Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń jókòó sórí tébùrù pọ̀nmọ́ obìnrin náà. | 0 |
Ó ní àìmọye àwọn ọmọbìnrin ni àwọn bá nínú ilé nígbà tí àwọn dé ìlú Kánò. | 0 |
Àyọ̀ká ti gba ìyọ̀nǹda lẹ́nu iṣẹ́, ó kú kí òun náà máa kọ ọmọ ni ohun tó mọ̀. | 0 |
Ó ní ẹni náà fún àwọn ní ọtí ẹlérìndòdò tí wọ́n ti fi oògùn orun sínú rẹ̀. | 0 |
Akéde ò jẹ iyán gbígbóná. | 1 |
Mo kó sáàárín obìnrin náà àti ọmọ mi láti là wọ́n. | 0 |
Bigbà ba já tonígbà níí dà. | 1 |
Wọ́n jí Ayọ̀mídé gbé ní agbègbè ààfin Ọ̀jọ̀mú nílùú Ọ̀wọ̀. | 0 |
Ọjọ́bọ ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tó fi ojú kan ara wọn. | 0 |
Atiku ní ìjọba ti kéde iye tí àwọn máa ná lórí ọ̀nà náà. | 0 |
Afúnijẹ kì í fúnni í tà. | 1 |
Ajá tòun tìrù e. | 1 |
Ọ̀gá ọlọ́pàá ṣàlàyé pé dókítà kan ṣoṣo ni àwọn àkàndá ẹ̀dá náà gé jẹ tí ó sì fara ṣèṣe. | 0 |
Àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ló gbé alága ìgbìmọ̀ àìlámòójútó àwọn gáréèjì Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀. | 0 |
Àkàrà òkú kò yókùú, ẹni jẹ ẹ l'óun kò yó. | 1 |
A kìí jẹ òmùgo èèyàn lẹgọ̀ọ́. | 1 |
Bánjókòó bá ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìjàmbá ilẹ̀ rírì. | 0 |
B'éèyàn bá f'ọrọ araa rẹ gbọ; kó ràjíná. (ojà) | 1 |
Ayé kì í sú ni kí a dífá Onà-Ọrun wò. | 1 |
Bí abẹ́rẹ́ bí abẹ́rẹ́ lèèyàn ń ṣèké; ọjọ́ tó bá tóbi tó ọkọ́ tí a fi ń roko ní ń pani. | 1 |
Èkùlù kì í bá ikòokò p'agbo ijó. | 1 |
Agbẹjọ́rò dabarú ètò ìgbẹ́jọ́ nípa lílo àwọn ohun tí kò lẹ́tọ̀ọ́. | 0 |
Àwọn oníròyìn òfegè ló gbé ìròyìn náà. | 0 |
Tọ́pẹ́ ṣubú níbi tá a ti ń jà, ó sì tún dìde padà. | 0 |
Ayé ń lọ, à ń tọ̀ ọ́. | 1 |
Eni juni lo, jufá eni lọ. | 1 |
Ejidún àtèșin tó l'óun ó palẹ, ara rẹ níí pa. | 1 |
Àtẹ̀síta tí Dòsùnmú fi síta ní àkọ́lé tó fanimọ́ra. | 0 |
Bí òkú bá kú láyé, àkàlà a mọ̀ lọ́run. | 1 |
B'omodé bá sẹsę tó tóbi, kó lo jawé oríjin fi bebe. | 1 |
Bí wọn bá ránni nise erú, kí á fi tọmo jẹ e. Bí wọn bá ránni níse omo, kí a fi t'omọlúàbí jẹ e. | 1 |
Bí o rí i, wà pé o ò rí; ọkọ́ fún ọ lówó, àlé gbà á ná. | 1 |
Egbọn ẹni alùgbọn (bíi) baba ení. | 1 |
