Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
A ti fi yé ìjọba pé àwa kìí ṣe àtẹ̀mẹ́rẹ̀. | 0 |
Amòòkùṣìkà ẹ̀dá kan pa àwọn arúgbó tọkọtaya kan nílùú Àràdàgún. | 0 |
A-kọrin-láì-lélégbè, bí ẹní lu agogo lásán. | 1 |
Bí àwọn darandaran ṣe ń ya wọ oko ni wọ́n sì ń gba ẹ̀mí àwọn ènìyàn. | 0 |
Géńdé tó ń ṣe bí ẹbọra láti fi jalè ti wà lákóló àwọn ọlọ́pàá. | 0 |
Àáyá ní ohun tí a bá mọ̀-ọ́ ṣe, bí ẹní ń ṣeré ni; ó ni bí òun bá ń lọ lóko ẹ̀pà, ọ̀kọ̀ọ̀kan a máa bọ́ sí òun lẹ́nu. | 1 |
Olúwọlé ti jẹun nígbà tí ó dé. | 0 |
Bí ekù tenikan ò gbààyè, kí a wá ekù elòmíràn lọ se po tẹni. | 1 |
B'ómùgo 'ò bá fego e pa ologbon lá'ra, k'ologbon má fogbon e pa á lára. | 1 |
Bámgbọ́lá lo ọjọ́ mẹ́rin lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá kí wọ́n tó wọ́ ọ sọ́kọ̀ Eléwéeran. | 0 |
Kò tún sí àṣepọ̀ kan danindain láàárín tọkọtaya náà láti ìgbà tí ikú ọmọ wọn ti ṣẹlẹ̀. | 0 |
B'ó pẹ tí a tì n dabì, bó yá obi yóó yàn. | 1 |
A kì í f'omií dáni lára. | 1 |
Afefe tó ń dààmú Ológì, kÓníyefun má sàfira. | 1 |
Àṣẹ ti wá láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀ pé kí ará ìlu so nọ́ḿbà ìdánimọ̀ wọn mọ́ nọ́ḿbà àṣùwọn wọn. | 0 |
A kì í sọ pé ó di ọjọ́ tí a bá bímọ ká tó sọ ọmọ níkòó. | 1 |
Bí a bá gbá ilé gbá ọ̀nà, ọ̀dọ̀ ààtàn là ńdà á sí. | 1 |
Ẹní máa f'ológìnní (fológbò) sọlé; kò ní fọbę sísaasùn. | 1 |
B'óyún bá ș'oyún ọkọ eni íí pọnnií lé ni. | 1 |
Àgbà tí ò jà, ó níhun tó rí. | 1 |
Yọ̀mí sọ pé nítorí ọdún àjíǹde lòun fi ra adìẹ náà. | 0 |
Eégún tí yó ṣe bíi Lébé, Lébé ni yó dà; èyí tí yó tàkìtì bí Olúfolé, òfurugbàdà ni yó ta á. | 1 |
Bí ológbòó bá pámi pámi, yó wọ̀ ọ́. | 1 |
Aró ḿbẹ lÓṣogbo; àtàtà èèyàn ḿbẹ nÍbàdàn. | 1 |
Àbúrò kì í pa ẹ̀gbọ́n nítàn. | 1 |
Abíọ́lá pè wọ́n ní aláìlọ́gbọ́n tó ń ṣe bí ọlọ́gbọ́n. | 0 |
Bí a bá pẹ, pẹ láyé bí ẹni lọ àjò tí kò dé, bí emí sì gùn gùn gùn bí okùn tó gùn, nijọ așọ bá rírí dandan ni k'áso ó wọmi. | 1 |
Ahun níí jolá igbá, igbín ń jọlá ikarahun. | 1 |
B'éèyàn 'ò tìẹ m'òjò ogànjọ; ó yẹ kó gọbo kúkù eji. | 1 |
‘‘Mo mỌ̀bàrà mo mỌ̀fún’’ ti kì í j kí àwòko kọ́ ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ́ nÍfá. | 1 |
Bí baálẹ̀-ẹ́ bá ń tàkìtì, òrógi là ń bá ẹmẹsẹ̀. | 1 |
Ayọ̀mídé ni orúkọ ọmọ tí orí kó yọ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé ní Ọjọ́ru. | 0 |
