raw_text
stringlengths
2
128k
ẹ̀ṣọ́ àmọ̀tẹ́kùn ọ̀lọ́pàá ìlẹ̀ oòduà àmọ̀tẹ́kùn jẹ́ ẹ̀ṣọ́ aṣọ́lùú tí àwọn gómìnà mẹ́fà tí ó wà ní ilẹ̀ yorùbá ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù kìíní ọdún 2020 9th january 2020 láti kún ìjọba àpapọ̀ lọ́wọ́ láti mójú tó ètò ààbò gbogbo ilẹ̀ káàárọ̀-ó-jíire tí ó dàbí pé ó ń mẹ́hẹ àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó wà il...
naira
wunmi toriola wunmi toriola tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù keje ọdún 1988 jẹ́ òṣèrébìnrin àti oǹkọ̀tàn sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ ògùn lórílẹ̀ èdè nàìjíríà ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ àti sinimá-àgbéléwò rẹ̀ wùnmí toríọlá kàwé gboyè nínú ìmọ̀ ìpèdè linguistic ní ifáfitì ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní ìlú ìlọrin univers...
french village badagry french village badagry tí àpèjá orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ the nigerian french language village jẹ́ ilé ìwé gíga fún ẹ̀kọ́ èdè faransé ti ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní ìlú àjárá ní ìjọba-ìbílẹ̀ badagry ní ìpínlẹ̀ èkó lórílẹ̀ èdè nàìjíríà ó jẹ́ ilé ìwé gíga ti àwọn yunifásítì káàkiri orílẹ̀ èdè nàìjíríà máa ń wá k...
ṣẹ́gun toríọlá ṣẹ́gun moses toríọlá tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹsàn-án ọdún 1974 18th september 1974 jẹ́ gbajúgbajà eléré ìdárayá ẹyin orí àga table tennis ọmọ bíbí ìlú ìlọrin ní ìpínlẹ̀ kwara lórílẹ̀ èdè nigeria
káyọ̀dé odùmósù pa kásúmù káyọ̀dé odùmósù tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ pa kásúmù ni wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹta ọdún 1953 16th march 1957 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré àti oǹkọ̀tàn sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ ògùn lórílẹ̀ èdè nàìjíríà pa kásúmù di gbajúmọ̀ òṣèré ìlúmọ̀ọ́kà nígbà tí ó kópa nínú àwọn sinimá-àgbéléwò ṣ...
káyọ̀dé ọlásẹ̀hìndé káyọ̀dé ọlásẹ̀hìndé tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí pa james ni wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹfà ọdún 1957 4th june 1957 jẹ́ gbajúmọ̀ aláwàdà òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn gbajúmọ̀ òṣèré nínú eré àwàdà tẹlifíṣàn tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ bàbá ajasco kódà nínú eré yìí ni wọ́n ti...
samuel ọlásẹ̀hìndé samuel ọláolúwa ọlásẹ̀hìndé tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹfà 16th july jẹ́ òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè nàìjíríà bàbá rẹ̀ ni gbajúgbajà aláwàdà òṣèré sinimá àgbéléwò káyọ̀dé ọlásẹ̀yìndé tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí pa james ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún márùn-ún nígbà ...
akátá akátá acinonyx jubatus jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹbí ológbò tó tóbi jùlọ tí wọ́n sì pọ̀ lórílẹ̀ alààyè ológbò ẹ̀yà ẹranko yí wópọ̀ jùlọ ní agbègbè sàhárà àríwá ilẹ̀ adúláwọ̀southern east africa àti àwọn díẹ̀ lára ìletò ní orílẹ̀ -èdè iran ẹranko yí fẹ́ràn láti máa gbé ní àwọn orílẹ̀ gbígba níbí tí koríko pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ w...
operation àmọ̀tẹ́kùn operation àmọ̀tẹ́kùn jẹ́ àgbáríjọ pọ̀ ẹ́ṣọ́ ọ̀tẹlẹ̀-múyẹ́ àti ọlọ́pàá gbogbo ìpínlẹ̀ iléẹ̀ yorùbá lápapọ̀ tí olú ilé iṣẹ́ wọn wà ní ìlú ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí gbogbo àwọn gómìnà ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ nàìjíríà gbé kalẹ̀ láti ró ilẹ̀ yorùbá lágbára ní abala ètò àbò kókó iṣẹ́ wọn ...
ọlọ ojúewé yìí jẹ mọ́ nípa ohun èlò ìdáná fún other uses ẹ wo batan ọlọ ni ó jẹ́ ọ̀kan lára ohun èlò ilé ìdáná tí wọ́n ma ń lò láti pèsè tàbí lọ oríṣiríṣi nkan bí ata ẹ̀wà ẹ̀gúsí àlùbọ́sà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́é lọ ìrísí rẹ̀ ọlọ ní ojú tó tẹ́ pẹrẹsẹ tí ó sì mọ níwọ̀n tí ó ṣeé gbé láti ibìkan sí ibòmíràn ẹ̀wé ọlọ ma ń ní ọmọ ọlọ...
