Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Ó rọrùn fún olè ènìyàn láti máa lu àwọn ènìyàn ní jìbìtì káàkiri. | 0 |
A kì í wáyé ká má da nǹkan; oun a ó dà la ò mọ̀. | 1 |
Ikọ̀ ọlọ́pàá sáré wá síbi ìṣẹ̀lẹ̀ Màgbòrò nígbà tí àwọn ènìyàn fi tó wọn létí. | 0 |
‘‘Èyí wù mí kò wù ọ́’’ lọmọ ìyá méjì-í fi ńjẹun lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. | 1 |
Ó dára bí ènìyàn bá ta ko ẹni tó fẹ́ gba ipò lọ́wọ́ ẹni. | 0 |
À ń wọ́nà àti fi aṣiwèrè sílẹ̀, ó ní bí a bá dé òkè odò ká dúró de òun. | 1 |
Àlàyo ni tÒsùmàrè. | 1 |
Àgbọ́ìgbọ́tán Ègùn, ìjà ní ńdá sílẹ̀. | 1 |
Ìyá àwọn ọmọ náà gbé wọn sínú ọkọ̀. | 0 |
Ààrẹ lóun ò tiẹ kọ kí orò gbé obìnrin òun, tórúkọ òun tó mú r'ọrun ló ń dun òun. | 1 |
Ìwà táwọn ọlọ́pàá Nàìjíríà ń hù yìí ń fi wọ́n wọ́lẹ̀ láwùjọ àwọn ọlọ́pàá ní àgbáyé. | 0 |
Binú bá se rí l'obìí yàn. | 1 |
Díẹ̀-díẹ̀ lẹyẹ ń mu ọsàn. | 1 |
A ti wá olùkọ́ náà, a ti rí i. | 0 |
Ẹ fi sílẹ̀ nítorí eré ló ń ṣe. | 0 |
Àwọn tó dìde ìrànwọ́ yìí máa ń fi ẹ̀mí ara wọn wéwu. | 0 |
Wọ́n sọ wí pé àwọn yóò rí i pé ọkùnrin náà rí ìtọ́jú tó péye | 0 |
Mákindé kò mọ̀ pé obìnrin onípọ̀nmọ́ ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. | 0 |
Aláṣejù, baba ojo. | 1 |
Awo Eégún lobìnrín lè ṣe, awo Gẹ̀lẹ̀dẹ́ lobìnrín lè wò; bóbìnrín bá fojú kan Orò, Orò á gbé e. | 1 |
Àwọn agbébọn tó ṣọṣẹ́ náà lo ìbójú lásìkò tí wọ́n ṣe ìkọlù náà. | 0 |
Ààrò kì í gbóná dalę. | 1 |
Àlàní rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí adájọ́ pé kó ṣíjú àánú wo òun. | 0 |
Èyí sì ló ń kọ àwọn ènìyàn Mosáfẹ́jọ́ lóminú lórí ààbò ẹ̀mí wọn. | 0 |
Ẹmí gígùn ló ń sànyà. | 1 |
Bíná bá gbepo, ipọnrí 'ẹ á gùnkè. | 1 |
Ėwo l'àgbà l'ọmọ-ajá? Ńlá ẹgbẹfà, kèkeré egbefà. | 1 |
Olúṣọlá àti Ògúnrónbí ni wọ́n jọ ṣiṣẹ́ láabi ọ̀hún. | 0 |
Ení n tan a ra rẹ jẹ șì lè yó, eni ń tan ara rẹ dànú l'ebí ń pa. | 1 |
Eni tẹte débi òkú olọrọ níí șa ibi rere gbé. | 1 |
Ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ǹjẹ́ ó mọ̀ pé ẹnìkejì rẹ̀ nínú yàrá ti fẹ́ máa lọ. | 0 |
Wọ́n dá ọgbọ́n sí ìdìbò tó kọ́kọ́ gbé Oyètọ́lá wọlé ní sáà àkọ́kọ́ ni. | 0 |
Àlàní sọ fún ilé ẹjọ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí òun yóò gbé egbòogi olóró. | 0 |
Ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀sùn tó bá tibi ètò ìdìbò yọ ni ó lè dáhùn ìbéèrè bẹ́ẹ̀. | 0 |
