Dataset Viewer
Auto-converted to Parquet Duplicate
id
int64
0
48
text
stringlengths
103
3.71k
0
copyright © 2018 bbc. bbc kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta. ọwọ́ tí a fi mú ìbáṣepọ̀ ti ìta.
1
ìforúkọsílẹ̀ àwọn olùdìbò àti gbígba káàdì ṣe pàtàkì fún ìlànà ìdìbò bẹ́ẹ̀ sì ni ó ní ipa tí ó ń kó nínú ìsèjọba àwa ara wa, ó ma ń músẹ́ yá nínú ìlànà ìdìbò àti ìsèjọba àwa ara wa.
2
àwọn yorùbá ní ọ̀nà tí wọn ń gbà ṣe ìsirọ̀, bẹ́ẹ̀ ní àti ọmọkékeré ní àwọn yorùbá ti ń kọ́ ọmọ wọn ni ìṣirò ní ṣíṣe. wọn yóò ni kí ó máa fi ení, èjì kọrin, ṣere bíi
3
ààrẹ fún ẹgbẹ́ àwọn ọmọbíbí ìpínlẹ̀ òndó ní fásitì nàá, popoọla morayọ samson sọ fún bbc pe ìjọba ìpínlẹ̀ òndó ṣèlérí ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nàá láti fi tùwọ́n l'ójú. ṣùgbọ́n, ó ní àwọn kò fẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ nàá, ẹ̀dínwó owó ilé-ìwé l'àwọ́n fẹ́.
4
níwọ̀ngbà ọjọ́ diẹ tókù kétò ìdìbò sípò gómìnà wáyé nípínlẹ̀ èkìtì, ó ti lé lọ́gọ̀rún àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn tíwọ́n ti mú lọ́kanòjọ̀kan ibùdó tó ń bẹ yíká àwọn ìlú àtabúlé nípínlẹ̀ náà. ọ̀gbẹ́ni hammed sàlàyé pé, gbogbo àwọn ami dúdú kọ̀ọ̀kan tó wà láwọn ìlú àtàwọn abúlé yíká ìpínlẹ̀ náà láwọn tí sèpalẹ̀mọ́ wọn nípasẹ̀ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbo àwọn àjọ aláábo pátá, káláfìa lè lè ba jọba.
5
ara àwọn nǹkan tí ó sokùn fa ogun àgbáyé àkọ́kọ́ nìyí ogun àgbáyé àkọ́kọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ láàárin orílẹ̀-èdè méjì kan tí orúkọ wọn ń jẹ́ austria-humgary ati serbia. ìlú kékeré kan ní awọn orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí ń jà lé lórí. orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ ló kọ́kọ́ gba ìlú yìí lọ́wọ́ ẹ̀kẹjì nínú ogun kan tó wáyé ní ọdún 1908. orílẹ̀-èdè kejì wá ń dún kòkò lajà láti gba ìtú yìí padà. sáájú àsìkò yìí, àwọn ìsẹ̀lẹ̀ kan sẹ̀lẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ sí mú kí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé máa ṣe gbún-ùn gbùn-ùn gbún-ùn sí ara wọn. sáájú ogun àgbéyé kìíní, àwọn orílẹ̀-èdè ló máa ń jẹ gàba lórí àwọ́n orílẹ̀-èdè mìíràn nígbà máà, kò pẹ́ kò jìnnà tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ní mú sìn yìí bẹ̀rẹ̀ ń jà fún òmìnira. orílẹ̀-èdè [belgium] gba òmìnìra ní ọdún 1830, nígbà tí ilẹ̀ [germany] gba tiwọn ní 1871. ìjà òmìnìra wá bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lólogbó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jà fún òmìnira. àwọn orílẹ̀-èdè amúnisìn kọ́kọ́ tako èyí, síbẹ̀síbẹ̀, wọn kò rí nǹkan ṣe si èyí. gbogbo àwọn tí wọ́n tí wọ́n ti jẹ́ gàba lé lórí bẹ̀rẹ̀ sí jà fún òmìnira. gbogbo wọn kóra pọ̀. bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí ni ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà bẹ̀rẹ̀ sí sẹlẹ̀, àti àwọ́n ìsòro tí ó rọ̀ mọ́ ẹlẹ́yàmẹ̀yà. àwọn nǹkan wọ̀nyí ló sokùnfà rògbòdìyàn ogun nígbà náà yàtọ̀ sí èyí, wíwá àwọn òyìnbó sí ilẹ̀ aláwò dúdú [africa] wà lára àwọn nǹkan to sokùnfà ogun àgbáyé kìíní. owó ló gbé àwọn òyìnbó dé ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, wọ́n wá ri pé yíò rọrùn fún àwọn láti rí nǹkan àlùmọ́ọ́nì tí wọ́n ń fẹ́ tí àwọn bá mú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú sìn. ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn òyìnbó wọ̀nyí dé ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, ìjọ̀ bèrè sí wáyé láàárin wọn lórí orílẹ̀-èdè tí oníkálukú wọn yíò mú sìn. nígbà tí wọ́n ń pín ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú láàárin ara wọn, bí wọn ṣe pin kò tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè amúnisìn kan lọ́rùn lórí bí wọ́n ṣe pín àwọn orílẹ̀-èdè aláwọ̀ dúdú láàárin ara wọn nígbà náà àyọrísí gbogbo wàhálà yìí ló sokùnfà ogun àgbáyé àkọ́kọ́. àwọn orílẹ̀-èdè alágbára wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí funra sí ara wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kó nǹkan ijà olóró jọ. àwọn orílẹ̀-èdè kan bẹ̀rẹ̀ sí ní bá ara wọn sọ̀rẹ́ láti gbógun ti orílẹ̀-èdè mìíràn. nígbà tí ogun yìí yóò fi bẹ̀rẹ̀, awọn orílẹ̀-èdè alágbára pín ara wọn sí ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
6
lọ́wọ́lọ́wọ́ kò sí ìkọ̀ nínú ojúewé yìí. ẹ le wá àkọlé ojúewé yìí nínú àwọn ojúewé mìíràn, tàbí wá àwọn àkọọ́lẹ̀ tó bámu, sùgbọ́n ẹ kò ní àṣẹ láti ṣ'ẹ̀dá ojúewé yìí.
7
ẹ̀ka yìí wà fún àwọn àgbájọ, ibi, ilé-iṣẹ́ tàbí àwọn ohun míràn tí wọn jẹ́ dídásílẹ̀ tàbí filọ́lẹ̀ ní ọ̀rúndún 14k.
8
ẹgbẹ́ òṣèlú pdp ní gbogbo ariwo ìwé orúkọ àwọn tó jí owó ìlú tí ìjọba orílẹ̀èdè nàíjíríà ń pa báyí kò yẹ̀ lẹ́yín ìgbésẹ̀ láti gbé ojú àwọn ọmọ orílẹ̀èdè nàíjíríà àti àjọ àgbáyé kúrò lóríi ìkùnà ìṣèjọba rẹ̀.
9
ẹ̀tẹ̀ ti ń ran àwọn ènìyàn fún àwọn ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn.[3] àrùn yí gba orúkọ rẹ láti látínì ọ̀rọ̀ lepra, tí ó túnmọ̀ sí "scaly", nígbà tí ọ̀rọ̀ "àrùn hansen" wá láti orúkọ oníṣègùn gerhard armauer hansen.[3] yíya àwọn èniyàn sọ́tọ̀ ní awọn ìletò adẹ́tẹ̀ ṣsì ń wáyé ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi índíánì, pẹ̀lú iye ju ẹgbẹ̀gbẹ̀rún lọ;[6] ṣáínà, pẹ̀lú iye ní ọgọgọ́rùn;[7] àti ní áfíríkà.[8] síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ìletò kòsí mọ́.[8] ẹ̀tẹ̀ ni ó rọ̀mọ́ àbùkù ìbálópọ̀ fún ọ̀pọ̀ ìtàn,[1] tí ó jẹ́ ìdènà fún ìfi-ara-ẹni sùn àti ìtọjú lọ́gán. ọjọ́ ẹ̀tẹ̀ àgbayé bẹ̀rẹ̀ ní 1954 láti mú mímọ̀ nípa wá fún àwọn tí o ní ẹ̀tẹ̀.[9]
10
ẹ̀wẹ̀, ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀èdè nàìjíríà ti fi àìdunú hàn sí bí wọ́n se ńpa àwọn ọmọ orílẹ̀èdè yìí ní ìlú òyìnbó láì jìnà síra.
11
ọ̀jọ̀gbọ́n àti onímọ̀ tó yanrantí ni wọ́n, ní ìgbà ayé e wọn. kò sí akẹ́kọ́ tí kìí sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere.
12
àwọn adigunjalè náà pa ọlọ́pàá mẹ́fà àti àwọn ará ìlú mẹ́fà níbi ìkọlù sí àwọn ilé ìfowópamọ́ márùń ní ìlú ọ̀ffà.