ẹ̀ṣọ́ àmọ́tẹ̀kún ọ̀lọ́pàá ìlẹ̀ oòduà
benjamin káyọ̀dé ọ̀ṣúntókun ọ̀jọ̀gbọ́n benjamin olúwakáyọ̀dé ọ̀ṣúntókun tí wọ́n bí ní ọdún 1935 tí ó sìn di olóògbé lọ́dún 1995 19351995 jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsì àti olúṣèwádìí ìjìnlẹ̀ researcher àti neurologist ọmọ bíbí ìlú okemesiní ìpínlẹ̀ ekiti lórílẹ̀ èdè nàìjíríà
ẹgbẹ́ oòduà opc oòduà peoples congress tí a ń pè ní oòduà peoples congress opc jẹ́ agbaríjọ pọ̀ àwọn ọmọ yorùbá tí wọ́n jẹ́ ajìjàngbara ilẹ̀ yorùbá ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà àwọn ọmọ yorùbá ló jẹ́ pé wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti ní púpọ̀ọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè bíi benin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ̀pọ̀lọp...
frederick fáṣeun frederick isiotan fáṣeun ni wọ́n bí ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹsàán ọdún 193521-9-1935 1-12-2018 jẹ́ onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó adarí àti alága gbogbo gbò fún ẹgbẹ́ oòdua opc ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ètò ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ìṣègùn òyínbó ó kẹ́kọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ blackburn college tí ó sì tẹ̀ síwá...
àtòjọ àwọn ilé-ìwòsàn ti ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ nàìjíríà àtòjọ àwọn ilé-ìwòsàn ìjọba àpapọ̀ ti ilẹ̀ nàìjíríà ni
àtòjọ orúkọ àwọn gbajúmọ̀ òṣèré sinimá àgbéléwò nàìjíríà àtòjọ yìí ni orúkọ àwọn gbajúmọ̀ òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ nàìjíríà àwọn ìtọ́kasí https//nigerianfindercom/list-of-nollywood-actors-and-actresses/
akanu ibiam alàgbà francis akanu ibiam tí a bí ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 1906 tí ó sì kú ní ọjọ́ kìíní oṣù keje ọdún 1995 jẹ́ ẹni tó ń polongo ìlera pípé tí wọ́n sì yàn gẹ́gẹ́ bíi gómìnà apá ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdè nàìjíríà ní oṣù kejìlá ọdún 1960 títí wọ oṣù kìíní ọdún 1966 láti ọdún 1919 wọ ọdún 1951 fra...
ogedengbe agbogungboro ògèdèngbé agbógungbórò jẹ́ ìnagijẹ fún jagun jagun tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ ọ̀rìṣàráyíbí ògúnmọ́lá ògèdèngbé jẹ́ akínkanjú alágbára àti jagun jagun ọmọ bíbí ìlú iléṣà ní ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn olórí ogun nínú ìtàn ilẹ̀ yorùbá òun ni adarí ogun àwọn ọmọ ogun èkìtì-parapọ̀ ìgbé ayé rẹ...
àtòjọ orúkọ àwọn mínísítà ètò ẹ̀kọ́ ní nàìjíríà àwọn wọ̀nyí ni orúkọ mínísítà-àgbààti mínísítà-abẹ́lé tí wọ́n ti jẹ lórílẹ̀ èdè nàìjíríà
àtòjọ orúkọ àwọn mínísítà ètò ìlẹ̀-òkèrè ní nàìjíríà
àtòjọ orúkọ àwọn mínísítà ètò omi ní nàìjíríà
àtòjọ orúkọ àwọn agbẹnusọ ilé-ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin ní nàìjíríà àwọn wọ̀nyí ni orúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú àti àkókò àwọn agbẹnusọ ilé-ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin ní nàìjíríà
femi gbajabiamila fẹ́mi gbàjàbíàmílà tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 1962 june 25 1962 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèlú agbẹjọ́rò àti agbẹnusọ ilé-ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú all progressives congress tí ó ń ṣojú ìjọba ìbílẹ̀ sùúrùlérè ni ìpínlẹ̀ èkó láti ọdun 2019 ìbẹ̀rẹ̀...
regina daniels nigerian actress regina daniels tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá ọdún 2000 october 10th 2000 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀ èdè nàìjíríà ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́ kíkà rẹ̀ regina kàwé ní hollywood international school bẹ́ẹ̀ náà ló kàwé gboyè nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ mass comm...
uche azikiwe uche ewah azikiwe tí a bí ní ọjọ́ kẹrin oṣù kejì ọdún 1947 jẹ́ ọ̀mọ̀wé ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà olùkọ́ àti òǹkòwé òun ni opó nnamdi azikiwe ààrẹ orílẹ̀-èdè nàìjíríà nígbà kan rí ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ti ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ tí ìmọ̀ ìpìlẹ̀-ẹ̀kọ́ the department of educational foundation faculty of education ní university of ...
ilé ìfowópamọ́-àgbà tí nàìjíríà ilé ìfowópamọ́-àgbà tí nàìjíríà jẹ́ ilé-ìfowópamọ́-àgbà tí ó ń ṣe kòkárí àti ìmójútó àwọn ilé ìfowópamọ́ káràkátà lábẹ́ òfin ìfowópamọ́ tí ìjọba àpapọ̀ gbé kalẹ̀ lọ́dún 1958 tí ó sìn bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kìíní oṣù keje ọdún 1959 ó jẹ́ ilé-ìfowópamọ́ fún àwọn ilé-ìfowópamọ́ gómìnà ní orúkọ oyè t...
ilé ìfowópamọ́-àgbà tí nàìjíríà the central bank of nigeria
niniola níníọlá àpáta tí a bí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kejìlá ọdún 1986 tí a mọ̀ sí niniola jẹ́ olórin ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti akọrin sílẹ̀ ó kópa nínú project fame west africa ẹlẹ́ẹ̀kẹfà ni ọdún 2013 lẹ́yìn tí ó gbé orin àdákọ rẹ̀ ibadi jáde wọ́n yàn án bíi most promising act to watch ní 2015 nigeria entertainment ...
