Proverbs
stringlengths
8
373
Labels
int64
0
1
Èyín èèkàn ewà.
1
A kì í ṣe ọmọ ju ọmọọ́lé; a kì í se ọmọ òrìṣà ju ààfín.
1
Olúmọ korò ojú sí bí àlàbọrùn àṣà náà ṣe fẹ́ dẹ̀wù fún ilé-iṣẹ́ Gómìnà Èkó.
0
Ẹ̀míọlá sọ pé ẹ̀yà àwọn lè dá dúró gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan.
0
Aláàánú kì í tán.
1
Irú ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ yìí yà mí lẹ́nu gidi gan-an ni.
0
níi rún wómúwómú.
1
Wọ́n rí àwọn oògùn tí ọ̀daràn ọ̀hún so mọ́ ara àti ọta ìbọn gbà lọ́wọ́ rẹ̀.
0
Àwọn aláṣẹ ilé ìtura Ìgbáládùn sọ pé àwọn yóò ran àwọn agbófinró lọ́wọ́.
0
Àkèekèé ní òún kúrò ní kòkòrò-o kí nìyí?
1
‘‘Òkè ìhín ò j ká rí tọ̀ún’’ ò ṣéé pa lówe nílé àna ẹni.
1
Ogúnlọ́gọ̀ òṣìṣẹ́ ìjọba ti kó àjàkálẹ̀-àrùn.
0
Bí iṣẹ́ abẹ igbákejì Ààrẹ ṣe lọ ní ìrọ̀rùn.
0
Èkuté 'ò le b'Ólóginní șe pọ k'ọrọ má dakitiyan.
1
Abẹnugan ọlọ́pàá sọ wí pé ìwádìí sì ń lọ lọ́wọ́.
0
Èèyàn mèjì kì í șíyèlé nnkan (eyọkan)
1
Ẹní à ń bọ, kì í bọ ajá.
1
Àmọ̀jù là ń mọ ẹkùn-un Sàárẹ́ .
1
Èèyàn ẹni là ń fi ààyè ọmọ hàn; nígbà tó bá dòkú gbogbo ayé ní ń yọrí-i rẹ̀.
1
Bí a bá wáyé eni a á nígbà ni.
1
Dìẹdíę là á j'ewó eni tán nílé àna.
1
Ọlágòkè gba ilé lọ nígbà tí ó hànde pé kò lè rí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ náà.
0
Àṣírí àwọn gbọmọ-gbọ́mọ tú ní Sókà nílùú Ìbàdàn.
0
Bákan náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ààrin ìlú ló ti bàjẹ́.
0
Èèyàn kì í subú òwò, kó subú oko.
1
Akótilétọ yàto sí akótílętà.
1
Àdàbà ń pògèdè, ó rò pé ẹyẹlé ò gbọ́; ẹyẹlé gbọ́, títiiri ló tiiri.
1
Àwọn ènìyàn kan fẹ́ fọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú mi.
0
Èèyàn níí pé "ó rẹ mí,' Ọlọrun Ọba kì í dàwọ isę dúró.
1
Hìhìhì là á dáná ogun; pẹlẹkùtù là á dáná ọtẹ.
1
Aṣunú ò mọ̀-ọ́ láyọ̀; ó dìgbà tó bá rí ẹni tí kò lè ṣu.
1
Séríkí Fúlàní ti fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun létí.
0
Bilẹ bá șú; eku Ọtọ pęlú ť'Ìsàlę-Èkó áá ję kanra.
1
Àmàlà ló wù mí jẹ ṣùgbọ́n kò sí àbùlà, ewédú nìkan ló wà.
0
Epo òyinbó kì í bàję.
1
Bí yóò ti rí ni yóò rìí; alágbẹ̀dẹ ò lè gbé ọmọ owú mì.
1
Kí ló dé tó jẹ́ àìmọye oṣù la ó fi máa ṣètò ìdìbò?
0
Aṣòfin mìíràn sọ pé ìwà àìbófinmu yìí kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wáyé.
0
Aṣọ̀rọ̀kẹ́lẹ́ bojú wògbẹ́; ìgbẹ́ ò délé sọ fẹ́nìkan; ẹni a ń bá wí ní ń wíni kiri.
1
Ọ̀gá àgbà ilé ìfowópamọ́ fajúro sí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀.
0
Ọláfisóyè sọ pé òun kò lè sọ bóyá wọ́n ri ohunkóhun tó jẹ mọ́ ètùtù nínú ọkọ̀ rẹ̀.
0
Eégún ṣé-é jó; òòṣà-á ṣé-é jó; ti Olódùmarè-é yàtò.
1
Bí ère bá n pé kò sí b'óun ò se je, kí á gbé e renú igbe, ki a figi tí a fi gbẹ e hàn án.
1
Baṣọ̀run ìlú Ọ̀yọ́ ló léwájú àwọn olùpẹjọ́ Gómìnà.
0
Ègún 'ò lódó, ẹsan 'ò lọlọ.
1
Oore kí ló máa mú kéèyàn fi tipátipá jọba mọ́ àwọn èèyàn lórí.
0
Àjàkálẹ̀-àrùn ti bẹ́ sílẹ̀.
0
Ewúrę kì í rèso àgùntàn lọ ję.
1
Àwọn ọlọ́pàá náà fa Àjàní wá sí àgọ ọlọ́pàá.
0
Àwárí lobìnrin ń wá nǹkan ọbẹ̀.
