Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Ẹ̀tọ́ olóṣèlú tó fẹ́ ìdàgbàsókè ìlú ni láti forí balẹ̀ fún ohun tí ìlú ń fẹ́. | 0 |
Eni búburú wo'gbó; iwàa re to 0. | 1 |
Ẹgbẹ́ ẹni kì í wọ́n láyé ká wá a lọ sọ́run. | 1 |
Bí owó bá sì nínú ọ̀rọ̀, a súni pa. | 1 |
Àwọn olóri kan fi orúkọ wọn sílẹ̀ fún àmì-ẹ̀ye. | 0 |
Ààlà-á tó, ìmàle ò dúró de ara-a wọn. | 1 |
Ẹdá tí 'ò mọ 'Èyí tó mi', yóó mọ, 'Èyí tẹ mi'. | 1 |
Ebi kì í p'ààyàn kí a pé k'Ọlọșẹ sáá wò ó. | 1 |
Ẹ wo báwọn ọmọ ọ̀ṣọtà ṣe ya bó màmá Ire. | 0 |
Ẹni fẹ'ree rí; àyàfi kí ó na sùúrù sí i, torí bínú bá le lálejù, áá léire dànù. | 1 |
Àmọ (ni) kò w'ára eran. | 1 |
Kò jọ pé ìjà láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí àti ọmọ lẹ́yìn Kírísítì yóò parí láé. | 0 |
A kì í gbá ẹni tó yọ̀bẹ mú. | 1 |
Èkó j'ọba fúnlẹkílẹ tó lè ję. | 1 |
A kì í b'ẹni tí 'ò sí nílẹ. | 1 |
Awo ní ń perí awo. | 1 |
B'ówó bá rú ọmọdé lójú, a sì fún àgbà kà. | 1 |
Ajá kì í kọ ‘‘Wá gbà; wá gbà.’’ | 1 |
À-rí-ì-gbọdọ̀-wí: baálé ilé ṣu sápẹ. | 1 |
Àwọn ará àdúgbò tí wọ́n rí fídíò náà ni wọ́n fi ẹjọ́ sun àwọn ọlọ́pàá. | 0 |
Àhàráámù lè sài tó wọn lẹrù láàárọ mọsàn-án, bó dàșáálẹ a wámáa ta won lórí janjan. | 1 |
Fífi owó mọ́ èèyàn lórí jẹ́ àṣà tó wọ́pọ̀ láàárín ìran Yorùbá. | 0 |
Àwọn ọ̀dọ́ ń ṣe ìfẹhonúhàn ní Ọjọ́ta. | 0 |
Àìdé ikú là ń bọ Ògún; àìdé ikú là ń bọ òrìṣà; bíkú bá dé ikú ò gb bọ. | 1 |
Ìjà ti bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá ní ìlú Káraóle. | 0 |
Bí a bá fi ojú igi gbígbẹ wo tútù, tútù-ú lè wó pani. | 1 |
Èèyàn l'óun yóó bá o jẹ, o ní kò tó bẹè. B'ó bá ní o su, o 'ò nùdíń kọ? Èèyàn mélòó l'o ó fè'dí hàn? | 1 |
A kì í jẹ òkèlè lérí òkèlè. | 1 |
Àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kò ta àṣà àti ẹ̀sìn tiwọn nù. | 0 |
Àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé tí ó lọ ṣe ọṣẹ́ púpọ̀ fún dúkìá àti ẹ̀mí. | 0 |
Epo kì í pamọ kéèrà má mọbẹ. | 1 |
Ó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ láti má ṣe fòyà. | 0 |
Gbamgba gbàmgbà gbámgbá l'Àșá alátagbà ń gbẹyẹlé. | 1 |
Èmi àti ọ̀rẹ́ mi kan jà nígbà tí ìdìbò ọdún tó kọjá ń bọ̀ lọ́nà. | 0 |
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ ìròyìn nàka àléébù sí Pétérù fún ẹ̀sùn pé ó dalẹ̀ ìlú ẹ̀. | 0 |
