Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Bí Ẹfúnṣetán ṣe di ilú Ìbàdàn mú nígbà ayé rẹ̀, kò gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀ mọ́. | 0 |
Ojú òṣèlú ni àwọn ará ìlú yóò fi máa wo ìṣẹ̀lẹ̀ náà. | 0 |
Ìdíje àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ Fáfitì Èkó yóò bẹ̀rẹ̀ ní oṣù tó ń bọ̀. | 0 |
Ajóbíewé Àrẹ̀mú jẹ́ ọmọ bíbí Ìlá-Ọ̀ràngún. | 0 |
Bí a bá ń sọrę, kí a máa f'ààfo ijà sílę. | 1 |
Èèyàn yin-ni yin-ni kẹ́ni ó ṣe òmíràn. | 1 |
Bí a bá lu Ògbóni jẹjẹ, a ó san ẹgbàafà, bí a bá sì lu Ògbóni bàmùbàmù, à ó san ẹgbàafà, kò ha sàn kẹni kúkú lu Ògbóni bàmùbàmù! | 1 |
Fúnnifúnni kì í táwọná. | 1 |
Àwọn òbí mi ti kọra wọn sílẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́. | 0 |
Àgbò ò ṣéé mú; ọ̀dá ò ṣéé mú; ohun gbogbo ní ń tóbi lójú ahun. | 1 |
‘‘Òru ò molówó’’ nIfá tí à ń dá fún ‘‘Ìwọ ta nìyẹn?’’ | 1 |
Alágbẹdẹ ò f'óogún ó ó tán láyé. | 1 |
B'ọgbọn bá fo àràbà, tó fo òrùlé, eyìnkùnlé agọ níí ba'lę sí. | 1 |
Ọ̀kan lára ọmọ Balógun jẹ́ agbábọ́ọ̀lu. | 0 |
Àbíjo là á mọtan. | 1 |
Èèkù 'ò mọ p'ára ń tàdá, okà àmọlà ò mọ p'ára ń ta igbako | 1 |
Agbàdá ya l'ọrùn ó bàjẹ, igbá kán lérí, ó di ti gbonmigbonmi. | 1 |
A kì í tani lójì, kí a tún f'ọná ilée Baále han ni. | 1 |
Ekún ťọmọ Ọlọjà bá sun tó gba erinlá(eyinla)bós'omotálik wọn a ní kó sun àsunkú. | 1 |
Àjùlọ ò pin, ìyá ẹnikan nìyàwó elòmíràn. Baba enìkan, omo elòmíràn ni. | 1 |
Abiyamọ, a-bẹ̀hìn-jíjà. | 1 |
Èní; Agemo Ola AgAgẹmọ kú sáàrò Onílé. B'ójú ò | 1 |
Ẹ̀mẹerin sí ẹ̀ẹmàrùn-ún ní àárín ọ̀sẹ̀ ni àwọn àgbẹ̀ máa ń lò láti fi ṣe iṣẹ́ wọn. | 0 |
Adénẹ́kàn kò mọ̀ pé onírúurú làwọn ohun tí ìjọba ṣe àgbékalẹ̀ nílùú rẹ̀. | 0 |
Ẹkẹ sowọ gbàgìdì múlé ró, àbọn se rìgìdì deyìn. | 1 |
Bí a bá rí òwúrọ̀, alẹ́ ń kọ́? | 1 |
Dàgídàgí mọbi òun ń rè. | 1 |
Àwọn ará ìlú òkèèrè náà ń mọ ipa ogun náà lára. | 0 |
Ataare-é rẹ́ni tún ìdí-i rẹ̀ ṣe ó ń fi òbùró ṣẹ̀sín; òbùró ìbá r ni tún ìdí-i rẹ̀ ṣe a sunwọ̀n jú ataare lọ. | 1 |
B'ọmọdé bá l'ọgbọn, a máa fi tàgbà lọrẹ. | 1 |
Àwọn ènìyàn mú ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá ní pàtàkì ju ti ìbílẹ̀ lọ. | 0 |
Bí àwọn ènìyàn ti ń wọ ìpínlẹ̀ Èkó lójoojúmọ́ ń fa ìbẹ̀rùbojo sọ́kàn àwọn olùgbé Èkó. | 0 |
Àgbà tí ò bínú l'ọmọ ẹ ń pọ. | 1 |