13
àwọn àdéhùn wọ̀nyí ("àwọn àdéhùn") bo ìlò àwọn àgbéjáde aṣàmúlò microsoft, ojúlé wẹ́ẹ̀bù àti àwọn ìpèsè tí a ṣàkójọ níbí (àwọn "ìpèsè náà"). o gba àwọn ìpèsè wọ̀nyí nípa ṣíṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ microsoft kan, nípa ìlò rẹ ti àwọn ìpèsè náà, tàbí nípa ìtẹ̀síwájú lati máa lo àwọn ìpèsè náà lẹ́yìn tí a ti sọ àyípadà sí àwọn àdéhùn wọ̀nyí fún ọ. 5. lílo àwọn ohun èlò àti iṣẹ́ ẹlòmíràn. àwọn ìpèsè náà le gbà ọ́ láàyè láti ráyèsí tàbí gba àwọn àgbéjáde, àwọn ìpèsè, ojúlé wẹ́ẹ̀bù, ìtọ́kasí, àkóónú, ohun ìní, ìṣeré, ọgbọ́n-inú, àkójọpọ̀, bọ́ọ̀tì tàbí àwọn ìfilọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹta (àwọn ilé-iṣẹ́ tàbí àwọn ènìyàn tí kìíṣe microsoft) ("àwọn ìpèsè àti ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta"). ọ̀pọ̀ nínú àwọ́n ìpèsè wa tún ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wá, ṣe ìbèrè sí, tàbí bá àwọn ìpèsè àti ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta ṣe pọ̀ tàbí gbà ọ́ láàyè láti ṣàpínlò àkóónú tàbí dátà rẹ, ó sì yé ọ pé o ń darí àwọn ìpèsè wa láti pèsè àwọn ìpèsè àti ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta fún ọ. àwọn ìpèsè àti ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta náà lè ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà ìpamọ́ kan fún ọ, tàbí kí wọ́n ní kí o faramọ́ àwọn àfikún àdéhùn kí o tó le ṣàgbékalẹ̀ tàbí lo ìpèsè tàbí ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta náà. àwọn ìpèsè àti ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta le fún ọ ní òfin ìkọ̀kọ̀ tàbí bèrè lọ́wọ́ rẹ láti gba àwọn àfikún àdéhùn kí o tó le ṣàgbékalẹ̀ tàbí lo ìpèsè tàbí ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta. wo abala 13(b) fún àwọn àfikún àdéhùn fún àwọn ohun èlò tí o rà nípasẹ̀ ibi ìpamọ́ office, ibi ìpamọ́ xbox tàbí ibi ìpamọ́ windows. o gbọ́dọ̀ ṣàtúnyẹ̀wò èyíkéyìí àwọn àfikún àdéhùn àti àwọn òfin ìkọ̀kọ̀ kí o tó gba, lo, bèrè tàbí ṣe àsopọ̀ àkọọ́lẹ̀ microsoft rẹ mọ́ èyíkéyìí àwọn ìpèsè àti ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta. àwọn àfikún àdéhùn yòówù kò yí àwọn àdéhùn wọ̀nyí padà. microsoft kò fún ọ ní ìwé-ẹ̀rí fún ohun-ìní iṣẹ́ ọpọlọ yòówù gẹ́gẹ́ bí ara àwọn ohun èlò àti iṣẹ́ àwọn ẹlòmíràn yòówù. o gbà láti gbé gbogbo ewu àti ojúṣe tó lè wáyé nípasẹ̀ ìmúlò rẹ fún àwọn ohun èlò àti iṣẹ́ àwọn ẹlòmíràn wọ̀nyí, àti pé microsoft kò ní ojúṣe fún ọ̀ràn yòówù tó lè wáyé nípasẹ̀ ìmúlò rẹ fún wọn. microsoft kò ní ojúṣe yòówù, òun kì yóò sì ní láti dá ìwọ tàbí àwọn ẹlòmíràn lóhùn nípa àlàyé tàbí àwọn ìpèsè ìfilọ́lẹ̀ àtí ìpèsè ẹnikẹta. iii. àwọn ìpèsè àti ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta. gẹ́gẹ́ bíi ara ìfijíṣẹ́ àwọn ìpèsè cortana, cortana le ṣe ìpàrọ̀ àlàyé pẹ̀lú àwọn ìpèsè àti ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta, bíi kóòdù ìfìwé ránṣẹ́ rẹ àti ìbéère àti