Proverbs stringlengths 8 373 | Labels int64 0 1 |
|---|---|
Amúnisẹ Ọlọrun Lèmọmù Aríkú, tílé rẹ jó, tí wọn dá páànú jọ fún un,tó lo fi bo Mosáláșí. | 1 |
Àwọn ènìyàn gbàgbọ́ pé Ògúnǹdé ni bàbá àwọn òsèré fíìmù Yorùbá. | 0 |
Àlàbí gbìyànjú láti mú ọ̀daràn náà àmọ́ wọ́n yìnbọn fun lápá. | 0 |
Bàtáakoto, atiro àrìnjó, ṣaworo ọ̀gẹ̀dẹ̀, gbogbo wọn bákan-náà bákan-náà. | 1 |
Àlà funfun, ọ̀rẹ́ òrìṣà. | 1 |
Àwọn ẹ̀ṣọ́ elétò àbò ń sapá láti dóòlà àwọn tí àwọn jàǹdùkú jí gbé. | 0 |
Ẹ̀fọ́ kì í sún ẹ̀fọ́ sọhùn-ún. | 1 |
Ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìdàgbàsókè ti ń wọ inú ìlú. | 0 |
Bí yó ṣe èmi, bí yó ṣe ìwọ, kì í jẹ́ ká ṣu sóko a-láì-rójú. | 1 |
Ahún bu òkèlè, ọmọ-ọ rẹ̀-ẹ́ lanu, ó ní ó gbọ́ bẹ́ẹ̀ òun rí? | 1 |
Àjàkálẹ̀-àrùn kò ṣeé fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú. | 0 |
Obìnrin náà sọ wí pé ilé ará àdúgbò òun kan ni òun lọ sùn. | 0 |
Àgbàtán l'odi ń gbàlú. | 1 |
Àyẹ̀wò ìbátan lọ́jọ́ iwáju lè fihàn pé ọmọ àlè ni ìyàwó gbé wálé. | 0 |
Ènmọ lukutupẹbẹ sòbià Àjàyí, tó dá a lesẹ tí ó sí ń ro ó lógòóró.eyìn. | 1 |
Àwọn onímọ̀ sáyẹ̀nsì ṣàpèjúwe abẹ́rẹ́ àjẹsára náà pé yóò sọ̀gbà dọ̀tun. | 0 |
Àrínfín ni mo ka kí ọkùnrin má súfèé pènìyàn sí. | 0 |
Alága ẹgbẹ́ tẹ́lẹ̀rí ti pàdánù ipò rẹ̀. | 0 |
Aáyán ati eèràá ṣígun, wọ́ ní àwọn ń lọ mú adìẹ; àlọ la rí, a ò rábọ̀. | 1 |
A kì í ṣúpó alààyè. | 1 |
Àdàbà ò náání à ń kùngbẹ́; iná jó, ẹyẹ́ fò lọ. | 1 |
Ajá tó yó kì í bá àiyó seré. | 1 |
Bí adìẹ́ bá gbélẹ̀ a ya òpìpì. | 1 |
Èkúté ilé ní bí a bá yọ tológbò, kí a yọ ti pàkúté;iléló dún-ún gbé joko. | 1 |
Àkọbí eni l'òdiwọn eni. | 1 |
Alábòsí làwọn ọba alayé tó ń pe ara wọn ní Kìrìtẹ́nì àti Àlùfáà ní gbangba. | 0 |
Ó sọ wí pé kinní kan kò ní ṣe Yorùbá bí Yẹmí bá di ààrẹ. | 0 |
Àìmọ èèyàn lọjà ò tà. | 1 |
Àdàpọ̀ owó ní ń mú ìjà wá. | 1 |
Baálẹ̀ tó sọ ọmọ ajá di ẹgbàá, ọmọ tirẹ̀ á wọ́n níbẹ̀. | 1 |
·Ení s'àsùngbàgbéra, yói sàsùnpiyè. | 1 |
Ẹnìkan kì í f'owó-ẹkún rajà erín. | 1 |
Bákàá bá ya lẹsẹ, a bàję lórí. | 1 |
Alùkáwàní,kàyán Allah', Àdéhùn, ẹrù Ọlọrun ni. | 1 |
Àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ti fọn sóde nígbà tí wọn gbọ́ ìró ìbọn. | 0 |
