raw_text
stringlengths
2
128k
white supremacy
sámúẹ́lì odulana odugade i
western region of nigeria
kyoto animation kyoto animationjapanese京都アニメーション - ile-iṣẹ idanilaraya japanese yi ni a kukuru article jọwọ mu yi
jonas altberg
federal university of agriculture abeokuta =yunifásítì ẹ̀kọ́ ọ̀gbìn ti ìjọba àpapọ̀ abẹ́òkúta funaab= ìtàn-àkọọ́lẹ̀ yunifásítì ẹ̀kọ́ ọ̀gbìn ti ìjọba àpapọ̀ ti o wa ni ìlú abeokuta ni ìpínlẹ̀ ògùn ni ìjoba àpapọ̀ da silẹ̀ ni ọjọ́ kini oṣù kini ọdún 1988 1 january 1988 ìjọba àpapọ̀ pa yunifásítì ìmọ̀ ẹrọ mẹrin papọ̀ mọ awọn yunifásítì mẹrin miran ni ọduń 1984 ki o to di wípé wọ́n ni ki wọ́n da dúró eléyì ló fa ìdásílẹ̀ yunifásítì ẹ̀kọ́ ọ̀gbìn méjì ọ̀kan si ìlú abeokuta ati èkejì sí ìlú mákúrdi ni ọjọ́ kan naa yi ni ìjọba yan ọ̀jọ̀gbọ́n nurudeen ọlọrun-nimbe adedipẹ gẹ́gẹ́ bi igbákejì aláṣẹ àkọ́kọ́ ti yunifásítì ẹ̀kọ́ ọ̀gbìn abeokuta ọ̀jọ̀gbọ́n adedipẹ dáwọ́lé iṣẹ́ ni pẹrẹwu lábẹ́ àṣẹ́ ní ọjọ́ kejìdín-lọ́gbọ̀n oṣù kinni ọdún 1988 28 january 1988 fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni wọ́n ti ṣèsì gba ọjọ́ ti ọ̀jọ̀gbọ́n adédípẹ̀ dáwọ́lé iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìdásílẹ̀ nígbàtí tí wọ́n ṣe àtúnyẹ̀wò sí ̀ofin tí ó dá yunifásítì yí sílẹ̀ àjọ ìgbìmọ̀ ṣe ìpinnu nínú ìpàdé kẹtale-laadọta rẹ 53 statutory council meeting ní oṣù kẹfà ọdún 2010 june 2010 dá ọjọ́ ìdásílẹ̀ padà sí ọjọ́ kinni oṣù kínní ọdún 1988 1 january 1988 gẹ́gẹ́ bí òfin tí ó dá yunifásítì ẹ̀kọ́ ọ̀gbìn yi ṣe làá sílẹ̀ kí ó tó di wípé yunifásítì ẹ̀kọ́ ọ̀gbìn abeokuta funaab wáyé ìjọba ti kọ́kọ́ ṣe ìdásílẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti ìmọ̀ ẹ̀rọ abéòkúta ní ọdún 1983 sùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún 1984 ní ìjọba pa ilé ẹ̀kọ́ gíga yi pọ mọ yunifásítì eko university of lagos tí wọ́n sì yí orúkọ rẹ padà sí ilé-ìwé gíga ti ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ àti ti imo ero ti ilu abeokuta college of science and technology abeokuta costab kí ó tó di wípé o da dúró ní oṣú kíní ọdún 1988 ilé-ẹ̀kọ́ gíga yunifásítì yí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́ ẹ̀kọ́ ní gbọ̀ngan ilé-ìwé abẹ́òkúta girama tí àtijọ́ tí ó wà ní ìgboro ìsàlẹ̀-ìgbèhìn yunifásítì yí parí ìṣípò padà rẹ lọ sí ibi tí yí ò wà títí láìyẹsẹ̀ ní òpòpónà alábàtà ní ọdún 1997 ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ẹ̀ka ìkọ́ ẹ̀kọ́ marun-un ni wọ́n kọ́kọ́ fi lélẹ̀ ní yunifásítì yí ní oṣù kẹwàá ọdún 1988
ọ̀wọ́n gbọ̀ngàn tinúbu ọ̀wọ́n gbọ̀ngàn tinubu tí a n pe ni ọ̀wọ́n gbọ̀ngàn òmìnira tẹ́lẹ̀ rí jẹ ọwọn manigbagbe ti o wa ni opopona gbooro broad street ni erekusu eko lagos island ni ipinle eko ni orilẹ-ede naijiria ni igba kan ri ita tinubu ni a npe ni irati iyaafin efunroye tinubu ti o je oniṣowo ẹrú ati gbajugbaja oniṣowo ki o to di pe a yi orukọ rẹ pada si ọ̀wọ́n gbọ̀gàn ominira lati owo awon oludari eto iṣejọba ara ẹni akoko ni orilẹ-ede naijiria leyin eyi ni a tun wa yi oruko re pada si ọ̀wọ́n gbọ̀ngàn tinubu àgbékalẹ̀ gbọ̀ngàn yii je onigun-mẹrin ti a fi irin se odi yii kaakiri o si ni orisun omi meji ti o nfan omi si awon ododo ati awon igi ilẹ̀ olóoru ti o wa ninu rẹ̀ ère iyaafin tinubu ti o ga to iwon eniyan wa ninu gbọ̀ngàn yii o si duro lori orori kan
persepolis fc persepolis fc پرسپولیس
emmanuella immanuẹlla samuẹli a bi ni ọjọ́ kejì-le-lógún oṣù keje ọdún 2010 orúkọ ìnagijẹ ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn mo si ni emmanuella o si jẹ ọmọdé ò dẹrin p'oṣonu lori ikanni mark angel lórí ẹ̀rọ alatagba youtube ni ọdún 2017 ni ikanni awada mark angel lórí ẹ̀rọ alatagba youtube di akọkọ irú rẹ̀ ti o jẹ́ wípé ọmọ naijiria lo nii oun si ni àkọkọ ti yoo ni awon ololufe ti o to milionu kan ní iye ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀ immanuẹlla samueli jẹ ọmọ bibi ipinle imo ni apá ihà ila-oorun orílẹ̀-èdè naijiria a bi ni port harcourt ni ipinle rivers iṣẹ́ immanuẹlla bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àwàdà nigbati o pe ọmọ ọdun marun
balogun yakub abiodun yakub abiodun balogun tí a bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù karun ọdún 1951 jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè naijiria tí ó mọ̀ nípa ètò ọrọ̀-ajé olùdarí ètò ìṣèjọba aṣòfin ní ileé aṣojú-ṣòfin kéréré ní orílẹ̀-èdè naijiria tí ó ń ṣojú fún lagos island federal constituency ii ipinle eko south-west nigeria àti olùtọ́jú aṣojú ti ìpínlẹ̀ èkó nígbà kan rí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ a bí balogun yakub ní ọjọ́ karùn-ún oṣù karùn-ún ọdún 1951 ní lagos island ilé-ìwé fazil-omar ahmadiyya ní ìpínlẹ̀ èkó ni ó lọ kí ó tó lọ ilé-ìwé girama ti ansar-ud-deen ní surulere àmọ́ ó gba ìwé-ẹ̀rí waec ní ahmadiyya college ní agege ó gboyè bsc àti masters nínú ẹ̀kọ́ economics ní university of ibadan ní ọdún 1976 àti 1983 kí ó tó lọ royal institute of public administration níbi tí ó ti gb a ìwé-ẹ̀rí public administration ní ọdún 1996 iṣẹ́ ìjọba ó dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ìjọba ti ìpínlẹ̀ èkó ní ọdún 1977 gẹ́gẹ́ bíi akọ̀wé kékeré ní ẹ̀ka tó ń rí sí ìdàgbàsókè àti ìfilélẹ̀ ètò ajé ní ọdún 1990 ó lọ sípò olùdaríkejì fún àwọn orí-orí ní àjọ tó ń rí sí ètò-ìṣúná lẹ́yìn tó ti sìn ní onírúurú ọ̀nà wọ́n yàn án sípò akọ̀wé àgbà ní àjọ tó ń rí sí ètò ìṣúná ní ọdún 1997 ó sì wà nípò yìí títí wọ́n tún fi yàn án sípò olórí àwọn òṣìṣẹ́ ní ọdún 1999 lábẹ́ ìṣèjọba olóyè bola tinubu tó fìgbà kan jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ èkó àti adarí àgbà ẹgbé òṣèlú all progressives congress apc ní oṣù kaùn-ún ọdún 2010 ó fẹ̀yìntì nídìí iṣẹ́ ìjọba láti wọ ẹgbẹ́ òṣèlú iṣẹ́ òṣèlú ní oṣù kẹrin ọdún 2011 ódíje fún ipò ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ rẹ̀ lagos island federal constituency ii tí ó sì wọlé balogun jẹ́rìí sí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tó dúró fún lagos island federal constituency ii lagos state ní ọjọ́ ajé ọjọ́ kẹfà oṣù kẹfà ọdún 2011
édẹ́nì ti ihà ìlà oòrùn édẹ́nì ti ihà ìlà oòrùn bí a ti n kọ ní èdè japanisi 東のエデン àti ní èdè hepburn higashi no eden jẹ́ eré ìgbà-dé-gbà orí ẹ̀rọ mohunmaworan ti o da lori ẹranko ti a kọ́kọ́ ṣe afihan rẹ̀ lorí ẹ̀rọ mohunmaworan fuji ni ọjọ́ kẹsan oṣù kẹrin ọdún 2009 ni àkókò ti àwọn oluworan pọ julọ oludasilẹ oludari ati onko ere naa ni kenji kamiyama o si ṣe àfihàn àwọn onsere ti chika umino ṣẹda àti àwọn idaraya ti ilé iṣẹ́ production ig gbé kalẹ̀ a gbe ere yii kale lori itan ti kamiyama ko ni igba kan ri oun si ni ojulowo ere akoko ti ile ise ẹ̀rọ mohunmaworanit noitamina gbé jáde=àwon ìtokasí==
chioma chukwuka a bi chioma chukwuka ni ọjọ́ kejila oṣu kẹta ọdun 1980 a tun n pe orúkọ rẹ̀ ni chioma chukwuka akpotha tabi chioma akpotha o jẹ́ oṣere ati olugbekale fiimu ni orile-ede naijiria ni ọdun 2007 o gba ami ẹyẹ ti àwọn osere tiata fún ilẹ afrika gẹgẹbi obinrin ti o dara julo ti o si kopa gegebi osere akoko lobinrin ninu ere ati ami eye fun awon alawodudu ni hollywood gegebi oṣere lobinrin ti o dara ju lọ
boris johnson alexander boris de pfeffel johnson born 19 june 1964 jẹ́ olóṣèlú ará ilẹ̀ britènì tí ó wà nípò àṣẹ alákòóso àgbà ilẹ̀ britènì àti aṣíwájú ẹgbẹ́ òṣèlú the conservative party lọ́wọ́lọ́wọ́ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú egbe oselu conservative láti july 2019
theresa may theresa mary may ' brasier ibi 1 october 1956 je oloselu ara britani to figba kan wa nipo gegebi alakoso agba ile britani ati olori egbe oloselu konsafetifu lati 2016 de 2019
rufus giwa polytechnic rufus giwa polytechnic jẹ́ ile-ẹ̀kọ́ giga gbogbonìṣe tí ó wà ní ìlú ọ̀wọ̀ ní ìpínlẹ̀ òndó nàìjíríà ó gbàṣẹ gbòntẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ìgbìmọ̀ tí ó ń ri sí ètò ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe nílẹ̀ naijiria láti jẹ́ kí ó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ aládàáni ti ìjọba ìpínlẹ̀ àjọ tí ó ń ri sí ìdásílẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà national boars of technical education àti institute of chatered accountant wọ́n dá ilé-ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀ ní ọdún 1979 pẹ̀lú àṣẹ látẹnu gómìnà lásìkò ìjọba ológun sunday tuoyo wípé kí ó ma jẹ́ the polytechnic owo lẹ́yìn èyí ni gómìnà adekunle ajasin bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣagbátẹrù iké-ẹ̀kọ́ náà ní kété tí ó gorí oyè àṣẹ ní ọdún 1980 wọ́n yí orúkọ iké-ẹ̀kọ́ yí padà ondo state polytechnic ní ọdún 1990 nígbà tí yóò fi tó ọdún 2010 ilé-ẹ̀kọ́ náà ti ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin 4000 ilé-ẹ̀kọ́ yìí ní àwọn agbọ́nrin ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ lábẹ́ ẹ̀ka faculty ti engeneering science àti technology lems àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ bákan náà ni wọ́n ń sapá ní ìkẹ́kọ̀ọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ ìmọ̀ ìwádí àyíká ìmọ̀ ìṣirò ìmọ̀ ètò ọrọ̀ ajé àti ìṣúná ilé-ẹ̀kọ́ yí ti wọ́n tún ń dà pè ní rufus giwa polytechnic ní àwón olùdarí wọ̀nyí ti darí mr olúṣẹ́gun aródúdú mr james kọ́láwọlé dr adéyẹrí prof adedimila mr àlàó mr ogundowole prof peter fapetu prof agibefun
ilir meta ilir meta ojoibi 24 march 1969 je oloselu ara albania to ti wa nipo bi ààrẹ ilẹ̀ albáníà lati 24 july 2017 itokasi
oluseyi makinde olusèyí abiọ́dún mákindé ni a bí ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1967 25 december 1967 ó jẹ́ oníṣòwò olóṣèlú àti ọlọ́rẹ àtinúwá ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà òun ni gómìnà tí ó ń bẹ lórí àléfà lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ní apá ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ nàìjíríà wọ́n dìbò yàn-án ní ọdún 2019 lábé àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú people's democratic party pdp ó jẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ àti onímọ̀ nípa ìwọ̀n epo àti afẹ́fẹ́ gáàsì fluid and gas metering ibere pepe aye re ati eko a bi makinde si ile pa olatubosun makinde ati abigail makinde ni adugbo aigbofa oja’ba ni ilu ibadan ìpínlẹ̀ oyo ọ̀un ni awon obire bi siketa makinde bere eko re ni ile eko-ibere st paul primary school o pari eko- ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ni st michael primary schoolni ye metu makinde se eko girama ní bishop phillips academy ó tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní yunifásitì ìlú èkó níbi tó ti gba ìwé-ẹrí bachelor degree nínú ìmò electrical engineering
gregory hines gregory oliver hines february 14 1946 august 9 2003 je onijo osere akorin ati onimoijo ara amerika
samuel okwaraji samuel sochukwuma okwaraji 19 may 1964 12 august 1989 je oni-ise agbaboolu-elese to gba boolu fun naijiria o tun je agbejoro lori ofin ibasepo awon orile-ede lati pontifical lateran university ilu romu o ku nigba to wo lule nitori idina inu okan-aya to ba ni iseju 77k ere boolu ikopa ninu ife-eye agbaye pelu angola ni papa isere national ni surulere lagos state ni ojo 12 osu kejo odun 1989
joycelyn elders minnie joycelyn elders abiso minnie lee jones august 13 1933 je is an american oniwosan omode ati alakoso eto ilera igboro o je ogagun igbakeji adari ni ile-ise awon omose alafunse ise ilera igboro ati omo afrika amerika akoko to je yiyan sipo gege bi oniwosan agba orile-ede amerika o fi ipo yi sile ni 1994 lowolowo elders je ojogbon eniowo ninu eko iwosan omode ni yunifasiti arkansas fun sayensi oniwosan
