Proverbs
stringlengths
8
373
Labels
int64
0
1
Baálé ilé kan wọ́ ìyàwó rẹ̀ lọ sí ilé ẹjọ́.
0
Kò sí bí a ṣe lè wo ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí tí ìdájọ́ wa kò ní fì sí apá kan.
0
Ẹni tí 'ò nílé, àsíríẹ 'ò bò.
1
Ó dá lórí olóṣèlú tó ń gbìyànjú láti parí ìjà.
0
A pa ìgbín a ò bá ẹ̀pọ́n; a pa ìrẹ̀ a ò kan ẹ̀jẹ̀.
1
Ọkọ̀ tó ní ìjàmbá ní títì márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn tàkìtì tí kò sì kọlu ọkọ̀ mìíràn.
0
Ẹjọ là á kọ kí a tó kọjà.
1
Bí a kò bá sọ fún ọmọdé pé èèyàn lọkọ ìyá-a rẹ̀, a ní ta ní ń wá gba ìyá òun lẹ́kọ jẹ lójoojúmọ́ yìí?
1
Ináọlájí mú dábàá ọ̀nà àbáyọ láti kó àwọn ènìyàn kúrò níbi ogun.
0
Àjà kì í jìn m'ólógbò lẹ́sẹ̀.
1
Eléwe-é ní iyènú; àìní mọ ìwà-á hù.
1
Báwo ni ìdìbò ọdún tó ń bọ̀ yí ó ṣe lọ gan-an?
0
Ọ̀pálọla sọ pé Múìbí yóò fojú balé ẹjọ́ ní kété tí ìwádìí bá parí lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
0
Béèlì náà ń farahàn ní àgọ̀ ọlọ́pàá.
0
“B'ó bá ń yá kì í pẹ mọ”, àgbẹ tó tilé bẹrẹ ló sòkó.Ó ni: 'B'áa kúkú dọhùnún náà, ișẹ ibẹrẹ la ó se.'
1
Àjàká sọ pé àwọn tínú ń bí ò fún òun láǹfààní àti-sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́.
0
Bọ̀dẹ́ àti Lọlá gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́dún.
0
Agbẹjọ́rò tó darí àwọn ti ìjọba ni Ọ̀gbẹ́ni Babájídé Bóyè.
0
Ẹlòmíràn nínú àwọn olùkọ́ kò bìkítà bí akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́ ẹ̀kọ́ yé tàbí kò gbọ́.
0
A kìí dégbè gbalé gbé.
1
Àjọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti gbóríyìn fún àwọn ọlọ́pàá rẹ̀ fún iṣẹ́ ribiribi.
0
Bi won ti n se níbìkan làá bá wọn-ọn se. Bí a dé Ìfọnyìn kí á su sojà.
1
Dà-dà-dà-n-dadá' èwo la 'ò se rí?
1
Ẹ̀sùn ìpànìyàn ni ilé ẹjọ́ dá fún Olórí ọlọ́ṣà.
0
Àgó tó gbó ṣáṣá, ẹ̀bìtí pa á; aḿbọ̀sì olóósè a-bara-kùọ̀kùọ̀.
1
Àsìkò tí ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan yóò là wà lọ́wọ́ orí.
0
Bí a bá ti mọbi èèyàn ba sí, àtijáde rẹ ò lèe báni lábo.
1
Àwòdì òkè 'ò rà; kó gbẹkòo-òwú.
1
Ìjọba gbọ́dọ̀ fòpin sí kí ọkọ̀ máa gba ọ̀nà tí kì í ṣe tiwọn lójú pópó.
0
Abebẹ níí bẹkú, abẹbẹ níí bẹ àrùn. Bí oru bá mú abẹbẹ làá fiíbe e.
1
Abẹ́ àtíbàbà tó wà níwájú ìta oko ni a sùn mọ́jú.
0
Bániwí kì í báni débẹ̀.