Ẹrù tó wíwo ju ogbe, Àkùkọ kì í rù ú. | 1 |
Alásẹ́ mọ̀ pé ó ń jò kó tó rà á; ẹní hún mọ̀ pé ó ń jò kó tó tà á; iṣẹ́-ẹ jíjò ni wọ́ fi ń ṣe. | 1 |
Ìtọ̀ ṣúgà wà lára àmì tí àjàkálẹ̀-àrùn máa ń mú lọ́wọ́. | 0 |
Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn ikú Aláàfin Ọ̀yọ́ ni Àlùfáà àgbà ìlú Ọ̀yọ́ jáde láyé. | 0 |
Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ọ̀rọ̀ ètò ẹ̀kọ́ ti kéde ìyípadà. | 0 |
Bàtà lesẹ fì ń sagbára láwùjo egún. | 1 |
Àwọn ará àdúgbò ti késí ẹbí àti ará láti ràn wọ́n lọ́wọ́. | 0 |
Akóbáni lèkúté-ilé; ejò kì í jàgbàdo. | 1 |
Apá èkúté-ilé ò káwùsá, ẹnu k'ó máa yí i kírí ló mọ. | 1 |
Èkùlù tó p'Èkùlù lẹgàn, ọjó-ikú ẹ ló gbà. | 1 |
Bí mo lọ lẹ́hìnkùlé Olúgbọ́n, Olúgbọ́n á mọ̀ pé mo lọ lẹ́hìnkùlé òun; bí mo lọ lẹ́hìnkùlé Arẹsà, Arẹsà á mọ̀ pé mo lọ lẹ́hìnkùlé òun; bí mo lọ́ lẹ́hìnkùlé Oníkòyí Màgbó, yó mọ̀ pé mo lọ lẹ́hìnkùlé òun. | 1 |
Ilẹ̀pa wó lu àwọn ọmọ ilé kéwú Àlùmọ́njìrì méje. | 0 |
Àì-mọhun t'Ólúwa Yóó șe ni kì í jẹ́ kí á kánjú. | 1 |
Mo kó jáde nígbà tí ọkọ Àjíún bá mi jà nílé wọn. | 0 |
Mo ṣèlérí pé mi ò ní ṣe irú rẹ̀ mọ́. | 0 |
Adéníyì pẹ̀lú àwọn òṣèré tó lọ sí ẹ̀wọ̀n. | 0 |
Ẹni ayé ń fẹ kì í lárùn lára. | 1 |
Ara ò niwọfà bíi Onígbowo, abánikówó lara ń ni. | 1 |
” Eégún tó gbení; là á dàsọo fún. Òòșá tó gbeni là á bọ. Bi'ígi bágbeni kí a kóbi, k'á máa bọgi. | 1 |
Olóyè Ìkẹ́ àti ìyàwó sọ wí pé àwọn gbà pé àwọn jẹ̀bi ẹ̀sùn náà. | 0 |
B'Ásunrárà bá ní òngbẹ ń gbẹ òun,k'á fún un l'ómi,kìí u sàwà | 1 |
Àyìnlá Ọmọwúrà jẹ́ amúlùúdùn fún ìran Yorùbá. | 0 |
A kì í fàilẹșin dé wọn-ọn-wọn-ọn. | 1 |
Bí a bá n torí èèyàn kú, ó tọ kí tọún mọ obee sè. | 1 |
Àlùmọ́nì méjì kì í gbé ọwọ́ ẹnìkan. | 1 |
Àwòkọ́ṣe ló yẹ kí àwọn òṣèré àti àwọn olórin jẹ́ láwújọ. | 0 |
Amúgbálẹ́gbẹ́ Gómìnà SanwóOlú kó àrùn àìmọ̀ ràn án. | 0 |
Àkòtán ni gẹgẹ ń kó ọrùn. | 1 |
Máníjà lọ fi kọ́kọ́rọ́ ilé ìtura tó wà nípamọ́ ṣí ilẹ̀kùn. | 0 |
Èmi àtàwọn aládùúgbò tó wà ní tòsí la là wọ́n. | 0 |
A kì í ṣe fáàárí itọ́ dídà sọ́mọ a-kú wárápá. | 1 |
A kì í fi ìgbín sọ̀kò sórìṣà. | 1 |
Bí wọ́n bá pàrọ̀ àtọ̀ ọkọ ìyàwó, àyẹ̀wò ìbátan máa yàtọ̀. | 0 |
Àbùlẹ̀ ní ń mú aṣọ tọ́; ẹni tí kò tọ́jú àbùlẹ̀ yó ṣe ara-a rẹ̀ lófò aṣọ. | 1 |