dapo abiodun dapo abioduntí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkándínlọ́gbọ̀n oṣù kàrún-ún ọdún 1960 jẹ́ oníṣòwò àti olóṣèlú ọmọ ilẹ̀ yorùbá láti ìpínlẹ̀ ògùn lórílẹ̀-èdè nàìjíríà ó jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ ògùn nígbàtí o borí ìdìbò ti gómìnà ni ọdún 2019 lábẹ́ àsíyá ẹgbẹ́-òṣèlú apc dàpọ̀ abíọ́dún ni olórí ìgbìmọ̀ ti corporate affairs commission ó tún jẹ́ alakoso àti olùdarí ti ilé epo heyden àti olùdásílẹ̀ first power limited ní ọjọ́ kewa oṣù kẹta ọdún 2019 ìgbìnmọ̀ ti o n darí ìdìbò ni ilẹ̀ nàìjíríà èyí tí ó jẹ́ independent electoral commission kede dapo abiodun gẹ́gẹ́ bí gómìnà ti a dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ ògùn wọ́n ṣe ìbúra fún un gẹ́gẹ́ bi gomina ìpínlẹ̀ ògùn ní ọjọ́ kọnkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2019 29 may 2019 ìgbà èwe dapọ abiọdun wa láti ìpèrù remọ ni ìpínlẹ̀ ògùn ó wá láti ìdílé ọba a bi sínú ẹbí dọ́kítà emmanuel àti arábìnrin victoria abiodun tí wọ́n wá láti ìpèrù remọ ní ìla-òrùn ìpínlẹ̀ ògùn ni ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karun ọdún 1960 29 may 1960 ẹ̀kọ́ dapọ abiọdun kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásìtì obafẹ́mi awólọ̀wọ̀ tí ó wà ní iṣẹ́ dapọ abiọdun ni alakoso àti olùdarí ilé iṣẹ́ heyden petroleum limited upl ilé iṣẹ́ ti epo ati gaasi ni ilẹ̀ nàìjíríà ó tún jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ first power limited òṣèlú dapọ abiọdun jẹ́ ọ̀kan lara ọmọ ẹgbẹ́ tí ó dá ẹgbẹ́ alábùradà peoples democratic party sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ ògùn bíòtilẹ̀jẹ́pé ó jẹ́ ọ̀kan lara ọmọ ẹgbẹ́ onigbalẹ all progressive congress lọ́wọ́lọ́wọ́ bayi nígbàtí o fi ẹgbẹ́ ti ó wà tẹ́lẹ̀ sílẹ̀ lẹhin ìdìbò gbogboogbo ti ọdún 2015 ó díje du ipò láti lọ si ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà lati lọ ṣojú ilà oorun ti ìpínlẹ̀ ògùn lábẹ́ ẹgbẹ́ onigbale all progressive congress nínú ìdìbò gbogboogbo tí ó waye ni nàìjíríà ni ọdún 2015 èyí tí ó pàdánù rẹ fún ọmọ ẹgbẹ́ alábùradà peoples democratic party wọ́n yan dapọ abiọdun gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan lára àwọn aṣòfin àgbà tí ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ nàìjíríà ní ọdún 1988 lábẹ́ ẹgbẹ́ united nigeria congress party uncp èyí tí o ti kógbá sí ilé ó ti ṣiṣẹ́ sìn lábẹ́ ìgbìmọ̀ aarẹ àti ilé iṣẹ́ lórísirísi ní ọdún 2019 ó díje nínú ìdìbò ti gómìnà ní ìpínlẹ̀ ògùn labẹ ẹgbẹ́ onigbale all progressive congress ó sì borí ìbò na ó jẹ́ ọmọ lẹ́hìn kristi tooto ti o si njọsin pẹ̀lú ilé ìjọsìn mountain of fire and miracles ministry ó ti jẹri pe pẹ̀lú gbogbo bí àtakò láti má lè dé ófìsì ti gómìnà ìpínlẹ̀ ògùn ṣe pọ̀ tó olórun sì tún mú ò un dé ibẹ̀ ìgbésí ayé ara rẹ̀ abiodun ṣe ìgbéyàwó sí bamidele abiodun lọ́dún 1990 ó sì bí ọmọ márùn-ún lára rẹ̀ ni olóògbé olugbenga abiodun dj nàìjíríà kan tí a tún mọ̀ sí dj olu
bolaji abdullahi bolaji abdullahi a bi ni ọdún 1969 jẹ́ olóṣèlú àti oǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ nàìjíríà láti ìpínlẹ̀ kwara ó wà nínú ìgbìnmọ̀ ti alakoso orílẹ̀-èdè naijiria tẹlẹ lábẹ́ àkóso goodluck jonathan gẹ́gẹ́ bi minisita fún ìdàgbàsókè ọ̀dọ́ ní oṣù keje ọdún 2011 ati lehinna bi minisita idaraya ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ abdullahi kọ́ ẹ̀kọ́ gboyè lórí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láti ilé ẹ̀kọ́ gíga yunifásítì èkó ní ọdún 2001 pẹ̀lú sikolashipu chevening abdullahi fi orúkọ sílẹ̀ fún ikẹkọ ní ilé ẹ̀kọ́ fún iwadi ìdàgbàsókè institute of development studies ní yunifásítì ti sussex níbití o ti kọ́ ẹ̀kọ́ gboyè gíga tí ó peregedé lori ìṣèjọ́ba ati ìdàgbàsókè governance and development iṣẹ́ ayanse ní ọdún 1997 abdullahi darapọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ ìwé ìròhìn tí this day gẹ́gẹ́ bí oníròhìn sùgbọ́n lẹ́hìn ọdún kan ó kúrò láti lọ darapọ̀ mọ́ àpèjọ alákòso áfríkà african leadership forum ó padà ní ọdún 2002 tí ó sì ní ìgbega sí ipò igbákejì olóòtú ti ìwé ìròhìn ní ọdún 2003 lehinna wọ́n kọ́kọ́ yan abdullahi gẹ́gẹ́ bí olùránlọ́wọ́ pàtàkì fún ìbáraenisọ̀rọ̀ àti ìpín ýikáspecial assistant communication and strategy sí gómìnà ìpínlẹ̀ kwara tẹ́lẹ̀ bukola saraki ní ọdún 2003 lehinna ni o wa di olùdámọ̀ràn pàtàkì lórí ìmúlò àti ìpín yíká special adviser on policy and strategy ní ọdún 2005 wọ́n yan bolaji abdullahi gẹ́gẹ́ bi koomisoanna fún ètò ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ́ ti ìpínlẹ̀ kwara láti ọdún 2007 sí ọdún 2011 ó tẹ̀ síwájú láti lọ sìn nínú ìgbìmọ̀ minisita ti aàrẹ ilẹ̀ nàìjíríà tẹ́lẹ̀ goodluck jonathan nígbàtí wọ́n yàán gẹ́gẹ́ bi minisita fún ìdàgbàsókè ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ní oṣù keje ọdún 2011 lehinna ni wọ́n yàán gẹ́gẹ́ bi minisita fún eré ìdárayá ní oṣù kejìlá ọdún 2016 wọ́n kéde abdullahi gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé gbogboogbo ti orílẹ̀ national poblicity secretary fún ẹgbẹ́ onigbale all progressive congress ní ọjọ́ kini oṣù kẹjo ọdún 2018 abdullahi finú fẹ́dọ̀ fí ìwé sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé gbogboogbo tí ẹgbẹ́ onigbale all progressive congress tí ó sì kúrò nínú ẹgbẹ́ na àwọn ìtọ́kasí 1 https//wwwthisdaylivecom/indexphp/2018/10/02/bolaji-abdullahi-seven-others-withdraw-from-kwara-pdp-guber-race/ 2 https//punchngcom/ex-minister-laments-hardship/ 3https//wwwthisdaylivecom/indexphp/2018/03/02/bolaji-abdullahi-newly-inaugurated-boards-will-help-mdgs-navigate-political-difficulties/ 4https//punchngcom/i-like-doing-house-chores-to-encourage-my-sons-bolaji-abdullahi/ 5https//wwwvanguardngrcom/2017/11/bolaji-abdullahi-a-liar-exposed-his-book-as-tissue-of-lies-jonathan/ 6 http//saharareporterscom/2018/08/01/breaking-its-official-bolaji-abdullahi-resigns-apc 7https//wwwtammysenglishblogcom/2019/02/jambs-201920-english-novel-bolajihtml 8https//wwwbasedonnewscom/download-pdf-bolaji-abdullahi-sweet-sixteen-16-jamb-novel-summary-likely-exam-questions-150-plus-answers-jamb-examination/ 9https//dailypostng/2018/08/01/breaking-apc-spokesman-bolaji-abdullahi-confirms-exit-party/ 10https//wwwthecableng/payback-time-bolaji-abdullahi 11 https//dailypostng/2018/08/24/apc-ex-spokesman-bolaji-abdullahi-run-kwara-governor/ 12https//wwwdailytrustcomng/why-i-wrote-a-book-on-former-president-jonathan-bolaji-abdullahihtml
kyoto kyoto je ilu kan ni orile-ede japan population 1467702 2019
mudashiru obasa mudashiru àjàyí ọbasá jẹ́ agbẹjọ́rò olóṣèlú ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú all progressives congress ilẹ̀ nàìjíríà kan òun tún ni ó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ èkó lọ́wọ́lọ́wọ́ ibẹ̀rẹ̀ aye rẹ̀ a bí i ní ilù agege ní ìpínlẹ̀ èkó ní apa gúsù ìwọ̀ olorun ilẹ̀ nàìjíríà ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ st thomas acquinas ní sùúrù-lérè ṣáájú kí ó tó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama archbishop aggey memorial ní ìlú mushin ní agbègbè ìlasa-màjà ní ìpínlẹ̀ èkó níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gba ìwé ẹ̀rí ìdánwò àpapọ̀ ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ adúláwọ̀ waec ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀òfin ní ilé-ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀ èkó ní ọdún 2006 iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olóṣèlú ní ọdún 1999 mudashiru díje dupò sí ipò àga ijọba ìbílẹ̀ agege lábẹ́ egbẹ́ òṣèlú alliance for democracy bori ó sì borí léyìí tí ó ṣiṣẹ́ nibẹ̀ láàrín ọdún 1999 sí 2002 ẹ̀wẹ̀ ó ran díje dupò sí ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ìpínlẹ̀ èkó ní ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀ agége ní ọdún 2019 tí ó sì tún jáwé olúborí nínú ìdìbò naa tí ó sì sọ́ di agbẹnusọ́ fun ilé ìgbìmọ̀ náà ní ipinlẹ̀ ẹ̀kó àwọn ìtọ́kasí
gbenga adébóyè gbénga adébóyè 1959 oṣu kẹrin 2003 jẹ́ akọrin apanilẹ́rìín olótùú ètò orí rèdíò àti olùdarí ayẹyẹ ibẹ̀rẹ̀ aye rẹ̀ elijah olúwágbémiga adébóyè ni wọ́n bí ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù késàn ọdún 1959 3091959 ní ìlú ọdẹòmu ní ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ní gúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ nàìjíríà ìgbòkè-gbodò iṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ ògbóntagì sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí rédíò ní ipinlẹ̀ èkó ní ibẹ̀rẹ̀ ọdún 1980 ní bi tí ó ti gba ìnagijẹ rẹ̀ fúnwọntán oduọ́lọ́jì gbajúgbajà òṣèré orí-ìtàgé ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ìdòwú philip tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí ìyá rainbow ṣàpèjúwe gbenga gẹ́gẹ́ bí adẹ́rìín-pòṣónú àti aláwàdà tí ó ma ń tọrẹ àtinúwá fẹ́ni tó bá ni lo ìrànlọ́wọ́ nigba tí ó ń sọ bí gbenga ṣe fun òun ní ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ àkọ́kọ́ tí òun kọ́kọ́ ní láyé òun wọ́n tu ṣàpèjúwe olóògbé náà gẹ́gẹ́ bí òntajà àti aláfihàn fàbú lọ́nà ìbílẹ̀ ṣáájú kí ó tó ku látàrí àìsàn tí ó nííṣe pẹ̀lú kídìnrín ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kẹ́rin ọdún 2003
supo shasore ọláṣùpọ̀ sháṣore agbejoro agba ni orile-ede naijiria ọjọ́ ìbí - ọjọ́ kejì-lé-lógún oṣù kíní ọdún 1964 jẹ́ onimo nipa ofin ó jẹ okan lara awon oludasile ati alabaṣepọ ninu ile-iṣẹ ofin ti alp ofin ilu afirika o jẹ agbejoro agba ati alabojuto eka idajo ti ipinle eko lati ọdun 2007 titi odun 2011 shasore jẹ́ agbẹjọ́rò àgba~a ti nigeria san ati okan gboogi ninu egbe awon alagbawi ni orile ede naijiria oun ni alaga ana fun awon egbe alagbawi ati onilaja ti eka ofin okoowo ni eka awon amofin ni orile ede naijiria
sùpọ̀ shasore ọláṣùpọ̀ sháṣore agbejoro agba ni orile-ede naijiria ọjọ́ ìbí - ọjọ́ kejì-lé-lógún oṣù kíní ọdún 1964 jẹ́ onimo nipa ofin ó jẹ okan lara awon oludasile ati alabaṣepọ ninu ile-iṣẹ ofin ti alp ofin ilu afirika o jẹ agbejoro agba ati alabojuto eka idajo ti ipinle eko lati ọdun 2007 titi odun 2011 shasore jẹ́ agbẹjọ́rò àgba~a ti nigeria san ati okan gboogi ninu egbe awon alagbawi ni orile ede naijiria oun ni alaga ana fun awon egbe alagbawi ati onilaja ti eka ofin okoowo ni eka awon amofin ni orile ede naijiria
tọ́pẹ́ àlàbí
ty bello toyin ṣókẹ́fun-bello ọjọ́ ìbí - ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kíní ọdún 1978 tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí ty bello jẹ́ ọmọ orílè-ẹ̀dẹ̀ nàìjíríà akọrin ni a sì tún máa ṣe àgbékalẹ̀ orin fún àwọn ẹlòmíràn lá ti kọ́ ọ jáde ayàwòrán ni ó sì tún jẹ́ elẹ́yinjú àánú kí ó tó di àkókò tí ty bello bẹ̀rẹ̀ isẹ́ àdáṣe rẹ̀ ó ti wà pẹ̀lú ẹgbẹ́ olórin ẹ̀mí tí a n pè ní kush kí ẹgbẹ́ náà tó kó igbá wọlé ty bello jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àgbáríjọ àwọn olùyàwòrán ní orílè-èdè nàìjíríà tí a n pè ní depth of field ty bello di gbajúgbajà nípasẹ̀ àwọn orin àdákọ rẹ̀ tí ó ṣe bíi greenland ilẹ̀ ọlọ́ọ̀rá ẹkùndayọ̀ this man ọkùnrin yìí freedom òmìnira àti fúnmiṣe
iṣẹ́ iranṣẹ igbagbọ ihinrere kariaye the gospel faith mission international iṣẹ́ iranṣẹ igbagbọ ihinrere kariaye gofamint jẹ ọkan gboogi ninu awon elesin kristieni lati orilẹ-ede naijiria ti a ti ọwọ́ rubeni akinwalere george dá silẹ ni agbegbe iwaya ni adugbo yaba ni ilu eko ni ọdun 1956 iṣẹ́ iranṣẹ igbagbọ ihinrere kariaye ti ni ẹ̀ka kaakiri awọn orilẹ-ede ni agbaaye bi ni orilẹ-ede gẹẹsi lati ọdún 1983 àti ní ilu amẹrika lati ọdun 1985 iṣẹ́ iranṣẹ igbagbọ ihinrere kariaye gofamint tẹdo si ìlú ìhìnrere ni kilomita ogoji opopona marosẹ ti o ti eko wa si ibadan aṣeeṣe ipinlẹ ogun nigbati olu ile-iṣẹ iṣẹ́ iranṣẹ igbagbọ ihinrere kariaye wa ni gbongan ihinrere ọjọọ oju ọna ọyọ ibadan ipinlẹ ọyọ sugbọn laipẹ wọn o ma kó olu ile iṣẹ iṣẹ́ iranṣẹ igbagbọ ihinrere kariaye lọ si ogunmakin ti ipinlẹ ogun
gary ridgway gary leon ridgway ọjọ́ ìbí - ọjọ kejìdínlógún oṣù kejì ọdún1949 ẹnì tì á tún mọ sì green river killer jẹ apànìyàn tí òun pá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn pẹ̀lú bartani kàn ẹnì tí wọn tí tí mọ́lẹ̀ fún ẹ pànìyàn lè méjì dín là aadota ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti dunadura ẹ̀bẹ̀ rẹ à fi idajo míràn kún ìdájọ́ rẹ ní tí ó wà sọ ìdájọ́ rẹ lápapò sì ọkàn dín laadota ṣiṣe ni u ni apaniyan apania keji ti o ga julọ ni itan amẹrika ni ibamu si awọn ipaniyan timo timo o pa nọmba nla ti awọn ọmọdebinrin ati awọn ọdọ ni ilu washington ni awọn ọdun 1980 ati ọdun 1990
soji cole olusoji henry cole jé olùkọ́ àgbà ilé èkó kan ní nàìjíríà tí í şe ti kan yunifásitì t'ìlú ìbàdàn gbajú-gbajà akòtàn àti onkòwé ní ó jé pèlú ó jé olùgba èbun fún lítíréşo ní nàìjíríà t'odún 2018 àwọn agbègbè tàbí àfojúsùn ìwádìí rẹ dá l'órí i eré òun ìtójú u àwọn ìjìnlè ogbè àti ìwádìí iṣé àdáṣe ti àṣà ìwé e rè embers je òkan nínú u àwọn ìwé nàìjíríà tí ó dára jù lọ fún ọdún 2018 nínú u àkójọ ìwe ìròyìn àgbékèléojoojúmó dailytrust cole jé akẹ́kọ̀ọ́ jáde ilé ìwé gíga ti yunifásitì ìbàdàn university of ibadan ó tún jé ẹlégbé àbèwò ní ilé èkó gíga ti roehampton cole ṣo fún dailytrust pé kíkọ àwọn ìtàn kúkúrú ni bí òun ṣe ní ìkéde àkókó ọ rè nígbà tí ó ń s'òrò l'órí i àwọn ìtaláyà tí àwọn onkòwé tí ó ṣé yọ ní orílè èdè nàìjíríà ó s'ọ̀rọ̀ àwọn ìdíwó ìnáwó àti ìdínkù àwon olùgbé ìlú bí i àwọn okùnfà tí ń dín awon awakò ìmòwé kù l'óríle èdè ná à ó tún ṣ'àlàyé bí iná ṣe jé ìpèníjà ń lá l'ákòókò tó ńko àwọn ìwé àkọólè rè nínú u ìfòròwánilénuwò pèlú ìwé ìròyìn oòrùn the sun cole rántí pé òun béèrè ìwé kíkọ l'ákòkóò tí òun wà ní ilé ìwè alákòóbèrè láti ta yo láàárín in àwọn ojúgbé e rè ó tún sọ àsọtélè bí i òdó kékeré mi ṣe di ìwé ìtàn àtèjáde àkókó rẹ ó ṣe àtèjáde eré àkókó ọ rè bóyá ní òla 2014 ìtàn tí ó dá l'órí i ipò tí àwọn ènìyàn niger delta wà ìwé ná à ní atokọ fún ìgbà pípé l'énu gbígba ìwé àṣẹ l'órílè èdè nàìjíríà l'ódún un 2014 l'éhìn-ò-r'ẹhìn ó padà gba àmì èrí àpéjo àwon onkòtàn association of authors ana ti nàìjíríà ní oṣù kẹwàá oṣù òwàrà ọdún 2018 íwé e cole mìíràn embers f'arahàn gégè bíi èyí tó dára jùlọ nínú u àwọn òkàndínláàdórùn- ún89 tí a şe àfihàn won fún pípéye tó sì jo'jú fún ìwé lílò ní 2018 ìwé náà dá l'órí i ipa tí ìwà ipá àti ìkolù ti èsìn ń kó l'órí i ìbágbépò àwọn ènìyàn ní àríwá nàìjíríà yàyò sí àwọn àmì èyẹ tí ó wà ní ìsàlè cole ti ní atokọ fun wolé şóyínká prize fún lítíréşo ní áfíríkà àti ìdíje ìfigagbága iṣé kíkọ bbc world
