Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Èké kú, a gbẹ́lẹ̀ ó kan òkúta. | 1 |
Agbẹjọ́rò kan fẹ́ kí Babájídé farahàn níwájú ìgbìmọ̀. | 0 |
Bí ẹlẹ́dẹ̀ bá pàfọ̀ tán, ẹni rere ní ń máa-á wá fi yí lára. | 1 |
Bí a bá fasọ wé'șọ, a á kánná sí tẹni ni. | 1 |
Bí ológìnní bá lọ sájò tó bọ̀, inú èkúté a bàjẹ́ . | 1 |
Bi a 'ò bá dáșo l'áșọ; a kì í pè'kan lékiísà. | 1 |
Ẹdẹ l'Atẹẹrẹ ti níyì l'Óòșà. | 1 |
Àwọn afọbajẹ sọ wí pé Adégún ni Ifá rẹ̀ kún jùlọ. | 0 |
A-wí-fúnni-kó-tó-dáni, àgbà òmùjà ni. | 1 |
Asọrọdáràn, ẹnu ara rẹ ni yóò fì tán an. | 1 |
Gbọnmogbọnmọ là á rọfá adití. | 1 |
Àwọn olóṣèlú tó ń díje ni wọ́n gba iṣẹ́ ọ̀hún ṣe. | 0 |
Egbìn kò jọ elọ (jẹ lọ), opó ò jọ àtowọfę. | 1 |
Onídàájọ́ sọ pé kí olùjẹ́jọ́ ṣì wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n gẹ́gẹ́ bí ìbéèrè agbèfọ́ba. | 0 |
Oyètọ́lá sọ pé ó dá òun lójú tádàá pé òun kò ní pẹ́ gba ipò òun padà. | 0 |
Aboyún kì í gbọn kílẹ má jẹ lára ẹ. | 1 |
Fọrọ síkùn bí àgbà; fi gbígbọ saláigbọ. | 1 |
Bi o rí o wi, àiwí lese. | 1 |
Ajá tó jẹ líìlí, enu rẹ ó ṣẹjẹ. | 1 |
Ẹni mutí ogójì, yóó sọrọo okòó. | 1 |
Ṣọlá feré ge nígbà tí ìbọn ọwọ́ rẹ̀ kò yìn mọ́. | 0 |
Àwọn mìíràn lè ní àrùn yìí láìsí àmì kankan. | 0 |
A kì í fi ẹ̀jẹ̀ ìbálé pa tírà; alákoto ò bí abo ọmọ. | 1 |
Àgbàlagbà Àáfà ló ń jẹ Ráájí. | 1 |
Wọ́n tẹ́wọ́ gbogbo àwọn nǹkan dáradára tó wá láti ilẹ̀ àjèjì. | 0 |
Ọmọwúrà ṣe iṣẹ́ ọkọ̀ wíwà fún ìgbà díẹ̀. | 0 |
Òkú àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ wà nílẹ̀ níbi tí ọkọ̀ tẹ̀ wọ́n pa sí. | 0 |
Ẹ kú ọdún, ẹ kú ìyèdún, ẹ̀mí wa ó ṣe ọ̀pọ̀ rẹ̀. | 0 |
Bíbì là á bí odò wò, kí a tó rọ lù ú. | 1 |
Àwọn agbébọn ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri àwọn ìgbèríko. | 0 |
Àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè rọ̀ àwọn ikọ̀ méjèèjì láti dáwọ́ ogun dúró. | 0 |
A gbọ́ wí pé àwọn ọlọ́pàá mú Adébísí lórí ìwà láabi tó hù. | 0 |
Arábìnrin kan já ara rẹ̀ sí ìhòhò ní Ìkẹjà. | 0 |
Abẹ́rẹ́ tó wọnú òkun ò ṣéé wá. | 1 |
Eégún Mọgají ni orúkọ ìnagijẹ Wàídì Àyìnlá Ọmọwúrà. | 0 |
