Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Àtípìjí, a-wúwo-bí-àtẹ-ìbànújẹ́ ; ìbànújẹ́ dorí àgbà kodò. | 1 |
Àwọn ọlọ́pàá ti yin gáàsì tajútajú sí àwọn ọ̀dọ́. | 0 |
Ajìjàgbara ni Àdìsá ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. | 0 |
A ìí rojo wíwò kí á jàre. | 1 |
Ẹni fẹ j'oyè kì í rìn láàjìn òru. | 1 |
Eku ò gbọdọ̀ ná ọjà tí ológìnní dá. | 1 |
Abùléra ọ̀fọ́n-ọ̀n: ó ní ọjọ́ tí ológbò-ó ti bí òun ò ìtí-ì dá a ní báríkà. | 1 |
Àitètèfeyàwó, ọrẹ làá tọjú. | 1 |
Mi ò mọ̀ pé bí ìwà àwọn ènìyàn ti burú tó rèé. | 0 |
Bí ọmọ ṣe ń wá sáyé náà ni èèyàn ń jáde kúrò láyé lójóojúmọ́. | 0 |
A kì í re nísun lọ dà síbú. | 1 |
B'óòrún bá yọ; a á kárí-ayé. | 1 |
B'óbìnrin 'ò dánlé-ọkọ méjì wo, kò ní mọyí tó da. | 1 |
Haúsá l'óun jẹrìí ìyá òun kò jẹ kọ lẹtà sí òun. | 1 |
Ọ̀gá àwọn jagunjagun sọ wí pé àwọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọlọ́ṣà. | 0 |
Ara 'ò rọ èké; ọkàn òșìkà 'ò balę. | 1 |
Àjọ eleto ìdìbò kéde ọjọ́ tí ìdìbò ààrẹ Nàìjíríà ọdún tó ń bọ̀ yóò wáyé. | 0 |
Èbìrìpò tó rọ, a kì í tà á sílé. | 1 |
‘‘Gbà mí, gbà mí!’’ ò yẹ àgbà; àgbà kì í ṣe ohun àlémú. | 1 |
Ìwà tí àwọn ọlọ́pàá hù kò tẹ́ àwọn ará ìlú lọ́rùn. | 0 |
Àjà ti sẹ, kílé tó jó. | 1 |
A kì í t ní fún ẹni ilé jókòó. | 1 |
Àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n. | 0 |
Wọ́n ní ó ti fi gbogbo iyì tó wà lára ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olorì Ikú bàbá yèyé lọ́dọ̀ Òkìkíọlá. | 0 |
Kò sí ẹ̀mí kankan tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ọkọ̀ àjàgbé tó wáyé nílùú Ìsẹ́yìn lọ. | 0 |
Egúngún t'óbìnrin bá ń tẹlé kì í tẹ. | 1 |
Ìlú Adó-Èkìtì ni ọwọ́ ti ba àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta nígbà tí wọ́n ń kiri àwọn ẹrù òfin. | 0 |
Ilé ìyá afurasí ọ̀daràn ní agbègbè Òkúsà ni ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ti wáyé. | 0 |
Aṣeburúkú tẹsẹ̀ mọ́nà. | 1 |
Ẹ̀gbọ́n ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló ṣe agbátẹrù sísan owó ìrìnnà wọn. | 0 |
Bí a kò bá rádànán, à fòòbẹ̀ ṣẹbọ. | 1 |
‘‘Wó ilé ẹ kí n bá ọ kọ’’: ẹrù ikán kan ní ń pa fúnni. | 1 |
Adẹ́tẹ̀ sọ̀rọ̀ méjì, ó fìkan purọ́; ó ní nígbà tí òun lu ọmọ òun lábàrá, òun já a léèékánná pàtì. | 1 |
Àwọn aráalé sáré lọ fọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí. | 0 |
Akitiyan àwọn agbófinró jẹ́ kí ó rọrùn láti rí owó gbà padà. | 0 |
Ení bá se burúkú gọ. | 1 |
Adénúgà máa ń gbárùkù ti Ojúde Ọba. | 0 |
Àwọn kan sọ pé ìjọba ò fẹ́ ta epo ni. | 0 |
Ėyí kó tójà', ló n bí oníjà nínú. | 1 |
B'ọgbọn bá tán agbára ní í kù. | 1 |
Àwọn ajínigbé ọ̀hún tún ní oko igbó mímu. | 0 |
Kò ní sí iṣẹ́ bí àwọn alákòóso kò bá fi dá wọn lóhùn. | 0 |
Ẹ̀fẹ́-ẹ́ dẹ̀fẹ̀ iyán; ò báà gbémi lulẹ̀ n ó bàá ọ jẹun. | 1 |
Ní kété tí wọ́n fà á lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ ni àwọn ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí. | 0 |
B'á a b'Òkun wẹrí, bí a b'Ọsàwese; OlorunWe ló n mo roro. | 1 |
A kì í dájọ orin kíkọ, b'ó bá ti wá sí ni lára làá kọ ọ. | 1 |
Àbá pé ka fi ọ̀rọ̀ náà lọ bàbá àgbà dára. | 0 |
Dídán là ń dán ọ̀ràn wò; bí olówó ẹní kú, à lọ ṣúpó. | 1 |
Gbà mí, gbà mí làá gbà, kò s'ẹni tó ń gba, 'kò-sí-nnkan.' | 1 |
B'éèyàn 'ò bá sọnú, yóó sọnù. | 1 |
