Proverbs
stringlengths
8
373
Labels
int64
0
1
Àwọn ènìyàn ti ń fi ìlú sílẹ̀ nítorí bí iná ṣe ti gba ilé wọn.
0
Egbìnrìn ọ̀tẹ̀, bí a tí ń pàkan ní ọ̀kan ń rú.
0
Ó pé ọdún kan tí àjàkálẹ̀-àrùn bẹ́ sílẹ̀.
0
Èèyàn kí í sèsií pụrọ. Bí èèyàn bá ní òun sèsì purọ, ó tún puro mìràn nùn-un.
1
Bí a dayùn pọ mọ sęgi, bí ata węẹrę ní í jọ lójú atẹni.
1
Ẹni tí ń bínú ẹni níí taari nnkan ẹni sínú omi. (sójò)
1
Àwọn òbí awakọ̀ náà sáré lọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà nígbà tí wọ́n gbọ́.
0
Ẹní jeun tí kò yó, ọwọ ebì ló wà.
1
Àwọn jàǹdùkú ti ń pààyàn bó ṣe wù wọ́n láwọn ìpínlẹ̀ lÓkè Ọya lọ́hùn-ún.
0
Àwọn ọ̀daràn yóò gbọ́ ohun tí ìwé òfin sọ lórí ẹni tó bá ń ṣòwò tí kò bófin mu.
0
Ààrẹ sọ wí pé ọgbọ́n àgbà làwọn lò nínú ìdìbò àkọ́kọ́ tó gbé Oyètọ́lá wọlé.
0
Ẹ̀bà gígan ni Bísí jẹ sùn lánàá.
0
Ẹ máa gbàdúrà fún àwọn ọ̀tá àti ọ̀rẹ́ yín.
0
B'ónílé 'ò bá mọó jó níí pé k'álejò ó kọkọ bọọjó.
1
Àwọn agbófinró sọ wípé Adéyanjú yóò fojú ba ilé ẹjọ́ lọ́sẹ̀ tí a wà yìí.
0
Bánjo ti dáná sun ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí.
0
Àkàó ní òun ṣetán láti lo gbogbo ayé mi tókù lẹ́wọ̀n.
0
Tọ́pẹ́ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn gbajúmọ̀ agbègbè náà.
0
Àgbàlagbà kì í ṣe lágbalàgba. An elder should not behave in an unbecoming manner.
1
Bí wọn bá ń wá Olùwọ Ọbàlùfọn, wọn 'ò ni wá a d'ágbàláà mi.À ó jùmọ máa wá a kiri ni.
1
Àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ti gùn lé iṣẹ́ lórí ẹ̀sùn náà”.
0
Bí iwín bí iwín ní ń ṣe ọlỌ́ya; bíi wèrè bíi wèrè ní ń ṣe elÈṣù; àjótàpá àjópòyì ní ń ṣe oníṢàngó.
1
Àgùntàn 'ò rí ti jẹ nínú èpo èsúrú.
1
Bájòkòó-jẹjẹ bá jòkóò ę jeję, ajòkòókunkun kì í ję ó gbádùn ara.
1
Bí ooré bá pọ̀ lápọ̀jù, ibi ní ń dà.
1
À ń gbèjà Ọ̀jàá, Ọ̀jà ní ta ní ń jà lẹ́hìnkùlé òun?
1
Ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ ti rọ àwọn ọ̀dọ́ látí gba ààwè àti àdúrà.
0
Àṣejù baba àṣetẹ́ ; ẹ̀tẹ́ ní ń gbẹ̀hìn àṣejù; àgbàlagbà tó wẹ̀wù àṣejù ẹ̀tẹ́ ni yó fi rí.
1
Iléeṣẹ́ panápaná ti dé sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ láti dóòlà ẹ̀mí àwọn ènìyàn.
0
Ẹ má șèkà pa'gún, lgún 'ò gbádiẹ, àșá alátagbà ló gbęyẹlę.
1
Bí ojú bá ṣọ̀bùn ojú làáfií hàn; bí a bá yọpin lójú, à fi han ojú.
1
Mo ṣì ní ìwé tí mo níláti ka fún ìdánwò tó ń bọ̀.
