Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Àwọn ọlọ́pàá lé Olúṣọlá bí ó ti ń sá lọ. | 0 |
Bàbá Àyìnlá Adédiwúrà di olóògbé. | 0 |
Àwọn ni wọ́n gbé gbogbo owó tó yẹ káwọn ọmọ ẹgbẹ́ san nítorí ìbò tí wọ́n ń wá. | 0 |
A kì í rójú ẹni puró mọ̀ni. | 1 |
Wọ́n ti dáná sun ilé ìyá ọ̀daràn náà. | 0 |
Adéọlá ti fi ipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alága ẹgbẹ́ òṣèlú aládìyẹ. | 0 |
Mo nígbàgbọ́ nínú ìgbésẹ̀ tí olórí Iléeṣẹ́ mi bá gbé. | 0 |
Akánjú jayé, ọ̀run wọn ò pẹ́ . | 1 |
A-fi-tiẹ̀-sílẹ̀-gbọ́-tẹni-ẹlẹ́ni: ọ̀gànjọ́ ni wọ́n ń sìnkú-u rẹ̀. | 1 |
Ejò-ó kéré kò kéré, kò ṣéé dì ní ìgbànú. | 1 |
Afàìmọ̀ kí ilé ẹjọ́ máà dá ẹ̀wọ̀n gbére fún adigunjalè tó ṣekú pa olówó kan. | 0 |
Babátúndé ní ejò lọ́wọ́ nínú lórí ìsẹ̀lẹ̀ rògbòdìyàn tó ń wáyé. | 0 |
B'ẹlẹbọ 'ò peni a kì í sàrúfín. | 1 |
Ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ péjú láti ṣayẹyẹ ìkẹyìn fún Bàbá tó kú lánàá. | 0 |
Ęgún owọ ni kì í jẹ kí tẹsèé seé mú. | 1 |
Awakọ̀ àwọn olóògbé nígbà kan rí ni ọ̀gbẹ́ni Májẹ́kódùnmí. | 0 |
Màá fa èèyàn lọ́wọ́ ni dípò kí n gbára ta. | 0 |
Akóredé,Àlàbá àti Àjàní súnmọ́ ọkọ̀ tí wọ́n fi ń gbé Àjàlá lọ sí ẹ̀wọ̀n. | 0 |
Gbogbo àwọn ilé tó wà nínú báràkì ti di ẹgẹrẹ mìtì. | 0 |
Àwa àti aṣojú àwọn àkàndá ẹ̀dá fẹ́ ṣe ìpàdé. | 0 |
A kì í fi ojoojúmọ́ rí olè jà kó dà bí-i tọwọ́ ẹni. | 1 |
Ayẹyẹ ìdána ọmọbìnrin rẹ̀ jẹ́ èyí tí gbogbo èèyàn mọ̀ nípa rẹ̀. | 0 |
Ẹni tó jìn sí kòtọ, ó kọ aráyókù lọgbọn. | 1 |
A kì í namọ tán kí a tún máa bèèrè aṣọ. | 1 |
Bí a bá torí igi gbodì, ẹtọ ni kó sunaá' re fún ni ya. | 1 |
Àì-mọ̀-kan, àì-mọ̀-kàn ní mú èkúté-ilé pe ológbò níjà. | 1 |
Bámtẹfá kàn 'ò sí mọ, kóníkálukú máa (dá) tęfẹ ara rẹ. | 1 |
Ẹni àigbọn pa ló pọ; ẹni ọgbọn pa 'ò tó nnkan. | 1 |
Bí èdè Yorùbá ṣe di kíkọ sílẹ̀ kò ṣẹ̀yìn Àjàyí àti àwọn ajíhìnrere. | 0 |
Àìrí owó oṣù gbà jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ṣekúpa wọ́n. | 0 |
B'ádie bá ń sunkún iyę, ìyẹ a sì bòó. | 1 |
Àtíkù ń pe ìjọba sí àkíyèsí ojú ọ̀nà tí wọ́n fẹ́ ṣe. | 0 |
