raw_text
stringlengths
2
128k
mary durojaye mary adeola temitope asake durojaye tabi nìkan mary durojaye tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlá osù keje ọdún 1990 ní ìlú jẹ́ ògbóǹtarìgì agbá bọ́ọ̀lù inú agbọ̀n obìnrin ti ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì tí ó sẹ̀ wá láti orílẹ̀-ède nàìjíríà
ileri amukamara promise amukamara tí a bí ní ọjọ́ kejìlélógún osù kẹfà ọdún 1993 jẹ́ agbá bọ́ọ̀lù inú agbọ̀n ti orílẹ̀-ède nàìjíríà-amẹrika fún charnay basket bourgogne sud fra àti ẹgbẹ́ orílẹ̀-ède nàìjíríà ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé àti ẹ̀kọ́ promise ga ní ẹsẹ̀ bàtà marun ó lé inch mẹsan175 cm ó jẹ́ ọmọ ilé-ìwé gíga ti arizon...
ebenezer andrews ebenezer andrews ni a bini ọjọ mọkan lèèlogun óṣu may ni ọdun 2000 jẹ elere badminton ti ilẹ ghana ni óṣu april ọdun 2019 elere naa jẹ ọkan lara team ilẹ ghana to gba ami ọla ti idẹ ni idije ti gbogbo ilẹ afirica to waye ni port harcourt naigiria igbèsi ayè arakunrin naa andrews wa lati winneba ni ilẹ ...
victor mbaoma nigerian footballer victor mbaomati a bini ọjọ ogun óṣu kẹ̀wá ọdun 1996 jẹ ogbon tarigi agbaabọlu ọmọ orílè-èdè nàìjíríà toun ṣèrè fun fc qizilqum gẹ̀gẹbi centre forward igbèsi aye arakunrin naa victor ni a bisi ilu eko arakunrin naa bẹrẹ iṣẹ rẹ pẹlu remo stars fc akwa united lẹyin naa ló lọsi enyimba fc ...
michael baah michael opoku baah jẹ elere badminton orilẹ ede ghana ti a bini ọjọ keji lèèlogun óṣu july ọdun 1996 igbèsi àyè ati àṣèyọri àràkunrin naa michael wa lati takordia ni órilẹ ede ghana to si jẹ akẹẹkọ ti ile iwe giga cape coast ni óṣu february ọdun 2018 michael ati akẹgbẹ rẹ abraham ayittey emmanuel yaw donko...
emmanuel botwe emmanuel botwe ni à bini ọjọ ogun óṣu may ọdun 1999 jẹ elere badminton órilẹ ede ghana iṣẹ emmanuel ati àṣèyọri ni ọdun 2010 botwe kopa ninu idije gbogbo ilẹ afirica to waye ni mauritius ni ọdun 2013 elere naa kopa ninu idije junior badminton gbogbo ilẹ afirica to waye ni algeria botwe pẹlu awọn akẹgbẹrẹ...
getaneh kebede getaneh kebede gebeto àmháríkì ጌታነህ ከበደ ti a bi 2 kẹrin 1992 jẹ agbabọọlu alamọdaju ara etiopia kan ti o ṣere bi ikọlu fun ologba premier league ti wolkite city
nana abdullahi nana aisha abdullahi tí a bí ní ọdun 1960 tí ó sì fi ayé sílè ní ọjọ́ kàrún-ún oṣù kẹta ọdún 2014 jẹ́ adájọ́ àti agbejọ́rò tẹ́lẹ̀rí ní nàìjíríà ní ọdún 2010 abdullahi di adájọ́ high court ìpínlè jigawa òun sì ni obìnrin àkọ́kọ́ tó máa kọ́kọ́ dé ipò náà jigawa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní apá àríwá oríl...
mary odili mary ukaego odili née nzenwa cfr tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kárùn-ún ọdún 1952 jẹ́ adájọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti ìyàwó peter odili tó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ rivers láti ọdún 1999 sí 2007 ààrẹ goodluck jonathan ni ó yàn án gẹ́gẹ́ bíi adájọ́ 'associate' ti ilé-ẹjọ́ gíga ti nàìjíríà jsc àti pé olóy...
rosaline bozimo nigerian lawyer rosaline patricia irorefe bozimo ọjọ́-ìbí ọjọ́ kìíní oṣù kìíní ọdún 1946 jẹ́ agbẹjọ́ro ọmọ nàìjíríà tí wọ́n yàn-án gẹ́gẹ́ bí adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ delta láti ọjọ́ kẹta-lé-lógún oṣù kẹta ọdún 2003 ó fẹ̀hìn ipò tì ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní ọdún 2011 tí honorable justice abiodun smith sì tèlé ẹ...
rahila hadea cudjoe onísòfin nàìjíríà justice rahila hadea cudjoe ofr ọjọ́ ìbí jésù ojọ́ kẹfà osù kẹwàá ọdún 1948 jẹ́ onísòfin kan ri to àti adájọ àgbà kan ri ni ìpínlè kaduna o jẹ́ obìnrin àkọkọ́ láti dé ipò adájọ àgbà ní ìpínlè kaduna tí ó sì ṣe ìsìn láti ọdún 1996 títí dé ọdún 2014 ó tún jẹ́ agbẹjọ́rò obìnrin àkọkọ́...
eberechi wike nigerian judge adájọ́ eberechi suzzette wike tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù karùn-ún ọdún 1972 jẹ́ adájọ́ ní ilé-ẹjọ́-ńlá ti òun ni ìyàwó gómìnà ìpínlẹ̀ rivers gómìnà ezenwo nyesom wike láti ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2015
saint george sc saint george sports club amharic ቅዱስ ጊዮርጊስ ስፖርት ክለብ kidus giorgis sport club ti inagijẹ rẹ ń jẹ kidus giorgis jẹ ogbontarjgi ẹgbẹ agbabọọlu afẹsẹgba kan ti a da silẹ ni addis ababa ethiopia ẹgbẹ yí ń gba bọọlu ni ipele oke ti bọọlu afẹsẹgba ajumọṣe tí itiopia premier league ethiopia ti a da ni ọdun 1935...