steve babaeko steve babaeko tí a bí ní june 1 1971 kaduna jẹ́ ọmọ orílé-èdè nìgérìa ó jẹ́ ọ̀gá awọ́n onípolówó àgbejoro oludasile ti x3m ideas ajo onipolowo ni ilu eko ti o je ọkan ninu awọn ajo ibaraẹnisọrọ to n gbajumo ni orile-ede nigeria ni odun 2017 o tun jẹ oludasile/alakoso x3m music ajo olorin to ni simi akọrin-olukorin kan ni nigeria gege bi akorin agba laarin awọn miiran o wa lori igbimo adajo 2018 ti ayẹyẹ ipolowo ti new york itan igbesiaye ati iṣẹ babaeko lọ si ile-ẹkọ federal arts of arts and science ni suleja ni ipinle niger fun a-level rẹ ati ile-iwe ahmadu bello zaria fun oye akọkọ rẹ ni theatre arts sugbon o sọ pe nigbagbogbo fẹ lati wa ni ipolowo o ṣe dandan ti iṣẹ iṣẹ ọdọmọde ti orilẹ-ede nysc ni nta kaduna
abẹli ìdòwú ọlayinka abẹli idowu ọlayinka fas ti a bi ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù èrèlé 1958 jẹ́ ọmọ orílẹ̀èdè nàìjíríà ọ̀jọ̀gbọ́n applied geophysics ó ti fi ìgbà kan jẹ́ igbákejì gíwá àti gíwá yunifásítì ìbàdàn bákan náà ni ó jẹ́ ààrẹ ẹgbẹ́ ìṣàkóso ìwádìí àti ọ̀tun-ìmọ apá ìwọ̀ - oòrùn áfíríkà ní 2012 wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ nigerian academy of science ajọ́ alákadá tí ó ga jù lọ ní nàìjíríà òun àti ọ̀jọ̀gbọ́n isaac folorunso adewole tí ó jẹ́ gíwá kọkànlá tí yunifásítì ìbàdàn ni wọ́n fi mọlé sínú àjọ náà ọ̀jọ̀gbọ́n mojeed olayide abass ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ sáyẹ̀nsì ẹ̀rọ ayára-bí-àṣá tí yunifásítì àpapọ̀ tí ìlú èkó àti ọ̀jọ̀gbọ́n akinyinka omigbodun ààrẹ kọ́lẹ́jì àwọn oníṣẹ́-abẹ́ apá ìwọ̀ oòrùn áfíríkà àti olùdarí kọ́lẹ́jì ìṣègùn òyìnbó yunifásítì ti ìbàdàn ní oṣù òwàrà ọdún 2015 wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí gíwá iléẹ̀kọ́ yunifásítì ìbàdàn nígbà tí ọ̀jọ̀gbọ́n isaac folorunso parí sáà tirẹ ní oṣù bélú 2015 ọ̀jọ̀gbọ́n olayinka parí sáà tirẹ̀ ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù bélú ọdún 2020 tí ọ̀jọ̀gbọ́n adébọ́lá babátúndé ẹ̀kànọlá sí gba ọ̀pá àṣẹ ìṣàkóso ẹ̀kọ́ wọn bí ọ̀jọ̀gbọ́n olayinka ni ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù ẹ̀rẹnà oṣù 1958 ní odò-ìjẹ̀sà ìlú kan ní ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ó bẹ̀rẹ̀ iléẹ̀kọ́ rẹ̀ ní iléẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ bartholomeow ní odò-ìjẹ̀sà ó lọ sí iléẹ̀kọ́ gírámà iléṣà níbi tí ó ti ṣe wasc ní ọdún 1975 ó gba oyè ba nínú imọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ilẹ̀geology ní yunifásítì ti ìbàdàn nígbà tí ó ṣe tán bíi àgùnbánirọ̀ ní ẹ̀ka hydrogeology àti hydrology tí ẹ̀ká ní ọdún 1982 ó ṣiṣẹ́ ráńpẹ́ ní deptol consultants gẹ́gẹ́ bí onimọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ilẹ̀ kí ó tó lọ sí yunifásítì london ó gba oyè master's ní geophysics ní 1984 ọdún yìí náà ni ó gba dípúlómà tí kọ́lẹ́jì imperial ní oṣù agẹmọ ọdún 1984 kí ó tó di pé ó gba àmì-ẹ̀yẹ ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tí ó sọ di ọ̀mọwé nínú imọ̀ geophysics ní yunifásítì birn ní oṣù igbe 1997 ó lọ ṣe iṣẹ́ ìwádìí ní yunifásítì technical braunschweig láti ìgbà tí ó ti gba oyè ọ̀jọ̀gbọ́n ó ti mójútó ọ̀gọ̀rọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ akẹ́kọ̀ọ́ master's mẹ́rìndínlààdọ́rin àti akẹ́kọ̀ọ́ fún oyè ọ̀mọwé mẹ́sàn-àn ó ti gbé iṣẹ́ àpilẹ̀kọ ó lé àádọ́ta jáde ní àwọn jọ́nà akadá tó lókìkí
chelsea fc ikọ̀ bọọlu aláfẹsẹ̀gbá chelsea jẹ ile-iṣẹ bọọlu alamọde gẹẹsi kan ti a da ni ọdun 1905 wọn n dije ni premier league ipin kìńní ti bọọlu gẹẹsi chelsea wa laarin awọn ẹgbẹ tí ó ṣe àṣeyọrí jùlọ ni ìlú england wọn ti bori ọgbọn idije tí premier league pẹlu awọn akọle oke-oke mẹfa ife fa mẹ̀jọ ife uefa europa méjì ife uefa cup winners méjì ife uefa champions league ẹyọ kan ati uefa super cup ẹyọ kan ile ilẹ wọn ni stamford bridge ni fulham ni ìlú london
pornhub pornhub jẹ́ ìtàkùn orí ẹ̀rọ-ayélujára fún fọ́nrán ìwòkuwò lóríṣiríṣi èyí tó jẹ́ tí ìlú canada ọkàn lára àwọn ìtàkùn ayélujára náà tó gbajúmọ̀ ni ti eré-ìdárayá àwọn àgbàlagbà ti aylo ítí di 2023 update pornhub jẹ́ ìtàkùn ayélujára ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá tí àwọn ènìyàn ń wò jù lọ ní àgbáyé òun sì ni ẹlẹ́ẹ̀kejì tí àwọn àgbàlagbà máa ń wò jù lọ lẹ́yìn xvideos ìtakùn yìí gba àwọn àlejò láàyè láti wo fọ́nrán ìwòkuwò lóríṣiríṣi láti oríṣiríṣi ìpele ó sì tún gbani láàyè láti fi fọ́nrán tirẹ̀ sí orí ìtakùn náà níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti bá òfin wọn mu wọ́n sì tún máa ń ṣe ìgbà àmì-ẹ̀yẹ lọ́dọọdún ní oṣù kejìlá ọdún 2020 lẹ́yìn tí the new york times tú àṣírí àwọn kan tí wọ́n ń nípìn-ín nínú ìfipábánilò àti ìṣenibáṣubàṣu àwọn ẹ̀rọ ìsanwó bíi mastercard àti visa yọ ọwọ́ wọn kúrò nínú gbogbo nǹkan tó jẹ́ ti pornhub èyí sì mú kí pornhub yọ àwọn fọ́nrán tí ò bá òfin wọn mu èyí sì mú kí àwọn fọ́nrán náà díkù láti mílíọ̀nù mẹ́tàlá 13million wọ mílíọ̀nù mẹ́rin 4million ètò kan ní ọdún 2023 tí wọ́n pè ní money shot the pornhub story ṣàfihàn ìdojúkọ wọn àti àríwísí àwọn tó ń ṣe àwọn fọ́nrán ìwòkuwò yìí ìtàn wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ pornhub ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2007 láti ọwọ́ matt keezer gẹ́gẹ́ bíi ìtàkùn ayélujára láàrin ilé-iṣẹ́ interhub ní oṣù kẹta ọdún 2010 fabian thylmann ra ilé-iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bíi àfikún sí manwin conglomerate tí ó ti wá di aylo báyìí ní ọdún 2013 thylmann ta ìpín rẹ̀ fún feras antoon àti david tassillo tó ṣiṣẹ́ títí wọ ọdún 2022 gẹ́gẹ́ bíi ceo àti coo látàrí ìgbìyànjú láti ṣe ìdásílẹ̀ fọ́nrán tó pé dáadáa ilé-iṣẹ́ náà ṣe ìdásílẹ̀ ètò kan tí wọ́n pè ní pornhub select ní oṣù kẹwàá ọdún 2013 pornhub tún ṣe ìdásílẹ̀ ètò kan ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹwàá ọdún 2013 tí wọ́n pè ní porniq èyí tó ń lo ìmọ̀ ẹ̀rọ láti ṣàtòjọ oríṣiríṣi fọ́nrán fún àwọn òǹwòran ní ìbámu pẹ̀lú àwọn fọ́nrán tí wọ́n ti wò sẹ́yìn àti àsìkò tí wọ́n ń wo àwọn fọ́nrán náà ní ọdún 2009 ìtàkùn ayélujára ti àwọn fọ́nrán ìwòkuwò mẹ́ta tó tóbi jù lọ ìyẹn redtube youporn àti pornhub ní tó àlejò mílíọ̀nù ọgọ́rùn-ún 100 million ní oṣù kẹfà ọdún 2015 pornhub ṣe ìkéde pé wọ́n máa ṣàgbéjáde fíìmù àgbéléwò tó dá lórí ìwòkuwò tí wọ́n sì máa pè ní sexplorations èròǹgbà wọn ni láti bẹ̀rẹ̀ ìyafọ́nrán fíìmù náà ní ọdún 2016 tí wọ́n sì máa gbọ́ gbogbo owó tí wọ́n nílò àmọ́ wọ́n máa tọrọ 34 million láti ọwọ́ indiegogo crowdfunders tí wọ́n bá rí owó náà gbà fíìmù náà máa jáde ní ọdún 2016 ní ọjọ́ kìíní oṣù kejì ọdún 2016 pornhub ṣe ìdásílẹ̀ ètò onítẹ́tẹ́ lórí ẹ̀rọ-ayélujára èyí tí betsoft endorphina àti 1x2 gaming jẹ́ onígbọ̀ọ́wọ́ rẹ̀ ní oṣù kẹwàá ọdún 2017 igbá kejì ààrẹ ìyẹn corey price ṣe ìkéde pé pornhub máa lo ìmọ̀-ẹ̀rọ láti ṣàwárí fọ́nrán lórí ẹ̀rọ náà tí ó sì máa fúnni ní ìròyìn nípa fọ́nrán àti àwọn ọ̀ṣèré inú fọ́nrán náà ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹrin ọdún 2018 ìtàkùn pornhub bẹ̀rẹ̀ sí ní gba crypto currency gẹ́gẹ́ bíi ọkàn lára àwọn ọ̀nà láti san owó ní oṣù kejìlá ọdún 2020 lẹ́yìn ìròyìn kan ní the new york times láti ọwọ́ nicholas kristof mú kí mastercard àti visa yọ ọwọ́ wọn cut their services to pornhub pornhub then removed all videos by unverified users
isaac florunso adewole isaac folorunso adewole fas ti a bi ni ojo karun oṣu karun ni ọdun 1954 je ọjọgbọn kan ni orilẹ-ede naijiria ti o mo nipa igbebi ati ilera obinrin o jẹ minisita ilera ni orilẹ-ede nigeria tẹlẹ lati oṣu kọkanla ọdun 2015 - may 2019 igbimọ alakoso muhammadu buhari o jẹ oga agba olori ile-ẹkọ giga unifasiti ti ile ibadan ati alaga fun igbimo iwadi ati ikẹkọ arun jejere ni ile adu lawo ṣaaju si iyan sipo re gege bi elekonkanla oluko agba ti ile eko giga unifasiti ile ibadan o ti je oga agba ati oludari ile ikekoo gboye nipa eto imo isegun unifasiti ile ibadan- eleyi to je ile to tobi julo ati agba ni ni ile naijiria agbegbe iwadii re ni imo nipa papillomavirus ninu eniyan aarun kogboogun ati gynaecologic onkoloji agbegbe kan ninu imo eto isegun ti o n risi aarun jẹjẹrẹ awon eya ara obinrin ati arun jẹjẹrẹ ile omo obinrin pẹlu uterine akàn jejere abẹ obinrin jejere oju ara obinrin ati vulvar canser adewole jẹ ọmọ ẹgbẹ igbimọ ti o n dari ile-ẹkọ giga adeleke ati alaga igbimọ orilẹ-ede lori eto iṣakoso ati idina arun jejere enu ile-omo obinrin oun nikan ni ọjọgbọn ti orilẹ-ede naijiria ti a yan gege bi ọmọ ẹgbẹ igbimọ awon ile eko giga ti commonwealth won yan lati ṣiṣẹ bi ọmọ ẹgbẹ ti ajọ igbimọ imọran ti o n risi arun jejere ni ile adu-lawo ile-iṣẹ ti mo nipa arun jẹjẹrẹ ti ila iwo oorun ile adu lawo ni ọdun 2014 o ṣe ayẹyẹ ọjọ-ibi ogota odun rẹ nibi eto idanileko gbogbgboo ti o waye ni ile ikojo kariaye ti ile-ẹkọ ibadan ni a tun ranti bi awọn olutọpa ṣe gbiyanju aigbagbọ lati baje ipade rẹ gẹgẹ bi igbakeji alase ti ile-ẹkọ naa ni ọdun 2010 alaga ti ayeye ọjọ-ibi ọdun 60 ni wole olanipekun onimọran t’olofin oga agba ti naijiria alakoso iṣaaju ti ẹgbẹ ile - igbimọ naijiria ati pro-chancellor giga ti ile-ẹkọ giga tẹlẹ o ṣe apejuwe adewole bi “o nran kii ṣe nikan pẹlu awọn ẹsan mẹsan ṣugbọn ọkan pẹlu awọn ọdun 18 ẹniti o daamu gbogbo awọn idena ati awọn iwe itẹwọgba lilu si nipasẹ awọn olukọni rẹ” ni ọdun 2012 o dibo gẹgẹbi ẹgbẹ ti ile ẹkọ ijinlẹ ti ilu naijiria agbari ẹkọ ẹkọ apex ni nigeria o si ti a wọ inu ọmọ ile-ẹkọ naa pẹlu ọjọgbọn mojeed olayide abass olukọ ọjọgbọn ti imọ-ẹrọ kọnputa ti ọmọ ile- ẹkọ giga ni yunifasiti ti eko ati ọjọgbọn akinyinka omigbodun alakoso ile -ẹkọ giga ti iwọ-oorun ti ile- iwosan iwọ-oorun ati provost ti ile-iwe oogun university of ibadan
mahmood yakubu mahmood yakubu jẹ́ ọ̀mọ̀wé orí̀lẹ-è̀dè nàíjírìa àti alága ti ìgbìmọ̀ àjọ elétò ìd̀ibò nàìjíríàindependent national electoral commission-inec ààrẹ orílẹ̀-èdè nàíjíría muhammadu buhari ni ó yan mahmood yakubu sí ipò alága ètò ìdìbòinec pẹ̀lú ìfọwọsí ilé ìgbìmọ̀ asòfin ní ọjọ́ kọkànlé lógún oṣù kẹ̀wá ọdún 2015 òun ni ó gba ipò náà lọ́wọ́ amina zakari ẹni tí ó jẹ́ alága àdilémú fún àjọ ìdìbò inec lẹ́yìn tí attahiru jega fi ipò náà kalẹ̀ igbesi aye ati eto-eko mahmood yakubu je omo bibi ipinle bauchi ni apa oke oya orile ede naijiria o lo si ile iwe alakobeere kobi ati ile eko ti awon olukoni ijoba tii toro ni sisentele ipinle bauchi northern nigeria o te siwaju ninu eto eko re lo si unifaasiti sokoto ti an pe ni usmanu danfodiyo unifaasiti nibiti o ti je eni akoko ti o tayo pelu iwe eri ninu imo itan lati apa arewa oke oya titi di asiko yii o lọ si ile-ẹkọ giga ti ile-ẹkọ giga ti ilu-ẹkọ ti ilu sokoto ti isiyi usmanu danfodiyo university nibiti o ti di akọkọ ati titi di oni ọmọ naijiria nikan lati ariwa lati gba iwe - ẹri ile-iwe akọkọ ni itan-akọọlẹ ni ipele ipo ile-iwe lẹhin o kẹkọ awọn ibatan kariaye ni ile-ẹkọ wolfson cambridge yanju pẹlu alefa ọga ni ọdun 1987 ati itan-akọọlẹ naijiria ni university of oxford ti o yan iwe-ẹkọ pẹlu doctorate ni ọdun 1991 ijoba ipinle bauchi funni ni sikolashipu kan lati kọwe ni university of cambridge ati ile-ẹkọ giga oxford o tẹsiwaju lati di olugba mẹta-akoko ti sikolashipu iwadi kọja o tun ṣẹgun sikolashipu agbaye lati ọdọ ẹgbẹ ti awọn ile-ẹkọ giga ti agbaye
