raw_text stringlengths 2 128k |
|---|
lérè pàímọ́ lérè pàímọ́ ofr tí wọ́n bí ní oṣù kọkànlá ọdún 1939 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìlú ògbómọ̀ṣọ́ ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ lórílẹ̀ èdè nàìjíríà |
lizzy àńjọọ́rìn lizzy àńjọọ́rìn tí orúkọ rẹ̀ gangan ń jẹ́ elizabeth ìbùkúnolúwa àńjọọ́rìn tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹrin jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìjọba ìbílẹ̀ àgbádárìgì ni ìpínlẹ̀ èkó lórílẹ̀ èdè nàìjíríà lizzy jẹ́ oníṣòwò bákan náà aáyan rẹ̀ nínú iṣẹ́ tíátà lẹ́yìn tí ó ... |
ẹ̀gbà ọrùn ẹ̀gbà ọrùn jẹ́ ohun tí àwọn ènìyàn ọkùnrin àti obìnrin lń lòbláti fi ṣe ọ̀ṣọ́ ara àwọn ènìyàn sábà ma ń lòó níbi àwọn ayẹyẹ bíb ayẹyẹ ẹ̀sìn or ìsìnkú ìkómọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ó tún wà fún ṣíse àdáyanrí tàbí ìyàtọ̀ láàrín olówó àti tálíkà láàrín àwùjọ ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹ̀gbà ọrùn wọ̀nyí ni wọ́n fi ohun èlò oníy... |
kamaru usman kamaru usman tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù karùn-ún ọdún 1987 jẹ́ gbajúmọ̀ ajẹ̀ṣẹ́-gídígbò mixed martial artist ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè nàìjíríà àti amẹ́ríkà tí ó ń jẹ̀ṣẹ́ ònígídígbò jẹun lórílẹ̀ èdè amẹ́ríkà àwọn ìdíje àti àmì ẹ̀yẹ rẹ̀ kàmárù ti díje lọ́pọ̀ ìgbà nínú ìdíje ìjà-ẹ̀ṣẹ́ ònígídígbò tí ultimate fi... |
ayẹyẹ ìsìnkú ayẹyẹ ìsìnkú jẹ́ ọ̀nà ìṣe ẹ̀yẹ ètùtù tàbí ìṣípà ẹni tí ó di olóògbé kú ìgbàgbọ́ yorùbá nípa ikú yorùbá gbàgbọ́ wípé ikú kìí ṣe òpin ìrìn-àjò ẹ̀dá bí kò ṣe ìrín-àjò kúrò ní ipò alààyè sí ipò àìrí àti wípé ikú jẹ́ ìtẹ̀síwájú nínú ìṣẹ̀mí lásán àmọ́ ní àyè ọ̀tọ̀ ìdí tí wọ́n fi ń ṣòkú yorùbá bọ̀ wọ́n ní orúkọ r... |
aisha buhari aisha buhari tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì ọdún 1971 jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ lorílẹ̀ èdè nàìjíríà àti ìyàwó ààrẹ muhammadu buhari ààrẹ ana orílẹ̀ ède nàìjíríà tí sa a re dopin ni ojo kokan din logbon osu kefa odun 2023 ààrẹ buhari gbàpò lọ́wọ́ ààrẹ goodluck jonathan lọ́dún 2015 bẹ́ẹ̀ náà ó tún borí ... |
àkàrà àkàrà jẹ́ óńjẹ abínibí ìbílẹ̀ ilẹ̀ yorùbá àti púpọ̀ nínú ilẹ̀ adúláwọ̀ ṣíṣe àkàrà àkàrà wà nínú àrà tí wọ́n ma ń fi ẹ̀wà dá wọ́n ma ń rẹ ẹ̀wà sínú omi fún bii ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tàbí wákàtí kan kí ó lè rọ̀ lẹ́yìn èyí wọn yóò fi ata àlùbọ́sà edé àti àwọn nkan mìíràn tí ó bá wù wá si kí wọ́n tó lọ̀ọ́ kúná lẹ́yìn tí wọ́n... |
dọlápọ̀ oṣínbàjò dọlápọ̀ oṣínbàjò tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje ọdún 1967 jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ ògùn lórílẹ̀ èdè nàìjíríà àti ìyàwó igbákejì ààrẹ orílẹ̀ èdè nàìjíríà ọ̀jọ̀gbọ́n yẹmí òsínbàjò dọlápọ̀ jẹ́ ọmọọmọ gbajúgbajà òṣèlú àti olórí-òṣèlú àná àwọn ẹ̀yà àwọn yorùbá olóògbé ọbáfẹ́mi awolọ́wọ̀ ìgbà èwe àti aá... |
ẹgbẹ́ òṣèlú ẹgbẹ́ òṣèlú jẹ́ ẹgbẹ́ tí àwọn òṣèlú tí ìmọ̀ òye àti èròǹgbà jọra dá sílẹ̀ láti díje dupò òṣèlú ní orílẹ̀ èdè tí wọ́n bá lẹ́tọ̀ọ́ rẹ̀ lábẹ́ òfin ìfojúsùn gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú ni láti jẹ àwọn ipò òṣèlú tí ó bá ṣí sílẹ̀ lórílẹ̀ èdè wọn iye ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó wà ní nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ti independent nationa... |
àtòjọ ohun mímu afúnilókun energy drinks wikimedia list article ohun mímu afúnilókun ohun mímu tí wọ́n pèsè láti ara àwọn èròjà oríṣiríṣi àwọn ohun mímu afúnilókun yí lè jẹ́ coffee ẹlẹ́rìndòdò bí coca-cola mountain dew pepsi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ àtòjọ wọn àwọn ìtọ́kasí |
àyinla omowura waidi ayinla yusuf gbogbolowo better known as ayinla omowura 1933 6 may 1980 was a nigerian apala musician born in itoko abeokuta in 1933 w í wàádì àyìnlá yusuf gogbo lówó tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí àyìnlá ọmọwúrà 1933- 6 may 1980 ó jẹ́ olórin àpàlà orílé-èdè nàìjíríà tí wọn bí ní itoko abeokuta ní ọdún 1933 ... |
jùmọ̀kẹ́ ọdẹ́tọ́lá ọlájùmọ̀lẹ́ ọdẹ́tọ́lá tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹwàá jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà lédè gẹ̀ẹ́sì ṣùgbọ́n ní kété tó dára pọ̀ mọ́ tí èdè yorùbá ní ìràwọ̀ rẹ̀ tàn ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ jùmọ̀kẹ́ kàwé gírámà rẹ̀ ní abẹ́òkúta... |
