raw_text
stringlengths
2
128k
thelma okoduwa thelma okoduwa ojiji tí a bí ní oṣù kẹẹ̀ta ọjọ́ kẹẹ̀sán jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó rí yíyàn gẹ́gẹ́bi amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré tí ó dára jùlọ ní ọdún 2012 níbi ayẹyẹ africa movie academy award íṣẹ ìṣe rẹ̀ nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú ìwé ìròhìn encomium thelma fi hàn pé òun wá sí ìdi-iṣẹ́ fíìmù níp...
rachael okonkwo nnenna rachael okonkwo tí a bí ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kaàrún ọdún 1987 tí a mọ̀ sí nkoli nwa nsukka jẹ́ òṣèré fíìmù ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó gbajúmọ̀ jùlọ fún fíìmù nkoli nwa nsukka ìgbé ayé àti iṣẹ́ rẹ̀ rachael okonkwo wá láti ukpata ní agbègbè uzo uwani ti ìpínlẹ̀ enúgu ó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe ní àkó...
angela okorie angela okorie jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ní ọdún 2015 ó gba àmì-ẹ̀ye fún ti amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ city people entertainment awards ó ti kópa nínu àwọn fíìmù tó lé ní ọgọ́rùn-ún ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ okorie jẹ́ ẹ̀kẹẹ̀ta nínu àwọn ọmọ márùn-ún ti òbí rẹ̀ a bi ní ìlú coto...
bimbo manuel bímbọ́ manuel tí wọ́n bí ní ọgbọ̀njọ́ oṣù kẹwàá ọdún 1958 jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé tí wọ́n yàn án fún òṣèré tó peregedé jùlọ nínú amì-ẹ̀yẹ 2013 nollywood movies awards ní ọdún 2013 iṣẹ́ rẹ̀ wọ́n bí bímbọ́ ní ìpínlẹ̀ èkó ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ akàròyìn ní orí ìkanì rédíò ti ìpínlẹ̀ ògùn ogbc tí ó sì tún dara pọ̀ mọ́ ilé-...
ọrọ orúkọ ọ̀rọ̀-orúkọ ní èdè yorùbá ọ̀rọ̀-orúkọ ní ọ̀rọ̀kọrọ̀ tí a lè lò gẹ́gẹ́ bí i olùwà fún ọ̀rọ̀ ìṣe àbọ̀ fún ọ̀rọ̀ ìṣe àti àbọ̀ fún ọ̀rọ̀ atọ́kùn ọ̀rọ̀-orúkọ ni ọ̀rọ̀kọrọ̀ tí ó lè dúró gẹ́gẹ́ bí i ìdánimọ̀ fún enìyàn ẹranko ibìkan tàbí nǹkan bí àpẹẹrẹ ènìyàn àánú ọmọladé pẹ̀lúmi ṣeun abbl ẹranko ajá olońgbò ẹkùn à...
chioma okoye chioma okoye jẹ́ òṣèré ònkọ̀wé àti agbéréjáde tí ó wá láti ìlú aguleri-otu èyí tí ó n bẹ ní ìjọba agbègbè ti ìwọ-òòrùn anámbra orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó ti kópa nínu fíìmù nollywood tó lé ní 100 láti ìgbà tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2002 lẹ́hìn gbígba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àmì-ẹ̀yẹ chioma ti di àwòkọ́ṣe nínu ìdi-iṣẹ́ fíì...
oge okoye oge okoye tí a bí ní 16 oṣù kọkànlá ọdún 1980 jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó wá láti nnewi ní ìpínlẹ̀ anámbra ìlú lọ́ndọ̀nù ni a bí oge okoye sí kí ó tó di pé ó gbèrò láti wá gbé ní ìlú èkó pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀ ó parí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ìlú lọ́ndọ̀nù ṣááju kí ó tó wá sí nàìjíríà nígbàtí ó padà s...
maureen okpoko maureen okpoko jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ní ọdún 2016 ó rí yíyàn fún àmì-ẹ̀yẹ africa movie academy fún ẹ̀ka ti òṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tí ó dára jùlọ iṣẹ́ ìṣe rẹ̀ ní ọdún 2013 ó kópa nínu eré golden egg pẹ̀lú àjọṣepọ̀ justus esiri nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan ti ọdún 2015 ó sọ di mímọ̀ wípé fíìmù du...
ivie okujaye ivie okujaye tí a bí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kaàrún ọdún 1987 jẹ́ òṣèré orílẹ̀-èdè nàìjíríà olùgbéréjáde ònkọ̀wé eré oníjó akọrin àti ajìjàgbara ní ọdún 2009 ó jáwé olúborí níbi kíkópa nínu ètò tẹlifíṣọ̀nù ti amstel malta box office ambo àwọn èyàn maá n pèé ní little genevieve nítorí wípé ó fi ojú jọ òṣè...
oyinkánsọ́lá àbáyọ̀mí nigerian politician olóyè oyinkánsọ́lá àbáyọ̀mí ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí oyínkán ni wọ́n bí lọ́jọ́ kẹfà oṣù kẹta ọdún 1897 tí ó sìn kú lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù kẹta ọdún 1990 jẹ́ ajàjàòmìnira àti aṣègbèfábo ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà òun ni adarí ẹgbẹ́ obìnrin girl guides àti oludásílẹ̀ ẹgbẹ́-òṣèlú àwọn ob...
adebukola oladipupo adébùkọ́lá ọládipúpọ̀ tí a bí ní oṣù kaàrún ọjọ́ 23 ọdún 1994 jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà kan tí ó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe rẹ̀ nínu eré mtv shuga ìgbé ayé rẹ̀ a bí ọládipúpọ̀ ní ìlú lọ́ndọ̀nù ṣùgbọ́n ó ní ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ìlú èkó ó ní àwọn tẹ̀gbọ́ntàbúrò méjì ọládipúpọ̀ lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ be...