Aàyè gba aláboyún ó dá koto-itọ. | 1 |
‘‘Ó ḿbọ̀!’’ ló yẹ baba; bí babá bá dé, ọ̀rán tán. | 1 |
Ayéfẹ́lẹ́ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn. | 0 |
Àfẹ́ẹ̀rí kan ò ju ká rí igbó ńlá bọ́ sí lọ; ẹbọ kan ò ju ọ̀pọ̀ èèyàn lọ; ‘‘Òrìṣá gbé mi lé àtète’’ kan ò ju orí ẹṣin lọ. | 1 |
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn èèyàn dáná sun ọkọ̀ tí ó fi pààyàn náà. | 0 |
Àìrọ́rọ̀sọ ìyàwó tó wí pé èkúté-ilé yó jẹ idẹ; bẹ́ẹ̀ni Mọ́jidẹ nìyálé-e rẹ̀ ńjẹ́ . | 1 |
Àwọn onímàlúù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ̀bẹ sí àwọn màlúù wọn lọ́rùn bí wọ́n ṣe ń ṣubú. | 0 |
Bí a ṣe ń yanjú ìṣòro kan, òmíràn ń dìde. | 0 |
Ọ̀pá tí àwọn ọmọdé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fi ń ṣeré ti sọnù sì igbó. | 0 |
Abẹ́rẹ́ àjẹsára yóò wọ Nàìjíríà láìpẹ́. | 0 |
Èyí tó kàwé nínú wọn yọ kálàmù, ó lóun á parí wọn. | 0 |
Adégbémilé fẹ́ kí aya rẹ̀ máa múra bí ayaba. | 0 |
Bí wèrè bá ti gbòde Ọlọgbọn ma ń sá kóólé ni. | 1 |
Ọkàn àwọn tó ra fọ́ọ̀mù kò balẹ̀ mọ́ látàrí ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà. | 0 |
Àkàndé yọjú síbi ìpàdé náà ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti kópa nínú nǹkankan. | 0 |
Baálé lọlọ́ràn awo. | 1 |
Ẹni tí wọn ń d'ẹrùú dè, kì í sọ pé kí wọn dì í kó wíwo. | 1 |
Ohun tó ṣẹlẹ̀ ò yé ẹnikẹ́ni ní pàtó. | 0 |
Ẹgún kì í gún ọmọ lẹsę, kí á lọ yọ ọ l'ẹsẹ ẹrú. | 1 |
Ṣọ́jà tẹ̀lé Ayọ̀mídé láti lọ gbèjà ní Adínlẹ́wàá. | 0 |
A kì í dọdọbálẹ kí a múná lójú. | 1 |
B'éèyàn bá f'ẹsọ (rọra) pa eèrà, yóò rífun ẹ. | 1 |
·Eni kọse tó dákú, bí ó bá jíi, ę pé ki ó kọ'se miíràn. | 1 |
Ọlálọmí tú àṣírí obìnrin náà síta pẹ̀lú pé kò bímọ fóun. | 0 |
Ajá ní òun ìba má dèé oko rí òun ìbá sọ pé ọ̀run ni wọ́n ti ńkálá wá. | 1 |
Ní àfikún sí àrùn kíndìnrín tó ń ṣe Adérántí, ó tún ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà àti ìfúnpá tó ga. | 0 |
Akin Adéṣínà ní òun kì í ṣe àjèjì bí àwọn kan ti rò. | 0 |
Eni niyàwó méji, a'á puro merin. | 1 |
Ẹja yíyan ni mò ń tà, kódà ohun ni a ń jẹ ní ilé e wa. | 0 |
lorùn, Elúùlú eye senu gongo kò leè fi gbegi. | 1 |
Àrò kì í gbóná kalẹ́ . | 1 |
Ẹnu bíbu Ilẹ̀pa làwọn akẹ́kọ̀ọ́ wà tí Ilẹ̀pa fi ṣí láti òkè. | 0 |
Akẹ̀sán lòpin Ọ̀yọ́; ibi a báni lọ́wọ̀ ni ilé ẹni. | 1 |
