Proverbs
stringlengths
8
373
Labels
int64
0
1
Ọwọ́ àjọ tó ń rí sí lílo egbòogi olóró tẹ àwọn afurasí ọ̀daràn mẹ́ta lẹ́yìn oṣù méjì.
0
Èèyàn nílé ń je.
1
Gbé-rù-mú' fàyà tọrẹ.
1
Bàbá mi ní ìfarapa nígbà tí ó ń lọ ibiṣẹ́.
0
Àwàseyìn ni tìre.
1
B'íyán 'ò pọ; iyán a le.
1
Níbi ìgbìyànjú ènìyàn la ti ń mọ bí ó ṣe ní akíkanjú sí.
0
Àìsí owó ni, ‘‘Jẹ́ kílẹ̀ ó mọ́’’; ajé kì í gbowó ká ní ó dọ̀la.
1
B'ónkà bá ń kà á, k'ọlọgbọn máa f'inú rári an.
1
A kì í kó èlé ṣẹ̀ṣọ́.
1
Kò sí ẹ̀rí tàbí àrídájú kankan pé wọ́n bá ohun ètùtù nínú ọkọ̀ rẹ̀.
0
Àjọ àláàbò ìlú ló mú àwọn ajínigbé ọ̀hún.
0
Àjọ elétò ìdìbò tẹ̀lé gbogbo ohun tó wà nínú ìlànà ìwé òfin.
0
A kì í torí erin f'ẹsẹ gún așá; a kì í torí àlè f'ẹsẹ pejò.
1
Akínbami fa ìwé kan yọ nígbà tí ó tọwọ́ bọ agbádá rẹ̀.
0
Ẹ ṣeun púpọ̀ fún àwọn dáadáa tí ẹ ṣe fún ilé ẹ̀kọ́ wa.
0
Àwọn tó forí sọta ìjàmbá iná ń bẹ ìjọba láti dìde ìrànwọ́
0
Ẹni tí kò í kú, yóó họra.
1
A di gàárì sílẹ, ewúrẹ́ ń gbọnrí; ìran ẹ gbé e rí?
1
Báyé bá ń yẹ wọn; ìwà ibàję niọn ń hù, a Édá félémpe àkoko tódẹsà-ejò yọ sorun.
1
Bí a kò bá lè kú, ìpẹ̀ là ń gbà.
1
Ekún t'ọmọ olówó (olọlá) sun tó gba eyinlá,bó s'omo tálikà, yóo sun gbojogo leyìn-ọrùn.
1
Àwọn ọ̀daràn jẹ́wọ́ pé iṣẹ́ igbó àti egbòogi olóró mìíràn ni àwọn yàn láàyò.
0
Gbòngbò-onà je'lese ó rin, ayé gbogbo kí í seé lesin.
1
Fúlàní ti jẹ tinúu màlúù tán k'ó tó dẹran apatà.
1
Fákẹ́yẹ fi ipá bá Rìnsọ́lá lò pọ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà.
0
A kì í mú oko lọ́nà ká ṣèmẹ́lẹ́ ; tajá tẹran ní búni.
1
Akẹ́kọ̀ọ́ gidi ni Bíọ́lá ṣùgbọ́n eré pá rẹ̀ pọ̀.
0
Àwọn agbébọn já lu àwọn ológun lójijì bí wọ́n ti ń lọ dóòlà ẹ̀mí àwọn aráàlú.
0
Ata loògùn ẹ̀mí; ẹ̀mí tí kò jata, ẹ̀mí yẹpẹrẹ.
1
A kì í gb'ọmọ lọ kíyàá ę.
1
ika owọ 'ò dọgba, tẹsę ò foríkorí.
1
Ẹní pé kí la ó se, làá se é hàn.
1
B'ọlọkọ 'ò bá ì tíì wà á gún; a kì í bi í b'ọwọ dẹ.
1
Àáyá gbọ́n, Ògúngbẹ̀- sì gbọ́n; bí Ògúngbẹ́-ẹ́ ti ń bẹ̀rẹ̀ ni àáyá ń tiro.