Wọ́n ní àwọn kò lè rìn yan fanda nínú ọgbà rárá. | 0 |
Bí a bá rí ọlọ́rọ̀ ẹni, ṣọ̀rọ̀-ṣọ̀rọ̀ là ń dà. | 1 |
Àìgbọ́ràn ló sún un dé ibi tí ó wà yìí torí kì í gbọ́ràn. | 0 |
Ẹni tó ní kí olókùnrùn má jẹ èèwo, ohun tí yóò jẹ, á wá a fún un | 1 |
Ẹgbẹ̀rún eèrà ò lè gbé ṣúgà; wọ́n ó kàn tò yí i ká lásán ni. | 1 |
Àwọn jàndùkú ṣá ẹ̀ṣọ́ Àmọ̀tẹ́kùn ní àdá ní Ìkòròdú. | 0 |
Amùṣùà àgbẹ̀ tí ń gbin kókò. | 1 |
A kò gbọdọ b'ẹrù Onílé kí a tún berù asọ-iloro. | 1 |
Àgbòméji kì í mumi ni koto, k'ọrùn ọkan má yẹ. | 1 |
Bí Ahun se mọ níí yọrí. | 1 |
Bàbàńgídá ń kan sáárá sí Àtíkù fún bí ó ṣe ń ṣe lámèyítọ́ àwọn ìgbésẹ̀ ìjọba. | 0 |
Ẹ̀lúlùú ní kàkà kí òun má dun ọbẹ̀, òun á rúnwọ rúnsẹ̀ sí i. | 1 |
Àfiohunwéohun, àfọ̀rànwéọ̀ràn; fi ọ̀ràn jì ká lè yinni. | 1 |
Àdán tó sùn sídìí ọsàn ò rí he, áḿbọ̀sì oódẹ tó ní òún jí dé. | 1 |
Ayọ̀ abaratíńtín. | 1 |
Bí gbàmjarè básẹ ń di ìbòòsí o! K'ọlọgbọn gbogbo ó kíyèsíi. | 1 |
Wọn kò gbé Táyé lọ sí ilé ẹjọ́ mọ́. | 0 |
Bí a o ba figi nagi, a kì í gbóhùn igi. nàpe Biaòbáfope leè gbóhùn ope. | 1 |
Kò lè burú títí kí a má rí ọ̀nà tí a lè gbà yanjú aáwọ̀ wa. | 0 |
Àrífín ilé-ìgbẹ́, tí ń mú ọmọdé wo ìhòòhò àgbà. | 1 |
Ìgbìmọ̀ ìjọba buwọ́lu sísọ ilé ìjọba Nàìjíríà tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà di ààyè Ìdánilẹ́kọ̀ọ́. | 0 |
B'etu bá gbofá, ará ilé e ní í fi í hàn. | 1 |
Àwọn ènìyàn kan fi ìpè ìdágìrì ṣọwọ́ sórí aago ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá lánàá. | 0 |
Agbe ló laró; àlùkò ló losùn. | 1 |
Adébọ́lá ṣèlérí pé òun yóò gbé ìgbìmọ̀ atọpinpin kan dìde láàárín àwọn ọlọ́pàá. | 0 |
Wọ́n ti gbé òkú ọmọdé náà lọ sí ààyè ìtẹ́kùúsí. | 0 |
Ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀ wíwa epo rọ̀bì ní ìpínlẹ̀ Bodè àti Gáà. | 0 |
Ọ̀nà láti yọ àwọn ènìyàn kúrò nínú ìṣẹ́ ni ó yẹ kí ṣíṣe àwárí epo rọ̀bì jẹ́. | 0 |
“Atọmọ-Ẹkùn, àtọmọ-Ẹyá; wọn ò t'ọmọ-Kìnìún.” | 1 |
Èrò-Ọnhà níí dájọ Ológbò òun Àgùá. | 1 |
A-sáré-lówó ń bẹ lọ́nà ogun; A-pọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ lọ́nà èrò; Bó-pẹ́ -títí-n-ó-là ǹ bẹ lábà, ó ń jẹ ẹ̀sun iṣu. | 1 |
Àrífín tí ejò-ó fi yán ahun. | 1 |