A ò mọ ohun tí eléwé-e gbégbé ń tà kó tó sọ pé ọjà ò tà. | 1 |
Agílítí, a-bara-yíyi. | 1 |
B'Ókèété bá j'Àràbà, k'Áse náà jOjùgbọnà. | 1 |
A kunle a yan ipín, a d'áyé tán ojú ń kán gbogbo wa. | 1 |
A kì í gba àkàkà lọ́wọ́ akítì; a kì ígba ilée baba ẹni lọ́wọ́ ẹni. | 1 |
Àṣìwí ò tó àṣìṣe; àṣìṣe ò tó ká múra ọ̀run. | 1 |
Àwọn aláṣẹ Arò kì í wá ọ̀nà láti tan ẹ̀rọ amúnáwá. | 0 |
A kì í dàgbà Ọjẹ kí a má níkà nínú. | 1 |
Àiì-lápá làdá ò mú, ọmọ-Ówú seé gégi. | 1 |
Ìyá ọ̀daràn akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún ló ni ilé tí wọ́n dáná sun. | 0 |
B'irókò méji bá dúró tira, èyí tí ó láyà jù ni yóó máa gbebo | 1 |
Àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú kan pinnu láti yọ olórí wọn. | 0 |
Dùdù ilé 'ò mọ'bẹẹ sè, pupa tó mọ o sè, ó ràjò. | 1 |
Bákan náà, wọ́n kọlu ilé ìjọsìn àgùdà ní ìlú Ojúmọ́. | 0 |
Ìjọba yóò fi páńpẹ́ òfin gbé ẹnikẹ́ni tí ajere ìwà ìbàjẹ́ bá ṣí mọ́ lórí. | 0 |
A kì í fi ìtìjú kárùn. | 1 |
Àyọ̀ká, ọmọ ẹnìkan ló kù. | 1 |
Àtánrán ti mọtàn, ẹni à n tàntí gbọn. | 1 |
Bí ìṣẹ́ bá ń ṣẹ́ ọ̀dọ́ láṣẹ̀ẹ́jù, kó lọ sígbó erin: bó bá pa erin ìṣẹ́-ẹ rẹ̀ a tán; bí erín bá pá a, ìṣẹ́-ẹ rẹ̀ a tán. | 1 |
Àjàgbé ṣe àlàyé pé gbogbo rẹ̀ náà ni ọmọ òun ti gbọ́. | 0 |
Ẹ wo bí ìjíròrò tó dán mọ́rán ṣe ń lọ láàárin àwọn ọmọ orogún. | 0 |
Ẹyin lohùn, bó bá ti bọ (fọ) kò seé kó mo. | 1 |
Àwọn agbébọn náà pa obìnrin méjì àti ọkùnrin méjì tí wọ́n wà nínú ọkọ̀. | 0 |
Bí a ò bá ta èèyàn wò, a kì í mọ bí yóò jòó, bí kò ní jó. | 1 |
Babatúndé kò mọ̀ pé agbófinro ni Ọ̀gbẹ́ni Mobọ́lájí, nítorí kò wọṣọ iṣẹ́. | 0 |
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ẹdó ti fọnrere àtìlẹyìn fún Òjó. | 0 |
Tàbí ṣé ibi tí wọ́n ti yọ ọ̀bẹ àti dágà sí i ló ti máa yanjú wọn. | 0 |
Ayé ò si lọ́wọ́ afàgbọn mu gààrí, igi ló fi ń mugi (jegi). | 1 |
Bí a sọpọ òògùn-isọyè f'ọmọ tí kò níyẹ;isóni yóó fi só. | 1 |
Ènìyàn méje kò tó láti ṣe iṣẹ́ àkànṣe tí a fẹ́ ṣe. | 0 |
Fùú l'alágbára ń dìde. | 1 |
Àkànbí dèrò ọ̀run nítorí 'Eré orí ẹní' ní ìlú Èkó | 0 |
Adẹ́tẹ̀ ní òun ò lè fún wàrà, ṣùgbọ́n òun lè yí i dànù. | 1 |