ẹgbẹ́ awakọ̀ ojú pópó nurtw ẹgbẹ́ awakọ̀ ojú pópó nurtw jẹ́ àgbáríjọ ẹgbẹ́ gbogbo ọlọ́kọ̀-èrò tó dá dúró lábẹ́ ẹgbẹ́ oníṣe ọwọ́ nilẹ̀ nàìjíríà ẹgbẹ́ yí wà fún láti mú ìṣọ̀kan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàrín àwọn ọlọ́kọ̀-èrò ojú pópó gẹ́gẹ́ bí àlàkalẹ̀ inú òfin wọn ìṣàkóso ẹgbẹ́ wọn ẹgbẹ́ yí ní àwọn adarí tí wọ́n jẹ́ ti àpapọ... |
national agency for food and drug administration and control nafdac national agency for food and drug administration and control nafdac jẹ́ àjọ tí ó ń rí sí ìṣàkóso ipò oògùn óńjẹ ìbílẹ̀ àti tókè òkun ohun èlò ìṣaralóge costmetics ohun èlò ilé-ìwòsàn omi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ àjọ nafdac yí wà lábẹ́ àṣẹ àti àkóso federal m... |
ìjọba ìbílẹ̀ ọ̀jọ́ ìjọba ìbílẹ̀ ọjàọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí lórúkọ jùlọ ní ìpínlẹ̀ èkó tí ó wà nínú ìlú ọ̀jọ́ ní ìpínlẹ̀ èkó ibẹ̀ sì ni fásitì ìpínlẹ̀ èkó wà ìlú ọ̀jọ́ wà ní apá ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ èkó ní òpópónà márosẹ̀ tí ó lọ sí ìlú àgbádárìgì ìlú ọ̀jljọ́ jẹ́ ibùgbé fún tonílé tàlejò tí ọjà oríṣiríṣi bi... |
folúkẹ́ dárámọ́lá folúkẹ́ dárámọ́lá jẹ́ gbajúgbajà òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kejì 15th february ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà bí folúkẹ́ tí ń fakọyọ nínú sinimá àgbéléwò èdè yorùbá bẹ́ẹ̀ náà ló dáńgájíá nínú tí èdè gẹ̀ẹ́sì ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní sinimá àgbéléwò tí ó ti kópa tí ó sìn pegedé |
ronke ojo ronke ojo tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù keje ọdún 1974 july 17 1974tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ rónkẹ́ òṣòdì-òkè jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ yorùbá láti orílẹ̀ èdè nàìjíríàbákan náà rónkẹ́ jẹ́ akọrin ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rónkẹ́ jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ oǹdó ṣùgbọ́n ... |
mercy johnson mercy johnson okojie tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1984 28th august 1984jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè nàìjíríà sinimá àgbéléwò èdè gẹ̀ẹ́sì àti ìgboò ni mercy johnson máa ń kópa tí ó sìn gbajúmọ̀ nínú wọn ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ mercy johnson-okogi... |
kanayo o kanayo anayo modestus onyekwere tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí kanayo o kanayo ní wọ́n bí ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹta ọdún 1962 march 1 1962 ni ìlú mbaise ní ìpínlẹ̀ imolórílẹ̀ èdè nàìjíríà jẹ́ gbajúgbajà òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà gbajúmọ̀ rẹ̀ lágbo òṣèré tíátà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ tí ó fi gba àmìn ẹ̀yẹ... |
ṣẹ́gun ògúngbè ṣẹ́gun àkànní ògúngbè tí wọ́n bí ní ọgbọ̀n ọjọ́ kẹta jẹ́ gbajúmọ̀ oṣèré olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ yorùbá láti orílẹ̀-èdè nàìjíríà |
akin ògúngbè akin ògúngbè tí wọ́n bí ní ọdún 1934 tí ó sì kú ní oṣù kọkànlá ọdún 2012 jẹ́ òṣèré orí ìtàgé adarí eré orí ìtàgé àti agbéréjáde ọmọ rẹ̀ ni gbajúgbajà òṣèré olóòtú àti olùdarí sinimá-àgbéléwò ṣẹ́gun ògúngbè ìgbà èwe àti ááyan ìkẹ́kọ̀ọ́ a bí ní ọdún 1934 ní ìlú abẹ́òkúta tí ó jẹ́ olú ìlú ìpínlè ògùn ní apá g... |
apala |
hassan taiwo |
edirne edirne je ilu ni ariwa iwo oorun orile-ede turki ni bi odun 16 century ni mosalasi selimiye di kiko lati owo ayaworan ile kiko mimar sinah awon ohun ona ati ti eso ti orileede naa ati ti musulumi je ohun afihan fun gbogbo eniyan eleyi ti o ti bere lati isejoba ottoman mosalasi uç serefeli eleyi ti kiko re waye l... |
matthew asimolowo matthew ashimolowo ti wọ́n bí ni ọdun 1952 osu keta jẹ́ olusho aguntan ati oludari kingsway international christian ìgbésí ayé rẹ̀ ashimolowo yipada si kristiẹniti lati inu islam ni ọmọ ọdun 20 lẹhin iku baba rẹ ṣaaju ki o forukọsilẹ pẹlu ile-iwe bibeliforbes ifoju idiyele iye apapọ ashimolowo ni o wa... |
ashimolowo |
bolaji amusan bọ́lájí amúṣàn-án tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí mr látìn tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹwàá ọdún 1966 october 15th 1966 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré aláwàdà àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí yorùbá ti ìlú gbọ̀ngán ni ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun lorílẹ̀ èdè nàìjíríà ìgbà èwe àti aáyan ìṣe tíátà rẹ̀ ìlú kan tí ó ń jẹ́ gbọ̀ngán n... |