vlado goreski vlado goreski 1958 jẹ oṣere ara makedonia oluṣeto ipele o pari ile-iwe giga ti ile-iwe fine arts ni ljubljana slovenia o jẹ oludari aworan ti international graphic triennial - bitola o si ti kopa ninu lori ọgọrun aworan ifihan slovenia kroatíà fránsì ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì itálíàmẹ́ksíkò pólàndì rọ́síà japan o si ti...
elvis
àtòjọ orúkọ àwọn ààrẹ orílẹ̀-èdè amẹ́ríkà
àtòjọ orúkọ àwọn ààrẹ orílẹ̀-èdè amẹ́ríkà amẹ́ríkà
marcel quintet
àtòjọ àwọn ààrẹ orílẹ̀-èdè amẹ́ríkà
reece james reece james tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kejìlá ọdún 1999 8th december 1999 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì is footballer tí ó máa ń gbá àyè ìdáàbò bo ojúlé fún ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù chelsea fc
àtòjọ orúkọ àwọn agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ìdíje àgbábuta orílẹ̀-èdè gẹ̀ẹ́sì èyí ni àtòjọ orúkọ àwọn agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ìdíje àgbábuta orílẹ̀-èdè gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ti kópa nínú ìdíje àgbábuta bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá tí orílẹ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì fún ìgbà ọ̀ọ́dúnrún tàbí jù bẹ́ẹ̀ àtòjọ orúkọ àwọn agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ìdíje àgbábuta orí...
arsenal f c arsenal football club jẹ́ ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá ṣiṣẹ́ tí ó fìkàlẹ̀ sí ìlú islington ni london lorílẹ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì tí ó ń díje nínú ìdíje àgbábuta bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá tí orílẹ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì ìdíje bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá tí ó ga jùlọ lorílẹ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá yìí tí gba ìfẹ́-ẹ̀yẹ ...
ìdíje àgbábuta bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá tí orílẹ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì ìdíje àgbábuta bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá tí orílẹ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì tí ògbufọ̀ rẹ̀ lédè gẹ̀ẹ́sì jẹ́ english premier league epl jẹ́ ìdíje bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá tí ó ga jùlọ lorílẹ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì tí ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá okòó 20 máa ń díje fún lọ́dọọdún ó jẹ́ okowò pàtàkì ló...
ovie omo-agege obarisi ovie omo-agege tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹjọ ọdún 1953 23rd august 1953 jẹ́ amọ̀fin olóṣèlú ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ delta lorílẹ̀ èdè nàìjíríà òun ni igbákejì-ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ti orílẹ̀ èdè nàìjíríà àti asojú agbègbè àárín delta ní ilé ìgbìmò asòfin láàrin ọdún 2015 sí 2023 wọ́n dì...
omawumi omawumi megbele tí a bí ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹrin ọdún 1982 tí a mọ̀ sí omawumi jẹ́ olórin orílẹ̀-èdè nàìjíríà akọrin sílẹ̀ àti òṣèré tí ẹ̀yà itsekiri ó jẹ́ brand ambassador fún globacom kongacom àti malta guinness ó dara pọ̀ mọ́ kàm̀páìnì kan tí ń jẹ́ rise with the energy of africa ní ọdún 2007 tí ó kópa nínú w...
àlìmájìrín àlìmájìrín jẹ́ ìlànà ikẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn ará ilẹ̀ hausa ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ń lò láti kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn islam wọ́n ṣe àfàyọ orúkọ ìlànà ikẹ́kọ̀ọ́ yí láti ara ọ̀rọ̀ lárúbáwá al-muhajirun tí ó túmọ̀ sí a rìn rìn-àjò bi ó ṣe bẹ̀rẹ̀ laye àtijọ́ wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ yí ìlú kanem borno níbi t...
odó odó ni ohun-èlò ilé ìdáná kan tí a má ń sábàá lò láti fi lọ ata gún ẹ̀wà èlùbọ́ iyán àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ nípa fífi ọmọ odó gún wọn pọ̀ títí yóò fi rí bí a tí ń fẹ́ ìrísí rẹ̀ odó tí a ń wí yí ni ìrísí rẹ̀ dà bí igbá roboto ohun tí wọ́n fi ń ṣe odó wọ́n ma ń ṣe odó láti ara akọ igi irinsẹ̀rámíìkì tàbí akọ òkúta bí àpá...
ata ata ni ohun èso tí a ká tí a sì fi pèsè yálà ohun jíjẹ bí ọbẹ̀ tàbí mímu mìíràn kí ó le ta lẹ́nu kí ó sì lè ṣe ànfàní fún ará pàá pàá jùlọ lásìkò òtútù tàbí ọ̀gìnìntìn
tajudeen oyèwọlé abìjà tajudeen oyèwọlé tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí abìjà ni wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwá ọdún 1957jẹ́ gbajú-gbajà òṣèré orí-ìtàgé àti sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó sábà ma ń kópa nínú eré sinimá gẹ́gẹ́ bí ògbójú babaláwo àti oníṣègùn tó gbóná tí ó sì ma ń fi agbára rẹ̀ gba àwọn ènì...
fàsáásí ọlábánkẹwin dágunró fàsáásí ọlábánkẹwin tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí dágunró jẹ́ òṣèré orí ìtàgé oun sinimá àgbéléwòọmọ bíbí ìlú òṣogbo ní ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà àwọn sinimá tí ó ti ṣe ìkìlọ̀ agba 2008 àti bẹ́ẹ̀ beẹ̀ lọ ikú rẹ̀ fàsáásí si olóògbé ni ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹfà ọdún 2019 sílú eko
benedict peters nigerian oil billionaire benedict peters jẹ́ olówó billionaire ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà oun ni ó dá ilé iṣẹ́ aiteo group sílẹ̀ ilé iṣẹ́ tí ó níṣe pẹ̀lú iṣẹ́ epo rọ̀bì tí ó jẹ́ ti àdáni tí ó sì tóbi jùlọ ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ní nkan bí oṣù kọkànlá ọdún 2014 benedict ti ní to iye owó tí ó to bílíọ́nù méj...
