Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Ẹ̀gbọ́n ọmọbìnrin tí Àjàdí nà lọ ká Àjàdí mọ́lé. | 0 |
À ń jọ-ọ́ rìn, a kò mọ orí olówó. | 1 |
Eyìn ewú lọ làá dáròó rẹ. | 1 |
Ataare rẹni túndìí e se, ó ń fòbùró sẹsín, òbùró ì bá rẹni túndìíẹ se kì bá sunàn ju ataare. | 1 |
Ajèkuru-jẹwà ló morúkọ térèé ń jẹ. | 1 |
Bí a ba fi ọwọ́ ọ̀tún bá ọmọ wí a máa fi ọwọ́ òsì fa ọmọ náà mọ́ra. | 0 |
Ahéré ní ń kẹ́hìn oko; ààtàn ní ń kẹ́hìn ilé. | 1 |
Aboyún kì í gbọn kílẹ má jẹ lára ẹ. | 1 |
Àgùntàn ò pa aṣọ èṣí dà. | 1 |
Olóṣèlú ọ̀hún fi ọ̀wọ́ kan nínú wọn ṣe onígbọ̀wọ́ owó. | 0 |
Eni a fe kì i siwàhù. | 1 |
Àbùkú kan aláșejù, ó tẹ kò dumbę. | 1 |
Bí ọmọdé bá máa só, a wo iwájú; bí àgbàá bá máa só, a wo ẹ̀hìn. | 1 |
Àsàwí; ejo enikan àre. | 1 |
Bí'gi ti tó kọ lọrọ inú ẹ ń tó. | 1 |
Ajéìgbé jẹ́ ẹni kan tó máa ń fi ẹ̀mí ìmoore hàn púpọ̀. | 0 |
Kò fẹ́rẹ̀ sí ẹ̀ka tí kò ní àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tirẹ̀ ní àwọn ẹ̀ka Iléeṣẹ́ ìjọba. | 0 |
Eyìn-in 'A-'ò-ní-sanwó-orí' lèròó pọ. | 1 |
Àgbààgbà ìlú ò lè péjọ kí wọn ó jẹ ìfun òkété, àfi iyán àná. | 1 |
Ọwọ́ pálábá àwọn géńdé mẹ́rin ségi nígbà tí wọ́n lọ jí kẹ̀kẹ́ mẹ́ta gbé. | 0 |
Ará ilé Yọ̀mí sọ pé kíkọ tí adìẹ náà máa ń kọ lákọjù kò jẹ́ kí òun lójú oorun. | 0 |
Àpárá ń lá ni iná ń dá; iná ò lè rí omi gbéṣe. | 1 |
Aṣọ tí a bá fi ṣe ìtẹ́lẹ̀-àpótí ẹni kì í ṣe èyí tí à ń wọ̀ lọ sí gbogbo òde. | 0 |
Àlàáfíà, baba orẹ. | 1 |
Abíọ́lá sọ wí pé ipò àìlera tí alátakò òun wà kò dára. | 0 |
Ọlọ́pàá fi ẹ̀sùn ìjínigbé kan afurasí kan lórí ọ̀rọ̀ náà. | 0 |
Olùpẹjọ́ sọ pé òun kò fẹ́ kí ìyàwó òun máa wọ aṣọ oníhòòhò. | 0 |
Àyájọ́ èdè abínibí jẹ́ ohun tó yẹ ní pàtàkì ní àwùjọ káwùjọ. | 0 |
Ìbínú ò da nǹkankan àyàfi ìsọnilórúkọ̀ burúkú. | 0 |
Ení múlé ti Kootù ló ń gbóhùn akowé.Ení mú'lé tigbó ló ńgb'óhùn eyekeye. | 1 |
Arọ̀lẹ̀kẹ̀ ò rọ bàtà; gbẹ́dó-gbẹ́dó ò rọ ojúgun. | 1 |
Èèyàn loògùn èèyàn. | 1 |
B'ójú bá n pọnnì bíi k'á puro, ká má sèké, kí a sì má sẹdà (puro)torí àtisùn eni. | 1 |
‘‘Ojú ò fẹ́rakù’’ tí ńta ajá ẹ lókòó; ó fowó ṣíyán jẹ. | 1 |
Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ni ọrọ̀ ajé Nàìjíríà yóò búrẹ́kẹ́ síi. | 0 |
Gbogbo ọtọnkùlú péjọ; wọn 'ò róògùn àbámọ se. | 1 |