Àwọn òbí ìbejì tó lẹ̀pọ̀ ní ọ̀kàn àwọn bàjẹ́ láti rí ibèjì wọn tó. | 0 |
Eégún atiro wọ'gbàle, èèyàn atiro tigbàle jáde,ta ni ò mo -(Eégúnatio wolé, èègan atiro jáde; ta ni ò mọ péèyàn atiro tó wolé ló dèèyd atiro!) | 1 |
Bàtá dún kò dún, á tan ilẹ̀kú kanlẹ̀ kanlẹ̀. | 1 |
Kò ní sí ìnáwó lásìkò tí ààrẹ tuntun bá wọlé. | 0 |
Èso l'ó ti kọkọ hu igi, k'ígí ť'ó máa so èso. | 1 |
Baálé di mẹ́ta, itan adì dàròyé. | 1 |
Aláparútu ẹdá ò séé bá dòwò pọ. | 1 |
Àjọ ayánilówó àgbáyé kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú mẹ̀kúnnù. | 0 |
Àjànàkú àwọn oníṣẹ́ ibi ti jẹ májèlé, wọ́n dẹran awo. | 0 |
Àdó gba ara ẹ̀ tẹ́lẹ̀, ká tó fi oògùn si? | 1 |
Ẹ má ṣe lọ́ra láti ké sí mi bí ẹ bá nílò ìrànlọ́wọ́. | 0 |
Sọ̀rọ̀ mi lẹ́yìn kí n pe ọlọ́pàá sí ẹ. | 0 |
À ń fọtún ťẹní, à ń fòsi gbálẹ, abiyamọ ní wọn 'ò bá òun ș'ọrọ ọmọ. | 1 |
Baba tó ń b'òbìnrin omọo rèé lò. Ó ní: “Ęyin náà gbọ; e wá? Ó ńtán lọ náà nùn-un" | 1 |
A kì í fi orí wé oríi Mokúṣiré; bí Mokú kú láàárọ̀ a jí lálẹ́ . | 1 |
Gegele 'ò seé șe l'óríi gègèlè; kó má yọyę. | 1 |
G'ẹsin ní kẹsẹ, bó dé'núu wọn, bí 'ò dọkàn-an wọn. | 1 |
Ài mọ o gbé kalẹ l'eégún fi ń gbọtí lọwọ eni. | 1 |
Àwọn ọlọ́pàá bá kẹ̀kẹ́ Márúwá tuntun tí Àjàyí jí lọwọ rẹ ní ìlú Ondo. | 0 |
Mi ò jẹ́ tún sún mọ́ nǹkan ẹni ẹlẹ́ni mọ́ láé. | 0 |
Àtúntò ti bẹ̀rẹ̀ sí ẹ̀ka tó ń gbé ìròyìn jáde. | 0 |
A pọ bí oníbàjẹ; àwọn gógó-bí atúnnìṣe. | 1 |
Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò lè máa gbowó lọ́wọ́ àjọ ayánilówó àgbáyé kí wọ́n má san án padà. | 0 |
Eégún fẹ jó, òjò fẹ rọ, Adébòmí fẹ wòran. Ó ku ká wá dúró, káwo teni tí yóó se. | 1 |
Àṣìṣe kò pọ̀ nínú ìdánwò tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe lọ́dún yìí bíi ti ọdún tó lọ. | 0 |
Eran tí Òmùgo pa níjù, Ọlọgbọn ní í fi í jẹ. | 1 |
B'ájá bá ń sínwín ó yẹ kò mojú iná. | 1 |
Àkèré pète ìyẹ́ ; ìyá olódò ni ò gbà fún un. | 1 |
B'ó bá ję kìtàkìtà ló ń múnií là kì bá pọ sọdọ àwọn àlágbárá bíesin. | 1 |
Àwon ọ̀nà wà tí wọ́n fí ń ba ara wọn sọ̀rọ̀. | 0 |
Àwọn ọmọ olúwo ṣe èèmọ̀ bí wọ́n ṣe gbọ́ pé olúwo papò dà. | 0 |
Bí ìbí ò bá wọ, tí ìbí ò bá sì tẹ, eni a bá bá níwájú ni a á fií s baba. Àmọ bí ìbí bá tẹ; tíbìí sì wọ, kálukú tó baboa nílé ara won | 1 |