B'Óbìnrin bá ní “șe bóó ti se” obìnrin gbà nùn-un. | 1 |
,Bí a bá fẹ rí eyín arúgbó, ìwọ șá bèèrè ọkọ ę. | 1 |
Àwọn aṣòfin Èkó sọ pé ìyànsípò àwọn ènìyàn kan kò bófin mu. | 0 |
Ináọlájí sọ pé wọ́n ti fi àwọn ohun ìjà ránṣẹ́. | 0 |
Àkíìjẹ ló ń m'Óòṣà níyì. | 1 |
Ẹ̀ka náà wà ní pápákọ̀ òfurufú Nnamdi Azikwe nílùú Àbújá. | 0 |
Ojoojúmọ́ ni àwọn èèyàn ń kú lórílẹ̀ ayé yìí. | 0 |
B'ọmọdé s'òkò lu Agẹmọ, kò ní kú,kóní rùn,aápọn láso nì | 1 |
Ilé iṣẹ́ ìròyìn ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún àwọn méjì mìíràn. | 0 |
Ajẹnifẹ́ni, èkúté ilé. | 1 |
A kì í mọ ọkọ ọmọ ká tún mọ àlè-e rẹ̀. | 1 |
Ẹwà Rìnsọ́lá tí Fákẹ́yẹ rí ni ó wọ̀ ọ́ lójú. | 0 |
Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ tí ó ń wọlé tọni wá ni ọ̀rọ̀ ìjínigbé ní ìpínlẹ̀ Ondo. | 0 |
Agbọnmi níí wolé ẹja, apàjùbà níí ba'lé àparòó jẹ | 1 |
Awakọ̀ sọ pé níṣojú òun ni wọ́n fi lọ́rí ọkọ̀ náà padà. | 0 |
Àmọ̀tẹ́kùn Òndó mú àwọn afurasí tó já wọ oko olóko. | 0 |
Àìsàn là ń wò, a kì í wo ikú. | 1 |
Èsì tí Dámilọ́lá kọ́kọ́ kọ sí i bó ṣe ń fìbínú sọ̀rọ̀ ni kó múra sí i. | 0 |
Àkíyèsí pàtàkì tí a níláti ṣe ni kí a ṣọ́ ilé kówá ó wa. | 0 |
Àrá méjì ló wà lájùlé; bí ọkan bá ń kéle, ọkan yóókù a sì máa kẹrọ. | 1 |
A gbọ́dọ̀ wá ọ̀nà tí a fi lè ran ìjọba lọ́wọ́. | 0 |
Bí àlá ni ó kọ́kọ́ rí lójú wọn nígbà tí wọ́n délé Àjàdí. | 0 |
Ení rewọ, resẹ; ó bù ré. | 1 |
B'egbe enib á wà ní má-yẹ-lóyè, a kì í wà ní súré-pẹgbę. | 1 |
À ń pa ẹ̀kukù, ẹ̀kukù ń rúwé; à ń yan nínú aṣẹro, aṣẹro ń dàgbà; à ń kébòsí Ògún, ara Ògún ń le. | 1 |
A-bániwọ́ràn-bá-ò-rídá; ó yé kọ́ńdú-kọ́ńdú sẹ́yin ẹlẹ́yin; ó di òkúta s rù ẹni tó fúyẹ́. | 1 |
Ọlọ́dẹ àdúgbò Dálímore ni olóògbé yìí ń ṣe láti bíi ọdún mẹ́ta sẹ́yìn. | 0 |
Adébáyọ̀ Bánjọ jẹ́ ọmọ orílẹ̀èdè Bírítéènì. | 0 |
B'ọmọ 'ò bá mọ 'Baba ẹ gbà' Baba a sì mọ 'ọmọ mú wá'. | 1 |
Àwọn igun ọmọ-ìta fẹ́ gba owó lọ́wọ́ bàbá olówó tó ra ilé gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn. | 0 |
Aṣọ àdìrẹ jẹ́ aṣọ tó rẹwà, ìlú Ẹ̀gbá ló sì ti gbajúmọ̀ jù. | 0 |
Aṣòroówọ̀ bí ẹ̀wù àṣejù. | 1 |
