Proverbs
stringlengths
8
373
Labels
int64
0
1
Aṣaájú tó kọ́kọ́ gbógun tí àwọn alájẹbánu gbìyànjú gan ni.
0
Ibi tí wọ́n ti lọ wáṣẹ́ ni wọ́n ti ṣàgbákò àjálù búburú yìí.
0
Méjì lára àwọn ẹni afurasí sá lọ.
0
Ahun ènìyàn ló ń gbóńjẹ s'ájà jẹ.
1
Àwọn ọlọ́pàá dábàá ọ̀nà àbáyọ sí aáwọ̀ wọn.
0
Ẹni a 'ò bá tà kí a fi ra èèbù, ó lóko òun ku òọdún.
1
Bí ìyàwó bá ṣojú ẹni, tó tún ṣẹ̀hìn ẹni, ó ní láti ní èrè tí yó jẹ níbẹ̀.
1
Ọ̀gá ọlọ́pàá kìlọ̀ pé kí àwọn ọ̀daràn wá ibi gbà kúrò ní ìpínlẹ̀ Ògùn.
0
Òkìkí kàn lórí ìdigunjalè ilé ìfowópamọ́.
0
A kì í f'àikú mọrun.
1
Òkìkíọlá sọ pé òun ti di bùkátà ìjọba àpapọ̀ báyìí.
0
Itẹ́ òkú tó wà ní Ìdíòro ni wọ́n yóò sin òkú Ràúfù sí.
0
Aláǹgbá tó já látorí ìrókò tí kò fẹsẹ̀ ṣẹ́, ó ní b nìkan ò yìn un òun ó yinra òun.
1
Kò sí ojú àánú fún gbogbo ẹni tí ò bá gbèrò kí ìjọba ṣe àṣeyọrí.
0
Àti wí pé lọ́yà tó mòfin ni Yẹmí.
0
‘‘O kú iṣẹ́ ’’ ò lè bí aráyé nínú.
1
Àgbọ́mújójó ni orin Àyìnlá Ọmọwúrà fún gbogbo ènìyàn.
0
Adéṣọlá ní ènìyàn tó tó Ọgọ́rin ni àwọn ní láti dá ààbò bò.
0
Ẹni t'ọn bẹ lórí tó tún ń jẹnu wúyẹ, kí ló tún kù tí yóó se?
1
Ọwọ́ ba agbódegbà tó ń gbin igbó ní agbègbè Etí-osè.
0
Béèyàn 'ò tìẹ là, kò pé kó lanúú le.
1
Bí wọn kò bá sì rí oṣù lónìí á jẹ́ wí pé ó di ọ̀la kí àwẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.
0
Wọ́n kọ ìwé àpilẹ̀kọ náà ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.
0
È̀èmọ̀ lukutu pẹ́bẹ́! Ìyàwó lóyún tán ọ̀nà ò gbọkọ.
0
À ń sọ̀rọ̀ elégédé, obìnrín ń bèrè ohun tí à ń sọ, a ní ọ̀rọ̀ ọkùnrin ni; bí a bá kó elégédé jọ, ta ni yó sè é?
1
Ìjà àgbà ti wà tẹ́lẹ̀ láàárín àwọn ọmọ-ìta tí wọ́n ń jà tẹ́lẹ̀.
0
‘‘Òun ló mọ̀’’ kì í mọ ní òun nìkan.
1
Bí kò sí towó, kí la ó fòwò ṣe?
1
Bàbá mi kọ̀ láti bá mi sọ̀rọ̀ torí ọ̀kọ akáta tí mo mú wálé
0
Bóníbàtá bá lù lọ, lù bọ, ibi ojú-o-fẹrakù ló ń parí ẹé sí.
1
Jíjìnnà sí ènìyàn lè dẹ́kun ìtànká àrùn.
0
Pẹ̀lú ìjà ni àwọn ọmọ lẹ́yìn Kírísítì náà fi ń fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀.