1
Àjànàkú tí a gbẹ́ ọ̀fìn sílẹ̀ dè, erin-ín mojú; erin ò bá ibẹ̀ lọ.
1
Abiyamọ náà sọ pé òun ò lè wo òkú ọmọ òun.
0
Ògúnrónbí ti mu ọtí yó.
0
‘‘Lọ kúrò nílé mi’’ kì í ṣe ‘‘Kúrò láyé.’’
1
Ìpele kẹ́ta: Wíwọlé sí agbègbè tí ogun tàbí wàhálà ti ń ṣẹlẹ̀.
0
Lójú-ẹsẹ̀ ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti fi ọkọ̀ méjì ṣọwọ́ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
0
B'éèyàn ò mẹsọ, kò leè bá wọn gbé ljió.
1
Ẹ ní ká má tafà; kí ni a ó fi lé ogun? Kànnà-kànnà la fi lé Boko.
1
Ààyò, níí lọbẹ èèbó, ẹni ọkọ fẹ níí f'ọpọn-ifá jẹun.
1
Èèyàn 'ò wábi òkú (ìyáà mi) șeé gbọ, kò síbi ti wọn tí ń ro'jo péèèyàn wá kò sunkún.
1
A șí ogún ișu, agbọn lóun ò lọ; kí la ó fi rù ú?
1
Eku t'á a bá nísà là á pa.
1
B'á a jà tán; inú 'ò dùn mọ.
1
Babarìndé sọ pé kì í ṣe ọ̀kadà nìkan ni wọ́n gbà lọ́wọ́ òun.
0
A bẹ Ọbásanjọ́ lásìkò ìbò ààrẹ kó ti Ládi lẹ́yìn.
0
Ọdúnlámì sọ pé kò sẹ́ni tó tí ì lè sọ bóyá oníjìbìtì ni ọmọkùnrin náà àbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
0
A kì í b'ókùnrùn eyẹ l'órí itẹ pírí Lolongo ń jí.
1
Akọ̀wé ìjọba àjọ tó ń mójútó ètò ẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀ lórí ìbáṣepọ̀ yìí.
0
Ebi ń pa mí; olọșẹ ń pólówó, ìgbà tí n'ò wẹnú, n ó șe wẹdi (wẹòde)
1
·Eyin ò seé gbé l'érí pàntèté.
1
Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ni ọba tuntun yóò bọ́ sí orí oyè.
0
Ó ṣeni láàánú pé ìyà ni wọ́n fi ń jẹ àwọn àkàndá ẹ̀dá tí wọ́n nílò ìtọ́jú.
0
Bí a bá ránni níṣẹ́ ẹrú, à fi jẹ́ tọmọ.
1
Eyin àgbà tí ę ję ișẹbì,e pera yín jo.
1
Bí ò sí ojú; orí kò ríran.
1
Ẹnu 'ò sunàn; elẹnu pọn ọn lá.
1
Gómìnà Mákindé yóò ṣe ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ikọ̀ ọmọ ẹgbẹ́ tuntun onímọ́tò.
0
Afẹ́ẹ́ṣe-má-rìí; kò kan tahun.
1
Àwọn olùgbé Bodè àti Gáà béèrè fún iṣẹ́ lọ́wọ́ ìjọba.
0
Ẹrín 'ò dùn l'ọjo ogun pókitì lęsę-Qya.
1
Afínjú egbò ní ń gba ewé iyá; àgbàlagbà egbò ní ń gba ẹ̀gbẹ̀sì; ọ̀kánjúwà egbò ní ń múni ní san-san ojúgun.
1
Ààrẹ Yar'Adua ti di olóògbé tí igbákejì rẹ̀ sì gorí oyè.
0
Ó sọ wí pé ohun tí ó kù ni pé kí ìjọba bá àwọn ṣe ọ̀nà.
0
Èmi àti ọkọ mi kò tí ì ní ìjà tó burú tó eléyìí rí.
0
Àjọ elétò ìlera ìlú ti kéde ẹ̀dínkù àwọn tí wọ́n kó àjàkálẹ̀-àrùn.
0
Àwọn mọ̀lẹ́bí Adérántí sọ wí pé ó jẹ́ ẹnìkan tó máa ń pa àwọn lẹ́rìn-ín.
0
Adára-má-nìí-șùgbọn ò sí.
1
Akẹ́kọ̀ọ́ náà ń gbá bọ́ọ̀lù pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀.
0
Àì-dúpẹ́-oore-ànà mú ooré súnií ṣe.
1
Ẹsìn tí wèré yóó se, kì í jẹ ó kú ní kékeré. (rèwerèwe)
1
Àitètèjí ìnú ọtá ń dùn, a jí tán inú ń bí wọn.
1
B'ógun bá di odò, ó ma ń sàn lọ rerẹ ni.
1
Àkànṣe iṣẹ́ ìdàgbàsókè yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀.
0
Gbégbé kì í gbé s'óko-iwáje.
1
Bigbá ba reni fín òun, kò ye kó máa fi àwo se fintínrín
1
Àìlọ́ràá ògòǹgò, a ò lè fi wé ti agílítí.
1
À báà ṣẹbọ; à báà ṣoògùn; bí a ti pé a ó rìí láyé là ń rí.
1
Ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kí baálé ilé lọ fẹ́ ìyàwó mìíràn.
0
Àbúrò Màríà sọ pé kò tí ì mọ bó ṣe ń ṣe é.
0
Ẹni máa dá'jọ kì í sí nílé; ẹní máa mújà kì í wà lájò (kì í ràjò).
1