Proverbs
stringlengths
8
373
Labels
int64
0
1
Bí túlàsí bá di méjì, ọ̀kan làá mú.
1
Àtètèlóbìnrin ò kan ọmọ bíbí.
1
Bí a bá fi ọdún mẹ́ta pilẹ̀ṣẹ̀-ẹ wèrè, ọjọ́ wo la ó bunijẹ?
1
Débọ̀ ti sọ̀rọ̀sókè fún ìjọba Nàìjíríà lẹ́yìn tó ti àtìmọ́lé dé.
0
Ariwo tí Ayọ̀mídé pa mú kí ẹ̀rù ba àwọn ajínigbé.
0
Gbogbo ẹni wọn gbójú lé sígun, fèrè lásán nì wọn múra sile àtifọn lógun.
1
A kì í bí fẹ.
1
"Fojú kàn mí nípa ọrọ àná” ò lásán, (kì í se asán), bí kò fẹgbowó, a jẹ pé ó lọrọo sọ ni.
1
A bímọ kò gbọ́n, a ní kó má ṣáà kú; kí ní ń pa ọmọ bí àìgbọ́n?
1
Wọn kò ní ṣàdúrà ọdún ìtunu àwẹ̀ ní mọ́ṣáláṣí ìlú Ìkàrẹ́.
0
E je a be Ofún, ki a șipẹ f'Ọlọkànràn k'ayélerojú,kigbà ó le gbààyè.
1
Mó ti dáko ewéédú sọ́nà Bẹ́lẹ́njẹ́ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ mi.
0
Ảlè má sàsenù mọ, omọ ń b'ọkọ lọ.
1
Bí a bá bá ẹrán wí, ká bá ẹràn wí.
1
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan gbéra lọ sí ìlú Abẹ́òkuta ní ìpínlẹ̀ Ògùn fún ìwádìí.
0
Dídùn ló dùn tí à ń b'ọrệé j'ẹkọ, tilé oge tógeé jẹ.
1
Èrú pọ̀ gan-an nínú ìdìbò náà ju ohun tí Mínísítà ń lọ.
0
Àwọn òṣìṣẹ́ náà yóò wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n títí ìgbẹ́jọ́ yóò fi wáyé lórí ẹ̀sùn jìbìtì náà.
0
Ẹni wọn fi yáwó-èlé kì í kọrọ ìwọsí.
1
Egbin jẹ́ ẹranko kan tí ó rẹwà tí ó sì yàtọ̀ torí àwọ ara rẹ̀.
0
Fáàrí àșejù, oko-olówó ló ń múnií lọ.
1
Àwọn olùgbé ìlú Ọ̀yọ́ tí àwọn jàǹdùkú lé ni wọ́n ti fọ́n káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
0
Ẹni fáya l'Ẹgbàá, ò póun 'ò fẹ erú. Ẹní fẹ ní Rẹmọ 'ò fóbìnrin.
1
Ọ̀nà tí ẹ̀dá lè gbà láti wá owó pọ̀ jaburata.
0
Àkànnàmàgbò kì í pọdún èșí jẹ, àimahù.
1
Bínú bá konú, pẹwú làá jobì.
1
Ògúnrónbí fi ọ̀bẹ gún ọ̀gá àwọn ọlọ́pàá náà.
0
Apànìyàn ní í ba níi j'ẹkọ eépìnnì.
1
A kì í fi eku kan rẹ ọmọ méji.
1
Ẹní jewọ obùn fún ni làá dásoo ró.
1
Ọkọ àti ìyàwó yóò ṣàlàyé ohun tó sún wọn dé ìdí ẹgbẹ́ òkùnkùn fún ilé ẹjọ́.
0
Ajá ò gbọdọ̀ dé mọ́ṣáláṣí ìkókò ṣàlùwàlá.
1
B'ólówe 'ò bá m'òwe; ẹrù ìjà ló ń bonítọhún.