lateef adegbite lateef adegbite ọjọ́ ìbí ogúnjọ́ oṣù kẹta ọdún 1933 o si di oloogbe ni ọjọ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsan ọdun 2012 nígbà ayé rẹ ó jẹ́ agbejọ́rò kan tí ó di attorney gbogboogbo attorney general ti apá ìwọ̀ oorun ilẹ̀ nàìjíríà western region of nigeria ki o to wa di akọ̀wé gbogboogbo ti ìgbìmọ̀ gíga fún àmójútó ọ̀rọ̀ islam ní nàìjíríà ìbí àti ètò-ẹ̀kọ́ abdul-lateef oladimeji adegbitẹ ni a bi ni ogúnjọ́ oṣù kẹta ọdún 1933 sínú ẹbí mùsùlùmí ẹ̀gbá ti o múná ní ìlú abẹ́òkúta ìpínlẹ̀ ògùn gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ kan ó lọ sí ilé-ìwé methodist abeokuta sùgbọ́n ó sọ fúnrararẹ̀ pé ò ún kọ́kọ́ lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ arabiki lẹhinna ni o un wọ ilé-ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ ti paulu mímọ́ st paul ní ìgbórè abẹ́òkúta ní ọdún 1942 nígbàtí adegbitẹ di ọmọ ọdún mẹsan ní ó gba ìwè-ẹ̀kọ́ sikolashipu láti lọ sí ilé-ìwé gíga ti ọba king's college ní èkó níbití o ti jẹ́ ọ̀kanlára àjọ olùdásílẹ̀ àti àarẹ orílẹ̀ àkọ́kọ́ fún àwùjọ akọ́ ẹ̀kọ́ mùsùlùmí ti orílẹ̀ èdè naijiria muslim students society of nigeria ó parí ilé-ẹ̀kọ́ ní ọdún 1956 ní ọdún 1959 asájú ẹkún ti ìwọ̀ oorun ni nàìjíríà oloye obafẹmi awolowọ fún adegbitẹ ni sikolashipu kan láti rin ìrìn-àjò lọ sí ìlú gẹ̀ẹ́sì lat́i lọ kọ́ ẹ̀kọ́ gboyè nípa òfin lábẹ́ èrò tí olóyè fra williams là kalẹ̀ adegbitẹ lọ sí yunifásítì ti southhampton ó sì kàwé gboyè lórí ìmọ̀ òfin ní oṣù keje ọdún 1962 lẹhinna ó kàwé ní ilé-ìwé gíga ti òfin fún àwọn asojú lancaster gate ní ìlú london àti lẹhinna ni grey's inn 1963-1965 ó tún gba sikolashipu ti commonwealth fún ìkẹ́kọ̀ gboyè oní pele kejì ní ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ olùkọ́ ìmọ̀ òfin ní yunifásítì ìlú èkó tí ó sì di ipò yí mú títí tí o fi lọ́ da iṣẹ́ àdáni tirẹ̀ sílẹ̀ nínú oṣù kẹsan ọdún 1976 iṣẹ́ ní ọdún 1971 wọ́n yan adegbitẹ gẹ́gẹ́ bi koomisoanna fún ìjọba agbègbè àti ti ọ̀rọ̀ oyè ní ẹkùn ìwọ oorun ti naijiria lakoko ìjọba ológun ti ọ̀gágun christopher oluwọle rotimi lehinna wọ́n tún yan an gẹ́gẹ́ bi koomisoanna fún ìdájọ́ àti attorney-gbogboogbo tí ẹkùn ìwọ̀ oorun ní ọdún 1973 ní oṣù kẹwà ọdún 1976 ó ṣe ìdásílẹ̀ àjọ ilé-iṣẹ́ òfin ti lateef adegbitẹ tí ò un fúnrarẹ̀ si jẹ olórí alájọṣepọ̀ èyí tí ọ́fíìsì àkọ́kọ́ wọn wa ní èkó àti ẹ̀ka kan ní abẹ́òkúta òfin òwò àti àjọ commercial and corporate law ní o jẹ́ pàtàkì iṣẹ́ wọn ẹ̀ka ófíìsì ti abẹ́òkúta wa ni àgọ́-ọ̀bà adegbitẹ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n dá ẹgbẹ́ amuludun ti abẹ́òkúta sílẹ̀ ní ọdún 1972 adegbitẹ jẹ́ ààrẹ ìgbìmọ̀ ti olympic ti ilẹ̀ naijiria nigeria olympic committee láti ọdún 1972 sí ọdún 1985 ó jẹ́ olórí-asíwájú àti alága ti ìgbìmọ̀ ìṣàkóso yunifásítì ilu maiduguri láti ọdún 1984 sí ọdún 1990 ó di ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìgbìmọ̀ okoowo ti ìpínlẹ̀ èkó lehinna ó di ọ̀gá àgbà ti iṣẹ́ àti ìṣèdúró wọ́n fi oyè alakoso tí ó ga jùlọ ní ilẹ̀ naijiria commander of the order of the niger con dá adegbitẹ lọ́lá ó tún jẹ àwọn oyè ìbílẹ̀ bi i séríkí ti ilẹ̀ ẹ̀gbá àti bàbá àdínì ti musulumi ẹ̀gbá ní ọjọ́ kẹsan oṣù kẹta ọdún 2011 aarẹ goodluck jonathan yan an gẹ́gẹ́ bi alága ìgbìmọ̀ lórí àkọsílẹ̀ ìmọ̀ lórí aàbò àti ojuṣe abẹ́lé chairman presidential committee on public awareness on security and civic responsibilities dọ́kítà lateef adegbitẹ jẹ́ arákùnrin si olóògbé olókìkí àti ògbóǹtarìgì akọìtàn ọ̀jọ̀gbọ́n saburi biobaku 1918-2001 ẹni tí o tí jẹ gíwá yunifásítì ti èkó tẹ́lẹ̀ olórí mùsùlùmí ní ìjọ constituent ní ọdún1976 adegbitẹ jiyàn nípasẹ̀ ojúrere pé ki wọ́n ṣe agbékalẹ̀ ilé ẹjọ́ àpètúnpè tí islam sí àwọn ìpínlẹ̀ tí ó wà ní guusu ilẹ̀ naijiria ó sọ wípé àwọn musulumi ní ètò láti pe ki a ṣe ìdájọ́ won ní ìbámu sí òfin sharia o se e ní àlàyé pé àwọn musulumi kò ní òfin àti ìlànà òmíràn yàtọ̀ sí èyí tí sharia ti gbé kalẹ̀ sharia gẹ́gẹ́ bí òfin mímọ́ yọrí ju gbogbo òfin ìlú àti ti ìhùwàsí lọadegbitẹ fẹ́ ṣe àtìlẹ́hìn fún akitiyan mko abiọla láti ṣe agbékalẹ̀ sharia sí àwọn ìpínlẹ̀ guusu ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990 ó tún fi ipò yíí múlẹ̀ ní oṣù kejìlá ọdún 2002 ní àkókò aríyànjiyàn tí ó gbooro ní àárín àwọn kristiani àti àwọn musulumi adegbitẹ jẹ́ alága ìgbìmọ̀ àwọn arìnrìn ajo mímọ́ ní ìpínlẹ̀ ògùn ati ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ àwọn arìnrìn ajo ti orílẹ̀ nígbàtí ibrahim dasuki di sultan ti sokoto ní ọdún 1988 àti aare-gbogboogbo fún ìgbìmọ̀ gíga ti naijiria fún ọ̀rọ̀ islam ni naijiria nscia adegbitẹ ni wọ́n yàn gẹ́gẹ́ bi akọ̀wé-gbogboogbo fún ìgbìmọ̀ naa lábẹ́ àkóso adegbitẹ àti dasuki ni nscia èyí tí wọ́n fi ìdí rẹ múlẹ̀ ní ọdún 1974 di èyí tí o tun bo n ṣe iṣẹ́ pẹ̀lú ìtara ní ìparí ọdún 2002 àti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2003 adegbitẹ ṣe àríyànjiyàn ti gbogbo ènìyàn pẹ̀lú onkowe gba ẹ̀bùn nobel wọle ṣoyinka ẹni tí ó fi ẹ̀sùn kan àwọn olùdarí musulumi pe wọ́n ru ìwà-ipá sókè lẹ́hìn rúdurùdu tí ó ṣẹlẹ̀ ní ìlu kàdúná ti o mu ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí ṣòfò ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tẹ̀ yí ni àtakò ti o wáyé láti ọ̀dọ̀ àwọn musulumi pe ki wọ̀n ṣe ìdádúró ìdíje arẹwà ọ̀dọ́bìnrin àgbáyé miss world ní naijiria rògbòdìyàn yi tún bọ̀ gbèrú si nítorí o un tí àwọn musulumi kà sí gẹ́gẹ́ bi gbólóhùn òdì ni ìròyìn tì oníròyìn isioma daniel kọ sínú ìwé ìròyìn ti kristiani kan pe ti o ba jẹ wípé woli bá lọ sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ arẹwà ọ̀dọ́bìnrin àgbáyé yi ni kò bá ti mú ọ̀kan nínú àwọn olùdíje yi fi ṣe ìyàwó lehinna ni wọ́n sọ wípé igbákejì gómìnà ti ìpínlẹ̀ zamfara mamauda aliyu shinkafi sọ ọ̀rọ̀ gbangba pé ó lè jẹ́ òfin fún musulumi láti ta ẹ̀jẹ isioma daniel sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni adegbitẹ ti lòdì sí ọ̀rọ̀ yí ó ní níwọ̀n ìgbàtí akọìròyìn yí kii ṣe musulumi àti wípé ìwé ìròyìn yí ti tọrọ gáfárà ní gbangba adegbitẹ sọ nínú ìwé ìròyìn ti oṣù kẹwa ọdún 2003 pé tí wọ́n ba le yi ilẹ̀ amẹ́ríkà àti àwọn alájọṣepọ̀ rẹ lọ́kàn padà láti gbà pé gbogbo ìpayà tí o nmulẹ kákàkiri àgbáyé yí ò dínkù tí ìdájọ́ òdodo bá lè fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní àárín ìla-oorun ẹ fún àwọn ará palestini ní ilẹ̀ wọn padà ko si ni si àyè fún osama bin ladens tí ayé yi láti gbérí láì sí ìdajọ òdodo ko le si alaafia nígbàtí unesco ṣe ètò àpérò lórí ọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀sìn ní àbújá ní oṣù kejìlá ọdún 2003 wọ́n pe adégbìtẹ́ láti sọ̀rọ̀ lórí ipa tí àwọn olùdarí ẹ̀sìn ńkó láti dẹ́kun rògbòdìyàn ikú rẹ̀ dọ́kítà adegbitẹ kú sí ìlú èkó ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsan ọdún 2012
roger scruton roger scruton je is a englishamoye to gbajumo pataki fun ipa re si imoye aesthetics sugbon to tun gbajumo fun ise re lori oloselu ohun ni elegbe iwadi agba ni gbangan awon eko kant ati wittgenstein
swásílándì
ààrẹ ilẹ̀ índíà president of india denotes vice-president acting as president
oluremi sonaiya olúrẹ̀mí comfort sónáìyà a bi ní ọjọ́ kejì osù keta odún 1955 ó jẹ olóṣèlú kan gbòógì ní orílè-èdè nàíjírìa ọ̀mọ̀wé àti ònkọ̀wé ni òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó díje fún igbákejì olòrí orílẹ̀-èdè nàíjírìa ní abẹ́ àsìá ẹgbẹ́ kówà ní ọdún 2015 ó fìdí rẹmi ní ọdún 2019 tí ó tún jáde gẹ́gẹ́ bíi aṣojú ẹgbẹ́ náà tí dókítà adésínà fágbénró byron sì gbégbá orókè ìgbésí ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ sónáìyà jẹ ọmọ bíbí ìlú ìbàdàn olú-ìlú ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀ alápéjúwe sẹnti lukes mòlété ìbàdàn àti ilé ẹ̀kọ́ girama sẹnti annes mòlété́ bakaánà ní ìlu ìbàdàn ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga ní ilé ifè tí à ńpè ní obáfémi awólọ́wọ̀ unifásítì báyìí níbi tí ó ti kẹ́kòó èdè faransé o parí ní ọdún 1977 ó gba másításì ti art nínú lítírésọ̀ faransé ní unifásítì cornell ní amẹ́ríkà àti masításì ní lìngúísítíkì ní unifásítì nàìjíríà ní ọdùn 1984 ó padà sí cornell ní ọdún 1988 láti lépa ètò ẹkọ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú lìngúísítíkì ètò isẹ́ ní ọdún 1982 wọ́n gbàá síṣé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ọbáfẹ́mi awólọ́wọ̀ gẹ́gẹ́ bíi igbákejì olùkọ́ ní abala àwọn tí ó ń mójú tó ètò ẹ̀kọ́ èdè àjèjì ó padà di ọ̀jọ̀gbọ́n nínú èdé faransé àti lìngùísítíkì ní ọdún 2004 ó jẹ́ ọ̀kan nínú awọn ọmọ ẹgbẹ alexander von humboldt foundation níbití wọ́n ti sọ ọ́ di ambassador àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì láti 2008 sí 2014 ní ọdún 2010 ó fẹ̀yìn tì kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ní obáfẹ́mi awólọ́wọ̀ unifásitì ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsèlú kówà wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bíi alukoro ẹgbẹ́ wọ́n sì tún fàá kalè ní ọdún 2015 gẹ́gẹ́ bií olùdíje fún igbákeji olórí orílẹ̀ èdè lábẹ́ ẹgbẹ́ náà sónáìyà se ipò kej̀ilá níbi ìdìbo pè|lú ìbò mẹ́rin dín lọgọrin lé lẹ́ gbẹ̀rún mẹ́tàlá àwọn àtẹ̀jáde sónáìyà ní abala tí ó ń siṣẹ́ le lóri nínú ìwé ìròyìn ayélu já́ra nàij́íria sónáíya tí ṣe atèjade opolopo iwe pèlú ọkọ rẹ̀ ni babafúnsọ́ sónáìyà ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ sáyẹ́nsì ẹranko won bí ọmọkùnrin kan àti obìnrin kan àti àwọn ọmọ-ọmọ
yorùbá academy àjọ yorùbá academy ni àjọ tí ó kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpele ékọ́ àti àkójọpọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ òṣèlú okòwò àti àwọn onímọ̀ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa èdè yorùbá àṣà ètò ọrọ̀-ajé ofin sáyẹ́nsì àti ìmọ̀ tẹkinọ́lọ́jì àti ìmọ̀ ètò ìṣèjọba wọ́n dá àjọ yí sílẹ̀ ní ìlú ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ní oṣù kẹ́wàá ọdún 2007 lẹ́yìn tí àwọn ọ̀dọ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nínú àwọn ìmọ̀ tí a ti mẹ́nu bà pinu láti padà sórílẹ̀-èdè baba wọn tí ẹgbẹ́ afẹ́nifẹ́re renewer group ń ṣàkóso rẹ̀ ohun tí ó jẹ́ ìlépa wọ́n ni láti dá àbò àti láti tọ́jú èdè yorùbá pàá pàá jùlọ àṣà àwùjọ àti ìdàgbàsókè àwọn ọmọ yorùbá nílé àti loke okun nínú ìlépa wọn ni kí wón ma ṣe àkóso iwe atúmọ̀ èdè yorùbá láti lè fi ẹsẹ̀ èdè yorùbá múlẹ̀ láàrín èdè tó kú lágbàáyé ibi tí àwọn ọmọ yorùbá wà ilẹ̀ adúláwọ̀ in togo benin sierra leone àti apá kan nílẹ̀ ghana ibi tí àwọn ọmọ yorùbá wà yàtọ̀ sí ilẹ̀ adúláwọ̀ ní haiti cuba puerto rico brazil united states uk ireland
makoto hasebe makoto hasebe 18/1/84 jẹ́ agbá bọ́ọ̀ orí ọ̀dàn ọmọ orẹ̀-èdè japan
festus keyamo festus keyamo tí a bí ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kíní ọdún 1970 jẹ́ agbẹjọ́rò àti alágbàwí àgbà san ọmọ ilẹ̀ naijiria alátakò àti alámùṣẹ ẹ̀tọ́ ẹ̀dá ènìyàn ní oṣù keje ọdún 2017 ì̀gbì̀mọ̀ tí ó ní anfaani sí iṣẹ́ òfin ti ilẹ̀ naijiria legal practitioner privilege committee dárúkọ keyamo gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò ọmọ ilẹ̀ naijiria tí ó dáyàtọ̀ láti fún ní ipò san bayi festus wà lára mínísítà muhammadu buhari keyamo àti àwọn miiran tí wọ́n dárúkọ nínú àkójọpọ̀ orúko fún ipò san ní ọdún 2017 ni wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ wọn sinu àjùmọ̀ṣe gíga ti àwọn alágbàwí àgbà naijiria san ní oṣù kẹsan ọdún 2017 ní ọdún 2017 bakanna ìgbìmọ̀ alákòso àgbáyé ti america tí ó wà ní washington tún fún keyamo ní àmì ẹ̀yẹ ẹ̀tọ́ ẹ̀dá ènìyàn ti àgbáyé fún àwọn akitiyan rẹ̀ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn lórí ti ìdáábòbò àti ìgbéga ti ẹ̀tọ́ ẹ̀dá ènìyàn àti ipolongo fún ìjọba naijiria tí yíò ṣe ìsírò iṣẹ́ rẹ ní oṣù kẹrin ọdún 2018 wọ́n yan keyamo gẹ́gẹ́ bí olùdarí fún ìbáráẹnisọ̀rọ̀ agbẹnusọ òṣìṣẹ́ fún àtúnyàn sípò ìbò ọdún 2019 ti aarẹ orílẹ̀ èdè naijiria igba ewe a bí festus kayamo ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kíní ọdún 1970 ní ughelli ìlú kan ní ìpínlẹ̀ delta ní guusu naijiria ṣùgbọ́n baba rẹ wá láti effurun ìlú kan ní ìpínlẹ̀ delta bakanna keyamo kọ́ ẹ̀kọ́ onípele kini rẹ ní ilé-ìwé alakobere ti model àti ẹ̀kọ́ onípele keji ní ilé-ìwé gíga ti ìjọba tí ó wà ní ughelli níbití ó ti gba ìwé ẹ̀rí oniwe mẹwa west african school certificate ní ọdún 1986 lehinna ó lo sí yunifásítì ambrose alli tí ó wà ní ekpoma ní ìpínlẹ̀ ẹdó guusu naijiria níbití ó ti gba oyè àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ òfin ní ọdún 1992 ó sì gba ìpè sí pẹpẹ amọ̀fin ti orílẹ̀ èdè naijiria ní oṣù kejìlá ọdún 1993 ise ofin festus keyamo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òfin rẹ̀ ní ọdún 1993 ní ilé iṣẹ́ òfin ti gani fawehinmi tí ó wà ní ìpínlẹ̀ èkó guusu naijiria lẹ́hìn tí ó lo ọdún méjì ní ilé iṣẹ́ òfin ti gani fawehinmi ó kúrò níbẹ̀ láti lọ ṣe ìdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ òfin festus kayamo keyamo jẹ́ agbẹjọ́rò fún mujahid dokubo-asari ẹni tí ó jẹ́ olórí fún niger-delta peoples volunteer force nígbàtí wọ́n pee lẹ́jọ́ fún dídalẹ̀ ìlú ò un tún ni olórí agbẹjọ́rò fún ralph uwazuruke olórí fún ẹgbẹ́ ajàjàngbara láti jẹ́ kí ìdádúró ìpínlẹ̀ biafra wásí ìmúṣẹ massob nígbà ìpẹ̀jọ́ rẹ fún dídalẹ̀ ìlú keyamo tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò fún ikú bọla ige ńi ọdún 2008 ó gbé ìjọba àpapọ̀ ilẹ naijiria lọ sí ilé-ẹjọ́ lórí yíyàn àwọn olórí iṣẹ́ lọ́nà tó lòdì sí òfin ní ọdún 2017 arábìnrin stephanie otobo akọrin kan tí ó fi ìlú canada ṣe orísun fi ẹ̀sùn kan aposteli suleman johnson látipasẹ̀ festus keyamo ẹnití nṣe agbẹjọ́rò rẹ pé aposteli suleman kùnnà láti mú ìlérí ìgbéyàwó tí ó ṣe pẹ̀lú òun ṣẹ lẹ́hìn ìgbà tí ó ti bá òún ní ìbálòpò lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà keyamo tún jẹ́ agbẹjọ́rò fún àwọn olókìkí olórin ọmọ ilẹ̀ naijiria tí wọ́n npè ní duo of psquare àti laarin àríyànjiyàn fidio tí o nlọ kákààkiri èyí tí ó ṣe àfihàn àwọn arákùnrin mejeeji yi níbití wọ́n ti nbu ara wọn tí wọ́n tún nkan ara wọn ní ẹ̀ṣẹ́ lẹ́hìn èyí ni festus keyamo ṣe àgbéjáde ìlòdì sí fidio yi tí ó sì see lálàyé pé fidio yi ko ti ilé-iṣẹ́ ofin oun jáde yíyàn sínú òṣèlú festus wa lára àwọn mínísítà tí a yàn fún ìṣàkóso ìjọ́ba ẹlẹ́ẹ̀kejì ti aarẹ muhammadu buhari lẹ́hìn tí wọ́n ti yan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ṣe àyẹ̀wò rẹ ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹjọ ọdún 2019 títí di ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsan ọdún 2019 wọ́n yan keyamo gẹ́gẹ́ bi mínísítà ìpínlẹ̀ fún niger delta kí ó tó di wípé aarẹ muhammadu buhari yan pada sí ilé iṣẹ́ ìjọba ti o nrisi ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ àti ìgbanisíṣẹ́ laarin oṣù kan sí ìgbà tí wọ́n ti kọ́kọ́ yan ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣú kẹjọ ọdún 2019 àwọn ìtọ́kasí
