Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Onírúurú ọ̀nà ni ènìyàn lè gbà lùgbàdì àrùn. | 0 |
A kì í b'ápọn-ọn jẹjẹ̀ẹ́ ìgbà alẹ. | 1 |
Bí a kò bá ṣèké, a kì í fi ẹ̀tẹ́ kú. | 1 |
Àwọn agbébọn bí i mẹ́jọ ni wọ́n ń ṣe ìkọlù sí àwọn abúlé ní Ẹ̀gbá. | 0 |
Àwọm onímọ̀ ti ṣe àwárí àwọn àìsàn tuntun mìíràn lágbàáyé | 0 |
Olálẹ́yẹ sọ wí pé àwọn yóò sọ fún gbogbo ènìyàn bí ọ̀rọ̀ bá ti wọ̀. | 0 |
Kí ni mo fẹ́ fi àwọn ohun tí ẹ kà sílẹ̀ yìí ṣe bí? | 0 |
A rí èyí rí ni tonílé; a ò rí èyí rí ni tàlejò; bónílé bá ní ká jẹ tán, àlejò a ní ká jẹ kù. | 1 |
B'ọmọdé bá ń b'ágbà jẹun, titíiri ní í tiiri. | 1 |
Ọláníyan fi àáké kọ́rí pé kìkìdá irọ́ lásán ni gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ. | 0 |
Àyìnlá Ọmọwúrà borí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro tó kojú nílé ayé. | 0 |
Ẹsin fọmọ tiẹ sílẹ lái pọn; ó ń pọnmọ ọlọmọ. | 1 |
Emín l'ọle wà. | 1 |
Akẹ́kọ̀ọ́ onípele àṣekágbá kan ní Fásitì Ifẹ̀ jí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ gbé. | 0 |
Àwọn agbébọn ya wọ oko àgbẹ̀ wọ́n sì ṣoró. | 0 |
Ìyàwó Adégbémilé sọ wí pé àwọn ọmọ ọkọ òun máa ń bú òun. | 0 |
‘‘Sìn mí ká relé àna,’’ ó wẹ̀wù ẹtù. | 1 |
Sún-kẹrẹ-gbà-kẹrẹ yóò dínkù ní àwọn ojú pópó ní ìpínlẹ̀ Ògùn pẹ̀lú àwọn ìgbésẹ̀ ọ̀tun. | 0 |
Ara kì í rọni ká ṣẹ́gi ta. | 1 |
Àti àwọn nǹkan mìíràn tí a ó nílò láti fi rìnrìn àjò náà. | 0 |
Àjàkálẹ̀-àrùn ti ṣe àkóbá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́. | 0 |
Ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ kò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tuntun yìí lójú. | 0 |
Àwọn mọ̀lẹ́bí Balógun kò tí ì lẹ́yìn nígbà tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ orin. | 0 |
Egbò-àyà ló ń bá ẹnu mímì wá. | 1 |
Àwọn aráàlú sa gbogbo ipá wọn láti paná ọ̀hún. | 0 |
N óò lọ sí ibùsọ̀ àwọn aláṣọ bí n bá lówó lọ́wọ́. | 0 |
Oyètọ́lá yóò rí i bí ayé ti ń yínmú sí ni bí ó bá fipò sílẹ̀. | 0 |
B'ára ilé ẹni bá lẹnu, ẹsẹ là à ní. | 1 |
Yíyan adelé adelé lèmọ́mù lásìkò yìí kò lè tún nǹkankan ṣe rárá. | 0 |
Bí ojú kò bá ti olè, a ti ará ilé ẹ̀. | 1 |
