Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Àwọn ọlọ́pàá ti palẹ̀ òkú arákùnrin náà lọ sí ilé ìgbókùúpamọ́sí. | 0 |
Ibà náà jẹ́ ọ̀kan lára àìlera àjàkálẹ̀-àrùn. | 0 |
Ọjọ́ Ajé nínú oṣù yìí ni wọ́n wọ́ òṣèré náà lọ sí ilé ẹjọ́ ní ìlú Ifọ̀. | 0 |
Ọ̀gangan ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé ìtàn àròsọ tí mo kà jẹ́ inú iná iléru. | 0 |
Àtẹkì, àtajá, ẹran ìkokò nì. | 1 |
Ẹgbẹ̀rún kan owó náírà ló fa èdè àìyedè láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì. | 0 |
A kì í lé Ọmọdé l'órò, b'ágbà bá dàgbà tán, Ọmọdé ní í kù lÓrò. | 1 |
Ajá fẹ́ràn à ti máa jẹ eegun lọ́pọ̀lọpọ̀. | 0 |
Bí ọjọ́ ewúrẹ́ bá pé, a ní kò sí ohun tí alápatàá lè fi òun ṣe. | 1 |
Agbábọ́ọ̀lù ọmọ Nàìjíríà kan ti dá àjọ kan sílẹ̀. | 0 |
Àpésan kì í tú ìlú. | 1 |
Ayéfẹ́lẹ́ ní ohun gbogbo lè di ṣíṣe pẹ̀lú ìfọkànsí. | 0 |
Àsìkò tí ó yẹ kí àwọn olóko gbìn nǹkan rèé. | 0 |
Bọ́lá máa dá ilé-ìfowopamọ́ sílẹ̀ tí ó bá dàgbà. | 0 |
Ẹjọ́ ẹlẹ́jọ́, lọ́yà ń rò ó, áḿbọ̀ǹtorí ẹjọ́ ara-a rẹ̀. | 1 |
‘‘Ng ó ṣe ìyá’’ ò lè jọ ìyá; ‘‘Ng ó ṣe baba’’ ò lè jọ baba; ‘‘Wòsọ̀ dè mí’’ ò lè jọ onísọ̀; ojú mẹ́wàá ò lè jọ ojú ẹni. | 1 |
Adébọ́lá ọmọ ọdún mẹ́rindínlógún náà pàdánú ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìjàm̀bá náà. | 0 |
Àwọn iléeṣẹ́ búrẹ́dì ti kéde àfikún sí owó ọjà wọn. | 0 |
A kì í dé ilé arúgbó lọ́fẹ̀ẹ́ . | 1 |
Àwọn tí wọ́n ní dúkìá púpọ̀ ni wọ́n ń ṣe onídùúró ẹlòmíràn. | 0 |
Owó tí ìyá mi fún mi ti sọnù níbi tí mo ti ń bọ́ aṣọ lọ́rùn. | 0 |
Awakọ̀ kò mọ̀ pé ọkọ̀ mìíràn wà lẹ́yìn rẹ̀ bí ó ti fẹ́ yà fún kòtò tó wà láàárín ọ̀nà. | 0 |
Ajíjìfà ní ń ní tìtì ìpàkọ̀. | 1 |
Àwọn orílẹ̀-èdè aláwọ̀ funfun náà ti ń kó àwọn ènìyàn wọn kúrò. | 0 |
Bí a bá ní ká b igi, a ó bẹ̀ẹ́ èèyàn. | 1 |
Bí sòbìyà yó bàá degbò, olúgambe là á wí fún. | 1 |
Aboyún kì í gbọn kílẹ má jẹ lára ẹ. | 1 |
Ẹjọ́ yìí kò ní ẹ̀rí láti gbe ẹ̀sùn rẹ̀ lẹ́sẹ̀ nítorí náà, ilé-ẹjọ́ da ẹjọ́ náà nú. | 0 |
A kì í fi aṣọ ṣèdìdí yọwó. | 1 |
Àgbéga ti bá àwọn agbófinró ẹ̀ka ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́. | 0 |
Àwọn orin ti Àyìndé ti kọ tipẹ́ gan ò ṣá létí. | 0 |
Àwọn alátìlẹ́hìn Olúṣọlá ló pọ̀ jù lágbègbè tí Àjàká ń gbé. | 0 |
Ajóbíewé Àrẹ̀mù ń tẹ́ àwọn ará ìlú lọ́rùn. | 0 |
Iléeṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ti pariwo pé àwọn èèyàn kan ń ṣe kinní kan níbi kan. | 0 |
Àgbà tí 'ò lájẹkù, yóó ru'gbá ę dóko. | 1 |
Bí a bá na gogo ogbọn sí nnkan tí kò tò o, kí a fi wèrè díę ti ese | 1 |
Ajóbíewé Àrẹ̀mú Kì í mutí. | 0 |
Ení bú'ni ní dídùn, bí a bá bú u ní kíkan k'ò léèwọ. | 1 |
Aago wo ni ẹ fẹ́ lọ sí òde olókùú, ṣé ẹ mọ̀ pé ẹ ò gbọ́dọ̀ pẹ́? | 0 |
Arákùnrin kan dóòlà ẹ̀mí Erin tí alùpùpù gbá lójú pópó | 0 |
Èsù tó n lù fún 'Lándé 'ò dẹkun ilù-lilù.Lándénáào dekun jijó. | 1 |
Elégédé pagbo yóko ká, Ogede pagbo yódò ká. Eyín ìwòyí la ti ń jobì ìwòyí. | 1 |
A kì í lọ́mọ lẹ́hin kọ oúnjẹ. | 1 |
Baàyè bá gbàpá, dídán ní í dán. | 1 |
B'ówó bá ń lo, a á sìn ín ni. | 1 |
Àwọn kan sọ pé àwọn ti ń gbaradì. | 0 |
Fẹẹrẹ l'òjò-ìjà á șú. | 1 |
Àlékún túbọ̀ ń bá owó ilẹ̀ òkèèrè. | 0 |
Àdùnní dúró níbi iléepo pẹ̀lú mọ́tò ẹ̀, nígbà tí ó ṣàkíyèsi pé pátákó yẹn fẹ́ wó. | 0 |
Gbengbelekú, kì í rẹnií bá a kú. | 1 |
Bí ọmọ ẹní bá dára, ká sọ pé ó dára; bí-i ká fi ṣaya ẹni kọ́. | 1 |
Àbá kì í ṣòótọ, ojo ni kì í jẹ á dá a. | 1 |
Wọ́n tọpinpin ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ olóògbé dé agbègbè Àgọ́-oníwàrà. | 0 |
B'ọmọdé 'ò l'óògùn, a a bulę sarí. | 1 |
Adétáyọ̀ ní ohun tí yóò bá ṣe àǹfàní fún àwọn olórí Nàìjíríà àtàwọn ẹbí wọn ni wọ́n máa ń ṣe. | 0 |
Bí ológbò-ó bá pa eku,a fi ìrù-u rẹ̀ dẹlé. | 1 |
Agẹmọ kì í kú ní kékeré. | 1 |
·Erin'ò yàto dÉgùn. (dé'le àwọn Ògù) | 1 |
Àwọn bàbá wá gbọ́ orin Àyìndé. | 0 |
Ajá kì í gbàgbé olóore. | 1 |
Èèyàn kì í tan ara ẹ jẹ kí ó ríre. | 1 |
Dòsùnmú fi àtẹ̀síta kan síta fún àwọn akọ̀ròyìn. | 0 |
Ẹ jáde wá ṣe ìwọ́de àìṣùn ọdún. | 0 |
Ẹ̀gbọ́n ṣíwájú ó so aṣọ kọ́; àbúrò-ó kẹ́hìn ó wẹ̀wù; bí a ò mọ̀lẹ, ọ̀lẹ ò mọ ara-a rẹ̀? | 1 |
Ìjọba yóò parí ìwádìí àwọn ọ̀daràn tó sá lọ ní kíákíá. | 0 |
Ẹrùn (Èkùrọ) tó re'lé Ewúsà (òkété) tó bọ, orí ló ní (ìpín ló ní) | 1 |
Bí a bá bímọ fójú ó yẹ kó fi mọran-án wò. | 1 |
Àwọn olùkọ́ fásitì kú ní fásitì Kalabá. | 0 |
Àwọn tí kò fẹ́ kí Nàìjíríà gòkè ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. | 0 |
Ìjọba fi òfin de Olúkàrẹ́ láti má ṣe dábàá ìpàdé kankan lásìkò yìí. | 0 |
Àbúrò Màríà bá ìwé ìròyìn Elétí-ọfẹ sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. | 0 |
