Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Àwọn kàn máa ń bú àwọn aráàlú tó bá ń kọjá. | 0 |
Àwọn kan ò fẹ kí Abíọ́dún di Ààre. | 0 |
Wọ́n kéde ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù pé àrùn yìí ti dé àwọn ìgbèríko. | 0 |
A-kó-èésú-má-dàá, ẹrùngbà olè. | 1 |
Arábìnrin kan kígbe lórí ayélujára pé òun wá ọkọ. | 0 |
Àwọn mọ̀lẹ́bí ṣe ìrántí ẹni wọn tó lọ. | 0 |
Àpárá ń lá nikán ń dá; ikán ò lè mu òkúta. | 1 |
Ení gb'óhùn olóbùró lókéèrè, a ni bí ò térin kò ní sài po jefon.Béè ibi olóbùó bá búbú sí, kò tádię. | 1 |
Abísọ́là pariwo Ọlúwa ò, nígbà tí wọ́n yìnbọn fún ọlọ́pàá kan ní ìlú Èkó. | 0 |
A kì í ș'ọdún edì lẹyìn Ọjà, k'Ọjà sunko. | 1 |
Ògúnrónbí jáde láyé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Tolúlọpẹ́ gún un lọ́bẹ. | 0 |
Àwọn ohun kan jẹ́ ohun ìtìjú ńlá fún àwọn òbí. | 0 |
Wọ́n ní òkùnkùn birimùbirimù làwọn yóò wà bí iná ọba bá lọ. | 0 |
A-bánijẹun-bí-aláìmọra, ó bu òkèlè bí ẹ̀gbọ́n ìyá ẹ̀. | 1 |
Àkọ́dá oró kò dà bí àdágbẹ̀yìn. | 0 |
Ẹ̀lúlùú, ìwọ ló fòjò pa ara-à rẹ. | 1 |
Igi dá sí méjì nígbà tí obìnrin náà là á mọ́ ọmọ mi lórí. | 0 |
Àkéte kékeré ò gba èèyàn méjì. | 1 |
Àpà-á fi ọwọ́ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá bọ ẹnu; àpà, a-bìjẹun-wọ̀mù-wọ̀mù. | 1 |
Àárò ìyá àgbà lábúlé ń sọ mi. | 0 |
Àwọn ilé-iṣẹ́ aládàáni epo pẹtiróò kópa púpọ̀ lóri ọ̀rọ̀ owó epo yìí. | 0 |
Àsá 'ò ro t'òròmọ síre. Àánú òkòkó 'ò șÀwòdì. | 1 |
Àgbá òfìfo ní ń pariwo; àpò tó kún fówó kì í dún. | 1 |
Bá wo ni a ṣe máa sọ̀rọ̀ nípa eréṣùpá, tí a ò ní mẹnu ba àlọ́. | 0 |
Adé pa ejò ọka nínú oko rẹ̀ ní ọ̀sá yìí. | 0 |
Alákatam̀pòó ṣe bí ọ̀bọ ò gbọ́n; ọ̀bọ́ gbọ́n; tinú ọ̀bọ lọ̀bọ́ ń ṣe. | 1 |
Ẹ má kìlọ fún 'yàwó àsesegbé kó má re'nú èèkan lọ rèé fún sáárí. | 1 |
Ẹgbẹ́ òṣèlú Alágbàdo sọ pé ìhùwàsí wọn ń tako ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn. | 0 |
Eni buburú wọgbó, iwàa rẹ tọ ọ. | 1 |
A kì í b'ẹnìkan jà fọwọ gún gbogbo ìlé lójú. | 1 |
A kì í wáyé kí a má lárùn kan lára.ljà-igboro làrùn ìbàdàn,Owó-Òde ni tOyọ, ilé-jijó ni ť'Ọfà, má-șu-mátọ ni t'Èkó. | 1 |
Wọ́n sọ wí pé ìgbésẹ̀ Goríọlá yìí jẹ́ èyí tó burú nínú àkọsílẹ̀ ìtàn ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. | 0 |
