Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
A kì í pé kí òṣìkà ṣe é ká wò ó. | 1 |
Bádéjọ sọ pé irọ́ pọ̀ ju òtítọ lọ. | 0 |
Àlejò bí òkété là ń fi èkùrọ́ lọ̀. | 1 |
B'ówó bá tán lọwọ oníwà, a ď'òsónú. | 1 |
Àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe gudugudu méje yààyà mẹ́fà níbi ìsìnkú ìyá ìyáà mi. | 0 |
Ọkọ̀ tó ní ìjàmbá ní ojú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn yà kúrò lójú títì ọlọ́dà. | 0 |
Adéwálé ní ìgbésẹ̀ tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ gbé yìí dára púpọ̀. | 0 |
Bí ojú kò pọ́nni bí osùn, a kì í he ohun pupa bí idẹ. | 1 |
Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa olóògbé tí wọ́n ń ṣe ayẹyẹ tòkú ẹ̀ | 0 |
Èyí ni bí a ṣe ka ìtàn gbajúgbajà olórin lórí ìtàkùn àgbáyé. | 0 |
Ẹsẹ yá ju mọtò; ara ló ń fàbọ sí. | 1 |
B'éèyàn 'ò bá l'ọbẹ (tí ara ẹ) kò leè yọrẹ (yọlę) jẹ'șu 'ẹ (níbònkele). | 1 |
Bi Baàsè 'ò se, kí ni Baàlà óó làá? | 1 |
Dàńdógó kọjá ẹ̀wù àbínúdá; bí a bá ko ẹni tó juni lọ, a yàgò fún un. | 1 |
A kì í fi pàtàkì bẹ èlùbọ́ ; ẹní bá níṣu ló ń bẹ̀ ẹ́. | 1 |
Ẹdá tó mayé jẹ kì í gun ope. | 1 |
Èèyàn ló ń k'ọni k'á gọ, èèyàn ló ń kọní k'á gbọn. | 1 |
Àlùfáà di èrò ẹ̀wọ̀n nítorí ó fi ipá bá ọmọ ìjọ lòpọ̀. | 0 |
Àwọn ajá ń pariwo lóru lẹ́yìn tí wọ́n pariwo olè ní apá ilé kan. | 0 |
A ki ẹsẹ̀ kan bọ odò omí fà á; bí a bá wá ti mejèèjì bọ̀ ọ́ ńkọ́? | 1 |
Ẹnu 'ò mọ 'mo jẹ rí.' | 1 |
Bíṣọ́ọ̀bù Olúwafèyírọ́pò fipá bá ọmọ ìjọ rẹ̀ méjì lòpọ̀. | 0 |
Àáké tí ń gégi-í kọsẹ̀, gbẹ́nàgbẹ́nà-á bu ètù sórí. | 1 |
Bàbá Túnjí ni ó gbọ́ ìròyìn yìí tí ó fi tó ìyàwó rẹ̀ létí pé Túnjí jẹ́ ọ̀kan lára akópa nínú ìjàm̀bá náà. | 0 |
Àwọn àkàndà ẹ̀dá maá ń ìdíje eré-ìdárayá wọn tayọ̀tayọ̀. | 0 |
Ọkọ̀ akẹ́rù méjì sẹrí mọ́ra wọn lọ́nà márosẹ̀ Ìjẹ̀bú-òde. | 0 |
A kì í gbin àlùbọsà kó hu ẹfọ.Ohun a bá gbìn la ó kàá. | 1 |
Àilọràá ògòngo, a 'ò leé fi wé tadígbónákú. | 1 |
Àwọn Ìpínlẹ̀ mẹ́ta ni yóò ṣe ìdìbò gómìnà tiwọn ní ọdún tí a wà yìí. | 0 |
Gọgo tó ń kábì káhùsá, òòj tó bá fẹ ká odi ẹyìn ni yóó ya. | 1 |
Èyí ni láti ní àrídájú pé bóyá ọkọ̀ tí wọ́n rí ni tirẹ̀. | 0 |
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù oníbọn kò ní láǹfààní àti-jáwé-olúborí ní sáà tí a wà yìí. | 0 |