mọ́sà mọ́sà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn omi lẹgbẹ óńjẹ ìbílẹ̀ ní ilẹ̀ nàìjíríà ìwúlò mọ́sà gẹ́gẹ́ bí ọ́ńjẹ ìbílẹ̀ ní pàtó jíjẹ ni mọ́sà wà fún àmọ́àwọn ènìyàn ma ń lòó fún sàráà ṣíṣe fún àwọn òkú ọ̀run nípa fífún àwọn atẹ́wọ́ gbọrẹ wọ́n tún ma ń lo òun àti àkàrà láti fi ṣọdún egúngún bí wọ́n ṣe ń jẹ mọ́sà wọ́n ma ń jẹ mọ́sà pẹ... |
fèrèsé fèrèsé jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀yà ilé tí ó ma ń wà ní àárín ògiri méjì ilé ósì tún lè jẹ́ gíláàsì tí a fi sí ara ọkọ̀ láti lè jẹ́ kí òye ohùn tàbí afẹ́rẹ́ ó wọlé ìyátọ́ fèrèsé ayé òde òní àti ayé àtijọ́ láyé àtijọ́ ọ̀pọ̀ àwọn fèrèsé ló ma ń jẹ́ pákó tí a figi ṣe pàá pàá jùlọ ilé tí àwọn aláìní ma ń gbé ni wọ́n ma ń fi ... |
rótìmí akérédolú former nba president and gubernatorial aspirant in ondo state olúwarótìmí ọdúnayọ̀ akérédolú san or rótìmí akérédolú ní wọ́n bí ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje ọdún 1956 21st july 1956 jẹ́ òṣèlú agbẹjọ́rọ̀ àti gómìnà ìpínlẹ̀ oǹdó lọ́wọ́lọ́wọ́ ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó jẹ́ amòfin-àgbà san tí ó ti joyè alá... |
anne omolola famuyiwa |
julius àràbà julius o àràbà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olórin tí ó di orin jùjú mú tí wọ́n sì gbajúmọ̀ ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ní àsìkò tirẹ̀ òun ati àwọn bí àkànbí wright victor ọláìyá jọ jẹ́ olórin jùjú lásìkò náà nínú iṣẹ́ orin rẹ̀ ó ṣalábàápàdé àkànbí wright tí ó ràn an lọ́wọ́ nípa ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni lórí iṣẹ́ tí ó yàn láà... |
b s hùndéyín b s hùndéyín tí wọ́n bí ní oṣù kẹta ọdún 1934 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèlú àti olùkọ́ ọmọ bíbí ògù láti ìlú badagry ní ìpínlẹ̀ èkó lórílẹ̀ èdè nàìjíríà nígbà ayé rẹ̀ ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ olùkọ́-àgbà kọmiṣọ́nnà ní ìpínlẹ̀ èkó àti àgbà òṣèlú |
bọ̀dé ṣówandé bọ̀dé ṣówandé ni a bí ní ọjọ́kejì oṣù karùún ọdún 1948 2-05-1948 jẹ́ ònkọ̀wé eléré oníṣe àti ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ònkọ̀wé ó jẹ́ olùkọ iwe nípa ọmọnìyàn àti ìṣesí àwùjọ ó jẹ́ ònkọ̀wé tí ó ma ń lo àwọn ọgbọ́n àtinúdá tí a ṣe lọ́jọ̀ pẹ̀lú àṣà àti ìṣe ilẹ̀ yorùbá ṣówandé wà lára ọ̀wọ́ ìp... |
ọ̀jọ̀gbọ́n ṣiyan oyèwẹ̀sọ̀ ṣiyan oyèwẹ̀sọ̀ tí wọ́n bí ní ọjọ́ kíní oṣù kejì ọdún 1961 ní ìta ìdí-ọmọ ní agbègbè màpó ọjà ọba ní ìlú ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ni oriilẹ-ede nàìjíríà wọn bi ṣiyan sínú ẹbí ẹlẹ́sìn mùsùlùmí ìdílé oyeweso ni wọ́n ṣẹ̀ wá láti agbolé olójò ní ìlú ẹdẹ ní ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ìbẹ̀... |
ọ̀mọ̀wé shafi lawal ọ̀mọ̀wé ṣháfì lawal tí a mọ̀ sí ṣl edu ni a bí ní ọdún 1911 tí ó sì kú ní ọdún 2002 jẹ́ oníṣòwò ìlúmọ̀ọ́ká àti ajàfẹ́tọ̀ọ́agbègbè ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà nígbà kan rí ó wá láti ìlú ẹ̀pẹ́ ní ìpínlẹ̀ èkó òun ni olùdásílẹ̀ ètò-ìṣúná ajàfẹ́tọ̀ọ́agbègbè ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà èyí tí kìí ṣe tí ìjọba tí ó s... |
shafi edu olóyè shafi lawal edu 19112002 tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí sl eduni ó jẹ́ òṣùpá lágbo àwọn ó lò kò wó àdàni ní ilẹ̀ nàìjíríà àti conservationist ọmọ bíbí ìlú ẹ̀pẹ́ ní ìpínlẹ̀ èkó òun ni ó dá conservation fund ilẹ̀ nàìjíríà sílẹ̀ tí ó jẹ́ àjọ tí ó jẹ́ ti aládáni wọ́n bí eru ní ìlú ẹ̀pẹ́ sínú ẹbí ọ̀gbẹ́ni lawani ed... |
bíńtà ayọ̀ mọ́gàjí bíńtà ayọ̀ mọ́gàjí ni wọ́n bí ní ọdún 1964 jẹ́ gbajúgbajà òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìlú ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ láti orílẹ̀ èdè nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ sinimá àgbéléwò shaibu husseini ṣe sọ bíńtà ayọ̀ mọ́gàjí tí kópa nínú sinimá àgbéléwò eré-ìtàgé àti eré àṣà fihàn orí tẹlifíṣàn tó ti tó... |
baṣọ̀run gáà olóyè ìlú ọ̀yọ́ baṣọ̀run gáà jẹ́ olóyè alágbára ìlú ọ̀yọ́ láyé àtijó nígbà ayé rẹ̀ gáà burú débi pé aláàfin ọ̀yọ́ tí ó jẹ́ ọ̀ba aládé bẹ̀rù rẹ̀ òun ni ònkọ̀wé adébáyọ̀ fàlétí kọ nípa rẹ̀ nínú ìwé eré-oníṣe tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní baṣọ̀run gáà lọ́dún 1972 níbi tí baṣọ̀run gáà burú dé òwe yorùbá kan jẹmọ òwe n... |
