Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Adéwálé sọ wí pé ó yẹ kí ìlanilọ́yẹ̀ kọ́kọ́ ṣíwájú ìgbésẹ̀ àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́. | 0 |
Ewé ahùn la fi ń se ahùn ję. | 1 |
Àwọn ẹgbẹ́ agbá bọ́ọ́lù kan na ìkejì lọ́jọ́ ìsinmi olóyin. | 0 |
Àwọn iṣẹ́ Diméjì Ajíkòbí ṣì ń fọhùn lẹ́yìn ikú rẹ̀. | 0 |
Kò tí ì sí àkọsílẹ̀ kankan wí pé ọmọ orílẹ̀-èdè yìí kankan kú. | 0 |
Ẹlòmíràn sọ pé àwọn ìyànsípò yìí kò lè rẹ́sẹ̀ walẹ̀ rárá. | 0 |
Àì-mọwọ́-ọ́-wẹ̀ ni àì-bágbà-jẹ; ọmọ tó mọwọ́-ọ́ wẹ̀ á bágbà jẹ. | 1 |
Onírúurú ohun ìjà ogun gbọ́dọ̀ wà fún àwọn ènìyàn. | 0 |
A kì í kó imí tán kó tún máa rùn. | 1 |
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìyanṣẹ́lódì àwọn òṣìṣẹ́ fásítì ń ṣe àkọ́bá fáwọn. | 0 |
Èèysàn mẹ́rìnlá kú látàri ọkọ̀ bàálù tó jábọ́ ní Àbújá. | 0 |
Gbogbo ajá ló ń jemí èyí tó bá jẹ e lájejù ló di dìgbòlugi. | 1 |
Wọ́n sọ wí pé àwọn kò fẹ́ ohun tí yóò ba ilẹ̀ àwọn jẹ́. | 0 |
Wọ́n lu ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá náà pa lójú-ẹsẹ̀. | 0 |
Ó tó wákàtí kan àbọ̀ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ ohun tí wọ́n wá ṣe níbẹ̀. | 0 |
Èèyàn tí kò ní oníșáíì nì wọn ń bẹ l'ódeó-ku-àáro. | 1 |
Akì í w'Òròkò lái dé Fìdítì. | 1 |
B'Óbinrin bá gba kobo, yóó gba kọbọọrú. | 1 |
Balógun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olórin tí ajé rẹ̀ bu igbá jẹ jùlọ. | 0 |
Bó șe gín-íngín; ínú eegun níí lọ', Baba tí ń b'ọmọ rẹ pínre | 1 |
Ará sọ fun pé kó kúrò níbẹ̀ torí àjálù kan fẹ́ ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. | 0 |
Ajíṣafẹ́ ṣàlàyé pé kí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún tó ṣẹlẹ̀ lòun ti ń bá ọmọ ọdún mẹ́wàá ọ̀hún dọ́rẹ̀ẹ́. | 0 |
Àwọn arúgbó méjì tó di lọ́kọ-láyà lẹ́yìn ìbáṣepọ̀ ọgbọ̀n ọdún | 0 |
B'ójúmo bá mo Olówó a gbówó.t'òunt'erúko,omoode a a gbé pàáfin, omo àgbe a jítapótapó.· Bi àgbàlagbà bá sojú kònye bí eni pé yóò bu nije, | 1 |
B'Ójòwúbìnrin bá ń jowú, a ní tinú òun l'òun ń se. | 1 |
Àìmète, àìmèrò, lọmọ ìyá mẹ́fà fi ń kú sóko ẹgbàafà. | 1 |
Òwò tó pé ni ṣíṣe òwò káràkátà owó ilẹ̀ òkèèrè. | 0 |
A-lágbára-má-mèrò, baba ọ̀lẹ́ . | 1 |
Òṣùwọ̀n tí a gbé kalẹ̀ láti mú òṣìṣẹ́ tó dángájíá jùlọ níléeṣẹ́ wa kò yí padà. | 0 |
Àsese so ogbesì níí faraá jọ 'kù Osanyìn. (ikù Osanyìn, igi oko kan tí a tún n pè ní ìkù-ljẹbú) | 1 |