B'éèmọ ó ó bàá wọlú, tánúntánún lojúu pópóó mọ. | 1 |
À-tẹ́ -ẹ̀-ká ni iyì ọlọ́lá; sálúbàtà ni iyì ọlọ̀tọ̀; bá a bá gbéra lágbèéjù ọba ni wọ́n ń fini íṣe. | 1 |
Akínjídé máa ṣe ètò amóríyá náà pẹ̀lú àjọṣepọ̀ ilé-iṣẹ́ kan. | 0 |
A kì í pàșamọ mọ ọmọ ẹni, bí a bá tó baba. | 1 |
A-ṣọ́-ẹ̀hìnkùlé ba ara-a rẹ̀ nínú jẹ́ ; ohun tó wuni là ń ṣe nílé ẹni. | 1 |
Amúnidélùú ò tó adélùúmọ', òwe afibisúolóore ni. | 1 |
Àì-lóbìnrin kò ṣé-é dákẹ́ lásán; ó tó ká pe gbogbo ayé kó báni gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. | 1 |
Bí a kò bá fi oògùn pa ọmọ ìyá ẹni, ọmọ bàbá ẹni kì í sá fúnni. | 1 |
Alukoro ọlọ́pàá ìlú Jóbíewé ṣàlàyé bí ọwọ́ ṣe tẹ afurasí ọ̀daràn náà. | 0 |
Àjò àìwuniíyún là ńdÍfá sí. | 1 |
Bí a kò rí ọkọ̀, a ò lè dé Èkó. | 1 |
Àwọn adigunjalè fọ́ àwọn ṣọ́ọ̀bù inú ọjà lẹ́yìn tí wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀. | 0 |
Bí a bá ḿbú ẹtù, orí a máa fọ́ awó. | 1 |
B'o ò kú rí, o 'ò sùn rí? | 1 |
Eleye leye, eyẹ ìràwọ l'ójúu sánmọ ló wà. | 1 |
B'éèyàn le lálejù; ibi ni wọn ń kó bá ara wọn. | 1 |
Ọ̀kan lára àwọn olùgbé abúlé ṣàlàyé pé àwọn agbébọn ọ̀hún tó mẹ́jọ. | 0 |
Amùrín ò sunwọ̀n, ó yí sáró. | 1 |
Àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ rí àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n yìnbọn fún. | 0 |
E bá mí kí (so fún) onié yl o e ní mo pé bó sē n se nnì ní kómáa se'Oro | 1 |
Bí gbogbo ìlù mà ń pẹgàn-an bàtá, kò yẹnu móló. | 1 |
Bí 'ò bá sí ti Kàrà Àdàmú ẹnu ará Ìlọrin 'ò bá tí wẹrú. | 1 |
Bí ojú bá rí ọ̀rọ̀, a wò ó fín. | 1 |
Pẹ̀lú ìbẹ̀rù ni Ayọ̀mídé fi tẹ̀lé àwọn ajínigbé. | 0 |
Ìjọba dẹwọ́ fífi ọ̀kadà gbérò ní ìpínlẹ̀ Èkó bí ìdìbò Gómìnà ṣe ń bọ̀. | 0 |
Ẹja ló nibú. | 1 |
Àwọn olùgbé Ìbàdàn ni àpọ̀jù iná mọ̀nàmọ́ná ń da àwọn láàmú. | 0 |
Afohunpamọ níí sàmì ọnà. | 1 |
Ẹní bá le gbÓlúpọnnà, ó le bárá-ọrun bèésú. | 1 |
Àwọn ará Asà ò ní ọrọ̀ ajé lára. | 0 |
A kì í já lórí ọ̀pẹ ká tún jọba nísàlẹ̀. | 1 |
Àwọn ọmọ baálẹ̀ míràn ṣẹ̀ dé padà láti àjò tí wọ́n lọ pẹ̀lú èsì ayọ̀. | 0 |
Filà kì ílẹ kó dé orí kan tì. | 1 |
Adígbọnnákú t'ọn rò p'ó kú, ojúu wọn ní í fọrun sàrèbọ. | 1 |
Bẹ́ẹ̀ ni ó mẹ́nuba àwọn ìrírí rẹ̀ lákàtà àwọn ajínigbé tó jí i gbé. | 0 |
Àì-jọnilójú lọ́sàn-án ní ń múni jarunpá luni lóru. | 1 |