ìdáhùn tí àwọn ìpèsè àti ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta dá padà láti mú ìbèrè rẹ ṣẹ. nípasẹ̀ sísopọ̀ àkọọ́lẹ̀, cortana le mú àwọn aṣàmúlò ṣiṣẹ́ láti rajà nípasẹ̀ àwọn ìpèsè àti ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta nípa lílo àwọn irúfẹ́ àkọọ́lẹ̀ àti awọn etò tí aṣàmúlò ti fi múlẹ̀ tààrà pẹ̀lú àwọn ìpèsè àti ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta. àwọn aṣàmúlò le ṣèpínya ìsopọ̀ àkọọ́lẹ̀ nígbà kugbà. ìlò rẹ ti àwọn ìpèsè àti ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta wà lábẹ́ abala 5 ti àwọn àdéhùn wọ̀nyí. àwọn olùgbéjáde ìpèsè àti ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta le ṣe àyípadà tàbí fòpin sí iṣẹ́-ṣíṣe tàbí àfidámọ̀ àwọn ìpèsè àti ìfilọ́lẹ̀ ẹnikẹta tàbí ìbáṣiṣẹ́pọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn ìpèsè cortana. microsoft kò ní dáhùn tàbí jẹ gbèsè fún àwọn ẹ̀yà àìrídìmú tàbí fámúwià àwọn olùgbéjáde. 1. àmúyẹ fún ètò. o nílò ojúlówó àkọọ́lẹ̀ microsoft, ẹ̀rọ rẹ sì gbọ́dọ̀ kún ojú òṣùwọ̀n àwọn àmúyẹ tó kéré jùlọ tí ẹ̀rọ gbọ́dọ̀ ní. ètò náà ṣí sílẹ̀ fún àwọn aṣàmúlò tí ngbé ní àwọn agbègbè ìpèsè ọjà tí a kọ sílẹ̀ ní faq. ẹnìkọ̀ọ̀kan kò gbọdọ̀ ní ju àkọọ́lẹ̀ ètò kan lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì, ìdílé kọ̀ọ̀kan kò sì lè ní ju àkọọ́lẹ̀ mẹ́fà lọ. ètò náà wà fún ìlò àdáni àti àìfiṣòwò rẹ nìkan. 9. ipa ti òfin ní. ìfohùnṣọ̀kan yìí ṣe àpèjúwe àwọn ẹ̀tọ́ ẹni kan lábẹ́ òfin. ìwọ lè ni àwọn ẹ̀tọ́ mìíràn lábẹ́ àwọn òfin ìpínlẹ̀ tàbí orílẹ̀-èdè rẹ. ìfohùnṣọ̀kan yìí kò yí àwọn ẹ̀tọ́ rẹ lábẹ́ àwọn òfin ìpínlẹ̀ tàbí orílẹ̀-èdè rẹ padà bí àwọn òfin ìpínlẹ̀ orílẹ̀-èdè rẹ kò bá gbà á láàyè lati ṣe bẹ́ẹ̀.
14
redirect {{àwọn orílẹ̀-èdè áfríkà}} {{àwọn orílẹ̀-èdè ásíà}} {{àwọn orílẹ̀-èdè europe}} {{àwọn orílẹ̀-èdè àríwá amẹ́ríkà}} {{àwọn orílẹ̀-èdè oṣéáníà}} {{àwọn orílẹ̀-èdè gúúsù amẹ́ríkà}}
15
ní agbègbè orí òkè nuba ní orílẹ̣̀ èdè sudan ni àwọn ènìyàn tí ó n sọ èdè yìí wọ́pọ̀ sí jùlọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun àti ọ̀tẹ̀ ti fọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn yìí ká. àtẹ ìṣàlẹ̀ yìí ni ó ṣe àkójọpọ̀ àwọn ìsọ̀rí èdè tí ó wà ní abẹ́ ori èdè kordofanian.
16
alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ èkó, tó fìdí ìsẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní, wọn kò tíì mọ ẹnití ọkùnrin naa jẹ́ àti ibití ó ń gbé, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò rí ojú ọgbẹ́ ní ara òkú náà.
17
nísàlẹ̀ ni àtòjọ àwọn àjápọ̀ mọ́ àwọn ibiìtakùn míràn tí wọ́n únta ìwé tuntun àti ìwé àtijọ́, wọ́n sì le ní ọ̀rọ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa àwọn ìwé tí ẹ únwá:
18
àwọ́n ènìyàn, máa ń rin ìrìnàjò afẹ́ lọ sí ìlú yìí. wọ́n máa ń kan ọkọ̀ ojú omi ńlá níbẹ̀. wọ́n ní àwọn èso wọ́n sì ní àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó ń sọ epo dọ̀tun.