Ẹni pòòyì șe dię ní tÀgbó. | 1 |
Hààhin' làá fọ l'ésì sejo alápepe. | 1 |
A ní ká jẹ ìrọ̀ kó rọni, ó tún ń fúnni lọ́rùn. | 1 |
Àwọn adarí ilẹ̀ Nàìjíríà ń ṣèdárò Tola ọmọ ilé-ìwé tó papòdà. | 0 |
Àtètèdáyé ò kan tọrọ̀; Ọlọ́run ní ńṣe orí owó. | 1 |
Ó láwọn ti kó àwọn tó fara gbọgbẹ́ lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní Ìjẹ̀bú-òde. | 0 |
Àjọ kan ké sí ààrẹ lórí èròngbà àwọn eeyan lórí ìforúkọsílẹ̀. | 0 |
Àwọn olorì ti ń kú rò nílùú lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan nítorí àìsàn ọba. | 0 |
Ìròyìn àfẹ̀mọ́jú òní bani lẹ́rù púpọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. | 0 |
‘‘ Ọ̀la ni mò ńlọ,’’ tí ńfi koto ṣe àmù. | 1 |
Ó sọ pé òun gbà pé èṣù ló yá òun lò. | 0 |
Agbájé l'ówó, ọmọọ rẹ l'óògùn, fún ànfààní àdúgbòò wọn ni. | 1 |
A kì í torí-i gbígbó pa ajá; a kì í toríi kíkàn pa àgbò; a kì í torí-i wérewère pa òbúkọ. | 1 |
Èdè kan tó yé e ni àtìmọ́lé, fífi òfin gbéni, àti àwọn tó kù rẹ̀. | 0 |
Adelé Gómìnà fi èyí hàn nínú lẹ́tà kan tó fi ṣọwọ́ sí ọba alayé ìlú Òndó. | 0 |
Àwọn ìṣòro tí mo máa dojúkọ pọ̀ gidi. | 0 |
Ọkọ̀ méjì tí àwọn agbófinró kún inú rẹ̀ ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi ránṣẹ́. | 0 |
B'ọwọ 'ò bá silẹ, kò ní si ẹnu. | 1 |
Àwọn ọkùnrin náà yóò wá láti wa ṣe ojúṣe wọn ní ilé wa. | 0 |
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méje kú lójú-ẹsẹ̀ pátápátá nígbà tí Ilẹ̀pa wó. | 0 |
Àyìnlá Ọmọwúrà ní ohùn tó gbòòrò tó sì dùn ún gbọ́ létí. | 0 |
Ó yẹ káwọn aláṣẹ ìjọba Nàìjíríà tètè wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn agbébọn. | 0 |
Ẹ̀hìnkùlé lọ̀tá wà; ilé laṣeni ń gbé. | 1 |
Ó dàbí ẹni pé àwọn aṣíwájú inú ìjọ kò fara mọ́ àbá tí a mú wá. | 0 |
Abíọ́lá sọ wí pé "ìgbà ọ̀tun ló wọlé yìí" | 0 |
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ni wọ́n há sí Ìlú Súnmọ́mi báyìí. | 0 |
Àwa ni wọ́n ń fìyà jẹ jù. | 0 |
A-ṣoore-jókòó-tì-í, bí aláìṣe ni. | 1 |
Eni to tijú fun ni là á tijúú fún. | 1 |
Bí ó pẹ́ títí, àlejò á di onílé. | 1 |
Àwọn òṣèré máa ń kúrò nílé fún ọjọ́ púpọ̀ nígbà mìíràn. | 0 |
Àwọn alákoso fásitì Èkó ò fẹ́ ìwọde àwọn akẹ́kọ̀ọ́. | 0 |
Ení bá wí làá gbo. | 1 |
Àwọn jàǹdùkú kan já ọ̀kadà Bajajì gbà lọ́wọ́ Babarìndé. | 0 |
Àgbẹ tí ò kọ àkùrọ, kì í jiyán Ọsán. | 1 |
Alẹ́ ọjọ́ Ẹtì ni ìbọn ba Àjàlá ní ìlú Ìjẹ̀bú ní ìpínlẹ̀ Ògùn. | 0 |
Bí orí ṣe kó mi yọ tí mo sá jáde nìyẹn. | 0 |
A rí ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó fẹ́ pokùn so nínú fọ́nrán kan. | 0 |
Húnùnhúnùn inú ęlẹdę, inú e ló ń gbé. | 1 |
Adìẹ ò bí yọyọ kú yọ̀. | 1 |
Àwọn òbí tọkọtaya méjèèjì ni wọ́n fi ọwọ́ sí i pé kí ìgbéyàwó náà tú ká. | 0 |
Ẹrín 'ò dún leeemejì. | 1 |
Aṣe-má-mọ ò sí, a-mọ-má bèèrè ló wà. | 1 |
A kì í ní agbára kékeré ṣe èkejì. | 1 |
Ẹni tí ń dẹ'lé Òkété, Ọlọrun Níí dẹdí òun náà. | 1 |
Àwọn ọlọ́pàá dóòlà agbẹjọ́rò tí wọ́n jígbé ní Òṣogbo. | 0 |
Abẹ́rẹ́ àjẹsára náà dára láti dènà àìsàn ibà. | 0 |
Eégún ju eégún; òrìṣá ju òrìṣà; Pààká lé oníṣàngó wọ̀gb . | 1 |
‘‘Mo mọ̀-ọ́ gún, mo mọ̀-ọ́ tẹ̀’’ niyán ewùrà-á fi ń lẹ́mọ. | 1 |
Àwọn òṣìṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ikọ̀ ọmọ ogun. | 0 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.