ìṣasùn ìṣasùn jẹ́ ìkòkò tí wọ́n fi ń se ọbẹ̀ láyé àtijó láwùjọ yorùbá ó yàtọ̀ sí àwọn ìkòkò tí wọ́n fi ń se àgbò ẹnu ìṣasùn máa ń fẹ̀ dáradára ju ìkòkò lásán lọ ó sìn máa ń ní ìdérí kìí fi bẹ́ẹ̀ tóbi púpọ̀ |
músílíù ìṣọ̀lá 'músílíù hárúnà-ìṣọ̀lá jẹ́ gbajúmọ̀ olórin àpàlà ó jẹ́ ọmọ bíbí akọrin àpàlà tí ó ti di olóògbé hárúnà ìṣọ̀lá gbajúmọ̀ rẹ̀ gbòde kan nígbà tí ó ṣe àtúnkọ orin bàbá rẹ̀ kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ sóyòyò lọ́dún 2004 |
olamide ọlámídé adédèjì tí a bí ní ọjọ́ kéẹ̀dógún oṣù kẹtaọdún 1989 15-3-1989 ní agbègbè bàrígà ní ìpínlẹ̀ èkó tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ ọlámidé badoo tàbí baddosneh jẹ́ gbajú gbajà olórin hip-hop ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó jẹ́ olórin hip-hop tí ó ń akọrin pẹ̀lú àmúlù-ma la èdè yorùbá àti èdè gẹ̀ẹ́sì ní ọdún 2011 ó ṣe àgbéjá... |
dèbórà adébọ́lá fáṣọyin dèbórà adébọ́lá fáṣọyin ni wọ́n bí ní ìlú ọ̀yọ́ ní ọdún 1944 sí ìdílé pa afọlábí ó jẹ́ ọ̀kánlàwọ́n ọmọ obìnrin àti àbíkẹ́yìn ọmọ nínú ẹbí náà iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọrin ìjọ dèbórà bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ láti inú ìjọ micheal anglican church gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ akọrin ìjọ ó dara pọ̀ mọ́ ìjọ cac ní ọdún 1... |
orin ọdún ń lọ sópin orin ọdún ń lọ sópin ni orin tí ẹgbẹ́ akọrin obìnrin rere ti ìjọ cac gbé jáde lábẹ́ ìdarí dèbórà adébọ́lá fáṣọyin lọ́dun 1979 orin 'ọdún ń lọ sópin' yí jẹ́ orin tí wọ́n fi èdè yorùbá gbé jáde tí ó sì rìnlẹ̀ gidigidi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lò ma ń lo orin yí gẹ́gẹ́ bí orin àdúrà láti fi ṣe ìpalẹ̀mọ́ fún ... |
ọjà pàṣípàrọ̀ ọjà pàṣípàrọ̀ jẹ́ ètò ṣíṣe pàṣípàrọ̀ ohun-ìní tàbí iṣẹ́ láàárín ènìyàn méjì láyé àtijó nígbà tí wọn kò ì tíì ṣẹ̀dá owó fún káràkátà ṣíṣe bí àpẹẹrẹ ẹni tí ó bá ní ìṣù ṣùgbọ́n tí ó nílò gaàrí yóò wá ẹlòmíràn tí ó ní gaàrí tí ó sìn nílò iṣu láti ṣe pàṣípàrọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ọjà pàṣípàrọ̀ jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe ... |
ajé ajé jẹ́ òrìṣà tí yorùbá gbàgbọ́ pé ó ṣẹ̀dá owó ajé jẹ́ orúkọ mìíràn tí yorùbá máa ń pe owó láwùjọ yorùbá wọn a máa pe owó ní ajé owó ẹyọ ní àrokò tí ó dúró gẹ́gẹ́ bí owó tàbí ajé láwùjọ yorùbá nílẹ̀ yorùbá wọ́n máa ń bọ ajé gẹ́gẹ́ bí òrìṣà àkúnlẹ̀bọ oríkì ajé ajé káàárọ̀ ajé olókun ajé ògúgúlúṣọ̀ ajé onísọ̀ ibòji a... |
àrokò àrokò jẹ́ ìlànà bí a ṣe ń fi nǹkan ṣe ìfidípò ọ̀rọ̀ ẹnu láti bá ènìyàn sọ̀rọ̀ láyé àtijọ́ àrokò jẹ́ ọ̀nà tí àwọn alágbára ọba tàbí àwọn olóyè ń gbà ṣe ìbánisọ̀rọ̀ sí ara wọn láìlo ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn lásán náà lè pàrokò ránṣẹ́ sí ẹlòmíràn tàbí kí wọ́n fi pa àlè lé nǹkan àrokò pípa ní ayẹ́ àtíjó àrokò pípa jẹ́ ònà ti... |
pákò pákò tàbí orín jẹ́ egbò igi tàbí ẹ̀ka igi tí a gé tí a jẹ láti fi ṣe ìmọ́ tótó ẹnu fe eyín tí ó ti ń kẹ̀ ṣe tàbí fi bá kòkòrò ẹnu wọ̀yá ìjà ànfàní pákò pa ko ni ó ní àwọn ànfàní wọ̀nyí àwọn ìtọ́kasí ÷ |
kànga kànga jẹ́ ihò jíjìn kan tí a gbẹ́ sínú ilẹ̀ léte àti rí omi ilẹ̀ bu jáde fún ìwúlò àti ìṣẹ̀mí ọmọnìyàn àti ẹranko ìrísí kànga kànga ni ihò nla tí a fi búlọ́ọ́kù àti sìmẹ́ntì mọ yíká ihò tí a gbẹ́ náà lọ́pọ̀ ìgbà ni wọ́n ma ń fi ìfami tí a so okùn mọ́ nídìí fa omi jáde láti inú kànga náà |
afeez ẹniọlá afeez ẹniọlá tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kejì jẹ́ òṣeré olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìlú ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ láti orílẹ̀ èdè nàìjíríà ìgbà èwe rẹ̀ wọ́n bí afeez ẹniọlá lọ́jọ́ kejìlélógún oṣù kejì 22nd february ní ìlú ṣómólú ni ìpínlẹ̀ èkó lórílẹ̀ èdè nàìjíríà ìpínlẹ̀ èkó náà ló ti... |
moji afolayan moji afolayan tí wọ́n bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kejì ọdún 1969 february 5 1969 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin olóòtú àti olùdarí sinimá-àgbéléwò ọmọ bíbí yorùbá láti ìlú ìbàdàn lórílẹ̀-èdè nàìjíríà mojí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ bíbí olóògbé òní-sinimá àgbéléwò adeyemi afolayan tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí ade love nígb... |
