Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Àlùfáà tí kò f'áláya méjì níjọ, á nìkan sẹsìn. | 1 |
Àwọn olùgbàtọ́jú sọ wí pé àwọn kì í lè rí àwọn ẹbí àwọn tí yóò mú àwọn padà sílé. | 0 |
A kunle a yan edá, a d'áyé tán ojú ń kán gbogbo wa. | 1 |
Adémọ́lá ní ìgbàgbọ́ pé òun yóò di olókìkí. | 0 |
Adití ò gbọ́, ‘‘Yàgò!’’ | 1 |
Ẹmí tó jẹ gbèsè ló ń san án. | 1 |
Ìgbà mìíràn rèé, wọ́n lè lé wọn dànù bí wọ́n bá rí wọn láwùjọ. | 0 |
Àgbàtán là ń gbọ̀lẹ: bí a dáṣọ fọ́lẹ à pa á láró; bí a lani níjà à sìn ín délé. | 1 |
· Bise owo eni bá tónií je, a kì í gbójú l'ólè-lè-jíjà. Olè-jíjà 'ò tó niíje bi ise-owo eni. | 1 |
À-jókòó-àì-fẹ̀hìntì bí ẹní nàró ni. | 1 |
Awọn aṣáájú ẹgbẹ ẹlẹ́sìn àbáláyé ti ṣekìlọ̀ fún àwọn olóṣèlú. | 0 |
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ wí pé àwọn yóò fimú àwọn apànìyàn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dánrin. | 0 |
Awo ló m'òórùn awo, ológìnní ló mọ àáyán èkúté-ilé. | 1 |
Bí òwe bí òwe ni Ifá ń sọ̀rọ̀. | 1 |
Lẹ́yìn tí Fákẹ́yẹ fipá bá ọmọbìnrin ọ̀hún lò pọ̀ ni ó tún pa á dànù. | 0 |
Babalọlá Fálémi rí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì he. | 0 |
Bí a bá ní ká jẹ èkuru kó tán, a kì í gbọn ọwọ́-ọ rẹ̀ sáwo. | 1 |
Bí a 'ò bá b'Ọba gbélé, abẹ Ọba ki í pání lorí.Bi a ò bá bob pààlà, ọkọ Ọba kì í sáni lęsẹ. | 1 |
Ilé iṣẹ́ àgbẹ̀ fi ẹ̀sùn kan àwọn akọ̀ròyìn ọ̀hún pé wọ́n gbé ayédèrú ìròyìn jáde. | 0 |
Agbẹjọ́rò arákùnrin náà rọ adájọ́ láti ṣíjú àánú wo oníbàárà òun. | 0 |
Àdàbà ń pògèdè bí ẹni pé ẹyẹlé ò gbọ́, ẹyẹlé gbọ́ tiri tiri ló ń tiri. | 0 |
Ayọ̀ ò rúbọ. | 1 |
Bí ewé bá pẹ́ lára ọṣẹ, á dọṣẹ. | 1 |
Fun'ra ra Ègùn ló ń wa ara ẹ lọ tà. | 1 |
B'áráyé bá ń búni kí a fowo lerán. | 1 |
B'étí eni bá ń já, bákan-n-méjì nì. Bí wọn 'ò bá ń yìn nì, a je péwọn ń teni (búni.) | 1 |
A kì í s'ọba lórù. | 1 |
Àánú kì í ṣe olójúkòkòrò ọmọ torí ó ní ìtẹ́lọ́rùn. | 0 |
Alágbẹdẹ ò jẹrin, ó ń bọwú. | 1 |
Ẹlejo sàyí tó dùn rò (wí). | 1 |
Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ máa ń bẹ̀rù láti kojú ikọ̀ tí ọmọ Balógun bá wà. | 0 |
Kódà, ó fẹ́ẹ̀ le bi aṣọ́lé pé ibo ló fẹ́ kí òun gbá bọ́ọ̀lù wọlé sí. | 0 |
Àwọn ìgbìmọ̀ afọbajẹ Ọ̀yọ́ sọ pé àwọn ti fi orúkọ Aláàfin tuntun ránṣẹ́ sí ìjọba. | 0 |