Ó ṣeni láàánú pé ẹ̀mí ti bọ́ lára ọmọ náà nígbà tí wọn yóò fi yọ ọ́ jáde. | 0 |
B'ọlọbọnhùnbọnhùn bá yó tán; a finú ara rẹ dá gbẹdu. | 1 |
À-gbẹ́rù-àì-wẹ̀hìn lọ̀pálábá fi gbàgbé ìyá ẹ̀ sílẹ̀. | 1 |
Àìlèfọhùn ní ń ṣáájú orí burúkú. | 1 |
Ẹjọ́ bá ọ, bí ọ̀ràn ìkúnlẹ̀-ẹ́ bá arọ. | 1 |
Àtidádé Olókun ò ṣẹ̀hìn òkun; àtidádé Ọlọ́sà ò ṣẹ̀hìn ọ̀sà; àti dádée kìnnìún ò ṣẹ̀hìn Olúigbó. | 1 |
Èèmọ̀ lukutupẹ́bẹ́, sòbìyà Àjàyí, èyí tó dá a lẹ́sẹ̀ tó ń ro ó léhín. | 1 |
Adìẹ funfun ò mọ ara ẹ̀ lágbà. | 1 |
Afẹká l'ayéé fẹná, àrànká l'oòòrún ń ràn. | 1 |
Ìgbésẹ̀ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn fẹ́ gbé yóò mú kí ìrìnnà ọkọ̀ já geere ní ìpínlẹ̀ náà. | 0 |
Àgbà kì í subú yẹkẹ kó da tikùn sílę. | 1 |
Adie fiye seso, eyelé f'eegun senu. | 1 |
‘‘Mo yó’’ ń jẹ́ ‘‘mo yó,’’ ‘‘mo kọ̀’’ ń jẹ́ ‘‘mo kọ̀’’; jẹun ǹ ṣó, àgbà ọ̀kánjúwà ni. ‘ | 1 |
Ẹja t'ó l'óun 'ò bábú șe àwọn máa wọ won bọ. | 1 |
Bí ẹlẹ́hìnkùlé ò sùn, à pẹ́ lẹ́hìnkùlé-e rẹ̀ títí; bó pẹ́ títí orun a gbé onílé lọ. | 1 |
Mo pinnu láti máa dúró sí Ìlọ́tí lẹ́yìn iṣẹ́ ojoojúmọ́. | 0 |
Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan àti ọkọ̀ akẹ́rù sẹrí mọ́ ara wọn nítòsí Ìyànà Ìdọ̀gọ̀. | 0 |
Àwọn ènìyàn kan ní Abíọ́dún nìkan ló lè ṣeé. | 0 |
Aláròyé, olókotoro, onítìjú àwòko tí ń gbónu nínú oko; ó délé tán ó ṣẹnu mẹ́rẹ́n. | 1 |
A kì í fàitó baálẹ șe bí Ọba. | 1 |
Eni wáyé tí ò lówó lọwọ, onítọhún ò ráyé wá. | 1 |
Agbègbè Ọbaléndé ní ìpínlẹ̀ Èkó ni wọ́n ti mú ọkùnrin náà. | 0 |
Bí ọmọdé bá ń bẹ́ igi, àgbàlagbà a máa wo ibi tí yóò wòó sí. | 1 |
A-gúnyán-sanyán kì í bẹ̀rù òkèlè. | 1 |
Àwọn ènìyàn fò fún ayọ̀ lórí ìfilọ́lẹ̀ ààyè wíwa epo inú ìlú wọn. | 0 |
Dànìdànì kì í bá wọn l'ágbálágbá, kékeré ló ti ń bà wọn-ọn lọ. | 1 |
Àwọn ọlọ́pàá fi ẹ̀sùn kan Olájídé. | 0 |
Adéyanjú ti kó sí akóló àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ orí gádà nílùú Abẹ́òkúta. | 0 |
Àsá, fi fífò gbayì láwùjo eye-oko. | 1 |
Akátá ń dÍfá, ẹtà ń dìbò, ìkamùdùn ń yìnbọn ìdí; wọ́n ní kí ní ń rùn? | 1 |
Bí a bá kìlọ̀ fólè, ká kìlọ̀ fóníṣu ẹ̀bá ọ̀nà. | 1 |
Àto-eré n'ọn fi bẸșin. | 1 |
‘‘Gba ọmọ fún mi kí n rèdí’’; bí ìdí ò bá ṣe-é re ká gbọ́mọ fọ́lọ́mọ. ‘ | 1 |