19
ẹgbẹ́ òsèlú sdp ní ìpínlẹ̀ èkìtì ti ń gbàlèjò ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú pdp tó ń ya wá sínú ẹgbẹ́ náà báyìí.
20
ológun ojú omi fún àwọn ìpínlẹ̀ aṣọ̀kan amẹ́ríkà jẹ́ ẹ̀ka iṣẹ́ ogun tí ojú omi fún àwọn ìpínlẹ̀ aṣọ̀kan amẹ́ríkà àti pé ó jẹ́ ìkan nínú meje aláṣọ ogun fún àwọn ìpínlẹ̀ aṣọ̀kan amẹ́ríkà. ológun ojú omi fún àwọn ìpínlẹ̀ aṣọ̀kan amẹ́ríkà jẹ́ èyí tọ tọbi jù tí ó sì pójuwọ̀n jùlọ ní gbogbo àgbáyé[1][2][3] tí ó sì ní ohun ìjà jùlọ ní gbogbo àgbàyé.[4][5]
21
iléesẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ògùn ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọwọ́ òun ti tẹ afurasí mọ́kàndínlọ́gbọ̀n lórí ìpànìyàn tó wáyé ní ìjẹ̀bú igbó ní aago márùń ààbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ọ́jọ́ àìkú ní agbègbè òkè-sopen, tó sì sún wọ ìdàjí ọjọ́ ajé, èyí tó tún tàn wọ àwọn àdúgbò míì bíi òkè àgbò àti ojowo.
22
nínú ètò ìkànìyàn 1995, àwọn tí ó ń gbé andorra jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì-dún-láàádọrin (68,000). àwọn èdè tí ó jẹ́ ti ìjọba níbẹ̀ ni kàtáláànù tí ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ń sọ (60%) àti èdè faransé. wọ́n tún ń sọ kàsìtílíànù ti àwọn pànyán-àn-àn gan-an fún òwò àgbáyé àti láti fi bá àwọn tí ó bá wá yẹ ìlú wọn wo sọ̀rọ̀ .
23
ìṣàìtó àwọn enzymes àti àwọn ọlọ́kọ̀ tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìyípo urea lè fa àwọn àìsàn tí ó rọ̀ mọ́ ìyípo urea bíi:
24
ìfihàn àwọn àtúnṣe tí wọn jẹ́ àtúnyẹ̀wò àìpẹ́ nìkan ìfihàn àwọn àtúnṣe tí wọn jẹ́ ìdá ojúewé nìkan fi àwọn àtúṣe kékeré pamọ́
25
ìlù àgẹ̀rẹ̀ jẹ́ ìlù àtijọ́, ìlù àtayébáyé. nítorí ìró aminlẹ̀ tí ó ní, ìlù àgẹ̀rẹ̀ ni ìlù àwọn ògbójú ọdẹ àtijọ́. bákannáà, wọ́n máa ńlù ìlù àgẹ̀rẹ̀ nígbàtí ọlóde tàbí onífa tàbí ọba ìlú bá pa ipò dà. ní àfikún, wọ́n tún máa ńlu ìlù àgẹ̀rẹ̀ fún àwọn ọba àti ìjòyè láti yẹ́ wọn sí.
26
owóorí sísan ni ilẹ̀ nigeria wà ni ìbámu pẹ̀lú ìlànà bi wọn se ń se káàkiri àgbáyé. étò yìí ni ó fi àǹfààní sílẹ̀ fun ìdàgbàsòkè, nibi ti àwọn tó ń gba owó osù gọbọi yóò san owóorí wọn gẹ́gẹ́ bí owo tí wọn ń gbà ni gbogbo àkókò supgbọ́n tó jẹ́ wí pé ọ̀pọ̀ àwọn onísẹ́ àdáni, àwọn akọ́sẹ́mọsẹ́ ati àwọn ilé isẹ́ ọlọ́kan-ò-jọ̀kan kìí san owóorí wọn déédé látàrí bí àwọn tó wà ní ẹ̀ka owóorí gbígbà kò se mọ iye tó ń wọlé sí àpò irú àwọn ènìyàn wọ̀nyìí. ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpínlẹ̀ ni kò ni òsìsẹ́ to lati mọ àkọsílẹ̀ nipa iye àwọn ènìyàn to ń san owóorí ni ìpínlẹ̀ wọn.