ọbẹ̀ ọbẹ̀ ni ohun jíjẹ tí a fi oríṣiríṣi ohun èlò ìsebẹ̀ pèsè láti fi jẹun lájẹ gbádùn ọbẹ̀ ni ó ṣeé jẹ ní gbígbóná tàbí kí ó lọ́ wọ́ọ́rọ́ a sì lè jẹẹ́ ni tútù pẹ̀lú àwọn èròjà ọbẹ̀ lílo èròjà ọbẹ̀ dá lórí irúfẹ́ ọbẹ̀ tí a bá fẹ́ sè díẹ̀ lára àwọn èròjà ọbẹ̀ ni oríṣi ọbẹ̀ tó wà ó yẹ kí a pààlà rẹ̀ wípé oríṣiríṣi ọbẹ̀ l...
ìjàpá family of turtles ìjàpá jẹ́ ẹranko tí ó máa ń gbé nínú omi tàbí ìyàngbẹ ilẹ̀ ó jẹ́ ẹranko tó ní ọgbọ́n tí ó fi ń dá ààbò bo ara rẹ̀ ìjàpá lè wà láàyè fún ọgọ́rin sí àádóje ọdún
ata rodo ata rodo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ewébẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì nínú ohun èlò ìsebẹ̀ jákè-jádò orílẹ̀ àgbáyé oríṣiríṣi ata rodo ni ó wà ní wà pàá pàá jùlọ ní àwọn ọjà ilẹ̀ nàìjíríà ànfàní ata rodo ata rodo ni ó ní àwọn èròjà aṣara lóore fítàmì bii c a b6 àti folate ó tún ní èròjà lycopeine àti capsaicin àwọn èròjà yí ni wọ...
ata ṣọ̀mbọ̀ ata ṣọ̀mbọ̀ tàbí chili ata ṣọ̀mbọ̀ ni wọ́n ma ń lo láti lè jẹ́ kí ónjẹ ó ta lẹ́nu èròjà capsaicin ni ó ma ń fún ata ṣọ̀mbọ̀ ní agbára láti ṣe iṣẹ́ títa lẹ́nu ibi tí ṣọ̀mbọ̀ ti ṣẹ̀ wà ata ṣọ̀mbọ̀ lò ni ó ṣẹ̀ wá láti orílẹ̀-èdè mẹ́síkò ata ṣọ̀mbọ̀ lò tan kalẹ̀ àgbáyé láti ilẹ̀ mẹ́síkò látàrí ìdòwòpọ̀ wọ́n máa...
ata tàtàṣé ata tàtàṣé ni wọ́n tún ń dà pe ní sweet pepper bell pepper paprika tàbí ní èdè gẹ̀ẹ́sì ata yí ma ń ní ẹ̀yà ewébẹ̀ tí a fi ń ṣe ohun jíjẹ tí ó ma ń ní oríṣiríṣi àwọ̀ bí àwọ̀ pupa funfun àwọ̀ ewé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ata tàtàṣé kìí sábà ta ní tirẹ̀ nítorí wípé ó ma ń dùn ní tirẹ̀ agbègbè tí ata yí ti fẹ́ràn jùlọ...
tìmọ́ọ̀tì tìmọ́ọ̀tì jẹ́ èso ewébẹ̀ àti ohun ọ̀gbìn tí a lè jẹ lásán tàbí kí á slọ̀ọ́ pọ̀ mọ́ àwọn èròjà ìsebẹ̀ tó kù bí lílo tìmọ́ọ̀tì lílo tìmọ́ọ̀tì dá lórí irúfẹ́ ọbẹ̀ tí a bá fẹ́ sè àmọ́ tí a bá fi èròjà ìsebẹ̀ yí kún àwọn èlò ọbẹ̀ tókù yóò mú kí ọbaẹ̀ náà ó ní àádùn tó peregedé commonly known as a tomato plant the ...
helen paul helen paul jẹ́ aláwàdà ólórin àti òṣèré orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó tún máa ń ṣiṣẹ́ ìpanilẹ́rìn-ín rẹ̀ lórí ètò stand up nigeria tatafo sì ni a mọ̀ ọ́ sí lórí ìtàgé ohun tó yà á sọ́tọ̀ ni óhùn rẹ̀ tí ó dà bí ti ọmọdé bírín tí ó máa ń lò láti fí p anlẹ́rìn-ínn àìpẹ́ yìí ni ó gbóyè doctorate nínú theater arts láti y...
àgbọn àgbọn jẹ́ èso tí igi àgbọn máa ń so ó jẹ́ èso tí ó wúlò lọ́pọ̀lọpọ̀ pàápàá jùlọ fún jíjẹ ìwòsàn ṣíṣe àdí-àgbọn àti àwon ohun èlò mìíràn tí wọ́n máa ń fi àgbọn ṣe ìwúlò àgbọn oríṣiríṣi nǹkan ni àgbọn wúlò fún bí wọ́n ṣe ń jẹ àgbọn bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń fi í ṣe oríṣiríṣi nǹkan mìíràn àgbọn wà fún jíjẹ ènìyàn lè jẹ fu...