1
Àsọ̀rọ̀àìlàdí ló pa Elempe ìṣáájú tó ní igbá wúwo ju àwo.
1
Kí ni ipa tí Gómìnà Adémọ́lá ti kó lórí ọ̀rọ̀ náà láti ìgbà tí ó ti ṣẹlẹ̀?
0
Bí asọ ológójì yóò bá fi gbéni subú kí á fi gìgìríse fà á ya.
1
Àwọn kọ̀ọ̀kan jáde láyé látara ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹ̀ nílùú Èkó.
0
Àkùkọ gàgàrà ní ń dájọ́ fúnni láàrin ọ̀gànjọ́.
1
Múìbí sọ pé òun ní ẹ̀gbọ́n kan lókè òkun tó ń fún àwọn èèyàn ní iṣẹ́.
0
Bí òyìnbó bá máa lọ nílùú, a ṣu sága.
1
A gbé ọ ga ẹni ìbẹrẹ̀ àti òpin.
0
Ó sáré gba ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá tó wà ní agbègbè ibi tí ó wà.
0
Àwọn darandaran ń ya wọ gbogbo oko ní ìpínlẹ̀ Oǹdó.
0
Ó ní bí ìjọba bá lè bá àwọn ṣe ọ̀nà, àwọn yóò rí iṣẹ́.
0
Ẹni tí kò ní 'Ba-mi-mu-un' kì í sínwín.
1
Àwọn akẹ́kọ́ọ̀ méjì náà fi ẹ̀mí ìmoore hàn sí ilé-ẹ̀kọ́.
0
Àgbà mẹ́ta ní ń mọ ìdí ẹẹ́ta.
1
Adéjàre kò yọjú sí ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ti kọ̀wé sí i.
0
A ji pọnmi òwúrọ̀ kùtù-kùtù kì í pon omi rúrú.
0
A kì í gbójúu fífò ládie àgádá.
1
Fákẹ́yẹ pẹ̀lú Rìnsọ́lá wọ́yá ìjà lọ́jọ́ náà nítorí Rìnsọ́lá kò gbà fún un.
0
Àjekù làá ma yo.
1
Ayéfẹ́lẹ́ ní àwọn ọ̀dọ́ náà lè di ìlúmọ̀-ọ́nká olórin àti onítíátà.
0
Inú ọkọ̀ ni wọ́n ká Àkànbí mọ́ nígbà tí àwọn ọlọ́pàá sún mọ́ ọn
0
Àlejò tó ń fọwọ́ nusẹ; bó ba jeun tán, bí wàhálà bá dé b'ónilé yóó sá lọ.
1
Àwọn olórin maa n fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n lójoojúmọ́.
0
Àìlówó lọ̀rẹ́ ò sí; bí a bá lówó lọ́wọ́, tajá tẹran ní ń báni tan.
1
Àkèekèe òjògán fìdí jà; ará ilé ẹni-í fojúdini.
1
Gbogbo wa ni a óò jọ lọ síbi òde tí Gbádégẹṣin ní lópin ọ̀sẹ̀ yìí.
0
Ayéfẹ́lẹ́ fẹ́ kí wón mọ̀ pé kìí ṣorin tàkasúfèé nìkan ni wọ́n lè ti fakọyọ.
0
Bí iṣẹ́ kò pẹ́ ẹni, a kì í pẹ́ iṣẹ́ .
1
Lójú rẹ̀ ni gbogbo àwọn tí wọ́n ń bẹ́ mọ́ ọn yóò bẹ́ mọ́ ẹni tó gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀.
0
A kì í b'ọlẹ bèésú, bó kó tán a di akìtiyan.
1
Mẹ́ta nínú àwọn ọmọbìnrin náà sá lọ nígbà tí iyè wọn ṣí.
0
Adéníyì wa ọkọ̀ rẹ̀ ní ìwàkuwà lọ́jọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú náà.