Ọkọ̀ akẹ́rù gbọ̀gbọ̀rọ̀ kan ti kó mọ̀lẹ́bí baálé ilé tó olóògbé sínú ọ̀fọ̀ àti ìbànújẹ́. | 0 |
Gómìnà Arẹ́gbẹ́ṣọlá ló kọ́kọ́ mú àyípadà bá àmì ìdánimọ̀ ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. | 0 |
‘‘Ọmọ-ọ̀ mi ò yó’’ la mọ̀; ‘‘ọmọ-ọ̀ mí yó, ṣùgbọ́n kò rí sáárá f ,’’ a ò mọ ìyẹn. | 1 |
Wọ́n fi ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ kan Dáwódù lórí ọ̀rọ̀ Oròbíyìí. | 0 |
Àbá alágẹmọ lòrìṣà ń gbà. | 1 |
Lára àwọn dúkìá tí ó ṣòfò pẹ̀lú òjò ni ọ̀kadà tuntun kan. | 0 |
A kì í dùn yùngbà ká fi wé ìbòsí ìgárá. | 1 |
Ó dájú pé orin ọpẹ́ lọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ Oníràpadà yóò máa kọ báyìí. | 0 |
Ikọ́ híhú tó kíyèsí gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àrùn. | 0 |
Ẹbọ à dà, òògùn à jẹ, òótọ-inú ni yóó lékè. | 1 |
Bọ́sẹ̀ ṣàlàyé ohun tójú rẹ̀ rí níbi ìfẹ̀míṣòfò àwọn olùwọ́de ní Ifẹ̀. | 0 |
Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ wí pé àwọn ń dúró de èsì ìwádìí àwọn ọlọ́pàá. | 0 |
Mo fẹ́ láti ṣe àfikún sí àwọn ohun tí ìgbìmọ̀ yìí ti sọ síwájú. | 0 |
Àìsàn kòró tó mú Gómìnà Abíọ́lá Ajímọ̀bí ló dóró. | 0 |
Ènmọ n ò rí ọ rí, mo rojú ológbò láte. | 1 |
Hòo' làá jẹ, b'ẹgbe eni ń peni, b'ógbà èèyàn ń pènìyàn. | 1 |
Àwọn ará àdúgbò bá ilẹ̀kùn ní títì pa. | 0 |
Ẹní fò sókè,ó be'jó lórí. | 1 |
Aaka ò gbé ọ̀dàn; igbó ní ń gbé. | 1 |
A kì í bá ọmọ ẹni ṣeré kó doko ẹgba. | 1 |
Àjọ elétò ìdánwò ilẹ̀ adúláwọ̀ ti sọ wí pé àwọn ti gbaradì fún ìbẹ̀rẹ̀ ìdánwò náà. | 0 |
Àṣàkẹ́ wà nínú oyún oṣù márùn-ún nígbà tí Adébáyọ̀ jáde láyé. | 0 |
Ìyàtọ̀ díẹ̀ ló wà láàárín àgbọ́yé àti ìmọ̀. | 0 |
Nígbà tí gbogbo wa bá rí èsì àyẹ̀wò ni a máa mọ ohun tó kàn. | 0 |
Bí àgbàdo bá tò, okan ma ń súnmora jùkan. (jura) | 1 |
Ẹní jẹ búrédì tó lóun ò yó alábòsí ni, torí búrẹdì fúnra rẹ 'ò yó. | 1 |
A kì í s'ọrọ k'á da aásà s'éjiká k'á se bí ẹnu ni. | 1 |
Kò ní sí àtúnṣe ìdánwò fún akẹ́kọ̀ọ́ kankan tí kò bá wá fún ìdánwò. | 0 |
Ààrẹ Bọ́lá Tinúubú sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ àárọ̀ yìí jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu. | 0 |
Adùn-ún tán lára aṣọ ogóje; a nà án han ẹni méje; a bẹ̀ ẹ́ wò a rí iná méje; ó di ọjọ̀ keje ó fàya. | 1 |
Ẹ̀gbọ́n mi fi owó ránṣẹ́ sí mọ̀lẹ́bí wa ní òpin ọ̀sẹ̀ tí a wà yìí. | 0 |
A ta bàbà, a fowó-o bàbà ra baba. | 1 |