ìwà àjẹbánu ìwà àjẹbánu jẹ́ abala ìwà àìṣòdodo tàbí ìwà ọ̀daràn tí àwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́ àwọn òṣèlú tó wà nípò àṣẹ tàbí agbára máa ń hù fún àǹfàní ara wọn ó jẹ́ ìwà ìṣagbáralò fún àǹfàní ara ẹni lára àwọn ìwà àjẹbánu ni ẹ̀gúnjẹ gbígbà ìwà ìkówójẹ nípò àṣẹ ìṣègbè fún ẹ̀bí ará tàbí ọ̀rẹ́ ẹni fún àǹfàní láìtẹ̀lé ìlànà tàbí ...
owó-ẹ̀yìn corrupt solicitation acceptance or transfer of value in exchange for official action owó-ẹ̀yìn tàbí ẹ̀gúnjẹ ni gbígba owó tàbí ẹ̀bùn mìíràn lọ́nà àìtó láti ṣẹ̀gbẹ̀ fúnni fún èyíkéyìí àǹfàní ó jẹ́ ọ̀kan lára ìwà àjẹbánu tó burú jáì àwọn ọ̀gá ilé-iṣẹ́ àwọn olórí aláṣẹ tàbí àwọn olóṣèlú ni aje ìwà ìbàjẹ́ yìí sáà...
ewúro ewúro tí ó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára ẹbí asteraceae jẹ́ ewébẹ̀ tí ó wọ́pọ̀ jù lọ ní ilẹ̀ adúláwọ̀ ìrísí rẹ̀ igi ewúro máa ń ga nílẹ̀ tó iye bàtà tí ewé rẹ̀ sì máa ń gùn tó níye ẹ̀yìn ewé náà kò sì dán mọ́rán àwọn orúkọ tó ń jẹ́ ewúro ni wọ́n máa ń pè ní bitter leaf ní èdè gẹ̀ẹ́sì nítorí adùn kíkorò tó ní wọ́n máa ń p...
bíọ́dún ọ̀kẹ́owó bíọ́dún ọ̀kẹ́owó tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ ọmọ butty ni wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1971 26th december 1971 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ọmọ bíbí rẹ́mọ ni ìpínlẹ̀ ògùn ṣùgbọ́n ó dàgbà sí ìpínlẹ̀ èkó lórílẹ̀-èdè nàìjíríà ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú bíọ́dún jẹ́ ọm...
instagram instagram tí wọ́n tún máa ń pè ní kúkúrú ní ig tàbí insta jẹ́ ìkànnì ayélujára abánidọ́rẹ̀ẹ́ aláwòrán àti fídíò tí ilé iṣẹ́ facebook ní tí ó gúnwà sí orílẹ̀-èdè amẹ́ríkà ọ̀gbẹ́ni kevin systrom àti mike krieger ní wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ lọ́dún 2010 kí ilé iṣẹ́ facebook tó wà rà á lọ́wọ́ wọn orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbè...
cristiano ronaldo ká mọ́ ṣe àṣìṣe rẹ̀ mọ́ ronaldo brazilian footballer cristiano túndarí síbí yìí fún other people named cristiano ẹ wo cristiano given name and cristiano surname cristiano ronaldo dos santos aveiro ti a mọ sí cristiano ronaldo ronaldo tàbí cr7 ti a bi ní oṣu kẹta ọjọ 5 ọdun 1985 ní funchal jẹ agbabọọlu...
samuel ortom samuel ioraer ortom tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹrin ọdún 1961 23rd april 1961 jẹ́ òṣèlú oníṣòwò àti aláàánú ọlọ́rẹ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ benue lórílẹ̀ èdè nàìjíríà òun ni gómìnà ìpínlẹ̀ benue lọ́wọ́́lọ́wọ́ lọ́dún 2015 ló wọlé gẹ́gẹ́ bí gómìnà lábẹ́ àsíyá ẹgbẹ́ òṣèlú apc nígbà tó di ọdún 2019 ó tún wọlé...
eyo festival eyo festival jẹ́ òrìṣà ayẹyẹ tí a mọ̀ mọ́ erékùsù èkó ní ìpínlẹ̀ èkó lórílẹ̀ èdè nàìjíríà ó jẹ́ òrìṣà tí àwọn ẹgbẹ́ awo máa ń fi ń ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fún olóyè pàtàkì tàbí ọba tí ó bá wàjà ní èkó nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀ wọn a máa gbé ẹ̀yọ̀ jáde fún àwọn ayẹyẹ pàtàkì mìíràn ní erékùṣù èkó ọdọọdún ni wọ́n máa ń ṣodún ẹ...
eré òṣùpá eré òṣùpá jẹ́ erémọdé tí àwọn ọmọdé máa ń fi dára yà tàbí kẹ́kọ̀ọ́ lálẹ́ nígbà tí ìmọ́lẹ̀ òṣùpá bá tàn láyé àtijó àwọn ọmọdé àdúgbò á máa kó ara wọn jọ lálẹ́ láti dára yá nípa ṣíṣe àwọn eré òṣùpá bíi bojúbojú onídè ré àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀ àgbà àdúgbò kan ni yóò kó àwọn ọmọdé jọ láti pa àlọ́ f...