0
Bí a bá de'jú a ó rìí imú.
1
Ẹ̀dá àgbààyanu rè é o!
0
Ayọ̀ da epo pupa nù sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ̀lẹ́.
0
Àṣá ò kú, ara ń ta ẹtù; àwòdì á wo ìgbín kọ̀rọ̀.
1
Ẹ jẹ ṣẹ́kù nítorí ọ̀dá, ìgbà kan ò lọ bí òréré.
0
Ẹni tí a ò fẹ làá yìn ni ibọn ẹnu. À á pé: "Ìwọ yií kę."
1
Atẹ̀hìnrọ́gbọ́n agétí ajá; a gé e létí tán ó fabẹ pamọ́.
1
A kì í fài lẹșin léèkan l'ópìjẹ.
1
Àwọn ènìyàn ní apá Gúúsù ilẹ̀ Afíríkà ń ṣe gbogbo ohun tó wà ní ìkáwọ́ wọn láti dáàbòbò ìlú wọn.
0
Èèyàn gbọdọ̀ mọ ojúse rẹ̀ láti jẹ onítara àti láti má dáwọ́ lé wàhálà.
0
Abẹ́rẹ́ àjẹsára náà ni orúkọ tí wọ́n ń pè é.
0
Àwọn agbófinró ti ránṣẹ́ pe èèyàn méjì ládùúgbò náà.
0
Ijọba ilẹ Gẹẹsi ti ko awọnv aṣoju rẹ at’awọn mọlẹbi wọn kuro lorilẹede Sudan l’asiko igbesẹ maṣafira kan ti awọn ọmọ ogun orilẹede naa ṣe lọjọ Aiku
0
Adię-ìrànà níí ș'aájú òkú délé.
1
Ẹni ń retí pàdé ení ń fẹé wá.
1
B'éégún bá șupa, b'ó șubi, a a f'àbọ sĺgbàlę.
1
Bí 'ò rẹjà a kì í là á. (sọ sí í)
1
Àrùn kò tètè fi ara hàn lára ènìyàn.
0
Abere bo lowo adete ó dète.
1
Ọwọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti tẹ àwọn èèyàn méjìdínlọ́gbọ̀n tí wọ́n ń wa kùsà lọ́nà àìtọ́.
0
Àtamú 'L'olúọde ń ta ẹran.
1
Ajègbodò ń wá ẹni kúnra.
1
Àwọn ènìyàn ti pa ilé ìgbé tì láti dènà ìjàmbá tó lè wáyé níbẹ̀.
0
Bí a bá sotàn ta 'ò leè rọ, ojú níí tini.
1
Ẹní mojú ẹkùn ló ń gbá a ni igbáwo mú.
1
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn kọ̀ láti bá akọ̀ròyìn Aláròyé sọ̀rọ̀ nítorí ìbẹ̀rù.
0
Àwọn ọ̀dọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọọ́fíìsì amòfin àgbà.
0
Bí ọmọdé ń lérí bébé, tí kò ní baba, ti baba là ń ṣe.
1
Èyí ni àtúnṣe tí ìjọba fẹ́ ṣe sí ẹgbẹ́ àwọn ibùdókọ̀ ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
0
B'órí 'ò sunàn, ọgbọn-inú ni kò tó.
1
Asúnkun s'ágbárí fi pamọ ni; ó sì ń padàá bọ. Bí ò wa níkún yóo wá ní kelebẹ.
1
Àkùkọ adìẹ fi dídájí ṣàgbà; ó fi ṣíṣu-sílẹ̀ ṣèwe.
1
Bí a bá pẹja tán, lébé ẹja la fi ńhá ẹja lẹ́nu.
1
Enu ise l'aagoo ń kú sí.
1
Ajiḿọ̀bi gba Mákindé nímọ̀ràn láti gbaradì fún iṣẹ́ tó wà níwájú rẹ̀.
0