daisy w okocha daisy wotube okocha tí a bí ní ọjọ́ keedogun oṣù kínní ọdun 1951 jẹ́ adájọ́ àgbà ìpínlè rivers òun ni ó ní ìkáwọ́ high court of justice àti judicial service commission gọ́minà ezenwo wike ni ó yàn sípò náà ní ọjọ́ kẹrin oṣù kínní ọdun 2016 ó sì di ipò náà mú títí di ìgbà tí ó fi ipò náà kalẹ̀ ní ọjọ́ mee...
monica dongban-mensem monica bolna'an dongban-mensem cfr ọjọ́-ìbí ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹfà ọdún 1957 jẹ́ adájọ́ ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà ó jẹ́ ààrẹ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní nàìjíríà ìpinnu yíyán rẹ̀ jẹ́ ìfọwọ́sí ní ọjọ́bọ̀ oṣù kẹfà ọjọ́ kọkànlá ọdún 2020 àwọn àmì ẹ̀yẹ rẹ̀ ní oṣù kẹwàá ọdún 2022 ọlà orílẹ̀-èdè nàìjíríà kan t...
binta fatima nyako ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù karùn-ún ọdún 1959 ni wọ́n bí binta nyako ní ìjọba ìbílẹ̀ remawa ní ìpínlẹ̀ katsina wọ́n bí i sí ilé ẹbí tí wọ́n gbìyànjú láti ṣètò ayé wọn ó dàgbà ó sì lọ sí ilé-ìwé ní bauchi nígbà náà ó gbìyànjú láti gba ẹ̀kọ́ tó yẹ yálà àwọn ìṣòro tó dojú kọ èyí ló sì mú kí iṣẹ́ rẹ̀ gboyè nísì...
kudirat kekere-ekun nigerian jurist born 1958 kudirat motonmori olatokunbo tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí kudirat kekere-ekun cfrcfr ọjọ́ ìbí ọjọ́ keje oṣù karùn-ún ọdún 1958 jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí ó jẹ́ adájọ́ ilé-ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ẹ̀kọ́ rẹ̀ a bí kekere ekun ní ọjọ́ keje oṣù karùn-ún ọdún 1958 ní...
olubunmi olateru olagbegi olubunmi olateru olagbegi ofr jẹ́ ọmọ ilé-ìgbìmọ̀ nàìjíríà àti adájọ́ àgbà tẹ́lẹ̀ ti ìpínlẹ̀ ondo nàìjíríà ó tún jẹ́ olùkàwé ní yunifásítì afe babalola ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ ìdílé omitowoju ní ilé-ifẹ̀ ìlú kan ní ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ni wọ́n bí adájọ́ olubunmi ìyàwó sínú ìdílé ọlágbẹ́gi ìdílé ọba ní ...
olatokunbo olopade olatokunbo oduyinka olopade con jẹ́ onímọ̀ amòfin lórílẹ̀-èdè nàìjíríà ẹni tí wọ́n yàn sípò àgbà onídàájọ́ ní ìpínlẹ̀ ogun òun ni ìdájọ́ obìnrin àkọ́kọ́ láti ìgbà ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀ náà ayé àti iṣẹ́ rẹ̀ ọdún 1953 ni wọ́n bí olopade ó kẹ́kọ̀ọ́ alákọbẹ̀rẹ̀ àti gíràmà ní ilé-ìwé queens èdè àti adéọlá odùt...
uwani musa abba aji uwani musa abba aji tí a bí ní ọjọ́ keje oṣù kọkànlá ọdun 1956 jẹ́ adájọ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti adájọ́ ilé-ẹjọ́ àgbà orílẹ̀-èdè ti orílẹ̀-èdè nàíjíríà àárò ayé àti èkó rẹ̀ wọ́n bí aji ní ọjọ́ keje oṣù kọkànlá ọdun 1956 ní ìlú gashua ìpínlè yobe ó tètè bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ìwé central primary...
fadima murtala aminu fadima murtala aminu jẹ́ ọmọbìnrin tí a bí ní ọjọ́ ógbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 1968 ní zaria ìpínlẹ̀ kaduna ní ilẹ̀ nàìjíríà ó jẹ́ adájọ́ pẹ̀lú ilé-ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà
toyin bolaji adegoke toyin bolaji adegoke tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún osù ògún ọdún 1964 jẹ́ adájọ́ ilé-ẹjọ́ ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀-èdẹ̀ nàìjíríà ìlú ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ní wọ́n bí í sí èkọ́ ó ka ìwé mẹ́wàá rẹ̀ tán ní ojuku grammar school ní ọdún ní ọdún 1981 ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní fásítì maiduguri ní ìpínl...
modupe omo-eboh modupe omo-eboh ọdun 1922 ọjọ́ karúndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdun 2002 jẹ́ agbẹjọ́rò ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti ọ̀jọ̀gbọ́n amòfin tí ó jẹ́ adájọ́bìnrin àkọ́kọ́ ní orílẹ̀ èdè náà ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ wọ́n bí modupe akingbehin sí ìpínlẹ̀ èkó ní ọdún 1922 ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ-ọmọbìnrin oshodi tapa gbajúgbaj...
nkemdilim izuako nigerian judgenkemdilim amelia izuako jẹ́ adájọ́-bìnrin ti orilẹ̀-èdè nàìjíríà láti ọdún 2009 ó ti wà lára ọ̀kan lára àwọn adájọ́ mẹ́ta àkọ́kọ́ ní united nations dispute tribunal undt ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀ izuako gba kẹ́kọ̀ọ́ níoa òfin ó sì gba ìwé-ẹ̀rí ẹ̀kọ́ náà ní obafemi awolowo university ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́...