27
ogun ẹkú dédé àsìkò yìí ẹ̀yin ọmọ ogun. ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́kí á tún bọ̀ sọwọ́pọ̀ láti gbé ògo ilẹ̀ yorùbá ga.inù mi dùn púpọ̀ sí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ẹ̀ẹ̀tí kẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ yorùbá yálà nílẹ̀ yorùbá tàbí ní òkè òkun bá lè bẹ̀rẹ̀ láti máa kọ́ ọ̀pọlọ̀pọ̀ nínú àwọn àròkọ wọn ní èdè abínibí wà nítorí òní kọ́ àmọ́ nítorí ọjọ́ ọ̀la kí àwọn ọmọ tí wọn kò ì tíì bí lè rí nnkan kà nípa gbogbo ohun mère mère tí ó n sẹlẹ̀ jákè jádò àgbáyé. tí a bá wo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sì ní máa gbérí níwọ̀n ọgbọ́n ọdún sẹ́yìn a ri wí pé púpọ̀ nínú wọn ni wọn fi èdè abínibí kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ́n, kòsí iṣẹ́ìwádìí kan tí wọ́n se tí wọ́n kò kọ ní èdè wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé èdè gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n gbà fi se ìwádìí náà. ó seni láànu láti máa pàdé àwọn ara ilé nílu òyìnbó kí wọ́n máa fara pamọ́ ki a máà ba pè wọ́n ní ọmọ yorùbá.ogún lọ́gọ̀ àwọn olùkọ́ni nílu òyìnbó ni wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ yorùbá sùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo akitiyan wọn kò sí ọ̀kan soso nínú isẹ́ ìwádìí wọ́n pẹ̀lú aroko tí ó wà ní èdè yorùbá- kí ló dé?
28
ìyá àgbà ó gbẹ́yìn nínú àjọọṣepọ̀ láti kọ́ áwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀. èròǹgbà wọn ni láti ríi wípé àjàyi àti àwọn ọmọdé ìyókùn ńhu ìwà ọmọlúàbí.
29
ìlù dùndún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ìlù tí a mọ̀ jùlọ ní ilẹ̀ yorùbá. a le lo ìlù dùndún lóhun nìkan tàbí pẹ̀lú àwọn ìlù míràn láti mú kí ìró ìlù lárinrin létí. ní ayé àtijọ́, àwọn onílù dùndún máa ńfi ìlù yǐ ki àwọn ọba àti àwọn ìjòyè ìlú lójoojúmọ́. fífi ìlù ki àwọn ọba àti àwọn ìjòyè sì wà ní ilẹ̀ yorùbá lónǐ. àwọn tí ó ti dàgbà ní ó máa ńlu ìlu dùndún. ṣùgbọ́n ní ìdílé onílù, ní ibi tí ó ti jẹ́ wípé iṣẹ́ wọn ni ìlù lúlù, ẹ̀kọ́ nípa ìlu lúlù bẹ̀rẹ̀ láti kékeré. àwọn àgbàlagbà á ṣe ìlù àti ọ̀pá ìlù kékeré fún àwọn ọmọdé, wọ́n a fún wọn láyè láti tẹ̀lé wọn lọ sí ibi ayẹyẹ tàbí kí wọn máa fi ìlù wọn ṣeré kiri. fífi ìlù kọ́ àwọn ọmọdé báyǐ máa jẹ́ kí wọn tètè mọ ìlù’úlù. àwọn ọmọ onílù kìí ṣe aṣáájú ní ìgbà tí wọn bá ńkọ́ ìlù lọ́wọ́. àwọn agba onílù ṣe báyǐ láti ríi dájú wípé ìró ìlù tí ó yantanran ni wọ́n ńgbe jáde sí etí àwọn olùgbọ́ ní gbogbo ìgbà.
30
ìwé àjàyí gbọ́ ìtumọ̀ ìlù jẹ́ ìwé tí a ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀rọ òde òní fún àkàgbádùn àwọn ọmọdé pẹ̀lú àwọn òbí. ìwé yǐ fi ìlò èdè àti ẹwà èdè yorùbá bíi òwe, àṣàyàn ọ̀rọ̀, oríkì àti ìjìlẹ̀ ọ̀rọ̀ hàn. bákannáà, ìwé yǐ tún fi àṣà àti ìṣe yorùbá hàn ní ọ̀nà tí ó le rọrùn fún àwọn ọmọdé wa láti tẹ̀lé.
