Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Àtètèdáyé ò kan tàgbà; orí ẹni ní ń gbéni ga. | 1 |
Èpè (ni) 'ò j'ọmọ olè ó dàgbà. | 1 |
Bí a șe mìn ín kọ là á pọ ọ. | 1 |
Akíkanjú ọmọ tí ó ṣeé fi yangàn ni mo jẹ́. | 0 |
À-jẹ-ì-padà-wálé ò jẹ́ ká mọ ọdẹ adìẹ. | 1 |
Ajá wo ẹyẹ láwòmọ́jú. | 1 |
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ wí pé àwọn ọ̀daràn ọ̀hún yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ ní kíákíá. | 0 |
Afẹ́fẹ́ ń gbá eruku lálá; ẹ̀fúùfù ń mi ewé àgbọ́n jìà-jìà. | 1 |
Bí ọ̀làjú ti ní àǹfààní náà ló ní àléébù. | 0 |
Àkúrẹ́ ní ìpínlẹ̀ Oǹdó jẹ́ ìwọ̀n gbígbóná méjìlélọ́gbọ̀n. | 0 |
Bí a bá finú wénú, iwọ là á ję. | 1 |
A kì í bọ́ sínú omi tán ká máa sá fún òtútù. | 1 |
A-ṣe-bọ̀rọ̀kìnní-má-kìíyè-sábíyá, gbogbo abíyá dọ́ṣẹ. | 1 |
Alákòró kì í sá fógun. | 1 |
Àìgbọ́Fá là ń wòkè; Ifá kan ò sí ní párá. | 1 |
B'ólóde 'ò kú, òdé kò lè hu gbẹgi. | 1 |
Ìlérí gómìnà àná ni pé kí fásitì náà jẹ́ àpéwááwò káàkiri. | 0 |
Adénúgà kì í kúkú ṣe ìlú-mọ̀-ọ́n-kà. | 0 |
B'ọmọdé s'ọkò lu agẹmọ, kò ní kú, kò ní rùn, á á pọn láso ni. | 1 |
Ọlọ́pàá dá owó tó rí gbà padà fún ilé ìfowópamọ́. | 0 |
Ọmọwúrà jẹ́ sàwáwù pẹ̀lú àwọn ìlú-mọ̀-ọ́n-kà olórin àsìkò rẹ̀. | 0 |
Ẹgbẹ́ Agbọmọlà fẹ́ wọ́de ní ìrántì àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn tó kú. | 0 |
Alẹ́ tí kò ti ojú ẹni lẹ́, a kì í mọ òkùnkùn-un rẹ̀ẹ́ rìn. | 1 |
Àjànàkú yáwó tán kò singbà mọ́; erin-ín gbówó olówó wọgbó lọ. | 1 |
A kì í rí àjẹkù orò. | 1 |
Báyìí ni kálukú wọn ń sọ tiẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. | 0 |
‘‘Sún mọ́hùn-ún, a fé ṣorò ilé-e wa,’’ kì í jẹ́ kálejò di onílé. | 1 |
Bí ọmọdé ò bá rí oko baba ẹlòmíràn, a ní kò sí oko baba ẹni tó tó ti baba òun. | 1 |
Bọ́látíto wá láti ìlú ìṣẹ́yìn, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. | 0 |
Jíjálu àwọn ọlọ̀tẹ̀ yóò jẹ́ kí àwọn ológun lè borí wọn. | 0 |
‘‘Gba wèrè,n kò gba wèrè’’ lọjà-á fi ń hó. | 1 |
Ahun ń mí; igbá ẹ̀hìn-in rẹ̀ ni ò jẹ́ ká mọ̀. | 1 |
Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ti ṣàfihàn àwọn afurasí ọ̀daràn méjèèjì àti àwọn ajínigbé. | 0 |
Olùkọ́ tí mo fẹ́ràn jùlọ ni ọ̀gbẹ́ni Adédèjì. | 0 |