sunday dare sunday dáre ni a bí ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kárùún ọdún 1966 29-5-1966 jẹ́ ògbóntagì oníwèé-ìròyìn ọmọ ilẹ̀ nàìjíríà tí ó ti ṣiṣẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn tí ṣiṣẹ́ ní onírúurú ilé-iṣẹ́ ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ rédíò àti ilé-iṣẹ́ atèwé-ìròyìn ó sín ní ìmọ̀ tó dáńgájíá fún odidi ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n gbáko nínú iṣẹ́ yìí misanna-agba ti nigerian communications commission ncc aare president of the federal republic of nigeria muhammadu buhari ni o yan-an si ipo naa ni osu ikejo odun 2016 lowolowo bayii o je minisita fun eto nipa odo ati ere-idaraya ti orile-ede naijiria aare buhari yan-an si ipo minisita ni ojo kokanlegun osu keejo odun 2019 o je omobibi ipinle oyo
oba akran ti badagry oba aholu ti o tumo si oba lede ogu akran ti ilu badagry je oruko oye oba ni ilu badagry oruko oba akran ti badagry ti o wa lori oye lowolowo ni de wheno aholu babatunde menutoyi i
akanlo-ede àkànlò-èdè ni ìpèdè tàbí ìṣòro ni ṣókí ṣókí tí ó kún fún ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ìtumọ̀ rẹ̀ sì farasin a ma n fi àkànlò-èdè ṣe àgbékalẹ̀ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ sínú gbólóhun kan ni ṣókí nínú èdè yorùbá àkànlò-èdè jẹ́ lílo ọ̀rọ̀ tàbí awẹ́-gbólóhùn lọ́nà tó jinlẹ̀ tí ìtumọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ sí ìtumọ̀ òrèfé oun ni ìpèdè tí gbólóhùn inú rẹ̀ kò ní ǹǹkankan ṣe pẹ̀lú ìtumọ̀ rẹ̀ ìwúlò rẹ̀ àkànlò-èdè wúlò púpọ̀ fún elédè yorùbá l'ọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ pẹ́ ọ̀rọ̀ kan sọ àpẹẹrẹ
ilu ede ilu ede je ilu kan ti o gbajumo nile yoruba ni ipinle osun lorile-ede naijiria timi ti ilu ede ni oruko oye ti oba alade ti o n pase ilu naa n je
oba oluwo ti ilu iwo oluwo ti ilu iwo ni oruko oye oba alade ti o n joba ni ilu iwo iwo je ilu kan ti o gbajumo nile yoruba ni ipinle osun ni orile-ede naijiria oba abdul-raheed akanbi adewale ni oba ti o wa lori oye lowolowo ni ilu iwo oba adewale akanbi joba ni odun 2015 awon itokasi
ilu epe ìlú ẹ̀pẹ́ jẹ ìlú kan gbòógì ti o gbajúmọ̀ n'ílẹ̀ yorùbá ni ìpínlẹ̀ èkó lápá ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀-èdè nàìjíríà ni ẹ̀pẹ́ jẹ o tún jẹ olú-ìlú ìjọba ìbílẹ̀ ẹ̀pẹ́ ẹ̀pẹ́ local government iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ẹja pípa ni iṣẹ́ ìbílẹ̀ wọn n'ilú ẹ̀pẹ́
frank lampard frank james lampard je agba-oje agbaboolu-afesegba ti orile-ede united kingdom oti figba kan je agbaboolu iko chelsea ki won to wa yan-an laipe yii gege bi akonimo-ongba fun iko chelsea bakan naa lodun2019 gege bi agbaboolu o je ogbontarigi agbaboolu aringbungbun ori papa lasiko re a bi frank lampard ni ogunjo osu kefa odun 1978
àwọn obìnrin alámì pupa àwọn obìnrin alámì pupa {wir} jẹ́ àgbékalè iṣé láti dí àlàfo láàrin okunrin sí obìnrin lórí ẹ̀rọ ayélújara ti wikipédia àwọn obìnrin alámi pupa jé àkànṣe iṣé wikiproject lóri ẹ̀rọ ayéluja yanju idojukọ lati ṣẹda awọn nkan nipa awọn obinrin olokiki ti ko si nibe lowolowo bayii ifiyesi lati mo nipa awon akole ti o sonu ni lati wo awon hyperlink pupa ninu awon ti won ti seda won tele
ireti osayemi nigerian actressireti osayemi jẹ ògbóǹtarìgì òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò ti orílẹ̀-èdè naijiria ó sì máa ń se fíìmù ní èdè yorùbá àti gẹ̀ẹ́sì ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní ọdún 1982 ni a bí osayemi sí apá gúúsù ti apá ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ naijiria ipinle eko ní lagos state primary school ni ó ti bẹ̀rẹ̀ ètò èkọ́ rẹ̀ tí ó sì parí ó gboyè nínú ẹ̀kọ́ economics ní lagos state university ó ti siṣẹ́ lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré bíi heavy storm ife owo spiritual war towo tomo oreke mulero àti béè bẹ́è lọ
taiwo hassan taiwo hassan tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ ògògó ni a bí ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1959 31-10-1959 ó jẹ́ àgbà òṣèré olóòtú olùdarí eré orí ìtàgé àti sinimá-àgbéléwò ọmọ bíbí ìlú ìlaròó ní ìpínlẹ̀ ògùn ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà
ayo adesanya nigerian actressayọ́ adésànyà tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹjọ ọdún 1969 jẹ́ àgbà òṣèrébìnrin olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò lédè yorùbá àti gẹ̀ẹ́sì ó tún jẹ́ adarí àti olóòtú eré ayo adesanya máa ń ṣàfihàn nínuụ eré yorùbá àti ti gẹ̀ẹ́sì ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ ijagu ní ìlú ijebu ní ipinle ogun ni ayo adesanya ti wá ìyẹn ní apá gúúsù ti apá ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀-èdè naijiria ilé-ìwè st anne's ní ìlú ibadan ni ó ti kàwé fún ti alákọ̀ọ́bèrẹ̀ àti ti girama lẹ́yìn náà ó lọ university of ibadan láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú mass communication iṣẹ́ rẹ̀ ayo adesanya bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní ọdún 1986 lẹ́yìn tí ó sin orílẹ̀-èdè rẹ̀ tán ìyẹn nysc ní ọdún 1996 ó darapọ̀ mọ́ àwọn tí ń ṣe eré àgbéléwò ti orílẹ̀-èdè naijiria fíìmù tunji bamishigbin tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ palace ní wọ́n ti kọ́kọ́ se àfihàn rẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ ó padà darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn tí ń ṣe fíìmù yorùbá nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ní darí eré tó sì ń gbé eré jáde ó ti gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré jáde ó sì ti darí eré púpọ̀ ayo adesanya tún máa ń ṣe fíìmù yorùbá àti ti gẹ̀ẹ́sì ayé rẹ̀ ayo adesanya fìgbà kan jẹ́ ìyàwó goriola hassan àmọ́ wọ́n ò fẹ́ ara wọn mọ́ báyìí ó bí ọmọkùnrin kan
ekuro ope ekuro ope je eso igi ope lara eso yii ni a ti maa n se epo pupa ati epo adi-soso awo pipon ara eso yii ti a mo si eyin-ekuro ni a ti n ro epo pupa ekuro inu re ni a ti a ro epo adi-soso
adele regent adele regent ni ile kaaaro-o-jire yoruba ni eni ti a yan lati dari ilu ti oba won ba waja ti asa won kosi faye gba a pe ki ori ite oba naa sofo adele a maa dari ilu ti oba won ba n saare tabi ti ko le danto mo laaarin ilu adele kii pe lori oye bi oba o maa n ni iwonba igba ti adele maa fi n wa lori ite awon itokasi
idiat adebule dr oluranti adebule ti a bi ni ojo ketadinlogbon osu kokanla odun 1970 je oloselubinrin omo yoruba lati ipinle eko lorile-ede naijiria o je omo bibi idile idowu-esho ti iku ojo alaworo ni ijoba ibile ojo ni ipinle eko oun ni igbakeji gomina ipinle eko nigba ijoba gomina akinwunmi ambode ti saa won sese pari ni odun 2019 obafemi hamzat ni o ropo re gegebi igbakeji gomina awon itokasi
enoch adejare adeboye nigerian clergyman ini a bí ní ọjọ́ kejì oṣù kẹ́ta ọdún 1942 olusoagutan enoch adéjàre adébóyè ni a bí ní ọjọ́ kejì oṣù kẹ́ta ọdún 1942 jẹ́ òjíṣẹ́ ọlọ́run àti olùṣọ́ àgùntan-àgbáyé tí ijo oníràpadà ti a mọ̀ sí the redeemed christians church of god rccg ó jẹ́ ọmọ bíbí ifẹ̀wàrà ní ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà o lọ si ile-ẹkọ giga university of nigeria unn ni nsukka ṣugbọn nitori ogun abele naijiria o pari iwe-ẹkọ akọkọ rẹ ni university of lagos ti o gba oye oye oye ni imọ-iwe giga ni imọ-ẹkọ ni ọdun 1967 ni ọdun kanna o fẹ foluke adenike wọn ni ọmọ mẹrin adeolu adeboye bolu adubi nee adeboye leke adeboye and dare adeboye ni ọdun 1969 o gba oye ni hydrodynamics lati university of lagos o darapọ mọ ile ijọsin kristiẹni redeemed ti ọlọrun ni ọdun 1973 o se itumọ ede yoruba si gẹẹsi fun olusoagutan josiah olufemi akindayomi pe si iṣẹ-iranṣẹ o jẹ alufaa ti ile ijọsin ti redeemed christian church ni ọdun 1977 o di olutọju gbogbogbo ti ile ijọsin ni ọdun 1981 ile ijọsin naa eyiti a ko mọ daradara ṣaaju adeboye di olutọju gbogbogbo lọwọlọwọ ni ọpọlọpọ awọn ẹka ni kariaye ni awọn orilẹ-ede 196 adeboye ti ṣalaye pe ete rẹ ni lati fi ile-ijọsin wa laarin ijinna iṣẹju marun iṣẹju marun ni awọn ilu idagbasoke ati iṣẹju iṣẹju awakọ marun ni awọn ilu ti o dagbasokenewsweek</ref> awọn ẹbun ati idanimọ 'ikan ninu awọn aadọta eniyan alagbara julọ ni agbaye' ' newsweek 2008
david oyedepo nigerian clergyman david o oyedepo ti a bi ni ọjọ́ kẹtà-dín-lọ́gbọ̀n oṣù kẹ̀sán ọdún 1954 jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà òjíṣẹ́ ọlọ́run biṣọọbu-àgbà àti oludasile ìjọ living faith church worldwide ìjọ ìgbàgbọ́ ààyè tó káríayé ti gbogbo eniyan mo si winners' chapel ìjọ aṣẹ́gun olu-ijo yii fun gbogbo agbaye ni a tedo si ilu ota ni ipinle ogun lorile-ede naijiria oyedepo ni oniwaasu ọlọla julọ ni orilẹ-ede naijiria pẹlu iye apapọ ti o ju us 150 milionu dọla ìgbésí ayé àti ìtàn ní ọjọ́ kẹtà-lé-lọ́gbọ̀n oṣu kẹsan ọdún 1954 ni wọn bi david olaniyi oyedepo ni ilu osogbo orílẹ̀-èdè nàìjíríà ṣugbọn ó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú ọmú-aràn ní agbegbe ìjọba ìbílẹ̀ irẹpodun o dagba ni ìdílé ẹsin ti o papọ kan ibrahim baba rẹ jẹ olutọju musulumiiya rẹ jẹ ọmọ ìjọ kérúbù àti séráfù nigbati o dagba ni iya-nla rẹ ni osogbo ẹniti o ṣafihan rẹ si awọn iṣe ti igbesi-aye onigbagbọ nipasẹ awọn adura owurọ ti o lọ pẹlu o tun kọ ọ ni pataki idamẹwa oyedepo di “atunbi” ni ọdun 1969 nipasẹ ipa ti olukọ rẹ betti lasher ẹniti o nifẹ si rẹ ni awọn ọjọ ile-iwe giga o kọ ẹkọ faaji ni ile-iṣẹ polytechnic ilorin ti kwara ati pe o ṣiṣẹ ni ṣoki pẹlu ile-iṣẹ federal ti ile ni ilorin owa fi ise re le lati dojukọ iṣẹ ihinrere rẹ gẹgẹbi rẹ o gba aṣẹ kan lati ọdọ ọlọrun nipasẹ ojuran mejidinlogun - ni oṣu karun ọdun 1981 lati gba ominira kuro ninu gbogbo irẹjẹ ti eṣu nipasẹ iwasu ọrọ igbagbọ iwaasu kristiẹni awọn ẹkọ rẹ ti gbe e si kilasi oro igbagbọ awọn oniwaasu bii kenneth copeland awon
àbàwọn stigma fiimu ọdún 2013 abawọn stigma jẹ́ eré oníṣe lati orilẹ-èdè nàìjíríà tí a gbé jáde ni ọdun 2013 ere oniṣe yii da lori ìdẹ́yẹ sí ti àwọn eniyan ti arun kogboogun eedi n ba fínra n doju kọ abúlé kan ni ipinle rivers ni ète eré yii da le diminas dagogo ni oludari eré naa nigbati awọn gbajugbaja osere bii jackie appiah hilda dokubo àti emeka ike kopa ninu ere naa ile-iṣẹ elétò ilera ti ìpínlẹ̀ rivers ni o se agbejade ere naa
ọ̀gà ọ̀gà tí a tún lè pè ní agẹmọ jẹ́ eranko kan tó farajọ alángbá ṣùgbọ́n tí ó ní àbùdá kan tí ó lè fi pàrọ̀ àwọ̀ èyíkéyí tí ó bá fẹ́ ọ̀gà lè lò tó ọdún mẹ́ta sí márù-ún kí ó tó kú
ọmọlúàbí ọmọlúàbí jẹ́ gbólóhùn tí ó fi ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àṣà àti ìṣe àwọn baba ńlá baba yorùbá hàn nípa ọgbọ́n inú àti inọ̀ ikùn láti fi ṣàpèjúwe iwa rere tí ó tọ́ kí ènìyàn ó ma hù láwùjọ ẹ̀wẹ̀ gbólóhùn yí fi iwa akin ìjáramọ́ṣẹ́ ìwà ìrẹ̀ ìrẹ̀lẹ̀ àti àpọ́nlé tí ń bẹ lára àwọn yorùbá ẹni tí a è pè lọ́mọlúàbí ni ẹni iyì tí ó gbàgbọ́ nípa ìjáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ ẹni tí ó ń bọ̀wọ̀ bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọlàkejì rẹ̀ tí ó sì ń ṣojúṣe rẹ̀ láwùjọ níbi ìfarajìn àti ìnọwọ́sí lákòó tán ẹni tí ó bá jẹ́ ọmọlúàbí yóò jẹ́ tí ó yàgò tàbí sá fún iwa èérí ọmọlúàbí tún jẹ́ gbólóhùn àpónlé tí àwọn yorùbá tò papọ̀ láti àwọn ẹyọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ọmọ + tí + olú-ìwà it + bí ládàáyanrí ìwà ni ó jẹ́ ọmọ tí olú olódùmarè bí ẹni tí ó bá jẹ́ ọmọlúàbí yóò hùwà tí ó dára jùlọ tí ẹlòmíràn lè kọ́ṣe nínú ìwà pẹ̀lẹ́ ìwà pẹ̀lẹ́ ni gbòngbò tí a fi ṣẹ̀dá àṣà àti ìṣe yorùbá tí ó sì ń orígun kan nínú ìwà ọmọlúàbí àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí ó sì tún jẹ́ ìpìlẹ̀ ìwà ọmọlúàbí nìwọ̀nyí ò sẹ́ni tí a kò le pè lọ́mọlúàbí láì kò fi ti ẹsìn kan ṣe èyí túmọ̀ sí wípé ìwà ọmọlúàbí jẹ́ ohun pàtàkì tí àwọn ẹlẹ́sìn mú ní ọ̀kúnkúndùn tí wọ́n sì ń kọ́ àwọn olùkópa nínú ẹ̀sìn wọn nípa kí jíjẹ́ olótìítọ́ oníwà ìrẹ̀lẹ̀ kí á sì ma sòtítọ́ nígbà gbogbo esin wọn yálà nínú ẹ̀sìn kristẹ́nì tàbí ẹ̀sin and mùsùlùmí
