Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Ẹrú tó báni rẹrù ló sọ òsùká nù. | 1 |
Àyìnlá máa ń ṣó àfẹ́ṣọ́nà rẹ̀ kiri ko má bá ẹlòmíì lọ. | 0 |
Èké ló pabí tí kò yàn, Olóòótọ pa tiẹ ó yàn peregede. | 1 |
A kò lè mọ ohun tó ṣokùnfà ikú Alọ́ba bí a kò bá rí èsì àyẹ̀wò òkú rẹ̀. | 0 |
Àwọn ọ̀daràn ẹ̀dá kan fi egbòogi olóró pamọ́ sínú àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gé irin. | 0 |
Wọ́n gbé àwọn ènìyàn lọ sí ilé ìwòsàn ijoba fún àyẹ̀wò àti ìtọ́jú ní kíákíá. | 0 |
Àjàdí wí pé ẹ̀rù ilẹ̀ rírì tó kójá lọ kò tí ì kúrò lára òun. | 0 |
Fásitì Iléṣà yóò dàgbàsókè kíákíá bí àwọn ènìyàn bá lè fọwọ́sowọ́pọ̀. | 0 |
Èèyàn tó bá tì nìfèé owó jù kì í tún nnkan se. | 1 |
Bí ọmọ́ bá jágbọ́n-ọn kíkú, ìyá rè a jágbọ́n-ọn sísin. | 1 |
Àwọn agbénipa tí wọ́n jí ọmọ náà gbé ní ojú pópó lásán ló paá | 0 |
Àrífín ilé ò j ká jẹ òròmọ adìẹ. | 1 |
Èèyàn tí kò nítìjú, ohun gbogbo ní í se. | 1 |
Ẹlẹ́dẹ̀ẹ́ ní ọjọ́ tí òun ti jágbọ́n-ọn hùn, ọjọ́ náà ni ọ̀rọ̀ ò ti nìun lára mọ́. | 1 |
B'ábọn 'ò kú; eyìn níí dà. | 1 |
Akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n lù kò gba ìtọ́jú kankan tí ó fi jáde láyé. | 0 |
A kì í ṣoore tán ká lóṣòó tì í. | 1 |
Mi ò mọ irúfẹ́ àlàyé tí mo lè ṣe láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí gbà mí gbọ́. | 0 |
A gbà á ládùráà kí Ọlọrun dáwọ́ ogun dúró. | 0 |
Akígbe ọba ń kì í ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá. | 0 |
Bí ẹ̀yá bá dẹkùn, ẹran ní ń pajẹ. | 1 |
Bí wọn bá p'eèyàn l'Ádégòkè, ó yẹ kó lè gun pepe. | 1 |
Àwọn ìyàwó mìíràn máa ń ṣe aṣemáṣe níta pẹ̀lú ọkùnrin míì. | 0 |
Eni tí'ò mo Lákànlú ljàyè,ló n figbá eé mùko. | 1 |
B'Ólóunjẹ bá rí ni tó rojú, k'á fàiję tẹ ę. | 1 |
Adétutù bí ọmọ rẹ̀ àkọ́kọ́ sí Èkó. | 0 |
A kì í bá ẹrú mulẹ̀, ká bá olúwa mulẹ̀, ká má da ẹnìkan. | 1 |
Adébóyè ní Nàìjìríà kò yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè tí ogun ń jà. | 0 |
Akitiyan ti wà lórí mímú ìlọsíwájú bá ìlànà ìgbà-ṣe-nǹkan. | 0 |
Èlùbọ ș'ògbodò rí, èkùrọ ti șààbọn seyìn. | 1 |
Àti ọjọ́ ìbí àtí ọgọ́fà ẹgbẹ̀rún Ọpẹ́yẹmí kò rí ǹkankan ní gbà tí ó ṣi ọjọ́ ìbí rẹ̀ kọ. | 0 |
Ará-ilé eni níí gbé ni fún ará-òde, kí ará-òde tó fani férò-ọjà, kí a tó dẹni à ń sápẹ lé lórí. | 1 |
Èpéénúșẹe, á hun ẹní bá sebi. | 1 |