Fọlọ́runṣọ́ sọ wí pé àwọn kan ni wọ́n kàn án nípa fún òun. | 0 |
Ata ò mọ̀ pé òun ó dèélé. | 1 |
Òṣèré kan tó fi orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe ibùgbé náà kí Bíọ́lá kú oríire. | 0 |
‘‘Gba àkàṣù bàm̀bà’’ lóṣù agà ni ‘‘Gba iṣu gbọọrọ’’ lẹ́ẹ̀jọ̀dún. | 1 |
Abere bọ s'ómi tàló, Ọdọfin lóun gbọ tàbú. | 1 |
B'ọmọdé kan ń jèèwo, b'ẹnìkan 'ò bi í, bó pẹ títí ohun tí í bi ní a bìí, èèwọ a sì bèèrè ọrọ. | 1 |
Ṣùgbọ́n olóṣèlú yìí kojú onírúurú ọ̀ràn. | 0 |
Àjẹ tó pọkọ ẹ, a á nìkàn sùn. | 1 |
Àgbàbọ̀-ọ ṣòkòtò, bí kò fúnni lẹ́sẹ̀ a ṣoni; rẹ́mú-rẹ́mú ni ohun ẹni ń báni mu. | 1 |
Bí kò bá nídìí, ẹ̀ṣẹ́ kì í déédé ṣẹ | 0 |
Sísan owó ibodè ní pápákọ̀ òfurufú wà lára àwọn ìgbésẹ̀ ìjọba àpapọ̀ tuntun. | 0 |
Wọ́n ti rí òkú àwọn ènìyàn mẹ́jọ nínú odò. | 0 |
Afọ́jú onílù; atiro àrìnjó; bàtá ọ̀gẹ̀dẹ̀; ṣaworo òkòtó. | 1 |
Báwo ni àwọn ojúlówó fíìmù èdè Yorùbá ṣe bẹ̀rẹ̀? | 0 |
Eni tí à ń tori ee kú, tí kò f'ojúu rere woni. | 1 |
Ọjọ́ wo ni gbogbo ìlàkàkà ẹ̀dá fẹ́ dópin láyé yìí na. | 0 |
Ọkọ arábìnrin náà kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni bá wọn dá sí ìjà wọn. | 0 |
Bí àáké ń ké'gì nígbó, Olúgbohùn a gbà á. | 1 |
Bákan náà lọmọ ń sorí lẹyìn abiamọ. | 1 |
Ayaba Adénìké Adéyemí kò ní ìbàlẹ̀ ọkàn nínú ilé ẹ̀ | 0 |
Ọjọ́ tí a fi máa ń ya ẹni tí ó ní àrùn yìí sọ́tọ̀ máa ń tó ìdajì oṣù kan. | 0 |
Adéwálé Alukoro, ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́,tún fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀. | 0 |
B'ẹlejọ bá m'ẹjọ ẹ ľẹbi kì í pẹ níkùn-únle. | 1 |
Bí a bá l'éni tá 'ò bá báni; ìwọn làá bánií sọtáá mọ. | 1 |
Bí ìgbà ṣe ń yí náà ni orin àti ọgbọ́n inú ọ̀kọrin náà ṣe ń bá wọn yí. | 0 |
Ìjọba kò ní dẹ́kùn rírí i pé ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ọ̀daràn forí ní agbègbè Kìíṣí. | 0 |
Agbègbè Sùúrùlérè wà ní ìlú Èkó. | 0 |
Ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ni ilé ìwòsàn yóò dá bàbá mi sílẹ̀ láti máa lọ sí ilé. | 0 |
Èjì Ogbè ni baba Ifá. | 1 |
Bọrọ bá gb'ọfà, áá gboró ikú. | 1 |
Àsìkò tí Adétúnjí fi yà sí abẹ́ afárá náà ni pátákó ìpolówó ọjà fi wó pa mọ́ bẹ̀. | 0 |
Agbésùmọ̀mí ni Àdìó. | 0 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.