Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Àì-fojú-kan-ara-ẹni ò j kí ọ̀tẹ̀ ó tán. | 1 |
Fífọ ọwọ́ déédéé wà nínú ọ̀nà láti dẹ́kun àjàkálẹ̀-àrùn. | 0 |
B'á a níyàá là á hùn; b'á a hún sí tẹniẹleni a gbáni nígi. | 1 |
Àgùntàn tó bá ajá rìn á jẹ̀gbẹ́ . | 1 |
A kì í mọ ọ̀nà ọgbà ju ọlọ́gbà lọ; ẹní múni wá là ń tẹ̀lé. | 1 |
Àìgbọ́ra-ẹni-yé ni ó jẹ́ kí agbófinró ṣi Olúdélé mú ní ọ̀daràn. | 0 |
Àkànní fàbínú yọ lórí ọ̀rọ̀ ìkíni tí ìyàwó ìbejì rẹ̀ Lọlá Ọmọ́táyọ̀ kọ. | 0 |
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn lùgbàdi àjàkálẹ̀-àrùn níbi ọdún ìbílẹ̀. | 0 |
Onímọ̀ nípa ọrọ̀ ajé ṣàlàyé pé Nàìjíríà ń gba àmọ̀ràn lọ́wọ́ àjọ ayánilówó àgbáyé. | 0 |
Báǹkì ayánilówó ti kógbá wọlé. | 0 |
Dan-dan kì í sélẹ̀. | 1 |
Àlàbí ní àwọn oníbàárà tí ó máa ń ta ọjà fún. | 0 |
Èèyàn níí șelégbè l'ẹyìn ọkọ, ọkọ ò leè dóko ro. | 1 |
Ení fi agbádá wa kẹkẹ, ara ikú ló ń yá a. | 1 |
Ẹgbẹ́ òṣèlú Alágbàdo sọ wí pé igun Làmídì kò yẹ nínú ẹgbẹ́. | 0 |
Olówólafẹ́ ní kí ìjọba Oǹdó jọ̀wọ́ jàre bá àwọn fi wọ̀rọ̀kọ̀ ṣe àdá. | 0 |
Bàbá Ọlọ́ṣun sọ pé ilẹ̀ Adúláwò nìkan ló ń ta ẹ̀sìn wọn nù. | 0 |
Buhari gbósùbà káre fún ikọ̀ agbábóòlù Nàìjíríà fún iṣẹ takun-takun wọn. | 0 |
Ìyẹ̀wù kékeré kan ni ibi ìṣeré. | 0 |
‘‘Ó mọ́ mi lọ́wọ́’’ ní ń di olè. | 1 |
Esinsin ò ní Dáwúdù, Èèrà 'ò lÁrẹmọ. | 1 |
B'ọrọ lu okùn, tó lu pampẹ, òwe l'ọlọgbọn fi n tú u. | 1 |
Bó pẹ́ bó yá yóò lẹ́yìn fún gbogbo wọn. | 0 |
Èèyàn-án dára ó ku ìwà; ilé dára ó ku ìgbé. | 1 |
Àwọn ọlọ́pàá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fọ́n ọta tó wà nínú ìbọn ọwọ́ wọn dànù. | 0 |
Àjọsùn ní ń mú iná wá sáṣọ. | 1 |
Àáyá yó níjọ́ kan, ó ní ká ká òun léhín ọ̀kánkán. | 1 |
Àwọn èèyàn tó fèsì lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà pọ̀. | 0 |
Bí a bá ni eégún-un baba ẹni ó jòó, tí kò jó, ọ̀ràn kọ́. | 1 |
Enu nibo Orí. | 1 |
Àwọn ènìyàn ń ṣi orúkọ, ọjọ́ ìbí àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ nínú ètò ìforúkọsílẹ̀ fún nọ́ḿbà ìdánimọ̀. | 0 |
Alángbá tó dùró lórí Èșù, tòun tÈșù lelejo. | 1 |