èrànkòrónà àwọn ẹ̀rànkòrónà jẹ́ àwọn èràn tọ́ ń kó àrùn ran àwọn ẹranko afọ́mọlọ́yàn bíi ènìyàn àti àwọn ẹyẹ bí ó bá jẹ́ ènìyàn coronavirus tàbí koronafáírọ́ọ̀sì yìí a máa fa àrùn sí àwọn ẹ̀yà ara inú tí ènìyàn fi ń mí tí ó sìn lè pànìyàn kíákíá ó lè fa irú àrùn yìí tàbí ìgbẹ́-gbuuru diarrhea fún ẹyẹ ẹlẹ́dẹ̀ tàbí màlúù...
adedotun aremu gbadebo iii adedotun aremu gbadebo lll tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹsan ọdún 1943 ní aláké ti ilẹ̀ ẹ̀gbá lọwọlọwọ bayi ẹ̀gbá jẹ́ ẹ̀yà kan ní ìlú abẹ́òkuta orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó ti wà lórí oyè láti ọjọ́ kejì oṣù kẹjọ ọdún 2005 ìbẹ̀rẹ̀ ayé a bí gbádébọ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹsan ọdún 1943 sínú ìdílé ọba t...
ekoexcel ekoexcel jẹ́ ìlànà ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ tuntun tí ìjọba ìpínlẹ̀ èkó ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ lọ́dún 2020 nípa lílo ẹ̀rọ ìléwọ́ kọ̀m̀pútà fún ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ilé ìwé àkóbẹ̀rẹ̀ ó jẹ́ ètò ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìṣèjọba gómìnà ìpínlẹ̀ èkó babájídé olúṣọlá sanwó-olú ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ lọ́dún 2020 nínú ìlànà ekoexcel yìí gbogbo àw...
àtòjọ orúkọ àwọn olóòtú sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ètò orí tẹlifíṣàn talk show host túndarí síbí yìí fún the radiohead song ẹ wo talk show host songní ìsàlẹ̀ yìí ni àtòjọ orúkọ àwọn olóòtú sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ètò orí tẹlifíṣàn tí a tò orúkọ bàbá wọn ní àtòjọ ábídí èdè gẹ̀ẹ́sì
efinrin efinrin ni wọ́n tún ń pè ní clove basil tàbí african basil tí àwọn hawaii mọ̀ sí wild basil jẹ́ ẹ̀yà ewé kan tí ó wà tí ó sì wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ adúláwọ̀ madagascar apá gúsù ilẹ̀ ásíà ilẹ̀ bismarck archipelago wọ́n ń gbìn ín ní polynesia hawaii mẹ́síkò panama west indies bìràsílì àti orílẹ̀-èdè bolivia orúkọ rẹ̀ ní ...
coronavirus
ambrose olútáyọ̀ ṣómidé ambrose olútáyọ̀ ṣómidé jẹ́ olóòtú ètò lórí ẹ̀rọ tv/radio ó kàwé gboyè nínú ẹ̀kọ́ urban and regional planning ní ilé-ẹ̀kọ́ ọbáfẹ́mi awolọ́wọ̀ university ní ìlú ilé ifẹ̀ ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà òun ni adarí àgbà fún ilé iṣẹ́ ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ ti daar communications plc dcp tí ó sì dá ìkànì fàájì fm...
fàájì fm fàájì fm jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ kan tí ó jẹ́ ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ daar communications tí ó jẹ́ ti ọ̀gbẹ́ni raymond dokpesi jẹ́ olùdásílẹ̀ rẹ̀ ilé-iṣẹ́ fàájì wà ní ìlú alágbàdo ní ìpínlẹ̀ èkó ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà fàájì fm bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọjọ́ kíní oṣù kejìlá ọdún 2012 tí olùdarí àgbà fún ẹ̀ka ti rédíò ìyẹn ọ̀g...
jẹ̀dí jẹ̀dí jẹ̀dí jẹ̀dí tí a tún mọ̀ sí ìròbo jẹ́ àìsàn tí ní ṣe pẹ̀lú iṣan pàá pàá jùlọ iṣan inu ihò ìdí ní ibẹ̀rẹ̀ jẹ̀dí ma ń fa kí ènìyàn ó ma rígbẹ̀ẹ́ yà tàbí kí ó ma yàgbẹ́ gbuuru ní kòṣẹ kòṣẹ tí àìsàn yí bá ti dàgbà tàbí gbó sí ènìyàn lára ni ó ma ń jẹ́ kí ihò ìdí swelling medical|wú tàbí pọ́n bí ẹ̀jẹ̀ tí yóò sì ...
yẹmí ayébọ̀ yẹmí ayébọ̀ tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí yẹmí my lover jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé òun sinimá ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ òndó iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà ní ọdún 1983 lásìkò tí ó wà ní ilé-ẹ̀kọ́ oníwé mẹ́wá tí ó sì ko pa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré sinimá àgbéléwò yorùbá eré sinimá tí ó gbe jáde ní àsìkò ọdún 1990s ni yẹ...
fàrándà fàrándà jẹ́ àyè gbangba tí a fi sílẹ̀ ní ẹnu àbáwọlé inú ilé wa láti ìta tí ó sì wà lára ibi tí a fi òrùlé bò mọ́ ara ilé wa
ọbáfẹ́mi martins ọbáfẹ́mi akínwùnmí martins tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1984 28th october 1984 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè nàìjíríà tí ó máa ń gbá bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ni ipò agbábọ́ọ̀lù-sáwọn o gbajúmọ̀ látàrí eré sísá rẹ̀ bí ehoro bí ó bá ń gbá bọ́ọ̀lù martins wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìd...
ọjà balógun ọjà balógun ajéníyà jẹ́ ọjà kan tí ó wà ní ere-kùṣù ìpínlẹ̀ èkó ọjà yí kò ní atọ́nà ina pàtó nítorí wípé ó wọnú pupọ̀ àwọn àdúgbò lọ́tún lósì ni ṣùgbọ́n oríṣiríṣi aṣọ tàbí bàtà igbá-lódé èyíkéyí tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tàbí wà ni wọ́n yóò rí ra níbẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti wáyé níbeẹ̀ àwọn oríṣiríṣi ríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ lò ...