ọ̀rọ̀-ìṣe ọ̀rọ̀-ìṣe ni òpómúléró tàbí kókó ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn èdè yorùbá òhun ni ó máa sọ ohun ti olùwà ṣe nínú gbólóhùn àpẹẹrẹ wálé jẹ iṣu jẹ ni ọ̀rọ̀ ìṣe nínú gbólóhùn yìí https//enmwikipediaorg/wiki/verb
kofoworola ademola olorì kòfowórọlá adémọ́lá tí a tún mọ̀ sí kòfowórọlá aina adémọ́lá àti arábìnrin adémọ́lá tí ó gboyè order of the british empire mbe mfr ofr ni wọ́n bí lọ́jọ́ kọkànlélógún oṣù karùn-ún ọdún 1913 tí ó sìn kú lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù karùn-ún ọdún 2002 jẹ́ olùkọ́ ọmọ nàìjíríà òun ni ààrẹ àkókò ti àjọ ẹgb...
peggy ovire nigerian actress peggy ovire enoho tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí peggy jẹ́ olùgbéré-jáde òṣèré àti módẹ́ẹ̀lì ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà òun ni ó gba amì-ẹ̀yẹ fún “òṣèrébìnrin tí ọjọ́ iwájú rẹ̀ dára jùlọ ti english” níbi ayẹyẹ city people entertainment awards ti ọdún 2015 ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ ovire jẹ́ ọmọ ìlú u...
charlotte ọlájùmọ̀kẹ́ ọbasá nigerian socialite and philanthropist charlotte ọlájùmọ̀kẹ́ ọbasá tí orúkọ abilékọ rẹ̀ ń jẹ́ blaize ní wọ́n bí ní ọjọ́ keje oṣù kìíní ọdún 1874 tí ó sìn kú lọ́jọ́ kẹtàlélógún ọdún 1953 jẹ́ gbajúmọ̀ afowóṣàánú ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó jẹ́ ọmọ bíbí pàràkòyí oníṣòwò rb blaize àti ìyàwó rẹ̀ tí ...
kenneth okolie nigerian actor and model kenneth obinna okolie tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹjọ ọdún 1984 jé òṣèré orí-ìtàgé módẹ́ẹ̀lì tí ó sì ti fìgbà kan jẹ́ ọ̀gbẹ́ni nàìjíríà nígbà kan rí látàrí ipa rẹ̀ nínú iṣẹ́ módẹ́ẹ̀lì ní ọdún 2010 o tún gba àmì-ẹ̀yẹ tí ayẹyẹ city people entertainment awards gẹ́gẹ́ bí òṣé...
toks olagundoye ọlátòkunbọ̀ susan ọlasobunmi àbẹ̀kẹ́ ọlágùndóyè tí a bí ní 16 oṣù kẹẹ̀sán ọdún 1975 jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ bi hayley shipton nínu castle àti jackie joyner-kersee nínu eré aláwàdà abc tv kan tí a mọ̀ sí the neighbors ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ a bí ọlátòkunbọ̀ susan olasobunm...
àtòjọ àwọn obìnrin agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá ọmọ nàìjíríà lókè òkun wikimedia list article èyí ni àtòjọ àwọn obìnrin agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá ọmọ nàìjíríà lókè òkun tí wọ́n ti gbà bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gba fún ọkọ̀ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tí nàìjíríà láti ọdún 1991
nkiru sylvanus nigerian actress and politician nkiru sylvanus tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹ́rin ọdún 1982 jẹ́ òṣèré àti olóṣ̀èlú ó tí kópa nínú eré tí ó tó àádójé tí ó sì ti gba àmì-ẹ̀yẹ tí africa magic viewers choice awards fún òṣèré léwájú tí ó peregedé jùlọ nínú ayẹyẹ africa movie academy awards ìbẹ̀rẹ̀ ayé...
mercy akide mercy akide udoh tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1975 ní ìlú port harcourt jẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá obìnrin fún nàìjíríà tẹ́lẹ̀ ìgbà èwe rẹ̀ mercy bẹ̀rẹ̀ sí ní gbá bọ́ọ̀lù nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún márùn-ún pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin seleipiri àti àbúrò rẹ̀ ipali ní pápá erùpẹ̀ ti bundu wate...
destiny etiko destiny etiko tí wọ́n bí lọ́jọ́ kejìlá oṣù kẹjọ ọdún 1989 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣẹ̀rẹ́bìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí ó ti gba àmìn ẹ̀yẹ òṣẹ̀rẹ́bìnrin tí ó ń dàgbà jù lọ ní àgbàlá sinimá àgbéléwò lédè òyìnbó ti city people movie award for most promising actress english ní city people entertainment awards lọ́dún...
sani musa danja nigerian film actor sani musa abdullahi tí wọ́n tún mọ̀ sí sani danja tàbí danja tí wọ́n bí ní ogúnjọ́ oṣù kẹrin ọdún 1973 jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé olùgbéré-jáde alájótà àti olórin ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó kópa nínú àwùjọ kannywood àti nollywood ní oṣù kẹ́rin ọdún 2018 tí ó jẹ́ etsu nupe yahaya abubaka wé l...
aisha yesufu aisha yusufu tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kejìlá ọdún 1973 ní ipinle kano jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ ọ́ ọmọ ènìyàn ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti alábàṣiṣẹ́pọ̀ ẹgbẹ́ tí ó ń polongo fún ìdápadà àwọn ọmọ obìnrin wa bring back our girls movement èyí tí í ṣe ẹgbẹ́ alágbàwí tí ó ń pe ìjọba sí àkíyèsi lórí í àwọn ọmọbìnrin tí ó l...
wùnmí mosákú
abiodun koya abiodun abi koya a bí ní ọjọ́ kejìlélólógún oṣu kejìlá ọdún 1980 ó jẹ́ ọmọ abínibí ìlú nàijíríà ó jẹ́ olórin aláìlẹ́gbẹ́ akọrin akewi òṣèré ònkọ̀wé ati onínúrere tí ó tẹ̀dó sí ìlú amẹrika ó jẹ́ ọkán nínú awọ́n ọ̀jọ̀gbọ́n akọrin tín se abínibí ìlú áfíríkà tó gba ẹ̀kọ́ orin aláìlẹ́gbẹ́ wọ́n pèé ni akọrin àwọ...