A wo fọ́nrán kan ni ìrọ̀lẹ́ àná. | 0 |
Àlàáfíà baba ọ̀rẹ́ . | 1 |
Àjọ náà rọ̀ gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí yóò ṣe ìdánwò láti yẹra fún àkóbá. | 0 |
Ànìkànrìn ejò la fí ń f'àdá pa á. | 1 |
Àkùkọ ń kọ kekeréèkeè. | 0 |
Àwọ tí Tòtó mú wa'yé, ló máa mú rọrun. | 1 |
Eégún níí s'owo pó, atókùn níí s'àyà gegesì, isowọ mo-wá-wòran níí sẹ'sẹ pó pò pó. | 1 |
Ààrẹ Bọ̀bádé fún Tóbi ní àmì ẹ̀yẹ ìdánimọ̀. | 0 |
Ṣọ́jà tó gún Bùnmi lọ́bẹ ti wà láhàámọ́. | 0 |
Àjẹ́gbà ni ti kọ̀ǹkọ̀. | 1 |
A kì í ṣe ọ̀jẹ̀ ṣe ojú tì mí; konko lojú alágbe. | 1 |
A kì í bun ni lóńjẹ tán kí a fi oògùn ìgbọnsẹ tì í. | 1 |
Esinsin kì í mọni, kó tó bà lé ni. | 1 |
Ara la mọ̀, a ò mọ inú. | 1 |
Gbogbo ọrọ níí s'ojú èké. Ibi gbogbo lọlẹe wà. | 1 |
Bàbá Jídé nà ọmọ rẹ̀ lọ ilé-ìwé nígbà tí kò fẹ́ lọ. | 0 |
Àwọn olùdíje pariwo pé èrú ti wọ ìdìbò tí wọ́n ṣe. | 0 |
Ẹní gun àjà, ò bu ọrun dé. Ẹní gun pẹpẹ, ó b'òkè se. | 1 |
Akíni-kúuṣ ńjiyán yó; apòyì-kábà ńyá ìwọ̀fà; olóko ńpa ẹgbàa-gbẹ̀ẹdógún kó tó jẹun. | 1 |
A-pèèpò-lẹ́hìn-àgbà, àgbà ḿbọ̀ wá. | 1 |
Mo bẹ obìnrin onípọ̀nmọ́ pé kó máà bínú àná. | 0 |
Àkànní gbọ́dọ̀ fowó kún owó oṣù tó fẹ́ san fún àwọn asòfin. | 0 |
Ejò kì í ti ojú Ààrẹ gun ọgbà lọ. | 1 |
Àjọ tó ń ṣègbèfábo ti rọ àwọn obìnrin láti má dúró sínú ìgbéyàwó tí kò dára. | 0 |
Wọ́n ti fi orúkọ àwọn agbésùmọ̀mí sínú ìwé ìròyìn. | 0 |
Ìjọba ti kéde ọjọ́ tí wọn yóò sin òkú Ràúfù. | 0 |
Akíni ń jẹ akíni. Afinihàn ń jẹ a finihàn. Èwo ni 'pẹlé o ará ljàye'lójúde Ogúnmolá? | 1 |
Bílé bá ga, lágajù, wíwó níí wó. | 1 |
Àjèjé ọwọ́ kan ò gbégbá karí. | 1 |
Àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n ń ṣeré ti fọ́ gíláàsì ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. | 0 |
Ilé ìwòsàn Ẹ̀mílàgbà sọ pé àwọn kò rí ẹ̀rí kankan tó tọ́ka sí i pé iṣẹ́ abẹ tó ṣe ló pa á. | 0 |
Agbàtá l'abiamọ ń gbàjá m'ọmọ ę. | 1 |
Àwọn mẹ̀kúnnù ń pariwo pé ìnira náà pọ. | 0 |
Àwọn tó lùgbàdi àjàkálẹ̀-àrùn láàárin ọjọ́ mẹ́fà kò lóǹkà. | 0 |
A ò ní fowó kún ọkọ̀ ojú irin nítorí àwọn mẹ̀kúnnù. | 0 |