modupe omo-edeh
kelvin katey carboo kelvin katey carboo tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹta oṣù ẹrẹ́nà ọdún 2000 ó jẹ́ eléré ìdárayá bọ́ọlù àláfọwọ́gbá volleyball tẹ́lẹ̀ ní orílẹ̀-èdè ghana ìgbèsi ayè ati iṣẹ́ rẹ̀ wọ́n bí carboo ní ìlú accra ní orílẹ̀-èdè ghana ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹta oṣù ẹrẹ́nà ọdún 2000 carboo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gégẹ́ bíi...
lahcen ahidous moroccan boxer lahcen ahidous ni a bini ọjọ kẹtalaóṣu april ọdun 1945 jẹ̀ afẹṣẹja órilẹ ede morocco àṣèyọri lahcen kopa ninu olympics ti summer ni ọdun 1964 ati 1968
àtòjọ àwọn adájọ́bìnrin ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà àwọn adájọ́bìnrin ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà ni
kudirat abíọ́lá
morenike olasumbo obadina morẹ́nikéjì ọlásùḿbọ̀ ọbádínà tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù kẹwàá ọdún 1963 jẹ́ adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga ìjọba-ìpínlẹ̀ èkó tí ó wà ní igbóṣeré ní nigeria ìjọba ìpínlẹ̀ èkó yàn án gẹ́gẹ́ bí adájọ́ lọ́dún 2001
hadiza rabiu shagari hadiza dawaiya shagari tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí hadiza shehu shagari ọdun 1940/41 ọjọ́ kejìlá oṣù kẹjọ ọdun 2021 jẹ́ gbajúmọ̀ ènìyàn obìnrin àkọ́kọ́ ilẹ̀ nàìjíríà láàrin 1979 to 1983 àti ìyàwó shehu shagari nígbà tí àwọn méjèèjì wà láyé òun àti àwọn ìyàwó shagari tó kù jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ ilẹ̀ nàìjíríà...
mustapha adnane moroccan weightlifter mustapha adnane ni a bini ọdun 1931 to si ku ni ọjọ keji dinlọgbọn óṣu april ọdun 2006 jẹ àdánù gbigbe ti órilẹ ede morroco àṣèyọri mustapha kopa ninu olympics summer ti ọdun 1960 ati 1964
vivian yusuf nigerian olympic judoka vivian aminu yusuf ni a bini ọjọ kẹjọ óṣu kẹjọogún ni ọdun 1983 ó jẹ ọkan ninu awọn óbinrin to kopa ninu ere judo ni órilẹ ede naijiria ninu abala idaji heavyweight àṣèyọri vivian gba ami ọla ti idẹ ni ere ti gbogbo ilẹ afirica ni ọdun 2007 to waye ni algiers ati idije judo ti ilẹ a...
ijeoma lucia ojukwu ijeoma lucia ojukwu jẹ́ ọmọbìnrin tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejìlá ọdún 1966 ní kaduna ní ilẹ̀ nàìjíríà ó kọ́kọ́ gba satífíkéètì òye waec àkọ́kọ́ rẹ̀ ní ọdún 1985 ó jẹ́ adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó wá láti ìpínlẹ̀ abia ayé rẹ̀ arábìnrin náà wá láti akuma ní ìjọba ì...
zainab bage abubakar zainab bage abubakar jẹ́ adájọ́ ní ilé-ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà wọ́n bí i ní ọjọ́ ọ̀kàn-dín-lógún oṣù kọkànlá ọdún 1964 ní zuru ní ìlú kebbi
joyce obehi abdulmalik hon justice joyce obehi abdulmalik jẹ́ adájọ́ ní ilé-ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà a bí i ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù keje ọdún 1968 ní london ní ilẹ̀ united kingdom ó jẹ́ ọmọ ìwọ̀-oòrùn esan ní ìpínlẹ̀ edo
dorcas venenge agishi dorcas venenge agishi tí a bí ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹrin ọdún 1961 jẹ́ adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ̀-èdè nàìjíríà a bí i ní wukari ní ìlú taraba ó wá láti ìpínlẹ̀ benue àti pé ó jẹ́ ìyàwó sí solomon agishi tí ó wá jẹ́ ọkọ rẹ̀
beni lar beni lar tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹjọ ọdun 1967 jẹ́ olóṣèlú ọmọ ẹgbẹ́ people's democratic party láti ìpínlẹ̀ plateau nàìjíríà ó jẹ́ asojú ìkọ̀ langtang north àti langtang south ti ìpínlẹ̀ plateau ní ilé ìgbìmò asofin kékeré a kọ́kọ́ yán sí ipò náà ní 2007 wọ́n sì tún dìbò yán ni ọdun 2019 fún sáà kẹrin ní i...
abdelhak achik moroccan boxer abdelhak achik tí a bí ní ọjọ́ kọkànlá osù kẹta ọdun 1959 jẹ́ afẹ̀ṣẹ́jà órilẹ̀-èdè morocco ìgbà kan rí afẹ̀sẹ́jà náà gba àmì ọlá ti idẹ ní olympic tí summer tó wáyé ní seoul àṣeyọrí abdelhak kópa ninu ére olympic ti ọdun 1988ótoáyé eíni seoulíni round 64 32 16 quarterfinaà ati semifinalíni...