Ẹ ṣe àtúnṣe sí gbogbo àwọn ilé-ìwòsàn alábọ́dé lórílẹ̀ èdè yìí. | 0 |
Kò sí àrídájú pé Adéyanjú mọ bí ọ̀ràn tí ó dá ṣe pọ̀ tó. | 0 |
B'éèyàn 'ò sọrọo kùmọ, kò yẹ kó kíyèsí ìpàkọ | 1 |
B'ábiamọ bá ro'jọkan ikúnlę yóó b'ayé ọmọ ję. | 1 |
A sìnkú Olóògbé Adébáyọ̀ Ayọ̀kú ní ọjọ́ Ẹtì. | 0 |
Ẹ̀fúùfù-ú gbé ológìì lọ; oníyẹ̀fun ni ègbé yán-yán. | 1 |
Bí àrùn búburú bá wọ̀lú, oògùn búburú la fi ń wò ó. | 1 |
Wọ́n kọ́kọ́ kẹ́fín àjàkálẹ̀-àrùn ọ̀hún lára ọkùnrin kan. | 0 |
Alásejù, pẹrẹ ló ń te | 1 |
A kì í bá ẹni gbé ká má mọ ojú ẹni. | 1 |
Abẹ́rẹ́ bọ́ lọ́wọ́ adẹ́tẹ̀ ó dète; ọ̀rán balẹ̀ ó dèrò. | 1 |
Wọ́n pe olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba sí ìpàdé láti wá ṣàlàyé bọ́rọ̀ ṣe rí nípa owó oṣù. | 0 |
Ààlà alágemọ 'ò tó gèlè. | 1 |
Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tó lè ṣekú pa ọkùnrin lásìkò ìbálòpọ̀. | 0 |
Aṣọ̀ràn ní ń ṣe aájò. | 1 |
Akẹ́kọ̀ọ́ kan kú lásìkò tó ń gbá bọ́ọ̀lù. | 0 |
Èkejì ni ẹni tó ń tún pa omi ṣe. | 0 |
Àwọn ọ̀dọ́ dáná sun tírélà akẹ́rù tẹrùtẹrù ní Èkìtì. | 0 |
A ki í ye pópó kó má kanlé. A kì í yẹna taara k'ó má kan ọjà. Aìí gbáwòrán gę; ge; gę, k'á má f'ọwọ e tì síbikan. | 1 |
Kí oníkálukú mú èyí tó bá rọ̀ ọ́ lọ́rùn nínú ẹ̀sìn méjèèjì. | 0 |
Ògúnrónbí fa ọ̀bẹ yọ nínú àkọ̀. | 0 |
·Èsi l'obinrin fi i yan oko rere. | 1 |
Ègé ni Balógun máa ń gé jù lọ́pọ̀ ìgbà. | 0 |
Edé kì í rebi kó má dèé. | 1 |
Eni tí 'ò rihun wò ló ń wohun olóhun. | 1 |
Eni à ń tàn mọ. | 1 |
‘‘Gbà kún tìrẹ’’ ò bí ọmọ aráyé nínú. | 1 |
Ọwọ́ ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá tẹ Ọládipúpọ̀ lórí ẹ̀sùn olè jíjà. | 0 |
Àwọn mùsùlùmí kan máa ń gbọ́ orin Ayéfẹ́lẹ́. | 0 |
Òṣìṣẹ́ èlétò ìdìbò tawọ́ sí Àjàká nígbà tí àwọn aráàlú béèrè èsì ìdìbò lọ́wọ́ rẹ̀. | 0 |
Ayò kì í jẹ ká yẹ̀ ẹ́ . | 1 |
Díẹ ọkùnrin 'ò tó. | 1 |
Ọ̀gbẹ́ni Pẹ̀lúmi sọ pé irọ́ àti ète ni Bọ́lá ń lò láti má lè san owó-orí. | 0 |
Èéfín nìwà bí a bá so ó mọlẹ a à jáde. | 1 |
Ọmọ́tóyèṣe figbe bọnu lójú-ẹsẹ̀ tí ó rí òkú ìyá rẹ̀ lórí ìkọ́. | 0 |
Àwọn ọmọ ìyá méjì náà gbé ẹjọ́ ara wọn lọ sílé-ẹjọ́. | 0 |
Èró jìyà bí ẹni tí 'ò nílé. | 1 |
A kì í pa asínwín ilé, nítorí ọjọ́ tí tòde yó bàá wá sílé. | 1 |