Wọ́n sọ wí pé adìẹ yìí kì í jẹ́ kí àwọn sùn lásìkò tí àwọn bá fẹ́ sùn. | 0 |
Àìsàn ibà, ikọ́ wíwú àti àìlèmíkanlẹ̀ wà lára àwọn àpẹẹrẹ àrùn. | 0 |
Àkúdin ò kọminú àáké. | 1 |
Ìjọba àpapọ̀ ṣe ìpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ aláṣẹ rẹ̀ nílùú Àbújá fún ọ̀pọ̀ wákàtí. | 0 |
Àwọn ìgbìmọ̀ atọpinpin ni yóò ṣe akitiyan láti gba àwọn ènìyàn tí wọ́n jí gbé sílẹ̀. | 0 |
A ní ka w'ẹni tó lẹyìn fọmọ fún, Alábáhun (Abuké) bọ síbę, irú eyìn tiẹ là n wí? | 1 |
Àìgbọràn ni ó ṣekú pa Àjàó ní ìjẹtàá | 0 |
Àwọn ìgbìmọ̀ afọbajẹ Ọ̀yọ́ sọ pé Ọmọọba Gbádégẹṣin tí àwọn yàn ló dára jù. | 0 |
Àwọn ohun èlò ìsọmọlórúkọ ni à máa ń lọ láti fi ṣàdúrà fún ìkókó. | 0 |
Ẹni níșu lébè kó má se jẹ ìkókóró; ohun a bá jẹ síkùn ni tẹni. | 1 |
Owó rọ̀gbùnrọ́gbún ni Àdìó gbà. | 0 |
Àtíkù náà sọ pé Akínwándé wà lára àwọn tó ni ilé iṣẹ́ tó ń ṣe ojú ọ̀nà. | 0 |
Bákan náà ni kò fi abala ẹ̀kọ́ sílẹ̀ rárá. | 0 |
Bí a kò ránni sọ́jà, ọjà kì í ránni sílé. | 1 |
Ení tàkitì lOyòo tó ní òun bale nilé lbàdàn, wọn ní llú tó kù ńkọ? Ó ní: 'ká fò ó'. | 1 |
Adéṣọlá bẹ̀bẹ̀ fún oṣù díẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìwádìí nínú ìlú náà. | 0 |
Akẹ́kọ̀ọ́ tí ọwọ́ bá fi tẹ̀ pé ó ṣe àṣemáṣe nínú ìdánwò yóò fi imú dánrin. | 0 |
Ẹ ti pé yó rìí, nígbà tí ọmọ olè ń gun ìbaka? | 1 |
‘‘Kò mọ̀ọ́ tà kò mọ̀ọ́ rà’’ tí ń gun ẹṣin lórí àpáta. | 1 |
Alàgbà Ajíbọ́lá àti Fákúnlé ní olùkọ́ wa lórí ètò lónìí. | 0 |
Yóò ṣòro fún àjọ tó ń gbógun ti gbígbé egbòogi olóró bí Bọ́lá bá di ààrẹ. | 0 |
Aya-méè-rọ́mọ-rí ní ń tanna wo oyún ọ̀gànjọ́. | 1 |
A-rí-erin-látẹ ò mọyì erin. | 1 |
Kò ju wákàtí mélòó kan lọ tí ilé-ẹjọ́ da ẹjọ́ àwọn Ọ̀yọ́mèsì nù. | 0 |
Ẹní bá se'bę, k'á k'ẹkọ lọ fún un. | 1 |
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fòfin gbé àwọn afurasí mélòó kan lórí ikú ÌléríOlúwa. | 0 |
Kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn lè mú ẹ̀mí ẹni lọ. | 0 |
B'éèyàn bá gba lyàwó Àrìrá, yóo f'ẹbọ jura. | 1 |
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn tẹ àwọn adigunjalè méjì. | 0 |
Bíná Onílé bá kú, tàlejò làá gbàá tàn. | 1 |
Ẹ̀dá ní kó má torí òun dá; ológùn-ṣẹṣẹ̀ẹ́ ní kó má torí òun ṣẹ̀; ọkàa bàbàá ní kó má torí òun bàjẹ́. | 1 |
Ejò kì í pọnmọ rẹ rebi ijó. | 1 |
