Proverbs
stringlengths
8
373
Labels
int64
0
1
Adébọ́lá wa ọkọ̀ gúnlẹ̀ sáàárín ọ̀nà nígbà tí wọ́n ń lọ ilé ìjọsìn.
0
A kì í sòwò ìbòsí k'ágbọn isàlẹ ó torí ẹ ya dànù.
1
Màríà sọ pé wọ́n yìnbọ̀n pa ènìyàn méjì níwájú òun.
0
B'áwo ò mu bàbà, báwo ò mu sẹkẹtẹ, awo kì í níyè olóókan nínú.
1
Bí a wí fọmọ eni, a á gbọ; Orí Òkẹrę koko láwò.
1
Ọwọ́ ba àwọn tí wọ́n kọ̀ láti séra ró.
0
B'érì bá sę, ewé-oko a jí pépé.
1
Ẹ ṣeun gan-an ni fún àtìlẹ́yìn-in yín.
0
Ó fi yé ìyá rẹ̀ pé kí ó máà da ara rẹ̀ láàmú lórí lọ́yà gbígbà.
0
Amẹ́ríkà yóò ran Nàíjíríà lọ́wọ́ nípa ètò ajé, okòòwò, ààbò àti ẹ̀kọ́.
0
B'ójúmo bá mọ; a kì í yọgbẹrì bíi ọjo àná.
1
Àṣá ń b'ẹyẹlẹ ṣeré, ẹyẹlẹ ń yọ ẹyẹlé ń fikú sere.
1
Bó ti wá ni yó lọ; ọ̀gbẹ̀rì ò jẹ iyán odù.
1
Ọọ́fíìsì ọ̀gá àgbà fún ètò abẹ́lé ti fòpin sí ìgbani-síṣẹ́.
0
Àtàrí obìnrin 'ò gberù, ni ò jẹ a mú obìnrin rèé mawo.
1
Àtàm̀pàkò ò ṣéé júwe ọ̀kánkán.
1
Àwọn aráàlú ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn nítorí wọn kò mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀.
0
B'ọmọ bá șe gbọrọ mọ, ló fi ń ní láàrí mọ.
1
Àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan lorílẹ̀-èdè yìí máa ní ìwọ́de lórí ìfipábánilòpọ̀.
0
Bí ojú ọmọdé ò tó ìtàn, a bá àwígbọ́.
1
Ẹgbẹ́ búburú ní ń ba ìwà rere jẹ́.
1
Dídà ló dà, ľ'ọmọo d'ẹgbẹé; ẹgbẹ kì í se'lé-ọmọ.
1
Wọ́n ti gba ohun tí Tolúlọpẹ́ fi pa Ògúnrónbí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí.
0
Ìrètí ọlọ́kadà ni pé kí òun tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò òun bí òjò bá rọlẹ̀.
0
Ẹní fún ni lọmọ ní í retí igbe.
1
Ẹní máa rọyìn ejò, a á gb'owọ lutan.
1
Ìṣẹ́jú díẹ̀ ló kù tí a óò fi kádìí ètò tí à ń ṣe nílẹ̀.
0
Àìtà ni àdánù onígi.
1
Adiẹ tí kò ì kú șì lè ję yangan.
1
Ìjọba àpapọ̀ ti kéde ọjọ́ ìṣègùn gẹ́gẹ́ bí àyájọ́ ọjọ́ ìsàmì ọjọ́ àwọn òṣìṣẹ́.
0
Àgbàlagbà tó ń gun ọ̀pẹ, bó bá já lulẹ̀ ó dọ̀run.
1
Àgbà ti ò mọ̀wọ̀n ara ẹ l'odò ń gbé lọ.
1
Àgbà kì í fàárọ̀ họ ìdí kó má kan funfun.
1
Aláàjàá gbé e sókè, o ní, ‘‘Kó ṣẹ!’’; o mọ̀ bí ibi lówí tàbí ire?