1
Ṣẹ́gun Adénúgà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àgbàọ̀jẹ̀ akọ̀ròyìn èdè Yorùbá ní ayé àtijọ́.
0
Aya ọ̀lẹ là ń gbà, a kì í gbọmọ ọ̀lẹ.
1
B'ó bà se pé gbogbo ori ló ń sunnúu pósí igi ì bá tí kùkan nínúigbó.
1
‘‘Èmi ló lòní, èmi ló lọ̀la’’ lọmọdé fi ń dígbèsè.
1
Ayo òtòṣì lọlọ́rọ̀ ń fọwọ́ tẹ̀ níkùn.
1
Ẹyẹ tí kò ní hùùhùù lápá, e șí i pọ mádię.
1
Àyè kì í há adìẹ kó má dèé ìdí àba-a rẹ̀.
1
Bí a bá wí a dàbí òwe; bí a ò bá wí a dàbí ìjà.
1
Adémọ́lá ní ara ọ̀nà à ti máa dá aráàlú lárayá ni ṣíṣe ọjọ́ ìbí.
0
Gbogbo asọ kọ làá sá lóòrùn.
1
Àgbẹ̀ tó bá pẹ́ nílé ò níí kọ oko ọ̀sán.
1
Ẹní n bólókùnrùn jiyàn ni yóó pa á.
1
Bí a se ń pabì kọ là ń pèkùrọ.
1
A kì í bá Òșubú lọọlẹ.
1
Àwọn èèyàn kò fún àwọn agbófinró láàyè láti ṣèwádìí tó yẹ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
0
Níbi tí ọkọ ti fẹ́ fi ògbójú bu omi ni ìyàwó rẹ̀ ti lọ fa ọ̀bẹ yọ sí i láti ilé ìdáná wọn.
0
Arákùnrin náà kò kú sí àkàtà wa gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe ń polongo rẹ̀.
0
Akanpósí kì í rore.
1
Adékànḿbí ò du oyè; ó bèèrè ni.
1
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun àná ló yan àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ gíga náà.
0
Ẹjọ́ ahun ò kúnni lọ́wọ́.
1
A kì í wí k'ẹnu ó wú.
1
Babaláwo fọmọ tiẹ silę láibọ, ón b'ọmo gúnnugún.
1
Kókó ohun tí wọ́n torí rẹ̀ pe ẹjọ́ ni pé kí Gómìnà má ṣe yan ọmọ-oyè mìíràn.
0
Ẹni tó níka l'òrùkọ ń yẹ.
1
Ọ̀bọ kan já ọmọ gbà lẹ́yìn ìyá rẹ̀ ní agbègbè Ìta-Ẹ̀kọ.
0
Ààrẹ ní àwọn ọ̀dọ́ yóò gbádùn àtìlẹyìn òun lọ́dún tuntun
0
Eégún tí yóó j'àkàrà ju Owólęwà, áá fìgbàlę gbin erèé.
1
Ìdí fún àbẹ̀wò ni láti jíròrò lórí àwọn ìpalẹ̀mọ́ wọn.
0
Bí àkùkọ bá kọ láyé, àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀ á gbè é lọ́run.
1
Àlejò kì í tún bèèrè abẹ, bí onílé ba ti ń fi àpáàdì fá irùngbọn.
1
Ajá là bá kí; èse ò pẹran fúnni jẹ.
1
Fátólú oyanjú-Oro.
1
Ọmọkùnrin tí ṣọ́jà gún lọ́bẹ ṣì wà lẹ́sẹ̀-kan-ayé ẹsẹ̀-kan-ọ̀run nílé ìwòsàn.
0
Ẹni tí ò yani l'ówó, tí kò fún ni lásọ kì í peni l'árungún. Bó báp'eni lárungún ìjà ní í dà.