ezzaki badou moroccan footballer born 1959 ezzaki badou ni a bini ọjọ keji óṣu kerin april ọdun 1959 ti inagijẹ rẹ njẹ zaki jẹ a-ko-ni-mo-o-gba coach ere bọọlu alafẹsẹgba ati elere tẹlẹ ri to ṣèrè gẹgẹbi asole goalkeeper órilẹ ede morocco iṣẹ ezzaki ezzaki ṣoju as salè wydad ac rcd mallorca ati fath union gẹgẹbi elere ...
catherine obianuju acholonu catherine obianuju acholonu tí a bí ní ọjọ́ kẹrindínlógún oṣù kẹ̀wá ọdun 1951 ọjọ́ méjìdínlógún oṣù kẹta ọdun 2014 jẹ́ olùkọ̀wé olóṣèlú àti ajàfẹ́to ẹni ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà òun ni senior special adviser ssa sí ààrẹ olusegun obasanjo lórí ọ̀rọ̀ àwòrán àti àsà ó sì tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ associ...
bilkisu yusuf nigerian journalist bilkisu yusuf tí àwọn ènìyàn tún mọ̀ sí hajiya bilkisu yusuf ọjọ́ kejì oṣù kejìlá ọdun 1952 ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsàn 2015 jé oníròyìn àti akọròyìn fún àwọn ilé ìròyìn tó gbajúmọ̀ ní abuja kano àti kaduna ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà bilkisu jẹ́ ẹ̀yà ọmọ yorùbá máa mọ́ hausa mùsùlùmí àti a...
folashade adekeko adesiyan olubanjo adájọ àgbà ní orílé èdè nàìjíríà chief magistrate folashade adekoke adesiyan olubanjo ọjọ́ ìbí jé ojọ́ kejì osù keje ọdún 1968 jẹ́ adájọ àgbà tí wọn bí sí ìpínlè katsina ní orílé èdè nàìjíríà tí ó sì ṣe ìsìn fún ìjọba láti ọọ́ kíni oṣù kẹjọ odun 2003 tí di ọdún 2009 ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀ ìgbé a...
mustapha el biyaz moroccan footballer mustapha el-biyaz ni a bini ọjọ kejila óṣu february ni ọdun 1960 ni taza jẹ elere bọọlu afẹsẹgba defender ti órilẹ ede morocco to ti fi ẹhinti el biyaz ṣèrè fun club kac marrakech ninu botola àṣèyọri biyaz kopa ninu olympic summer ti ọdun 1984 ati cup fifa àgbayè ti ọdun 1986 ni ọd...
aziz bouderbala moroccan footballer abdelaziz el idrissi bouderbala ni a bini ọjọ kẹrin din lọgbọn óṣu december ni ọdun 1960 jẹ elere bọọlu afẹsẹgba nigba kan ri ni ọdun 2006 elere naa jẹ okan lara awọn igba elere bọọlu afẹsẹgba to dara ju ni ilẹ afirica ti caf yan fun adọta ọdun sẹyin iṣẹ elere naa ati àṣèyọri aziz bẹ...
felicity okpete ovai felicity okpete ovai tí a bí ní 1961 jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọengineer àti ọ̀mọ̀wé láti degema ti ìpínlè rivers nàìjíríà ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ rivers state people's democratic party òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tí a yàn sípò kọmíṣọ́nà fún iṣẹ́ ó dipò náà mú láàrin ọdun 2003 sí 2006
noureddine bouyahyaoui moroccan football defender noureddine bouyahiaoui ni èdè larubawa نور الدين البويحياوي ni a bini ọjọ keje óṣu january ọdun 1955 jẹ agbabọọlu afẹsẹgba to ṣèrè gẹgẹbi defender fun órilẹ ede morocco àṣèyọri elere naa ṣèrè fun kac kenitra ni ọdun 1986 noureddine kopa ninu cup agbaye ti fifa
mustapha fadli moroccan boxer mustapha fadli jẹ afẹṣẹja ti órilẹ ede morocco fadli kopa ninu idije awọn ọkunrin omi ara to fuyẹmen's lightweight ni summer olympic to waye ni ọdun 1984
mustafa el haddaoui moroccan footballer mustafa el haddaoui ni ede larubawa مصطفى الحداوي ni a bini ọjọ keji dinlọgbọn óṣu july ni ọdun 1961 ni ilu casablanca jẹ akọṣẹmọṣẹ agbabọọlu afẹsẹgba to ti fi ẹyinti àṣèyọri mustapha lo ọpọlọpọ igba rẹ gẹgẹbi àkọṣẹmọṣẹ agbabọọlu afẹsẹgba ni ilu france arakunrin naa wa lara awọn ...
comfort ekpo comfort ekpo tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kọkànlá ọdun 1954 jẹ́ ọ̀mọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó ti fi ìgbàkan jẹ́ adarí yunifásitì ìlú uyo ìtàn ayé rẹ̀ wọ́n bí comfort memfin ekpo ní uyo ní ọdun 1954 àwọn òbí rẹ̀ ni etim udoh isok àti nyong sam akpan comfort ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi olùkọ́ sunday school teacher àti...
zaynab alkali zaynab alkali tí a bí ní ọdún 1950 jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà tí wọ́n sínú ìdílé tura-mazila ní ìpínlẹ̀ bọ̀rnó ó lọ ilé-ìwé queen elizabeth secondary school ti ìlú ilorin kí ó tó tẹ̀síwájú ní yunifásítì àmọ́dù béllò abu zaria àti ní yunifásítì bayero ti kano buk láti gba àmì-ẹ̀yẹ dokitaphd nínú ìmò ingli...
juice wrld american rapper singer and songwriter 19982019 jarad anthony higgins tí wọ́n bí ní 2 1998 tí ó sì kú ní december 8 2019 tí orúkọ ìnágijẹ rẹ̀ ń jẹ́ juice wrld tí kíkọ sílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ juice world jẹ́ ọmọọmọ olórin ilẹ̀ ìlú america àti akọrin sílẹ̀ ó jẹ́ aṣíwájú fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ emo rap àti soundcloud rap sound...