1
À ń kọ́lé ikin, à ń yọ̀dẹ̀dẹ̀ imọ̀, hòrò ni ilé àgbékẹ́hìn.
1
Abẹ́rẹ́ kì í nù tòun tòwú nídìí.
1
Ó máa ń kó àwọn nǹkan ọ̀sìn tí ó bá rí lọ́pọ̀lọpọ̀.
0
Àgbéré lẹyẹ ń gbé; kò lè mu omi inú àgbọn.
1
Àkẹtẹ kì í lẹ lẹ lẹ kí ó má leè dá orí kan dé.
1
Ẹdá 'ò l'áròpin, Sábárúmọ ń ra Mọtò; wọn ń kọlé.
1
Aládé kì í kọ Orẹ/Àkọ-ápò l'aládéé kọrẹ.
1
Bí ojú bá sé ojú; kí ohùn má yẹ ohùn.
1
Àwọn òbí Ayéọ̀la kò rokàn pé eré fíìmù ni ó máa ṣe là láyé rẹ̀.
0
A ní kó múwá, ó ní kò sí; ahun ni lójú alágbe.
1
A-fọ́nú-fọra ní ń fi òṣì jó bàtá.
1
Omi kò ní ọ̀tá ṣùgbọ́n kòṣeémánìí ni omi jẹ́ fún ọmọnìyàn.
0
A ò morí olówó láwùjọ, a 'ò m'ẹsẹ òtòșì lọnà.
1
Àwòrán ṣètè kólóbó, igi tá-a bá gbẹ́ léhín ò lè bunijẹ.
1
Oyètọ́lá fúnraẹ̀ mọ̀ pé ìyẹn kì í ṣe ìfẹ́ àwọn ará Ọ̀ṣun.
0
Àṣá kì í rà kádìẹ gbé kòkòrò dání.
1
Asèyówùú bíi ìyàwó-ajẹrìí (iyàwó alárédè).
1
Aájò ș'òroó șe lÉkòó Àkéte. B'óo ní:
1
Àwọn jàǹdùkú agbébọn lé àwọn èèyàn kúrò ní abúlé àádọ́ta.
0
Ẹni ti 'ò rántí àná, kò leè mọyì òní, kò ní b'erù ola.
1
Àńtètè, ó dá yànpọ̀n-yànpọ̀n sílẹ̀.
1
Wọ́n tọpinpin àrùn ọ̀hún dé inú ọjà tí wọ́n ń ti ń ta oúnjẹ odò.
0
Àò-m'ẹni-tó-wù, tó délé ànọ rẹ tó yọ 'lagbá nínú șòkòtò. (Nnkan omokùnrin rẹ ni 'lagbà', túmọ sí)
1
Gbogbo ìgi ló ń s'owó, ọtọ ni tobì.
1
Lára àwọn ọlọ́pàá ti ń jẹ́jọ́ lórí bí wọ́n ṣe jẹ́ kí gómìnà ìpínlẹ̀ Kogí àná sá lọ.
0
Ẹní bímọ, kí la rí fún un, bèlènté ẹní tó ń bínú.
1
Àlùmọ́nì: ó ní ẹni tí òun bá wà lọ́wọ́-ọ rẹ̀ ló ni òun.
1
Akẹ̀sán lòpin Ọ̀yọ́; ilé ọkọ nibìsinmi obìnrin.
1
Kò sẹ́ni tó mọ ọjọ́ tí wọ́n bí Wàídì Àyìnlá Ọmọwúrà.
0
Olúṣọlá fo ìgànná lẹ́yìn tí ó gún àwọn ọlọ́pàá.
0
Bídií bá bàjẹ t'onídìí ló ń dà. ìdí tó bàję, alágbẹde 'ò sì rí i rọ.
1
Ajá kú ó feegun sílé ayé; adìẹ funfun-ún kú ó tu ìhùùhù gbugbu; ìgbín kú ó gbàgbé ìkaraun.