1
Àgbinsínú legbin ń gbin; àkùnsínú lẹkùn ń kùn; hùn hùn hùn ẹlẹ́dẹ̀ inú ẹlẹ́dẹ̀ ní ń gbé.
1
Àwòmojú ni Soyà (Sawyer) ń wo àràbà.
1
Aṣẹ́ ni ikọ̀ oyún; àtọ̀ ni ikọ̀ ọmọ; rírà lọ́dẹ̀dẹ̀ ni ikọ̀ àwòdì tí ń já ọmọ lẹ́hìn adìẹ.
1
Adénúgà ní àwọn okòwò ńláńlá mìíràn.
0
Wọ́n gbé oúnjẹ àti ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí wọ́n dé pa wá.
0
Ęgbe enì kì i gb'ómì-ijà k'aná k'á má fi owo bà á wò.
1
Àbúrò Ọmọlọlá sọ wí pé ẹ̀gbọ́n òun kò mọwọ́ nínú àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.
0
Olúwọlé ti darí dé láti ìlú Ọba.
0
Ìjọba ní di ìparí oṣù yìí láti gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ.
0
Àwọn ọlọ́pàá ṣe ìkéde pé àwọn yóò mú àwọn adigunjalẹ̀ ọjọ́si.
0
A máa ri bí àwọn ilé ìjọsìn ní ìpínlẹ̀ Èkó yóò ṣe máa jọ́sìn.
0
Àgbàká lodi ń gba ìlú.
1
Afàìmọ̀ kí pásítọ̀ tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn má ṣe ẹ̀wọ̀n.
0
Àwọn ọmọdé ni àìsàn ibà ń pa jùlọ.
0
Béèyàn 'ò je gbèsè, tí'ò dáràn, won ò leé bèèrè iye tó ní
1
Ọ̀kan pàtàkì nínú aṣọ ilẹ̀ Yorùbá ni Aṣọ Òfì.
0
Ikọ̀ àwọn ajínigbé kọ ojú ìbọn sí ikọ̀ àwọn jagunjagun.
0
Méjì nínú àwọn ọ̀daràn jẹ́ obìnrin.
0
A-bayé-jẹ́ kò ṣéé fìdí ọ̀ràn hàn.
1
Bí ó ku òní ku ọ̀lá kí ọmọ olódò-ó kú fún òùngbẹ, ọ̀ṣọ̀rọ̀ òjò á rọ̀.
1
Á dára tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà ní kíákíá.
0
‘‘Yán sí i, yán sí i’’ ní ń pa alákàrà l rìn-ín.
1
ìjọba kéde ìyàsọ́tọ̀-àmójútó fún àwọn ìlú tí àrùn ti kọlù.
0
Adákẹmáfọhùn; a 'ò mọ ťẹni tó ń se.
1
Ewọ ẹmi, kò jọ ewọ Ìrókò.
1
Adéjùmọ̀ sọ fún kóòtù pé olùrànlọ́wọ́ pàtàkì ni Oríyọmí jẹ́ sí òun.
0
Lórí ayélujára ni a ti rí fídíò bí àwọn ọlọ́pàá ṣe ń yìnbọn sókè.
0
Ataepo àti araepo ló mọ ohun tí wọ́n fi ń nuwọ́.
1
Ìjọba ti ṣe àgbékalẹ̀ òfin fífi òǹtẹ̀ lu ìwé ìrìnnà láàárín ọjọ́ méjì péré.
0
Olúwọlé bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí amòfin ní ìlú Ọ̀yọ́.
0
Àìfẹ̀sọ̀ké ìbòsí ni kò ṣéé gbè.
1
Ayédatiwa ti fẹ̀yìn àwọn alátakò rẹ̀ balẹ̀.
0
Gìrìgìrì 'ò mọlà, k'á șisę bí ẹrú 'ò da nnkan.
1
Awakọ̀ ọ̀hún ṣàlàyé síwájú sí i pé ọ̀nà Èkó ni wọ́n mórí ọkọ̀ lé.
