Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Kò sí àpèjúwe tí ènìyàn lè ṣe lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọmọ kékeré tó kó sí kọ̀ǹga. | 0 |
Àfowórọ́wó laláròóbọ̀-ọ́ fi là; àfowórọ́wó sì laláròóbọ̀-ọ́ fi dígbèsè. | 1 |
Ení máafonkun yín, eni máa lé tìróò, áá bètè je (á á sète àá fey perese) | 1 |
Gbogbo wa la jùmọ fòkété san ọgọfà, b'ókèété ó ó bá fi ď'ogóje, ojú gbogbo we, ló yę kó șe. (ojú wa ni yóó se). | 1 |
Àwọn jàndùkú yabò àwọn olùwọ́de ní Aláúsá l'Ékòó. | 0 |
Arúgbó ṣoge rí; àkísà-á lògbà rí. | 1 |
Àwọn panápaná ti ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti fòpin sí iná ńlá tó ṣẹ́yọ. | 0 |
Àrẹ̀mú ni ó yẹ kó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀sun. | 0 |
Ẹkọ 'ò bu l'ójú ogun. | 1 |
A kì í tún ẹbọọ rú, babaláwo là á yìn. | 1 |
Esinsin tó b'ọdẹ rìn; a á mẹję (mu eję) | 1 |
Àfikún owó náà pọ̀, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pariwo síta. | 0 |
Àwọn ọlọ́pàá ti gba ọ̀kadà tó jẹ́ mọ́kànlélógójì. | 0 |
Ẹlẹ́ẹ́fà kì í lọ ẹẹ́fà-a rẹ̀ ká sọ pé o di ìjẹfà tí a ti jẹun. | 1 |
Díẹ̀-díẹ̀ là ń mọ àpẹrẹ. | 1 |
Elérií (eléfòó) kì í kẹyìn (gbẹyìn) sọjà. | 1 |
Bójú ò bá r'óhun bí okùn, kò leè r'óhun bí idẹ. | 1 |
Bí a bá ti kárí așọ, àgbà làá mu ú fún. | 1 |
Àìsàn pa ẹni àkọ́kọ́ ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kìíní. | 0 |
Eni tó ranni nise ń retí eni. | 1 |
Olóògbé kò ṣàìsàn débi tí yóò ní àrùn ọpọlọ. | 0 |
Àgbò dúdú kọjá odò ó di funfun. | 1 |
·Epo-òyìnbó kì i sùn. | 1 |
Bọ̀rọ̀kìnní àṣejù, oko olówó ni ń múni lọ. | 1 |
Alágbàró ò yege; aláṣọ á gbà á bó dọ̀la. | 1 |
A máa ń dá àwọn èèyàn dúró láti ṣe àyẹ̀wò wọn. | 0 |
Bí a kò rówó ra ẹrú, à sọ adìẹ ẹni lórúkọ. | 1 |
Àwọn oníròyìn ṣe ìwádìi lórí nǹkan tó mú làásìgbò bá ìlú Ọ̀tà. | 0 |
Omi gbé ọ̀kadà kan lọ ní Ìsọ̀-màlúù. | 0 |
Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré ni Bámgbọ́lá bá Àjíún láṣepọ̀. | 0 |
Àlàyé rèé lórí ìdí tí mo ṣe dáná sun Mọ́ṣáláṣí. | 0 |
Àtẹ̀gbé lẹsẹ̀ ń tẹ ọ̀nà. | 1 |
Ẹrẹ Òkè-Ọdàn ni yóò kìlọ fún alárỏoógbále-aso. | 1 |
Ẹ sọ fún Bọ́lá pé kó sọ ibi tí ó ti rí owó ńlá tó wà lọ́wọ́ rẹ̀. | 0 |
Ẹní a pé kó féni lójú, ata ló fi senu. | 1 |
Àjòjì tó ń ș'ọtẹ, ó ń jọhun. | 1 |
Ó ti tó ogójì ọdún tí olóyè Àdìgún ti di olórí Ọlọ́ṣun ìlú Òṣogbo. | 0 |
A-mòòkùn-ṣolè, bí ọba ayé ò rí ọ, tọ̀run ń wò ọ́. | 1 |
Àijonilójú lọsàn-án, la fi ń jarunpá luni lóru. | 1 |
A kì í fi oko sin fún ìwọ̀fà. | 1 |
Àwọn ọmọ ìjọ nípé ejò lọ́wọ́ nínú lórí ìdájọ́ tí wọ́n dá fún olùṣọ́. | 0 |
Ẹgbẹ́ aṣòfin ilẹ̀ yìí ní ìjọba ń tẹ ẹ̀tọ́ olùdíje ààrẹ́ tẹ́lẹ́ náà lóju | 0 |
A kì í dúró nílùú ká fara hẹ. | 1 |
Àwọn ará ìlú kò fẹ́ ohun tí yóò ba ilẹ̀ wọn jẹ́. | 0 |
Àwọn aráàlú kò rí irinṣẹ́ tó tó láti kojú iná náà. | 0 |
Eyin tí ẹ ní baba, tí ẹ ń jijà-ẹbi, baba yín fẹệ kú ná. | 1 |
Ẹni tí yóó ròyìn ogun 'ò ní kú. | 1 |
Ààrẹ àgòrò tó bá gbójú, tòun tolúwa-a rẹ̀ lẹgbẹ́ra. | 1 |
Adé rí mi ní ilé-epo ní ìjẹ́ta. | 0 |
B'Ọba bá ń túsu, tÁrẹmnọ rẹ n tẹ e, ó lójú obinrin-ilé tí yóó péwọn ó bun òun níșu ję. | 1 |
Ẹnu táyé fi ń p'Adégún, ni wọn fi ń pAdéògún. | 1 |
Àjọ ètò ìlera àgbáyé ń gbé ìgbésẹ̀ láti buwọ́lu abẹ́rẹ́ àjẹsára náà. | 0 |