razaq olayiwola razaq olayiwola tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ òjòpagogo jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè nàìjíríà òun ni ọkọ gbajúgbajà òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò mojí afọláyan |
pákò / orín |
wòlíì àgbà wòlíì àgbà tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ ayọ̀ ajéwọlé jẹ́ òṣèré apanilẹ́rìn-ín àti olórin wọ́n bi ní ogúnjọ́ oṣù kọkànlá ní ìlú ìbàdàn ibẹ̀ ni ó sì ti ṣe ìgbà èwe rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ìgbà èwe rẹ̀ ijeda ní ìlú ìjẹ̀sà ti ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ni ó ti wá àmọ́ ìlú ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ni ó dàgbà sí ìlú ìbàdàn yìí náà ni ... |
park ji-hyo park ji-hyo je olorin omo orile-ede kòréà gúúsù |
adéníyì johnson adéníyì johnson tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹtàdínlógbọ̀n oṣù kejì ọdún 1978 27th february 1978 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó ti ju ogún ọdún lọ tí ó ti ń ṣeré tíátà ṣùgbọ́n ìràwọ̀ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní tàn nígbà tí ó kópa nínú eré orí tẹlifíṣàn kan tí àkọ́lé tinsel gbajúmọ̀ òṣèrébìnri... |
orin ọdún yìí a tura ọdún yìí a tura jẹ́ orin àwọn ẹlẹ́sìn ọmọ lẹ́yìn jésù tí gbajúgbajà akọrin ìgbàgbọ́ ajíyìnrere àti olùdarí ẹgbẹ́ obìnrin rere tí ìjọ cac tí ìlú ìbàdàn dèbórà adébọ́lá fáṣọyin kọ fún ìgbà pípẹ́ ṣùgbọ́n tí àwo rẹ̀ jáde lọ́dún 2012 |
igi agía igi méèlegbàgbé agía tàbí igi méèlegbàgbé agíya jẹ́ igi kan tí àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun tí kọ́kọ́ wàásù ìyìnrere ni orílẹ̀ èdè nàìjíríà lábẹ́ rẹ̀ ní ìlú àgbádárìgì lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsàn-án ọdún 1842 àgbádárìgì jẹ́ ìlú ògù ní ìpínlẹ̀ èkó orúkọ tí wọ́n sìn ń pe igi agía lédè ògù ní àsísọẹ tín igi yìí gú... |
ọ̀pá ọ̀rànmíyàn ọ̀pá ọ̀rànmíyàn jẹ́ ọ̀pá àṣẹ àti agbára tí ọ̀rànmíyàn ń lò lójú ogun àti gẹ́gẹ́ bí ọba ìlú ilé-ifẹ̀ nígbà ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtàn àtẹnudẹ́nu ọ̀rànmíyàn jẹ́ ọba alágbára ilé-ifẹ́ títí di òní yìí ọ̀pá ọ̀rànmíyàn wà lára àwọn nǹkan ìṣèm̀báyé tí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ máa ń lọ wò ní ilé-ifẹ̀ |
àkúdàáyà àkúdàáyà gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yorùbá ni ìṣípòpadà òkú ènìyàn sí àlàyè ènìyàn ní àgbègbè tí wọ́n kò mọ̀ ọ́n tàbí lọ́dọ̀ ẹni tí ó ti mọ̀ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí kú ìgbàgbọ́ yorùbá nípa àkúdàáyà yorùbá ní ìgbàgbọ́ pé àkúdàáyà wà wọ́n gbàgbọ́ pé ẹni tí ó bá kú láìtọ́jọ́ tàbí yálà wọ́n pa á tàbí ó kúkú nípa ìjàm̀bá máa ń... |
shade omoniyi shade omoniyi bi folashade omoniyi 16 april 1971 to dara mọ nipa rẹ lepa shandy ni a oṣere ere yorùbá ti a se apejuwe nipasẹ awọn iniwe iroyin bi a oniwosan ati ọkan ninu awọn aṣáájú ere yorùbá shade jẹ ohun kikọ ti o dun ni fiimu kan pẹlu akọle kanna |
èkùrọ́ èkùrọ́ jẹ́ kúrú inú ẹyìn ọ̀pẹ tí ó ṣe jẹ nígbà tí àgbà fọ ésan ara rẹ̀ kúrò ohun èlò tí ó wúlò púpọ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lò wà nínú rẹ̀ nínú èso ẹyìn nígbà tí a bá bo tàbí fọ pupa ara rẹ̀ kúrò ni a tó lè rí epo pupa tí a fi ń sebẹ̀ nígbà tí a lè rí òróró nínú èkùrọ́ tí ó wà nínú ésan tí a fọ epo kúrò lára rẹ̀ ẹ̀wẹ̀ ... |
coke coke tí a tún máa ń pè ní coca-cola jẹ́ nǹkan mímu ẹlẹ́rìndòdò tí tí ó wà káàkiri ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè tí wọ́n fi ń pòhùngbẹ tí ilé-iṣẹ́ coca-cola bottling company ń ṣe lórílẹ̀ èdè nàìjíríà arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ john stith pemberton ni ó ṣẹ̀dá coke ní sẹ̀ńtúrì ọkàn dínlógún 19th century tí ó sìn tà á fún on... |
john stith pemberton american pharmacist inventor of coca-cola ojúewé yìí jẹ mọ́ nípa the american druggist fún other people named john pemberton ẹ wo john pemberton disambiguation john stith pemberton tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹjọ oṣù keje ọdún 1831 july 8 1831 tí ó sìn kú ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹjọ 1888 august 16 1888 ... |
ayò ọlọ́pọ́n ayò ọlọ́pọ́n jẹ́ eré ìdárayá ìbílẹ̀ tí ó wọ́pọ̀ láàrín yorùbá ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ayò yí fẹ́ fara pẹ́ oware tí ó tan kálẹ̀ de orílẹ̀-èdè amerika láti ibi òwò-ẹrú ó jẹ́ ọ̀kàn lára àwọn eré àbáláyé títa ni à ń ta ayò títa èyí ló bí ìpèdè eré là á fi ọmọ ayò ṣe eré pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ ni ayò èso sẹ́yò ni wọ́n fi... |