31
èròǹgbà làti kọ ìwé yǐ bẹ̀rẹ̀ ní bíi ọdún mélǒ sẹ́yìn nígbàtí ọmọ òǹkọ̀wé yǐ bẹ̀rẹ̀ síí ka àwọn ìwé ọmọdé tí a kọ ní èdè òyìnbo. kò sí irú àwọn ìwé báyǐ ni èdè yorùbá, pàá-pàá jùlọ ní òkè àríwá america.
32
àjàyí fẹ́ràn àwọn ẹbí rẹ̀, pàá-pàá jùlọ ìyá àgbà fún ààlọ́ tí wọn máa ńpa nípa ìjàpá ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́. àjàyi bá àwọn òbi rẹ̀ lọ sí ibi ìwúyè ní ìlú ayépé, ní ibi tí ó ti pàdé àwọn ọmọ ẹ́gbọ́n ìyá rẹ̀, àdùkẹ́ àti àdùní. àyándìran onílù àrà àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ aríjóyọ̀ sọ ìlù sí wọn ní’bàdí, oyin mọmo, oyin àdò ni!
33
àkọọ́lẹ̀ ìṣe ìdínà àti ìgbéìdínàkúrò nìyí. àwọn àdìrẹ́ẹ̀sì ip tí wọn jẹ́ dídílọ́nà nífúnra wọn kò sí nínú àtòjọ yìí. ẹ wo àtòjọ ìdínà fún àtòjọ àwọn gbogbo ohun tí a dílọ́nà báyìí.
34
nísàlẹ̀ ni àtòjọ àwọn àtúnṣe sí àwọn àbò ojúewé. ẹ wo àtòjọ àwọn ojúewé aláàbò fún àtòjọ àwọn àbò ojúewé ìgbàyí.
35
ìkìlọ̀: ibùdó dátà ti jẹ́ títìpàdé fún ìtọ́jú, nípa bẹ́ẹ̀ ẹ kò ní le fi àwọn àtúnṣe yín pamọ́ lásìkò yìí. tí ẹ bá fẹ́ ẹ le fi ìkọ̀rọ̀ náà pamọ́ sínú fáìlì ìkọ̀rọ̀ fún ìgbà míràn.
36
ẹ lọ fọ́ọ̀mù ìsàlẹ̀ láti ṣèrùsókè àwọn fáìlì. láti wò tàbí wá àwọn fáìlì àrùsókè tẹ́lẹ̀ ẹ lọ sí àtòjọ àwọn fáìlì àrùsókè, àwọn à(tùn)rùsókè náà jẹ́ kíkọọ́lẹ̀ nínú àkọọ́lẹ̀ ìrùsókè, àwọn ìparẹ́ nínú àkọọ́lẹ̀ ìparẹ́.
37
àwọn fáìlì ìsàlẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ lílò sùgbọ́n wọn kò sí. àwọn fáìlì láti ibi-àkósí òkèrè le jẹ́ títò síbẹ̀ bótilẹ̀jẹ́pé wọ́n wà. ìrú àwọn àdájú irọ́ báhun yíò jẹ́ fífagi lé lórí. láfikún, àwọn ojúewé tí wọ́n ní fáìlì tí kò sí nínú jẹ́ títòjọ sínú ẹ̀ka:àwọn ojúewé pẹ̀lú àwọn ìjápọ̀ fáìlì gígé.
38
àwọn ẹ̀ka yìí ní ojúewé tàbí amóhùnmáwòrán. àwọn ẹ̀ka aláìlò kò hàn níbí. bákannáà ẹ wo àwọn ẹ̀ka wíwá.
39
ilé isẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ náà sọwípé lóòtọ́ ni ìsẹ̀lẹ̀ náà sẹlẹ̀ sùgbọn ènìyàn mẹ́ta làwọn rí òkú rẹ́ nígbà tí àwọn dé ibi ìsẹ̀lẹ̀ náà. tí a kò bá gbàgbé, ìsẹ̀lẹ̀ yíí wáyé lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí àarẹ muhamadu buhari se àbẹ̀wò sí ágbèègbè náà, tó sì se ìpàdé pẹ̀lú àwọn ọba àti àwọn àgbààgbà pẹ̀lú àsẹ wípé kí wọ́n palẹ̀ àwọn ọlọ́sà mọ́ lágbèègbè náà.
40
kànsí àwọn alaṣẹ apá ilé ayé tí ó jẹ́ ibùgbé ohun ẹlẹmí tí a fi pamọ́ ní orílẹ̀ èdè rẹ kí o sì sọ fún wọn nípa ìdíje yìí ̣ṣe ìfilọ̀ ìdíje yìí pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ oní fọ́tò, ilé ẹ̀kọ́ gíga àti àwọn ẹgbẹ́ tí ó bá mọ̀ pé ó lè fẹ́ kópa. ìdíje yìí máa jé àànfàní ńlá fún àwọn àwùjọ àti àwọn àjèjì sí awọn apá ilé ayé tí ó jẹ́ ibùgbé ohun ẹlẹmí tí a fi pamọ́ lati ya àwọn fọ́tò àwọn ibi wọ̀nyí, àti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa wọn síi.