Àwọn ará àdúgbò ibi tí Fọlọ́runṣọ́ ń gbé ni wọ́n rí fọ́nrán náà. | 0 |
Àtẹ́lẹ́wo f'òde sọkan, àtàmpàkò ló ya'ra ẹ̀ sọ́tọ̀. | 1 |
Èèyàn ò ríbi sùn, ajá ń hanrun. | 1 |
Lẹ́yìn-ò-rẹyìn ni wọ́n rí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ọ̀hún lọ́wọ́ Ẹ̀mílójù. | 0 |
Bí Básè ò sè, kí ni Bálá ó làá? | 1 |
Agbègbè Sùúrùlérè ní ìlú Èkó ni wọ́n bí Balógun sí. | 0 |
Ohun tí Adérántí gbé ṣe ló jẹ́ mánigbàgbé fún àwa mọ̀lẹ́bí rẹ̀. | 0 |
Bàbá Àdìsá ló jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún ọmọ rẹ̀ lórí kó lè dáa fun. | 0 |
‘‘À ń jù wọ́n’’ ò ṣéé wí lẹ́jọ́; ìjà ìlara ò tán bọ̀rọ̀. | 1 |
Bọla Ige ti kú, ọjọ́ pẹ̀ dí, àwọn nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa rẹ̀ rè é | 0 |
Àgbàlagbà kì í wẹwọ́ tán kó ní òun ó jẹ si. | 1 |
Asọrọșẹ kì í s'ọròó dànù. | 1 |
Àparò tó dúró lórí ebè, kó dúró tìfura-tifura. | 1 |
Àwọn aráalé sáré sí Ọmọ́tóyèṣe láti wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i. | 0 |
Dábírì ti fèsì lórí ọ̀rọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Òmìnira. | 0 |
Ẹgbẹ́ onígbàálẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ tí olóyè Láyíwọlá sọ kì í ṣe irọ́. | 0 |
Bí ó ti mọ ní ó mọ ọkọ ìyàwó ó ṣe ìlọ́dìí | 0 |
A kì í kunmọ l'ósùn tán, kí a fọwọ ẹ nu òpó-ilé. | 1 |
Bí a bá fi inú wénú, iwọ là ń jẹ. | 1 |
A-dùn-ún-jẹ bí àjẹpọ̀. | 1 |
Àwọn olùgbé Ayétòrò ní ó sàn káwọn kú. | 0 |
Asọ títun ló ń ș'olówó 'ẹ bí òde, bí òdè. | 1 |
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. | 0 |
Alárinká s'àgbà abewú. | 1 |
Ẹsẹ olóde kì í tòde kúrò. | 1 |
A kì í dáke á sì wí. A kì í wò sùn-ún dáràn. A kì í ríbi leyìn-in 'Hòo'. | 1 |
Ààrẹ gbọ́dọ̀ ṣe ìwádìí lórí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. | 0 |
Àjọ̀dún ìdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ lárinrin. | 0 |
Àjùmọ̀bí ò kan ti àrùn; kí alápá mú apá-a rẹ̀ kó le. | 1 |
‘‘Mo kúgbé’’ lehoro ń dún lóko; ‘‘Mo mówó rá’’ làparò ń dún lábà-a bàbà. | 1 |
Àwọn ẹyẹ pọ̀ sí ojú ọ̀nà àbáwọlé. | 0 |
Àìlówó-lowọ Olúbàdàn, a ò lè fi wé Báalẹ Lálúpọn. | 1 |
Akínlàdé Àbáyọ̀mí rọ́pò ọmọ Balógun gẹ́gẹ́ bíi alága àwọn ọlọ́kọ̀. | 0 |
Ẹni a jùlọni 'ò mowọn ara rẹ. | 1 |
À ń rìn nílẹ̀ inú ń bi ẹlẹ́ṣin, à ń jẹ̀fó sùn inú ń bí ẹlẹ́ran | 0 |
Àkísà m'ọ'wọn ara 'ẹ, párá ló ń gbé. | 1 |
Ẹní tí kò bá ni í jẹ nínú ogún ní í pin in. | 1 |
‘‘Ta ní ń bẹ níbẹ̀?’’ làgbẹ́ fi ń sán ìbàǹtẹ́ wọ̀lú. | 1 |
Àwọn èèyàn ń gbọ́ orin tuntun tí Òkìkíọlá kọ. | 0 |
Ọ̀gá ọlọ́pàá ẹ̀ka Ewu-Olíwo tẹkọ̀ dé ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà nígbà tí ó gbọ́. | 0 |
Adiẹ kì í șubú, ẹgẹ níí yę. | 1 |
Fèré ló ré kọjá ọná mo se bí ẹmọ ni. | 1 |
Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ Ìbò fẹ́ mọ iye gbogbo àwọn ọmọ wọn. | 0 |
Bí a bá ní mọ̀, ọ̀mọ̀ràn a mọ̀ ọ́. | 1 |
Ẹgbẹ́ òṣèlú kan ṣàlàyé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ààrẹ bó ṣe ń ṣàjọyọ̀ ọ̀jọ́ ìbí. | 0 |
A kì í fi ọ̀ràn-an pápá lọ ẹja; a kì í fi ọ̀ràn-an odò lọ àfè. | 1 |
Àwọn àjọ kan ń wá ìdájọ́ tó tọ́ lórí rògbòdìyàn jíjí ǹkan ìjọba. | 0 |
Aláșọ àlà kì í seré désọ elépo. | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.