omoyele sowore omoyele sowore ti a bi ni ojo kerindinlogun osu keji odun 1971 16-02-1971 je omo orile-ede naijiria ajafeto omo eniyan o dije dupo aare orile-ede nàìjirià labe egbé olósèlú african action congress lodun 2019 oun naa ni oludasile ile-ise iwe-iroyin elero atagba sahara reporters ni ojo keta osu kejo odun 2019 awon olopaa otelemuye fi sinkun ofin mu sowore nitori o se agbateru ifehonuhan lati gba ijoba lona aito àárò ayé àti èkó rè yele sowore jé omo ese-odo ipinle ondo ni guusu iwọ-oorun nàìjirià a bi ni agbegbe niger delta nibi ti o ti dagba ni ile olorogun pẹlu ọmọ mẹrindilogun nígbà tí ópé omo odún mejila o kọ bí a se ún wa okada kí o le ma lọ sí odò ní àárò ojojumo láti peja fun gbogbo ẹbi rẹ ki o to lọ si ile-iwe sowore keko nipa geography and planning ni yunifasiti ti ìlú èkó laarin odun 1989 si 1995 óparíparish notori pé leexpelled kuro lara àwon akóèkó ilé-ìwé rè ní emeji nitori òrò tí ójo mó oselu ati ìjà fún ètó omo ilé-ìwé ó jẹ́ ààrẹ ìjọba student union government ti yunifásítì ti èkó láàárín ọdún 1992 sí 1994 sowore gbà àmì-èye master degree ní public administration ní yunifásitì ti columbia sahara reporters sowore dá sahara reporters kalè ni odún 2006 ní ìlú new york láti lati gbogun ti iwa ibaje ati ti ijọba tí kò tọ ilé-ìsé ford foundation ati omidyar foundation ní óún se atileyin owó fún ilé ise sahara reporters gẹgẹbi ofin rè sahara ko ún gba ipolowo tàbí atilẹyin owo lati ọdọ ijọba naijiria ìdíje fún ipò ààré ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2018 sowore kéde èrò rẹ̀ láti díje fún ààrẹ nínú ìdìbò gbogbogbòo 2019 tí nàìjíríà ni oṣu kẹjọ ọdun 2018 o dá egbe oṣelu kan tí a ń pè ní african action congress aac kale ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹwàá ọdún 2018 a se ìdìbò alabele tí egbe oselu aac omoyele sowore sí jáde láìsí àtakò gẹ́gẹ́ bí oludije ààrẹ fún ẹgbẹ́ náà bí o tile jé wipe ofidi remi nínú ìdìbò gbogbogbò odun 2019 sowore ní ìbò 33953 èyí tí ómú kó jé eni ekarun tí ó ní ìbò tópòjù
femi adesina
jean cocteau jean maurice eugène clément cocteau to gbajumo bi jean cocteau 5 july 1889 11 october 1963 je olukowe akewi akun àworan njagun onise ati oludari filmu ara fransi
eya ogu ogu people eya ogu ogu people ti opo eniyan maa n si pe ni egun je eya ti tedo si ipinle eko ati ogun lapa gusu-iwo-oorun orile-ede naijiria awon eya ogu ni oniruuru ede-adugbo bii' thevi wheda seto toli ati bee bee lo awon ogu to iwon ipin meedogun 15 ni apapo awon olugbe ipinle eko orisun won awon eya ogu se wa lati orile-ede atijo dahomeh ti a mo nisinsinyi si orile-ede ominira benin benin republic itan atenudenu kan so wipe awon ogu je iran kan ti won se wa lati wheda alatha ati weme ti won je ilu ti o wa lorile-ede olominira benin leyin ogun dahomey ti o be sile ni senturi mejidinlogun seyin 18th century gegebi olusotan mesawaku se so ninu iwe re kan awon eya ogu wa tedo si badagry lati senturi meedogun 15th century seyin nitori aabo nigba ogun dahomey awon itokasi
reuben fasoranti reuben fáṣànràntì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùún 93 láti ìpínlẹ̀ òndó lápá gúsù ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó ti fìgbà kan jẹ́ olórí abala kan nínú ẹgbẹ́ afẹ́nifẹ́re ẹgbẹ́ tí ó ń ṣe kòkárí òṣèlú àti ìdàgbàsókè ilẹ̀ yorùbá lápapọ̀ ó kọ̀wé fipò adarí afẹ́nifẹ́re sílẹ̀ lọ́dún 2015 awon ìtọ́ka sí
midé fúnmi martins midé fúnmi martins tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹrin ọdún 1979 jẹ́ òṣeré-bìnrin àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ yorùbá lórílẹ̀-èdè nàìjíríà ó jẹ́ ọmọ gbajúgbajà òṣèré-bìnrin olóògbé fúnmi martins tó ṣaláìsí lọ́dún 2002 midé martins darapọ̀ mọ́ àwọn òṣeré sinimá àgbéléwò ní kété tí ìyá rẹ di olóògbé ó fẹ́ òṣèré olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò tí a mọ sí afeez owó ọmọ méjì ni ó bí
káyọ̀dé akíntèmi káyọ̀dé akíntèmi tí wọ́n bí ní june 26 1965 jẹ́ akọ̀ròyìn tv presenter onímọ̀ ní ọ̀rọ̀ tóńlọ subject matter expert alámòójútó iṣẹ́ àkànṣe olù fúnilámọ̀ràn nípa ict ict consultant ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ channels tv gẹ́gẹ́ bí olóòtú àgbà àti gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà fún ẹ̀ka ict àti alámòójútó iṣẹ́ àkànṣe fún london borough of hillingdon ó fi ilé iṣẹ́ amóhùmáwòrán channels sílẹ̀ ní ọdún 2016 láti lọ dá tirẹ̀ sílẹ̀ tí ó pè ní plus tv africa níbi tí jẹ́ aláṣẹ àti olóòtú àgbà fún ìgbé ìròyìn jáde káyọ̀dé ló ma ń gbàlejò àwọn ènìyàn lórí ètò tí ó pè ní sunrise saturday tí ó ma ń gbìnàyá ní orí ìkànì channels tv óun tún ninó ma ń ṣètò wake up africaèyí tí ó ma ń wáyé ní gbogbo ọjọ́ ẹtì láàrín agogo mẹ́fà sí ago mẹ́sàán àárọ̀ 6 am and 9am lórí ìkànì rédíò 943 fm ètò ẹ̀kọ́ àti ìgbòkègbodò iṣẹ́ rẹ̀ káyọ̀dé gba ìwé ẹ̀rí higher national diploma nínú imọ̀ -ẹ̀ẹ̀kọ́ mass communication àmọ́ tí ó yan broadcast journalism láàyò jùlọ ní ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ti ìpínlẹ̀ ògùn tínwọ́n ti yí padà sí moshood abiola polytechnic báyílẹ́yìn èyí ni ó gba ìwé-ẹ̀rí postgraduate diploma nínú ìmọ̀ information technologyó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1980s pẹ̀lú ilé ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ ikẹ̀ nàìjíríà radio nigeria gẹ́gẹ́ bí atọ́kùn fún ètòteen and twenty beats nígbà tí ó di ọdún 1987 ó dara pọ̀ mọ́ ogun state broadcasting corporation níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́ta ṣáájú kí ó tó di òṣìṣẹ́ fún ẹ̀ka-ìmọ̀ ẹ̀kọ́ mass communication ní fásitì ahmadu bello ní ọdún 1991 ó dara pọ̀ mọ́ ogun state television gẹ́gẹ́ bí olórí fún ẹ̀ka ètò amóhùmáwòrá ní ọdún 1993 ó ṣẹ̀dá ẹ̀ka independent production company tí wọ́n pè ní the kay associate pẹ̀lú ọmọba kehinde adeosun tí ó jẹ́ alága tẹ́lẹ̀ fún promoserve advertisement ní ọdún 1994 ó gbéra lọ sí ìlú london níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ ben television tí ó jẹ́ ilé iṣẹ́ ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ ti ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì ní oṣù kẹ́ta ọdún 2011 ó dára pọ̀ mọ́ ikẹ́ iṣẹ́ amóhùnmáwòrán channels tv gẹ́gẹ́ bí olótùú àgbà fún àjọ náà títí di ọdún 2016 ní ọdún 2013 wọ́n yàn án àmì ẹ̀yẹ nigerian broadcasters merit awards gẹ́gẹ́ bí best station's manager of the year ọ́dún yìí kan náà ni wọ́n fun ilé iṣẹ́ channels tv ní àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán tí ó dára jùlọ ní ọdun náà ní january 2013 káyọ̀dé bu ẹnu àtẹ́ lu ìròyì ẹlẹ́jẹ̀ kan tí ó ń jà ràìn ràìn wípé àpérò kan tí ilé iṣẹ́ channels tv gbé kalẹ̀ lórí bí ìgdàgbàsókè ṣe lè débá àwọn agbófinró nigerian police force ni ìjọba àpapọ̀ federal government of nigeria ó sọ àsọ minu ọ̀rọ̀ lórí rẹ̀ wípé ìfòté lé àpèjọ ìjíròrò náà ni ìjọba ri wípé àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ nípa ètò àbò ti kópa ìjọ́mọ ẹgbẹ́ rẹ̀ akíntèmi jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ tí ọ̀jọ̀gbọ́n ti royal television society àti ti ilé- ẹkọ redio ó tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ti àwùjọ tí ó wà fún ìṣàkóso àlàyé ọ̀erọ̀ àti ilé- iṣẹ́ àwọn olùdari ìtàkùn ìjásóde md/ceo kayode akintemi | about plus tv africa
akinola deko gabriel akinọlá dèkó tí wọ́n bí í ọjọ́ kaẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 1913 30-1-1913 tí ó sì kú ní ọjọ́ kárùún oṣù kọkànlá ọdún 1987 5 november 1987 ni ó jẹ́ oní kọ̀ngílá ìṣẹ́ ẹ̀kọ́lé àti mínísítà fún ètò ọ̀ aètò ọ̀gbìn nígbà kan rí apá ìwọ̀ oòrùn ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó tún jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́ tímọ́ fún olóyè awólówọ̀ gẹ́gẹ́ bí mínísítà ó kópa ribiribi nípa mímú ìlọsíwájú bá ètò ìgbnisíṣẹ́ àwọn àṣẹ̀sẹ̀ yọ ọ̀gọ́mọ̀ tí wọ́n kàwé jáde ní unifásitì tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ àgbẹ̀ tí ìjọba yóò ma kọ́ wọn ní iṣẹ́ ọ̀gbìn ní àwọn ìletò tí wọ́n ti kọ́ kalẹ̀ fún iṣẹ́ àkànṣe náà tí ìjọba yóò sì ma fún wọn ní owó ọ̀yà àwọn akẹ́ọ̀ọ́ náà yóò ma ṣiṣẹ́ f ọ̀gbìn dídá àwọn ìletò wọ́nyí ni wọ́n jẹ́ ètò àyálò láti ọ̀dọ àwọn israeli ètò yí wà fún láti já ọkàn àwọn ọ̀dọ́-langba kúrò nínú èrò wíwáṣẹ́ lọ sí àwọn ìlú ńlá ńlá tí wọ́n sì yan iṣẹ́ àgbẹ̀ ní pọ̀sìn akin dèkó ni wọ́n bí ní ìlú igbotu ní ìpínlẹ̀ òndó tí àwọn òbí rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ ìlú ìdànrè ní ìpínlẹ̀ òndó kan náà ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ st peters ní ìpínlẹ̀ èkó fún ètò ẹ̀kọ́ alákùkọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ti ìpele ọlọ́dún mẹ́fà ẹlẹ́ẹ̀kejì ó tún lọ sí government college ìbàdàn gci ó sì parí ẹ̀kọ́ kíkà rẹ̀ ní ilé-ẹ̀ ẹ̀kọ́ yaba higher college ní ìpínlẹ̀ èkó níbi tí ó ti gba ìwé-ẹ̀rí nínú ẹ̀kọ́ olùkọ́ ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ olùkọ́ ní ilé-ẹ̀ọ́ rẹ̀ tí ó ti jáde tẹ́lẹ̀ government college ìbàdàn tí ó sì ń kọ́ ni nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ṣíṣàmúlò ìṣirò mechanics and applied mathematics lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ ó yan iṣẹ́ ikọ́lé láàyò tí ó sì gb ilé-ẹ̀kọ́ ìkọ́lé brixton lọ ní ìlú london kò pẹ́ púpọ̀ tí ó fi bẹ̀rẹ̀ ilé-iṣẹ́ ìkọ́lé tirẹ̀ náà ní ọdún 1950s ọ̀rẹ́ rẹ̀ ba sọ̀rọ̀ wípé kí ó dara pọ̀ mọ́ òṣèlú ní ọdún 1956 ó gba imọ̀ràn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́gán tí ó sì dara pọ̀ mọ́ òṣèlú ni ó wọlé ìdìbò tí ó sọọ́ di mínísítà fún ètò ọ̀gbìn apá ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ nàìjíríà akinọlá ni ó ṣe aṣojú fún ilẹ̀ nàìjíríà níbi àpérò fún óńjẹ àti nnkan irè-okofood and agriculture organization ní ilẹ̀ adúláwọ̀ wọ́n tún fi ṣe ìgba-kejì gíwá ilé-ẹ̀kọ́ fún ilé-ẹ̀kọ́ federal university of technology àkúrẹ́ òun náà tún ní igbákejì gíwá ilé-ẹ̀kọ́ university of ìbàdàn àti university of benin
afẹ́nifẹ́re ẹgbẹ́ afẹ́nifẹ́re ni ó jẹ́ ẹgbẹ́ tó ó níṣe pẹ̀lú àṣà àti ẹ̀nìn ìbílẹ̀ t orùbá ilẹ̀ nàìjíríà tí olóyè abraham adésànyà adarí rẹ̀ nígbà tí olóyè bọ́lá ìgè nígbà ayé rẹ̀ sì jẹ́ igbá kejì rẹ̀ àwọn tí wọ́n tún jọ jẹ́ olùdásílẹ̀ ni olóyè ọnàsànyà olóyè ruben fáṣànràntì adégbọ̀nmírè òkúróunmú fẹ́mi gàníyù dáwódù ọláníhún àjàyí olú fálaè adébáyọ̀ adéfaratì alhaji adéyẹmọ àti ayọ̀ adébanjọ nígbà tí wọ́n dá ẹgbẹ́ òṣèlú alliance for democracy kalẹ̀ ní ọdún 1998 wọ́n lo àfojúsùn wọn ẹgbẹ́ afẹ́nifẹ́re gẹ́gẹ́ bí àfojúsùn ìpolongo ìbò náà lẹ́yìn ti ẹgbẹ́ yí pàdánù ìdíje ìbò dìbò wáyé ní oṣù kẹ́ta ọdún 2003 àwọn alátakò ọmọ ẹgbẹ́ náà lọ lọ́tọ̀ wọ́n sì dá ẹgbẹ́ ad sílẹ̀ tí wọ́n sì fi olóyè bísí àkàndée ja alága ad ní january 2006 àwọn jàndùkú olóṣèlú kọlu àwọn akọ́wọ̀ọ́rìn convoy adarí ẹgbẹ́ òṣèlú ní ìlú òṣogbo tí ó jẹ́ olú-ìlú ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ní ọdún 2008 wọ́n dá afenifere renewal group alias arg kalẹ̀ pẹ̀lú àwọn èrò àti ìlépa láti so ẹgbẹ́ afẹ́nifẹ́re papọ̀ kí ìyapa ó ma sii mọ́ láàrín wọn tí yóò sì tún máa jẹ́ ànfàní fún àwọn àgbà ẹgbẹ́ náà láti lè ma bá iṣẹ́ takun takun wọn lọ ní oṣù kọkànlá ọdún 2008 apá kan ẹgbẹ́ aafẹ́nifẹ́re tí wọ́n fi faction of afenifere in ìjẹ̀bú igbó ní ìpínl ògùn èyí tí olóyè ayọ̀ bánjọ ń darí rẹ̀ fi olóyè reuben fáṣọ̀nràntì jẹ gẹ́gẹ́ bí alága ẹgbẹ́ tiwọn àwọn àgbà arg ní èyí tí a ti rí senator ọlábíyí dúrójayé olóyè bísí àkàndé wálé ọ̀ṣun àti yínká òdúmákin fi léde wíé àwọn kò tẹ́wọ́ gba ìyànsípò náà wọlé ní tiwọn ní oṣù kẹwàá ọdún 2009 agbẹnusọ fún arg sọ̀rọ̀ nípa ètò yíyọ ìkúnpá lórí epo rọ̀bì lábẹ́lé ní ilẹ̀ nàìjíríà bákan náà ni ẹgbẹ́ náà tún kan sárá sí olóyè month the arg hailed the conviction of chief bọ̀dé george àti àwọn márùún mìíràn fún akitiyan wọn láti fòpin sí ìwà àjẹbánu tó ti gbilẹ̀ ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ọ̀pọ̀ ọmọ yorùbá ni wọ́n rí àwọn alátakò ìjọba lórí èrò wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tó tọ́ láti yí ìpinu ìjọba pada tí ó sì ń fún àwọn ọmọ yorùbá tí wọ́n wà nínú àjọ náà ní ìdánimọ̀ jákèjádò ilẹ̀ nàìjíríà ẹ̀wẹ̀ tí ó sì tún jẹ́ ọ̀nà kan láti tọ́jú ẹ̀yà yorùbá lápapọ̀ àríwísí àwọn kan wà lára àwọn ọmọ yorùbá tí wọ́n rí ìdásílẹ̀ àwọn ẹgbẹ́ alátakò gẹ́gẹ́ bí ohun tó léwu púpọ̀ sheik dr abu-abdullah adélabú tí ó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀sìn islam ṣàpèjúwe ba ẹgbẹ́ afẹ́nifẹ́re gẹ́gẹ́ bí àkójọ àwọn ẹlẹ́yà-ò-mẹ̀yà tí wọ́n sì ń lo inọ̀ tara ẹnìkan oní kèéta tí wọ́n kò mọ̀ ju ìbàjẹ́ àwọn ẹlẹ́yà tó kú lọ ó se èyí nibi àpérò london awqaf africa college sheikh adelabu yí náà ni ẹni tí ó jẹ́ olùdásílẹ̀ the awqaf africa society ní ìlú lọ́ndọ̀nù