labid khalifa moroccan footballer labid khalifa tí a bí ní ọjọ́ àkọ́kọ́ óṣu kìíní ọdún 1955 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá tó jẹ́ defender fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè morocco àṣèyọri labid ṣerè fun kac kenitra arákùnrin náà ṣerè fún orílẹ̀-èdè morocco ní cup fifa agbayè ti ọdún 1986
abdelmajid lamriss moroccan footballer abdelmajid lamriss tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kejì ọdún 1959 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá tó jẹ́ defender fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè morocco àṣèyọri abdelmajid ṣeré fún far rabat eléré náà ṣeré fún cup fifa àgbáyé ní ọdún 1986
safia abdul rahman safia abdul rahman tí a bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù karùn-ún ọdún 1986 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ti àwọn obìnrin ti ilẹ̀ ghana kan tí ó ń mú iwájú fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá àwọn obìnrin ti orílẹ̀-èdè ghana ó díje nínú ìdíje fifa women's world cup ti ọdún 2007 ní ìpele ẹgbẹ́ ó ṣeré fún ghatel la...
kulu yahaya kulu yahaya tí a bí ní ọjọ́ kẹtàlélógún osù kaàrún ọdún 1976 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ti orílẹ̀-ède ghana tí ó gbá bọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí olùgbèjà fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ti obìnrin ghana ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó kópa ní bi fifa world cup women's world cup ti ọdún 1999 lórí ìpele ẹgbẹ́ ó ṣeré fún ...
sherifatu sumaila sherifatu sumaila tí a bí ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kọkànlá ọdún 1996 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá agbabọọlu ọmọ orílẹ̀-ède ghana kan tí ó ń ṣeré bíi agbábọ́ọ̀lù ìkọlù olùgbèjà àti olùkọlù fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù primera federación spanish rayo vallecano ó ṣeré tẹ́lẹ̀ fún djurgårdens if fotboll àwọn obìnrin ó t...
suzzy teye suzzy dede teye tí a bí ní ọjọ́ kẹfà oṣù kọkànlá ọdún 2002 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-ède ghana kan tí ó dúró bí alárinà ní orí pápá fún hatayspor ní super league ti turkey àti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin ghana isé ẹgbẹ́ teye gbábọ́ọ̀lù fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù premier league women's ghana lady strikers fc ní ọdún 20...
faiza ibrahim faiza ibrahim tí a bí ní ọjọ kejìlélógún oṣù kẹta ọdún 1990 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ti orílẹ̀-èdè ghana ó gbá bọ́ọ̀lù ní ipò iwájú ó mi àwọ̀n ní bi ayò mẹ́ta sí òdo pẹ̀lú mali ní bi ìdíje àwọn obìrin afirika ti ọdún 2012 ó mi àwọ̀n ní bi ayò mẹ́ta sí òdo pẹ̀lú etiopia ní bi ìdíje àwọn obìrin afirika t...
rumanatu tahiru rumanatu tahiru tí a bí ní ọjọ kẹrin osù kẹfà ọdún 1984 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gba ọmọ orílẹ̀-ède ghana tí ó seré lókè-òkun tí ó mú ipò iwájú lórí pápá ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àwọn obìrin orílẹ̀-ède ghana ó wà lára àwọn tí ó kópa ní bi fifa women's world cup ti ọdún 2007 lórí ìpele ẹgbẹ́ ó ṣeré fún...
ayo ayoola-amale ayo ayoola-amale jẹ́ akéwì àti agbẹjọ́rò ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ìpìlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ wọ́n bí ayo ayoola-amale sí ìlú jos nàìjíríà ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ peace movement nígbà tí ó sì jẹ́ ọmọdé ó sì di adarí ẹgbẹ rotaract club àti girls guide nígbà tí ó sì jé ọ̀dọ́ ọmọbìnrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ obìnrin t...
elvan abeylegesse ethiopian-born long-distance runner for turkey elvan abeylegesse tó fìgbà kan jẹ́ hewan abeye አልቫን አበይለገሠ ní èdè amharic àti elvan can ní orílẹ̀-èdè turkey ni a bí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù september ní ọdún 1982 jẹ́ eléré ìdárayá tó máa ń sáré ọlọ́nà jínjìn ta bí sí orílẹ̀-èdè ethiopia arábìnrin náà ti kóp...
arinola olasumbo sanya arinola olasumbo sanya tí a bí ní ọdun 1953 jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní yunifásítì ìlú ìbàdàn àti kọmíṣọ́nà fún ètò-ìlera ara ti ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ orílẹ̀-èdè nàìjíríà arinola di òjògbón ní ọdun 2000 èyí tí ó sọ di obìnrin àkọ́kọ́ láti di ọ̀jọ̀gbón nínú bí a ṣe ń dá isẹ́ ara bọ̀ sípò physiotherapy ní orílẹ̀ afr...
ejgayehu taye ethiopian athlete ejgayehu taye ni a bini ọjọ kẹwa óṣu february ọdun 2000 jẹ elere idaraya ti ọna jinjin ti órilẹ ede ethiopia taye naa gba ami ọla ti idẹ fun 3000 metres ti idije agbaye ti inu ilè to waye ni ọdun 2022 àṣèyọri ni óṣu july ọdun 2018 ejgayehu taye gba ami ọla ti ninu idije u20 iaaf agbaye t...
samuel adesina gbadebo alake of abeokuta samuel adesina gbadebo èyí tí a tún mọ̀ sí gbadebo ii jẹ́ ọba ní orílẹ̀-èdè naijiria tí ó di oyè aláké ti ìlú ẹ̀gbá mú ṣáájú kí ó tó di alake gbadebo ṣe àwọn ètò ní ìwọ̀-oòrùn nàìjíríà láti polongo iṣẹ́ àgbẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ a bí gbadebo ní oṣù kẹsàn-án odun 1908 sí ìdílé oba gba...