gloria bámilóyè nigerian dramatist film actress producer and director gloria olúṣọlá bámilóyè tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrin oṣù kejì ọdún 1964 jẹ́ gbajúmọ̀ olùdarí olóòtú òṣerébìnri sinimá àgbéléwò àti ònítíátà ọmọ bíbí ìlú iléṣà ní ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun lórílẹ̀-èdè nàìjíríà she is a co-founder of mount zion drama ministry ìgbésí ay...
juliana olayode juliana olúwatóbilọ́ba ọláyọdé tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ toyo baby nípa ipa tí ó kó nínú eré jenifa's diary gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá-ìtàn tóyọ̀sí jẹ́ òṣèrébìnri sinimá àgbéléwò àti ti tẹlifíṣàn ó tún jẹ́ aṣègbè fún ìbálòpọ̀-ẹ̀tọ́ ọmọ nàìjíríà ó tún jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká nípa àtakò rẹ̀ sí ìbálòpọ̀ lọ́kọláya láìṣe ìgbéyà...
yakubu muhammed nigerian actor and singer yakubu mohammed tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kẹ́ta ọdún 1973 jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé olùgbéré-jáde adarí eré olórin àti olùkọ̀tàn ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó tún jẹ́ aṣojú àti olùpolówó ọjà fún ilé-iṣẹ́ ìbáraẹni sòrò ti globacom ó tún jẹ́ aṣojú fún àjọ sdgs ó sì tún fìgbà ka...
sharon ooja sharon ooja tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹfà oṣù kẹrin ọdún 1991 jẹ́ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò ọmọ nàìjíríà ó di gbajúmọ̀ òṣèré lẹ́yìn tó kópa nínú eré kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní skinny girl in transit nínú èyí tí ó kópa ẹ̀dá-ìtàn ṣaléwá ìgbésí-ayé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ sharon jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ benue ṣùgbọ́n tí wọ́n b...
idiat ṣóbándé idiat ṣóbándé jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò èdè yorùbá ọmọ nàìjíríà wọ́n yàn án fún àmìn ẹ̀yẹ ti òṣèrébìnrin tó dára jù ní ìpò olú-ẹ̀dá-ìtàn africa movie academy award for best actress in a leading role lọ́dún 2011 fún ipa tí ó kó nínú sinimá àgbéléwò aramotu iṣẹ́ rẹ̀ idiat jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀...
adetola juyitan adetola juyitan jẹ́ oníṣòwò àwùjo tí orílẹ̀-èdè nàijíríà alákòso ti glitz group of companies ati àare fún junior chamber international ní odún 2019 ìgbésí ayé juyitan jẹ́ omo ìpínlẹ̀ òndó ṣùgbọ́n a bíi ni ìlú èkó ó jẹ́ àkọ́bí nínú àwọn ọmọ márun o kẹ́kọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìṣirò láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti ìpí...
lola margaret lola margaret tí orúkọ àbísọ rẹ̀ gan-an ń jẹ́ lola margaret oladipupo jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ nàìjíríà ó di gbajúmọ̀ lẹ́yìn tí ó kópa olú-ẹ̀dá-ìtàn nínú eré tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ bísọ́lá aláàánú ìgbà èwe àti ìkẹ́kọ̀ọ́ wọ́n bí lọlá ní iléṣà ní a city located in ìpínlẹ̀ ...
nuella njubigbo nuella njubigbo jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin oǹkọ̀tàn sinimá àgbéléwò arẹwà àti olóòtú tẹlifíṣàn ọmọ nàìjíríà ó dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ eré tíátà lọ́dún 1999 wọ́n sìn yàn án fún ìdíje àmìn ẹ̀yẹ 2012 nollywood movies awardsfún oṣèré tó ń dàgbà jù lọ lọ́dún 2012 ìgbà èwe àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ wọ́n bí nuella njubigbo lọ́jọ́...
timini egbuson timini egbuson tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹfà ọdún 1987 jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé olùgbéré-jáde àti olùàiṣẹ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀ wọ́n bí timini ní ìpínlẹ̀ bayelsa ó jẹ́ àbúrò fún gbajú-gbajà òṣèré dakore egbuson àkàndé ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti greenspring montessori the afro schoo...
bose ogulu bose ogulu jẹ́ ọ̀mọ̀wé oníṣòwò obìnrin àti aláákòso ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ogulu ni aláákòso burna boy's èyí tí í ṣe iṣẹ́ orin kíkọ ọmọ rẹ ìdí nì yí tí wọ́n tún fi mọ̀ ọ́ sí mama burna ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ ogulu jẹ́ ọmọ bíbí inú benson idonije ẹnití ń ṣe ìlú mọ̀ ọ́ ká olórin ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà idojije ni alá...
tóbilọ́ba àjàyí nigerian female lawyer and disability rights activist tóbilọ́ba àjàyí jẹ́ agbẹjọ́rò ajàfẹ́tọ̀ọ́ abarapá ọmọ nàìjíríà òun náà jẹ́ abarapá ènìyàn fúnrarẹ̀ ó gba àmìn ẹ̀yẹ mandela washington fellowship lọ́dun 2016 ó kàwé gbàwé ẹ̀rí dìgírì kejì nínú ìmọ̀ òfin international law láti university of hertfordshi...
uche jombo nigerian actor and film director uche jombo rodriguez tí wọ́n bí lọ́jọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1979 december 28 1979 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin àti oǹkọ̀tàn àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ nàìjíríà ìgbésí ayé rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wọ́n bí uche jombo sí ìlú abiriba ní ìpínlẹ̀ abia lórílẹ̀ èdè nàìjíríà lọ́jọ́...