Àṣopọ ní í m'éwúrẹ wékùn. | 1 |
Ìwádìí tún fi yé wa pé àrùn yìí lè máà fojú hàn lára ẹlòmíràn. | 0 |
Àkókó inú igbó ní àwọ́n lè gbẹ́ odó; ọ̀pọ̀lọ́ lódòó ní àwọ́n lè lọ́ ìlẹ̀kẹ̀; awúrebé ní àwọ́n lè hun aṣọ. | 1 |
Arákùnrin atọ́kọ̀ṣe kan fi ikú oró pa bàbá àti ìyá àgbàlagbà kan ní Àràdàgún. | 0 |
Àrò m ta kì í da ọbẹ̀ nù. | 1 |
Agbójúlógún fi ara-a rẹ̀ fóṣì ta. | 1 |
Àisínílé Ológbòjígolo, wọn dérí Eléwií mákoto. | 1 |
Ilé ẹjọ́ sọ wí pé òun kò gbọ́ ẹjọ́ Lóńgẹ́ mọ́. | 0 |
Eyin-Odi;eyin-iyà. | 1 |
Ó ní lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bẹ̀ ni olùjẹ́jọ́ tó padà wọnú ọkọ̀ náà. | 0 |
Kí àwọn ọmọ ìlú Ìbò má ṣe jẹ́ kí wọ́n kà wọ́n mọ́ ará ìlú ibòmíràn. | 0 |
Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ń fọ́jú onídàájọ́. | 1 |
Adéwálé kò farabalẹ̀ wo ilé nígbà tí ó dé Ìjegun ní àárọ̀. | 0 |
Èèyàn lè gbé alátakò ẹni lọ sí ilé ẹjọ́ pé kò ní ìwé ẹ̀rí. | 0 |
Bím̀bọ́ Akínsànyà rí ogun ilé-ejọ́ látàrí bí wọ́n ṣe fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn án. | 0 |
Ìjọba ti fi bàlúù mẹ́fà ránṣẹ́ fún kíkó àwọn ènìyàn kúrò. | 0 |
Dókítà ilé ìwòsàn méjì ló ṣe ìtọ́jú bàbá mi. | 0 |
Àwọn àkàndá ẹ̀dá náà lè kópa nínú àwọn ìdíje eré-ìdárayá. | 0 |
Àwọn ajínigbé kó sí akóló àwọn jagunjagun. | 0 |
Akéérú níí mọ ibi ọkú-ọpẹ, a mọkóó ní í mọbi amọ dunle. | 1 |
Ìjà bẹ̀rẹ̀ látàrí bí àwọn ọlọ́kadà kò ṣe gbà kí àwọn agbófinró gbé ọ̀kadà náà. | 0 |
Aládàá ló làṣẹ àro. | 1 |
Àtàm̀pàkò baba ìka. | 1 |
A ò ní dàámú lórí ọmọ láṣe èdùmàrè. | 0 |
B'ọrọ bá ń pẹ nílẹ; ń șe ló ma ń gbọ síì. | 1 |
Ilé ẹjọ́ ìjọba ti dá àwọn Fúlàní méjì tí wọ́n fi ẹ̀sùn ìjínigbé kàn sílẹ̀. | 0 |
Àwọn ọmọ olókùú fi tó àwọn iléèwòsàn náà létí pé àwọn ń bọ̀. | 0 |
Èèyàn mẹ́tàdínlógún kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ bọ́ọ̀sì. | 0 |
Bí a bá ń fẹ́ràn ọmọdé ní ilẹ̀kú, à mọ̀ pé a fẹ́ẹ́ fi sọfà ni. | 1 |
Inú dídùn ni ọ̀gá Iléeṣẹ́ fi kéde àṣeyọrí tí a ṣe lóṣù tó kọjá. | 0 |
Abùlàǹgà kì í ṣasán: bíyàá ò lọ́rọ̀, baba a lówó lọ́wọ́. | 1 |
Ẹgbẹ́ ẹni là ń gúnyán ewùrà dè. | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.