Bí a jù abẹbẹ sókè nígbà igba, ibi pẹlẹbẹ ni yóó máa fi léle. | 1 |
Ayé lòyìnbó ń jẹ kú. | 1 |
Ààrẹ ìlú Òmìnira ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ wíwa epo rọ̀bì ní agbègbè Kówópé. | 0 |
Àrà 'ò seé dá lẹyìn așọ. | 1 |
Apá ọba ò lè ka ìjọ̀gbọ̀n tí ó ń fà lẹ́sẹ̀ yìí nítorí ìlú ló ń bá fà á | 0 |
Bámgbọ́lá fẹ́ràn àti-máa ṣiṣẹ́ alágbàṣe fún àwọn àgbẹ̀. | 0 |
Àdánù ó kéré, ó tóbi ọlọ́run ò ní jẹ́ a kò ó. | 0 |
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ń kan sáárá sí Dámilọ́lá. | 0 |
Ọlọ́pàá gbé òkú Alékúwọdò tí ó ti ń rùn jáde nínú ọkọ̀. | 0 |
Bí ọ̀pọ̀lọ́ bá fẹ̀hìn lélẹ̀, nǹkan ló ń ṣe é. | 1 |
Bí ọmọdé ò rí àjẹkù-u kìnìún nínú igbó, a ní kí ẹran bí ẹkùn ó pa òun. | 1 |
Àfenù ni ti ìyàngbò. | 1 |
Ẹsan kì í ràjò gbé sájò. | 1 |
Àwọn olùkọ́ fásitì kú láàárín oṣù méje. | 0 |
Bí Ọlọ́run ò pani, ẹnìkan ò lè pani. | 1 |
Àwọn èèyàn máa ń fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí mi lórí ayélujára pé àwọn fẹ́ kọ́ iṣẹ́ lọ́dọ̀ mi. | 0 |
Ení mọ èwe arúgbó ló leè rà á lọwọn-ọn. | 1 |
Akọ̀wé ìròyìn fún igbákejì ààrẹ ni Láolú Àkàndé. | 0 |
Àwúyẹ́wúyẹ́, àròyé ọ̀tẹ̀; wọ́n ní kí wọ́n tún ìlú ṣe, wọ́n fẹ́ẹ́ tú ìlú. | 1 |
A kì í léku méjì ká má pòfo. | 1 |
Kò sẹ́ni tó mọ̀ pé Òkìkíọlá ti gbalé fún Olorì Dámilọ́lá. | 0 |
Bí a bá ń gúnyán nínú ewé, tí à ń sebẹ̀ nínú èèpo ẹ̀pà, ẹní máa yó á yó. | 1 |
Bọtùn-ún bá kú ní, à f'òsì bẹra. | 1 |
Gbádégẹṣin ní ṣíṣe ní Ayédé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta tó ń bọ̀ yìí. | 0 |
Egbin omi kì í pani. | 1 |
Ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tí Olúmúyìíwá ṣẹ̀ṣẹ̀ rà ti bọ́ sínú omi. | 0 |
Ata sápá Dúpẹ́ lórí níbi tó ti ń sọ̀rọ̀ nídìí oúnjẹ. | 0 |
Díẹ díẹ là á mú àpẹẹre. | 1 |
Òkúnẹ́yẹ fi àwọn àga ìjókòó onílé ṣètọrẹ àánú lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tó ti ń ṣẹ̀wọ̀n. | 0 |
Bí ìlàrí bá fẹ́ẹ̀ tẹ́, a ní kí lọba ó ṣe? | 1 |
B'ásę bá ń bínú, kòkò-ògì 'ò gbọdọ bínú, kẹlẹkọ lè bàa rí dá. | 1 |
Ajẹlójú-onílé; kì í jẹ lójú Ológìnní; kó mú u jẹ | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.