ọjà ọjà jẹ́ àwùjọ kékeré tàbí ńlá tí ètò kárà-kátà tàbí ìdókowò pọ̀ láàrín olùtajà àti olùrajà ti ma ń wáyé yàlà ní àrín ìlú ni tàbí lẹ́yìn odi oríṣi ọjà tó wà ní aye àtijọ́ ọjà pin sí oríṣi méjì ọjà ìlú tàbí ọjà ọba ni ibi tí kárà-kàtá lórí oríṣiríṣi lórí ohun kóhun tí ènìyàn bá fẹ́ ra ti ń wáyé nípa lílé ọjà síléẹ̀ f...
àwọn ọjọ́ ọ̀sẹ̀ yorùbá àwọn ọjọ́ ọ̀sẹ̀ yorùbá jẹ́ ònkà tí à fi ń ṣe ìṣirò iye ọjọ́ ọ̀sẹ̀ oṣù àti ọdún ní ilẹ̀ yorùbá gẹ́gẹ́ bí àwọn elédè tó kù lágbàáyé ti ní tiwọn náà ọjọ́ aje ọjọ́ ajé ni ọ jọ́ tí a ma ń dájú iṣẹ́ ajé tí a sì ma ń mú iṣẹ́ owó pẹ̀lú ní ilẹ̀ yorùbá òun sì ni ọjọ́ kejì nínú ọ̀sẹ̀ ọjọ́ ìṣẹ́gun èyí ni ọjọ...
ọṣẹ sodium salt of fatty acids long chain carboxylic acids used for washing and cleaning ọṣẹohun èlò tí a ń lò láti fi fọ ohun tí ó bá ṣeé ṣe imọ́ tótó gẹ́gẹ́ bí imọ́ tótó ara aṣọ ilẹ̀ abọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ àwọn ohun èlò yí lè jẹ́ ohun tí a ń lò nínú ilé tàbí ní ìta ilé tàbí ilé iṣẹ́ bí a bá lo ọṣẹ́ fún imọ́ tótó ó m...
àjàkálẹ̀ àrùn nipha àjàkálẹ̀ àrùn nipha jẹ́ àrùn kan tó jákè jáko ní kòkò àìfojúrí nipha ń ṣokùfà rẹ̀ àrùn yí ma ń fojú han lára ẹni tí ó ba ko nípa kí ẹni náà ó ní àìsàn ibàikọ́ orí fífọ́ àìlè mí kanlẹ̀ àti iye méjì èyí tún lè mú kí alásìn yí ó dákú lọ gbọnrangandan ohun tí ó ń ṣokùnfà àrùn yí kòkòrò àrùn nípha ni ó j...
patrick seubo koshoni patrick seubo koshoni tàbí patrick sẹ́húbò koshoni tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹrin ọdún 1943 tí ó sìn kú ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kìíní ọdún 2020 april 17 1943- 25 january 2020 jẹ́ ajagun-fẹ̀yntì orí omi nigerian navy vice admiral ọ̀gágun yányán chief of naval staff àti mínísítà-ana fú...
máàdámidófò máàdámidófò jẹ́ ètò láti dá ààbò bo òfò owó tàbí dúkìá ó jẹ́ ètò láti máa ṣòfò owó dúkìá tí ìjàm̀bá àìròtẹ́lẹ̀ bá dé sí ní ènìyàn lè ṣètò máàdámidófò lórí ẹ̀mí dúkìá tàbí ìlera
àtòjọ orúkọ àwọn ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù jẹun lórílẹ̀-èdè nàìjíríà àwọn wọ̀nyí ni àtòjọ orúkọ àwọn ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù jẹun lórílẹ̀-èdè nàìjíríà y yankari babes fc
abia warriors fc association football club in nigeria abia warriors football club jẹ́ ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá jẹun lórílẹ̀ èdè nàìjíríà tí wọ́n wà ní ìlú umuahia ní ìpínlẹ̀ abia lọ́dún 2005 sí ọdún 2010 orji uzor kalu fc ni orúkọ tí wọ́n ń jẹ́ wọ́n ṣe èyí láti bọlá fún gómìnà ìpínlẹ̀ abia nígbà náà orji uzor k...
abiola babes nigerian football club abiola babes jẹ́ ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá jẹun nígbà kan rí ní ìlú abẹ́òkúta lórílẹ̀ èdè nàìjíríà àgbà òṣèlú olóògbé bashorun moshood k abiola ní ó ni ín wọ́n gba ìgbéga sí ìdíje àgbábuta bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá tí orílẹ̀ èdè nàìjíríà lọ́dún 1984 lodun 2000 àtúnṣe dé bá ikọ̀ ẹgbẹ́ ...
abs fc nigerian football club abs fc tí àpèjá rẹ̀ ń abubakar bùkọ́lá saraki fc jẹ́ ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá tí ó fìkàlẹ̀ sí ìlú ìlọrin lórílẹ̀-èdè nàìjíríà wọ́n gba ìgbéga sí ìdíje àgbábuta bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá tí orílẹ̀ èdè nàìjíríà sáà ìdíje tí 2009-2010 wọ́n gbá ìdíje àgbábuta bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá àkọ́kọ́ tí nàìjí...
abuja fc nigerian football club abuja fc jẹ́ ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá-jẹun lórílẹ̀ èdè nàìjíríà tí ó ń díje ni abala ìdíje nigeria nationwide league wọ́n dá ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá yìí sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ kano kí wọ́n tó darí rẹ̀ sí olú ìlú nàìjíríà àbújá wọ́n máa ń lo pápá ìṣeré old parade ground gẹ́gẹ́ ...