dorcas shola-fapson nigerian actress dorcas ṣọlá fapson jẹ́ òṣèrébìnrin àti atọ́kùn tí ó gbajúmọ̀ fún ipa tó kó nínú ètò kan tí wọ́n pè ní ṣúgà lórí ìkànnì mtv's as ‘sophie’ lọ́dún 2020 ó padà sí ètò ṣúgà náà lórí ìkànnì mtv láti sọ̀rọ̀ lórí àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà pẹ̀lú àwọn òṣèré tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ pọ̀ káàkiri ilẹ̀ adúláwọ...
adetoun ogunsheye felicial adetoun omolara ogunseye ti o je omobibi inu banjo ni a bi ni ojo karun un osu kejila odun 1926 adetoun ni ojogbon obinrin akoko ni orile-ede nàìjíríà o je ojogbon onimo ijinle lori ile ikowe pamo si ka library and information science ni ile-eko giga ti yunifasiti ilu ibadan ibere aye re ati ...
saidat adégòké nigerian footballer saidat adégòké tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsàn-án ọdún 1985 24 september 1985 ní ìlú ìlọrin ìpínlẹ̀ kwara lórílẹ̀ èdè nàìjíríà jẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá obìnrin iṣẹ́ rẹ̀ bí agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá obìnrin ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbá bọ́ọ̀lù jẹun fún ìkọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá tí r...
salma phillips salma phillips jẹ́ atọ́kùn ètò tẹlifíṣàn oǹkọ̀wé àti olóòtú ètò láti ìlà-oòrùn nàìjíríà àpèjá orúkọ rẹ̀ ni ummu salma nabila phillips ó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí atọ́kùn ètò lórí àwọn ìkànnì tẹlifíṣàn lápá ìlà-oòrùn nàìjíríàshe is popularly known as the face of northern televisionó kàwé gbàwé ẹri dípólómà láti ...
sarah michael sarah michael tí wọ́n bí lọ́jọ́ kejìlélógún ọdún 1999 22 july 1990 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá obìnrin ọmọ nàìjíríà ó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù-sáwọ̀n ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá obìnrin tí nàìjíríà ó sìn wà lára àwọn ìkọ̀ obìnrin agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá tí ìdíje bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá olympics lọ́dún àti ìdí...
adunni bankole adunni bankole oṣù kẹ́tá ọdún 1959 - ọjọ́ kẹ́tá oṣu kini ọdún 2015 jẹ ólùdarí àwùjọ ni nàijíríà atí óbinrín oníṣòwò ó jẹ́ yèyé mokun tí ijọ́bá owu ìlú kan ni abẹ́òkúta olú-ìlú ti ìpínlẹ̀ ògùn gúusù ìwọ̀-óòrùn nàijíríà ìgbésí ayé a bi ní oṣù kẹ́tá ọdún 1959 ni owu ti abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ ògùn gúusù ìwọ̀-ó...
abíọ́lá ọdẹ́jídé nigerian academic abíọ́lá ọdẹ́jídé jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n-ágbà nínú ìmọ̀ iṣẹ́-ọ̀nà èdè àti lítíréṣọ̀ láti yunifásítì ìbàdàn university of ibadan ó ti kọ́kọ́ jẹ igbákejì ọ̀gá yunifásítì lábala ètò ẹ̀kọ́ ní university of ibadan òun sìn ni obìnrin àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ dé irú ipò bẹ́ẹ̀ lọ́mọ ọdún méjìdínlọ́gọ́ta ìgbà...
dakore egbuson àkàndé
abibatu mogaji business magnate olóyè abibatu mogaji mfr oon tí wọ́n bí ní ọdún 1917 tí ó sì kú ni oṣù kẹfà ọdún 2013 october 1917june 2013 jẹ́ =pàràkòyí oníṣòwò ọmọ nàìjíríà àti ìyálọ̀jà yányán gbogbo nàìjíríà ìgbà èwe rẹ̀ wọ́n bí àbíbátù mọ́gàjí lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹwàá ọdún 1916 ní ìpínlẹ̀ èkó lórílẹ̀ èdè nàìj...
esther agbájé esther agbájé jẹ́ ọmọ ọdún márùnlélọ́gbọ̀n òṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà àti amẹ́ríkà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn sí ilé-ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin orílẹ̀ èdè amẹ́ríkà láti ṣojú ìpínlẹ̀ minnesota bàbá rẹ̀ jẹ́ àlùfáà ìjọ episcopal ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà tí ó fi amẹ́ríkà ṣe ìbùgbé ìyá rẹ̀ jẹ́ afowóṣàánú tí ó kọ́ ìbùg...
toni payne american-nigerian footballer toni payne tí orúkọ àbísọ rẹ̀ gan jẹ́ antionette oyèdúpẹ́ payne tí wọ́n bí lọ́dún 1995 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá ọmọ nàìjíríà àti amẹ́ríkà ó máa ń gba bọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ agbáyòsáwọ̀n fún ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá obìnrin sevilla lórílẹ̀-èdè italy ìgbésí-ayé rẹ̀ wọ́n bí toni payne ní...
abidemi sanusi author abídèmí sànúsí jẹ́ gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́ká oǹkọ̀wé ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí wọ́n bí sí ìpínlẹ̀ èkó ìgbésí-ayé rẹ̀ wọ́n bí abídèmí sànúsí sí ìlú èkó lórílẹ̀-èdè nàìjíríà ó kàwé lórílẹ̀ èdè england ní leeds university abídèmí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ ènìyàn tí ó sìn ṣiṣẹ́ ìbánimójútó ìkànn...
turai yar'adua first lady of nigeria turai yar'adua tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù keje ọdún 195726 july 1957 jẹ́ opó sí ààrẹ-àná tí orílẹ̀-èdè nàìjíríà ẹni tí ó tún jẹ́ gómìnà-àná ìpínlẹ̀ kàtsínà umaru musa yar'adua òun ní obìnrin àkọ́kọ́ orílẹ̀-èdè nàìjíríà lọ́dún 2007 títí ọkọ rẹ̀ ààrẹ-àná yar'adua fi ta tér...