1
Ajá gbó l'óko, wọn 'ò gbélé gbọ.
1
Àtàrí wo ọ̀run mọmọ bí ẹnipé kò ní ibẹ̀-ẹ́ rè; oye ojú tó wo ayé ni yó wo ọ̀run.
1
Bí a bá ní kí wèrè ó șòkú-iyá ẹ bó bá șe fẹ; yóó bẹbí l'órúko je.
1
Oòrùn tó ń mú ní àsìkò tí a wà yìí kò dẹrùn rárá.
0
‘‘Fínná fún mi!’’ ‘‘N ò fínná fún ọ!’’ ní ń dájà sílẹ̀ lárọ. ‘
1
Dòsùnmú ní àwọn akọ́sẹ́mọsẹ́ dọ́kítà òyìnbó ló ṣe isẹ́ abẹ ọ̀hún.
0
Àwọn ajínigbé kàn ń wa ọkọ̀ kiri àwọn àdúgbò kan.
0
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì láti ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ lọ.
0
B'ẹdàá 'ò bá mọnà-òwò, kò leè mọná owó.
1
Àwọn ará ìlú béèrè èsì ìdìbò lọ́wọ́ òṣìṣẹ́ àjọ èlétò ìdìbò.
0
Ààfáà-á sọ̀rọ̀ òjò-ó kù; ó ní Ọlọ́runún jẹ́rìí òun.
1
Adébóyè ní ó yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà fún wọn.
0
Olóṣèlú méjì wà lára onígbọ̀wọ́ àwọn ọ̀daràn.
0
Bí obìnrín bá di méjì, imú ọkọ a di odó, a ní wọn ò tún yí imú lu òun mọ́.
1
Àwọn ajìjàgbara sọ pé àwọn ò ní dúró de ìrànlọ́wọ́ ìjọba.
0
Bùn mi, kí n bun ọrẹẹ mi', owọo ta la ó ti dúpe?
1
Diẹ, diẹ ọmọ-ògòngò yóó múyàá ẹ wá.
1
Adarí fún àwọn ọmọ ọgọ́fà tí wọ́n bí lọ́jọ́ ọdún tuntun lẹ́bùn.
0
Eleran ló làkọbí.
1
“Bí mo bá gúnyán n ó bùn ọ ję”. “Bí mo bá rokà, n ó bùn ọ ję.”Ibi ẹsun-ișu là á ti í mọ.
1
Edá lára
1
A kì í rídìí òkun; a kì í rídìí ọsà; ọmọ-oní-gele-gele kì í jẹ́ kí wọ́n rídìí òun.
1
Ìkọlù àwọn darandaran ti mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn fi ilé ìgbé wọn sílẹ̀.
0
Gbogbo nnkan nilẹ ń jẹ, ilẹ kì í jẹ iwà.
1
Ako-igi kì í soje.
1
Páítọ̀ tí wọ́n jí gbé pàdánù ìyá rẹ̀ láìpẹ́ yìí.
0
Adégbémilé sọ pé ìyàwó òun kì í jẹ́ kí àwọn ṣe eré yùnkẹ́yùnkẹ́.
0
Alápàáǹdẹ̀dẹ̀ ń jayé lébé-lébé.
1
B'ílé bá dàbí oko, ťóko dàbí ilé, ọkan làá fọwọo mú.
1
Akúnleyàn òun làdáyébá
1
Ó ní káwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn yọjú sí àwọn aṣòfin lẹ́yẹ-ò-ṣọkà.
0
Ọwọ́ tẹ Àlàbí níbi tí ó ti ń jí ewúrẹ́ nílùú Àkúrẹ́.
0
Bí aráyé bá ṣìkà tán, wọn a tún báni dárò.
1
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ojú pópó ti gbé àwọn tó fara pa níbi ìjàmbá lọ sí ilé ìwòsàn..
0