Èròńgbà oníkálukú lórí iṣẹ́ yàtọ̀ síra wọn. | 0 |
Agbẹjọ́rò Fẹ́mi Fálànà ti sọ̀rọ̀ léréfèé lórí ọ̀rọ̀ ọmọ rẹ̀, Fọlárìn. | 0 |
Òṣìṣẹ́ ilé ìtura tó wà ní yàrá ìgbàlejò ló sọ fún ìwé ìròyìn Aláwìíyé | 0 |
Àgbà tó kọ'fá wọ'gbódù tí kò róbì tó gbó káká jẹ, ẹ pé kótúngbódù wọ lẹ́ẹ̀kan si. | 1 |
Ení tó fi gi giríse tẹ aso ara rẹ mọle, yóófiàtàmpàkò fa telòmíràn ya. | 1 |
A kì í torí pádiẹ eni ń s'ọmọọre (mọ ọmọ wò), kí a máa pè é ni 'lyá-lọhùn-ún.' | 1 |
Àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́rin ṣekú pa ọ̀rẹ́ wọn nítorí owó ọ̀wọ́ rẹ̀. | 0 |
Wọ́n fẹ́ yan Àlùfáà tuntun fún mọ́ṣáláṣí gbogbogbòò tó wà ní ìlú Ìkàrẹ́ . | 0 |
Bí a bá jadùn títí bí a 'ò bá jẹ ìkorò dię sí i, ayé a máa súnnií ję.Eni ti kò je ìpọnjú rí, kó le è mọyì plà. | 1 |
Ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ nìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ fún gbogbo àwọn tó ń ta ọjà nínú ọjà. | 0 |
A kì í jẹ ‘‘Mo fẹ́rẹ̀-ẹ́ ’’ lọ́bẹ̀. | 1 |
Àwọn olùwọ́de bá àwọn oníròyìn sọrọ nípà ìwọ́de. | 0 |
Pípèsè ilégbèé lọ́pọ̀ yanturu fún aráàlú yóò wáyé pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn Iléeṣẹ́ aládàáni. | 0 |
Ení gbé ara rę pamọ, áá gbé ara rẹ pa. | 1 |
A kì í b'Ónísuú jẹ ẹ débi ègùn. | 1 |
Ìlú Abẹ́òkúta ni wọ́n ti ń ṣẹ̀dá ojúlówó aṣọ àdìrẹ gidi. | 0 |
Àjàlá jẹ́rìí si pé pátákó ọ̀hún fi gbogbo agbára mì̀ kó tó wó lulẹ̀ sórí ilẹ̀. | 0 |
Àgálámàsà dúro tòun tìfura. (tifuratifura). | 1 |
Bí a bá wẹnu Ọlọjà, a dàb eni pé kò muyàn rí. | 1 |
Ẹni ogún ya lágbọn ló ń mọrọyìn ogun. A ní: 'Ogun ń bẹ lọhùn-ún, ọmọ ohaha'. | 1 |
Arákùnrin alápatà màlúù kan gún ìyàwó rẹ̀ pa. | 0 |
Adájọ́ Oṣòdì ní òun gba béèlì Àlùfáà náà. | 0 |
Bí màlúù-ú tó màlúù, ọ̀pá kan ni Fúlàní fi ń dà wọ́n. | 1 |
Àpò tí a kò fi ọwọ́ ẹni dá ṣòro-ó kiwọ́ bọ̀. | 1 |
Ejò-ó rí ihò tó há ó kó wọ̀ ọ́; ìyá-a rẹ̀-ẹ́ lọ́wọ́ àti fà á yọ? | 1 |
Adéwálé di amòfin orílẹ̀-èdè rẹ̀ ní ọdún tó lọ. | 0 |
·Eégún o leè ké kàrà; kó ké kòró, k'ówó-ojú e má mi gbogangbongan. | 1 |
‘‘Háó fọ̀ dúù’’ lòyìnbó fi ń jẹ̀bà lÓrígo. | 1 |
Àwọn agbẹjórò ní ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ní àwọn yóó kọṣẹ́ sílẹ̀ fún oṣù díẹ̀ ná. | 0 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.