41
iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti sọ pé àwọn kò tíì leè sọ bóyá àdó olóró ló bú nílééṣẹ́ ìtoògùn kan ní ìlú ilé ifẹ̀. ọ̀gá ọlọ́pàá nípínlẹ̀ ọ̀ṣun sọ pé irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò wáyé rí, àwọn yóò sì gbé ìgbésẹ̀ láti dẹ́kun àtúnṣẹ̀ rẹ̀. nígbà tí kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá, ọláfimíhàn adéoyè bẹ ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù náà ti ṣẹ̀lẹ̀ wò lọ́jọ́ ajé, ó ní àwọn agbófìnró yóò máa ṣètò àbò tó gbópọn fún àwọn aráàlú.
42
àwọn agbébọn náà tó máàrún níye nígbà tí wọ́n kọ̀lú àgọ́ ọlọ́pàá náà ní agogo méjì òru ọjọ́ ìṣẹ́gun tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀. kòsí ẹni tó lè sọ ní pàtó ohun tó ṣokùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣùgbọ́n ìròyìn sọ pé àwọn agbébọn náà gbe ìbọn kan lọ pẹ̀lú àwọn ọta ìbọn.
43
wikipedia jẹ́ ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́ tó wà nítorí akitiyan awọn oníse rẹ̀. gbogbo àwọn tí wọ́n kópa nínú iṣẹ́-ọwọ́ yìí lè dá àyọkà tuntun tàbí ṣàtúnṣe àwọn àyọkà tó wà. àfikún kọ̀ọ̀kan únjẹ́ kíkọ sílẹ̀ sínú ìtàn àwọn ojúewé bẹ́ẹ̀sìni wọ́n únhàn nínú àwọn àtúnṣe tuntun. àwọn ohun tí wọn kò bá ní ìbámu pọ̀ mọ́ ìwé ìmọ̀ wikipedia yíò jẹ́ píparẹ́.
44
gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọpaa hisbah ṣe sọ, oní nààbì ní àwọn ọmọbinrin yìí, tí wọn sì ń wa àwọn oníbara nínú iṣẹ́ wọn, sùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbinrin yìí ló sọ pe, ìdíkan tàbí òmíràn ló gbé àwọn jáde kúrò nílé ní àsìkò ti wọn mú àwọn.
45
ìpínlẹ̀ ẹdó jẹ́ ìkan nínú àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà. ó sàgbè pẹ̀lú àríwá àti ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ kogi, àgbè pẹ̀lú gúúsù ìpínlẹ̀ delta àti ìlà-oòrùn ìpínlẹ̀ ondo.
46
àọn àgùdà jẹ́ oníṣòwò pẹ̀lú àwọn benin nígbàyẹn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣàpèjúwe rẹ̀, ó jẹ́ àpẹrẹ́ àjọṣepọ̀ láàrin omi àti ilẹ̀.[17]
47
anguidae jẹ́ orúkọ àwọn ẹbí tí ó tóbi tí ó jẹ́ ti aláǹgbá ti northern hemisphere. àwọn tí ó wà ní ẹgbẹ́ yìí ni àwọn slowworm, alángbá gílásì àti alángbá inú omi, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. wọ́n pín ẹbí yìí sí àwọn ẹbí mẹ́ta tí ó sì ní àwọn ẹ̀yà mẹ́rìnlé làádọ́rún ní àwọn ìdílé mẹjọ. wọ́n ní àwọn osteodem tó le ní abẹ́ awọ ara wọn àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwpọn èyà yí ní àwọn ọwọ́ kúkurú tàbí tí kò sí rárá, léyí tí ó jẹ́ kí wọ́n dàbí ejò bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òmíràn ní ọwọ́ tó pé.[2]
48
àwọn olórí ẹgbẹ́ òsìsẹ́ ti sọfún ìjọba àpapọ̀ pe ko fíì ọ̀rọ̀ owó osù tuntun tí wọ́n fẹ́ ma san fún àwọn òsìsẹ́ falẹ̀, bí kòbá fẹ́ kí àwọn òsìsẹ́ fárígá.
README.md exists but content is empty.
Downloads last month
16