Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Bùsáyọ̀ ni ó ṣe ipò kejìlá nínú ìdánwò tó kọjá. | 0 |
Rìnsọ́lá kọ̀ jálẹ̀ lórí ohun tí Fákẹ́yẹ sọ. | 0 |
Ẹrú ọkọ ẹni; kò gbọdọ rí ìòòhó eni. | 1 |
A kì í fún ni l'ádiẹ sìn; kí a tún máa ka'ye ẹyin tó yé. | 1 |
Adédàmọ́lá ní kò sí ibi kankan tí àwọn ènìyàn lè sálọ láti fi orí wọn pamọ́ sí mọ́ báyìí. | 0 |
Eni a fọrọ lo tó ń tòún bàje, kí ni k'olọrọ ó șe. | 1 |
Bí ó bá bá ojú, á bá imú pẹ̀lú. | 1 |
Àgbàlagbà kì í se láńgbáláńgbá. | 1 |
Ẹni 'ògbàgbéàná;nií s'ọmọ òkú pẹlẹ. Ẹni rántí ojọ; níí s'ọmọarúgbó lóore. | 1 |
Mo dọ́gbọ́n sá pamọ́ sí balùwẹ̀ nígbà tí mo gbúròó ẹsẹ̀ àbúrò Àjíún. | 0 |
Ìròyìn ayọ̀ wọlé ìdílé òṣèrébìnrin ilẹ̀ wa lọ́jọ́ Ajé. | 0 |
Àwọn ẹgbẹ́ tí wọ́n kó ara wọn jọ yìí kò ní àṣẹ láti ọ̀dọ̀ ìjọba. | 0 |
Elègbè [or elégbè] ní ń mú orin dùn. | 1 |
Binisí-binisí: ọ̀tá ilé ò rí kòtò bini sí. | 1 |
Aboyún kì í gbọn kílẹ má jẹ lára ẹ. | 1 |
Àwọn ará ìlú béèrè fún ọ̀nà láti ọ̀dọ̀ ìjọba. | 0 |
Akúwárápá gbé adẹ́tẹ̀ șánlẹ̀, gẹ́gẹ́ șe gẹ́gẹ́. | 1 |
Adájọ́ Olúwatóyìn Táíwò dá Bàbá Ìjẹṣà lẹ́bi. | 0 |
Mo fẹ́ di agbẹjọ́rò, mo sì tún fẹ́ máa ṣe ohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí jùlọ. | 0 |
Degbedegbẹ ló ń ș'ọmọ àparò kujékujé ęyę. Àwọn apàjùbà níbalé àparò je yánányán. | 1 |
Ajá èṣín ò mọdẹ. | 1 |
Ako-ológbò níí m'ówó rá. | 1 |
Ó ní fọfọọfọ ni inú mọ́ṣáláṣí náà máa ń kún lásìkò ìrun. | 0 |
Bí a bá sọ idà sílẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹwàá, ibi pẹlẹbẹ ni yóò dà délẹ̀. | 1 |
B'éèyàn bá l'óun ríbà (júbà) Ìtá,tó ríbà Ìrele,tí toúnòriba Eégún-ilé, ibà rẹ 'ò pé. | 1 |
Àkàsọ̀ faratilẹ̀ faratilé; bí ẹni tí a fẹ̀hìntì ó bàá yẹni a wí fúnni. | 1 |
Ajá ò torí èèyàn ṣ'ọdẹ torí ajá lajá ṣe ń ṣọdẹ | 1 |
B'ólóko bá jágbọn esę-bú bú, olè a sì jàgbọn kíkó tinú àbàtá lọ. | 1 |
Àgbà tí kò mọ ìwọ̀n ara-a rẹ̀ lodò ń gbé lọ́. | 1 |
B'ọmọdé bá fojú ba alákàrà, a á sọșu nù. | 1 |
Ẹní tí kò l'ówó lọwọ; ìwà oníwà ló ń hù. | 1 |
Mi ò mọ̀ pé màá padà jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà nígbẹ̀yìn ni. | 0 |
A kì í kú sílẹ d'aṣọ orí-òfi. | 1 |
Bí òwe ò bá jọ òwe, a kì í pa á. | 1 |