0
A ò mọ ohun tí Dárò-ó ní kó tó wí pé olè-é kó òun.
1
Àwọn afurasí kan gún àwọn ìyàwó ṣákaṣàka títí wọ́n fi kú.
0
Ìyàtọ̀ ọdún mẹ́tàlá ló wà láàárín ẹ̀gbọ́n àti àbúrò tí wọ́n jáwé olúborí.
0
Wọ́n máa ń gba ẹyin ọkùnrin àti ti obìnrin nínú ìlànà níní oyún ti olóyìnbó.
0
Ìwà rádaràda pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀sìn kò dára.
0
‘‘N ó lọ, n ó lọ!’’ lobìnrín fi ń dẹ́rù ba ọkùnrin; ‘‘Bóo lè lọ o lọ’’ lọkùnrín fi ń dẹ́rù ba obìnrin.
1
À ń kì í, à ń sà á, ó ní òun ò mọ ẹni tó kú; a ní, ‘‘Alákàá ẹgbàá, a-biṣu-wọ̀rọ̀-wọ̀rọ̀-lóko, a-bàgbàdo-tàkì-tàkì-l gàn’’; ó ní, ‘‘Ọlọ́dẹ ló kú, tàbí ìnájà?’’
1
Awọ nídìí àdá ò wí pé kí àdá má kàn-án.
1
Èròńgbà ìjọba àpapọ̀ ni láti sọ ìgbé-ayé àwọn ènìyàn di ọ̀tun.
0
Ọ̀nà tí àwọn Ọ̀yọ́mèsì gbé yíyan Aláàfin tuntun gbà wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin.
0
Gbédógbédó'ò leè gbẹ agogo. Alọlẹkẹ 'ò lọ bàbà. Alágbẹdẹ 'òleè ro ojúgun.
1
Àgbà kì í wẹwọ (sanwọ) tán, kí ó tún l'óun yóó jẹ sí i.
1
B'Ęgbàá 'ò gba tẹni; à á gba ť'Ẹgbá ni.
1
Èyí ni ọ̀rọ̀ tí ìgbìmọ̀ àwọn agbẹjọ́rò fẹnu kò lé lórí.
0
Ẹ bá wa bẹ àwọn mọ̀lẹ́bí àti aláìsàn ní Ọ̀wọ̀.
0
Wọ́n ní owó tí ilé iṣẹ́ ọ̀hún kò rí yá mú ìfàsẹ́yìn bá iṣẹ́ wọn.
0
Ẹni tó ni ilé ìtajà kan ní àwọn kan ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ja òun lólè ni.
0
A kì í f'agbémáye adìẹ bọ'run (bọ'rí) eni.
1
Alu-ìyá-ìlù kì í jewọ, Olómele kì í sàwàdà.
1
Ẹ̀míọlá sọ pé lára àwọn ohun tí wọ́n fi máa ń tàbùkù àwọn rèé.
0
Àti wí pé òun ní ibi tí òun fẹ́ sáré dé ní tòun.
0
Eégún dẹ́bi, kò ṣéé gbá lójú.
1
B'ọmọdé 'ò bátàn, a á bá àrọbá, àrọbá baba itàn.
1
Ęni a se fún ní í seé fún ni.
1
Alukoro àwọn ọlọ́pàá ti fi àtẹ̀jáde sita.
0
Àwọn àgbààgbà ilú Ìgbòho ní ìyà tí ìjọba fi ń jẹ wọ́n tó gẹ́.
0
Ojúróngbé mú ẹ̀sùn lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá.
0
Adánilóró ò ṣéé fẹ̀hìntì.
1
Àjàyí, Àlàní àti Ajàgbé kó sọ́wọ́ àwọn ajínigbé agbébọn ní oríta mẹ́rin lánàá.
0
Ààrẹ ìlú Òmìnira sọ wí pé wíwa epo yóò tún tẹ̀síwájú.
0
Kò sí ìgbìyànjú tí kì í lérè bí ó ti wù kí ó mọ.
0