Afọlábí ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ tí òun gbé bí ọkọ òun nínú. | 0 |
Adénúgà jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run dá lọ́lá. | 0 |
A kì í jẹ méji lábà Àlàdé; ẹní jẹyán ò gbọdọ̀ jẹṣu. | 1 |
Kò ní sí ààyè fún wọn mọ́ láti pe ẹjọ́ kankan lẹ́yìn ọgbọ́n ọjọ́. | 0 |
Àgbẹ̀ tó níṣu lọ́gbà tó ń jẹ ẹ̀gẹ́, ohun tó fẹ́ ló ń ṣe. | 1 |
Gbinngbinnikin,erú tó wiwo nì. | 1 |
Bí igí bá dá, igi a yẹrí; bí èèyán bá kú, a ku èèyàn ṣàà-ṣàà nílẹ̀; bí ẹni orí ẹní bá kú, ẹni ilẹ̀ẹ́lẹ̀ a di ẹni orí ẹní. | 1 |
A kì í fi ọlá jẹ iyọ̀. | 1 |
Dídán lẹyẹlé ń dán kú. | 1 |
Arákùnrin kan lára àwọn ajínigbé máa ń sọ èdè Faransé. | 0 |
Àwọn èèyàn Ìsìnìgbò ń pàdánù àwọn nǹkan ọ̀sìn wọn. | 0 |
Gbà fún Gbàdà nilé, ni gba fúnGbàdàl'óko. | 1 |
Àwọn agbébọn mórí lé ọ̀nà kan tó jẹ́ ààlà láàárín ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun àti Kwara. | 0 |
Adébimpé gba omijé lójú Adédiméjì. | 0 |
Àwọn tó kùnà jíjẹ́ ọmọ ikọ̀ Amotekun ló ń gbé ìròyìn ìbàjẹ́ kiri. | 0 |
Ẹlẹ́jọ́ ṣa èyí tó wù ú wí. | 1 |
Àrùn tí ńṣọ̀bọ ò ṣegún: igún pá lórí; ọ̀bọ́ hùrù. | 1 |
A-kú-sí-ni-lorùn obinrin Ìrẹ, ọkọ rẹ ń bá a ṣeré-ifẹ, itán kán m'ọkọ lọwọ. | 1 |
A kì í láhun níyì. | 1 |
Àgbàlagbà kì í dáwo-bojú purọ́. | 1 |
Kò sí ẹni tó máa ń béèrè owó, tọ́rọ́ kọ́bọ̀ ni wọ́n máa ń fún wọn. | 0 |
Pásítọ̀ tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn ń káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́ lọ́wọ́ níwájú adájọ́. | 0 |
Àjálù náà tàn dé apá gúúsù orílẹ̀-èdè Súpèènì. | 0 |
Àlá bí Èkó yóò ṣe ní rélùwèé ti wà láti ọjọ́ pípẹ́. | 0 |
Àwọn ilẹ́ ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan kùnà láti pèsè àbò tó péye fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nile ẹkọ. | 0 |
A kì í bá ẹni tan ká tún fani nítan ya. | 1 |
Bí a bá ń șișẹ kí a mọná owó, àimọnà owó, ìșẹ níí kó bá wọn. | 1 |
Bí ẹrú bá jọ ara-a wọn, à mọ̀ pé ilé kannáà ni wọ́n ti wá. | 1 |
Àì-lápá làdá ò mú; bí a bá lápá, ọmọ owú tó-ó gégi. | 1 |
Bí ilé kò dùn, bí ìgbẹ́ nìlú ńrí. | 1 |
Ara kì í tu ẹni káká, kí ara ó roni koko, ká má leè jíkàkà dÍfá. | 1 |
Àyẹ̀wò ìbátan lè jẹ́ nǹkan kan náà. | 0 |
Afetenu-oníléégbọ. èkúté tó f'éèkù sílẹ tó ń jọbę. | 1 |
B'ágbà ń joyè, b'omode ń ję, emi a ję fOlọrunșo. | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.