Bàbá Sùwé ló yẹ kí ó jẹ ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn òṣèré Yorùbá | 0 |
Bí àgbàlagbà-á bá ń ti orí jẹ àkèré, kọ́mọdé má nìírètí ati jẹ níbẹ̀. | 1 |
Ajá tó ń lépa ẹkùn, ìyọnu ló ń wá. | 1 |
Àwọn aráàlú ní ó yẹ kí ìyansẹ́lódì àwọn olùkó ti dópin. | 0 |
A ní ìrókò ni yó pa ọmọdé, ó bojú-wẹ̀hìn; òòjọ́ ní ń jà? | 1 |
Àjàkálẹ̀-àrùn túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní ìlú Ìràwé. | 0 |
Ó gbìyànjú láti mú ọ̀daràn náà àmọ́ wọ́n yìnbọn fún un lápá. | 0 |
Àwọn èèyàn kan ní alárùn ọpọlọ ni Tọ́pẹ́. | 0 |
Biyàá 'ò sebẹ, ọmọ a á gbóòórùn-un tita. | 1 |
Bí a se ń palé kọ la se ń para. | 1 |
Aríkọgbọn kẹkẹẹ, Bánkọlá. | 1 |
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àgbẹ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè Afíríkà lé ní Ẹgbẹ̀rún lọ́nà Ọ̀ọ́dúnrún ní ye. | 0 |
Àwọn ajínigbé máa ń fún àwọn obìnrin tó bá ń ṣe nǹkan oṣù ní àkísà. | 0 |
Àdìó sọ wí pé láti kékeré ni àwọn ti ń retí èyí. | 0 |
A kì í pagún, a kì í figún bọrí. | 1 |
A fẹ́ra sọ́nà fún bí oṣù méje. | 0 |
Ọ̀gá àwọn jagunjagun yóò fi ojú àwọn ẹni afurasi hàn. | 0 |
Ẹ wo àwọn ọkọ̀ bọ̀gìnì tí ọ̀dọ́mọdé olówó kó jọ. | 0 |
Ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn Abẹ́yẹfò ló kọ́kọ́ gbé ìròyìn ọ̀hún. | 0 |
Afínjú méjì kì í wo òjìji wọn nínú agada. | 1 |
Ẹnìkan sá lọ lára àwọn tó lùgbàdi àjàkálẹ̀-àrùn. | 0 |
Àpọ́n tọrọ ọbẹ̀; kò mọ oye à ń kólá. | 1 |
Ayé le, èèyàn-án burú ju ẹkùn. | 1 |
Abẹ́rẹ́ tó ń dènà de ara sísan tún lè ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní fún àwọn àgbàlagbà. | 0 |
Èèyàn tí 'ò l'ẹni l'ẹyìn nií jọpọ ìyà. | 1 |
Eni ará rọ níí kan àkànpọ ẹwù. | 1 |
Bí gbogbo afínjú bá lọkọ tán, ọbùn á ní. | 1 |
Ipá àwọn èèyàn pin nígbà tí ilé ẹjọ́ da ẹjọ́ wọn nù. | 0 |
Bá ò kú ise ò tán. | 1 |
Ẹte tí yóó fi wọn sẹsín góngó-imú níí t ií mú wọn. | 1 |
Àwọn mọ̀lẹ́bí afurasí ti sọ àsọyán ọ̀rọ̀ lórí agbẹjọ́rò tí yóò dúró fún ènìyàn wọn. | 0 |
A kì í fẹlẹnu méjì lÓòsà bọ. | 1 |
Àrẹ̀mọ ni orúkọ ìnagijẹ tí Balógun kọ́kọ́ pe ara rẹ̀. | 0 |
Ẹ̀sùn pé pásítọ̀ ṣekú pa obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tóyìn ni ó gbé e dé ilé ẹjọ́. | 0 |