Àwọn agbófinró rí òkú bàbá arúgbó kan ní ẹ̀bá ọ̀nà. | 0 |
Amọ̀rànbini Ọ̀yọ́, bí o bá gbé kete lérí, wọn a ní oko lò ń lọ tàbí odò. | 1 |
Àgbà ajá kì í bàwọ̀j́ . | 1 |
Ìròyìn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé láàárọ̀ kùtùkùtù ni àwọn agbébọn náà ya wọ inú oko kan. | 0 |
A ó gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà. | 0 |
Adébáyọ̀ Bánjọ ń gbé ní Ṣómólú | 0 |
Òdú ni Wàídì Àyìnlá Ọmọwúrà ní ilẹ̀ káàárọ̀-o-ò-jíire láwùjọ olórin. | 0 |
Ilé ẹjọ́ gíga ìlú Ìlọrin dájọ́ ẹ̀wọ̀n oṣù márùn-ún fún àwọn akọ̀ròyìn méjì. | 0 |
Aṣiwèrè-é yẹ ìlú, kò yẹ ẹni ẹni. | 1 |
Àwọn ènìyàn kú nígbà tí Ọlọ́runfẹ́mi fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ kọlù wọ́n. | 0 |
Àgbà ẹyẹ kì í tukà. | 1 |
‘‘Yan àkàrà fún mi wá ká jìjọ jẹ ’’: àìtó èèyàn-án rán níṣẹ́ ní ń jẹ́ bẹ́ẹ̀. | 1 |
Ẹní ń b'Òlókunrùn jiyàn ní yóó pà á. | 1 |
Ẹ̀dá ò lè gbìn àlùbọ́sà kó ká ẹ̀fọ́ láyé láyé. | 0 |
Kò sẹ́ni tó lè ṣílẹ̀kùn fún àwọn ènìyàn láti inú ilé. | 0 |
Bí ọ̀ràn ò tán, ibì kan là ń gbé; arékété lohun ń ṣe. | 1 |
Akẹmọbí-ojú òbí, kì í șòbí rere. | 1 |
Àgùntàn kan kó sínú kàǹga bí ó ti ń wá ohun tí yóò jẹ. | 0 |
‘‘N ò lè jẹ ìjẹkújẹ’’ kì í gbé àwùjọ ọ̀pọ̀ èèyàn. | 1 |
A kì í rí ojú ẹkùn ká tọ́ ẹkùn. | 1 |
Àwọn ará Ọ̀ṣun yóò fi ìbò gbé Oyètọ́lá wọlé ni bí wọ́n bá fẹ́ ẹ. | 0 |
Ààrẹ Bọ̀bádé ní kí wọ́n fòpin sí ìyanṣẹ́lódì wọn. | 0 |
Àwọn èèyàn yòókù rọ ìjọba láti ràn wọ́n lọ́wọ́. | 0 |
Bàbá Doyin kò fẹ́ kí ó ṣe ìdánwò àṣekágbá rẹ̀. | 0 |
Bí a bá lé ẹni, tí a kò bá ẹni, ìwọ̀n là ń bá ẹni-í ṣọ̀tá mọ. | 1 |
Gbogbo yanàlè-yanàlè t'ọn bá yan Tápà lálè, wọn ó simi agbaja. | 1 |
Àwáìlọ-ọ́ lọ́ sílé Asèmásọ̀. | 1 |
Àtọ̀ìṣíwọ́ là ń mòkóbó. | 1 |
Àwọn ọlọ́pàá sọ pé ọmọbìnrin yìí kò rí ẹ̀rí kankan tó fìdí ọ̀rọ̀ ọ̀hún múlẹ̀. | 0 |
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn èèyàn Nàìjíríà ń kérora lórí àwọn àmọ̀ràn àjọ ayánilówó àgbáyé yìí. | 0 |
Èkúté ilé ní tẹni tó pa òun ò dun òun bí ẹni tó gbé òun ṣánlẹ̀. | 1 |
B'íkú 'ò bá p'ààbọn, bíkú 'ò bá p'èkùrọ, yóó j'órúkọ tẹyìn ń jẹ bódola. | 1 |
A kì í gbélé gba ọfà láìlọ ogun. | 1 |
Àwọn ará ìlú ń gbàdúrà pé ẹni tí yóó láànú wọn ni kó bọ́ sípò. | 0 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.