Àwíjàre tí gómìnà mú wá ni pé ìjọba fẹ́ yanjú àwọn ìṣòro owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́. | 0 |
B'lfá bá gbeni táa lówó lowo bíi Oba Egbelę, kí a gb'ęja-nlábọ'Fá ló tọ. B'ĺkin bá kín ni léyìn tí a là là là bíi ọdán Ìlalà, eyinlániánlá làá f ií bọ'kin ọhún. | 1 |
Eégún tí ò lẹni leyìn, olè ni. | 1 |
Kò fìdí múlẹ̀ nínú ìwé òfin Nàìjíríà pé ká máa pín ipò gómìnà sí ẹlẹ́kùn-jẹkùn. | 0 |
Àsá ń ké kò dáke, ọgbìngbìn ń rìn kò dábọ, jọhun páláisàn kan ń bẹ níhà ibèun! | 1 |
Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn tún ti gbé àwọn ètò tó lágbára dìde láti fi kojú àwọn ìwà ọ̀daràn. | 0 |
Àwọn ọlọ́pàá ní kí dẹ́rẹ́bà tó ké gbàjarè wá tẹ̀lé àwọn. | 0 |
Ìbéèrè tí ó ń wá sí ẹnu gbogbo àwọn ènìyàn abúlé náà kò yàtọ̀. | 0 |
Afẹ́fẹ́ oko ní ń fẹ́ ewé oko lámilámi, ẹ̀fúùfù lẹ̀lẹ̀ ní ń fẹ́ ewé àgbọn jìàjìà. | 0 |
Ẹní tó mọo kì í wó o. | 1 |
Àwọn adigunjalè yìí máa ń yọ ìbọn sí awakọ̀ níbi tí ọ̀nà kò ti dára. | 0 |
Wọ́n ti ń kọ̀wé ìgbani-síṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn nínú wọn lọ́nà àìtọ́. | 0 |
Ẹlẹ́rìí ní ń yanjú ẹjọ́; ẹlẹ́rìí kì í ṣe elégbè. | 1 |
Bí a bá láyà díẹ, kí a fi ojo bíntín kún un. | 1 |
Atọrọ-ohungbogbo-lọ́wọ́-Ọlọ́run kì í kánjú. | 1 |
Adébáyò wá kábàámọ̀ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n ń tọwọ́ òṣèlú bọ. | 0 |
A kì í sipę nàró fábuké. | 1 |
Ìlú Oko-ìrèsé ni wọ́n ti rí ọkọ̀ náà. | 0 |
Aṣọ à-fọ̀-fún ò jẹ́ ká mọ olówó. | 1 |
Ẹni hègbín láàárọ kùtù, tó lóun he erọ;ara ì bá rọ ìgbín a jíjáde láàáro kùtù! | 1 |
Babáfẹ́mi ní àwọn ti dáná sun oko ọ̀hún. | 0 |
Ẹni tí a ní a ó tòó 'ò ní dáke. | 1 |
Ẹ̀gbọ́n iwájú: alugbọn baba. | 1 |
Gbamgba l'Ògèdèmgbé ń s'awó e tí kì í ya. | 1 |
Agbèfọ́ba ṣàlàyé fún kóòtù pé ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún wáyé ní àdúgbò Mofẹ́rere. | 0 |
Arúgbó odó la fi ń gún elú. | 1 |
Àwọn aṣojú ilé-iṣẹ́ náà máa ń gba owó. | 0 |
À-ríni-mọ́ni ni à-kíni-mọ́ni. | 1 |
A fegbọn rólé, ẹsẹ ń se gìrìgìrì nílé àbúrò. | 1 |
Àwọn oníròyìn ń jábọ̀ àjàkálẹ̀-àrùn lójoojúmọ́. | 0 |
Ẹ̀bùn Àyìndé nínú orin fújì kíkọ ò lẹ́gbẹ́ | 0 |
A gbọ́ pé wọ́n fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò. | 0 |