àbí ọlájùwọ́n àbí ọlájùwọ́n tí apèjá orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ alon abísọ́lá arisicate àjọkẹ́ ọlájùwọ́n tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹfà oṣù keje ọdún 1988 jẹ́ akọ́ni àti agbábọ́ọ̀lù-ajùsáwọ̀n ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà àti amẹ́ríkà ó jẹ́ ọmọbìnrin gbajúmọ̀ agbábọ́ọ̀lù-ajùsáwọ̀n hakeem olajuwon gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ abísọ́là ọlájù...
bíńtà bello fatima bíńtà bello tí ó jẹ́ olùkọ́ kọmíṣánnà nígbà kan tí ó sìn jẹ́ igbákejì ọlọ́pàá deputy minority whip ilé igbimọ̀ aṣojú-ṣòfin nigerian house of representatives tẹ́lẹ̀ tí ó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò kaltungo/shongom ti ìpínlẹ̀ gombe tẹ́lẹ̀ jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèlú-bìnrin ọmọ nàìjíríà ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú peoples demo...
ade hassan ade hassan adétọ́lá kúnlé-hassan tí a mọ̀ sí ade hassan mbe ọjọ́ ìbí april 1984 ó jẹ́ onísòwò obìnrin láti ìlú òyìnbó tí ó dá nubian skin sílẹ́ ni 2004 ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀ wọ́n bí hassan ní oṣù igbe ní ọdún 1984 a tọ́ ọ díẹ́ ní nàìjíríà ó sì ń sọ yorùbá àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì jẹ́ onísòwò ó lọ ilé ìwé gíga ní duke ...
amina oyiza bello amina oyiza bello tí wọ́n bí lọ́jọ́ kejì oṣù kẹrin ọdún 2 april 1978 jẹ́ agbẹjọ́rò afowóṣàánú àti ìyàwó gómìnà ìpínlẹ̀ kogi yahaya bello kogi state governor òun ni alága àti olùdásílẹ̀ fairplus international hayat foundation bẹ́ẹ̀ náà lọ jẹ́ pàràkòyí oníṣòwò amina kàwé gboyè nínú ìmọ̀ òfin láti obafem...
àjàkálẹ̀-àrùn covid-9 ní gàbọ̀n
àjàkálẹ̀ àrùn covid-9 ní orílẹ̀-èdè mozambique
àjàkálẹ̀-àrùn covid-9 ní sámbíà
adama ndiaye adama ndiaye tàbí adama amanda ndiaye tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí adama paris tí ó tún jẹ́ orúkọ ilé-iṣẹ́ rẹ̀ ni a bí ní ìlú kinshasa jẹ́ aránṣọ ìgbà-lódé ọmọ orílẹ̀-èdè senegal àwọn aṣọ tí ó ń rán ni ó ma ń kó wọlé láti orílẹ̀-èdè morocco tí a sì lè rí àwọn aṣọ rẹ̀ rà ní àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé gbogbo bí parag...
aduke alakija jayéọlá àdùkẹ́ alákijà tí wọ́n bí lóṣù kẹta ọdún 1921tí ó sìn kú lóṣù kẹta ọdún 2016 march 1921 march 2016 jẹ́ gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́ká ọmọ nàìjíríà tí ó fìgbà kan jẹ́ òṣìṣẹ́ alámọ́jútó amọ̀fin àti aṣojú orílẹ̀-èdè nàìjíríà ní orílẹ̀-èdè sweden tẹ́lẹ̀ láti ọdún 1984 sí 1987 bẹ́ẹ̀ náà ló fìgbà jẹ́ ààrẹ àwọn ẹgb...
doris simeon doris simeon jẹ́ òṣèré fíìmù èdè gẹ̀ẹ́sì àti yorùbá ni orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ edo ni orílẹ̀ èdè nàìjíríà ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ wọ́n bí simeon si ìpínlẹ̀ èkó lórílẹ̀ èdè nàìjíríà ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí peft institute níbi tí ó ti gboyè nínú ìmò production management iṣẹ́ ó kópa ...
sola david-borha olusola adejoke david-borha jẹ́ olùdarí àgbà fún ilé ìfowópámọ́ standard bank tí ilẹ̀ áfríkà láti ọdún 2017 ó jẹ́ olùdarí àgbà fún stanbic ibtc holdings títí di oṣù kìíní ọdún 2017 ò jẹ́ adarí fún ẹgbẹ́ nigerian economic summit group láti ọdún 2015 ó darapọ̀ mọ́ àwọn adarí ibtc ní oṣù keje ọdún 1994 ó ...
smaranda olarinde smaranda olarinde jẹ́ olùkọ́ nínú ìmò òfin ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà òun sì olórí ẹgbẹ́ nigerian association of law teachers àti vc fún ilé ẹ̀kọ́ gíga tí afé babalolá university ní ọdún 1995 ó ṣiṣẹ́ pẹlu unicef iṣẹ́ arábìnrin olarinde tí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi olùkọ́ ìmò òfin fún ọdún tí ó tí lé ní ọgbọ́n ó jẹ...
somkele iyamah somkele iyamah idhalama jẹ́ òṣèré àti mọ́dẹ́lì ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó gbajúmọ̀ fún ipá tí ó kó nínú àwọn eré bíi 93 days the wedding party the arbitration àti gidi up ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ wọ́n bí somkele sí ìlú ika ní ìpínlẹ̀ delta àwọn òbí rẹ̀ ni andrew àti onyi iyamah tí wọn sì jẹ́ ọmọ ìl...
sophie oluwole sophie bosede oluwole bíi ni ọjọ́ kejìlá oṣù karùn-ún ọdún 1935 tí orúkọ ìnagi rẹ̀ jẹ́ iyanifa jẹ́ onímọ̀ ìjìnlè áfríkà òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó má gboyè jáde nínú ìmò ìjìnlè ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà ayé àti iṣẹ́ rẹ̀ wọ́n bí sophie ní ọjọ́ kejìlá oṣù karùn-ún ọdún 1935 ó sì jẹ́ ọmọ ìlú edo ó lọ sí ilé ẹ...