Àwọn ajínigbé ọ̀hún lo ọkọ̀ yìí láti fi kó àwọn ènìyàn àti ohun tí wọ́n jí gbé. | 0 |
Bí a bá yọ ipin lójú, ojú la fi ń hàn. | 1 |
Àkànmú ni akẹ́kọ̀ọ́ tó fakọyọ jùlọ láàárín àwọn tó ń jáde lọ́dún yìí. | 0 |
Egbò-ó kẹ̀, iná kẹ̀, ohùn èèyàn-án kẹ̀. | 1 |
Kò sí ohun tí ẹnikẹ́ni tún lè ṣe bí ìjọba bá fi pàṣẹ. | 0 |
Awo kì í yalé awo, k'áwo ó jẹfọ, afi șukușuku ẹja. | 1 |
Àjọ ìṣègbèfábọ sọ fáwọn ọ̀dọ́ láti fòpin sí ìwọ́de | 0 |
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ti gbìyànjú ìlànà ti olóyìnbó láti ní oyún ṣùgbọ́n tí kò bọ́ sí i. | 0 |
Báwo ni odò Ọ̀ṣun ṣe jìn sí abúlé Alákijà? | 0 |
Àwọn Gómìnà ń gbé iṣẹ́ àkànṣe fún àwọn iléeṣẹ́ tó jẹ́ ti ẹbí. | 0 |
Bí a bá rẹni túnni șe; a kì í bàję. | 1 |
Àgbègbè Dáńmọ̀la ni ìṣẹ̀lẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn ti bẹ̀rẹ̀. | 0 |
Àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà borí àwọn agbésùnmọ̀mí. | 0 |
Bí a bá kí àgbẹ l'ákìíjù; a șebí a fẹ tọrọ ișu jẹ lọwọ wọon ni. | 1 |
Eni sise jàre ise. (òși) | 1 |
Gbogbo nìjà, bí Lágúnjú dá mi mọlę ma mọ ọ lójú lákọláko. | 1 |
Àwọn ènìyàn náà ya bò ó, wọ́n sì pa á. | 0 |
ÀàrẹTinúubú buwọ́lu ṣíṣe ọ̀nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin kìlómítà náà nínú oṣù Kejì ọdún tí a wà yìí. | 0 |
Ẹjọ́ ní ń bá mo-kó-mo-rò wa. | 1 |
Ọdún tó lọ ni ìlú kéde Owólabí gẹ́gẹ́ bí Kábíyèsí tuntun ti ìlú Ìwàyà. | 0 |
B'Ígìn-ín j'àfọn lájęjù, yóó dá ara rẹ lẹbí. | 1 |
A kò gbọdọ̀ fi àkókò ṣòfò bí ìjọba bá ti kéde ìbẹ̀rẹ̀ ọjà títà. | 0 |
Abúni ò tó abẹ̀rín; bẹ́ẹ̀ni abẹ̀rín ò mọ ẹ̀hìn ọ̀la. | 1 |
Àwọn agbófinró kò nawọ́ gán ẹnikẹ́ni fún ikú Babátúndé. | 0 |
Adelé Gómìnà júwe ìwà Olúkàrẹ́ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ìtìjú. | 0 |
Bí etí kò gbọ́ yìnkìn, inú kì í bàjẹ́. | 1 |
B'Írẹlẹ ó ó j'ègbodò, yóó dèé Ìkìrun. | 1 |
Àrùn tí ńṣe aláárùn-ún ò ṣe ẹlẹ́ẹ́ta. | 1 |
Bí orogún ìyá ẹní bá ju ìyá ẹni lọ, ìyá là ń pè é. | 1 |
B'ẹgbẹ ẹni 'ò lùlù mọ, a ì í tún bọọjó. | 1 |
1466. Eku tí yó pa ológìnní ò níí dúró láyé. | 1 |
Ibi tí wọn kò mọ̀ ni wọ́n ti bá ara wọn nígbà tí wọ́n mu ọtí ẹlẹ́rìndòdò náà | 0 |
B'áyé bá ń run (tọ) gún fún ni, a kì í pẹlòmíràn lólòșì. | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.