Mo gbàgbọ́ pé èyí tí ó dára jùlọ ni yóò ṣẹlẹ̀ nínú àwọn èróńgbà wa. | 0 |
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́kùnrin ti ń gbaradì fún ìgbàlejò àwọn olùkọ́. | 0 |
Ení bánij'òbúko pínnísín níí bá nií jàgbò tó làwo lóríwààkàwààkà. | 1 |
Ara la mọ a 'ò mọnù. | 1 |
Akọpẹ méjì ò kíra wọn kú ìyà, wọn ń jìjàdù àgbàkọ. | 1 |
Aṣọ-ńlá niyì eégún. | 1 |
Àwọn ọlọ́pàá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kò bìkítà rárá pé owó ńlá ni ìjọba fi ra ọta ìbọn. | 0 |
B'ádie bá ń fese tanlẹ, ire ló ń wá. | 1 |
A-jí-má-jẹ-ǹkan, a-fàkàṣù-mẹ́fà-ṣoògùn-aràn. | 1 |
A kì í peni lákọ ẹran ká ṣorí bòró. | 1 |
Bí a bá rí èké, à ṣebí èèyàn rere ni; à sọ̀rọ̀ ságbọ̀n a jò. | 1 |
Agbófinró ń wá olùkọ́ tó lu akẹ́kọ̀ọ́ pa ní Ifọ̀ nítorí ibéèrè ìṣirò. | 0 |
Wọ́n ń yìnbọ̀n pa àwọn tó bá ṣe orí kunkun nínú wọn. | 0 |
Alukoro ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá sọ pé ikú gbígbóná ni wọ́n fi pa ọkùnrin náà. | 0 |
Bó bá ti rí ni ẹ wí, àlá kì í b'ọmọ lẹrù kó má leè rọ ọ. | 1 |
Ewú níí pile ogbó. | 1 |
Kò sí àkọsílẹ̀ nípa ọjọ́ tí wọ́n bí Wàídì Àyìnlá Ọmọwúrà. | 0 |
Àyẹ̀wò ọpọlọ la óò ní kí arúfin tọ́wọ́ bá bà lọ ṣe ná. | 0 |
Àwọn èèkàn ilẹ̀ Yorùbá ń ṣèpàdé ṣáájú dídìbò fún Tinubu. | 0 |
Àtàrí ni ò jẹ́ kóòrùn ó pa àgbọ̀n ìsàlẹ̀. | 1 |
Afinisesín àlè t'ó ľ'óun fẹ jẹbẹpẹ. | 1 |
Àwọn amúlùúdùn lè jẹ́ olórin tàbí onifíìmù. | 0 |
Agbọmábiwọn àti amọmábéèrè, kò sómùgọ̀ nínúu wọn. | 1 |
B'áráyé bá ń bú ę fọwọ lẹrán. | 1 |
Ẹrú 'ò duyè ọba, Ègùn 'ò duyè Eyọ. | 1 |
Ení nàka kan s'ọmọlàkejì, mọkàndílógún tó kù ni tię. | 1 |
A máa sọ̀rọ̀ lórí àìsàn ìtọ̀ ṣúgà àti ọ̀nà tí a lè gbà dènà rẹ̀. | 0 |
Adájọ́ àgbà dárúkọ àwọn tí wọn yóò jìyà òfin. | 0 |
Màríà fi ẹ̀sùn kan ẹni tó gbà wọ́n lálejò. | 0 |
B'éèyàn bá se rolé-ayé sí ló máa ń jẹ fún un. | 1 |
A kì í kígbe l'ákèéwọ, gbogbo ara la fi ń kígbe. | 1 |
Bí ènìyàn ń gúnyán bọ́ ìlú, ó máa ní ọ̀tá. | 0 |
Àdọgbọn jẹyán àtèsí là ń pèkan léèépá. | 1 |
Àwọn olóṣèlú ti fi èrò wọn hàn lórí kíkọ́ ọ̀nà ọ̀hún. | 0 |
Ẹní bá rìnrìn mùtàmùtà làá mú tà. | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.