adekunle gold adekunle almoruf kosoko tí a bí ní oṣù kìíní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n ọdún 1987 tí a mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi adekunle gold àti ag baby jẹ́ akọrin ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà akọrin sílẹ̀ ati ayàwòrán ó di ìlúmọ̀ọ́ká olórin lẹ́yìn tí ó kọ orin kan tí a mọ̀ sí “ṣadé” ní ọdún 2015 ní ọdún 2015 ó fọwọ́síwèé àdéhùn ìgbàsílẹ̀ pẹ... |
fausat balogun fausat balogun tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí madam ṣajẹ ní wọ́n bí ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì ọdún 1959 february 13th 1959 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè nàìjíríà sinimá àgbéléwò èdè yorùbá ni madam ṣajẹ tí gbajúmọ̀ gbajúmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré sinimá àgbéléwò bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ó kópa ère àwàdà lorí t... |
faithia balogun faithia williams tí a bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kejì ọdún 1969 jẹ́ òṣèré olóòtú ati olùdarí fíìmù ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀ a bí i ní ìlú ikeja ní oṣù kejì ọdún 1969 ó wá láti ìlú okpara ní ìpínlẹ̀ delta ó kàwé ni ilé-ìwé alákòóbẹ̀rẹ̀ maryland àti maryland comprehensive secondary school ní ip... |
toluse olorunnipa tolúṣẹ tolú ọlọ́runnípa tí a bí ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kejìlá ọdún1986 jẹ́ ẹ̀yà american-nigerian oníròyìn olú-ilé-iṣẹ́ ìṣèjọba orílẹ̀ èdè amẹ́ríkà white house àti akọ̀ròyìn orí tẹlifíṣọ̀ọ̀nú òun ni oníròyìn orílẹ̀-èdè nàìjíríà àkọ́kọ́ tí ó ṣiṣẹ́ ó oníròyìn olú-ilé-iṣẹ́ ìṣèjọba orílẹ̀ èdè amẹ́ríkà w... |
ọlájùmọ̀kẹ́ òrìṣàgúnà ọlájùmọ̀kẹ́ òrìṣàgúnà tí wọ́n bí ọdún 1989 jẹ́ awẹ́lẹ́wà àti aláwòkọ́ṣe ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà tí ó di gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́kà nígbà tí ó ń kiri búrẹ̀dí ni ìlú èkó tí orí sìn gbé e ko olóore ó jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun tí ó kiri búrẹ́dì tà ní èkó |
jimi ṣolanke jìmí ṣólàńkẹ́ tí wọ́n bí ní oṣù keje ọdún 1942 july 1942 - 5 oṣù kejì 2024 jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé eléré-oníṣe olórin ìbílẹ̀ akéwì àti oǹkọ̀tàn omọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ṣólàńkẹ́ kàwé gboyè ní ifáfitì ìbàdàn níbí tí ó ti gbàwé ẹ̀rí dípúlọ́mà nínú eré oníṣe iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré lẹ́yín tó parí ẹ̀... |
kunle afod kúnlé afod tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹwàá ọdún 1973 24-10-1973 jẹ́ òṣèré sinimá àgbéléwò yorùbá tí wọ́n bí ní ìpínlẹ̀ èkó àmọ́ tí òṣẹ̀ wá láti ìlú ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ tí ó sì jẹ́ akọ́bí nínú ọmọ mẹ́rin tí àwọn òbí rẹ̀ bí ètò ẹ́kọ́ rẹ̀ kúnlé bẹ̀rẹ̀ ẹ́kọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ́kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ìlú fe... |
david àlàbá david ọlátòkunbọ̀ àlàbá tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ọdún 1992 jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè nàìjíríà ṣùgbọ́n tí ó di ọmọ orílẹ̀ èdè austria tí ó sìn ń ṣojú orílẹ̀ èdè náà gẹ́gẹ́ bí agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù bayern munich ní o ti ń gba bọ́ọ̀lù jẹun gẹ́gẹ́ bí agbábọ́ọ̀lù tó tó gbangb... |
bayern munich bayern munich jẹ́ ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá jẹun lórílẹ̀ èdè germany |
ìlú festac ìlú festac jẹ́ ìlú kan tí ìjọba kọ́ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ilé-ìgbé sí ní ìpínlẹ̀ èkó ìlú yí wà ní òpópónà márosẹ̀ ti èkó sí àgbádárìgì wọ́n ṣe ìkékúrú orúkọ ibùgbé náà sí festactí àkótán rẹ̀ dúró fún second world african festival of arts and culture ìyẹn ọdún àṣà àti ìṣe ti àpapọ̀ ilẹ adúláwọ̀ tí ó wáyé níbẹ̀ ní ọdún 1... |
victor osimhen victor james osimhen tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1989 29th december 1998 jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà agbábọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù lille tí orílẹ̀ èdè france òun ni agbaboolu sáwọ̀n tó dára jù lọ fún ikọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́́lọ́wọ́ ní ọdún 2020 wọ́n tari osimhen lọ sí inú ẹgbẹ́ agbábọ... |