0
Àjànàkú ò lẹ́kàn; ọba tí yóò mùú erin so ò tíì jẹ.
1
Alákatanm̀pò ò mọ irú ẹran.
1
Bísọ́lá tí tun bímọ titun.
0
Akíọdé sọ wí pé ó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn padà sínú àwọn ilé yòókù.
0
Fáàrí òfo, àjùlọ ilệélẹ.
1
Fúnlengefúnlenge, fúnlenge àkàrà kò s'eyìnerèé.Fúnlenge fúnlenge,funlenge iyán 'ò seyìn isu.
1
Àwọn ènìyàn kan sárá sí fíìmù tí ó ṣe kẹ́yìn.
0
Àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá mẹ́ta ṣìwà hù.
0
Alága àwọn òntàjà lóun pàdánù owó níbi ìjà tó ṣẹlẹ̀.
0
Lójú-ẹsẹ̀ tí àwọn ọkọ̀ méjèèjì kọ lu ara wọn tán ni wọ́n ti gbaná.
0
A kì í fi ìkánjú lá ọbẹ̀ gbígbóná.
1
Ajedé kì í ję'kan kó ló tó.
1
Wọ́n tún rí ẹ̀rọ kékeré kan tí wọ́n fi ń lẹ egbòogi gbà lọ́wọ́ wọn.
0
Adájọ́ sọ fún wọn pé àǹfààní wà fún wọn láti pe ẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn.
0
Àsìkò tí a wà yìí ni ó dára jùlọ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ oko dídá.
0
Ìlú Ayégbajú tí yan Ọba aládé tuntun.
0
Wọn kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ayédatiwa sétí rárá.
0
Àkèekèé ta Kindo lẹpọ̀n, ará ilée Labata ń rojú; kí ló kàn án níbọ?
1
Ará ilé kan ló máa ń ba gboogbo ará ilé gba ilẹ̀ wọn jọ, tí á dẹ̀ jo.
0
Èkùrọ́ lalábàákú ẹ̀wà.
1
Àwọn oníwádìí ti ṣàwárí ẹranko tuntun tí wọn kò rí rí.
0
Dídùn là ń bá láfárá oyin.
1
Bí eegbọ́n bá so ayínrín nímú, adìẹ kọ́ ni yó ja.
1
Ọ̀rọ̀ àwọn agbébọn náà rú àwọn èèyàn lójú.
0
‘‘Gbà lẹ́nu asín ni gbà lẹ́nu èkúté.
1
Àfẹ́ẹ̀rí kan ò ju ká rí igbó ńlá bọ́ sí lọ; ẹbọ kan ò ju ọ̀pọ̀ èèyàn lọ; ‘‘Òrìṣá gbé mi lé àtète’’ kan ò ju orí ẹṣin lọ.
1
Àkẹtẹ l'owó; ẹni tó ba wu Olúwa Ló fi ń dé lórí.
1
Ẹ bá mi fi owó yẹ ayẹyẹ náà sí kí ẹ fi bu ọlá fún bàbá mi.
0
Ėsúrú sàsejù, ó tẹ lowo oniyán. Alángbá ș'àsejù, ó tẹ lowọogiri.
1
Àṣá ò gbádìẹ níkọ̀kọ̀; gbangba làṣá ń gbádìẹ.
1
Àìsàn ọgbẹ́ inú ló gbé Yínká lọ iléèwòsàn lọ́dún tó kọjá.
0
Àwọn ìgbésẹ̀ tuntun ni yóò túbọ̀ jẹ́ kí ọrọ̀ ajé Nàìjíríà gbòòrò sí i.
0
Bá a bá ni aá mú òní, ọ̀la là á mú.
0
Ìjọba fòfin de gbígbẹ́ ilẹ̀ tàbí kànga ní kìlómítà mẹ́wàá sí gbogbo afárá ìjọba àpapọ̀.