0
Àwówówó ni ti irínwó; ìdọ̀bálẹ̀ ni tẹ̀bìtì; bájá bá gbé egungun a dọ̀bálẹ̀ gbọọrọ.
1
Ààrẹ fi dá wọn lójú pé orílẹ̀ èdè Nàíjíríà kò ní gbàgbé wọn.
0
Lójijì làwọn jàǹdùkú agbébọn ya wọ oko wọn.
0
Ó sọ wí pé àwọn àwòrán irọ́ ni wọ́n ń gbé kiri bíi pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yà á.
0
À ń gbà àdúrà fún Ajéìgbé.
0
Àbọ̀ṣẹ́ kì í ṣe iṣ òòjọ́; iṣẹ́-ẹ baba ẹni ní ń gbani lọ́jọ́ gan-an.
1
Béèyàn 'ò ló bí àtòrì l'éwe, kò leè ró wámú bíi àsórín lágbà.
1
B'ọn pe'ni l'ólè, a kì í gbọmọ-ẹran jó.
1
Ọ̀gbìn yóò jáde dáradára bí ènìyàn bá gbìn erèé lọ́wọ́ yìí.
0
A kì í rí ẹṣin ní ìso.
1
Àìníṣẹ́ẹ́ṣe ló fà á tí àwọn géńdé ọkùnrin kùnrìn fi ń tayò lọ́sàn-án.
0
Àṣàwí ẹjó ẹnìkan-án ṣàre.
1
À ń jọo rìn, a 'ò morí olówó.
1
A tún gbé ìgbésẹ̀ lọ́dún to lọ yìí láti se isẹ́ lórí ojú ìrìnnà ọkọ̀.
0
Gúgúrú d'ógun; ó doyin.
1
Àkànní ni alága ìjọba ìbílẹ̀.
0
Àkúnlẹ̀yàn làdáyébá; a kúnlẹ̀ a yan ìpín; a dáyé tán ojú ń roni.
1
B'obìnrin ò bá i tíì kú kò lè máa sírò iye ìsàasùn tó ti lò fọ.
1
Baálẹ̀ jẹ ọba ìlú wa.
0
B'ẹyẹ b'á se lọ là á s'òko ę.
1
Àtìkà àtoore, ọ̀kan kì í gbé.
1
Alága ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ fásitì ní Kàlàba ni Jógunómí.
0
Agbéniga là á p'owó. Òbìwàję là á p'owó.B'éèyàn bá feràn owó l'áfèéjù, ìwà rẹ yóó bàję. (Ìwàláyé ni,kì í se ìwà tí àn hù).
1
Inú bí mi sí ìwà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ilé-ẹ̀kọ́ mi hù sí olùkọ́ wa.
0
A rí i lójú, a mọ̀ ọ́ lẹ́nu; òṣòwò oṣẹ kì í pọ́n-wọ́-lá.
1
Àfẹ́sọ́nà Tèmi mú ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu bàbá olówó.
0
A kì í gb'áàrín èjì èèyàn kí a má sì wí' ló mú Ọbàtálá fẹ Yemọónikan (fi saya)
1
Màríà sọ pé òun lọ sí ìpínlẹ̀ Èkó pẹ̀lú ọ̀rẹ́ òun lóṣù kẹwàá ọdún náà.
0
Èyí ló mú kí onítọ̀hún lọ fi tó máníjà ilé ìtura létí.
0
Ní nǹkan bí oṣù díẹ̀ sẹ́yìn ni àjàkálẹ̀-àrùn bẹ̀rẹ̀.
0
Bí ẹlẹ́jọ́ bá mọ ẹjọ́-ọ rẹ̀ lẹ́bi, kì í pẹ́ níkùnúnlẹ̀.
1
Mi ò fẹ́ kí àríyànjiyàn pọ̀ púpọ̀ lórí ọ̀nà tí a lè gbà wá ojútùú sí àwọn ìṣòro tó wà nílẹ̀.
0
Ẹ̀mí kan ló máa ń mú orí àwọn èèyàn wú níbi ìnáwó bí wọ́n bá ti gbọ́ ìlú tàbí orin.
0
Kọ̀m̀pútà ilé ìfowópamọ́ daṣẹ́ sílẹ̀.