erik satie éric alfred leslie satie to gbajumo bi erik satie 17 may 1866 1 july 1925 je ara fransi alasopo orin ati olórin
nnamdi kanu nnamdi kanu jẹ́ ajìjàǹgbara ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti bìrìtìkó òun ni olùdásílẹ̀ àti adarí ẹgbẹ́ ajìjàǹgbara indigenous people of biafra ipob ẹgbẹ́ yìí ló ń jìjàǹgbara òmìnira àti ìdásílè orílè-èdè biafra nnamdi kanu náà olùdásílẹ̀ ilé-ìṣe rédíò kan tí a mọ̀ sí radio biafra tó wà lórílẹ̀-èdè bìrìtìkó ìjọba orílẹ̀-èdè nàìjíríà fi ṣìnkún òfin ìfipá-dàjọba-bolẹ̀ mú un ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹwàá ọdún 2015 wọ́n sì tì í mọ́lé fún ìgbà pípé bí ó tilè jẹ́ pé ọ́pọ̀ ilé-ẹjọ́ dájọ́ pé kí wọ́n dá a sílẹ̀ nígbà tí kanu ń farahàn nílé ẹjọ́ ìṣe ló máa ń múra bíi ọmọ júù ó sọ nílé-ejò pé òun nígbàgbọ́ nínú ẹ̀sìn àwọn júù òun sì ń rí ara òun gẹ́gẹ́ bíi ọmọ júù ìjọba orílẹ̀-èdè nàìjíríà dá a sílè lọ́jọ́ kejìdínlógún oṣù kẹrin ọdún 2017 pẹ̀lú béèlì pé kò gbọ́dọ̀ fi orílẹ̀-èdè nàìjíríà sílè ṣùgbọ́n ó sá lọ gba ọ̀nà ẹ̀bùrú sí òkè-òkun
owó owó ni ohunkóhun tí àwọn ènìyàn kan bá gbà lágbègbè ìlú tàbí orílẹ̀-èdè wọn láti máa fi ṣe kárakáta ọjà tàbí san gbèsè ó jẹ́ ohunkóhun tàbí àkọsílẹ̀ tó dájú tí gbogbo ènìyàn gbà láti máa fi san owo ọjà rírà iṣẹ́ tí a ṣe fúnni tàbí san gbèsè àti owó-orí àwọn onímọ̀ ṣàlàyé pàtàkì owó gẹ́gẹ́ bí ohun tí a fi ń ṣe pàṣípàrọ̀ ọ̀jà nǹkan-ìdíyelọ́jà nǹkan-ìdíyelé dúkìaí àti nǹkan ipààlà iye ọjà ohunkóhun tí ó bá lè ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni a lè kà sí owó owó nínú ìtàn jẹ́ ohun to tọ́ tí a fi ń ṣe ìdókòwò ọja àmọ́ ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ wípé owó láyé òde òní ni ónì ètò tó dálé n owó tí oun tí alè fojú rí bíi góólù tàbí sílífà kòlè rópò fiat money da bi sowe dowo tabi akosile fun eto isanwo ko wulo laaye ara re
owó money
diahann carroll òṣeré àti akọrin ará amẹ́ríkà diahann carroll tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ carol diann johnson july 17 1935 october 4 2019 jẹ́ òṣèré akọrin aláṣọ-oge ati alákitiyan ará amẹ́ríkà ó kọ́kọ́ di ìlúmọ̀ọ́ká láti inú àwọn fíìmù tó ní òṣèré aláwọ̀-dúdú nínú bíi carmen jones 1954 àti porgy and bess 1959 ní ọdún 1962 carroll gba ẹ̀bùn tony bí òṣèré obìnrin tó dára jùlọ obìnrin aláwọ̀-dúdú àkọ́kọ́fún ipa rẹ̀ tí ó kó nínú eré orí-ìtàgé broadway nípa kíkọ orin no strings
tsáda tsáda jẹ ilu kekere kan ni iha iwọ-oorun ti cyprus o wa ni agbegbe eparchía páfou ni apa iwọ-oorun ti orilẹ-ede naa 90 km iwọ-oorun ti olu-ilu nicosia ati 8 ibuso si ariwa ti paphos tsáda jẹ 619 mita loke omi okun o ni awọn olugbe 1043
gbàngàn tafawa balewa square gbàngàn pápá ìṣeré tafawa balewa tbs jẹ́ ilẹ̀-ayẹyẹ tí ó tó sààre ilẹ̀ bí ìwọ̀n èyí tí a àkọ́kọ́ pè ní ilé eré-ìje” èyí tí ó wà ní erékùṣù eìpínlẹ̀ èkó ìtàn nípa gbàgàn yí ilé eré-ìje ìpínlẹ̀ èkó tí ó ti di tbs báyìí ni ó jẹ́ pápá tí ìfẹṣin sáré ìdárayá tẹ́lẹ́ ní ìlú èkó tí wọ́n sì ya apá ibì kan sọ́tọ̀ fún eré bọ́ọ́lù aláfẹsẹ̀gbá àti àyè kan fún eré bọ́ọ̀lù ẹlẹ́yin orí ilẹ̀ wọ́n yan ilẹ̀ náà fún àwọn ìjọba amúnisìn tí ó ń ṣàkóso lórí ilẹ̀ nàìjíríà tẹ́lẹ̀ nípa àṣẹ ọba dosunmu ní ọ̀dún 1859 tí ó sì padà mú ìdàgbàsókè bá agbègbè náà pápá náà ni ó ọ̀ ọ̀gágun yakubu gowon wo palẹ̀ tí ó sì yi padà sí gbàgàn tafawa balewa squarenígbà pápá yí wà l loju iṣẹ́ àwọn ìlà eré-ìje fún àwọn esin tí ó ń sáré níbẹ̀ tó méje sí mẹ́jọ tí wọ́n sì gùn tó ibùsọ kan 1 mile ní ọdún 1960 wọ́n tún pápá yí ṣe láti fi sàmì ayẹyẹ òmìnira orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí wọ́n sì fa àsíá orílẹ̀-èdè gẹ̀ẹ́sì amúnisìn wálẹ̀ ibi tí gbàgàn yí wà gbàngàn tbs tí wọ́n kọ́ ní ọdún 1972 fìdí ti òpópónà awólọ́wọ̀ cable street ọ̀nà fọ́ọ̀sì ọ̀nà catholic mistree àti 26-storey independence building gbàgàn yí bí ohun mánigbàgbé ẹnu àbáwọlé gbàgàn yí ni àwọn ère ẹṣin mẹ́rin tí a ṣe ànọ̀ rẹ̀ lọ́jọ̀ pẹ̀lú àwọ̀ funfun báláu àti àwọ́n éyẹ àṣá méje tí a ṣe ọ̀nà wọn pẹ̀lú àwọ̀ pupa tí wọ́n ń ra bàbà lójú ọ̀run tí àwọn ìṣeẹ́ ọ̀nà yí sì ń tọ́ka sí àmì agbára àti iyì gẹ́gẹ́ bí àkọmọ̀nà orílẹ̀-èdè nàìjíríà àwọn ohun ará ọ̀tọ̀ tí ó jẹ́ mánigbàgbé nì 1àmì ìrántí ogun àgbáyé àkọ́kọ́ i ogun àgbáyé ẹlẹ́kejì ii àti àwọn tó fara káṣá nínú ogun abẹ̀lé ilẹ̀ nàìjíríà tí ó sì tún dúró fún the26-storey independence house tí wọ́n kọ́ ní ọdún 1963 tí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé tí ó ga jùlọ fún ìgbà pípẹ́ jùlọ ní orẹ̀-èdè nàìjíríà àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ gbàngàn yí gba àwọn ènìyàn tí ó tó ẹgbẹ́ẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo àwọn aye bí ibi ìtajà oríṣiríṣi ilé ońjẹ àyè igbóọ́kọ̀ sí àti ibi tí wọ́n ti ń ṣé tó ìwé ìrìnà lè sókè òkun àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tí ó ti wáyé níbẹ̀ rí lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti wáyé tí ó kẹ́ mánigbàgbé ni ayẹ̀yẹ ìgbòmìnira tí ó wáyé ní ọjọ́ kíní oṣù kẹwàá ọdún 1960 1-10-1960 tí olórí mínísítà nígbà náà tafawa balewa sì bá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà sọ̀rọ̀ lára rẹ̀ náà ni ayẹyẹ ọjọ́ òṣèlú àwa-ara wa democracy day àti àwọn mìíràn bí ìpàgọ́ orin àti ìpàgọ́ àti ìpéjọ pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn gbogbo
owó ẹyọ owó ẹyọ jẹ́ ohun alùmọ́nì tí wón ń lò láyé àtijó gẹ́gẹ́ bí owó láti fi ṣe káràkátà láwùjo yorùbá àti ilẹ̀ áfríkà lápapò láwùjọ yorùbá a máa ń rí owó ẹyọ gẹ́gẹ́ bí àmín ọlà tàbí ajé àwọn mìíràn a máa lò ó gẹ́gẹ́ bí ẹgbà-ọrùn tàbí ẹgbà-ọwọ́ láti fi ṣẹṣọ̀ọ́ a máa ń fi ṣe ẹ̀ṣọ́ àwọn babaláwo á tún máa lò ó bí ọ̀pẹ̀lẹ̀ fún ifá dídá
idowu philips
ilé ìtàwé ilé ìtàwé ti a tun pe ni ilé ìtàwé css jẹ́ ile kan ni erékùsù èkó ó wà ni apá ariwa-ila-oorun òpópónà gbòòrò broad street ni òpópónà odunlami àwọn ilé iṣẹ́ ti o n ya aworan ile ti a npe ni godwin ati hopwood architects ni o ya aworan ile náà
samsoni ọlajuwọn kokumọ ọlayide samsoni ọlajuwọn kokumọ ọlayide bí ni iléṣà ìpínlẹ̀ ìwọ̀ oòrùn nàìjíríà tẹ́lẹ̀ 1928 - 1984jẹ́ olùkọ́ àti ọ̀jọ̀gbọ́n ní ìmọ̀ ọrọ̀ ajé ajẹmọ́-ohun-ọ̀gbìn-ati- ìsìn àwọn òbí rẹ̀ ni josiah ogunpooo ọláyídé ti ẹgbẹ́ ògbóni ipele gíga ní iléṣà àti mariam ọláyídé ọmọ oni - ìbátan lisa ti eti-ooni ní ìjẹ̀sà ó fẹ́ theresa folashade ọláyídé ọmọ ikoli ọmọ gbajúmọ̀ olóṣèlú olùfẹ́-orílẹ̀èdè àti oníròyìn ernest sessei ikoli ní 1961 ó bí ọmọ mẹ́rin àwọn náà ni biodun tokunbo oluwole àti olajide ọláyídé kẹ́kọ̀ọ́ ní iléẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ ṣọ́ọ̀sì àpọ́sítélì apostolic church primary school ní iléṣà àti kọ́lẹ́jì àwọn olùkọ́ tí ìjọba ní ìbàdàn kí ó tó tẹ̀síwájú lọ sí yunifásítì ti ìlú lọ́ndọ́nnù ní 1955 níbi tí ó ti gba oyè ba nínú ẹ̀kọ́ ọrọ̀ - ajé ní 1957 ó lọ sí us níbi tí ó ti gba oyè msc àti òye ọ̀mọwé ní ẹ̀kọ́ ọrọ̀-ajé ajẹmọ́-ohùn-ọ̀gbìn- àti - ọsìn ó jẹ́ gíwá láàrin ọdún 1979 sí 1983 wọ́n sì yàn án láti du ipò fún sáà kejì kí ó tó kú lójijì ní march 1984 òǹkọ̀wé àti alákòóso tó gbámúṣe ni bákan náà ni ó ti di àwọn ipò bí olùwádìí àti olùdarí mú púpọ̀ gbajúmọ̀ ní benin - owena river basin authority nifor niser fao àjọ oúnjẹ àti ajẹmọ́-ọ̀gbìn-àti-ọ̀sìn ní milan ìtàló àti ẹ̀ka ìṣàkóso ètò ajẹmọ́-ohùn- ọ̀gbìn-àti-ọ̀sìn tí ìjọba àpapọ̀ naijiria federal agricultural coordinating units facu ọláyídé ti gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àpilẹ̀kọ jáde ní àwọn ìwé àtìgbàdégbàjọ́nà tí orílẹ̀èdè àti jọ́nà àgbáyé ajẹmọ́-ìmọ́ báyéṣerí èyí tí ó gbayì jù ni àpilẹ̀kọ rẹ̀ lórí ìṣòro oúnjẹ orílẹ̀èdè nàìjíríà tí ó kà ní 1974 tí ó jáde nínú ìwé àtìgbàdégbà jọ́nà ti ibùdó-ìmọ̀ ìwádìí ajẹmọ́ ìbáraẹnigbépọ àti ọrọ̀ ajé tí orílẹ̀èdè nàìjíríà - nigerian institute of social and economic research niser bákan náà ni ó jẹ́ òǹkọ̀wé ogúnlọ́gọ̀ àwọn ìwé ní ọrọ̀ ajé àtúpalẹ̀ àti tíọ́rì ọrọ̀-ajé àti ọrọ̀-ajé ajẹ́mọ́-ohun ọ̀gbìn àti ọ̀sìn
eniola ajao eniolá àjàó jẹ ọmọ orilẹ-èdè nàìjíríà òṣeré tíátà ni ìlú ẹ̀pẹ́ ni ó ti wá ó sì ti kópa nínú fíìmù tí ó lé ní márùndínlọ́gọ́rin ní iye a dáa mọ̀ gẹ́gẹ́bí òṣeré nípa bí ó ṣe ma ń fi ọgbọ́n-inú àti òye hàn nígbà tí ó bá ń kópa nínú eré ìgbé ayé rẹ̀ ẹniọlá àti ìbejì rẹ̀ ni àbígbẹ̀yìn nínú àwọn ọmọ mẹ́fà tí àwọn òbí rẹ̀ bí nígbàtí o ń dàgbà ẹniọlá lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ máíkẹ́lì mímọ́ ti ìjọ àǹgílíkàn ati ilé-ẹ̀kọ́ girama tí àwọn ológun ni ìlú ẹ̀pẹ́ gẹgẹbi ẹniọlá ti sọ ọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wù ú láti mú orí àwọn òbí rẹ̀ wu sibẹ̀ ìfẹ́ inú rẹ̀ ni láti jẹ́ òṣèré tíátà lati ìgbà èwe rẹ̀ ẹniọlá tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ nígbàtí ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ ní yaba àti ilé-ìwé -yunifásítì ìlú èkó níbi tí ó ti gboyè nínú imọ̀ ìṣirò bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọ̀lọpọ̀ awuyewuye ti wáyé lórí ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàrin ẹniọlá àti ọdúnladé adékọ́lá ẹniọlá ṣàlàyé pé kò sí ìbáṣepọ̀ mìíràn láàrin òun àti ọdúnladé adékọ́lá lẹ́yìn ti iṣẹ́
ibrahim chatta ibrahim chatta tí a bí ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹwàá ọdún 1970 jẹ́ gbajúgbajà olùdarí àti òṣèrè sinimá àgbéléwò ọmọ yorùbá láti ìpínlẹ̀ kwara lórílẹ̀ nàìjíríà ìgbé-ayé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ibrahim chatta kò fi bẹ́ẹ̀ kàwé pùpọ́ ìpele kẹta ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdìrì ní ó ti fi ẹ̀kọ́ kíkà sílẹ̀ ò wá pápá kẹ́kọ̀ọ́ lóríṣiríṣi nípa ère sinimá àgbéléwò kí ó tó di ìlúmọ̀ọ́ká ọ̀pọ̀ ni iṣẹ́ ló tí ṣe àkọsílẹ̀ kan sọ pé ó ti fìgbà kan ṣíṣe apèròsọ́kọ̀
ọdúnladé adékọ́lá ọdúnladé adékọ́lá tí a bí ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ́n oṣù kejìlá ọdún 1976 jẹ́ òṣèrè sinimá àgbéléwò ọ̀kọrin olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ yorùbá láti ìpínlẹ̀ èkìtì lórílẹ̀ èdè nàìjíríà àwọn sinimá àgbéléwò tó mú ọdúnladé adékọ́lá gbajúmọ̀ ni ìṣọ̀lá dúrójayé àṣírí gómìnà wa adébáyọ̀ àlàní abẹ́rẹ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá àgbéléwò yorùbá tó pọ̀ jáǹtirẹrẹ ìgbé-ayé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìlú abẹ́òkúta ní ìpínlẹ̀ ògùn ni ọdúnladé adékọ́lá ti ṣe kékeré rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ ekiti ní ìlú ọ̀tun-ekiti ni bí ó ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ọdúnladé adékọ́lá lọ sí ilé-ìwé akọ́bẹ̀rẹ̀ st john primary school abẹ́òkúta ó tẹ̀síwájú lẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní st peter's college ní abẹ́òkúta bákan náà ibẹ̀ ni ó ti gba ìwé - ẹ̀rí west african school certificate examination waec kí ó tó kàwé gboyè ẹ̀rí diploma ní ilé ẹ̀kọ́ gíga moshood abíọ́lá polytechnic lọ́dún 2018 ó tún kàwé gboyè bachelors of business administration ní ifáfitì ìjọba àpapọ̀ ní ìpínlẹ̀ èkó university of lagos
yemi shodimu yẹmí ṣódìímú ni wọ́n bí ní kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kínní ọdún 1960 january 29 1960 ní ìlú abẹ́òkúta ní orílẹ̀-èdè a nàìjíríà jẹ́ eléré orí ìtàgé atọ́kùn ètò olùdarí àti olùgbéré jáde ìgbòkègbodò ayé rẹ̀ wọ́n bi ní ìlú abẹ́òkúta tí ó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ ògùn ní apá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè nàìjíríàó lo ìgbà èwe rẹ̀ ní ìlú abẹ́òkúta í ààfin ọba aláké ilẹ̀ ẹ̀gbá ní bi tí ó ti ní àwòfín nípa àṣà yorùbá ó lè sí ilé-ẹ̀kọ́ kọ́wbáfẹ́mi awólọ́wọ́ university níbi tí ó ri gba ìwé ẹ̀rí bachelor of arts ba nínú ìmọ̀ ọ̀nà ìṣeré ìtàgé dramatic art lẹ́yìn èyí ni ó tẹ̀ síwájú ní fásitì ìpínlẹ̀ èkó níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí master of arts ma nínú ìmọ̀ mass communication iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ ní ọdún 1976 tí ó aì kópa tó lààmì laka nínú eré orí ìtàgé tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ village head master ó di ìlúmọ̀ọ́ká pẹ̀lú ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú ẹ̀dá ìtàn ó tún jẹ́ olú ẹ̀ ẹ̀dá ìtàn nínú eré orí ìtàgé tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ lekú gẹ́gè bí àjàní nínú eré yí túndé kèlání ṣe adarí rẹ̀