stella chinyelu okoli stella chineyelu okoli bíi ní ọdún 1944 jẹ́ onísègùn àti oníṣòwò ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà òun ní olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ emzor pharmaceutical ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ wọ́n bí stella sí ìlú kano sí ìdílé felix ebelechukwu àti margaret modebelu tí wọ́n sì jẹ́ ọmọ ìran nnewi ní ìpínlẹ̀ anámbra ó bẹ...
stella thomas stella jane thomas bíi ní ọdún 1906 jẹ́ agbejọ́rọ̀ ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà òun ní obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ adájọ́ ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ wọ́n bí stella ní ọdún 1906 sí ìlú èkó ó sì jẹ ọmọ peter john claudius thomas bàbá rẹ̀ ní ọmọ ilẹ̀ áfríkà àkọ́kọ́ tí ó má jẹ́ adarí fún l...
kyle larson kyle miyata larson bi ni sakaramento california on july 31 1992 jẹ ẹya american ọjọgbọn isare ti japanese ayalu ti o competes ninu awọn nascar cup series larson darapo chip ganassi racing egbe lati 2014 akoko to awọn ibere ti 2020 akoko pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ nọmba 42 ni yi egbe ti o gba mẹsan ije victories o ti ...
margaret etim nigerian sprinter margaret etim tí wọ́n bí lọ́jọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 1992 jẹ́ asáré ọmọ nàìjíríà tí ó gbajúmọ̀ nínú eré ìwọ̀n irínwó mítà 400 metres ó gba àmìn-ẹ̀yẹ lọ́dún 2010 nínú ìdíje àgbáyé àwọn ọmọdé yàtọ̀ sí àwọn àmìn-ẹ̀yẹ tí ó dìjọ gbà pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ̀ nínú ìdíje eré gbagigbagi 4...
adéjọkẹ́ làsísì adéjọkẹ́ làsísì jẹ́ gbajúmọ̀ aránṣọ aṣègbè ìmọ́tótó àyíká àti oníṣẹ́-ọ̀nà ọmọ nàìjíríà òun ni olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ planet 3r tí wọ́n máa ń tún àlòkù ike àti di ohun èlò tuntun mìíràn lọ́dún 2020 adéjọkẹ́ gba àmìn-ẹ̀yẹ ti msme of the year award an event which was well attended by state governors and minis...
jimmie johnson jimmie kenneth johnson bi ni el cajon california september 17 1975 jẹ ẹya american ọjọgbọn ọkọ ayọkẹlẹ isare johnson dun ninu nascar cup series lati akoko 2002 si 2020 pẹlu ẹgbẹ hendrick motorsports ni yi jara o gba meje oyè 2006 2007 2008 2009 2010 2013 ati 2016 ati equaled awọn igbasilẹ ti richard pett...
esther igbekele esther igbekele jẹ́ gbajúmọ̀ olórin ẹ̀sìn ọmọ-lẹ́yìn-jésù ọmọ bíbí ìlú ifọ́n ìjọba ìbílẹ̀ ọsẹ́ ní ìpínlẹ̀ òndó lórílẹ̀-èdè nàìjíríà ó jẹ́ ọmọ bíbí òjíṣẹ́ ọlọ́run olúwafẹ́mi ìgbẹ́kẹ̀lé ṣùgbọ́n tí ó gbé lọ́dọ̀ òjíṣẹ́ ọlọ́run mìíràn tí orúkọ wọn ń jẹ́ àpọ́sítélì j a bánkọ́lé ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin kíkọ lọ́dún ...
níyì akínmọláyàn níyì akínmọláyàn jẹ́ olùgbéré-jáde adarí eré ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó di ìlú-mòọ́ká látàrí eré kan tí ó darí rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ the wedding party 2 ní èyí tí àwọn òṣèré bíi banky wellington adesua etomi àti enyinna nwigwe ti kópa tó lààmì-laaka ní ọdún 2016 òun ni olùdásílẹ̀ àti adarí ilé-iṣẹ́ an...
níyì akímọláyàn
ọláídé ọláògún ọláídé ọláògún tí a tún mọ̀ síọláídé omololá ọláògún emmanuel tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù kẹfà ọdún 1986july 9 1986 jẹ́ òṣèrébìnrin afẹ́wà-ṣojú àti atọ́kùn ètò ọmọ nàìjíríà ó ti fìgbà kan jẹ́ afẹ́wà-ṣojú oṣẹ lux ìgbésí-ayé rẹ̀ wọ́n bí ọláídé ọláògún ní ìlú èkó lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù kẹfà ọdún 1986 ó kàwé...
ọlábísí afọlábí nigerian sprinter ọlábísí afọlábí tí wọ́n bí lọ́jọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1975 31 october 1975 jẹ́ gbajúmọ̀ eléré ìdárayá ẹlẹ́sẹ̀-ehoro nígbà kan rí tí ó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú ìlọrin ní ìpínlẹ̀ kwara ó gbajúmọ̀ nípa eré sísá oníwọ̀n irínwó mítà ó wà lára ìkọ̀ ẹgbẹ́ eléré tí wọ́n gba àmìn-ẹ̀yẹ bàbà n...
abímbólá adelakun abímbọ́lá adélakùn abímbọ́lá àdùnní adélakùn ọjọ́ ìbí 15 septemberọdún ó jẹ́ ọ̀nkọ̀wé nàìjíríà ìgbésí ayé a bíi ní ìlú ìbàdàn southwest nàìjírià ó kẹ́kọ̀ọ́ ní university of ibadan níbití ó tí jáde pẹlú bachelor's degree àti master of arts degree in communication and language artsó jáde pẹlú phd nínú i...