serkalem biset abrha serkalem biset abrha ni a bí ní ọjọ́ kẹjọ oṣù march ọdún 1987 arábìnrin náà jẹ́ asáré tó wá láti orílẹ̀-èdè ethiopia tó sì tún kópa nínú oríṣiríṣi ìdíje ọ̀nà jínjìn ìgbésí ayé biset biset kọ́ iṣẹ́ eré-sísá pẹ̀lú bizunesh deba genna tufa àti atalelech asfaw ní ilẹ̀ new york àti albuquerque new mexic...
netsanet achamo netsanet achamo tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù december ọdún 1987 jẹ́ eléré sísá ọ̀nà jínjìn ti orílẹ̀-èdè ethiopia àṣeyọrí netsanet parí pẹ̀lú ipò kẹrin nínú ìdíje àwọn eléré ní ọdún 2006 ní 3000 metres achamo kópa nínú ìdíje àgbáyé ti eré-sísá nínú 300 metres ti steeplechase ní ọdún 2007 arábìnrin náà gb...
kate okikiolu kate adebola okikiolu tí a bí ní ọdún 1965 jẹ́ onímọ̀ máàsì ọmọ orílẹ̀-èdè ilẹ̀ọba aṣọ̀kan àwọn ènìyàn mọ̀ ọ́n fún iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú elliptic differential operators àti inner-city children ìpìlẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ a bí okikiolu ní 1965 ní england bàbá rẹ̀ ni george olatokunbo okikiolu ó jẹ́ onímọ̀ mátì tó gb...
ilu owu ẹ̀yà owu jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ yorùbá ní ìwọ̀-oòrùn áfíríkà ago-owu ní abeokuta ni ibi ti àwọn owu ti pọ̀jù sí káàkiri ile yoruba ni a sì ti máa ń rí àwọn owu àjọṣepọ̀ ìjọba ilẹ̀ yorùbá gbòòrò kọjá ilẹ̀ nàìjíríà dé orílẹ̀-èdè benin àti togo orísun àkọsílẹ̀ ìtàn àwọn owu kọ́kọ́ wáyé lẹ́yìn ìtẹ̀dó wọn ní ago-ow...
olowu ti ilu owu olowu ti ilu owu jẹ́ ọba aládé ìlú owu àwọn ọmọọba tí wọ́n yàn láti ìdílé ọba mẹ́fa tí ń ṣe amororo otileta ayoloye akinjobi akinoso àti lagbedu ló ń darí ìlú òwu àwọn ògbóni àti àwọn ológun ló máa ń ran ọba lọ́wọ́ balógun ló jẹ́ olórí àwọn ìjòyè lábẹ́ rẹ̀ ni a sì rí otun osi seriki aare ago àti jagunn...
abdul-azeez olajide adediran abdul-azeez olajide adediran tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí jandor jẹ́ olóṣèlú nàìjíríà oniroyin oníṣòwò àti onímọ̀-ẹ̀rọ òun ni alága ẹgbẹ́ lagos4lagos àti olùdíje ipò gómìnà ìpínlẹ̀ èkó lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú people’s democratic party pẹ̀lú olùdíje àti igbákejì rẹ̀ funke akindele ó gba doctorate honor...
akọ̀ròyìn akòròyìn jẹ́ ẹni tí iṣẹ́ rè ní ṣe pẹ̀lú gbígbà ìròyìn yálà ní àkọsílẹ̀ tàbí lórí fọ́nrán tàbí àwòrán ṣíṣe àtòjọ àti àtúntò àwọn ìròyìn náà àti ìpínkárí ìròyìn náà fún àwọn ará-ìlú
àtòjọ àwọn akọ̀ròyìn ilẹ̀ nàìjíríà
wale aboderin gbadebowale aboderin 1958 30 may 2018 jẹ́ oniroyin láti orílẹ̀-èdè naijiria oníṣòwò àti alábòójútó eré-ìdárayá òun ni alága ìwé-ìròyìn punch títí ìgbà tó kú èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ tí bàbá rẹ̀ dá sílè ìwé-ìròyìn vanguard ṣe àpejúwe ìwé-ìròyìn yìí gẹ́gẹ́ bíi òpó kan pàtàkì fún iṣẹ́ ìgbéròyìn jáde ó kàwé ní gov...
kunle ajibade kunle ajibade tí wọ́n bí ní 28 may 1958 jẹ́ akoroyin olóòtú àti òǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè naijiria ní ọdún 1995 pẹ̀lú olusegun obasanjo àti àwọn oníròyìn mẹ́ta mìíràn ni wọ́n fi ẹ̀sùn ọ̀tẹ̀ kàn ní ọdún 1998/1999 ó di ọmọ ẹgbẹ́ feuchtwanger ní villa aurora ní los angeles ètò-ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ rẹ̀ ajíbádé gboyèẹ̀...
adanech zekiros ethiopian long-distance runner zekiros adanech ni a bini ọjọ kẹrin dinlọgbọn óṣu kẹta ni ọdun 1982 jẹ elere sisa ti ọna jinjin órilẹ ede ethiopia lori iṣẹ rẹ gẹgẹbi elere sisa awọn ibi to ti gbegba oroke julọ ni315937 ninu 10000 metres to waye ni sollentuna ni ọjọ keji dinlọgbọn óṣu june ni ọdun 2005 11...
grace ebun delano grace ebun delano tí a bí ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kọkànlá ọdún 1935 ní kaduna jẹ́ núrsì àti agbẹ̀bí tí ó kópa nínú ètò family planning àti àwọn ǹkan míràn nípa ètò ibí ní nàìjíríà ó wà lára àwọn tó dá ẹgbẹ́ reproductive and family health kalẹ̀ òun sì ni adarí ẹgbẹ́ náà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdun ní ọdún 1993 ó gb...