E sá máa forítì í', níí págbà lórí. | 1 |
Bí ilẹ̀-ẹ́ gbe òṣìkà, tí kò gbe olóòótọ́, oore a súni ṣe. | 1 |
Àwọn oníṣẹ́ láabi ṣọsẹ́ ní Ìbàdàn. | 0 |
A kì í gbọ́ búburú lẹ́nu Abọrẹ. | 1 |
Bébi bá ń pá'nìyàn; a dàbí ẹni tí kò ní yó mo. | 1 |
Wọ́n ti yan Folúkẹ́ gẹ́gẹ́ bí adarí ẹgbẹ́ òṣèlú aládìyẹ. | 0 |
Bàbá rẹ̀ ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ti gbà fún Ọlọ́run ṣùgbọ́n ikú rẹ̀ sì dá ọgbẹ́ sí òun lọ́kàn. | 0 |
Ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti gba ajá náà kúrò lọ́wọ́ Fọlọ́runṣọ́. | 0 |
Bí ilẹ̀-ẹ́ bá mọ́, ojú orun lọ̀lẹ ń wà. | 1 |
Àșá ń fò 'fẹ' Awòdí ń fò 'fẹ', rikìșí Àwòdì ni 'ò jÁdiẹ ó fò 'fe' | 1 |
B'Elekọlé ò ríhun má'șọ șe, kó dààlà bo Oșè. | 1 |
Ààyò mi àti ọkùnrin tó rẹwà jùlọ ní wọn fí ń ki ọba Adéyẹmí. | 0 |
Alápatà ekùn-ún sowọn. | 1 |
Ìkọlù ojú irin tó wáyé ni ìkẹta irú rẹ̀. | 0 |
Tóyìn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ayálégbé tí pásítọ̀ gbà sí ilé rẹ̀. | 0 |
À ń rọjú jẹkọ ọbùn, ọbùn tún ń dákọ ẹ kéré. | 1 |
Ó ní iyì tí bàbá òun àti àwọn ọmọ máa ń rí kì í ṣe kékeré. | 0 |
Bẹjà bá sù, ęja a máa męja ję. | 1 |
Ení-ń-fee-wá,pàdé ení-ń-retí. | 1 |
Àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ẹ̀ṣọ́ Àmọ̀tẹ́kùn ni wọ́n jọ gbèjà àwọn ènìyàn. | 0 |
Kò bá tiẹ̀ wá sunwọ̀n bí ó bá jẹ́ pé orí ìyẹn nìkan ló mọ. | 0 |
Bí awó ti ń lù lawó ti ń jó. | 1 |
Ẹ máṣe fààyè gba ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn- Ààrẹ gba àwọn èèyàn níyànjú. | 0 |
Àáyá kan-án bẹ̀ ọ́ wò; igba wọ́n ti rí ọ. | 1 |
Onírúurú ìlò ni omi wà fún yàtọ̀ sí mímu. | 0 |
Ẹ̀gbá mọ̀dí Ọbà; ẹni tó gbéniṣánlẹ̀-ẹ́ lè pani. | 1 |
Àìbalẹ̀-ọkàn tí ilẹ̀ rírì dá sílẹ̀ ṣì wà lára àwọn ará ìlú. | 0 |
A f'Àje so'lé, a fi Koówè so iso,9 àtálòde,a sìńfiGúnnugún sọso pé a ò i tí ì r'ẹyẹ tó gbójú tó.Ibi eye abàmìbátún kù sí,darúko e fún wa k'á gbọ. | 1 |
A kì í gb'eyin l'érí pàntèté. | 1 |
Ó sọ wí pé ní Ọjọ́bọ tó kọjá làwọn tún ṣàwárí igbó kìjikìji tí wọ́n ti ń gbin igbó. | 0 |
A kì í mọ alájá ká pé kẹ́kùn ó pa á jẹ. | 1 |
Ooru tó ń mú ní àsìkò yìí lè se òkúta jinná. | 0 |
Egbinrin ọ̀tẹ̀: à ń pàkan, ọ̀kan ń hù. | 1 |
A lọ sí ibi ìfẹ̀yìnti ìyáàfin Ṣiyanbọ́lá. | 0 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.