ejiro amos tafiri nigeria fashion designer ejiro amos tafiri jẹ́ gbajúmọ̀ aránṣọ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà òun ni olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ aránṣọ e a t tí ó dá sílẹ̀ láti máa ránṣọ ìgbàlódé àwọn obìnrin ìgbésí ayé àti iṣẹ́ rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ejiro jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ delta ṣùgbọ́n tí wọ́n bí sí ìpínlẹ̀ èkó láti kékeré lọ́mọdún...
scott dixon scott ronald dixon ti a bi ni brisbane australia oṣu keje ọjọ 22 ọdun 1980 ti a pe ni iceman jẹ onija ọkọ ayọkẹlẹ ọjọgbọn ti ilu niu silandii ti o ngba lọwọlọwọ ni indycar series oun ni aṣaju ti awọn akoko 2003 2008 2013 2015 2018 ati 2020 pẹlu ẹgbẹ chip ganassi racing
susan peter's òṣèrébìnrin ọmọ nàìjíríà susan peters tí wọ́n bí lọ́gbọ̀n ọjọ́ oṣù karùn-ún ọdún 1989 30 may 1980 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ọmọ nàìjíríà tí ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmìn-ẹ̀yẹ tí ó ju àádọ́ta lọ ó jẹ́ gbajúmọ̀ atọ́kùn orí tẹlifíṣàn afoge-ṣojú atúnnúleṣe àti aṣerunlóge láìpẹ́ yìí ó gbàmìn ẹ̀yẹ òṣèrébìnrin tó dára...
jùmọ̀kẹ́ akíndélé nigerian lawyer jumoke akindele jẹ́ agbẹjọ́rò ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà àti obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ agbẹnusọ nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ òndó ìgbésí-ayé rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wọ́n bí jùmọ̀kẹ́ ní ìlú òkìtì-pupa ní ìpínlẹ̀ òndó lápá ìwọ̀ oòrùn nàìjíríà ó kàwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní st john’s primary school ní òkìtì-pup...
sunkanmi olasunkanmi rehanat alonge bíi ni ọjọ́ kejì oṣù kẹfà ọdún 1988 tí àwọn èèyàn mọ̀ sí sunkanmi jẹ́ olórin ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà sunkanmi gbajúmọ̀ ni ọdún 2015 fún orin for body tí ó gbé jáde ó wà pẹ̀lú ẹgbẹ́ olórin hit the ground records sunkanmi lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí olabisi onabanjo university níbi tí ó tí ...
taiwo olayemi elufioye taiwo olayemi elufioye jẹ́ onímọ̀ ògùn ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó si ṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ pẹ̀lú ilé ẹ̀kọ́ gíga tí university of ibadan ó jẹ́ ìkan láàrin àwọn onímọ̀ ni ilé ẹ̀kọ́ gíga tí university of the sciences ní philadelphia ó gbà owó ńlá láti ọ̀dọ̀ macarthur foundation láti lè ṣe oríṣiríṣi àyẹ...
tejumade alakija tẹjúmádé alákijà bíi ni ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 1925 jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba ni orílẹ̀ èdè nàìjíríà òun sì ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó má jẹ́ olórí fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ bàbá tẹjúmádé jẹ́ ọba ní ìlú ifẹ̀ ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí oxford university ó sì gboyè jáde gẹ́gẹ́ bí olùkó ó ...
temi balogun temi lola balogun tí orúkọ inagi rẹ̀ jẹ́ taymib jẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà òun sì ní olùgbé sílẹ̀ ètò skinny girl in transit ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ queen's college ni ìlú èkó ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí nottingham trent university òun àti àbúrò rẹ̀ jọ kọ orin soyinka's afro ní ọdún 2009 balogun di...
titi oyinsan títí adélagún oyinsáǹ bíi ni ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹjọ ọdún 1985 tí orúkọ inagi rẹ jẹ titithedynamite jẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ni orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó jẹ́ atọ́kun fún ètò wake up nàìjíríà ní ilé iṣẹ́ tvc òun sì ní atọkun ètò wordsmith èyí tí wọn gbé kalẹ̀ fún àwọn ọmọdé kí wọ́n bá lè mọ èdè gẹ̀ẹ́sì dáadáa ìbẹ̀rẹ̀ pẹ...
bọ́lá agbájé bọ́lá agbájé tí wọ́n bí lọ́dún 1981 jẹ́ gbajúmọ̀ oǹkọ̀wé eré-oníṣe ọmọ nàìjíríà ìlú london ni àwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ nàìjíríà bí i sí iṣẹ́ rẹ̀ eré-oníṣe àkọ́kọ́ tí agbájé kọ ni gone too far wọ́n gbé e jáde ní royal court theatre ní london níbi tí ó ti gba àmìn-ẹ̀yẹ laurence olivierfún àrà ọ̀tọ̀ iṣẹ́ ...
abimbola alao abimbola alao tí a tún mọ̀ sí abi alao ó jẹ́ olùsọ̀tàn òǹkòwé atúmọ̀ ìwé àwọn ọmọ kékeré àti olùwídìí ìgbésí ayé abí abímbólá sí ìlú ibadan nàìjírià ó kẹ́kọ̀ọ́ ní university of ibadan nigeria níbití ó tí gba ba hon classics ní 1988 àti ma classics ní 1991 ó tún kẹ́kọ̀ọ́ pgce àti ma ní creative writing ní ...
mayowa adegbile máyọ̀wá adégbilé tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹ̀sán ọdún 1986 jẹ́ gbajúmọ̀ afowóṣàánú ọmọ nàìjíríà ó wà lára àwọn ọmọ nàìjíríà mẹ́ta tí wọ́n yàn mọ́ àwọn akẹgbẹ́ wọn ní áfíríkà fún àṣeyọrí ìdíje google lọ́dún 2014 máyọ̀wá kọ́kọ́ ló ìkànnì youtube láti ṣe ìkówójọ fún ilé-iṣẹ́ afowóṣàánú rẹ̀ ashake found...