̀Àwọn ọmọ oníjìbìtì lo arábìnrin kan fún ògùn owó. | 0 |
Ariwo ti pọ̀ jù ní àdúgbò yí pẹ̀lú bí kò ṣe jẹ́ ìgboro. | 0 |
‘‘Níbo ló gbé wà?’’ nìyájú ẹkùn. | 1 |
Àdìó fẹ́ kí wọ́n ṣe ìdájọ́ náà ní kíákíá. | 0 |
Ajogún-Ifá ní kí òun má kù-ú; ẹni tó kọ́ tẹ̀ ẹ́ dà? | 1 |
Àáyá bọ́ sílẹ̀, ó bọ́ sílé. | 1 |
·Eni ton fOrð lé, nibi tó gbé n sálo, ó tún lo b'órò nibitó n gbe | 1 |
Àwọn ẹlẹ́sìn ìbílè sọ pé Èṣù yàtọ̀ sí S̀àtánì àwọn onígbàgbọ́. | 0 |
Àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú méjì ti darapọ̀. | 0 |
Àṣìṣe ni ó ṣe tí wọ́n fi yọ ọ́ kúrò lára àwọn olùdíje ipò náà | 0 |
B'átòrì, bá lò síwá, a tún lò s'ẹyìn ni. | 1 |
Abẹ́ afárá ni púpò nínú àwọn abarapá oníbáárà ń sùn. | 0 |
A kì í jègún mọyán. | 1 |
Ènìyàn ogún ṣì wà ní ìsélémọ́ látàrí àjàkálẹ̀-àrùn. | 0 |
Bàbálọ́jà rọ Gómìnà láti dìde ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn. | 0 |
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní kí àwọn ènìyàn ké sí àwọn bí wọ́n bá mọ nǹkankan nípa ikú Àjàyí. | 0 |
Àjíǹde Jésù ni wọ́n ń ṣe àpéjọ fún. | 0 |
Ìjọba níláti fi àwọn arúfin ojú pópó jófin. | 0 |
Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ọkọ̀ àjàgbé akẹ́rù yìí máa ń takú sójú pópó. | 0 |
Gbogbo ohun ọdẹ rí níjù kọ ló ń délé wí. | 1 |
Eni dáso fún ni, làá fií gbá lójú. | 1 |
Ẹgbẹ́ agbésùmọ̀mí yìí ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ti ilẹ̀ òkèèrè. | 0 |
Àwọn lẹ wò, ẹ ò lè rí eégún. | 1 |
Àń șubú seré kí a tó ní kí a dọbálẹ kí àna ẹni. | 1 |
Àmọ̀tẹ́kùn-ún fara jọ ẹkùn, kò lè ṣe bí ẹkùn. | 1 |
Fákẹ́yẹ kò gbà, àfi ìgbà tí ó tẹ́ ìfẹ́ inú ara rẹ̀ ló tó dìde lórí rẹ̀. | 0 |
‘‘Ṣe é báyìí’’ ní ń kọ́ aya ẹ̀ lọ́bùn. | 1 |
Ení f'ojú àgbàrá wo Kúdẹtì, á tẹ | 1 |
Àgùntàn ń wò sùn-ùn; ọgbọ́n inú pé egbèje. | 1 |
Aláǹtakùn ò bójò rẹ; aráyé ò b'ẹni tí ò ṣunwọn se. | 1 |
Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí okùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ náà. | 0 |
Bígi bá wó lugi, tòkè làá kọkóó gbé.' Òwe plenìyàn nì. Ìsàle lalágbára tií fà á yọ. | 1 |
Ení máa fi Músù (Ológbò) delé; kó dé ìsàasùn re pinpin (daada). | 1 |
Pápákọ̀ òfurufú Elérewé ni ọkọ̀ ofurufu àwọn ọmọ ogun wa. | 0 |
Àgbẹ̀ ni baba oníṣòwò. | 1 |
Àgbẹ̀jẹ ò korò nílé ń lá. | 1 |
Ẹ̀tọ́ àjọ ayánilówó àgbáyé ni láti kọ́ Nàìjíríà ní ọ̀nà tí yóò gbà sanwó padà déédéé. | 0 |