levi chibuike ajuonuma levi chibuike ajuonuma tí a bí ní ọjọ́ kejì oṣù kejìlá ọdún 1959 tí ó sì kú ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹfà ọdún 2012 tí a mọ̀ sí livi jẹ́ ọ̀mọ̀wé naijiria o fìgbà kan jẹ́ sọrọ̀sọ̀rọ̀ lórí rédíò àti lórí ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán ó sì gbajúgbajà fún ètò rẹ̀ ní alaalẹ́ ọjọ́ àbámẹ́ta tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ open house...
beatrice aboyade beatrice aboyade tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹjọ ọdun 1935 jẹ́ olùmójútó ilé ìkàwélibrarian àti ọ̀jọ̀gbọ́n fẹ̀híntì ní nàìjíríà ààjọ world encyclopedia of library and information services se àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ara àwọn tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àmójútó ilé ìkàwé ní nàìjíríà aboyade ti ṣíṣe ní ilé ìkàwé...
henry akubuiro henry akubuiro jẹ́ akọ̀rọ̀yìn àti àti òǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ rẹ̀ akubuiro kàwé gboyè nínú ìmò englisi ni yunifásítì ìpínlẹ̀ ímò owerri ni ọdun 2003 ó bèrè isé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọ̀rọ̀yìn nígbà tó sì jẹ́ ọmọ ilé-ìwé yunifásitì ìpínlè imo níbi tí ó ti dá editor of the elite—the student...
jerry fisayo bambi jeremiah fisayo bambi jẹ́ akòròyìn ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà olùpìlẹ̀ṣẹ̀ òǹkọ̀wé ìròyìn agbàlejò ìròyìn àti showhost lórí africanews àti euronews iṣẹ́ rẹ̀ bambi ṣe àgbéjáde àti àfihàn “inspire africa” ètò tẹlifísàn kan pẹ̀lú àwọn ìtàn ti ìsọdọ̀tun ìyípadà àti ipa ní áfíríkà ó papọ̀ gbàlejò ètò ìròyìn à...
tunji bello olatunji bello ọjọ́-ìbí ọjọ́ kìíní oṣù keje ọdún 1961 jẹ́ àgbẹjọ́ro onímọ̀ nípa àyíká onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ńsì òṣèlú oníròyìn àti kọmíṣọ́nà tó jókòó fún àyíká àti ọrọ̀ omi lábẹ́ ìṣàkóso babajide sanwo-olu ní ìpínlẹ̀ èkó ó jẹ́ ọmọ eko ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ó ní bsc ìwé gíga yunifásítì ti ìbàdàn níbi tí ó ti...
moses da rocha moses da rocha èyí tí a bí ní oṣù kìn-ín-ní ọdún 1875 tí ó sì kú ní oṣù karùn-ún ọdún 1942 jẹ́ onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó akọ̀ròyìn àti olóṣèlú ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn onímọ̀ ìṣẹgun òyìnbó bí i africanus horton orisadipe obasa àti john k randle tí wọ́n mú iṣé ìṣègùn mọ́ òṣèlú ní ọdún 1923 nígbà tí ó kù dẹ̀dẹ̀ kí...
abebech afework ethiopian long-distance runner abebech afework bekele ni a bini ọjọ kọkanla óṣu december ni ọdun 1990 jẹ akọṣẹmọsẹ elere sisa ti ọna jinjin to dari lori idaji marathon abebech ṣóju fun órilẹ ede ethiopia ninu idije iaaf agbaye cross country ti iadaji marathon ati idije iaaf agbaye ti idaji marathon awọn...
ruti aga ethiopian long-distance runner ruti aga ni a bini ọjọ kẹrin dinlogun óṣu january ni ọdun 1994 jẹ elere sisa ti ọna jinjin ti órilẹ ede ethiopia ruti yege ninu ere awọn óbinrin ti ọdun 2019 ninu marathon ti ilẹ tokyo àṣèyọri ni ọdun 2012 aga gba ami ẹ̀yẹ ti silver ninu idije agbaye ti junior ere sisa to waye ni...
stephanie busari stephanie busari tí a bí ní ọdún 1977 jẹ́ akọ̀ròyìn ọmọ orílẹ̀-èdè nàìjíríà kan tí ó gbajúmọ̀ fún gbígbá “proof of life” ní ìyasọ́tọ̀ fún àwọn ọmọbìnrin ilé-ìwé chibok tí ó pàdánù ní àtẹ̀lé agbawi bring back our girls èyí tí ó yọrí sí ìdúnadúrà pẹ̀lú boko haram pé yọrísí ìtúsílẹ̀ tí ó ju ọgọ́run àwọn ọ...
nasiru l abubakar ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ wọ́n bí nasiru ní ọjọ́ kẹ́rin oṣù kẹsàn-án ọdún 1977 ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ àríwá kaduna ní ìpínlẹ̀ kaduna nasiru kẹ́kọ̀ọ́ gboyè pgd nínú ẹ̀kọ́-ìmọ̀ mass communication ní buk gboyè pgd nínú ẹ̀kọ́-ìmọ̀ ìbáṣepọ̀ orílẹ̀-èdè àti diplomacy ní àfikún sí ẹ̀kọ́ hnd nínú ẹ̀kọ́...
moses da rocha
taiwo abioye taiwo olubunmi abioye jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ englisi ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà òun ni obìnrin àkọ́kọ́ láti di ìgbàkejì adarí covenant university ìpìlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ a bí taiwo ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gún oṣù kínní ọdun 1958 ní kaduna sínú ìdílé àwọn òbí tó wá láti ìpínlẹ̀ ogun abioye gba àmì-ẹ̀yẹ àkọ́kọ́ nínú ìm...