enyinna nwigwe nigerian actor enyinna nwigwe jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé ati olùgbéré-jáde ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà òun ni ó gbé àwọn aládùn bíi the wedding party black november àti black gold jáde ìbẹ̀rẹ̀ ayé ati ẹ̀kọ́ rẹ̀ wọ́n tó nwigwe ní ìlú ngor okpala ní ìpínlẹ̀ imo ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ilé-ẹ̀kọ́ fásì...
titilope gbemisola akosa titilope gbemisola akosa tí gbogbo ènìyàn mọ́ sì titolope akosa jẹ agbejọ́rọ̀ ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà òun ni olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ titi akosa co ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà ní ọdún 2015 ó jẹ́ agbenuso fún àwọn obìnrin lórí ètò tí àkọlé rẹ jẹ́ towards a gender responsive green climate fund in africa ní ...
titilope sonuga titilope sonuga ẹni tí àwọn èèyàn mọ sì titi sonuga je akéwì enginíà àti òṣèré ni orílẹ̀ èdè nàìjíríà wọ́n bíi sì ìlú èkó ó sì lọ sí orílẹ̀ èdè canada nígbà tí ó pè ọmọ ọdún mẹ́tàlá ó siṣẹ́ fún ọdún márùn-ún gẹ́gẹ́ bíi enginíà ní ọdún 2011 ó gbà àmì ẹ̀yẹ onkọ̀we tuntun láti ọ̀dọ̀ canadian authors associ...
tobiloba ajayi tobiloba ajayi jẹ́ agbejọ́rọ̀ ni orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó ní àrùn cerebral palsy ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ ajayi ni ọmọ kẹrin láàárín àwọn ọmọ márùn-ún tí àwọn òbí rẹ bí àwọn òbí rẹ kò kọ́kọ́ fẹ́ ran lọ sí ilé ẹ̀kọ́ nítorí àìlera tí ó ní àìlera yí kò fun ni àǹfààní láti lè jókòó dúró tàbí rìn ó bẹ̀rẹ...
wunmi mosaku wunmi mosaku bíi ni ọdún 1986 jẹ́ òṣèré àti olórin ni orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó gbajúmọ̀ fún ipa joy tí ó kó nínú eré moses jones 2009 àti holly lawson nínú eré vera2011 ó gba àmì ẹ̀yẹ best supporting actress láti ọ̀dọ̀ bafta tv award fún ipa gloria taylor tí ó kó nínú eré damilola our loved boy ni ọdún 2016 n...
chacha eke charity chinonso eke tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí chacha eke faani tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù keje ọdún 1987 jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ ìpínlẹ̀ ebonyi lórílẹ̀-èdè nàìjíríà ó di gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́ká nígbà tó kópa nínú sinimá kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ the end is near lọ́dún 2012 ìgbésí ayé rẹ̀ ní èwe ìkẹ́kọ̀ọ́ àti i...
yvonne orji yvonne anuli orji bíi ni ọjọ́ kejì oṣù kejìlá ọdún 1983 jẹ́ òṣèré ni orílẹ̀ èdè nàìjíríà àti amẹ́ríkà ó gbajúmọ̀ fún ipá tí ó kó nínú eré insecure ní ọdún 2016 èyí tí ó jé kí wọn yàán fún àmì ẹ̀yẹ tí primetime emmy award àti naacp image awards ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ wọ́n bí orji ni ọjọ́ kejì oṣù k...
yetunde barnabas yetunde barnabas jẹ́ òṣèré mọ́dẹ́lì àti olùgbé jáde eré fíìmù àgbéléwò ni orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó gbajúmọ̀ fún igbá orókè tí ó gbé nínú ìdíje obìnrin tí ó rẹwà jùlọ ní ìpínlẹ̀ abuja ní ọdún 2017 àti miss tourism ni ọdún 2019 ó kó ipa miss pepeiye nínú eré papa ajasco and company ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀...
sandra aguebor sandra aguebor jẹ́ mẹ̀kó ni orílẹ̀ èdè nàìjíríà òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó má se iṣẹ́ mẹ̀kó ní nàìjíríà òun ní olùdásílẹ̀ lady mechanic initiative tí ó gbé kalẹ̀ láti rán àwọn obìnrin tí ó lè tọ́jú ara wọn ó kọ́ wọn ní iṣẹ́ mẹ̀kó aguebor sọ wípé ó nira fún obìnrin láti dì mẹ̀kó ní ọdún 2015 wọn ṣe eré n...
shade okoya fọláṣadé noimat ọkọ́ya bíi ni ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 1977 jẹ́ aláàkóso fún ilé-iṣẹ́ eleganza group èyí tí okọ rẹ̀ gbé kalẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ wọ́n bí folashade ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù kẹrin ọdún 1977 sí ìdílé àlhájì tajú àti àlhájà nimosat adeleye sí ìlú èkó ó jẹ́ mùsùlùmí ó sì wá l...
sharon ikeazor sharon ikeazor bíi ni ọjọ́ kejìdínlógbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1961 jẹ́ agbejọ́rọ̀ àti olóṣèlú ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà óun ni akọ̀wé tẹ́lẹ̀ fún pension transitional arrangement directorate ní oṣù kẹjọ ọdún 2019 ó di mínísítà lórí ọ̀rọ̀ àyíká ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ sharon bẹ̀rẹ̀ è...
bọ́sẹ̀ ọ̀kẹ́owó bọ́sẹ̀ ọ̀kẹ́owó tí wọ́n bí lọ́dún 1994 jẹ́ gbajúmọ̀ àkàndá abarapá ọmọbìnrin ayàwòrán tí kò lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó ń ṣiṣẹ́ ọ̀nà lárà ọ̀tọ̀ ó jẹ́ abarapá ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ èkìtì tí ó máa ń rìn pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìjókòó-ìrìnnàwheelchair ìgbà èwe àti ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé bọ́sẹ̀ ló ti ní ìṣòro ...