Ẹní sùn làá jí a kì í jí apirọrọ. | 1 |
Àwùjọ Yorùbá jẹ́ orísun àwọn ọlọpọlọ pipe ninu gbogbo iṣẹ́. | 0 |
B'Ókùnrùn ó ó bá kú, kó kú jẹ, kó má bajá àlapà jẹ, kí ó má nìíomi-ata korò. | 1 |
Pọ̀pọ̀-ṣìnṣìn ọdún ti mú kí àwọn ọlọ́jà fi owó sórí ọjà. | 0 |
Àwọn agbẹnusọ ọlọ́pàá ní àwọn kò ní fi ààyè gba ìwà tó bá lòdì sí òfin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. | 0 |
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní àwọn ò ṣiṣẹ́ bí erin, jẹ ìjẹ èlírí mọ́. | 0 |
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn ti sọ pé kò sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn afipá-báni-lòpọ̀. | 0 |
Ẹni à bá f'orọ lọ; ńșe ló ba'lę jẹ. | 1 |
Ààrẹ foyè orílẹ̀-èdè yìí dá a lọ́lá. | 0 |
Ìjọba kò ní fojúure wo ìwà tí ọba alayé wù yìí. | 0 |
Adię irànà kì í ș'ohun àjęgbé. | 1 |
Eégún mọ̀ọ́ jó kò mọ̀ọ́ jó; yó gba owó ọjà-a rẹ̀. | 1 |
Bí a kò bá rí wọlé-wọ̀de a ò gbọdọ̀ wọlé ọba. | 1 |
Yọ̀mí bẹ adájọ́ pé kí ó fún òun ní àsìkò díẹ̀ sí i kí òun tó pa adìẹ náà. | 0 |
Àșá kì í roko-ìjẹ kó padìẹ òpìpì. | 1 |
Àìtódòó tọ sí ni a á pé “Alákàn má mùtọ̀ọ̀ mi. | 1 |
Bí ará ilé ẹní bá ń jẹ kòkòrò tí kò sunwọ̀n, tí a kò sọ fún un, hùrùhẹ̀rẹ̀-ẹ rẹ̀ ò níí jẹ́ ká sùn lóru. | 1 |
Àsìkò ọyẹ́ ti máa ń gbẹ jù. | 0 |
Agbègbè ọjà ńlá kan ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ àjàgbé ti wáyé. | 0 |
Bí iná kò bá láwo nínú, kì í gun òkè odò. | 1 |
A-rí-jẹ-níjà ò níṣẹ́ mìíràn àfi ìjà. | 1 |
Ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́ àti ìwà ọ̀daràn ni wọ́n fi kàn wọ́n. | 0 |
Ẹ fi àtẹ̀jíṣẹ́ ṣọwọ́ sí wa ní orí ẹ̀rọ ayélujára. | 0 |
A kì í nàró ká ọdún. | 1 |
Wọ́n bá òkú ọkùnrin náà níbi tó pokùnso sí lábẹ́ igi máńgòrò. | 0 |
B'éèyàn ò bá je arójú-ráyẹ, kò leè f'ọmọ-àdó jiyán. | 1 |
Dídùn dídùn nilé olóyin; kíkorò nilé agbọ́n. | 1 |
Àyálò ọ̀rọ̀ máa ń jẹ́ kí àká ọ̀rọ̀ kún dáadáa. | 0 |
À ń seni l'óde, ò tó tilé. llé lọtá wà. | 1 |
A sì tún ti rí orúkọ àwọn ọ̀daràn tó kọlu Ìdí obì. | 0 |
Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ adẹ́rìn-ín pani mẹ́ta ni wọ́n gbégbá orókè. | 0 |
Ara ń ro mi gidi gan, àmọ́ mo ti lọ sílé òògùn wọ́n sì ti kọ oogun fún mi. | 0 |
Bíkàá ò bá lósùn; kì í bá won-on sawo. | 1 |