0
Fákẹ́yẹ tẹ̀lé Rìnsọ́lá pẹ̀lú ìtara dé ibìkan tó ṣókùnkùn dáadáa.
0
Àgbà ò lówó a ní kò gbọ́n; olówó ń ṣe bí ọba lóko.
1
Bọmọlúàbí bá tafà, ó yẹ kó wá a.
1
Òfin ìlú Òmìnira tako ìfẹ́ akọ sí akọ.
0
Ìnira èémí máa ń ṣe ènìyàn bí àjàkálẹ̀-àrùn bá ti lágbára.
0
Akínṣọlá náà ti dá ilé iṣẹ́ ti ẹ̀ náà sílẹ̀.
0
Ẹní bá kó s'ódò ni ó mọbi odò mu ni dé.
1
Ọkùnrin tí wọ́n fi kíndìnrín ẹlẹ́dẹ̀ rọ́pò tirẹ̀ pàpà jáde láyé.
0
Ẹnìkan lára àwọn méjèèjì ló ṣe agbátẹrù bí wọ́n ṣe dáná sun ọkọ̀ olóògbé.
0
A-binú-fùfù ní ń wá oúnjẹ fún a-binú wẹ́rẹ́ -wẹ́rẹ́ .
1
Àfojúsùn wà pé ogun yóò ṣẹlẹ̀ lásìkò ìsìnkú Ràúfù.
0
Dídùn ló dùn tí à ń bọ́rẹ̀-ẹ́ jẹ̀kọ; tilé oge-é to oge-é jẹ.
1
Àlejò orí ni kókó.
1
Ọwọ́ ba àwọn adigunjalè tó fọ́ ilé ìfowópamọ́ lọ́sẹ̀ tó lọ.
0
A kì í jẹ méjì lóko N`tọfà; ẹní bá jẹyán kì í jẹ ẹ̀kọ; ẹní bá jẹ iṣu kì í jẹ àmàlà.
1
Àgbà tí kò fọ̀ mọ́ni níkùn kì í fọ̀ mọ́ni lórí.
1
Agbẹ́jọ́rò rẹ̀ sọ pé kò gbọ́ nípa rẹ̀.
0
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ málegbàgbé wáyé ní àsìkò ìpolongo ìbò lọ́dún tó lọ.
0
Àgbà Ìjèṣà ò lè ṣàìjobì.
1
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè ṣe àlàyé fún àwọn akọròyìn wa.
0
Bí a bá dàgbà, tí a gbó, bó pẹ́ títí ojú á kájọ́.
1
Àgbààgbà mẹta, wọn kì í tí èkùlùú pè, (pèkùlù tì). B'ókan bápékùlù, ọkan a pékùlú, ọkan yòókú a pèkùlù jálę koroko.
1
Àwọn òbí mi ṣiṣẹ́ takuntakun lórí ẹ̀kọ́ mi.
0
Àbáyọ̀mí sọpé iṣẹ́ abẹ ẹwà Obìnrin ló jẹ òun lógún.
0
Ọ̀gá ọlọ́pàá sọ wí pé onírúurú àwòrán ló wà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí lorí ẹjọ́ náà
0
Bí a bá bu ọba tí a sẹ́, ọba a fini sílẹ.
1
Ènìyàn méjì bá ọlọ́pàá jà ní Èkó.
0
Afẹ́fẹ́ lẹlẹ ò jẹ́ ká gbé orí igi; àgbàrá òjò ò jẹ́ ká gbé ilẹ̀- ẹ́lẹ̀.
1
Èwo lààlà l'óko ljágbó?
1
‘‘Má fi tìrẹ kọ́ mi lọ́rùn’’ là ń dá fún apènà àti òwú.
1
Àlàárì, baba aṣọ.
1
Ẹni kú (ti, ló) sọra e degbọn.
1
Ẹnu 'ò sunàn; elẹnu pọn ọn lá.
1
Ẹ̀bùn Ọlọ́run ò kan ọgbón.
1