1
Àwọn agbébọn jí ọ̀gá Ọlọ́pàá méjìlá gbé lójú ìbọn ní Oṣòdì.
0
Aboyún kì í gbọn kílẹ má jẹ lára ẹ.
1
A ìí kánjúwà ká mọ, o dijọ a bá rẹni wí fún ni.
1
Ẹgbẹ́ agbá bọ́ọ̀lù àwọn ilè Ọ̀yọ́ dáṣọ ìyà fún àwọn Ifẹ̀.
0
Láti ìgbà tí Adégbémilé ti fẹ́ ìyàwó rẹ̀ ni wàhálà àna rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀.
0
Yóò jẹ́ àǹfààní ńlá fún àwọn ẹ̀yà Ìbò bí wọn bá lè darí wá sílé.
0
Bí a kò bá ṣubú, a kì í mọ ẹrù-ú dì.
1
Àwọn ẹ̀mí tó ti sọnù láti ara ìkọlù ìgbésùnmọ̀mí kò kéré.
0
Láti ara wa ni àyípadà yóò ti bẹ̀rẹ̀ bí a bá fẹ́ àyípadà rere.
0
Ayé kì í fẹ k'Ábìídágbàá ó dàgbà.
1
Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ wíwa epo rọ̀bì ní àríwá.
0
A kì í ti ojú oníka mẹ́sàn-án kà á.
1
Àwọn ènìyàn kan gbìyànjú láti kojú àwọn ọlọ́pàá.
0
Àtètègbà làtètèsan.
1
Wọ́n ní àwọn máa ń lo àwọn irinṣẹ́ wọ̀nyẹn láti wá bóyá èèyàn kan jí ẹrù kó sí ibì kan.
0
Àwọn ẹ̀yà Yorùbá máa ń pé ara wọn ní ọmọ ilẹ̀ káàárọ̀-ò-jíire.
0
Bí a bá pẹ l'áyé a ó j'eran tó térin.
1
B'óbinrin bá ń petí așọ m'ábíá, bó rí jìbìtì kò ní sài bẹ wò.
1
Ó ṣọwọ́n nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òde-òní tó mọ ìyàtọ̀ láàárín òbí àti alágbàtọ́.
0
Àrà tó wu Oníbodè ló ń fi èrò- ọnàá dá.
1
Adéwálé tẹ̀síwájú pé nígbà tí ìbọn kò yìn mọ́ ni Àkànní ferége.
0
Ajóbíewé ṣe ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan pẹ̀lú ìwé-ìròyìn Akéde.
0
Epo ltùn n'ọn fi n dín ltùn.
1
Wọ́n ní ohun tó ń jẹ àwọn níyà ni àìníṣẹ́ lọ́wọ́.
0
Pẹ̀lúmi rọ àwọn aláṣẹ ìjọba ilẹ̀ òkèèrè láti ṣèrànlọ́wọ́ gidi fún ẹ̀ka ètò ìdájọ́ ilẹ̀ wa.
0
B'ée r'ọlẹ e pè é l'ólé, bó ní kí lòun gbé, e bi í pé kí ló ń je?
1
Akọ̀pẹ Ìjàyè ò gbọ́ tiẹ̀, ó ní ogún kó Agboroode.
1
Ẹní p'ọmọ Ọlọmọ l'ẹkún; ọmọ tiẹ náà 'ò ní rẹ-rìn-in.
1
Adéyọjú bẹ ìyá rẹ̀ pẹ̀lú eékún rẹ̀ méjèèjì tomijé lójú.
0
B'éèyàn ò bá lè pọn koko, ó yẹ kí ó lè pọn bàibài.
1
Ààrẹ lè mú ènìyàn bí ènìyàn bá jẹun jù.
0
·Enu kì i k'áfaráále; b'on wi fún un, a l'eran kiíje e.
1
Alukoro Ọlọ́pàá sọ pé ó ṣe pàtàkì láti tètè fi àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ jófin.
0