amúwò-ọ̀dọ̀fin amúwò-ọ̀dọ̀fin ni ìjọba ìbílẹ̀ tí ó wà nị́ ẹkùn àgbádárìgì ní ìpínlẹ̀ èkó ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ọ̀nà tí ìjọba ìbílẹ̀ yí pín sí ìjọba ìbílẹ̀ yí pín sí méjì níbi tí a ti rí onídàgbà-sókè oríadé àti ìjọba ìbílẹ̀ onídàgbà-sókè amúwò tí àwọn náà ní ìsọmọgbè méje 7 lábẹ́ ìkọ̀ọ̀kan wọn àwọn ni abúlé-òṣun agbój... |
ìjòyè ìjòyè nílẹ̀ yorùbá túmọ̀ sí àwọn ènìyàn péréte kan tí wọ́n ma ń ṣe ìṣàkóso ìjọba ìlú pẹ̀lú ọba tí ó jẹ́ aláṣe pátápátá lórí gbogbo ìlú àti ìgbìmọ̀ àwọn ìjòyè oyè jíjẹ gẹ́gẹ́ bí ogún ìdílé àwọn ìjòyè kọ̀ọ̀kan ni wọ́n jẹ́ aṣojú ìdílé kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ti jáde wá ìdílé kọ̀ọ̀kan tí ìjòyè kọ̀ọ̀kan ń ṣojú fún ni wọ́n ní... |
dupe jayesinmi dúpẹ́ jáyésinmi tí yóò pé ọmọ ọdún ménìlélọ́gọ́ta 62 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ọmọ bíbí ìjẹ̀bú igbó ni ìpínlẹ̀ ògùn ṣùgbọ́n tí àwọn òbí rẹ̀ bí sí ìlú ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ lórílẹ̀ èdè nàìjíríà ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ dúpẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní seventh day adventist primary school ní ilé-ìfẹ́... |
suleiman bogoro ọ̀jọ̀gbọ́n prof suleiman elias bogoro jẹ́ ọ̀gá àgbà executive secretary tí àjọ ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀ èdè nàìjíríà fún owó ìrànwọ́ fún àwọn ifáfitì tertiary education trust fund tetfund ààrẹ muhammadu buhari yàn án sípò yìí lọ́dún 2019 ó ti wà nípò yìí bákan náà lọ́dún 2014 sì 2016 |
erìgì erìgì tàbíeègìni jẹ́ àkójọpọ̀ iṣan tí ó wà lórí eegun tó gbé ẹnu dúró tí ó sì so pọ̀ mọ́ agbarí nínú làá ẹnu lọ́ùún ìṣòro kí ṣòro tó bá ń dojú ké erìgì yálà látara àásán àrùn tàbí kòkò búburú lè ṣe àkóbá kí ó sì mú kí ènìyàn tàbí ohun ẹlẹ́mìí tó bá ní eyín ó di aláìlera |
ata ilẹ̀ ata ilẹ̀ jẹ́ ohun ọ̀gbìn tí ó ń tinú ilẹ̀ ju tàbí jáde wọ́n ma ń lòó lọ́pọ̀ ìgbà fún ohun èlò ìsebẹ̀ tàbí oògùn tàbí àgbo ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun ọ̀gbìn tí kìí tètè kú tí ó sì ma ń pẹ́ kí ó tó bàjẹ́ ọdọdún ni ata ilẹ̀ ma ń ju lójú ibi tí wọ́n bá gbìín sí tí wọ́n sì ti kórè rẹ̀ ìrísí rẹ̀ nígbà tí ata ilẹ... |
láńre hassan láńre adéṣínà hassantí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí' ìyá àwẹ̀ró tí wọ́n ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹwàá ọdún 1950 3rd october 1950 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìlú láti orílẹ̀ èdè nàìjíríà sinimá àgbéléwò èdè yorùbá ní ó máa ń ṣe jùlọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń kópa nínú tí èdè gẹ̀ẹ́sì náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan... |
àdúrà olúwa àdúrà olúwa jẹ́ àdúrà tí àwọn ẹlẹ́sìn ọmọ lẹ́yìn jésù kírísítì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú bíbélì nínú ìwé mátíù orí kẹfà ẹsẹ kẹsàn-án títí dé kẹtàlá ó jẹ́ àdúrà tí àwọn kírísítẹ́nì máa ń gba pẹ̀lú ọ̀wọ̀ níbikíbi tí wọ́n bá ti ń gbà á àdúrà olúwa gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú bíbélì 69 nitorina bayi ni ki ẹnyin mã... |
kareem waris kareem ọlámilékan waris jẹ́ ọ̀dọ́mọdé ọmọ ọdún mẹ́tàlá tí ó jẹ́ gbajúgbajà afọwọ́-yàwòrán ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ ògùn lórílẹ̀ èdè nàìjíríà waris ya àwòrán ààrẹ orílẹ̀ èdè faransé emmanuel macron nígbà tí ó wà sì orílẹ̀ èdè nàìjíríà lọ́dún 2018 láàárín wákàtí méjì àwòrán yìí dára tó bẹ́ẹ̀ gẹ̀ẹ́ tí ààrẹ emmanuel m... |
murphy afolabi murphy afolabi tí wọ́n bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù karùn-ún ọdún 1974 5th may 1974 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré olùdarí àti oǹkọ̀tàn sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà murphy afọlábí dii olóògbé níí ọjó kẹ́rínlà oṣù karùn-ún ọdún 2023 14th may 2023 ìgbà èwe aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ àti iṣẹ́ tíátà rẹ̀ wọ́n bí afọlábí ni ìp... |
rebecca adébímpé adékọ́lá rebecca adébímpé adékọ́lá tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí ìrètí jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò ọmọ yorùbá lórílẹ̀ èdè nàìjíríà tí ó di olóògbé ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 2002 27th september 2002 kí ó tó di olóògbé ìrètí jẹ́ ọ̀kan lára ìlúmọ̀ọ́kà òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò pàápàá... |