Àwọn ènìyàn kan tilẹ̀ sọ wí pé bóyá nítorí owó tí wọ́n ń gbà. | 0 |
‘‘Màá kó ẹrú, màá kó ẹrù’’ là ń bá lọ sógun; ọ̀nà lẹnìkẹta ń báni. | 1 |
Aláàfin tó wàjà, Ọba Làmídì Adéyẹmí, fi Àyìndé jẹ oyè. | 0 |
Bí a'ò rí wọleę-wọde, a 'ò leè f'ojú kan eégún. | 1 |
Àwọn èèyàn mú Àlàbí níbi tí ó ti ń kó àwọn ewúrẹ́ tí ó pa sínú àpò. | 0 |
B'ẹrù bá pọ j'òșùká; ẹlẹrù l'orí ó ta, òun l'ọrùn ó wọ. | 1 |
Àwọn obìnrin kan kò mọ̀ pé kéèyàn máa pariwo kò dára. | 0 |
Aláàárù tí ń jẹran ń jẹ awọ orí-i rẹ̀. | 1 |
B'eeke omọ-ęranko 'ò bàję, tọmọ-èeyàn 'ò lè dùn. | 1 |
Wọ́n gbé Ayọ̀mídé láti ìlú Àkúrẹ́ lọ sí ìlú Ọ̀rẹ̀. | 0 |
Èșù 'ò ní s'ará Ìbàdàn, k'ọn namọ Àbátàn. | 1 |
Ogun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ ń pa àwọn ará ìlú lára. | 0 |
Ẹni tí kò báa lè jà, kó má bá wọn d'áșàa à-ń-gbé Șakí. | 1 |
Àpa èèyàn ló ń pé wọn ti sọhun tóun fẹ sọ. | 1 |
Àwọn alápatà ń gbé àwọn màlúù tí wọ́n pa lọ sí ọjà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ fún títà. | 0 |
Ẹni a bá ľ'ójúde e ťó ń jo, 'Daada kí lé?' kúrò lọrọ Onítọhún. | 1 |
Ẹnu òpùrọ kì í seję. | 1 |
Ó sọ fún wa pé ka dúró torí wọ́n ti ń ṣe ìwé ìrìnnà wa. | 0 |
‘‘Kùbẹ̀rẹ̀, ká roko ìpére.’’ Ó ní èyí tí òún lọ òun òì bọ̀. ‘ | 1 |
B'ó kèní kọlà, tóșìkà ó ó rọrun, a á kígbé k'ó tó kú. | 1 |
Àyìndé tọ̀ sílé gbálagbàla, ó sọ pé omíyalé ló ṣẹlẹ̀. | 0 |
Àyìnlá Ọmọwúrà kò lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ ìwé rárá. | 0 |
Àifòótọ-inú bọ Șàngó l'ebi fí ń p'Onímọgbà, l'ébí fi ń pAsokele. | 1 |
B'ára 'ò lójú, eșinșin kì í wọ ọ. | 1 |
Ẹni tó ń dùnrọ yàtọ s'ẹni ọrọ ń dùn. | 1 |
Bí aṣáájú ò bá mọ̀ọ́ rìn, ìgbẹ́ lará ẹ̀hìn ń wọ̀. | 1 |
Èjì làá fún, b'éèyàn ò fún sóyún, a sì fún sárùn. | 1 |
Ẹni dáke jeje n fokàn-an re ro nnkan ni. | 1 |
Èèdàrẹ; baba tó ń b'ọmọ ệ yandì. | 1 |
Wọ́n pe ìyàwó Páítọ̀ lórí aago ní nǹkan bí aago mẹ́jọ alẹ́. | 0 |
Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá fi dá àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lójú láti fọkàn balẹ̀ nípa ètò ààbò. | 0 |
Ẹní mọjo-òwò ló mọjọ-ikú. | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.