B'Ógun ó ó bàá wọlú Ọlọgbọn là á ké é sí. | 1 |
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ẹ̀ka ìrìnnà òfúrufú ní káwọn arìnrìnàjò wá ọgbọ́n dá sí ìrìn wọn | 0 |
Àtidé onígbàjámọ̀ là ń mọ̀, a kì í mọ àtilọ. | 1 |
Ajagun náà ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbáradì láti padà sí Nàìjíríà. | 0 |
Ẹkẹ òtòși kì í tólẹ láàárọ, bó d'owo alę gbọọgbọ ní í yọ. | 1 |
Àbúrò mi wálé pẹ̀lú àwọn àbúrò rẹ̀. | 0 |
Yóò tó ọ̀sẹ̀ mẹ́ta kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó parí ìdánwò tí wọ́n ń ṣe. | 0 |
Bí ọtí bá ń pani, ṣé òorùn ń pa bọ̀tí; oró táa dá ọkà lọkà ń dáni san. | 1 |
Ọ̀gá ọlọ́pàá rọ àwọn ará ìlú láti tètè ta ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá lólobó. | 0 |
Ọ̀gá ọlọ́pàá ní àwọn yóò fojú afurasí balé-ẹjọ́ bí ìwádìí bá ti parí. | 0 |
Àjọ elétò ìlera ti gbìmọ̀ràn àmójútó tó péye. | 0 |
Ẹni ti a lù ní kùmọ mẹfà, tó ní ìkankan 'ò bá òun, ara rẹ ló wvà. | 1 |
Àlọrìn lekòlòó fẹnuú lọlẹ. | 1 |
Bí a jèkuru; jàkàrà tán; kó lẹyẹ kí á gbàgbé erèé. | 1 |
Bí a bá ń reléeAníbijùwọn, etí ọtún a máa hó 'yeee', t'òsì a sìmaa ta (lù) gbùdù. Àmọ, ibi a bá ń rè (lọ) là á kọjú mọ. | 1 |
Alápámálèṣiṣ , baba ọ̀lẹ. | 1 |
Ajá mọ ìgbẹ́ ; ẹlẹ́dẹ̀ mọ àfọ̀; tòlótòló mọ ẹni tí yó yìnbọn ìdí sí. | 1 |
B'éèyàn 'ò bá ní “Ẹ-bá-mi-pè-é,” kì í gbọ àgbọya. | 1 |
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àwọn olùkọ́ ti gbà láti fòpin sí ìyanṣẹ́lódí wọn. | 0 |
Eni tó níran pé òun yóò kùú; kì í sùn gbọọrọ. | 1 |
Wọ́n ti sun ilé mìíràn tí ó súnmọ́ tòsí ilé ìyá ọ̀daràn náà. | 0 |
Bí a 'ò tìẹ șàlè mọ, kò pé k'á má fojú èsín wo ara eni. | 1 |
Àwọn ìgbìmọ̀ ẹlẹ́nu márùn-ún ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà da ẹjọ́ náà sígbó. | 0 |
Àṣá tó gbé adìẹ òtòṣì-í gbé ti aláròyé. | 1 |
Akéèésú-má-dàá, egbẹra olè ni. | 1 |
Èèyàn tí kò mọójó, kì í jìnà sónílù. | 1 |
Èèwọ; a kì í fàdí ròfọ f'Ọbalúayé. | 1 |
Àìsówó ní í “J'ẹ'lẹ ó gbọn.” | 1 |
Èèyàn ní ń kọ́ni ká gùn; èèyàn ní ń kọ́ni ká kúrú. | 1 |
Àkùkọ́ kì í pamọ. | 1 |
Aláàńtètè: ó jí ní kùtùkùtù ó ní òun ó dàá yànpọ̀n-yànpọ̀n sílẹ̀. | 1 |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.