Ìyàlẹ́nu ńlá gbáà nìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún jẹ́ fáwọn tó rí òkú olóògbé náà lórí ìkọ́. | 0 |
Adémọ́lá sọ pé òun yan eré ṣíṣe bí iṣẹ́. | 0 |
Ilé-iṣẹ́ ìròyìn Elétí-ọfẹ ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún Ináọlájí. | 0 |
Àbá ni ikán ń dá; ikán ò lè mu òkúta. | 1 |
Bía ò bá ì tíì san gbèsè, Olówó ò ní mọ pé à ń wá a. | 1 |
Àwọn ohun tí àwọn ìdílé ọba fẹ́ pèsè ló ń dá àwọn afọbaje dúró. | 0 |
Akíntọ́lá rí ìrànlọ́wọ́ gbà lọ́wọ́ àwọn ológun tí wọ́n jọ ń gbé papọ̀. | 0 |
Àfọwọ́rá ní ń jẹ́ olè. | 1 |
Àitètè-lóbìnrin ò pé a máa bímọ Àrẹ̀mọ wọn níí maá kéré ni. | 1 |
A gbọ́ pé ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó lọ ni àwọn ajínigbé ọ̀hún gba ọkọ̀ náà. | 0 |
B'áa r'ọkàn, a 'ò rínú kóówá. | 1 |
Àáké wọ igbo, a gbọ́ òkìkí. | 1 |
Ẹni ť'ó wu Elédùà L'ó ń jí b'ójúmọ mọ. | 1 |
Babaláwo tó kofá kofá tó lóun ò kofá moi tinúu re nì yóo nun ọrẹ yóo run. Àmo bí babaláwo bá kọfámofá,yóò di àgb bàisègùn. | 1 |
A kì í gb'ẹtù kí a má kìdí ìbọn. | 1 |
A kì í b'óníse rìn. | 1 |
Ata náà ti fẹ́ jiná tó bá ṣe díẹ̀ da ẹran yẹn sínú ẹ̀. | 0 |
Èpè la fi ń wo Èpè. | 1 |
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń rí Àyìnlá Ọmọwúrà bí olóògùn. | 0 |
Àjànàkú kì í ya aràrá, ẹni erin-ín bí erin ní ń jọ | 1 |
Àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní arúmọjẹ lásán ni àfikún tí ìjọba àpapọ̀ kéde. | 0 |
Àṣírí àwọn aṣebi kì í pẹ́ tú rárá sí ọwọ́ aráyé. | 0 |
A kì í dẹ igbó ká pẹja; a kì í gbọ́n odò ká pa àfè. | 1 |
Nígbà tí ìyá wọn yóò dé ló rí i pé àwọn ọmọ náà ti kú. | 0 |
Bí a l'ogbọn nínú bí a ò lò ó, ọgbẹrì làá dà. Bí a l'ágbára tá 'o lò ó, aó dole. | 1 |
Ara ń ta mí lórí bí Èṣù ṣe dojú kọ ìgbéyàwó mi. | 0 |
Àṣá kékélùké, àdàbà kékélùké, kò sí ọjà tí wọn ò ná. | 1 |
Àbúrò Àjíún ṣàkíyèsí pé ẹ̀jẹ̀ ń jáde lábẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. | 0 |
Àwọn àjòjì ló ń ṣe fàyàwọ́ wọnú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. | 0 |
Ẹni tó mú Màrè wà, nì yóó mùú Màrè lọ. | 1 |
Wọ́n ní kí wọ́n kọ́kọ́ lọ ṣàyẹ̀wò sí ọpọlọ afurasí ọ̀daràn kan. | 0 |
Ẹni mọwọn ara ę;kì ítę. | 1 |
Arẹwà ní owó ìdáǹdè ìjínigbé ni agbébọn fi ń ra ohun ìjà olóró. | 0 |
Bí ikú bá dé, kò sí lọ́yà tó lè ṣojú ẹni. | 1 |
Àsesewọn ológbò ló ń jìyà, b'ó pẹ yóó tékuú paję. | 1 |