tiger woods
ṣọlá kòsọ́kọ́ ṣọlá kòsọ́kọ́-abíná tí a bí ní ọjọ́ keje oṣù kínní ọdún born 1976 jẹ́ oṣèrébìnrin àti olùdarí sinimá àgbéléwò ọmọ yorùbá lórílẹ̀-èdè nàìjíríà ó jé ọmọ bíbí àgbà òṣèrè jídé kòsọ́kọ́ ìgbé-ayé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ kíkà rẹ̀ ṣọlá kòsọ́kọ́ jẹ́ ó ọmọbabìnrin ìsàlẹ̀ èkó ní ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀ ó lọ sí ilé-ìwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ methodist primary school yaba ní ìpínlè èkó yaba kan náà ló ti kàwé sẹ́kọ́ńdìrì kí ó tó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ifáfitì olábísí ọ̀nábánjọ níbi tí ó ti kàwé gboyè nípa ìmò àyíká sociology bí ó tilè jẹ́ pé ìdílé ọba ni ṣọlá kòsọ́kọ́ tí wá bàbá rẹ̀ jídé kòsọ́kọ́ jẹ́ gbajúgbajà òṣèrè sinimá àgbéléwò èyí rán án lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí ó dára pọ̀ mọ́ iṣẹ́ tíátà ní kété tí ó parí ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdìrì kí ó tó di ìlúmọ̀ọ́kà lọ́dún 1999 nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ ọmọ olórííre ó gùnlé orúkọ tí bàbá rẹ̀ ti ní pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ bàbá rẹ̀ó fẹ́ ọkọ rẹ̀ abíọ́dún abíná ní ọdún 2012 wọ́n sì bímọ méjì
làmídì adédibú olóyè làmídì aríyíbí àkànjí adédibú ni a bí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹwàá ọdún1927 24-10-1927 sí 11-6-2008 jẹ́ alẹ́nulọ́ agbara alẹ́nulọ́rọ̀ apàṣẹ-wàá ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà olóyè olúṣẹ́gun ọbásanjọ́ ṣàpèjúwe rẹ̀ bí “bàbá fún ẹgbẹ́ òṣèlú pdp ìbí àti ẹbí rẹ̀ a bí olóyè adédibú ní agbègbè ọjà ọba ní ìlú ìbàdàn ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ oyè láti ìdílé ọba olúpòyí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olóṣèlú adédibú dara pọ̀ mọ́ ìṣèlú ní ọdún 1950 nígbà tí ó di ọmọ ẹgbẹ́ peole's party tí ó sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlti action group lábẹ́ olóyè ọbáfẹ́mi awólọ́wọ̀ lẹ́yìn náà ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú national party of nigeria npn ẹgbẹ́ tí ọ̀gbẹ́ni àdìsá akinloyè àti richard akínjíde ó di onípò pàtàkì nínú òṣèlú ilẹ̀ nàìjíríà ní àkókò ìjọba ológun ọ̀ọ̀gágun ibrahim babangida lákòókò yí ni ẹgbẹ́ òṣèlú npn lo ànfàní ètò ìdìbò ojúmitó open ballot láti ṣe màdàrú ọ̀nà tí a lè gba ṣàpèjúwe ìlànà òṣèlú tirẹ̀ ni lílo àwọn ọmọ gànfé àti fífi ipá mú ọmọ ayo rẹ̀ tàbí alátakò rẹ̀ ṣe oun tí ó bá fẹ́ tí ó sì ma ń mú jàgídí-jàgan lọ́wọ́ lọ́pọ̀ ìgbà a gbọ́ wípé kò fẹ́rẹ̀ sí olóṣèlú kan tí ó goróyè ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ tí kò gbàṣẹ gbòntẹ̀ adédibú kí ó tó dépò àṣẹ èyí ló fàá tí wọ́n fi ń pèé ní òpómúléró òṣèlú ilẹ̀ ìbàdàn wọ́n yan ọmọ rẹ̀ kan kamorudeen adékúnlé adédibú gẹ́gẹ́ bí aṣojú -ṣòfin sílé aṣòfin àgbà fún ẹkùn ọ̀yọ́ south ní oṣùkẹ́rin ọdún 2007 senator teslim fọlárìn í wọ́n dìbò yàn sílé aṣòfin àgbà gẹ́gẹ́ bí senator fún ẹkùn àrin-gbùngbùn ọ̀yọ́ oyo central ni ó jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ lẹ́yìn adédibú ẹ̀wẹ̀ olóyè rasheed ládọjà tí ó jẹ gómìnà ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ní oṣù karùún ọdún 2003 náà tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ lẹ́yìn rẹ̀ àmọ́ òun àti adédibú padà di oje ọrọ́ àti ojú tí wọn kìí fẹ́ rí ara wọn lórí tani yòó yàn síàwọn ipò kọmíṣọ́nà ní ọdún 2004 ikú rẹ̀ adédibú kú ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹfà ọdún 2008 sí ilé ìwòsàn university college tí ó wà ní ìlú ìbàdàn nígbà tí ó wà ní ipò ẹ̀karún ti ilẹ̀ ìbàdàn gẹ́gẹ́ bí ipò tí ẹbí rẹ̀ wà sí ti olúbàdàn ti ilẹ̀ ìbàdàn
ìpín àgbádárìgì badagry ìpín àgbádárìgì ni ìpín kan lára ẹ̀ka tí ọ́ ń ṣe àkóso ní ìpínlẹ̀ èkó ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ìtàn rẹ̀ ìpín àgbádárìgì kópa tó lọ́ọrìn nígbà tí a bá ń ṣe àgbéyẹ̀wò nínú ìtàn ilẹ̀ olómìnira nàìjíríà àti europe gẹ́gẹ́ bí àgbádárìgì ṣe jẹ́ agbègbè tí wọ́n ti kó ẹrú tí ó pọ̀ jùlọ nínú iṣẹ́ òwò ẹrú lágbàáyé ṣáájú ìjẹ gàba àwọn èèbó amúnisìn ìpín àgbádárìgì tún jẹ́ ibi tí àwọn èèbó aláwọ̀ fundun ti kọ́kọ́ polongo ẹ̀sìn krístẹ́nì ní ikẹ̀ nàìjíríà ní ọdún 1842 wọ́n kọ́ ilé alágbèékà síbẹ̀ láti fi ṣebìrántí agia cenotaph àwọn ìjọba ìbílẹ̀ rẹ̀ ìpín àgbádárìgì ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rin àwọn ìletò tó yi ká àwọn ẹ̀ka àqórì
mowo badagry mowó jẹ́ ìlú kan ní àgbádárígí ìpínlẹ̀ èkó ní apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ nàìjíríà ìlú náà kò jìnà púpọ̀ sí agbègbè ìloro ibodè sẹ̀mẹ̀ kò ju ìwọ̀n kìlómítà diẹ̀ lè àwọn tí wọ́n tó ìdá 78897 àwọn olùgbé tí ó ń gbé níbẹ̀ lọ púpọ̀ nínú àwọn olùgbé ìlú yí ni wọ́n jẹ́ olùṣòwò àti olùtajà tí wọ́n sì ma ń lè láti ra àwọn ọjà títà wọn ní sẹ̀mẹ̀ agbọ́ wípé àwọn ilé tí wọ́n tó ìdá ọgọ́fà 600 tí ó wà ní orí ilẹ̀ tí ó tó àádóje 65 hẹ́kítà ni ilé-iṣẹ́ àjọ ọlọ́pàá ilẹ̀ nàìjíríà bì wo lulẹ̀ láti lè kọ́ ilégbèé àwọn ọlọ́pàá sí ní ọdún 2013
adé olúfẹkọ́ adé olúfẹkọ́ orúkọ ìbí adé àbáyọ̀mí olúfẹkọ́ ọjọ́ìbí 1980 jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n tí ìmọ̀ rẹ̀ jinlẹ̀ eniti ise re ni imo eda tayo ni igbimo awon to n pero lori komasi eyi ti o le jeki oro aje lo dede adé olúfẹkọ́ je olukeko ti o ko eko lori imo tẹknọ́lọ́jì lati orile ede amẹ́ríkà o tun je oludari ise ati alapero kakiri agbala aiye omo bibi ìjẹ̀bú ikorita ibiti imo re ni orisirise iriri imo de ni o je ki o da pinnu ni odun 2007 lati da ile ise wiwo ajọṣepọ visual collaborative ibiyi je oju apejo fun awon oniimo eniyan ati isedasile o je oga patatata ninu awon ti o seto ilodede idari ni apejo yi o tun je konsultanti ni imo ti o to eniyan si ona to pe ni ibm
ere idaraya eré ìdárayá jẹ́ àṣà àti ọ̀nà ìdárayá jákè-jádò ilẹ̀ yorùbá nígbà tí ọwọ́ bá dilẹ̀ yorùbá bọ̀ wọ́n ní ohun gbogbo ni ìgbà àti àkókó ńbẹ fún ìran yorùbá fẹràn iṣẹ́ ṣíṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ wọ́n sì gbàgbọ́ wípé iṣẹ́ ni òògùn ìṣẹ́ ṣùgbọ́n bí wọ́n ti fẹràn iṣẹ́ tó ó ní àwọn àkókò tí wọ́n máa ń fi sílẹ̀ fún eré ṣíṣe ninu ọjọ́ kọ̀ọ̀kan iru akoko bẹẹ ni a mọ si akoko ere idaraya eyi fi han pe kii ṣe awọn oyinbo ni o mu ere idaraya de ilẹ yoruba yoruba ka ere idaraya si ere pataki nitori o ye wọn pe ipa ti o gbopọn ni ere idaraya nko ninu alaafia ara ati ẹmi gigun bi ere idaraya ṣe wa fun awọn ọmọ ọwọ ati ọmọ irinsẹ naa ni o wa fun ọmọde ati agbalagba bi ere abẹle ti wa naa ni ti an ṣe ni ita wa oriṣiiriṣii ni ere idaraya ti a maa n ṣe nilẹ yoruba pupọ si ni ko mu agbara dani nitori lẹyin iṣẹ agbara ni yoruba nṣe wọn wọn wa lati fun ara ni isinmi lẹyin iṣẹ oojọ awọn ere idaraya kan wa fun ilera lati mu ki ara laagun awọn miiran wa fun inaju awọn kan wa gẹgẹ bii amuṣẹya bẹẹ ni awọn isọri miiran wa fun dida ọpọlọpọ laraya lara ere idaraya yoruba ni ere ayo arin okoto ijakadi kannakanna ere oṣupa ere alọ adendele ki-ni-n-lẹjẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ ayò títa ayò títa jẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn eré ilẹ̀ yorùbá ti wọn maa fi dárayá l'ẹhin iṣẹ́ oojọ wọn eré abẹ́lé tí kò gba agbára ni eré ayò bẹẹ si ni ori ìjokòó ni wọ́n ti nta á ọ̀sán tàbí ìrọ̀lẹ́ ni wọ́n ń ta ayò ní ìgbà tí wọ́n bá ṣíwọ́ oko wá sí ilé eré l'a nfi ọmọ ayò ṣe òwe nai gbólóhùn yì l'ede yoruba o si jasì pe eré ayo kii ṣe nkan ìjà tabi ohun ti o le mu ìkùnsínú wa bi a ba si tun f'eti si awọn àgbàlabà nigbamiran a o gbọ ti wọn nsọ bayi pe t'ọmọdé t'agba ni iyọ mọ ọmọ ayò eyi tun fihan kedere pe ko si ẹni ti ki i ta ayò eèyàn méjì ni ó má ń jòkóò láti tayò wọn yóò jókòó dojú kọ ara wọn ọpọ́n ayò yóò sì wà láàrin wọn ọpọ́n ayò jẹ ohun èlò ayò títa ti o ni ihò méjìlá tí à ń da ọmọ ayó si tí mẹ́fà-mẹ́fà kọjú sí ara wọn ihò mẹ́fà yóò wà lọ́dọ̀ ẹni kì-ín-ní ihò mẹ́fà yóò wà lọ́dọ̀ ẹni kejì l'oju ọpọ́n ayò mìíràn ihò náà lè jẹ́ mẹ́rìnlá ihò kọ̀ọ̀kan tò lé yìí a si maa wa ni apá ọtún ati apá òsi ọpọ́n naa ihò meji yi wa fun lilo awọn ọ̀tayò lati tọ́jú ayò ti wọn bá jẹ sí nígbà mìíràn àwọn ènìyàn máa ń gbẹ́ ihò sí orí ilẹ̀ tí yóò dúró gẹ́gẹ́ bí ọpọ́n ayò ṣùgbọ́n ohun ti a kàn nípá ni ihò mejila ojú ọpọ́n ayò bi ọpọ́n ayò bawa bi ko ba si ọmọ ayò ayò ko ṣe ta rara iyẹn tumọ si pe ayòtita kò lè rọrùn láìsí èso ayò tí a tún mọ̀ sì ṣẹ́yọ̀ ọmọ ayò jẹ kóró inu èso igi kan bayi eso yìí dán lára púpọ̀ ó sì le kóró kóró ara rẹ yóò ma yọ́ kọ̀rọ́ ọmọ ayò mẹ́rin ní ń gbé inú ihò kọ̀ọ̀kan eyi jasi pe ọmọ ayò méjìdínláàdọ́ta ni mbẹ l'oju ọpọ́n ayò awọn òtayò yóò si pin l'aarin ara wọn dọ́gbadọ́gba ọmọ ayò gbọ́dọ̀ pé kí eré ayò tóó bẹ̀rẹ̀ ṣugbọn bí a kò bá wá rí àdán à máa fòòsẹ̀ ṣẹbọ bi òùngbẹ ayò ba ngbẹ awọn eniyan ti nwọn ko si le ri ọkan ninu awọn ohun ti a fi nse ọmọ ayò a máa ń lo òkúta wẹ́wẹ́ láti fi dípò ọmọ ayò a sì ń lo kóró iṣin pẹ̀lú eèwọ̀ ni kìí a ta ayò ní alẹ́ àti àárọ̀ kùtùkùtù ìdì nìyí tí a fi ń pa òwe pé bí alẹ́ bá lẹ́ à fi ọmọ ayò fún ayò eré ayò ni ànfaani pupọ o máa ń pani lẹ́rìn-ìn a o gbe apá a o gbe ẹsẹ̀ ara wa yóò si ya gágá eré ayò a máa mú ni ronú jinlẹ̀ ti o si le mu ki ọpọlọ ẹni gbooro si i o nmu ni ronu kiakia o si mu ki ojú wa riran sìwaju si eré àrín bi awọn eniyan ba fẹ ta àrín tabi ṣe eré àrín nwọn a wa èso ti a npè ni seeàrín lọ si inu igbó èso kan bayi ti a nri ṣa ninu igbo la npe ni àrín ẹ̀so ìgi tí ó n fà bí i pákuǹ ni àrín èso náà dan lára ó sì tóbi púpọ̀ ju ọmọ ayò lọ àwọ̀ páànù tó dógùn-ún ni ó ní èniyàn mẹta ni nta iru àrín yi lẹ́ẹ̀kánnáá ki ọ́mọdé tabi awọn géndé to pade nibi eré àrín nwọn a ti wọ iho ti ko ju bi isun meji tabi mẹta wọn yóò tẹ́ ẹní pàkìtí lé ihò náà lórí bakannaa ni nwọn o si ti wá àrín bi mẹfa mẹfa tabi ju bẹẹ lọ dani àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yóò ta àrín wọn sínú ihò tí a tẹ́ ẹní sí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo àwọn àrín náà ti a npe ni apẹ àrín ẹnikẹ́ni tí àrín rẹ̀ bá jáde láti inú ihò yóò san àrín mìíràn fún ẹni tí ó ni àrín tó lé e síta sugbọn bi àrín awọn mejeeji ti o ṣẹkù si'nu ihò ba tuka lẹẹkannaa a jẹ'pe awọn mejeeji naa ta ọ̀mi ẹni tí àrín rẹ̀ bá sì gbẹ̀yìn sínú ihò ni ó borí ànfaní to wa lara ere arin pọ janti rẹrẹ lara ẹ ni pe o nkọ ni l'ẹkọ lati mọ bi a ti nf'ojú sun ohun òkèèrè o nfun oju wa l'agbara lati riran dárádárá ati bẹẹ bẹẹ lọ bojú bojú boojú boojújẹ́ ọ̀kan lára erémọde tí a máa nfi ọ̀yàyà ṣe eniyan bi mẹjọ tabi mẹwa le ṣe eré boojú boojú nínú eré boojú boojú a máa n bo ènìyàn kan lójú èyí le jẹ obìnrin tàbí ọkùnrin lẹ́yìn tí a bá bo ẹnìkan loju tan àwọn ọmọdé yòóku yoo lọ sá pamọ́ nigba ti nwọn ba nfi ara pamọ bayi ẹni t'o ndiju yóò maa kọrin pe bo ojú bo o ojú o awọn ti o nfi ara pamọ náà yóò máa dahun pe eee boojú boojú o olórò ń bọ̀ ẹ para mọ o ṣé kí ń ṣi ṣì ṣì ṣí ṣí ẹni tó lóro bá mu á pa á jẹ ò ojú ń ta mí ò lẹhin igba ti gbogbo wọn ba si ti fi ara pamọ tan nwọn yóò sọ pe ki o ṣi i nigba ti a ba ti ṣi aṣọ loju ẹni náà tan ko ni mọ ibi ti yóò lọ rara lẹhin igba pipẹ tabi diẹ o le lọ ri ẹnikan nibi ti o sa pamọ sí wípé ó rí ẹni yí kò sọ pé ki ọwọ rẹ̀ tẹ ẹ nitori ni riri ti o ti ri i yẹn ẹni ti à ri náà ko ni duro rara yóò yara ba ẹsẹ rẹ̀ sọrọ lati salọ ṣugbọn ti ẹni ti o nwa wọn kiri yi ba ṣe ri ẹnikan mu ẹni tí ó ba mú ni yóò ṣe eré boojú boojú mìíràn nigba ti ere ọ̀jọ́ yi ba fẹ ka'sẹ nilẹ ara ẹni ti nwọn ba ti mu yóò wa kan gógógó oun náà yóò si gbìyànju gidigidi lati ri ẹnikan mu nitori yóò maa bẹ́rù ki eré má bàá ku mọ oun lori ẹni ti ere ba ku mọ lórí awọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yóò mu u si aarin nwọn yóò si kọrin lee wipe ẹni oro ku mọ lori ko ṣe í ba ṣere alẹ orin yi ni nwọn yóò si kọ ti nwọn yóò si tu mọ ọ loju ti olúkúlùkù yóò si gba ile baba rẹ̀ lọ itọkasi 1 awọn àṣà ati òrìṣà ilẹ yoruba lati ọwọ olu daramola ati adebayo jeje 2 ẹ̀kọ́ èdè yorùbá òde òní lati ọwọ egbẹ́ akọ́mọlédè yorùbá 3 àkọ́bẹ̀rẹ̀ yorùbá lati ọwọ razat publishers 4 5
òrìsà
monkaen kaenkoon monkaen kaenkoon je olorin omo orile-ede tháílàndì
tai orathai tai orathai je olorin omo orile-ede tháílàndì
cory booker cory anthony booker jẹ oloselu orilẹ amẹrika kan oṣiṣẹ igbimọ fun new jersey o jẹ ọmọ ẹgbẹ ti democratic party arakunrin rẹ ni cary booker ii ati pe baba rẹ jẹ cary booker ni ọdun 1969 awọn obi rẹ ja lile lodi si ẹlẹyamẹya nipa tẹnumọ lati ra ile kan ni agbegbe nibiti a ko gba eniyan dudu he is a friend of kirsten gillibrand ni ọjọ 1 ọjọ kínní ọdun 2019 o kede pe oun yoo ṣiṣẹ fun idibo alakoso amẹrika 2020 jimmy carter nireti pe o ṣiṣẹ fun alakoso