Àtíkù àti Fálúsì sọ̀rọ̀ sókè nípa bí ìjọba Fálànà ṣé ti àkáúntì pa. | 0 |
Àrẹ̀mú gún olólùfẹ́ rẹ̀, Dúpẹ́ lọ́bẹ. | 0 |
Adìẹ kì í șubú, egẹ ló ń yẹ. | 1 |
Àwọn ọkọ̀, ọ̀kadà àti kẹ̀kẹ́ ò lè kọjá. | 0 |
Aré inú-omi ò jú sàá. Ìrìn inú-omi ò júrìn. | 1 |
A dúpę, a ti kúrò ľ'orun K'órisà tó dásęę (dá ișe) | 1 |
Báwo ló ṣe yẹ kí afurasí kan hùwà sí ọlọ́pàá tó bá fẹ́ mú un? | 0 |
A kì í sọ pé ọjà-á nígbà; bó bá nígbà, kíníṣe tí wọ́n tún ń ná a? | 1 |
Gbindingbindin là á ròfọ; gbẹdẹgbẹdẹ là á ro èkuru. | 1 |
Òmìnira lọ́wọ́ àwọn amúnisìn òyìnbó kì í ṣe iṣẹ́ ọjọ́ kan. | 0 |
Arábìnrin Tọ́pẹ́ Ọ̀wọ̀adé sọ pé inú ń run òun lọ́jọ́ kejì ìjà. | 0 |
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti ṣàgbékalẹ̀ àmì ìdánimọ̀ tuntun. | 0 |
Wọn kò rí ìwé kankan tó ṣeé ṣe kí ọlọ́dẹ yìí kọ sílẹ̀ kó tó gbẹ̀mí ara rẹ̀. | 0 |
· Èèyàn jù q o ní die nì, sé o rí die náà mú kúrò? | 1 |
Àkùkọ tó ń kọ nídàálẹ tí à ń gbọ ní Takétẹ, ó tọ kí a f'etí síhun tó ń sọ. | 1 |
Ẹṣin kò lè kọsẹ̀ bí ènìyàn bá gẹṣin ninu Abíọ́lá tó jẹ́ òṣèrébìnrin ilẹ̀ wa. | 0 |
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti gba ipò titun láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀. | 0 |
Ìrọ̀rùn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í dé sí àwọn ènìyàn ìlú Wúrà. | 0 |
Àwọn ènìyàn tó ti lààmìlaaka nínú ohun kan ni Ààrẹ̀ máa ń dá lọ́lá. | 0 |
Ayé lè pa fìtílà ẹ̀yẹ. | 1 |
Wọ́n ti da gbogbo ẹjọ́ tí ẹgbẹ́ òṣèlú pè tako yíyan alága ẹgbẹ́ nù. | 0 |
B'ẹni 'ò șe, ìbùkún ilé, ìbùkún ọjà kì í báni. | 1 |
Àsìkò ìdìbò kò dí àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lọ sí ibi iṣẹ́. | 0 |
Àjùwàpẹ l'òpin oore. | 1 |
Arákùnrin kan ní irọ́ ni Gbọ́láhàn ń pa. | 0 |
Àwọn òwe àti àkànlò èdè máa ń wà nínú orin Àyìnlá Ọmọwúrà. | 0 |
A ò gbé Amotekun kalẹ̀ láti máa yọjú sí ọ̀rọ̀ tí kò sí lábẹ́ òfin. | 0 |
Ẹ̀ka àjọ náà tó wà ní Àbújá ti gba àwọn arìnrìnàjò òfurufú lámọ̀ràn. | 0 |
Gbogbo ohun tí a bá ti fàșejù bọ, májèlé nì. | 1 |
Ìjọba ìpínlẹ̀ náà ti ná àìmọye owó láti dẹ́kun ìwà ọ̀daràn. | 0 |
Àwọn ìgbìmọ̀ afọbajẹ ìlú Ọ̀yọ́ sọ pé ìgbésẹ̀ ti ń lọ láti yan Aláàfin Ọ̀yọ́ tuntun. | 0 |
Àjọ elétò ìlera àgbáyé ti kéde ìgbésẹ̀ pàjáwìrì. | 0 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.