Aàsẹ kì í se gbọnrán; kí ikekere náà ṣe gbọnrán, torí owó ààsẹ la fi ra ìkekere. | 1 |
Alágbàró ò yege; aláṣọ á gbà á bó dòla. | 1 |
Lótìítọ́, mo gbà pé iyèkan ju ọ̀rẹ́ lọ ní tòótọ́. | 0 |
Bí a ó jỌsàákálá; kí a jỌsàákálá. Bí a ó j'Oșòókolo; kí a j'Ósòókolo. Ọsáákálá-șokolo, 'ò yẹ ọmọ èèyàn. | 1 |
Ó ṣe pàtàkì láti parí aáwọ̀ láàárin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kí ẹgbẹ́ lè tẹ̀síwájú. | 0 |
Bí a kò bá rí ohun fún òrìṣà èrò, a kì í gba torí-i rẹ̀. | 1 |
Àwọn tó gba àmì ẹ̀yẹ nínú ìdíje ọ̀hún ló ń jìyà jù. | 0 |
Àwọn ènìyàn kan ò mọ̀ pé iṣẹ́ ni ògùn ìṣẹ́. | 0 |
Gbogbo igi l'àfòmọ ń fó mọ; (bá tan) bíi tibèepe ko. | 1 |
Kí ẹnikẹ́ni tó lè bèèrè fún agbẹjọ́rò, ó ti gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba ìbílẹ̀. | 0 |
Abíọ́lá tún sọ bákan náà pé ibi tí Bọ́lá wà kò yé ẹnikẹ́ni. | 0 |
Ẹ̀jẹ̀ ń jáde lójú ara arábìnrin onípọ̀nmọ́ kí ó tó kú. | 0 |
Àwòdì-í lọ re ìyẹ́, wọ́n ní ẹyẹ́ sá lọ. | 1 |
Bí a yípo nígbà igba; tí a pòòyì nígbà òódún, ìdí 'ò ní kúrò láà)re. | 1 |
Bẹ ẹlẹ wò kí o tó wọ ọ, torí ikú ń bẹ l'ẹlẹ obìnrin t'ó ń pani. (ojú-ara obìnrin nì. Yorùbá tún ń pè lele) | 1 |
Ajóbíewé dáńtọ́ nínú ewì alohùn Yorùbá. | 0 |
Ẹ jẹ́ kí a jọ máa lo ìṣọ̀kan kí àtúbọ̀tán wa lè dára. | 0 |
Aṣọ tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọmọlúwàbí mú yàtọ̀ sí ti àwọn yòókù. | 0 |
Àwíyé ní ń mú ọ̀ràn yéni; ọ̀ọ́dúnrún okùn la fi ńsin ẹgbẹ̀ta; bí a ò bá là á, kì í yéni. | 1 |
Ọjọ́ Àlàmísì tó ń bọ̀ ni ìjọba àpapọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́. | 0 |
àwọn òṣìṣẹ́ tó da iṣẹ́ sílẹ̀ ṣe ìwọ́de ní ní ìlú Èkó. | 0 |
Bí ọ̀rọ̀ náà bá ṣe lọ, wọn yóò máa bun àwọn aráàlú gbọ́. | 0 |
Àrùn kòrónà wà lára ìṣẹ̀lẹ̀ ní ọdún méjì sẹ́yìn. | 0 |
Èèyàn méjì jẹ́ òṣìṣẹ́ mọ́ṣúárì. | 0 |
Àtàtà Ọrọ bí orin làá gbè é. | 1 |
Àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera, olùgbẹ̀bí aláboyún tàbí dọ́kítà lè ṣe àṣìṣe. | 0 |
B'ojú ò bá fọ; ẹsẹ 'ò ní sìnà. | 1 |
Bí wọ́n ṣe bá òkú Lọlá nínú ilé Láolú nìyẹn. | 0 |
Àwọn ará ìlú ní ọ̀gá ilé iṣẹ́ tí kò bá san ẹ̀kúnwó oṣù ń tàpá sí òfin. | 0 |
A ò lè kó iyán ìwúlò èdè kéré torí òhun ni ọ̀pá tí ẹ̀yà rọ̀ mọ́. | 0 |
Eewàá kì í wá lásán. | 1 |
Ẹ̀ẹ̀mejì lojú ahun ń pọ́n. | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.