àtòjọ àwọn olú-ìlú àwọn ìpínlẹ̀ ní nàìjíríà àwọn wọ̀nyí ni àtòjọ àwọn olú-ìlú àwọn ìpínlẹ̀ ní nàìjíríà
ronke odusanya ronke odusanya tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹta oṣù karùn-ún ọdún 1973 3rd may 1973 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò èdè yorùbá ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ ògùn lórílẹ̀ èdè nàìjíríà film producer and stage performer ìgbé-ayé àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ wọ́n bí rónkẹ́ ní ọjọ́ kẹta oṣù karùn-ún ọdún 1973 3rd ma...
roman polanski roman polanski ojoibi ọjọ́ 18 oṣù kẹjọ 1933 oludari filmu faranse
solomon ọlámilékan adéọlá solomon ọlámilékan adéọlá tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ yáyì ni wọ́n bí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá ọdún 1969 august 10 1969 jẹ́ onímọ̀ ìṣirò àti aṣòfin-àgbà nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀ èdè nàìjíríà tí ó ń ṣojú apá ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ èkó ó ti fìgbà kan jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin orílẹ̀ èdè nàìjír...
joaquin phoenix joaquin rafael phoenix né bottom tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1984 october 28 1974 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré sinimá àgbéléwò àti olóòtú ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè amẹ́ríkà ó ti gba ẹgbẹlẹmùkú àmìn ẹ̀yẹ nínú iṣẹ́ rẹ̀ pàápàá jùlọ àmìn ẹ̀yẹ bafta award a grammy award golden globe awards méjì screen ...
àtòjọ àwọn orílẹ̀-èdè áfíríkà nípa bi wọ́n ṣe pọ̀ tó níye èyí ni àtòjọ àwọn orílẹ̀-èdè àfíríkà nípa bí wọ́n ṣe pọ̀ tó níye a kọ èyí sílẹ̀ nípa lílo ìwòye iye ènìyàn tí ó wà lórílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìtọ́kasí ètò ìkànìyàn tí wọ́n ṣe lẹ́yìn lórílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan láìsí àní-àní ilẹ̀ áfíríkà ṣì ní ilẹ̀ tí ó ń dàgbà jùlọ níy...
àrùn kòkòrò jẹjẹrẹ àrùn kòkòrò jẹjẹrẹ jẹ́ àkójọpọ̀ àrùn tí ó kódà je pọ̀ tí wọ́n sì ń dàgbà lọ́nà àtiọ́ nínú apá ibìkan nínú ara tí ó sì lánfàní láti tan ká gbogbo oríkèríkè ara tó kù àrùn jẹjẹrẹ yàtọ̀ sí benign tumor èyí tí kìí tan ká ara bí a ṣe lè mọ̀ wípé a ní àrùn jẹjẹrẹ lára àwọn ọ̀nà tí a lè gbà mọ̀ wípé a ní àr...
àtòjọ àwọn orílẹ̀-èdè nílẹ̀ asia nípa àgbègbè wọn lábẹ́ yìí àtòjọ àwọn orílẹ̀-èdè nílẹ̀ asia nípa àgbègbè wọn ní àtò álúfábẹ́ẹ̀tì àpapọ̀ ìwọ̀n nípa ìbú àti òró ilẹ̀ éṣíà jẹ́ 44579000 km² àtẹ àkíyèsí àwọn kan nínú àwọn orílẹ̀ èdè yìí jẹ́ orílẹ̀ tí wọ́n wọnú ilẹ̀ mìíràn tàbí tàn ká sí ilẹ̀ mìíràn yàtọ̀ sí éṣíà àwọn wọ̀ny...
ìfètò sọ́mọ bíbí ìfètò sọ́mọ bíbí ni a lè pe ní ìlànà ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó ní ṣe pẹ̀lú bí a ṣe lè pinu lórí iye ọmọ tí ó bá wuni láti bí láì kò sí ìjẹni nípa lórí bí a ṣe lè fi àsìkò sí àárín àwọn ọmọ tí a fẹ́ bí náà lọ́nà tí kò ní pa wá lára yálà ní oògùn lílò ìgbé ayé tí ó dára nínú àwùjọ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ni àti bẹ́ẹ̀ ...
rọ́bà ìdáàbòbò rọ́bà ìdáàbòbò jẹ́ ohun èlò kan tí a lè fi dènà oyún àbadì àìsàn àrùn àti ìfara-káṣá tí ó lè ṣàkóbá fún àgọ́ ara ọkùnrin tàbí obìnrin nípasẹ̀ ìbálòpọ̀ lásìkò tí a bá ń ní ìbòpọ̀ lọ́wọ́ tàbí lẹ́yì ìbálòpọ̀ ọ̀hún sti tọkùnrin tobìnrin ni wọ́n ní rọ́bà ìdáàbòbò tiwọn àwọn ẹ̀rí máajẹ́mi nìṣó rẹ̀ ìwádi fi yén...
ìbálòpọ̀ copulation for reproduction or sexual pleasure or other penetrative sex acts for sexual pleasure ìbálòpọ̀ tàbí iyàrá ẹni lòpọ̀ jẹ́ gbólóhùn kan tí ó ń tọ́ka sí ìdàpọ̀ ìwọ̀nú-bọ̀nú akọ àti abo ọkùnrin àti obìnrin nípa kí akọ ó ki nkan ọmọkùnrin rẹ̀ bọ inú ojú nkan ọmọbìrin abo yálà léte àti ṣòwò ọmọ ni tàbí fi ...
fùrọ̀ / ihò ìdí fùrọ̀ túmọ̀ sí ihò róbótó tí jásínú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ àpò-àjẹsí ẹranko tàbí tènìyàn tí ó sì já sóde tí ó ń ṣiṣẹ́ fún yíya tàbí ṣíṣe igbáọ̀nsẹ̀ àwọn ohun burúkú tí kò wúlò fún ara mọ́ tó wà ní àgbàọ́ ara