john payne jackson biography orukọ john payne jackson ọjọ ibi 1848-03-25 ibi ibi cape palmas liberia ọjọ ikú 1915-08-01 ibi iku lagos orilẹ-ede liberia british west african iṣẹ́ ìròyìn ti a mọ fun igbasilẹ ọsẹ ọsẹ ni lagos igbesi aye john payne jackson 25 march 1848 1 august 1915 je onise americo-liberian kan ti a bi ...
ngozi nwozor-agbo nigerian journalist 1974-2012 ngozi nwozor-agbo ọjọ́ 21 oṣù kẹfà ọdún 1974 sí ọjọ́ 28 oṣù karùn-ún ọdún 2012 jẹ́ oníròyìn orílẹ̀-èdè nàìjíríà òǹkọ̀wé àti akéwì tí gbogbo ènìyàn ń pè ní ‘lady campus’ ó jẹ́ ìlú mọ̀ọ́ká ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà gẹ́gẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó dá ìwé-ìròyìn ọgbà fáṣítì sílẹ̀ tí ó p...
pelu awofeso pelu awofeso jẹ́ akọ̀ròyìn ọmọ orílẹ̀-edè nàìjíríà ó jẹ́ ọ̀ǹkọ̀wé nípa ìrìn-àjò àti àṣà tó ń gbé ìlú èkó ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ó jáwẹ́ olúborí nínú ìdíje ti cnn/multichoice ní africa fún àmì-ẹ̀yẹ ti ẹ̀ka àwọn oníròyìn nípa ìrìn-àjò ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní à ń ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gé bíi aṣáájú òǹkọ̀wé nípa ìrìn-àjò...
jahman anikulapo jahman oladejo anikulapo ọjọ́ ìbí je ọjọ́ kẹrìndínlọ́gún osù kíní ọdún 1963 ó jẹ́ onísẹ́ ìròyìn àti akọ̀wẹ́ àṣà aníkúlápó jẹ́ ọmọ naijiria ó kẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ tíátà ní yunifásitì tí ìbàdàn ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ akọọlẹ iṣẹ ọna rẹ ni the guardian bi iṣẹ ọna ati olóòtú media ni 1993 o ṣiṣẹ bi iṣẹ ọna ati olóòtú media...
zemzem ahmed ethiopian runner zemzem ahmed deko ni a bini ọjọ kẹta dinlọgbọn óṣu december ni ọdun 1984 ni ilu asella jẹ elere sisa ti steeplechase ati ti óju ọna ti órilẹ ede ethiopia arabinrin naa jẹ ọkan lara awọn elere sisa ti steeplechase to pegede julọ ni ilẹ ethiopia àṣèyọri zemzem ṣoju ethiopia ninu olympics ti ...
mizan alem ethiopian long-distance runner mizan alem ni a bini keji leelogun óṣu january ni ọdun 2002 jẹ elere sisa lobinrin ti ọna jinjin to gbajumọ ninu metres ti ẹgbẹrun marun ti órilẹ ede ethiopia àṣèyọri ni ọdun 2021 mizan gba ami ẹyẹ idanilọla ti gold ninu idije u20 ere sisa agbaye
kola muslim animasaun olóyè kola muslim animasaun tí wọ́n bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù keje ọdún 1939 jẹ́ akọ̀ròyìn orílẹ̀-èdè nàìjíríà àti alága ẹgbẹ́ olótùú fún ìwé-ìròyìn the vanguard tó ń ṣáájú àwọn ìwé-ìròyìn ní orílẹ̀-èdè nàìjíríà ìwé rè from 1939 to the vanguard of moodern journalism ní wọ́n gbé jáde ní nigerian inst...
elfenesh alemu elfenesh alemu ni a bini ọjọ kẹwa óṣu june ni ọdun 1975 ni lemo arya arsi zone jẹ elere sisa ti ọna jinjin órilẹ ede ethiopia arabinrin naa gbajumọ lori ere ti marathon àṣèyọri elfenesh ṣọju órilẹ ede ethiopia ninu olympics summer ti ọdun 2000 ati 2004 arabirnin naa kopa ninu marathon ti idjije agbaye lo...
femi d amele amele adefemi olubunmi d a bíi ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹ̀wá tí gbogbo ènìyàn mọ sí femi d ó jé olugbohunsafefe rédíò àti tv lorile-ede nàìjíríà alagbasọ ọrọ olupilẹṣẹ ayélujára ati oniroyin òṣèlú awọn kókó ọrọ ti ó jíròrò lori awọn ètò rẹ jẹ́ ìdàgbàsókè ètò imulo orilẹ-ede ọrọ-ajé mikro ìṣàkóso ìjọba àti àwọn...
samuel aruwa samuel aruwan tí a bí ní ọjọ́ kẹwà osù kárun ọdún 1982 o jẹ́ oníròyìn ọmo orílẹ̀-èdè nàìjíríà ati komisana àkọ́kọ́ fún ilẹ́-iṣẹ àabò abẹ́lé àti ọ̀rọ̀ abẹ́lé ti ipinlẹ kaduna
lanre alfred lanre alfred jẹ́ akọ̀ròyìn òǹkọ̀wé àti akéde ọmọ nàìjíríà òun ni olùtèjáde the capital olóòtú awujọ iṣaaju ati akọ̀ròyìn ìwé ìròyìn this day onkọ̀wé ìwé márùn àti ẹni tí ó ni itàkan ni ilu ekò nàìjíríà alfred lanre jẹ́ olóòtú ìwé-ìròyìn celebrity journalism iṣẹ́ rẹ̀ nínú ẹ̀ka ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ náà ni iṣẹ́ oníròyì...