Olùkọ́ ló rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti lọ bu Ilẹ̀pa fún àtúnṣe sí ilé-ẹ̀kọ́ wọn. | 0 |
Ẹrẹkẹ nilé ẹrín, ìmú nilé ìkun. | 1 |
A kì í rí idà lọ́rùn eṣinṣin. | 1 |
A kì í bọ Ìrókò, ká bọ ewé orí ẹ. | 1 |
Ayé ò rọ àwọn mẹ̀kúnnù lọ́rùn rárá. | 0 |
Àwọn agbébọn yin ìbọn mọ́ Bọ́látitó lápá nínú ìkọlù àná. | 0 |
Dókítà kan forí kó ìyà lọ́wọ́ àwọn alárùn ọpọlọ tí àlàáfíà ti ń tó náà. | 0 |
Eni a rò pé kò leè pàgo, ó kolé aláruru. | 1 |
Àgùntàn pòpó ṣe ońdè lọ́rùn: oníkálukú a-bi-tiẹ̀-lára. | 1 |
B'éèyàn ò níyàá, kì í jàbọ-ọjà. | 1 |
Bí ẹkẹ́-ẹ tálákà ò tó lówùúrọ̀, á tó lálẹ́. | 1 |
Aṣiwèrè èèyàn ní ń sọ pé irú òun ò sí; irú rẹ̀ pọ̀ ó ju ẹgbàágbèje lọ. | 1 |
Àkèré ń gbọ́ tọmọ ẹja lódò. | 1 |
Àdùnní jẹ́bi àdínkù tó bá owó àjọ mi nítorí ọwọ́ ẹ̀ ló wà. | 0 |
Etí tó gbo àyùn (àlọ) náà níí gbọ àbo. | 1 |
Wọ́n ti gbé márùn-ún tó fara pa nínú ìjàmbá lọ sí ilé ìwòsàn Ìdẹ̀ra. | 0 |
Gbogbo Ọyà l'ó ń pe'ra 'ẹ lódú. | 1 |
Abíọ́lá sọ wí pé ó yẹ kí a gbé ọwọ́ àdúà sókè fún ààrẹ wa ni. | 0 |
Bí ìyà ńlá bá gbéni ṣánlẹ̀, ké-kè-ké a máa gorí ẹni. | 1 |
Ojú fèrèsé ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbà jáde nígbà tí olùkọ́ wọlé. | 0 |
Àwọn ará ìlú sọ wí pé àwọn ọkọ̀ àjàgbé yìí ni wón ń dá sún-kẹrẹ-gbà-kẹrẹ sílẹ̀. | 0 |
Àwọn yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ ìgbàlódé ni Sanwó-Olú ń kọ́. | 0 |
Ará bàję, olùkù kọ o. | 1 |
B'áyé 'ò rójú, (l'óde Qyọ) a 'ò se bẹbẹ; bẹệ la ò soworà. | 1 |
B'ágbàlagbà bá lóun ò mọ ohun tó lé ejò wọhò; ìkà ni. | 1 |
Ení dènà fún ni kẹrù, ọkùnrin ni. | 1 |
Bólóde ò kú, ojúde rẹ̀ kì í hu gbẹ́gi. | 0 |
‘‘Gba àkàṣù bàm̀bà’’ lóṣù agà ni ‘‘Gbé ń nú agánrán’’ lẹ́ẹ̀jọ̀dún. | 1 |
A kì í fi ohun sọ́wọ́ búra. | 1 |
Bí ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ régérégé bá ro ẹjọ́-ọ tirẹ̀ tán, kó rántí pé ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ mẹ́kí á rí rò. | 1 |
Ẹni tí kò nírú ẹni, kì í mọyì eni. | 1 |
Àtẹ tí a fi ń pàtẹ ilẹkẹ; a kì í fi i pàtę orúlá. | 1 |
Àwọn ọkọ nínú ìdílé ń gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ọmọ wọn. | 0 |
Ębiti 'ò p'Eèrà, k'á șe pęlepele, eni eni nii seni. | 1 |
Àfi kí wọ́n ṣe ohun tó tọ́ ni wọ́n fi lè yanjú gbogbo ìṣòro tó wà nílẹ̀. | 0 |