Ọ̀nà láti yanjú ìṣòro ni kí wọ́n yanjú àwọn ẹjọ́ tó jáde látàrí ètò ìdìbò. | 0 |
B'ágbà bá ń jagun níwájú, kí ó sì máa bààlè leyìn; torí k'ọmo kéékèèké má baà jagun mọ. | 1 |
Gbíngbin ló ń máisàn níyì. | 1 |
A gbọ́ wí pé ọlọ́pàá tó di olóògbé fẹ́ fi páńpẹ́ òfin mú ọlọ́kadà kan. | 0 |
Àìsí owó là ńpa ọ̀ọ́dúnrún mọ́; kí ni irínwó baba ìgbiwó tó-ó ṣe? | 1 |
Arúgbó ẹṣín sàn ju bàtà-a ṣílè m wàá lọ. | 1 |
Àwọn Gómìnà kan fẹ́ràn láti máa yan àwọn ènìyàn sípò láì tẹ̀lé àwọn òfin tó tọ́ | 0 |
Atiro ń ṣe ẹsẹ̀ láká-ǹ-láká; arọ ò lọ́wọ́-nbẹ́sẹ̀. | 0 |
Àkókò àlááfíà ni ìgbà tí kò bá sí ogun àti ìjì. | 0 |
Ariwo àti awuyewuye pọ̀ ní àwọn oṣù àkọ́kọ́ tí Sanwó-Olú fi wà nípò. | 0 |
Ajá wéré-wéré ní ń pa ikún. | 1 |
Akẹ́kọ̀ọ́ náà gba ibi àìsàn náà lọ. | 0 |
Aso-ọdùn (așọ-iko), kì í wíwo. | 1 |
Dókítà tó ṣe àyẹ̀wò òkú Alọ́ba sọ wí pé èsì àyẹ̀wò ti jáde. | 0 |
Dẹ́rẹ́bà ọkọ̀ àjàgbé ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sá lọ. | 0 |
B'órí bá se tó ló se fi ń fọni. | 1 |
Àfojúdi ìlẹ̀kẹ̀ ní ń jẹ́ ‘‘Ẹrú-kò-ní.’’ | 1 |
Ẹ pàdé mi lórí ètò Láwùjọ Àwọn Òǹkọ̀wé lówùúrọ̀ yìí. | 0 |
Eye tó su iyùn lè su òkúta. | 1 |
Àsẹsẹrọ òjò níí ta eruku làùlàù. | 1 |
Awo tó bá rìn jìnà níí kó idẹ, níí kó okùn, níí kó jìngbìnní t'òde-awo bọ wánú ilé. | 1 |
Àwọn àìlámòójútó ilégbèé àwọn ọkùnrin ti tì í pa nítorí ìwà burúkú àwọn akẹ́kọ̀ọ́. | 0 |
Òṣìṣẹ́ ilé ìtura pe Ọláyínká lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ láti béèrè àlàáfíà rẹ̀. | 0 |
Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ọkùnrin náà yóò gbé egbòogi olóró. | 0 |
Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Ifẹ̀ bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà tí àwọn jàǹdùkú náà hù. | 0 |
Eyin ká ilé-ẹrin (ogbá-ẹrín) wó. | 1 |
Ẹgbẹ́ òṣèlú Alágbàdo yóò yan ààrẹ tuntun fún ẹgbẹ́ wọn. | 0 |
Wọ́n ti taari Àkànbí sí ẹ̀ka ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ fún ìwádìí. | 0 |
Àmọlà de'Lùúgùn, ó d'oyinmomo. | 1 |
Bí wọn ba ń p'èèyàn lábìfun ràirài, ó yẹ kó pàfun phún mo. | 1 |
Bígi ńlá bá ya dínà, ìlàgbẹ làá gbà. | 1 |
Ẹni tí kò lẹni lọnà, kì í gbẹrù sí ìdènà, olè nì yóó gbé e. | 1 |
Àtiràbọn ò tó àtirẹ̀tù; ọjọ́ kan là ń ra ìbọn; ojoojúmọ́ là ń rẹ̀tù. | 1 |
Egbé kì í gbéná. | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.