Fúnra'ra Gẹlẹdẹ ló ń fowọ ara rẹ tún orí ara rẹ se. | 1 |
Àyìnlá kò fi ọwọ́ rírọ̀ mú ọ̀daràn tí ó gbámú pẹ̀lú ìbọn ọwọ́ rẹ̀. | 0 |
A rí ọ̀pọ̀ tí wọ́n jẹ́ akọ̀ròyìn tí wọ́n sì tún jẹ́ olùkọ́. | 0 |
Ará Ìbàdàn kì í ságun; à ó rìn s hìn ni wọ́n ń wí. | 1 |
Àgbàyewó níí bàbọn Òyìnbóó jẹ. | 1 |
A kì í rí bàtá nílẹ̀ ká fẹnu sín in jẹ. | 1 |
A kì í kọ àgbàlagbà pé bí ó bá rún un tán, kí ó mì í. | 1 |
Akàrà kì í ș'ońjẹ àlejò. | 1 |
Ìdajì nínú àwọn tó ti kú ní àrùn mìíràn lára tẹ́lẹ̀. | 0 |
B'ápá 'ò bá seé sán; à á ká a lérí ni. | 1 |
Àjọ́kẹ́ ni obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò gbégbá orókè nínú ìdíje tí à ń sọ yìí. | 0 |
Filà funfun 'ò sunàn nígbà eẹrùn. | 1 |
A kì í gúnyán-an kókò kí á ṣe ìmẹlẹ. | 1 |
Àwọn aṣòfin Èkó sọ pé kí ìjọba gba ìwé ìyànsípò àwọn ènìyàn kan kúrò lọ́wọ́ wọn. | 0 |
4388. Wnṣàn-wnṣàn ò mú ehín gbórín; bí kò jù ṣ kí, a ó máa fi rún àgbàdo. Loud chewing does not increase the size of one’s teeth; if one’s teeth are short, one can at least chew corn with them. (One does not need to prove that one is great; no matter how lowly one might be, there is much one can accomplish.) On freed... | 1 |
Àkíyèsí mi lórí ọ̀rọ̀ tó ń lọ kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. | 0 |
Bíṣọ́ọ̀bù Olúwafèyírọ́pò ni olùdásílẹ̀ ìjọ náà. | 0 |
Atẹ́gùn ò ṣéé gbé. | 1 |
Bọ̀dé ra ẹran ńlá fún àwọn òbí rẹ̀ fún iléyá | 0 |
Àwọn agbébọn kó ọkùnrin mẹ́ta wọgbó lọ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n pa Àṣàkẹ́. | 0 |
A ti kàn sí kọmíṣọ́nà fún ètò ìròyìn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. | 0 |
Àwọn ẹgbẹ́ tí wọ́n kó ara wọn jọ fún ètò ààbò kò ní àṣẹ látọ̀dọ̀ ìjọba. | 0 |
Gege dùn-ún yo, mélòó ló ń bẹ lọrùn ejò? | 1 |
Bí òwe bí òwe là ńlùlù ògìdìgbó; ọlọgbọ́n ní ń jo; ọ̀mọ̀ràn ní ń sìí mọ̀ ọ́. | 1 |
Kò sí àwáwí kankan fún ẹni tí kò bá tẹ̀lé àṣẹ ọba. | 0 |
Ọ̀kan lára àwọn tí ọwọ́ tẹ̀ náà jẹ́ oníṣẹ́-ọwọ́. | 0 |
B'éwúrẹ pégba, b'ọn bá rí màlúù wọn á sá. | 1 |
Àwa ni à ń gba wúrà tó pọ̀ jù. | 0 |
Lọlá sọ pé àwọn ikọ̀ aláàbò ti wà nínú igbó káàkiri láti ṣàwárí ẹni tí wọ́n jí gbé. | 0 |
Bàbá bàbá mi jẹ́ èèyàn pàtàkì láwùjọ àwọn olóyè ìlú Ẹ̀gbá. | 0 |
B'ó pẹ tí a ti ń jijà ìkọkọ, òòjọ a bá d'élé Ọba làá sòóto. | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.