Ikọ́ wà lára àwo àìlera tí àjàkálẹ̀-àrùn ń mú dání | 0 |
Àwọn tí wọ́n ń kí Bíọ́lá ń gbàdúrà fún ìyá àti ọmọ. | 0 |
Agada ò morí alágbẹ̀dẹ. | 1 |
Ẹni tí kò nírú asọ, kò leè mọyì așọ. | 1 |
Àwọn èèyàn kan sọ pé kí Dámilọ́lá má yọ ohun ìfètò-sọ́mọ-bíbí tó wà lára rẹ̀. | 0 |
Àwọn ènìyàn kan rò pé oníjọ̀gbọ̀n ni Àdìsá. | 0 |
Àṣá ò leè bá kowéè ké. | 1 |
Àwọn mẹ́rìndínlógún ni wọ́n gba fọ́ọ̀mù nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Onígbàálẹ̀. | 0 |
B'éèyàn (bẹdàá) ń yolệệ dà, ohun wẹrẹ wẹrẹ abẹnú a máa yọ o se. | 1 |
Àsìkò ìtura ni àsìkò ààwẹ̀ jẹ́ fún gbogbo àwọn mùsùlùmí. | 0 |
Bí Ọlọ́run bá páni lórí, a fi irùngbọ̀n dípò-o rẹ̀. | 1 |
Àsárébá ní ń mú ìrìn yá. | 1 |
Firífirí yá ju òkolobo. | 1 |
Akíni ń jẹ́ akíni; afinihàn ń jẹ́ afinihàn; èwo ni ‘‘Ọ kú, ará Ìjàyè!’’ lójúde Ògúnmọ́lá? | 1 |
Ayéfẹ́lẹ́ ti ń kọrin láti ọjọ́ pípẹ́. | 0 |
Kò sí ìfọ̀kànbalẹ̀ fún Adégbémilé nínú ìgbéyàwó. | 0 |
Alukoro ètò ìròyìn fún Abíọ́lá sọ pé lóòótọ́ ni ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan alátakò wọn. | 0 |
Ìjà wáyé ní ilé epo ẹ̀bá-ọ̀nà ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú tó kọjá. | 0 |
Ó sọ pé nítorí àárẹ̀ tó ń ṣe é ni òun ṣe fi í sílẹ̀ nínú yàrá. | 0 |
A kì í bá Olójòngbòdú du omi òwúrọ. | 1 |
Ilé ẹjọ́ dá ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta fún Olúṣọlá àti Ògúnrónbí. | 0 |
Abiyamọ ọ̀tá àgàn; ẹní ń ṣiṣẹ́ ọ̀tá ọ̀lẹ. | 1 |
Páítọ̀ ilé ìjọsìn ìjọ Ìràpadà kan ni àwọn ajínigbé tún jí gbé. | 0 |
Arákùnrin kan bú sẹ́kún lẹ́yìn tí ó fi owó iyebíye ta tẹ́tẹ́ tí ó sì pàdánù rẹ̀. | 0 |
Ẹrẹkẹ olókún rùna 'á wú kó í bẹ. | 1 |
Ara líle loògùn ọrọ̀. | 1 |
Bí ènìyàn ń sọ̀kò sí àárín ọjà, ó máa ní ọ̀rẹ́. | 0 |
Adégbémilé sọ pé ìyàwó òun àti ìyá rẹ̀ kò fi òun lọ́kàn balẹ̀. | 0 |
Bírí-bírí layé ń yí bẹ́ẹ̀ ni àwa ẹ̀dá inú ẹ̀ ń yí pẹ̀lú. | 0 |
‘‘Yó bàá ọ,’’ kì í ba ẹnìkan mọ. | 1 |
Gbogbo ìlú wúre tinútinú fún ọba Owólabí pé ìgbà rẹ̀ yóò rọ ìlú lọ́rùn. | 0 |
Mi ò ní sè é rọ̀ bí mo bá máa kojú ẹni tó lè ṣe mí léṣe. | 0 |
Olùjẹ́jọ́ ṣẹ́ lórí gbogbo ẹ̀sùn tí ọkọ rẹ̀ fi kàn án. | 0 |
Ẹni 'ò sáré 'ò bá Șàngó, ẹní pẹ d'óde 'ò b'Ọya. | 1 |
Dídì là á kọkọ diyọ, kí a tó tú u. | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.