0
Àkòrí ìwàásù ni Àlááfíà ní ilẹ̀ náà.
0
Ẹni tí yóó kú, kòtò ara rẹ níí gbẹ.
1
Alukoro ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá sọ pé òun kò tí ì lè sọ okùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
0
B'óògùn 'ò ję; owó a á ję.
1
Àṣẹșẹ ra ońdè mọjèṣín, ó n ṣe é bí ogun, bí ogun. Wọn làsàá gbóròmọ ẹ lọ, ó dẹyìn síyẹwù, ó lọ ta mọra ogun. B'óògùn ó tilẹ gbìjà, kí ni gbékúdè lè ṣe fẹyẹ tó gbómọ-ẹyẹ lọ?
1
B'ọmọdé róyin a sọ àkàrà nù.
1
Eni jolúwo ká yìn ín, èèyàn ni ò jApènà.
1
Ikọ̀ àwọn ọmọ ogun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́yìn iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́.
0
Lára àwọn òǹtajà inú ọjà náà ti ṣíwọ́ kárà-kátà ọjọ́ náà
0
Adémọ́lá ní ọkàn láti ṣe iṣẹ́ náà.
0
Bí a șe ń s'àgbẹ kọ là ń șe ìnájà. Bí a se ń s'ẹrú kọ la se ńsomo.
1
Àdàpè olè ní ń jẹ́ ‘‘ọmọ-ọ̀ mi ń fẹ́wọ́.’’
1
Àwùjọ tó mọ́ jẹ́ ohun àmúyangàn fún ìjọba àti aráàlú.
0
B'ọmọ bá se rí làá sàna e.Bí a bá fọmọ oníkúrúnà,isu elékùúkú làá fíi dána ẹ.
1
Ọ̀gbẹ́ni Táyé Fọlájìmí, tó ń gbé ní agbègbè Amọ́yọ̀, ní ìlú Ìlọrin ni ó jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.
0
Egbò ò kín ṣe nǹkan gidi
0
Ṣóbíyìí ni akọ́ni-mọ̀-ọ́n-gbá tuntun ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
0
Àwọn agbébọn yìí tún jí àwọn ènìyàn gbé lọ, kódà, wọ́n tún ṣekúpa àwọn míì.
0
Àrókanlẹ̀ laṣọ ayaba; àwàkanlẹ̀ ni ti yàrà.
1
Àwọn ọlọ́pàá fi páńpẹ́ òfin gbé bàbá alápatà.
0
Eni a 'ò fe ni i wolé sùrá, eni a fe ni i wolé ganmbóro.
1
Ọwọ́ pálábá àwọn ènìyàn mẹ́ta ségi ní ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀wọ̀.
0
Awó șòróo se; ogbẹrì nì 'ò mo.
1
Láti ìgbà tí Ajíṣafẹ́ ti ṣe àṣemáṣe ló ti ń sá kiri mọ́ àwọn tí wọ́n fẹ́ mú un lọ́wọ́.
0
Àjọ woléwolé yóò gbé ẹsẹ̀ lé àwọn nǹkan mèremère tí ó bá jẹ́ ti àwọn arúfin.
0
Orí kó abílékọ méjì àti ọmọ-ọwọ́ kan yọ lọ́wọ́ ikú òjijì.
0
Àtúnse ilé-emọ ni àbọwásùn àfè.
1
Gbogbo ohun tí yóò bá fa èdè-àìyedè láàárín èmi àti ìyàwó ẹ̀gbọ́n mi ni mò ń yẹra fún.
0
Èèyàn lè gbé alátakò ẹni lọ sí ilé ẹjọ́ pé ó ti jalè rí.
0
Bí ọwọ́ kò sin ilẹ̀, tí kò sin ẹnu, ayo ní ń jẹ́ .
1
B'íka kan bá wọnú epo, ẹrin yóòkù a gbèèràn kankan.
1
B'ámọlà àti ebà bá ro'jọ ìjà dọdòo Onímọgbà, ẹbà ló máajebíoro.
1
Àti di ènìyàn láìsí olùrànlọ́wọ́ kò rọrùn.
0
Àwòrán tuntun yìí ń sọ nípa ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín àwọn ẹkùn tó wà ní Ọ̀ṣun.
0