Adélànà ní ọmọ òhun ń gbìyànjú láti dá ààbò bo ẹ̀mí mi àti gbogbo àwọn ènìyàn tó kù tí ó fi kú. | 0 |
Àgbàká lèéfí ń gba igbó. | 1 |
A bímọ nílé ọgbọ́n, a mú u relé ìmọ̀ràn lọ wò, nígbà tí ó ń bọ̀ ó pàdé òye lọ́nà; ọgbọ́n ni kò níí gbọ́n ni, tàbí ọ̀ràn ni kò níí mọ̀; tàbí òye ni kò níí yé e? | 1 |
Àwíyé nIfẹ̀ ń fọ̀; gba-n-gba lOrò ń pẹran. | 1 |
Ẹ̀là lọ̀rọ̀; bí a ò bá là á rírú ní ńrú. | 1 |
Àràbà se bí eré dìjí. | 1 |
Àtatu n ti gbegi. | 1 |
Àgbẹ̀ kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ agbébọn nílùú Oǹdó. | 0 |
Àkókó kun osùn ó kun orí; arèré kun osùn ó kun àyà; olóbùró kun osùn ó kun ọ̀fun. | 1 |
Ògúnbà sọ wí pé àwọn ti mú agbódegbà fún afurasi ọ̀hún náà. | 0 |
A-dìtan-mọ́ èsúó; ó ní èkùlù ló bí ìyá òun. | 1 |
Bí ó tí mmọ ní ó mọ; Ọkọ-ìyàwó yóó lọdìí | 1 |
Bí a bá bú ọba, à sẹ́; bí a bá bú ọ̀ṣọ̀run, à sẹ́ . | 1 |
Agbèfọ́ba kì í jẹ̀bi fún un. | 1 |
Àfòmọ́ ò légbò; igi gbogbo ní ń bá tan. | 1 |
Elẹdẹ ń pààfọ ó sẹ bí òun ń soge. | 1 |
B'áso pẹ lokee a hù (bu). | 1 |
B'Óníyàrá 'ò sùn, elẹsẹé 'ò tẹní. | 1 |
A kì í bọbùn l'oșọ pọ (dá ànńkò) | 1 |
Bákan náà ni Owólabí tún jẹ́ olóyè láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn. | 0 |
A kì í walẹ̀ fún adìẹ jẹ. | 1 |
Àwọn ènìyàn agbègbè omi ni ilẹ̀ rírì máa ń ṣe àkóbá fún jùlọ. | 0 |
A sìnkú tán, alugbá ò lọ; ó fẹ́ẹ́ ṣúpó ni? | 1 |
·Bi a 'ò rẹni àtàtà fínúhàn, (bá sọrọ àsírí) mọ; kí a kọrọo wa dàsíkùn eni. | 1 |
Àwọn agbaṣẹ́ṣe tí Sanwó-Olú gbé àwọn ọ̀nà náà fún mọ iṣẹ́. | 0 |
Ìjọba ní òun kò ní gbà bí àwọn ènìyàn kò bá gbọ́. | 0 |
Bí eégún eni bá jóore, orí a má a yá Atọkùn | 1 |
Àwọn aláṣẹ ìjọba ilẹ̀ òkèèrè ti gbé ẹsẹ̀ lé owó tó jẹ́ ti Bọ́lá. | 0 |
Alága sọ wí pé ààbò tó péye wà fún ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn. | 0 |
Àtẹ̀jáde lórí ìnáwó ìjọba kò dọ́gba. | 0 |
Àwọn aláìsàn ọpọlọ tí wọ́n ń gba ìtọ́jú ní Arò ṣe ìwọ́de. | 0 |
A lè mọ̀ nípa àwọn ohun àlùmọ́nì ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun láti ara àwòrán ìdánimọ̀ tuntun. | 0 |
Ààfáà-á jóná, ẹ̀ ń bèrè irùgbọ̀n; kí ló fa sábàbí? | 1 |
Olorì tó kúrò nínú ààfin ti ń bẹ̀bẹ̀ láti wọlé padà. | 0 |
‘‘Mo ròkè ọgbà mo tètè bọ̀’’: a lè fi wé tẹni tí ò lọ? ‘‘Àkèekèé ta mí kò tù mí’’: a lè fi wé ẹni tí sèbé bùjẹ? | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.