adesua etomi adesua etomi tí a bí ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kejì ọdún 1986 tàbí 1988jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà kan ní ọdún 2014 ó kópa nínú fíìmù àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ knocking on heaven's door èyí sì jẹ́ àkọ́kọ́ ṣe rẹ̀ ní ọdún 2016ó gba àmì ẹ̀yẹ fún òṣèrébìnrin tí ó dára jù lọ ti africa magic viewers c... |
banky w olúbánkọ́lé wellington tí a bí ní ọjọ́ ketàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta ọdún 1981 tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí banky w tí ó sì ń jẹ́ banky wellington nínú fíìmù àgbéléwò jẹ́ olórin orílẹ̀-èdè nàìjíríà òṣèré àti olóṣèlú ìgbésí ayé àti ètò-èkó rẹ̀ united states ni a bí banky w sí àmọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ni àwọn òbí rẹ̀ n... |
adékọ̀yà òkúpè agbọ́nmágbẹ olóògbé adékọ̀yà òkúpè agbọ́nmágbẹ tàbí mathew adékọ̀yà òkúpè agbọ́nmágbẹ jẹ́ pàràkòyí oníṣòwò àti ayánilówó tí ìjọba fọwọ́ sí gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ kan tí ọmọ rẹ̀ doyin òkúpè kọ lórí ìkànnì abánidọ́rẹ̀ẹ́ facebook òun ni olùdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ ìbílẹ̀ àkọ́kọ́ ilé ìfowópamọ́ agbọ́nmágbẹ agbọ́nm... |
hadiza isma el-rufai hadiza isma el-rufai ti a bi ni june 21 1960 jẹ onkọwe ati onkọwe ọmọ ilu naijiria iyawo ti gomina ipinlẹ kaduna malam nasir el-rufai hadiza da ipilẹ ti yasmin el-rufai foundation yelf ile-iṣẹ ti a ṣe iyasọtọ lati pese eto-ẹkọ si awọn obinrin ati awọn ọmọde pataki kikọ ati iwadi itan-akọọlẹ el-rufa... |
ilé ìfowópamọ́ agbọ́nmágbẹ ilé ìfowópamọ́ agbọ́nmágbẹ jẹ́ ilé ìfowópamọ́ ìbílẹ̀ àkọ́kọ́ lórílẹ̀ èdè nàìjíríà tí ìjọba àpapọ̀ fún láṣẹ olóyè mathew adékọ̀yà òkúpè agbọ́nmágbẹ ni ó dá a sílẹ̀ lọ́dún 1945 ilé ìfowópamọ́ agbọ́nmágbẹ ló wá di wema bank tí òde òní |
wema bank ilé ìfowópamọ́ wema jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ilé ìfowópamọ́ tó dáńgájíá jùlọ tí ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀ èdè nàìjíríà fún ní ìwé àṣẹ láti le ṣiṣẹ́ lórílẹ̀ èdè nàìjíríà pàràkòyí oníṣòwò ajé ọjọ́un oloye adékọ̀yà òkúpè agbọ́nmágbẹ ló dáa sílẹ̀ lọ́dún 1945 agbọ́nmágbẹ bank ní orúkọ tí ó sọ ọ́ nígbà náà ṣùgbọ́n àyípadà àti... |
doyin òkúpè doyin òkúpè jẹ́ olóṣèlú ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ ògùn lórílẹ̀ èdè nàìjíríà ó jẹ́ òlúrànlọ́wọ́ àgbà àná lórí ìbáṣepọ̀ àwọn ará ìlú fún ààrẹ àná orílẹ̀ èdè nàìjíríà goodluck jonathan láti ọdún 2010 sì 2015 kí ó tó bá goodluck jonathan ṣiṣẹ́ ààrẹ àná olúṣẹ́gun ọbásanjọ́ yàn án lọ́dún 2003 gẹ́gẹ́ bí agbenusọ rẹ̀ ó ti f... |
asisat òṣóàlà asisat lámínà òṣóàlà mon tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹ̀sán-án oṣù kẹwàá ọdún 9 october 1994 jẹ́ agbábọ́ọ̀lùbìnrin ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà tí ó ń gba bọ́ọ̀lù jẹun fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lùbìnrin barcelona ni orílẹ̀ èdè spain ó máa ń gba bọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ agbábọ́ọ̀lù-sáwọ̀n striker |
qasem soleimani qasem soleimani tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹta ọdún 1957 jẹ́ ọ̀gágun àti olórí ogun àṣírí orílẹ̀ èdè iran láti ọdún 1998 títí di ọdún 2020 tí àwọn ọmọ ogun orílẹ̀ èdè amẹ́ríkà pa á òun ni olórí ogun the islamic revolutionary guard corps irgc lórílẹ̀ èdè iran lọ́wọ́́lọ́wọ́ báyìí ikú qassem soleimani... |
fc pars jam |
facebook facebook jẹ́ ìkànnì abánidọ́rẹ̀ẹ́ lórí afẹ́fẹ́ ẹ̀rọ ayélujára ó jẹ́ ìkànnì tí lè ní àǹfààní sí láti orí foonu alagbeka ẹ̀rọ kọ̀m̀puta tábìlì àti èro komputa agbelowo tí ó ní àmúmọ̀ láti já lú ayé lórí afẹ́fẹ́ ilé iṣẹ́ tí ó ń ṣe kòkárí rẹ̀ gúnwà sí menlo park california lórílẹ̀ èdè amẹ́ríkà ọ̀gbẹ́ni mark zucker... |
mark zuckerberg mark elliot zuckerberg tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù karùn-ún ọdún 1984 14 may 1984 jẹ́ oníṣòwò ayélujára afọwọ́ṣàánú àti ọ̀kan lára olùdásílẹ̀ àti aláṣẹ yánányán ìkànnì abánidọ́rẹ̀ẹ́ facebook ọmọ orílẹ̀ èdè amẹ́ríkà |
jáwó jáwó tàbí ìgbànú jẹ́ àpò ìpawó sí tí àwọn ìyá-lọ́jà àti bàbá-lọ́jà ma ń so mọ́ inú tí wọn yóò daṣọ bo lásìkò tí wọ́n bá ń tajà lọ́wọ́ |
Subsets and Splits
No community queries yet
The top public SQL queries from the community will appear here once available.