B'ádàn-án bá ń se kátàkótò, gbogbo eyẹ oko a yára m'ẹnu ró. | 1 |
Ẹ̀mí àbàtà ní ń mú odò ṣàn; ọlá-a baba ní ń mú ọmọ yan. | 1 |
Eré t'ọn ní k'ọmọdé má se ló ń níyì lójú ę. | 1 |
Afẹ́fẹ́ tó wọlé tó kó aṣọ iyàrá, ìkìlọ̀ ni fún ẹni tó wọ tiẹ̀ sọrùn. | 1 |
Àhámọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó wà ní Ewu-Olíwo ni wọ́n ti Àkànbí mọ́. | 0 |
Àkísà-á ba ẹni rere jẹ́. | 1 |
Alàgbà Ṣọlá ti fìwé sílẹ̀ pé òun kò ṣiṣẹ́ mọ́. | 0 |
Ààrẹ bọwọ́lu ètò ìsúná ọdún tí a wà nínú ẹ̀ yìí. | 0 |
Àgbàlagbà tí ò kí Ààrẹ ń fi okùn sin ara-a rẹ̀. | 1 |
Àwọn olùgbé agbègbè náà ni wọ́n kọ́kọ́ dáàbòbò agbègbè wọn kí ọlọ́pàá tó dé. | 0 |
Ẹni tó máa fohun rere f'ẹlẹgàn; kò gbọdọ retí ọpẹ. | 1 |
Àìmọnúú rò lài m'ọpẹe dà. | 1 |
Ẹja t'ó wọnú àwọn; a á bára e láàrin omi-ata. | 1 |
Èèyàn mẹ́ta dèrò iléẹjọ́. | 0 |
Àgbéré onígàlúrà, bó bá d'ójó a á parę. | 1 |
Bí oògùn ò bá jẹ́, owó ẹ̀ á jíṣẹ́. | 1 |
Adáramáṣu ò sí. | 1 |
Bí a kò lówó, à léèyàn; bí a kò léèyàn à lóhùn rere lẹ́nu. | 1 |
Olúṣọlá feré gé e lẹ́yìn tí ó gún àwọn ọlọ́pàá. | 0 |
B'ojú bá yęjú, k'óhùn má yę. | 1 |
A kì í júbà afimọsíkùnkú. | 1 |
Ère Alápà, b'ó șe sunàn tó; imú e se tanganna. | 1 |
Àìpé, ‘‘Tìrẹ nìyí’’ ní ń bí ayé nínú. | 1 |
Ọlọ́pàá kan lágbègbè Ìjọrá fi ọ̀bẹ gún aráàlú kan pa. | 0 |
Gbogbo ẹ̀sín tí Òkìkíọlá bá fi Dámilọ́lá ṣe ni kí ó fara mọ́. | 0 |
Ọ̀daràn ọ̀hún sọ wí pé òun kò mọ ohun tòun fi ṣìwà hù lọ́jọ́ náà. | 0 |
Wọn yóò kọ́kọ́ fi ọkọ̀ kó àwọn ènìyàn kúrò ní ìlú Súnmọ́mi. | 0 |
Ará-oko tí yóo je búredì yóó fișu ránnse sílé. | 1 |
Ajálékokò tún ti fi ọkọ rẹ̀ kọju irin. | 0 |
Àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí àti rẹ̀ kì í fi àkàndá ẹ̀bùn rẹ̀ dùn ún. | 0 |
Wọ́n ní Dámilọ́lá nìkan ló ní làákàyè nínú àwọn obìnrin tí Òkìkíọlá ń kó kiri. | 0 |
Àgò ló ń dé adię. | 1 |
A-ṣúra-mú ò tẹ́ bọ̀rọ̀. | 1 |
Àwọn aṣáwó ti ń gba owó nlá lọ́wọ́ àwọn oníbàárà wọn. | 0 |
Bí ebí bá ń pa ejò, ahun kì í yan; àtahun àtejò, ẹran jíjẹ. | 1 |
B'álágbára jẹ ọ níyà, yára ferín sí. | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.