Agbègbè Òkè-Ìléwó ni ọjà tí àwọn adigunjalè fọ́ ní àṣálẹ́ Ọjọ́ru tó kọjá wà. | 0 |
Àkókò yìí ni Tóbi fi jáwé olúborí. | 0 |
Gbogbo akitiyan láti lè bá agbẹnusọ fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun já sí pàbo. | 0 |
Ejò ì bá sokùn, a bá fi digi bọ oko. | 1 |
Elétí-ọfẹ sùn etí ẹ 'ò sùn. | 1 |
Gege ló se; ọmọ wọn lóde Ọhan. | 1 |
Àwọn àkàndá ẹ̀dá ti fàáké kọ́rí. | 0 |
Gbogbo àkàșù kọ ló ń fojú kan ẹfọ. Gbogbo ọmọ-Ọba kọ ló ńdádé. | 1 |
Ẹnu Ìbọn fi ń fọhùn, nìbọn f ií sẹgun. | 1 |
Àyìnlá Ọmọwúrà fi àwo orin kan ki àwọn obìnrin tí wọ́n ń ta ọtí. | 0 |
Báa yó làá règbọnsẹ; ta ní jẹ su lójú ebi? | 1 |
Oyètọ́lá gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí àwọn ará Ọ̀ṣun yóò fi máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ títí ayé. | 0 |
Àwọn ènìyàn bu àtẹ́ lu Bọ̀bọ́ lórí ohun tí ó sọ. | 0 |
Àwọn àgbà dọ́kítà darí iṣẹ́ abẹ náà, ó sì lọ ní ìrọ̀rùn. | 0 |
‘‘Jẹ́ kí nfìdí hẹ́ ẹ.’’- gbàjòkó; àfòmọ́ di onílé. | 1 |
Bí àṣá bá ń bínú, sùúrù ló yẹ ọlọ́jà. | 1 |
B'ọmọ-ẹyẹ 'ò fùyẹ, kò leè fò. | 1 |
Adigunjalẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni wọ́n mu ní ìdíkọ̀ ní Ajẹ́gúnlẹ̀. | 0 |
Bá mi na ọmọo mi, kò dénú Ọlọmọ. | 1 |
Ẹni a ti mọ'kọ lọrùn, ó kú àgira șe. | 1 |
A-ṣòwò-ọṣẹ kì í pa owó ń la. | 1 |
“Ayé-ò-rí-mi-sójú”, àìmọwàá hù ni. | 1 |
Dandan l'ewúré fií jeun olóhun. | 1 |
Mi ò mọ ohun tí a fẹ́ fi ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà ṣe láàárín wa nílùú yìí. | 0 |
Ó sì sọ wí pé adìẹ náà máa ń dí òun lọ́wọ́ láti sùn. | 0 |
Àlejò làá jòóó fún. | 1 |
Enití òri bí Ahun í w'ewù abonà,ábontósi Ahun baba-onà. | 1 |
Àgbà ṣoore má wo bẹ̀. | 1 |
Àkọ́bí ẹni ní ń rọni. | 1 |
Eni mo èyi; ò mọ tọhún; ni kò jẹ k'álágbẹdẹ ó leè rọke. | 1 |
Bí ọlọ́pàá ṣe gbé Tẹjúmọ́lá tọ́ka sí ipò àìdára tí Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ilẹ̀ wa wà. | 0 |
Ọ̀gá àgbà àwọn agbófinró gbé ìgbésẹ̀ lórí àwọn agbingbó. | 0 |
Àjàní ní pátákó náà gùn ní ìwọ̀n ààdọ́rin, ó sì fẹ̀ ní ìwọ̀n Ààdọ́ta mítà. | 0 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.