùn, ó kú àìwo. | 1 |
Akótọbánu 'ò seé pè jẹrìí. | 1 |
Adìyẹ kan yàgbé sí orí ọkọ̀ mi. | 0 |
Akínjídé ní lọ́jọ́ kẹẹ̀dógún oṣù yìí ni ètò amóríyá náà. | 0 |
Àwọn Iléeṣẹ́ iná ọba kò ṣe iṣẹ́ wọn bí ó ti yẹ rárá. | 0 |
Àwọn ọlọ́pàá kọ́kọ́ rò bóyá kì í ṣe Ọládipúpọ̀ nìkan ló dá olè náà jà. | 0 |
Balógun yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn agbábọ́ọ̀lù òde òní gedegbe. | 0 |
Bá 'ò kú, ișe 'ò tán. | 1 |
Àjòjí lójú, ṣùgbọ́n kò fi ríran. | 1 |
Àjọ náà kan sárá sí àwọn ènìyàn fún ohun tí wọ́n ṣe yìí. | 0 |
Bí ikú bá tilẹ̀kùn, ebi ní ń ṣí i. | 1 |
Agbèfọ́ba júwe àwọn ẹ̀sùn yìí gẹ́gẹ́ bí èyí tó tako ìwé òfin ìpínlẹ̀ Oǹdó. | 0 |
Gbà sọkọ' ni 'gbà sókè.' | 1 |
Bí a kò bá tẹ̀lé wèrè, a kì í mọ ilé tí yó wọ̀. | 1 |
B'ónìí tì rí ọlá kì í rí bẹ lò ń mú Babaláwo dífá ojoojúmo. | 1 |
Adùn-únṣe bí àlejò omi. | 1 |
Ìpàdé àwọn olórí ẹ̀ka ìjọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni láti fojú rinjú lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n. | 0 |
‘‘Kiní yìí, n kò lè jẹ ẹ’’: kí Ọlọ́run má dà à sí agbada ẹni. | 1 |
Ayé ò ríni nígbà tí a sun ọ̀gẹ̀dẹ̀ jẹ; ìgbà tí a fi ẹ̀gúsí sebẹ̀ tó pọ́n bí edé layé ríni. | 1 |
Mo kẹ́kọ̀ọ́ àríkọ́gbọ́n lára ìṣẹ̀lẹ̀ ikú arábìnrin yìí. | 0 |
A kì í gbọn ju, 'Báyìí ni n ó șe nnkan mi' lo. | 1 |
A sìnkú tán, alugbá ò lọ; ó fẹ́ẹ́ ṣúpó ni? | 1 |
· Ẹni tó pé òun ò leè roko fọmọ òun jẹ, ọmọ ọlọmo ni yóó roko fún mú je. | 1 |
Onígbàjámọ̀ tuntun tí ọba ṣẹ̀ṣẹ̀ pè wá sí ààfin dángájíá púpọ̀. | 0 |
Ayéfẹ́lẹ́ ní òun ṣetán láti bùkún àwọn ọ̀dọ́. | 0 |
Ọ̀kan lára ọmọ àwọn olóògbé pe ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ àwọn òbí rẹ̀. | 0 |
Olóyè Àdìgún pe Ẹ̀sìn Kìrìtẹ́nì àti ẹ̀sìn Mùsùlùmí ní ẹ̀sìn àjèjì. | 0 |
Ọkùnrin tí wọ́n fi kíndìnrín ẹlẹ́dẹ̀ rọ́pò tirẹ̀ pàpà jáde láyé lẹ́yìn oṣù méjì tí iṣẹ́ abẹ wáyé. | 0 |
Eșin balẹ, ó m'óruku, ọkọ náà balẹ mú yẹpẹ. | 1 |
Bàbá Ìjẹ̀ṣà ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ ìlọ̀kulọ̀ ìbálòpọ̀, àti ìgbìyànjú ìfipábánilòpọ̀ sí ọmọ náà. | 0 |
Àwọn adarí ilé iṣẹ́ náà ni ó ń fa wàhálà fún àwọn òṣìṣẹ́ náà. | 0 |
Akíkanjú-kankan, ogun ní ń lọ; abùwàwà, ọjà ní ń ná; àkànní òbúkọ, bó bá tòṣì a máa rí jẹ. | 1 |
Ọ̀rọ̀ ìlera rẹ̀ kò yanranntí àti wí pé adájọ́ mọ̀ sí i. | 0 |
Àgbà ló n gbẹsẹ lọrọ. | 1 |
Àgbà adájọ́ sọ pé òfin yọ olú-ìlú orílẹ̀-èdè yìí sọ́tọ̀. | 0 |
Adẹbitì-sọlà, kì í fẹ k'ẹran tán nígbẹ̀ẹ́. | 1 |
Ọwọ́ gbọ́dọ̀ ba àwọn arúfin ojú pópó ni kíákíá ni | 0 |
Àìlówó lọwọ ni ẹ le rèé ròfọ' ẹran ni baba omitoro. | 1 |
Ará Ìkọlé dán èké wò, ó já jó wọn lọwọ (lójú). | 1 |
Bámgbọ́lá kábàámọ̀ ìwà tí ó wù sí Àjíún yìí. | 0 |
Adájọ́ sọ pé ariwo nǹkan ọ̀sìn ọ̀hún ń ni gbogbo àwọn ènìyàn lára. | 0 |
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ti farapa láti ìgbà tí ogun ti bẹ̀rẹ̀. | 0 |
Àwọn ọlọ́pàá pe ọ̀rẹ́kùnrin Ọláyínká fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. | 0 |
Àtiwáyé ìlẹ̀kè alágídígba ò ṣẹhìn èkùrọ́. | 1 |
Ilé ẹjọ́ ti ní ká kọ̀wé láti fi bèèrè fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó wà nínú èsì àyẹ̀wò náà. | 0 |
Bí igbá bá wọ odò a lé té-ń-té. | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.